I Samuẹli 17:1-58

Lesson 211 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Iwọ mu idà, ati ọkọ, ati awà tọ mi wá; ṣugbọn emi tọ ọ wá li orukọ OLUWA awọn ọmọ-ogun” (I Samuẹli 17:45).
Notes

Ni Ogun Pẹlu awọn Filistini

Awọn Ọmọ Israẹli ti lọ si oju ogun lati ba awọn Filistini jà, awọn ọta wọn atijọ kan naa. “Ogun na si le si awọn Filistini ni gbogbo ọjọ Saulu” (I Samuẹli 14:52). Ninu ori ikẹrinla Iwe Samuẹli Kin-in-ni, a kà pe, lati igbà de igbà ni awọn Ọmọ Israẹli ti maa n lepa ti wọn si maa n pa ninu awọn Filistini.

Kò si igba kan ti awọn Ọmọ Israẹli ṣẹgun ọta yii patapata gẹgẹ bi Gideoni ti ṣe si awọn ara Midiani (Ẹkọ 194). Gideoni le wọn titi de odi keji Jordani, o pa wọn, o mu awọn ọba wọn meji, o si ṣẹgun gbogbo ẹgbẹ ogun wọn. “Bḝli a si tè̩ ori Midiani ba niwaju awọn Ọmọ Israẹli, nwọn kò si gbè ori wọn soke mọ. Ilẹ na si simi ni ogoji ọdún li ọjọ Gideoni” (Awọn Onidajọ 8:28).

Awọn Ọmọ Israẹli kò ṣẹgun awọn Filistini patapata. Awọn Ọmọ Israẹli kò fi igbà kan bori wọn patapata nigba ti Saulu ati ọmọ rè̩ Jonatani n ṣaaju wọn lọ si ogun. Akoko kan si de ti awọn Ọmọ Israẹli tẹgun si apa kan afonifoji kan, ti awọn Filistini si dó si apa keji. Lati ibudo awọn Filistini ni akikanju wọn, Goliati ara Gati ti jade wá. Awọn Filistini fi gbogbo igbẹkẹle wọn sara ọkunrin kan ṣoṣo yii. Wọn n fẹ lati sọ ija naa di ijakadi laarin ọkunrin meji. O ṣọwọn lati ri orilẹ-ède kan ti o jẹ fi gbogbo igbẹkẹle rè̩ fun iṣẹgun lori ọkunrin kan, ṣugbọn awọn Filistini ni igbẹkẹle ti o pọ to bẹẹ ninu Goliati ti wọn fi fẹ lati fi gbogbo ogun naa ṣe ti ija laarin ọkunrin kan ati akikanju wọn.

Goliati

Goliati jẹ òmirán, ẹni ti giga rẹ to ilọpo mẹta giga ti ẹlomiran ninu ẹnyin ọmọde. Bi ọmọdekunrin kan ba duro lori ejika ọkunrin kan, sibẹ kò i ti le ga to Goliati. Dajudaju, ọkunrin ti o jẹ abami eniyan ni sisigbọnlè̩ bayi ni lati ba ni lẹru lati wò, paapaa bi o ba ni ẹmi ati agbara ti o pọ gẹgẹ bi o ti ga to yii. Lati kekere ni a ti fun Goliati ni ẹkọ nipa jijẹ ọmọ-ogun. O ni ẹwu irin ti o bò o lara ti o wuwo to bẹẹ gẹẹ ti kò si ọkunrin ti o le gbe e, ki a má tilẹ sọ pe ki o gbe e wọ lati fi jagun. Goliati mu ọkọ ti o dabi igi awọn ahunṣọ lọwọ, ori ọkọ naa si wuwo to ẹgbẹta oṣuwọn ṣekeli irin. Lẹyin gbogbo eyi, ọkunrin kan n lọ niwaju rè̩ ti o rù awà rè̩.

Ipenija

Goliati duro niwaju awọn ọmọ-ogun Filistini lati pè awọn Ọmọ Israẹli ni ijà. Laisi aniani,pẹlu ohun rè̩ nla ni o gàn ogun Oluwa. Dajudaju, pẹlu ọkàn igberaga ni o ran wọn leti pe wọn kò ni ẹni ti o ni agbara bi oun. Goliati fi wọn ṣe ẹlẹya lati jade wa lati ba awọn Filistini jà. Lai ṣe aniani, pẹlu ifunnu ni o sọ fun wọn pe wọn kò ni ẹni kan laarin wọn ti o le ba oun jà. Pẹlu igberaga ni Goliati kigbe pe, “Fi ọkunrin kan fun mi, ki awa mejeji jumọ ba ara wa jà.”

Idaamu Israẹli

Bayi ni Goliati bù è̩tẹ lu awọn Ọmọ Israẹli li aarọ ati li alẹ fun ogoji ọjọ. Dajudaju, ojoojumọ ni akikanju yii n ni igboya ti o si tubọ n kún fun igberaga si i, nigba ti àyà awọn Ọmọ Israẹli tubọ n domi ti è̩rù si n bà wọn si i. Boya idaamu ba awọn eniyan naa nitori pe àyà Saulu ọba wọn ti di omi. Tẹlẹ ri Saulu ki i ṣe ojo. Nigba ti Ẹmi Oluwa bà le Saulu (I Samuẹli 11:6), o dide si ipenija Nahaṣi ara Ammoni, o si ṣe aṣaaju awọn Ọmọ Israẹli lọ si iṣẹgun. Wọn pa awọn ara Ammoni, wọn si fọn wọn ka to bẹẹ ti meji wọn kò kù ni ibi kan (I Samuẹli 11:11).

Ki ni ṣe ti giga ọkunrin yii ati ọrọ igberaga ti o n jade lati ẹnu Filistini kan ṣoṣo mu è̩rù ba Saulu? Nitori pe Saulu ṣe aigbọran ni. O ti kọ Ọlọrun silẹ, Ẹmi Ọlọrun si ti fi i silẹ (I Samuẹli 16:14). Saulu ati awọn ọmọ-ogun Israẹli daamu, è̩rù si ba wọn lọpọlọpọ. Kò ha si ẹni kan ti yoo kò ẹni ti o n pe wọn nijà yii loju?

Ohun ti Dafidi Yàn

Ọlọrun ni ọmọkunrin kan ti o ti pese silẹ fun akoko yii gan an. Ni afonifoji Ela, eyi ti o to ibusọ melo kan si oju ogun ni ọdọmọkunrin kan wà ti o ni awọn ẹgbọn arakunrin mẹta ni oju ogun. O ti jẹ ẹni ti o n ru ihamọra Saulu, o si ti maa n fi ohun-elo orin kọrin fun ọba ri. Oun i ba ti duro lọdọ ọba, ṣugbọn Dafidi “yipada lẹhin Saulu, lati maā tọju agutan baba rè̩.” Dipo ti i ba fi maa gbe igbesi ayé irọrun, faaji, ati ọlẹ, o yàn igbesi-ayé iṣé̩, wahala ati ewu. O jẹ olutọju agutan baba rè̩.

Boya Dafidi yàn iṣé̩ yii nitori pe o fun un ni akoko ati anfaani fun adura ati ṣiṣe aṣaro niwaju Ọlọrun. Dajudaju, iṣẹ Dafidi gẹgẹ bi oluṣọ agutan ṣe e yẹ fun ogun, o si fun un ni igbẹkẹle kan ninu Ọlọrun, iru iriri ti oun ki ba ti ni anfaani lati ni bi o ba ṣe pe aafin ọba ni o duro si.

Iṣẹ ti a Ran Dafidi

Ni ọjọ kan Jesse ran Dafidi ọmọ rè̩ ni iṣẹ kan. O jẹ iṣẹ ti a ba ran ọmọ-ọdọ tabi iranṣẹ - eyi ni lati mu ounjẹ lọ fun awọn ọmọ baba rè̩ ti o wà ni oju ogun. Gẹgẹ bi o ti maa n ri fun gbogbo awọn obi ti ọmọ wọn wà ni ajo, Jesse n fẹ mọ nipa alaafia awọn ọmọ rè̩ -- bi nnkan ti ri fun wọn ati bi wọn ba si ni ounjẹ to lati jẹ. Pẹlu aniyan ninu ọkàn rè̩ fun awọn ọmọ rè̩, Jesse sọ fun Dafidi pe ki o mu agbado didin ati iṣu akara mẹwa fun awọn ẹgbọn rè̩, ati “warakaṣi” mẹwa fun olori-ogun wọn.

Dafidi ṣe eto, o si fi agutan wọnni le olutọju kan lọwọ, nitori pe o jẹ ẹni ti o n boju to iṣẹ rè̩ loju mejeeji ati “olõtọ ninu ohun diẹ.” O dide ni kutukutu owurọ, o si ṣe gẹgẹ bi baba rè̩ ti paṣẹ fun un.

Ni Oju Ogun

Nigba ti Dafidi de oju ogun, awọn ẹgbẹ ọmọ-ogun mejeeji tẹgun, ẹgbẹ kin-in-ni si ekeji. Dafidi ri awọn arakunrin rè̩; bi o si ti n ba wọn sọrọ, Goliati jade, ẹni ti ohun rè̩ n bú jade pẹlu ọrọ ipenijà. Dafidi gbọ ọrọ naa, o si ṣiṣẹ ninu ọkàn rè̩ yatọ si bi o ti ri ninu ọkàn gbogbo Israẹli. Dipo ti i ba fi sá ki è̩rù si ba a lọpọlọpọ, Dafidi beere pe, “Tali. . . . Filistini yi iṣe, ti yio fi mā gàn ogun Ọlọrun alāye?”

Nitori pe Dafidi fẹ gbe ọlá Ọlọrun ati Israẹli ró, owu ati ilara gbina ninu ọkàn ẹgbọn rè̩ agba si i. Eliabu bu è̩tẹ lu iṣẹ Dafidi gẹgẹ bi oluṣọ-agutan. O fi eke tako Dafidi pe o wa “lati ri ogun”, nigba ti o ṣe pe Dafidi jade wa fun ifẹ ti o ni si awọn ẹgbọn rè̩.

Ìdí Kan

Saulu ti ṣeleri ọrọ ati ọlá fun ẹnikẹni ti o ba pa Goliati. A tun ṣeleri pe, idile baba rè̩ yoo si di ominira ni Israẹli – ominira kuro ninu sisan owo ibode, owo-ode ati sisin ọba. O dabi ẹni pe Dafidi kò tilẹ gbe ọkàn le erè naa lọ titi. O ni “Ko ha ni idi bi?” Dafidi n fẹ lati lọ si oju ogun, ki i ṣe fun erè tabi iyin eniyan, ṣugbọn fun ogo Ọlọrun alaaye. Dafidi woye pe ipenijà ti Goliati pè wọn nijà jẹ kikẹgàn Ọlọrun ati awọn Ọmọ Israẹli.

Loni, Ọlọrun yoo lo ọmọkunrin tabi ọmọbinrin, tabi ẹnikẹni ti o ba duro fun otitọ laarin gbogbo inunibini ti o dojukọ ọ. Nipa ọrọ ati iṣesi eniyan, a le mu ẹgàn kuro lara Ihinrere. Ẹni ti o ba mu iduro rere ninu ọkàn rè̩ fun Kristi ki yoo rè̩wè̩si nitori ọrọ buburu tabi idojukọ lati ọdọ awọn ẹbi rè̩, awọn ẹni ti o yẹ ki o fun un ni atilẹyin ati iranlọwọ.

Ẹri Dafidi ati Igbagbọ Rè̩

Dafidi lọ si ọdọ Saulu, ọba, pe ki o fun oun ni ààyè lati lọ ba Goliati jà. Ko sọ ohunkohun nipa erè; o sa fẹ lati sin Ọlọrun rè̩ ati orilẹ-ède rè̩. Saulu sọ fun un pe ọmọde ni oun i ṣe, Goliati si jẹ ẹni ti a ti kọ ni ogun jijà. Dafidi dá ibẹrù ti o wa ninu ọkàn rè̩ lẹkun pẹlu ọrọ igbagbọ, o si sọ idi rè̩ ti o fi ni ireti ati igboya bẹẹ. Bi o tilẹ jẹ pe Dafidi jẹ ọdọmọkunrin, ki i ṣe ẹni ti kò ni iriri gẹgẹ bi Saulu ti rò. Oju ko ti Dafidi lati sọ pe oun n ṣọ agutan baba oun. Kò gberaga ninu agbara ti rè̩, ṣugbọn o fi ogo ati iyin fun Ọlọrun bi o ti n sọ nipa igboya rè̩ nigba ti o gba ẹran rè̩ silẹ - o gba awọn ọdọ-agutan naa silẹ, o si pa awọn ẹranko buburu wọnni. Nigba ti Dafidi sọ iriri rè̩, o sọ pẹlu igbagbọ pe Ọlọrun yoo gba oun bẹẹ gẹgẹ lọwọ Goliati. Dajudaju, nipa awọn iriri wọnyi, Dafidi ti kọ lati gbẹkẹle Ọlọrun ni kikun jù ti atẹyinwa lọ, ati lati maa fi igboya ṣe iṣẹ rè̩.

Aabo tí a ti Danwo

Saulu gba fun Dafidi lati lọ ba Goliati ja. Bi o tilẹ jẹ pe Saulu ko lọ si oju ogun lati lọ jà, ọrọ rè̩, “OLUWA yio si pẹlu rẹ” jẹ adura ti o gbà fun Dafidi.

Saulu gbiyanju lati fi ihamọra rè̩ wọ Dafidi. Ranti pe Saulu jẹ ẹni ti o sigbọnlè̩ - o ga jù gbogbo Israẹli lọ lati ejika rè̩ soke – Dafidi si jẹ ọdọmọkunrin. Idiwọ ni ihamọra Saulu yoo jẹ fun Dafidi.

Ko si ohun ti o buru ninu ihamọra Saulu; o dara pupọ fun Saulu, ṣugbọn kò ba Dafidi mu. Igba miiran wà ti ẹni ti a ko ti gbà ọkàn rè̩ la yoo gbà Onigbagbọ ni amọran lati gbẹkẹle ihamọra ti ara tabi nnkan ayé yii, ko si si eyi ti o yẹ Onigbagbọ ninu wọn. Ọlọrun n fẹ ki awọn eniyan Rè̩ gbẹkẹ wọn le Oun, aabo kan ṣoṣo naa ti o yẹ Onigbagbọ. “Ibukun ni fun ọkunrin na ti kò rin ni imọ awọn enia buburu” (Orin Dafidi 1:1).

Ọlọrun a maa ni imurasilẹ ati ihamọra fun ọmọ-ogun Agbelebu. Olukuluku Onigbagbọ ni eyi si le ba mu. “Ẹ jẹ alagbara ninu Oluwa, ati ninu agbara ipá rè̩. Ẹ gbe gbogbo ihamọra Ọlọrun wọ, ki ẹnyin ki o le kọ oju ìjà si arekereke Eṣu. . . . Nitorina ẹ gbe gbogbo ihamọra Ọlọrun wọ ki ẹnyin ki o le duro tiri si ọjọ ibi, nigbati ẹnyin bá si ti ṣe ohun gbogbo tan, ki ẹ si duro. Ẹ duro nitorina lẹhin ti ẹ ti fi àmure otitọ di ẹgbẹ nyin, ti ẹ si ti di igbaiya ododo ni mọra; Ti ẹ si ti fi imura ihinrere alafia wọ ẹsẹ nyin ni bàta: Léke gbogbo rè̩, ẹ mu apata igbagbọ, nipa eyiti ẹnyin ó le mā fi paná gbogbo ọfa iná ẹni ibi ni. Ki ẹ si mu aṣibori igbala, ati idà Ẹmi, ti iṣe ọrọ Ọlọrun” (Efesu 6:10-17).

Dafidi sọ bayi nipa ihamọra Saulu, “Emi kò le ru wọnyi lọ, nitoripe emi kò i dan a wò.” O ti dan Ọlọrun wò. O bọ ihamọra Saulu kuro, o si di igbagbọ rè̩ ninu Ọlọrun mu. Dafidi sure lọ si odò, o si ṣà okuta marun ti o jọlọ; o si jade lọ pade Goliati pẹlu kànnakànna oluṣọ-agutan ni ọwọ rè̩.

Fun Ogo Ọlọrun

Otitọ ni pe okuta marun ti o jọlọ ati kànnakànna jẹ ohun ija yẹpẹrẹ; ṣugbọn nigba ti a ba fi ohun kekere le Ọlọrun lọwọ lati dari rè̩, O le fi ṣe ohun nla. Dafidi lo ohun wọnni ti o ni lọwọ. Kò gbà a ni akoko ti o pọ lọ titi lati mura silẹ fun ijà naa.

Ọrọ orin àṣàyan yii fi han pe Ọlọrun ti lo awọn nnkan kéekèeké ti o wa ni arọwọto, nigba ti a ba yà wọn sọtọ fun Oluwa.

“S̩amgari ni ọpa malu kan,

Dafidi ni kànnakànna kan,

Samsoni ni pari ẹrẹkẹ kẹtẹkẹtẹ kan,

Rahabu ni owu kan,

Maria ni ororo ikunra diẹ,

Aaroni ni ọpa kan,

Dorka ni abẹrẹ kan,

Gbogbo wọn ni a lo fun Ọlọrun.”

Goliati fi oju iṣátá wo ọmọdekunrin ti o dahun ipènijà rè̩ yii. O fi Dafidi ré nipa oriṣa rè̩, bi ẹni pe ọrọ ihalẹ le pa eniyan. Goliati fọnnu, o si ni igbẹkẹle ninu ara rè̩.

Dafidi kò wa ọlá ti ara rè̩. O fi iyin ati ogo fun Ọlọrun, ki gbogbo aye ba le mọ pe Ọlọrun kan wà ni Israẹli, ki gbogbo Israẹli ba si lè mọ pe Ọlọrun ki i fi idà ati ọkọ gba ni là. Dafidi lọ si ogun ni orukọ Oluwa. “Nitoriti emi ki yio gbẹkẹle ọrun mi, bḝni idà mi kì yio gbà mi” (Orin Dafidi 44:6).

Ọlọrun Dari Rè̩

Goliati pẹlu didún iro ihamọra rè̩ dide pẹlu igberaga bi ẹni pe o fẹ da bira. Dafidi sun mọ ọn lai ni ihamọra pupọ, lai bè̩rù, lati pade ọta. Pẹlu ipinnu o fi okuta kan sinu kànnàkànna naa, o rin sẹyin, o si “fi i” pẹlu gbogbo agbara rè̩ ati adura ninu ọkàn rè̩. Ọlọrun dari okuta yii, o si wọ agbari Goliati lọ, ọkankan ibi ti ihamọra kò si. O fẹrè̩ jẹ pe ki awọn ẹgbẹ ọmọ-ogun Israẹli ati Filistini to mọ pe ija naa ti bẹrẹ ni Goliati ti ṣubu lulẹ. Dafidi sure tọ ọ. Kò ni ida lọwọ rè̩; ṣugbọn pẹlu ida Goliati – boya o tobi to bẹẹ ti Dafidi ni lati fi ọwọ mejeeji gbe e – o si bẹ ori Goliati kuro, akikanju awọn Filistini ti o kẹgàn Israẹli.

Ọkan ṣoṣo ni Dafidi lo ninu okuta marun ti o mu fun ihamọra rè̩. Kò daju pe Dafidi ni ero lati lo maraarun naa. Dajudaju, o n fẹ lati ni aniṣẹku - gẹgẹ bi oore-ọfẹ ati agbara Ọlọrun ti o wà fun olukuluku Onigbagbọ - ki i ṣe iwọn diẹ ti o to fun ogun naa tabi fun idanwo naa. Ọlọrun ni agbọnmagbẹ iṣura oore-ọfẹ ati agbara fun awọn ti yoo wa A.

Iṣẹgun

Nigba ti awọn Filistini rii pe akikanju wọn kú, wọn sá, wọn kunà lati ṣe gẹgẹ bi adehun ti Goliati ṣe pe wọn o jẹ ẹru Israẹli bi a ba pa Goliati. Awọn Ọmọ Israẹli lepa awọn Filistini titi rekọja afonifoji naa, ani de Ekronu. Ọpọlọpọ awọn Filistini ni o gbọgbẹ, awọn Ọmọ Israẹli si ni ọpọlọpọ ọrọ si i nipa ikogun lati-inu agọ awọn ọta.

Bayi ni o si ri, nitori pe ọdọ kan gboju-gboya lati duro fun eyi ti o tọ, Ọlọrun gba ọlá, a pa awọn ọta run, a mu awọn Ọmọ Israẹli lọkàn le, ọba si bu ọlá fun Dafidi.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni ṣe ti Dafidi n ṣọ awọn agutan baba rè̩?
  2. Ọna wo ni Dafidi fi de oju-ogun?
  3. Bawo ni Goliati ṣe gàn ogun Ọlọrun alaaye?
  4. Ki ni ṣe ti Dafidi fi fẹ dahun ipenijà Goliati
  5. Idojukọ wo ni Dafidi ni?
  6. S̩e àpejuwe Goliati.
  7. Aabo wo ni Dafidi ni nigba ti o ba Goliati jà?
  8. Ki ni awọn ohun ijà rè̩?
  9. Ki ni ṣe ti Dafidi kọ ihamọra Saulu?
  10. Ta ni ẹni ti o ṣẹgun?