Lesson 212 - Junior
Memory Verse
AKỌSORI: “Nipa eyi ni gbogbo enia yio fi mọ pe, ọmọ-ẹhin mi li ẹnyin iṣe, nigbati ẹnyin ba ni ifẹ si ọmọnikeji nyin” (Johannu 13:35).Notes
Ipadabọ Dafidi si Aafin
Dafidi ti pada bọ si aafin Saulu ti oun ti ori òmirán ti o ti fi kànnàkànnà rè̩ pa. Jonatani, ọmọ Saulu ti o si tun jẹ arẹmọ ti ijọba tọ si lẹyin ikú baba rè̩, ba Dafidi pade o si fẹran rè̩. A pinnu rè̩ pe ki Dafidi má ṣe pada si ile mọ, ṣugbọn ki o maa ba Jonatani gbé.
Aṣọ ti ọmọ-ọba naa maa n wọ a maa fi ipo rè̩ ni ilu hàn, kiki awọn ọmọ-alade nikan ni wọn si ni ẹtọ lati wọ ọ. Jonatani mu ninu aṣọ ọla wọnyi o si fi wọn fun Dafidi lati wọ. Eyi fi hàn bi Jonatani ti fẹran Dafidi tó. O ṣetan lati yọọda ipo rè̩ ni aafin fun ọrẹ rè̩.
Dajudaju, a mọ wi pe Ọlọrun ti fi ororo yàn Dafidi tẹlẹ gẹgẹ bi ọba ti oye kàn, nitori bẹẹ eyi yoo ṣẹ dandan. S̩ugbọn a ko le sọ boya Jonatani ati Saulu ti i mọ ni akoko yii.
Ifẹ Aimọ-ti–ara-ẹni Nikan
Ifẹ ti o wà laarin Dafidi ati Jonatani jẹ ọkan ninu awọn ifẹ ti o ga jù lọ ti ayé ti i mọ. Jonatani ṣetan ki i ṣe lati fi ọla ati agbara rè̩ silẹ nikan, ṣugbọn ojurere baba rè̩ pẹlu, nitori ti Dafidi ẹni àmi-ororo Oluwa.
Njẹ iwọ rò pe o le jẹ oninuure to bẹẹ lati fi ohun ti o dara jù lọ lọwọ rẹ fun ọkan ninu awọn ọrẹ rẹ? Iwọ yoo ha maa ba a ṣọrẹ sibẹ ti a ba fun un ni ọlá ti o rò pe iwọ ni o tọ si? O ha ti gbadura doju ami lati mọ pe ifẹ Ọlọrun ni o jẹ nigba ti a ba fun ẹlomiran ni ohun ti o jẹ iṣé̩ ti rẹ lati ṣe? Ki i ṣe pe Jonatani fẹ pe ki a gbà ọla ti rè̩ kuro lọwọ rè̩ ki a si fi i fun Dafidi nikan, oun tikara rè̩ ni o tilẹ gbe e fun un tọkantọkan.
Ifẹ Jonatani si Ọlọrun
Jonatani mọ Oluwa, o si ti n gbadun ibukun Rè̩ latẹyin wá. Ni igba kan oun ati ọkunrin ti o ru ihamọra-ogun rè̩ ti kọlu odindi ibudo-ogun awọn Filistini kan, pẹlu iranlọwọ Ọlọrun wọn si ti ni iṣẹgun. Jonatani kò gbẹkẹle agbara ati ọgbọn ti rè̩. O sọ fun ọdọmọkunrin rè̩ pe: “Wa, si jẹ ki a lọ si budo-ogun awọn alaikọla yi: boya OLUWA yio ṣiṣẹ fun wa: nitoripe kò si idiwọ fun OLUWA lati fi pupọ tabi diẹ gba là” (I Samuẹli 14:6). Ti Oluwa ni ogun naa yoo jẹ, Oun kò si wá ọpọlọpọ ọmọ-ogun lati ran An lọwọ. Awọn ẹni-iyasọtọ meji ṣẹgun agbara ibi.
Iya-ara ẹni sọtọ Jonatani yii ni o jẹ ki o fẹran Dafidi to bẹẹ lai rò ti ara rè̩. Ifẹ si Ọlọrun ninu ọkàn rè̩ ni o jẹ ki o bu ọlá fun Dafidi, bi o ti lẹ ṣe pe bi a ba fi oju ti aye wò o, a le ka Dafidi si ẹni ti n ba Jonatani du ipò.
Ikorira Saulu fun Dafidi
Saulu kò ni iru ifẹ ti ọmọ rè̩ ni fun Dafidi ni akoko yii. O n woye pe bi Dafidi ba di ọba anfaani ki ọba maa ti idile Saulu jade wá yoo bọ kuro ni idile Saulu. Samuẹli woli ti sọ ṣiwaju pe eleyi yoo ri bẹẹ gẹgẹ bi abayọri si aigbọran Saulu, sibẹ Saulu gbiyanju ninu agbara ti rè̩ lati yi idajọ Ọlọrun pada.
Ọlọrun ni agbara lori gbogbo eniyan ati lori gbogbo agbara Satani. Eniyan jẹ alailagbara lati ba A jà. Kò yẹ ki a bè̩rù rara pe Oluwa yoo kọ awọn ọmọ Rè̩ silẹ, nibikibi ti o wu ki ọta le doju kọ wọn.
Awọn ojiṣẹ Ọlọrun ni orilẹ-ède ti awọn keferi gbe n sin ẹmi eṣu ti sọ nigba pupọ nipa bi irọkè̩kè̩ agbara eṣu ti doju kọ wọn pupọ to, ṣugbọn nigba gbogbo, agbara Ọlọrun ni o bori. Satani kò le ṣẹgun eniyan Ọlọrun ti o ba wà labẹ È̩jẹ Jesu.
Ikorira Saulu di ipaniyan. O paṣẹ fun Jonatani ati awọn iranṣẹ rè̩ lati pa Dafidi. Nigba ti Dafidi fi ara pamọ, Jonatani gbiyanju lati ṣe alaye fun baba rè̩ pe ọrẹ oun ayanfẹ kò ṣe ibi si wọn ri afi ire nikan, ati pe kò yẹ fun iku rara. O dabi ẹni pe Saulu gbà bẹẹ, Dafidi si pada lati maa gbe inu aafin. S̩ugbọn lai pẹ Saulu tun binu, o si da irunu pupọ jade si Dafidi.
Ipo ẹlẹgẹ ni Dafidi wà, ẹmi rè̩ si wà ninu ewu ni iṣẹju kọọkan; nitori naa o ba Jonatani gberò nipa rè̩. O rò pe boya i ba sàn ki oun lọ kuro ki oun má si tun pada mọ.
Jonatani kò gbagbọ pe baba oun le buru to bẹẹ. Dajudaju oun le fi ọkàn tan Saulu pe kò jẹ pa ọrẹ kòrikòsùn oun. Dafidi rò pe oun ko ṣe ohunkohun ti oun fi yẹ lati ku, ṣugbọn bi a ba ri aiṣedeedee ninu oun, oun i ba fẹ ki Jonatani ṣe idajọ naa dipo ki a mu oun wa siwaju Saulu.
Idanwo Naa
Awọn Ju a maa ṣe ẹbọ oṣu titun ni ibẹrẹ oṣu wọn kọọkan. Eyi jẹ akoko pataki ni idile ọba, Dafidi si mọ pe a o maa reti oun nibi tabili fun ase alẹ naa. Eyi jẹ anfaani fun un lati jẹ ki Jonatani mọ erò ọba si oun. Dafidi sọ fun Jonatani pe oun kò ni wa sibi ase naa, ati pe, bi ọba ba binu nitori aiwa oun, ki Jonatani mọ daju pe ọba ti pinnu lati ṣe oun ni janba.
O dùn Saulu pe Dafidi kò wá, ṣugbọn o rò pe boya o ti huwa kan nipa eyi ti o fi di alaimọ fun ẹbọ naa. S̩ugbọn nigba ti Dafidi kunà lati tun wà ni aye rè̩ ni alẹ ọjọ keji, o fura pe Jonatani mọ nipa aiwa rè̩, o si beere pe, “Ẽṣe ti ọmọ Jesse kò fi wá si ibi onjẹ lana ati loni?”
Jonatani ati Dafidi ti ṣe adehun ohun ti wọn o wi bi ọba ba beere iru ibeere bẹẹ. Jonatani wi fun un pe Dafidi ti tọrọ ayè lati lọ si Bẹtlẹhẹmu fun ọjọ diẹ ki o ba le wà lọdọ awọn ara ile rè̩ ni akoko ẹbọ ọdun kan ti wọn n ṣe, Jonatani si ti yọọda fun un pe o le lọ. Saulu binu gidigidi. O kọ Jonatani ni ọmọ patapata. O sọ gbangba fun Jonatani pe n ṣe ni o n fi itẹ ijọba naa tọrẹ fun Dafidi. O ranṣẹ pe ki a mu Dafidi wa lẹsẹkẹsè̩ fun pipa.
Jonatani gbiyanju lati fi ọrọ we ọrọ pẹlu baba rè̩ pe Dafidi ko huwa buburu kankan, ṣugbọn n ṣe ni eyi tubọ ru ibinu Saulu soke to bẹẹ ti o fi sọ è̩ṣin rè̩ si Jonatani. Jonatani wa ri i daju pe kò si nnkankan ti oun le fi mu ki baba oun gbipè̩, o si dide kuro nibi tabili, inu rè̩ si bajẹ gidigidi pe a korira ọrẹ oun timọtimọ bẹẹ.
Tita Ọfa Soju Ami
Dafidi ati Jonatani ti fi ohun ṣọkan pe ni ọjọ kẹta lẹyin ti Dafidi ba ti kuro, wọn o pade ni pápa kan ti o jinna si aafin. Wọn ṣe eyi lai jẹ ki Saulu fura. Jonatani ko ọrun ati ọfa rè̩ jade lati lọ tafa, o si mu ọmọdekunrin kan pẹlu rẹ lati maa ṣa awọn ọfa naa fun un. Ọfa Jonatani fo jade lọ kuro ninu ọrun rè̩, lọ sọna jijin ninu papa, ọmọdekunrin naa si sure lati lọ ṣa wọn pada. Bi o ti n sare lọ, Jonatani tun ta ọfa kan sii lọna jijin siwaju rè̩, Jonatani si kigbe wi pe, “Ọfa na ko ha wà niwaju rè̩ bi?” Ami ti wọn ti jọ fohùn si niyi fun Dafidi lati mọ pe ẹmi oun wa ninu ewu laarin ile ọba. Nigba ti ọmọdekunrin naa kó awọn ọfa naa de, Jonatani ran an pada lọ si ilu, Jonatani si lọ pade Dafidi.
Ipinya
Rò o bi ọkàn awọn ọkunrin meji naa yoo ti ri! Wọn fẹran ara wọn pupọ. Jonatani fẹran Dafidi gẹgẹ bi ẹmi ara rè̩; Dafidi naa sọ nipa Jonatani pe: “Ifẹ rẹ si mi jasi iyanu, o jù ifẹ obirin lọ” (II Samuẹli 1:26). Sibẹ naa wọn ni lati pinya, boya wọn kò tun ni pade mọ ninu ayé yii; ṣugbọn wọn ni ireti pe wọn yoo pade ni Ọrun.
Ni iwaju Ọlọrun, wọn da majẹmu wi pe awọn yoo maa fẹran ara wọn, awọn yoo si maa ṣe rere fun idile ara wọn niwọn igba ti wọn ba wà laayè. Wọn mọ wi pe akoko le de ti Dafidi yoo ni lati gbejà Jonatani lodi si baba rè̩, ti aṣiiri ba tú wi pe Jonatani ti ran Dafidi lọwọ lati salọ.
Jonatani ni oju ẹmi lati ri wi pe ọjọ kan yoo de ti a o doju gbogbo awọn ọta Dafidi bolè̩, ati pe ijọba rè̩ yoo ni agbara. O bè̩ Dafidi pe nigba ti ọjọ naa ba de ki a má ṣe gbagbe idile oun, bi o tilẹ jẹ pe Jonatani funra rè̩ le ti ku. Jonatani ati Dafidi sọkun bi wọn ti n tun è̩jé̩ wọn jẹ; lẹyin igba ti wọn si ti fi ẹnu ko ara wọn ni ẹnu, wọn pinya. Jonatani pada lọ si ile rè̩, Dafidi si bẹrè̩ igbesi aye ifarapamọ, eyi ti yoo gbà a ni ọdun mẹwa sii.
Questions
AWỌN IBEERE- Bawo ni Dafidi ti ṣe pada si aafin Saulu?
- Bawo ni Jonatani ṣe fẹran Dafidi?
- Ki ni Saulu rò nipa Dafidi?
- Ki ni ṣe ti Saulu huwa si Dafidi bi o ti ṣe?
- Bawo ni Jonatani ati Dafidi ṣe dán Saulu wò lati mọ iru ọkàn ti o ni?
- Majẹmu wo ni Dafidi ati Jonatani da?
- Bawo ni Jonatani ṣe jẹ ki Dafidi mọ ọkàn baba rè̩?