I Samuẹli 22:1, 2, 6-19; 23:1-29

Lesson 213 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI:“ Emi o kepè OLUWA, ti o yẹ lati ma yìn; bḝli a o si gbà mi lọwọ awọn ọta mi” (Orin Dafidi 18:3).
Notes

Dafidi Sa Asala

Nitori owu Saulu, o di ọranyàn fun Dafidi lati fi agbala nì silẹ nibi ti oun ati Jonatani ti n gbadùn irẹpọ wọn gẹgẹ bi ọrẹ timọtimọ, ki o si sa asala lọ si ijù. Lẹyin ti Dafidi ati Jonatani ti ba ara wọn da majẹmu lati fẹran ara wọn titi laelae, Dafidi lọ fi ara pamọ ni iho Adullamu.

Baba Dafidi ati awọn arakunrin rè̩ ko kọ ọ silẹ ni akoko yii ti ko ri ojurere ọba mọ. Wọn tọ ọ lọ nibi ti o fara pamọ si. Awọn miiran lọ ba a nibẹ bakan naa -- awọn alaini tabi awọn ti o wà ninu wahala ti wọn rò pe awọn le jẹ iranlọwọ fun Dafidi ki oun naa si ran awọn naa lọwọ.

A Tẹwọgbà awọn Alaini

Gbogbo awọn ti o tọ ọ wa ni Dafidi tẹwọgbà. Oun ko kọ awọn ti ayé ko fẹran, awọn ti wọn wà ninu gbèsè ati ninu ibanujẹ, ati awọn ti ko ri itẹlọrun. Titẹwọgbà ti o tẹwọ gbà wọn rán wa leti ifẹ nla Jesu si gbogbo eniyan. Nigba ti Jesu wà ni ayé, o fẹrẹ jẹ kiki awọn ti wọn wà ninu wahala ti wọn kò si le ran ara wọn lọwọ ni wọn maa n tẹti silẹ tọkantọkan si Oluwa ti wọn si n tẹle E. Ipe ti O na ọwọ rè̩ si wọn, “Ẹ wá sọdọ mi gbogbo ẹnyin ti nṣiṣẹ, ti a si di ẹrù wuwo le lori, emi o si fi isimi fun nyin” (Matteu 11:28), ṣi n jade lọ bakan naa loni. Ẹnikẹni ti o n fẹ alaafia ọkàn rè̩, imularada fun ara rè̩, tabi isimi fun idaamu ọkàn rè̩ le wa sọdọ Jesu pẹlu igboya ki o si ri ohun ti o n fẹ gbà.

Fun igbà diẹ Dafidi ni lati wà ni ipo isansa ati fifi ara pamọ bayii, ṣugbọn ileri wà fun un pe yoo jẹ ọba Israẹli, nigba naa yoo si le ran awọn olootọ ọmọ-ẹyin rè̩ lọwọ.

Awa ti a jẹ Onigbagbọ dabi èrò ati alejo ninu ayé yii, ṣugbọn Ọba wa ti ṣeleri fun wa pe ni ọjọ kan Oun yoo gbe ijọba Oun kalẹ ni ayé yii, gbogbo awọn olootọ ọmọ-ẹyin Rè̩ yoo si maa ṣe akoso pẹlu Rè̩ ninu ijọba alaafia. Nigba ti o kù diẹ ki a kan Jesu mọ agbelebu, O sọ fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ pe: “Ẹnyin li awọn ti o ti duro ti mi ninu idanwo mi. Mo si yàn ijọba fun nyin, gẹgẹ bi Baba mi ti yàn fun mi; ki ẹnyin ki o le mā jẹ, ki ẹnyin ki o si le mā mu lori tabili mi ni ijọba mi, ki ẹnyin ki o le joko lori ité̩, ati ki ẹnyin ki o le mā ṣe idajọ fun awọn è̩ya Israẹli mejila” (Luku 22:28-30).

Owu Saulu

Kò pẹ ki Dafidi to ni ọmọ-ẹyin ti o to irinwo (400) ọkunrin. Eyi mu ki Saulu kun fun owú. O beere lọwọ awọn iranṣẹ rè̩ ti o yi i ka pe, “Ọmọ Jesse yio ha fun olukuluku nyin ni oko ati ọgba ajara bi, ki o si sọ gbogbo nyin di olori ẹgbẹgbẹrun ati olori ọrọrun bi? Ti gbogbo nyin fi dimọlù si mi?” O n fẹ mọ idi rè̩ ti awọn eniyan fi n tẹle Dafidi lẹyin. O ha le jẹ pe wọn n reti ọrọ pupọ ati ọlá lati ọwọ rè̩ wa?

Ki i ṣe pe Dafidi ni lati fi abẹtẹlẹ bẹ awọn ọmọ-ogun rè̩. Wọn n tẹle e nitori pe wọn fẹran rè̩. Saulu ko ṣe ohunkohun fun wọn, nitori eyi wọn ki yoo padanu ohunkohun bi wọn ba fi i silẹ.

Saulu kaanu fun ara rè̩, o si gbiyanju lati mu ki awọn eniyan naa kaanu fun oun. O gbiyanju lati rú ẹmi ibakẹdun soke ninu ọkàn wọn nipa sisọ fun wọn pe Jonatani ọmọ oun paapaa ditè̩ si oun, ẹnikẹni kò si sọ fun oun. Saulu rò pe ẹnikẹni ko fẹran oun mọ, tabi kaanu oun.

A Pa awọn Alufa Ọlọrun

Ẹni kan wà laarin awọn darandaran Saulu ti kò pada lẹyin ọba. Ara Edomu ni ti a n pè ni Doegi. Doegi wà ni Nobu, ilu kan ti awọn alufa n gbe, nigba ti Dafidi wá beere iranlọwọ lọdọ awọn alufa. Ahimeleki ti fun un ni akara lati jẹ ati idà Goliati. S̩ugbọn ki ni ṣe ti ki yoo fi ṣe bẹẹ? Dafidi kọ ni ana ọba, oun ko ha si ti mu iṣẹgun nla wa fun Israẹli bi? Ta ni ẹni ti o ni ẹtọ jù lọ si ida Goliati bi kò ṣe Dafidi ẹni ti o pa òmiran naa? Nigba gbogbo ha kọ ni oun ti jẹ olootọ si ọba? Ko si idi rè̩ ti Ahimeleki kò gbọdọ fi ran Dafidi lọwọ. Dafidi kò sọ ohunkohun fun awọn alufa nipa wahala ti o wà laarin oun ati Saulu.

S̩ugbọn ibinu wère ti o wà ninu Saulu ti pa oyé rè̩ ré̩, o si paṣẹ pe ki a pa gbogbo awọn alufa. Saulu ti lọ jinna kuro lọdọ Ọlọrun to bẹẹ ti ko fi bè̩rù lati pa awọn alufa Oluwa. Awọn iranṣe Saulu ni ibè̩rù Ọlọrun ninu ọkàn wọn ju ti oluwa wọn lọ; wọn si bè̩rù Ọlọrun jù bi wọn ti bè̩rù ọba. Wọn kọ lati mu aṣẹ ọba ṣẹ lati pa awọn alufa. S̩ugbọn Doegi, eniyan buburu ara Edomu nì, boya ni ireti pe oun yoo ri ojurere ọba nipa mimu aṣẹ buburu yii ṣẹ, o pa gbogbo awọn alufa afi Abiatari, ẹni ti o sa asala. Ki i ṣe awọn alufa nikan ni a pa, ṣugbọn awọn aya wọn ati awọn ọmọ wọn, ati awọn ẹran ọsin wọn. Iwọ rò o wò bi Saulu ti ya eniyan buburu to lati igba ti Ẹmi Ọlọrun ti fi i silẹ!

Abiatari, alufa kan ṣoṣo ti o kù lọ si ọdọ Dafidi lati wà pẹlu rè̩. Awọn mejeeji ni wọn n sa fun Saulu nisisiyi, o si dara fun wọn lati fara pamọ si ibi kan naa.

Awọn Filistini Gbogun ti Keila

Ni akoko yii awọn Filistini tun gbe ogun dide si awọn ilu Juda. Awọn ọmọ-ogun wọn ti o n wa ikogun kiri a maa wọ agbegbe awọn Ọmọ Israẹli lọ lati ji ohun ọgbin wọn. Nigba ti Dafidi gbọ pe awọn Filistini ti wa si Keila lati jà ilẹ ipaka wọn ni ole, aanu awọn ara ilu naa ṣe e, o si pinnu lati ran wọn lọwọ. S̩ugbọn o kọkọ beere lọwọ Ọlọrun bi o ba tọ bẹẹ fun oun lati ko awọn ọmọ-ogun rè̩, eyi ti o pọ to ẹgbẹta (600) ọkunrin nisisiyi lati gbejà Keila. Oluwa si dahun pe “Lọ, ki o si kọlu awọn ara Filistia ki o si gbà Keila silẹ.”

Dafidi ni ẹgbẹ ọmọ-ogun, ṣugbọn awọn ọkunrin rè̩ ki i ṣe jagunjagun ti o ni igboyà. Wọn ni, “Awa mbè̩ru nihinyi ni Juda; njẹ yio ti ri nigbati awa ba de Keila lati fi oju ko ogun awọn ara Filistia?” Bi wọn ba n bè̩rù nigba ti wọn wà nibi ti aabo wà, ki ni yoo ṣẹlẹ si wọn nigba ti wọn ba lọ doju kọ ewu?

È̩rù ko ba Dafidi ṣugbọn o fẹ ni idaniloju pe ifẹ Oluwa ni fun oun lati ṣe bẹẹ. Nitori naa o tun beere lẹẹkan si i, Oluwa si dahun pe “Lọ.” Eyii ni ti to fun Dafidi. O mọ pe oun n ṣe ohun ti Ọlọrun fẹ ki oun ṣe, awọn ọkunrin rè̩ ti è̩rù n ba ko tilẹ le fa a sẹyin. Awọn ọmọ-ogun wọnni ti o kun fun è̩rù si wá di onigboyà pẹlu, lẹyin ti wọn ti jade lọ lati lọ ṣe gẹgẹ bi aṣẹ Ọlọrun.

Boya Oluwa yoo pè wa lati ṣe ohun ti a rò pe a ko le ṣe. A le ri ọpọlọpọ idi ti a o fi rò pe a ko yẹ lati mu aṣẹ Ọlọrun ṣẹ. S̩ugbọn bi Ọlọrun ba wi pe, “Lọ”, a gbọdọ gbe iṣisẹ kan ki a tilẹ gbiyanju lati gbọran, bi o tilẹ jẹ pe ẹru n ba wa bi a ti bè̩rẹ. Ọlọrun yoo kiyesi igbọran wa, yoo si fi agbara kun wa fun iṣẹ naa. Iṣẹgun yoo si daju.

Awọn ọmọ-ogun Dafidi bori awọn Filistini, awọn ẹni ti o pada si ile lai ri eso ati ọkà ti wọn ti ni ireti lati kó.

Ewu ni Ilu

Dafidi ati awọn ọkunrin rè̩ duro ni Keila, ti i ṣe ilu olodi. O dabi ẹni pe wọn o wà lai lewu nibẹ jù ninu ijù lọ. S̩ugbọn nigba ti Saulu gbọ nipa ibi ti Dafidi wà, o rò pe oun ti ri anfaani nisisiyi lati mu un. O rò pe oun le do ti ilu naa, ki o se e mọ, ki o si fi ebi pa awọn ara ilu naa.

Dafidi bẹrẹ si i rò o bi awọn ara Keila yoo tilẹ duro ni iṣọkan pẹlu oun; tabi boya, nigba ti ebi ba bẹrẹ si pa wọn, wọn o fi oun le Saulu lọwọ ki wọn ba le gba ẹmi wọn là. Abiatari, alufa ti mu efodi wá pẹlu rè̩, eyi ti o jẹ pe boya Urimu ati Tummimu wà ninu rè̩. Dafidi ni ki o fi beere lọwọ Oluwa bi wọn o ba wà lai lewu laarin awọn ara Keila tabi bẹẹ kọ. Ọlọrun dahun pe Saulu yoo do ti ilu naa, awọn ara ilu naa yoo si fi wọn le Saulu lọwọ. Ko si ohun miiran ti o kù fun Dafidi ati awọn eniyan rè̩ lati ṣe bi ko ṣe lati pada si ijù ki wọn si fara pamọ sibẹ. Saulu lepa wọn lọ si ibẹ paapaa.

Laarin akoko yii, Jonatani lọ bè̩ Dafidi wò ni igba ikẹyin. Wò o bi ayọ wọn ti pọ to lati tun ri ara wọn, bi o tilẹ jẹ pe eyi yoo yọri si ikú fun wọn bi Saulu ba ri wọn papọ bẹẹ! Ifẹ wọn si ara wọn lagbara jù ibè̩rù ikú lọ.

Jonatani mu Dafidi lọkan le “ninu Ọlọrun.” Igbẹkẹle rè̩ ti o fi idi mulẹ ninu Ọlọrun ni o mu ki Jonatani sọ fun Dafidi pe: “Máṣe bẹru: nitori ọwọ Saulu baba mi ki yio tè̩ ọ: iwọ ni yio jọba lori Israẹli, emi ni yio si ṣe ibikeji rẹ.” Ko si owu ninu ọkàn Jonatani. Wọn ko tun ni anfaani lati ri ara wọn mọ, ṣugbọn o daju pe ọpọlọpọ igbà ni Jonatani gbadura fun Dafidi ni gbogbo ọdun wọnni ti Dafidi fi jẹ isansa kuro niwaju Saulu; oun ni idaniloju pe Ọlọrun yoo mu Dafidi là igbà wahala yii ja, ni ikẹyin yoo si fi i jọba lori gbogbo Israẹli.

Ko si Ibi Àabò

Ko si ibi ti Dafidi le sa pamọ ti a ko ni ri ẹni kan ti yoo ṣe ofofo fun Saulu. A tun gbọ nipa awọn ara Sifi ti wọn wi pe: “S̩e Dafidi ti fi ara rè̩ pamọ sọdọ wa ni ibi ti o ti sa pamọ si ni igbo. . . . ? Njẹ nisisiyi, ọba, sọkalẹ wá gẹgẹ bi gbogbo ifẹ ti o wà li ọkàn rẹ lati sọkalẹ; ipa ti awa ni lati fi i le ọba lọwọ.” S̩ugbọn Ọlọrun wà pẹlu Dafidi, Saulu kò si ni bà a. Dafidi gbẹkẹle Ọlọrun, o si le kọ iru iwe yii nigba naa pe, “Emi dubulẹ, mo si sùn; mo si ji; nitori ti OLUWA ti mi lẹhin” (Orin Dafidi 3:5). Dafidi ko bè̩rẹ si i ṣe aisun loru ki o si maa daamu pe, Saulu yoo ri oun.

Nitootọ nigba miiran Dafidi rè̩wè̩si ninu ọkàn rè̩, ṣugbọn nigba ti o ba rò nipa itọju ati ifẹ Ọlọrun, o le sọ ninu ọkàn rè̩ pe, “Ẽṣe ti ara rẹ kò fi lelẹ ninu mi? iwọ ṣe ireti niti Ọlọrun; nitori emi o sa ma yin i sibẹ, ẹniti iṣe iranlọwọ oju mi ati Ọlọrun mi” (Orin Dafidi 42:11).

Ni igbà kan, Saulu wà ni apakan oke kan, Dafidi si wà ni apa keji. Ni wakati ti wahala pọ pupọ bayii, awọn Filistini gbogun ti Saulu ni ile, o si ni lati pada lọ lati lọ gbà ara rè̩ silẹ lọwọ wọn. O le jẹ pe Ọlọrun mu ki eyi ṣẹlẹ ki a le fun Dafidi ni isimi diẹ kuro lọwọ awọn ti o n lepa rè̩.

Ninu awọn Psalmu Dafidi ni a ri orin yii: “Ibukun ni fun ẹniti nrò ti awọn alaini, OLUWA yio gbà a ni igbà ipọnju. OLUWA yio pa a mọ, yio si mu u wà lāye: a o si bukún fun u lori ilẹ: iwọ ki yio si fi i le ifẹ awọn ọta rè̩ lọwọ” (Orin Dafidi 41:1, 2). Igbẹkẹle ti Dafidi ni ninu Ọlọrun ti o n sìn ni eyi, o si wà lai lewu.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni ṣe ti Dafidi fi aafin Saulu silẹ?
  2. Ta ni ọrẹ rè̩ timọtimọ jù lọ ni aafin?
  3. Ki ni oun ati ọrẹ rè̩ ṣeleri fun ara wọn nigba ti Dafidi fi aafin silẹ?
  4. Ki ni ohun ti o ṣẹlẹ ni Keila?
  5. Bawo ni Dafidi ti ṣe mọ pe o lewu lati duro ni Keila?
  6. Bawo ni Jonatani ti ṣe mu Dafidi ni ọkan le?
  7. Ki ni ṣe ti ẹrù ko ba Dafidi?
  8. Ki ni fa Saulu sẹyin lati dojujà kọ Dafidi nigba ti o jẹ pe oke kan ni o wà laarin awọn mejeeji?
  9. Ki ni Jesu ṣeleri fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ ti wọn duro ti I ninu “idanwo” Rè̩?