Lesson 214 - Junior
Memory Verse
AKỌSORI:“OLUWA má jẹ ki emi nà ọwọ mi si ẹni-àmi-ororo OLUWA” (I Samuẹli 26:11).Notes
Lilepa Dafidi
Igbogun awọn ara Filistini ti fi opin si ilepa Saulu fun ẹmi Dafidi, fun saa kan. Nigba ti Saulu pada kuro lẹyin awọn Filistini, a sọ fun un pe Dafidi wà ni aginju Engedi. Iru iroyin bayi rú ikorira Saulu soke. O fẹ ṣe Dafidi ni ibi, nitori bẹẹ o pinnu lati tun sọ lu u lẹẹkan si i.
Pẹlu ẹgbè̩ẹdogun (3,000) akọni ọkunrin ti a yàn, Saulu tun bẹrẹ si i lepa Dafidi. Awọn ọmọ-ogun wọnyi yoo pọ ju awọn ọmọkunrin Dafidi lọpọlọpọ nitori pe ni akoko yii ẹgbẹta (600) ni wọn jẹ (I Samuẹli 23:13). Pẹlu imura bayi, o dabi ẹni pe Saulu yoo bori Dafidi ati awọn ọmọ ogun diẹ ti o wà pẹlu rè̩.
Aabo Dafidi
Akoko miiran ti wa ti gbogbo anfaani wà fun Saulu lati mu Dafidi. “Saulu ati awọn ọmọkunrin rè̩ ti rọgba yi Dafidi ati awọn ọmọkunrin rè̩ ká lati mu wọn” (I Samuẹli 23:26). Ọlọrun gbe iranwọ dide; Saulu ati awọn eniyan rè̩ fa sẹyin, wọn si fi Dafidi ati awọn ọmọkunrin rè̩ silẹ lati sálọ.
Nipa aṣẹ Oluwa ni a ti fi ororo yan Dafidi ni ọba. Ọlọrun ni agbara to lati pa a mọ ki O si daabo bo o titi di ọjọ ti a o fi mu Saulu kuro ti Dafidi yoo si gba ijọba.
Akoko le de ninu igbesi-aye rẹ gẹgẹ bi Onigbagbọ ti yoo dabi ẹni pe ni gbogbo ọna ọta yoo bori rẹ. Ọlọrun ni agbara to lati daabo bo ọ ki O si mu ki ọta fa sẹyin. Gẹgẹ bi Dafidi, duro ninu igbẹkẹle ati igbagbọ rẹ ninu Ọlọrun. Dafidi wipe “Ọlọrun. . . . ọkàn mi gbẹkẹle ọ: lotọ, li ojiji iyẹ-apa rẹ li emi o fi ṣe àbo mi” (Orin Dafidi 57:1).
Laarin awọn Apata
A le Dafidi kuro ni ilu, o si di ọranyan fun un lati sa pamọ laarin awọn iho-okuta ati apata ninu aginju. Saulu ko tilẹ jẹ ki o joko jẹẹ nibẹ. Ọkàn Saulu kò balẹ, o si fẹ pa Dafidi run. Saulu ati awọn ọmọkunrin rè̩ wá Dafidi kirii lori okuta awọn ewurẹ igbẹ, ni ibi giga ti o ṣe gẹrẹgẹrẹẹ ti o si ṣoro lati de. Kiki ibi – ikorira, ilara, ibinu ati owu - ni o le mu ki eniyan maa lepa ọkan ninu awọn iranṣẹ rè̩, ọkọ ọmọbinrin rè̩, ni iru awọn apata ati ibi gè̩ré̩gè̩ré̩ bayii.
Ninu Iho Kan
Laarin awọn apata naa ni awọn iho ti ki i ṣe eniyan ni o gbé̩ wà, nibi ti a gbe n ko awọn agutan pamọ si fun aabo. Boya nitori ki o ba le sinmi diẹ, Saulu wọ inu iho kan lọ, ọkan naa ti Dafidi ati awọn ọmọkunrin rè̩ ti sa pamọ si. Nitori pe lati inu imọlẹ lode ni Saulu ti wọ inu iho ti o ṣokunkun naa, oju rè̩ kò ni kọ riran daradara. Okunkun naa ti mọ oju Dafidi ati awọn ọmọkunrin rè̩ lara, wọn si le riran kederee bi wọn ti n wo ọba. Boya wọn reti lati rii bi awọn ọmọkunrin Saulu yoo ba tẹle e. O dabi ẹni pe Saulu dá nikan wà ni. Ọwọ Dafidi ati awọn ọmọkunrin rè̩ ti ba Saulu bayii. I ba ṣe pe odikeji ọrọ naa ni, bi o ba jẹ Dafidi ni o wọ inu iho ti Saulu ati awọn ọmọkunrin rè̩ sa pamọ si, wọn ko ni i ṣaanu diẹ fun Dafidi.
Aṣọ ti a Ge
Awọn ọrẹ Dafidi rọ ọ pe ki o gbe ọwọ le Saulu. Wọn sọ fun un pe Ọlọrun ni o ti fun un ni anfaani yii. O tilẹ le jẹ pe wọn n reti ki Dafidi pa Saulu. Boya o le dabi ẹni pe ohun ti eniyan nipa ti ara yoo ṣe niyi nigba ti o jẹ pe Saulu ti n lepa lati pa Dafidi. Bi awọn ọmọkunrin rè̩ ti rọ ọ, Dafidi yọ lọ ba Saulu. Lai tilẹ jẹ pe Saulu mọ wi pe o wa ni tosi rara, Dafidi gé eti aṣọ Saulu. Dafidi kò ṣe Saulu nibi rara; ṣugbọn iwọsi ni o jẹ fun iyi ọba pe ki a ri apakan aṣọ àwọleke rè̩ ni gige. Bakan naa ni o jẹ ẹri wi pe nigba ti Dafidi ni anfaani lati pa Saulu run oun kò ṣe bẹẹ.
Ikilọ
Lẹyin eyii, ọkan Dafidi da a lẹbi fun iwa iwọsi ti o hu si ipo ọla Saulu. Gẹgẹ bi ọba, Oluwa ni o fi ami ororo yan Saulu. Ọlọrun ti fi Saulu si ipo rè̩, O si gba a laaye lati wa nibẹ fun saa kan lẹyin ti Saulu tilẹ ti kọ Oluwa. Niwọn igba ti Saulu wà ni ipo yii, Dafidi kò nà ọwọ rè̩ jade lati ṣe e nibi. Lai ka bi Saulu ti huwa si i si, Dafidi pinnu lati gbọran ati lati bu ọlá fun ẹni ti n ṣe akoso lori rè̩.
Ohun rere ni lati ni àyà ti o rọ ati ẹri-ọkàn ti yoo dani lẹbi fun ẹṣẹ kekere. Boya eleyi gan an ni kò jẹ ki Dafidi da ẹṣẹ ati irekọja si Saulu lẹyin naa nipa pipa a lara. Nigba ti Ẹmi Ọlọrun ba n kilọ fun wa nipa ohun kekere, ẹ má ṣe jẹ ki a ṣe alai kà a si, ki ẹri-ọkàn wa má ba sele to bẹẹ ti yoo fi maa kọ ikilọ lati ọdọ Ẹmi Ọlọrun.
Si Ẹni Ami-Ororo Oluwa
Arun è̩tè̩ kọlu Miriamu nigba ti oun pẹlu Aaroni sọrọ odi si Mose, arakunrin wọn. Wọn kò tilẹ fi ọwọ kan Mose; wọn kàn sọrọ si i ni. Ọlọrun wi pe, “Njẹ nitori kili ẹnyin kò ṣe bè̩ru lati sọrọ òdi si Mose iranṣẹ mi?” (Numeri 12:8).
Dafidi fẹran Oluwa o si bẹrù lati bi I ninu. Dafidi ka ẹni ti Ọlọrun ti fi àmi-ororo yàn si eniyan pataki. Loni, awọn oniwaasu wa ni ẹni-àmi-ororo Oluwa. Ọwọ ti o yẹ ki a bù fun wọn ni ti ẹni ti Ọlọrun yàn lati maa waasu Ọrọ naa. O yẹ ki a ba wọn sọrọ tẹyẹtẹyẹ ki a si sọrọ nipa wọn tọwọtọwọ. O si yẹ ki a ka awọn ọmọ Ọlọrun si ẹni ọwọn ni oju Oluwa, nitori pe O fẹran wọn to bẹẹ ti O fi wẹ ẹṣẹ wọn nù ninu È̩jè̩ Jesu ati lati fi Ẹmi Mimọ Rè̩ yà wọn sọtọ. Dafidi kò pa Saulu lara, bẹẹ ni kò si gba awọn ọmọkunrin rè̩ ni ayè lati ṣe bẹẹ. Dafidi kò ba Saulu lo gẹgẹ bi ọta bi kò ṣe gẹgẹ bi ẹni àmi-ororo Oluwa ti o yẹ fun ọla (I Tessalonika 5:12, 13), ati gẹgẹ bi oluwa rè̩ ti o yẹ ki oun jẹ olootọ si (I Peteru 2:18). Awọn ọmọkunrin Dafidi yé̩ Dafidi si, wọn gbọ ti rè̩, wọn si bu ọlá fun un fun ipinnu rè̩ lati kọ lati ṣe ibi si Saulu.
Ọrọ Sisọ pẹlu Saulu
Nigba ti o ṣe, Saulu kuro ninu iho naa. Dafidi tẹle e, o si ké si i. Bi Saulu ti yi oju pada wo o, Dafidi tẹriba tọwọtọwọ, o bù ọlá fun ọba. Dafidi fi eti aṣọ naa han Saulu, o si jẹwọ pe, “Emi ke eti aṣọ rẹ. “ Dafidi fẹ ba ọba sọrọ nipa iwa rè̩ ki o má bà si ede-aiyede.
O yẹ ki a kọ ẹkọ lara Dafidi ninu nnkan yii. Bi o ba ba ẹni keji rẹ ṣe alayé, eyii le mu ki èdè-aiyede kuro; ju bẹẹ lọ, o le jẹ anfaani lati fi han pe, ni tootọ ọmọlẹyin Oluwa ni iwọ i ṣẹ. Ninu iwaasu Ori Oke, Jesu kọ ni pe: “Bi iwọ ba nmu è̩bun rẹ wá si ibi pẹpẹ, bi iwọ ba si ranti nibẹ pe, arakunrin rẹ li ohun kan ninu si ọ; Fi è̩bun rẹ silẹ nibè̩ niwaju pẹpẹ, si lọ, kọ ba arakunrin rẹ làja na, nigbana ni ki o to wá ibùn è̩bun rẹ” (Matteu 5:23, 24). Kiyesi i pe Jesu kò wi pe, “Bi o ba ti ṣè̩ arakunrin rẹ”, tabi, “Bi o ba jẹbi.” Nitootọ, Saulu ki i ṣe “arakunrin” mọ, nitori lẹyin ti o kọ Ọlọrun silẹ, Ọlọrun naa kọ ọ silẹ; ṣugbọn Dafidi ko jẹ ki ẹnikẹni ni ohun kan ninu si oun.
Ẹsun Eke
Dafidi gbiyanju lati fi ye ọba pe ẹsun eke ni a fi sun oun. Dafidi ko lepa lati ṣe ọba ni jamba. Dafidi kò da ẹbi fun Saulu, ṣugbọn awọn eniyan ti wọn gba ọba ni imọran ni o da lẹbi. Dafidi ṣe alayé fun ọba o si fi ẹri han lati mu ki ẹsùn èké naa han gbangba. Ti pe nigba ti Dafidi ni anfaani lati pa Saulu, aṣọ rè̩ nikan ni o ge jẹ ẹri pe Dafidi kò gbero ibi si Saulu tabi ijọba rè̩. “Wò, ki o si mọ pe, kò si ibi tabi è̩ṣẹ li ọwọ mi, emi kò si ṣè̩ ọ.”
Dafidi wi pe “Iwọ n dọdẹ ẹmi mi lati gba a. . . . ṣugbọn ọwọ mi ki yio si lara rẹ.” Dafidi sọ fun Saulu pe lilepa ti o n lepa oun ki i ṣe ohun ti o tọna, ati pe o jé̩ ohun abùkù fun ọlá ọba lati maa dọdẹ iru eniyan bi Dafidi -- iranṣẹ, oluṣọ-agutan, ati isansa. Pẹlu iwa irẹlẹ, Dafidi fi ilepa naa wé pe ki ọba maa lepa okú ajá tabi eṣinṣin. Dafidi ko gbeja ara rè̩ gẹgẹ bi okú ajá tabi eṣinṣin. Dafidi kò gbẹsan funra rè̩, nitori pe ti Ọlọrun ni igbẹsan ati ẹsan (Deuteronomi 32:35).
Eniyan Buburu
Gẹgẹ bi owe atijọ kan, iwa-buburu a maa ti ọdọ awọn eniyan buburu jade wá. Woli Isaiah sọrọ ti o jọ bẹẹ, “Eniakenia yio ma sọ isọkusọ, ọkàn rè̩ yio si ma ṣiṣẹ aiṣedede” (Isaiah 32:6). Dafidi wipe “Ki OLUWA ki o ṣe Onidajọ, ki o si dajọ lārin emi ati iwọ” bi o tilẹ jẹ pe kò ṣoro fun wa lati mọ ẹni ti o huwa buburu – yala Dafidi tabi Saulu.
Njẹ abayọrisi rere kan ha jade nipa ọrọ ti Dafidi ba Saulu sọ? Nipa ọrọ Dafidi, oun funra rè̩ jare; o fi igbagbọ rè̩ han pe Ọlọrun yoo gba oun; Saulu si jẹbi, gẹgẹ bi a ti le ri i nipa ọrọ Saulu funra rè̩.
Ijẹwọ Saulu
Saulu sọkun, ṣugbọn ẹkun rè̩ ki i ṣe ti ironupiwada. Alaye Dafidi ati iwa aanu rè̩ ti ọrọ wọnyii jade ni ẹnu Saulu “Iwọ ṣe olododo jù mi lọ.” O jẹwọ pe iwa rere ni Dafidi ti hu ati pe oun ti huwa buburu. Dafidi fi iwa rere san ibi. Dafidi fẹran ọta rè̩ o si ṣe rere fun Saulu ti o korira rè̩ (Matteu 5:44). Saulu kò tọrọ idariji lọwọ Ọlọrun tabi Dafidi. S̩ugbọn o wi pe Ọlọrun yoo fi ire san an fun Dafidi fun inurere ti o ni.
Saulu jẹwọ pe Dafidi yoo jọba ni tootọ, o si tọrọ idaniloju pe Dafidi kò ni pa idile oun run, gẹgẹ bi o ti jẹ aṣà ni ọpọlọpọ orilẹ-ede nigba ti ọba titun ba gba ijọba. Dafidi pinnu fun Saulu. Imuṣẹ ileri naa ni o mu ki Dafidi tọju Mefiboṣeti, ọmọ Jonatani ti o jẹ arọ (II Samuẹli 9:7, 13), oun ni o si fa ijiya awọn ti o pa Iṣboṣeti ọmọ Saulu (II Samuẹli 4:5, 11, 12).
Ni Alaafia
Dafidi ati Saulu pinya ni alaafia. “Nigbati ọna enia ba wù OLUWA, On a mu awọn ọtá rè̩ pāpa wà pẹlu rè̩ li alafia” (Owe 16:7). Fun saa kan Saulu sinmi lati maa lepa Dafidi kiri. Saulu lọ si ile rè̩, dajudaju pẹlu idalẹbi ati itiju. Dafidi duro si ibi aabo awọn apata wọnni sibẹ. Ọkan rè̩ ni lati balẹ gidigidi, nitori ti ẹri-ọkan rè̩ mọ gaara niwaju Ọlọrun ati eniyan. Oun kò nawọ rè̩ lati ṣe ẹni àmi-ororo Oluwa ni ibi.
Questions
AWỌN IBEERE- Nibo ni Dafidi sa pamọ si?
- Ki ni ṣe ti Dafidi fi wà ni iru ayè bẹẹ?
- Ki ni ṣe ti Saulu fi n lepa Dafidi kiri?
- Bawo ni Saulu ti ṣe pade Dafidi?
- Ki ni ṣe ti Dafidi ge aṣọ Saulu?
- Ki ni awọn ọmọkunrin Dafidi fẹ ṣe si Saulu?
- Ki ni ṣe ti wọn kò fi pa Saulu?
- Ki ni itumọ “ẹni àmi-ororo OLUWA” ti Dafidi n tẹnu mọ?
- Bawo ni o ti ṣe ṣẹlẹ ti wọn fi pinya ni alaafia?