Lesson 215 - Junior
Memory Verse
AKỌSORI: “Iwọ máṣe wipe, Emi o gbẹsan ibi; ṣugbọn duro de OLUWA, on o si gbà ọ” (Owe 20:22).Notes
Lilepa Dafidi
Lẹẹkan si i awọn ara Sifi mu iroyin nipa Dafidi tọ Saulu lọ (I Samuẹli 23:19). Saulu ti dawọ lilepa Dafidi duro fun igba diẹ. Iroyin awọn ara Sifi tun rú ikorira ati owu soke ninu ọkàn Saulu si Dafidi. Lati tun bẹrẹ ilepa Dafidi, Saulu gbá ẹgbẹẹdogun (3,000) àṣàyàn ọkunrin jọ lati lepa rè̩ ni Sifi.
Boya Saulu ki ba tun lepa Dafidi bi awọn ara Sifi ko ba rú ọkan rè̩ soke nipa ihin ti wọn mu wa. Ọrọ wọn ru iwa buburu inu ọkàn Saulu soke, ọkàn ẹni ti o ti “sé le nipa ẹtan ẹṣẹ” (Heberu 3:12, 13). Awọn ara Sifi tikara wọn ko lepa Dafidi; ṣugbọn nipa ṣiṣofofo Dafidi, awọn ara Sifi ti lọwọ si ipinnu buburu Saulu lati pa Dafidi. Ki a má ṣe ri i pe a n rú awọn ẹlomiran soke lati dè̩ṣẹ, ki a si gba ọna bẹẹ jẹ alajọpin ninu ẹṣẹ wọn. Awọn ọmọde miiran le ṣe alai da è̩ṣẹ kan tikara wọn, ṣugbọn ki wọn maa ti ẹlomiran lati lọ ṣe e. Nigba ti wọn ba rú iwa buburu ati ikorira soke, awọn paapaa jẹbi pẹlu awọn ẹlomiran.
Nigba ti Saulu gbọ nipa ibi ti Dafidi wà, lẹsẹ kan naa ni o yara jade lati lepa rè̩. Dafidi ṣe ohun ti o yatọ si eyii nigba ti o gbọ nipa ibi ti Saulu wà. Dafidi kò jade lọ lati jagun gẹgẹ bi awọn ẹlomiran ti maa n ṣe si awọn ọta wọn. Dafidi ko ni eredi ti yoo fi ja. Lati wà ni ibi ti kò si ewu ni Dafidi n lepa, ki i ṣe lati bori Saulu. Nipa yiyẹra kuro ni ọna Saulu, Dafidi fi hàn pe oun mu suuru o si n fẹ lati “duro de OLUWA.” Boya i ba ti rọrun lati gba ẹmi Saulu, ṣugbọn nigba naa Dafidi i ba jẹbi è̩jè̩ Saulu ẹni-àmi-ororo Oluwa.
Dajudaju ni akoko yii ni Dafidi kọ Psalmu (54) ikẹrin-le-laadọta. O ni, “Ọlọrun li oluranlọwọ mi. . . . O ti yọ mi kuro ninu iṣé̩ gbogbo” (Orin Dafidi 54:4, 7). Dafidi gbagbọ pe Ọlọrun yoo tun yọ oun kuro ninu wahala yii.
Ninu Ibudo Saulu
Awọn ọna miiran wà ti a le fi ba ọta lo yatọ si biba a ja. Dafidi ki i ṣe ojo. Nigba ti ayè ṣi silẹ, Dafidi lọ si ibudo Saulu, o si ri i ti ẹgbẹ ọmọ-ogun awọn ọta wọnyii ti sùn. Boya ki wọn ba le wà lai sewu, Saulu ati Abneri olori ogun rè̩ ((I Samuẹli 17:55) wà ni aarin ibudo, awọn ọmọ-ogun si yi wọn ká.
Abiṣai ọmọ arabinrin Dafidi (I Kronika 2:15, 16), yọọda lati ba Dafidi lọ bi o ti n lọ si ibudo Saulu – si aarin rè̩ gan an lọdọ Saulu. Dafidi ati Abiṣai lọ ni oru. Awọn aṣọde kò ri wọn bẹẹ ni ẹnikẹni ninu awọn ọkunrin naa ko si ri wọn. Wọn n rin lọ, wọn si n sọrọ laarin awọn ẹgbẹẹdogun (3,000) ọmọ-ogun Saulu ti o n sun.
Ki i ṣe ohun ti o ṣoro lati ri Saulu, nitori pe a fi ọkọ rè̩ gunlẹ ni ibi timùtimù rè̩ (tabi ohunkohun ti o wu ki o lò fun irọri rè̩). A sọ fun wa pe o jẹ àṣà ninu ibudo bẹẹ fun olori lati wà laarin, a si le mọ ipo rè̩ nipa ọkọ rè̩ ti a fi gunlẹ.
Wọn Sun
Nigba ti Dafidi ati Abiṣai yọkẹlẹ de è̩gbẹ Saulu, awọn ọmọ-ogun ti o n sun ni o yi wọn ká. Abiṣai beere lọwọ Dafidi pe ki o fun oun ni aṣẹ lati pa Saulu. Boya Abiṣai ti wà lọdọ Dafidi nigba ti Dafidi ge eti aṣọ Saulu. O ṣe e ṣe ki o mọ pe Dafidi ki yoo pa Saulu bi o ba tilẹ ri aye lati ṣe bẹẹ. Boya Abiṣai ba Dafidi sọ asọye pe ni akọkọ o le jẹ pe aye kàn ṣi silẹ lati pa Saulu ni; ṣugbọn ni akoko yii, dajudaju Ọlọrun ti fi Saulu le Dafidi lọwọ. Ki i ṣe oorun lasan ni eyi ti awọn ọmọ-ogun Saulu n sun yii, nitori pe awọn oluṣọ ati olori-ogun Saulu, ẹni ti o gbọdọ daabo bo ọba ni o sùn. Oluwa ni O mú ki oorun ijikà yii ki o bà le Saulu ati awọn ẹgbẹẹdogun (3,000) ọmọ-ogun rè̩.
Ni Ọwọ Ọlọrun
Abiṣai kò gbiyanju lati mu ki Dafidi pa Saulu. Abiṣai beere pe ki a fun oun ni aye lati pa a. S̩ugbọn Dafidi jẹ olootọ si ọba rè̩. Bi o tilẹ jẹ pe a ti fi àmi ororo yàn Dafidi ni ọba, o n fẹ lati duro de akoko Ọlọrun. Dafidi kò fẹ lati wara pàpà ki o si fi agbara mu ara rè̩ si ori oye. Dafidi ṣe gẹgẹ bi ọrọ ti o wà ninu ọkan ninu awọn Psalmu rè̩: “Fi ọna rẹ le OLUWA lọwọ; gbẹkẹlee pẹlu; on o si mu u ṣẹ” (Orin Dafidi 37:5).
O tẹ Dafidi lọrun lati fi ọna rè̩ le Ọlọrun lọwọ. Dafidi sọ fun Abiṣai pe oun yoo di ẹni idalẹbi niwaju Ọlọrun bi oun ba na ọwọ oun si ẹni àmi-ororo Oluwa. Ju gbogbo eyi lọ Dafidi gba pe Oluwa yoo pa Saulu, tabi yoo ṣegbe loju ogun, tabi ọjọ rè̩ yoo de ti yoo kú. Dafidi mọ pe o pé̩ ni o yá ni Saulu ati olukuluku eniyan yoo kú; ṣugbọn Dafidi kò fẹ ki Saulu ti ọwọ oun kú. O ni, “OLUWA má jẹ ki emi nà ọwọ mi si ẹni àmi-ororo OLUWA.” Bayi ni Dafidi da ẹmi Saulu, ọta rè̩, si.
Ọkọ kan ati Igo Omi Kan
Dafidi fun Abiṣai ni aṣẹ lati mu ọkọ Saulu ati igo omi rè̩, gẹgẹ bi àmi pe awọn ti wá si ibudo Saulu. Ọkọ Saulu wà fun ati daabo bo o nigba ti o ba wà ninu ewu; igo omi wà fun ati fun un ni itura nigba ti oungbẹ ba n gbẹ ẹ. Mejeeji ni ko ri mọ yii. Bẹẹ gẹgẹ ni eniyan le sọ agbara ti ẹmi ati itura rè̩ nu nipa aikiyesara ati fifi ọwọ yẹpẹrẹ mu ohun ti ẹmi. O ni lati “mā ṣọra, ki ẹ si mā gbadura” nigba gbogbo (Marku 13:33).
Dafidi ati Abiṣai fi pẹlẹpẹlẹ yọ jade lai sewu kuro ni ibudo Saulu. Nigba ti wọn ti rin jinna de ibi ti a le gbọ ohun wọn, ti a kò si le ba wọn, Dafidi kigbe si wọn. Saulu mọ ohun Dafidi nigba ti o n fi ẹsùn Abneri, olori ogun sùn pe o jẹ alaijolootọ ati alafara, nitori pe kò ṣe itọju ọba. Bi ọrọ ba ri bayii a ka ẹni naa yẹ si iku.
Dafidi tun wi pe nigba ti Abneri sùn ọkan ninu awọn eniyan naa ti lọ si ọdọ Saulu lati pa a, ṣugbọn Dafidi ni ko jẹ. Fun idaniloju, Dafidi ni ki wọn wo ọkọ Saulu eyi ti a ti mu kuro ni ẹgbẹ rè̩ ti o si wa lọwọ Dafidi. Boya Dafidi jẹ ki wọn mọ pe ayè ṣi silẹ fun ẹni ti o mu ọkọ Saulu lati pa a. Dafidi ni oun yoo da ọkọ naa pada bi Saulu ba rán ọkan ninu awọn ọmọkunrin rè̩ lati wa gba a.
A Le e Kuro ninu Ile ati Isin
Dafidi tẹnu mọ ọn pe oun ni ẹni naa ti a ti huwa buburu si. A le Dafidi kuro ni ile, kuro lẹnu iṣẹ rè̩ ati isin rè̩. A gba ini rè̩ lọwọ rè̩, a si sọ fun un pe “Lọ, sin awọn ọlọrun miran.”
Ninu irẹsilẹ Dafidi, o fi ara rè̩ we aparo, ẹyẹ kan ti ki i pa ni lara ti a si maa n pa jẹ, ṣugbọn ti o maa n fo lati sa asala fun ẹmi rè̩ nigba ti o ba ri ayè lati ṣe bẹẹ, nitori pe ko si ọna miiran ti o le gba daabo bo ara rè̩.
Eyi mu ki Saulu jẹwọ è̩ṣẹ ati aṣiṣe rè̩. O ni ki Dafidi pada si ile, o si ṣe ileri pe oun ki yoo wá ibi rè̩ mọ. Boya ni otitọ ni Saulu pinnu ohun ti o sọ yii ninu ọkan rè̩ ni akoko naa; ṣugbọn ijẹwọ è̩ṣè̩ ati ileri ti o ṣe kò ti inu ironupiwada tootọ wá.
Ọlọrun Onidajọ
Dafidi ran Saulu leti pe Ọlọrun yoo “san a fun olukuluku ododo rè̩ ati otitọ rè̩.” Oluwa ni onidajọ, yoo si “san a fun olukuluku gẹgẹ bi iṣẹ rè̩” (Matteu 16:27) ati gẹgẹ bi iṣe rè̩.
Dafidi kò sọ idi miiran ti o fi dá ẹmi Saulu si ju pe o jẹ ẹni àmi-ororo Oluwa. Idi yii ti tó fun Dafidi. Eyi yẹ ki o jẹ idi kan naa fun Saulu nitori pe ẹni àmi-ororo Oluwa naa ni Dafidi i ṣe (II Samuẹli 23:1). Eyi ni lati mu ki eniyan ki o ṣọra ni akoko yii nipa ohun ti eniyan n sọ tabi ti o n ṣe si ọkan ninu awọn iranṣẹ Ọlọrun. Ọlọrun wi pe: “Ẹ máṣe fi ọwọ kan ẹni-ororo mi” (Orin Dafidi 105:15). Dajudaju Ọlọrun n sọ nipa gbogbo awọn ọmọ Rè̩, ki i ṣe kiki awọn alufa ti a fi ororo yan lati waasu nikan. Bibeli sọ fun wa pe ifororoyan kan wà (I Johannu 2:27) eyi ti i maa kọ eniyan, ti o si n tọ ọ si ọna otitọ gbogbo (Johannu 16:13). Ọlọrun maa n kiyesi awọn ti o n fi ọrọ tabi iṣe wọn, pa awọn eniyan Rè̩ -- awọn ọmọ-ẹyin Oluwa, lara. Ileri Ọlọrun ni eyi fun Abrahamu ati gbogbo awọn Ọmọ Israẹli: “Emi o bukun fun awọn ti nsúre fun ọ, ẹniti o nfi ọ ré li emi o si fi ré” (Genesisi 12:3; 27:29; Ẹksodu 23:22; Numeri 24:9). Iriri ti fi han pe Ọlọrun maa n ṣoore fun awọn ti o ṣe inurere si awọn eniyan Rè̩, ati pe Ọlọrun maa n jẹ ki ibi ba awọn ti wọn huwa aitọ tabi ti wọn pa ọmọ-ẹyin Oluwa lara.
Lẹyin ọrọ wọnyii ti Saulu sọ, “Nitõtọ iwọ o si ṣe nkan nla, nitotọ iwọ o si bori,” Dafidi ati Saulu pinya gẹgẹ bi ọrẹ. Gẹgẹ bi a ti mọ, eyi ni igba ikẹyin ti Dafidi fi oju rè̩ ri Saulu. Titi di akoko iku Saulu, Dafidi wà ni ifarapamọ, o si gbẹkẹle aabo Ọlọrun ju ileri Saulu lọ.
Questions
AWỌN IBEERE- Awọn wo ni o rú Saulu soke lati tun bẹrẹ si i lepa Dafidi?
- Awọn melo ni o wà pẹlu Saulu?
- Bawo ni o ti ṣe e ṣe fun Dafidi ati Abiṣai lati wọ ibudo Saulu?
- Àmi wo ni wọn ni lati fi han pe wọn ti de ibẹ?
- Ki ni ohun ti o le ṣẹlẹ si Onigbagbọ ti ko “Sọra ki o si gbadura?”
- Ki ni idi rè̩ ti Dafidi kò fi pa Saulu?
- Bawo ni a ṣe da ọkọ Saulu pada?
- Bawo ni Abneri olori ogun Saulu ti ṣe kuna lati ṣe iṣẹ rè̩?
- Ni ọna wo ni a gba ṣe buburu si Dafidi?
- Iru ijẹwọ wo ni Saulu ṣe?
- Ki ni asọtẹlẹ ti Saulu sọ nipa Dafidi?
- Bawo ni Dafidi ati Saulu ti ṣe pinya?