I Samuẹli 28:3-25

Lesson 216 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Awọn enia buburu,ati awọn ẹlẹtàn yio máa gbilẹ siwaju si i, nwọn o mā tàn-ni-jẹ, a o si mā tàn wọn jẹ”(II Timoteu 3:13).
Notes

Israẹli ninu Wahala

Nigba gbogbo ni awọn Filistini n wa ọna lati ba awọn Ọmọ Israẹli jà. Ni akoko yii wọn tun gbá ogun nla wọn jọ lati kọlu wọn. Sibẹ Saulu ni olori ogun Israẹli, ni ọrùn rè̩ si ni akoso bi wọn o ti ṣe ba awọn Filistini jà wà, bi o tilẹ jẹ pe Dafidi ati awọn ọmọkunrin rè̩ naa, ti ni awọn iṣẹgun diẹ lori awọn ọta Israẹli yii.

Nigba ti Saulu ri bi ẹgbẹ ogun Filistini ti pọ to, ẹru ba a. O dabi ẹni pe ọgọọrọ awọn ọmọ-ogun ọta wọnni ti pọ ju fun un lati ba jà. Ni irú akoko bi eyi awọn olori ti wọn jẹ ẹni iwa-bi-Ọlọrun laarin awọn Ọmọ Israẹli a maa gbadura si Ọlọrun fun iranwọ nigba ti wọn ba ri i pe agbara wọn ko to nnkan, Ọlọrun a si fun wọn ni iṣẹgun. Ni ọna bayii wọn ti bori awọn ọta nipa agbara Ọlọrun.

Adura ti a Kò Dahun

Saulu mọ pe wọn a ti maa ni iṣẹgun nipa iranwọ Ọlọrun; nitori naa nisisiyi ti o ri i pe iranwọ miiran ko si, oun naa fẹ ke pe Ọlọrun fun iranwọ. S̩ugbọn nisisiyi Ọlọrun kò dahun – yala nipa ala tabi nipa Urimu ati Tummimu awọn alufa, tabi nipa awọn woli.

Akoko ti wà ri nigba ti Ọlọrun dahun adura Saulu. Eyi ni igba ti Saulu rin ninu ifẹ Ọlọrun. Ọlọrun ti fun un ni ọkan titun lati le mọ ifẹ Ọlọrun, ati pẹlu fun saa kan o ti gbadun irẹpọ ti o maa n ti inu igbọran si Oluwa jade wa. S̩ugbọn Saulu ti fa sẹyin, fun igbà pupọ ni o si ti mọọmọ ṣaigbọran to bẹẹ ti Ọlọrun fi yi pada kuro ni ọdọ rè̩ ti kò si dahun adura rè̩ mọ.

Ronu bi ipo yi yoo ti buru to – ki o má si ẹni ti yoo dahun adura rẹ! Njẹ o le woye bi yoo ti ri fun ọ bi kò ba si ẹni ti o le ran ọ lọwọ, ti Ọlọrun paapaa kò fẹ gbọ nigba ti o ba gbadura? Ranti, Ọlọrun ti wi pe, “Ẹmi mi ki yio fi igba-gbogbo ba enia jà” (Gẹnẹsisi 6:3). Bi ẹni kan ba wà ọrùn kì lati maa ba Ọlọrun jà, ti o ba si kọ lati tẹti silẹ nigba ti O ba sọrọ, akoko le de nigba ti Ọlọrun pẹlu yoo kọ lati gbọ. Awọn ẹlomiran a kọ wá iranwọ si oriṣiriṣi ọna; nigba ti wọn kò ba si ri iranwọ, wọn a wa ke pe Oluwa. Alaanu ni Ọlọrun, A si maa tẹti silẹ, a maa duro de adura wọn, ṣugbọn o yẹ ki eniyan ṣọra ki o ma ba duro pẹ kọja ju bi o ti yẹ lọ ki o to ke pe Oluwa.

Ọna Miiran

Ara Saulu kò lelẹ nigba ti o wa mọ daju pe Ọlọrun kò ni tẹti si adura oun. Woli Samuẹli ti o ti dabi baba fun un ti o si ti fi ifẹ Ọlọrun han an, ti kú; nitori bẹẹ kò si ẹni ti Saulu tun le tọ lọ.

Ni akoko ti Saulu ni ibẹru Oluwa ninu ọkan rẹ o ti ṣe nnkan ribiribi kan. O ti lé awọn alafọṣẹ ati awọn oṣó tabi awọn abokúsọrọ kuro ni ilẹ Israẹli. Ọlọrun ti paṣẹ pe iru eniyan bẹẹ ni a kò gbọdọ jẹ ki o wà ni Israẹli (Ẹksodu 22:18). Eṣu ni wọn n sin, o si ṣe e ṣe fun wọn lati sọ awọn eniyan Ọlọrun di aimọ. Ọpọlọpọ ninu wọn ti salọ, kò si si ẹni ti o tun kù lati maa polowo iṣẹ buburu rè̩.

Ninu wahala rè̩, Saulu gbiyanju lati wa alafọṣẹ kan ti oun le lọ wa imọran lọdọ rè̩. O pe awọn ọmọ ọdọ rè̩ o si bi wọn bi wọn ba mọ ẹni kan ti o n ṣe iru iṣẹ bẹẹ. Ọkan ninu wọn mọ nipa ajẹ kan ti o wa ni Endori, Saulu si pinnu lati lọ sọdọ rè̩.

Saulu ati Ajẹ

Ninu okunkun oru, Saulu ati awọn iranṣẹ rè̩ parada wọn si yọ jade lati lọ sọdọ obinrin buburu yii ti n ṣiṣẹ fun eṣu. Saulu jẹ è̩lẹṣẹ o si mọ wi pe oun n rú aṣẹ Ọlọrun nipa ohun ti oun n ṣe, ṣugbọn oju ti i to bẹẹ ti ko fi fẹ ki ẹlomiran mọ. O ro wi pe boya oun le bo è̩ṣẹ oun mọlẹ ki ẹnikẹni má le ri i. Dajudaju oun kò daba rè̩ pe a o kọ iroyin nipa irin ajo oun lọ si ile obinrin abokusọrọ ti Endori sinu Bibeli fun ọkẹ aimoye eniyan lati kà ni ọpọlọpọ ọgọrun ọdun ti n bọ. Gbogbo eniyan ti o ba kà Bibeli nisisiyi ni o mọ pe Ọba Saulu kọ Ọlọrun Israẹli silẹ, o si lọ si ọdọ Satani fun iranwọ.

Nigba ti Saulu de ile abokusọrọ naa o ni ki o mu Samuẹli wa fun oun. Gẹrẹ ti o sọrọ ni Samuẹli fara han. Obinrin yii kò ni agbara lori awọn ẹmi ti o ti rekọjá. Ko si nkankan ti o mọ ọn ṣe ti i ba fi mu Samuẹli tabi ẹnikẹni miiran pada wa si aye. Lati igba abokusọrọ ti Endori, ọpọlọpọ alalupayida ati abẹmilo ti gbiyanju lati ba awọn oku sọrọ, ṣugbọn kò si ẹni ti o ti i ṣe aṣeyọri. Ni ti eleyi, Samuẹli yara jade kiakia to bẹẹ ti obinrin naa kò tilẹ ni aye lati gbiyanju ati ṣe ohunkohun.

Obinrin naa kigbe lohun rara nigba ti o ri Samuẹli. Ẹnu yà a bi yoo ti ya ẹlomiran lati ri ẹmi Woli ti o ti rekọja naa. Ọlọrun ni O ti fi ayè silẹ fun Samuẹli lati jade wa da Saulu lẹbi lẹẹkan si i. Nigba ti obinrin naa ṣe apejuwe ohun ti o ri, Saulu wi fun un pe dajudaju Samuẹli ni. Nigba naa ni Samuẹli sọrọ, “E ṣe ti iwọ fi yọ mi lẹnu lati mu mi wá soke?” Saulu dahun pe: “Ipọnju nla ba mi: nitoriti awọn Filistini mba mi jagun, Ọlọrun si kọ mi silẹ, kò si da mi lohùn mọ, nipa ọwọ awọn woli, tabi nipa alá; nitorina li emi si ṣe pè ọ, ki iwọ ki o le fi ohun ti emi o ṣe hàn mi.”

Ọrọ Ọlọrun Kò Yipada

Awọn woli Ọlọrun tootọ ko jẹ yi Ọrọ Ọlọrun pada. O yẹ ki Saulu ti mọ pe ti Ọlọrun ba ti kọ oun silẹ, ko si nnkan ti Samuẹli le ṣe. Samuẹli yoo mu Ọrọ Ọlọrun ṣẹ.

Ni igba ayé Samuẹli, o ti jẹ olootọ si Saulu. O ti sọ ohun rere ti yoo de ba a nipa gbigbọran si Ọlọrun lẹnu; o si ti kilọ fun un nipa ohun ti aigbọran yoo mu wa ba a. Saulu ti n ṣaigbọran siwaju si i, nikẹyin Samuẹli ni lati sọ fun un pe a ti gba ijọba kuro ni ọwọ rè̩, a si ti fi i fun ẹlomiran ti o tọ si.

Ọrọ Ọlọrun kò yipada. Idajọ kan naa ni Samuẹli tun tẹnu mọ: “OLUWA si yà ijọba na kuro li ọwọ rẹ, o si fi fun aladugbo rẹ, ani Dafidi. Nitoripe iwọ kò gbọ ohun OLUWA.” Samuẹli ni ọrọ lati sọ kun idajọ naa: “OLUWA yio si fi Israẹli pẹlu iwọ le awọn Filistini lọwọ: li ọla ni iwọ ati awọn ọmọ rẹ ọkunrin yio pẹlu mi.”

Ni ọla Saulu gbọdọ ku! Iroyin idagiri! Ki i ṣe ohun ti Saulu n fẹ gbọ ni yii. Ni ọjọ keji oun ati awọn ọmọ rè̩ ọkunrin yoo wà pẹlu Samuẹli ni ibi awọn okú, ṣugbọn Saulu kò ni ni itunu ni “okan-aiya Abrahamu” gẹgẹ bi awọn ti o kú ninu igbala. Gẹgẹ bi a ti kọ ninu itan Lasaru ati ọkunrin ọlọrọ, ọgbun nla kan wà ni agbedemeji ibi ti Lasaru ti n gbadun itura, ati ibi ti ọkunrin ọlọrọ ti n jiya oró ti awọn ẹni ti o ṣègbé. Jonatani ti o jẹ olootọ si Ọlọrun, yoo lọ wa pẹlu Samuẹli ni ibugbe awọn alabukún-fun.

Wiwa Lai Nireti

Saulu le ti ro pe a o da oun si fun saa diẹ si i nitori ti awọn Ọmọ Israẹli. S̩ugbọn ọjọ iṣiro ti de fun Saulu, ilẹkun aanu si ti tì.

Iroyin yii daamu Saulu lọpọlọpọ ti ko fi ku agbara kankan ninu rẹ. Ipọnju rè̩ pọ to bẹẹ ti ko fi jẹun fun odindi ọsan kan ati oru kan, o si wó lulẹ nitori aarẹ ara rè̩. Ẹrù ba obinrin naa nigba ti o ri bi ọkàn Saulu ti bajẹ tó, o si ro pe Saulu le di ẹrù wahala rè̩ le oun lori, ki o si fẹ pa oun. O ran an leti pe o ti ṣeleri pe ohunkohun ti o wu ki o de, a kò ni pa oun lara.

Saulu kò pa ajẹ naa lara. Pẹlu iranwọ awọn iranṣẹ rè̩, obinrin naa rọ ọ pe ki o jẹun, lai pẹ ara rè̩ si mókun to lati maa ba ọna rè̩ lọ. S̩ugbọn ireti kò si fun un. Ni ọla oun o sa kú, a o si gba ijọba Israẹli lọwọ idile rè̩. Bayi ni eniyan ti ṣe le ṣegbe patapata lẹyin ti o ti ri igbala ti o si ti ba Oluwa rin, ṣugbọn ti o fà sẹyin kuro lọdọ Rè̩.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Wahala wo ni o wà ni Israẹli?
  2. Bawo ni awọn Ọmọ Israẹli ti ṣe n ni iṣẹgun latẹyinwa?
  3. Ki ni ṣe ti Ọlọrun kò gbọ adura Saulu?
  4. Bi eniyan ba wà ọrùn kì lati maa kọ ẹyin si Ọlọrun, ki ni o le reti lati ọdọ Ọlọrun?
  5. Ki ni ajẹ naa ṣe nigba ti o ri Samuẹli?
  6. Ta ni ni agbara lori ẹmi awọn oku?
  7. Ki ni Samuẹli sọ fun Saulu?
  8. Bawo ni ọkan Saulu ti ri nigba ti o fi ile ajẹ naa silẹ?
  9. Ka Gẹnẹsisi 6:3