Lesson 217 - Junior
Memory Verse
AKỌSORI: “ Kò si ohun- ijà ti a ṣe si ọ ti yio lè ṣe nkan” (Isaiah 54:17).Notes
È̩rù
Lẹyin ti Saulu ti ṣe ileri pe oun ki yoo tun wa ipalara Dafidi mọ, awọn mejeeji pinya. Dafidi ba ọna rè̩ lọ, Saulu si pada si ile rè̩. Ọlọrun ti wà pẹlu Dafidi lati gba a ni ọpọlọpọ igba kuro lọwọ Saulu. A ti fi àmi-ororo yan Dafidi lati jẹ ọba, eyi si to lati fun un ni idaniloju pe Ọlọrun yoo daabo bo oun. Nitori pe kò ni igbẹkẹle ninu Saulu ati ileri ti o ṣe, ẹrù wà ninu ọkan Dafidi. Ẹrù yii mu ki igbagbọ rè̩ ninu Ọlọrun fun aabo rè̩ di alailera. Nigba ti Dafidi wi pe, “Njẹ ni ijọ kan l’emi o ti ọwọ Saulu ṣegbe”, o dabi ẹni pe kò tun gbẹkẹle Ọlọrun fun iranlọwọ rè̩ mọ. Dajudaju Dafidi ro pe ninu agbara oun tikara rè̩ oun ki yoo le sa asala kuro lọwọ Saulu mọ.
Eyi ha ni Dafidi kan naa ti o wi pe, “OLUWA li agbara ẹmi mi; aiya tali yio fò mi?” (Orin Dafidi 27:1). Dafidi kọ ni o wi pe, “Awọn ẹlomiran gbẹkẹle kẹké̩, awọn ẹlomiran le ẹṣin; ṣugbọn awa o ranti orukọ OLUWA Ọlọrun wa” (Orin Dafidi 20:7)? Lẹyin eyi Dafidi naa kọ ni o wi pe “Nigbati è̩ru ba mbà mi, emi o gbẹkẹle ọ” (Orin Dafidi 56:3)? Ni akoko yii, fun igba diẹ ọkan Dafidi rẹwẹsi. O pinnu lati lọ si ilẹ awọn Filistini, jinna si Saulu ati awọn eniyan rè̩.
Ilẹ awọn Filistini
Lilọ si ilẹ awọn Filistini ki i ṣe ohun ti o rọrun fun Dafidi lati ṣe. Idi kan wà ti Dafidi fi ni lati bẹru ọba wọn, Akiṣi ara Gati (I Samuẹli 21:12; Orin Dafidi 56:1-13).
Rirẹwẹsi ti ọkan Dafidi rẹwẹsi mu ki o fi ilẹ ini rè̩ silẹ ati irẹpọ pẹlu awọn Ọmọ Israẹli iyokù. Fun ọdun kan ati oṣu mẹrin ni Dafidi ati awọn ẹgbẹta (600) ọkunrin ti o wà lọdọ rè̩, ati awọn ẹbi wọn fi gbe ni ilẹ awọn Filistini. Akiṣi, ọba Gati, fun Dafidi ni ilu Siklagi lati gbé.
Ọmọ-ọdọ
Nigba pupọ ni awọn eniyan ayé a maa fẹ ki ọkan ninu awọn ti n tẹle Ọlọrun lẹyin maa ba wọn gbe. Wọn mọ pe Ọlọrun yoo wà pẹlu awọn eniyan Rè̩. Wọn ni ireti lati ri ojurere Ọlọrun nitori onigbagbọ kan ti o wa laarin wọn yii. Akiṣi fara han bi ẹni pe o n ṣe inurere si Dafidi ati awọn eniyan rè̩ nipa gbigba wọn laaye lati gbe ilẹ rè̩ ati nipa fifun wọn ni ilu Siklagi. Akiṣi ṣe bẹẹ nitori pe o ni ireti lati ri èrè kan nipa gbigba Dafidi si ilẹ rè̩. Akiṣi ko ni ifẹ Dafidi lọkan. Dafidi jẹ jagunjagun akọni ọkunrin ati ọmọ-ogun tootọ. Akiṣi mọ pe Dafidi yoo ṣe ire pupọ fun awọn Filistini nipa biba awọn ọta wọn jà. Dafidi lọ si ilẹ awọn Filistini lati sa asala kuro lọwọ Saulu, ṣugbọn Dafidi ni lati fi ẹmi rè̩ wewu ninu ogun fun awọn Filistini. Dafidi ko jere ohun rere kan nipa bibẹru to bẹẹ ti o fi ni lati lọ gbe laarin awọn Filistini. Bayii ni Akiṣi wi nipa Dafidi: “On ti mu ki Israẹli ati awọn enia rè̩ korira rè̩ patapata, yio si jẹ iranṣẹ mi titi lai” (I Samuẹli 27:12).
Ninu Wahala
Igba kan de ti awọn Filistini n ba awọn Ọmọ Israẹli jagun. Akiṣi yàn Dafidi ni oluṣọ ọba -- oluṣọ ori ọba (I Samuẹli 28:2). Nipa biba awọn alaiwabi-Ọlọrun kẹgbẹ, Dafidi ba ara rè̩ ninu iṣoro. Wo ọpọlọpọ igba ti awọn ti o fi awọn eniyan Ọlọrun silẹ maa n bọ sinu wahala! Awọn ọmọde a maa bọ sinu wahala nitori pe wọn ti kó ẹgbẹ buburu. Ọrọ Solomoni sọ fun wa pe: “Maṣe bọ si ipa-ọna enia buburu, ma si ṣe rin li ọna awọn enia ibi” (Owe 4:14); “Iwọ máṣe ilara si awọn enia buburu, bẹni ki o má si ṣe fẹ lati ba wọn gbe” (Owe 24:1).
Boya Dafidi tilẹ ronu ninu ara rè̩ wo nipa ohun ti o le ṣe. Yoo ha kọ lati lọ si oju ogun lati ba awọn Ọmọ Israẹli ja bi? Ki oun ha jokoo si ile gẹgẹ bi ojo, ki o ma si fi imoore hàn fun ohun ti Akiṣi ṣe fun un? Tabi Dafidi yoo ha jẹ onikupani fun awọn eniyan rè̩? Oun yoo ha ba Israẹli ja gẹgẹ bi ọta? Njẹ eyi nì ko ha ni sọ Dafidi di alaiyẹ lati jẹ ọba? Bi wọn ba pa Saulu, ẹbi naa yoo ha wa lori Dafidi bi? Boya bi Dafidi ti n ro o bayii, o dabi ẹni pe è̩ṣẹ ati ọrọ è̩gan ni yoo jẹ abajade ohunkohun ti o ba ṣe. Ko ha si ọna abayọ fun Dafidi, lai ni jẹbi tabi ki o ni ibanujẹ?
Awọn Oluṣọ Ọba
Dafidi ati awọn ọmọkunrin rè̩ pẹlu Akiṣi ni o wa ni è̩yìn. O le jẹ wi pe Dafidi fẹ lati jẹ olutọju ọba. O ṣoro lati gbagbọ pe Dafidi yoo fẹ lati ṣe ohun ti o ju eyi lọ ninu ija awọn Filistini pẹlu Israẹli. Dafidi ti gbe igbesi-aye rere ati alailẹgan laarin awọn Filistini. O wà ni ipo ti o ṣoro nisisiyi. Dajudaju o gbẹkẹle Ọlọrun lati ran an lọwọ lati ṣe eyi ti o tọ.
Awọn ijoye Filistini tako Dafidi ati awọn eniyan rè̩. Wọn takú pe a gbọdọ ran Dafidi ati awọn eniyan rè̩ pada ki wọn má ṣe ba wọn lọ si ogun yii. Ẹru ba awọn Filistini pe bi wọn ba de oju ogun, Dafidi ati awọn ọmọkunrin rè̩ yoo yipada dojuja kọ wọn. Wọn wi pe ọta ni wọn jẹ ni igba atijọ ri, Dafidi si ṣe elewu eniyan si wọn ju Saulu lọ. Boya wọn ranti pe Dafidi ni ẹni ti o pa Goliati akikanju wọn (Ẹkọ 211). Lati tẹ awọn ijoye Filistini lọrùn, Akiṣi ran Dafidi ati awọn ọmọkunrin rè̩ pada si ile. Iroyin rere ni Akiṣi ni nipa igbesi-aye Dafidi. Akiṣi kò ri ẹbi tabi iwa buburu kan ni ọwọ rè̩. Iwa ati ibalo Dafidi ti té̩ Akiṣi lọrun. Ki awọn Filistini má ba binu, Akiṣi paṣẹ pe ki Dafidi ati awọn eniyan rè̩ pada ni owurọ kutukutu. Bayii ni Ọlọrun yọ Dafidi kuro laarin ẹgbẹ ọmọ-ogun Filistini, kuro ninu ogun awọn Filistini pẹlu awọn Ọmọ Israẹli.
Ile Wọn
Dafidi ati awọn ọmọkunrin rè̩ yara kankan pada si ilu wọn, Siklagi. Ọjọ mẹta ni wọn fi rin. Dajudaju yoo rẹ wọn, ọkan wọn si ni lati maa poungbẹ lati wa ni ile. Wo ohun ibanujẹ ti wọn ri! Nigba ti wọn kò si ni ile, awọn ara Amaleki ti wa kó Siklagi, wọn ti ṣẹgun gbogbo awọn eniyan ti o wa nibẹ, wọn si ti fi ina kùn ilu naa. Ibanujẹ bo ọkan Dafidi ati awọn ọmọkunrin rè̩ wọnyi, awọn akọni onigboya wọnyi, to bẹẹ ti wọn fi sọkun. Dafidi ati awọn ọmọkunrin rè̩ fẹran awọn ọmọ ati ile wọn. Abajọ ti Dafidi ati awọn ọmọkunrin rè̩ fi sọkun nitori pe a ti ko ẹbi wọn lọ a si dana sun ile wọn.
Ibawi
Boya Ọlọrun fi àye silẹ lati pa Siklagi run ati lati kó awọn ara ibẹ lẹrú gẹgẹ bi ibawi fun Dafidi. Ko si akọsilẹ pe Dafidi gbadura tabi ki o beere lọwọ Ọlọrun nipa gbigbe rè̩ laarin awọn Filistini. O dabi ẹni pe Dafidi ṣiyemeji pe Ọlọrun yoo daabo bo oun lọwọ Saulu. Nigba ti Dafidi lọ saarin awọn Filistini, Ọlọrun ko jẹ ki a pa a tabi ki a pa ẹbi rè̩, ṣugbọn wọn jiya. “Nitoripe ẹniti Oluwa fẹ, on ni ibawi” tabi tọ sọna (Heberu 12:6).
Nigba miiran, ni akoko yii, Ọlọrun a gbà wahala tabi ibanujẹ laye lati wá, fun ire awọn eniyan Rè̩. Eyi ki i ṣe pe Ọlọrun ti mu oju Rè̩ kuro. Ọna Ọlọrun ni lati fa wa sun mọ ọdọ Rè̩ ju bẹẹ lọ. Ọlọrun fẹran wa O si n fẹ ki a kọ lati gbẹkẹle Oun si i.
A ko ti i gbọ ri pe a ṣe ohun buburu kan si ẹbi Dafidi nigba ti o ba lọ lati ṣiṣẹ. Ọlọrun ni o ti n ṣe itọju ẹbi Dafidi ti o si n daabo bo o. Ni akoko yii ki i ṣe iṣẹ ni Dafidi ba lọ. Ero ti rè̩ ni lati lọ kuro ni ile. Ọlọrun kọ ni O paṣẹ fun un lati lọ, ki si i ṣe iṣẹ ni o mu un lọ.
Imọkanle ninu Oluwa
Inu Dafidi bajẹ, ṣugbọn “Dafidi mu ara rè̩ li ọkan le ninu OLUWA Ọlọrun rè̩.” Nigba ti o dàbi ẹni pe ohun gbogbo wà lodi si Dafidi, o wa Ọlọrun. Saulu ti le Dafidi jade kuro ni orilẹ-ede rè̩. Awọn Filistini ti ran Dafidi pada kuro laarin ẹgbẹ ọmọ-ogun wọn. Awọn ara Amaleki ti kó ilu rè̩ lọ, wọn si ti ko awọn ẹbi Dafidi lẹrú lọ. Lẹyin eyi awọn ọrẹ Dafidi tun dide si i -- awọn ọmọkunrin rè̩ n fẹ sọ ọ ni okuta. Ni igba irora ọkan ati ibanujẹ yii, Dafidi mọ ohun ti o yẹ ki oun ṣe. O ni igbagbọ ninu Oluwa. Boya oye yé Dafidi nisisiyi, nitori ni akoko yii o gbadura. Dafidi beere lọwọ Ọlọrun o si fi han pe o gbẹkẹle Ọlọrun lati ran oun lọwọ. Dafidi beere ibeere ti o yanju lọwọ Ọlọrun, “Ki emi ki o lepa ogun yi bi?” Ọlọrun si fun un ni idahun ti o daju, “Lepa: nitori ni biba iwọ o ba wọn, ni gbigba iwọ o si ri wọn gbà.” Boya idi rè̩ ti awọn ẹlomiran ki i fi ri idahun ti o daju gba nigba ti wọn ba gbadura ni pe wọn a maa gbadura gbogbo nnkan ni agbapọ, wọn ki i si i gbadura lori ohun kan daju. Ọlọrun ni iṣẹ kan ati ileri kan ti o daju fun Dafidi.
A Lepa awọn Ara Amaleki
Awọn ẹgbẹta (600) ọkunrin ti inu wọn bajẹ wọnyi, ti wọn wà pẹlu Dafidi kiyesi igbagbọ ati suuru rè̩. O fi inurere ba wọn lo, nitori naa wọn ba a lọ nigba ti o lepa awọn Amaleki. O rè̩ awọn miiran laarin wọn to bẹẹ gẹẹ ti wọn ko fi le gbesẹ ba Dafidi bi o ti n lepa lati ba awọn ti o wá ko ẹbi rè̩ ati ohun-ini rè̩ lọ yii. Dafidi ko lé awọn eniyan rè̩ ni are lati ṣe ju bi agbara wọn ti to lọ. Ni ibi odo Besori, idamẹta awọn eniyan naa duro lẹyin.
Aanu ati Iranlọwọ
Dafidi fi inurere hàn fun ọdọmọkunrin ara Egipti kan ti o ri ni oko. Dafidi fi aanu hàn nipa fifun un ni ounjẹ ati omi. Oju le kan awọn ẹlomiran to bẹẹ ti wọn ki yoo fi ri ayè lati ran iru ọdọmọkunrin bayi lọwọ, wọn a si gbà pe, iṣoro rè̩ kò kan awọn lati boju to. Bi Dafidi ti lo akoko ati ounjẹ rè̩ lati tọju ọdọmọkunrin yii, a san an pada fun un nipa iroyin ti a sọ fun un. Ara Egipti yii jẹ ọmọ-ọdọ ara Amaleki kan, o si sọ ohun ti Dafidi n fẹ lati mọ gan an fun un. Nigba ti ara Egipti naa n ṣaisan ni ọga rè̩ fi i silẹ. Nisisiyi, ọmọkunrin yii ti ni okun, o si n fẹ lati ṣe iranlọwọ fun awọn ti o ti ṣe oore fun un, ki o si jẹ ọga rè̩ ẹni ti o huwa buburu si i ni iyà.
Ohunkohun kò Sọnu
Ara Egipti yii tọka Dafidi si ibi ti agọ awọn ara Amaleki wà, awọn ti o n ṣe ariya nitori ikogun ti wọn kó ni ilu Dafidi. Ni igba ti awọn Amaleki ro pe wọn wà lai lewu ti wọn si ti mu ero ogun kuro lọkàn, Dafidi de ba wọn lojiji, o mu wọn lai mura silẹ, nigba ti wọn kò ni agbara pupọ lati gbejà ara wọn. Irinwo (400) eniyan pere ni o sa asala ninu wọn, bẹẹ ni “Dafidi si gba gbogbo nkan ti awọn ara Amaleki ti ko.” A dá awọn ẹbi wọn silẹ, wọn si gbà ohun gbogbo ti wọn ti kó ni ikogun padà. Dafidi kò padanu ohunkohun, o si jerè ọpọlọpọ ikogun.
Igbẹkẹle Rè̩ ninu Ọlọrun
Ẹ jẹ ki eyi ki o fi idi mulè̩ ṣinṣin ninu ọkàn wa bi o ti dara pupọ fun Dafidi, nigba ti o gbadura ti o si ni igbagbọ ninu Ọlọrun. Nigba ti Dafidi salọ si ilẹ awọn Filistini, o di ọmọ-ọdọ, o si ni lati lọ si ogun. Nigba ti Dafidi gbẹkẹle Ọlọrun, ko si ohun ijà ti a ṣe si i ti o le ṣe nnkan (Isaiah 54:17). Bẹẹ ni yoo ri ninu igbesi-aye wa bi a ba fẹ lati gbẹkẹle Ọlọrun ki a si sinmi le E.
Pipin Ikogun
Nigba ti Dafidi ati awọn ọmọkunrin rè̩ pada si Besori, awọn ti wọn ti duro sibẹ pade wọn. Bi o tilẹ jẹ pe wọn kò le ba Dafidi lọ, wọn yọ fun iṣẹ rere ti wọn ti ṣe. S̩ugbọn laarin awọn ti o ba Dafidi lọ ni awọn eniyan buburu wà, awọn amọ-ti-ara-wọn-nikan ati oniwọra. Wọn fẹ lati da ẹbi awọn ti ko ba wọn lọ pada fun wọn ṣugbọn wọn kò fẹ pin ninu ikogun fun wọn.
Dafidi ko feti si awọn eniyan rè̩, o wi fun wọn pe gẹgẹ bi imoore si Ọlọrun ti O ràn wọn lọwọ ti O si daabo bo wọn, gbogbo wọn yoo pin ikogun naa. Ohun ti o tọ ti o si yẹ ni lati pin ikogun fun awọn ti o duro ti “ẹru.” Ni ọjọ naa Dafidi fi ofin ati ilana kan lelẹ pe ipin kan naa ni yoo wà fun gbogbo eniyan.
Gẹgẹ bi o ti ri loni, olukuluku iṣẹ ti a n ṣe fun Oluwa ni a n ṣe fun ire gbogbo eniyan, ti o si tọ lati gba èrè ti o yẹ. Ki i ṣe gbogbo wa ni a ni anfaani lati maa ṣe aayan igbokegbodo ninu gbogbo iṣẹ Oluwa; ṣugbọn nipa jijẹ olootọ ninu adura gbigba – diduro “ti ẹru” – a o gba iyin fun iranlọwọ wa ati èrè.
Questions
AWỌN IBEERE- Ki ni ṣe ti Dafidi lọ gbe ni ilẹ awọn Filistini?
- Ilu wo ni a fi fun Dafidi?
- Ki ni ohun ti Akiṣi n fẹ lọwọ Dafidi?
- Ki ni ṣe ti awọn Filistini kọ fun Dafidi lati pẹlu wọn lọ jà?
- Ki ni ohun ti o ṣẹlẹ nigba ti Dafidi fi ile silẹ?
- Ki ni ṣe ti a ni lati ba Dafidi wi?
- Iru idahun wo ni Dafidi ri gbà nigba ti o gbadura?
- Ki ni ohun ti Dafidi ri gba nigba ti o ṣoore fun ara Egipti nì?
- Ki ni ṣe ti gbogbo awọn eniyan naa ni ipin ninu ikogun naa?
- Bawo ni a ti ṣe le duro ni ile “ti ẹrù”?