Lesson 218 - Junior
Memory Verse
AKỌSORI: “È̩ṣẹ na nigbati o ba si dagba tan, a bi ikú” (Jakọbu 1:15).Notes
Opin Buburu
Opin igbesi-aye Saulu ti buru to! Ni akoko kan, o jẹ ẹni ti Oluwa pè, ọba lori awọn eniyan ayanfẹ Ọlọrun, ti o si wà ni ojurere Ọlọrun ati eniyan. O kú gẹgẹ bi apẹyinda, ẹni ti Ọlọrun kọ silẹ ti awọn keferi si ṣẹgun rè̩.
Saulu ni o mu itiju yii wa sori ara rè̩. Ọlọrun ti fi ojurere wo o. O ti yàn an jade lati aarin awọn eniyan ki o ba le maa ṣe akoso awọn Ọmọ Israẹli. Ọlọrun ti fun un ni ọkan titun, Ẹmi Mimọ si ti ba le e. S̩ugbọn aigbọran kan ti tè̩le omiran titi Ọlọrun ko fi le ba Saulu sọrọ mọ. Ẹmi Mimọ ti fi i silẹ, ko si ni idalẹbi fun è̩ṣẹ mọ. Saulu ko tun le ni iṣẹgun mọ lai ni iranlọwọ Ọlọrun.
Ogun ti Saulu Ja Kẹyin
Ogun gbigbona kan ti bẹ silẹ laarin awọn Filistini ati awọn Ọmọ Israẹli. Awọn ogun Israẹli si n wo Saulu gẹgẹ bi ọba ati ọgagun sibẹ; awọn Filistini si mọ wi pe ti awọn ba le pa a, awọn Ọmọ Israẹli yoo salọ lai ni ireti.
Ko si afọnja, tabi ibọn, tabi ọta ti n ṣé̩ ina ni ijọ wọnni. Ohun ija wọn ni ọrun ati ọfà, idà ati ọkọ; nigba miiran wọn a si lo è̩rọ ti n ju okuta.
Nigba ti awọn Filistini ri Saulu, ọkan ninu awọn tafatafa wọn fa ọrun rè̩, ọfà naa si fo jade lọ ba ọba. Saulu gba ọgbẹ gidigidi, ṣugbọn oun kò ku lẹsẹkẹsẹ. O ke si ẹni ti o ru ihamọra rè̩ lati fi ida gun oun, ki awọn Filistini ma baa ṣogo pe awọn lo mu ayé rè̩ ati ijọba rè̩ lori Israẹli wa si opin. S̩ugbọn ẹni ti o ru ihamọra rè̩ kà a si eewọ pe ki oun pa oluwa oun, bi o tilẹ jẹ pe ko le ṣai ku lọnakọna.
Saulu ti pinnu tan pe ọkọ awọn Filistini kọ ni yoo pa oun nitori bẹẹ o ṣubu le ida kan, o si lọ si ayeraye ti ẹni ti o ba gba ẹmi ara rè̩ n lọ. Bayi ni ẹni ti Oluwa ti fi àmi-ororo yàn ri ṣe kú, ẹni ti ọjọ ayé rè̩ i ba kun fun ogo pupọ. Ìyè ainipẹkun ni oun i ba fi ṣe ere jẹ bi o ba ṣe pe oun ti jẹ olootọ si ipe Ọlọrun.
Ẹni ti o ru ihamọra Saulu woye pe itiju nlá nlà ni o de ba Israẹli nipa iṣubu olori wọn, nitori bẹẹ kò ṣanfaani mọ fun oun lati wà laaye. Oun naa ṣubu le ida rè̩ o si kú.
Ẹbun pataki fun Ile Oriṣa
Awọn Filistini fi iwọsi pupọ lọ awọn Ọmọ Israẹli. O jẹ àṣà lati maa yẹ ara awọn ọmọ-ogun ti o ba ṣubu loju ogun wò fun nnkan iyebiye ti o le wa lara wọn. Nigba ti awọn Filistini ri Saulu ati awọn ọmọ rè̩ ọkunrin, ki i ṣe iṣura wọn nikan ni wọn kó lọ, ṣugbọn wọn ke ori Saulu kuro pẹlu, wọn si fi i ranṣẹ, pẹlu ihamọra rè̩, si ile awọn oriṣa ilẹ wọn.
Dajudaju awọn Filistini yoo ṣe àriyá nitori pe a ti pa ọta wọn; nibikibi ti wọn ba si pade lati sin awọn oriṣa wọn, wọn fi ori Saulu hàn ni gbangba lati fi iṣẹgun wọn han. Ronu itiju ati ibanujẹ ti o de ba awọn Ọmọ Israẹli nitori pe a tabùku si olori wọn bayii! Gbogbo Israẹli ni o jiya nitori aijolootọ ọba wọn.
Iku Aṣẹgun
Bawo ni iku Saulu miiran ti yatọ to, àni ọkunrin ti o wa di Paulu Apọsteli! O ti bá iwa ibọriṣa wi, o si ti kede Ihinrere Jesu Kristi lai foya, bi o tilẹ jẹ pe o gbà pe ki o di ajẹriku fun igbagbọ rè̩. O ti fi tọkantọkan kilọ fun awọn ẹlẹṣẹ pe wọn ni lati ronupiwada ti wọn ba fẹ bọ ninu iya ayeraye. O fẹran ẹmi awọn eniyan to bẹẹ ti kò fi kọ lati fi ẹmi ara rè̩ lelẹ ki o ba le ràn wọn lọwọ lati mura silẹ fun Ọrun.
Ninu ọrọ ikẹyin Apọsteli naa niwọnyi; “Emi ti jà ijà rere, emi ti pari ire-ije mi, emi ti pa igbagbọ mọ: Lati isisiyi lọ a fi ade ododo lelẹ fun mi, ti Oluwa, onidajọ ododo, yio fifun mi li ọjọ na, ki si iṣe kiki emi nikan, ṣugbọn pẹlu fun gbogbo awọn ti o ti fẹ ifarahan rè̩” (II Timoteu 4:7, 8). O pade Ọlọrun rè̩ ni alaafia. O ti jẹ ipe Ọlọrun, o si ti ṣe olootọ de oju iku. Èrè n duro de e, iru eyi ti olukuluku ọmọ-ogun olootọ ti Jesu yoo ri gba.
S̩ugbọn niti Ọba Saulu, ireti kò si. O ti kọ ẹyin si Ọlọrun, ko si si ohun ti o le reti bi kò ṣe pe ki Ọlọrun kẹyin si oun naa.
Nigba ti awọn Ọmọ Israẹli gbọ pe olori wọn ti ṣubu loju ogun, wọn dàbi agutan ti kò ni oluṣọ. Ni ibẹru-bojo wọn sá kuro ni ilu wọn, awọn Filistini si kó sinu awọn ile ti wọn fi silẹ.
Ọlọrun fun Wa
Laarin akoko yii Dafidi fi ibujoko rè̩ si Siklagi, ilu kan ti o wà labẹ akoso awọn Filistini. Akiṣi, ọba Gati ti fun Dafidi ati awọn ẹgbẹta (600) ọkunrin rè̩ ni ayè lati maa gbe nibẹ ki wọn ba le bọ lọwọ Saulu.
Nigba ti Dafidi pada pẹlu iṣẹgun ninu ogun ti o ba awọn ara Amaleki ja, Ọlọrun wa pẹlu rè̩, nitori naa ni o ṣe bori. Wọnyi ni awọn ara Amaleki ti o yẹ ki Saulu ti parun; ṣugbọn nitori pe Saulu ti kuna ninu ojuṣe rè̩, a ran Dafidi lati lọ pari iṣẹ naa.
Ọlọrun ni iṣẹ fun wa lati ṣe, bẹrẹ lati igba ti O gba ọkan wa là. Oun le ri ọjọ iwaju ki O si ri ohun ti a yẹ fun lati ṣe, Oun a si ṣe eto fun wa bẹẹ gẹgẹ. S̩ugbọn bi a ba kuna lati ṣe iṣẹ ti O ti yàn n kọ? Ẹlomiran ni lati ṣe e, ẹni naa ni yoo si gba èrè naa. Iṣẹ Ọlọrun gbọdọ ṣe, bi ẹni kan ba kọ tabi ti ko ba naani ojuṣe rè̩, Ọlọrun yoo ri ẹlomiran ti yoo ṣe e.
Iroyin Ibanujẹ
Iroyin de ba Dafidi pe Saulu ati Jonatani kú. Ọkunrin ti o mu iroyin naa wa wá pẹlu aṣọ rè̩ ni fifaya ati erupẹ ni ori rè̩ lati fi han pe oniroyin ibanujẹ ni oun. O tẹriba buruburu fun Dafidi, pẹlu irẹlẹ ti ẹsín. N ṣe ni o wá lati wa ojurere fun ara rè̩ lọdọ Dafidi.
Nigba ti Dafidi gbọ pe iranṣẹ naa ti wà loju ogun nigba ti Saulu ba awọn Filistini ja, o beere ẹni ti o ṣẹgun. Iroyin itufọ ti o gbọ ti ba a ninu jẹ pọ to! “Awọn enia na sa loju ijà, ọpọlọpọ ninu awọn enia na pẹlu si ṣubu; nwọn si kú, Saulu ati Jonatani ọmọ rè̩ si kú pẹlu.” O ti bani-ninujẹ pọ to nigba ti awọn eniyan Ọlọrun ba jọgọ silẹ fun ọta ti wọn si salọ sinu agọ wọn!
Ọdọmọkunrin naa tè̩ siwaju lati ṣe alaye pe oun ti ri i pe awọn Filistini lori ẹṣin ati kẹkẹ n lepa Saulu ati Jonatani ninu igbona-gbooru ogun naa. Ọdọmọkunrin naa wi pe Saulu pe oun lati pa oun. Ọdọmọkunrin naa ti gbọran, gẹgẹ bi ọrọ rè̩, o si ti mu ibọwọ ati ade Saulu, o si kó wọn wa nisisiyi fun Dafidi. Lai ṣe aniani o ṣe bi Dafidi yoo bu ọlá fun oun fun pipa ẹni ti o gbiyanju nigba pupọ lati pa Dafidi. S̩ugbọn i ba ṣe pe Dafidi ti fẹ pa Saulu, igba pupọ ni oun i ba ti ṣe e funra rè̩.
Esi Dafidi
Dafidi kò gba ọrọ naa gẹgẹ bi ọdọmọkunrin naa ti rò. Kaka bẹẹ oun ati awọn ọmọkunrin rè̩ ṣọfọ fun iku Saulu ati Jonatani. Wọn gbaawẹ wọn si sọkun nitori pe ọba Saulu kú.
Dafidi kò mọ pe ọrọ ọdọmọkunrin yii kò ri bẹẹ. O bi i pe, “E ti ri ti iwọ kò fi bè̩ru lati nà ọwọ rẹ fi pa ẹni-àmi-ororo OLUWA?” Dafidi ti o jẹ ọkan ninu awọn ẹni ti Ọlọrun yàn, ti a si ti fi àmi-ororo yàn ni ọba, ti bẹru lati gbe ọwọ le ẹni àmi-ororo Oluwa; ṣugbọn keferi yii wi pe oun ti kugbù fi ida pa ọba. Ko ri ọpẹ gbà lọdọ Dafidi. Kàkà bẹẹ Dafidi fi ọrọ ara rè̩ da a lẹjọ -- pe oun ti pa ẹni àmi-ororo Oluwa – o si da a lẹbi ikú.
Dafidi S̩ọfọ
Kaakiri gbogbo agbaye ni a ti kokiki ifẹ ti o wà laarin Dafidi ati Jonatani. Iwa wọn jọra pupọ; ọkan Jonatani dabi ọkan Dafidi. Nitori pe Jonatani jẹ onirẹlẹ, o fẹran iwa irẹlẹ Dafidi. O jẹ akikanju, o si pọn igboya Dafidi lé. Awọn mejeeji jẹ ọmọ Ọlọrun, wọn si gbadun iṣọkan igbagbọ. Jesu wi pe: “Ko si ẹnikan ti o ni ifẹ ti o tobi jù eyi lọ, pe ẹnikan fi ẹmi rè̩ lelẹ nitori awọn ọré̩ rè̩” (Johannu 15:13). Jonatani ti yọọda lati fi ara gba ibinu baba rè̩ ki o ba le ran Dafidi lọwọ. Nisisiyi Dafidi ti padanu ọrẹ rè̩. Jonatani ti kú. Dafidi wi pe: “Wahala ba mi nitori rẹ, Jonatani, arakunrin mi: didùn jọjọ ni iwọ jẹ fun mi: ifẹ rẹ si mi jasi iyanu, o ju ifẹ obinrin lọ. Wo bi awọn alagbara ti ṣubu, ati bi ohun ija ti ṣegbe!”
Bi o tilẹ jẹ pe ibanujẹ Dafidi lori Jonatani, ọrẹ rè̩ timọtimọ ni o pọ ju, oun kò gbagbe igboya ọba, ati awọn ogun ti o ti ṣé̩ fun Israẹli. O sọkun bayii: “Ẹwà rẹ Israẹli li a pa li oke giga rẹ: wò bi awọn alagbara ti ṣubu!” O wi pe ki awọn ọmọbinrin ranti awọn ọṣọ iyebiye ti Saulu ati awọn ọmọ-ogun rè̩ ti ko wale fun wọn nigba ti wọn ba de bi aṣẹgun lati oju ija: “Ẹnyin ọmọbinrin Israẹli, ẹ sọkun lori Saulu, ti o fi aṣọ òdodó ati ohun ọṣọ wọ nyin, ti o fi ohun ọṣọ wura si ara aṣọ nyin.” O kokiki igboya Saulu ati Jonatani loju ogun, ṣugbọn o tun wi bayii “Nibẹ li a gbe sọ asà awọn alagbara nu, asà Saulu, bi ẹnipe a kò fi ororo yàn a.” Lai fi gbogbo ogo rè̩ atijọ, ifi-àmi-ororo Oluwa yàn, ati ọlá rè̩ gẹgẹ bi ọba ni Israẹli pè, o kú bi ẹlẹṣẹ, bi ẹni pe a ko ṣe e logo bẹẹ ri.
Questions
AWỌN IBEERE- Bawo ni Saulu ti ṣe bẹrẹ ijọba rè̩?
- Ta ni fi i jọba lori Israẹli?
- Ki ni tun ṣelẹ si i ni akoko naa?
- Ki ni Saulu ṣe nipa awọn ofin Ọlọrun nigbooṣe?
- Ki ni ṣẹlẹ nigba ti o ke pe Ọlọrun fun iranwọ loju ogun?
- Bawo ni Saulu ṣe ku?
- Iru ọkan wo ni Dafidi fi gba iku Saulu ati ti Jonatani?
- Ki ni ọrọ ikẹyin Paulu Apọsteli?