Lesson 219 - Junior
Memory Verse
AKỌSORI:“Ẹ san ohun ti o tọ fun ẹni gbogbo” (Romu 13:7).Notes
Bibeere ibeere lọwọ Jesu
Awọn olori alufa ati awọn agbagba beere lọwọ Jesu pe aṣẹ wo ni O ni ti O fi n kọ ni bẹẹ ninu Tẹmpili (Matteu 21:23). Idalẹbi wọ inu ọkàn awọn Farisi ti o n gbọ owe Jesu, wọn si mọ pe awọn ni O n bawi. Awọn Farisi pinnu ọna kan nipa eyi ti wọn ni ero lati “mu” Jesu nipa ọrọ Rè̩ (Marku 12:13). Ipinnu wọn ni lati mu ki Jesu sọrọ ti yoo lodi si awọn ara Romu, “ki nwọn ki o le fi i le agbara ati aṣẹ Bālẹ” lọwọ (Luku 20:20).
Awọn Farisi tikara wọn ko wa sọdọ Jesu. Wọn ran awọn ọmọ-è̩yìn wọn pẹlu awọn ẹgbẹ kan ti a n pe ni awọn-ti-Hẹrọdu, awọn ti o daju pe wọn wà labẹ akoso Hẹrọdu ati ẹbi rè̩. Wọn ro pe nipa ọrọ ipọnni, wọn yoo mu Jesu lai ro tẹlẹ. Wọn pe E ni “Olukọni” bi ẹni pe ọmọ-è̩yìn Rẹ ni wọn.
Olootọ Olukọni
Awọn eniyan naa wi pe, “Awa mọ pe olotitọ ni iwọ, iwọ si nkọni li ọna Ọlọrun li otitọ.” Otitọ ni ọrọ ti wọn sọ, wọn i baa mọ bẹẹ tabi wọn ko mọ. Olotitọ ni Jesu, otitọ ni O si n kọ ni. A ti fi orukọ yii fun Un, “Olododo ati Olõtọ” (Ifihan 19:11). Jesu wi ni ti ara Rè̩ pe, “Emi li ọna, ati otitọ, ati iye” (Johannu 14:6).
Olotitọ Olukọni ni Jesu i ṣe. Jesu kò jafara lati ba eniyan wi nitori è̩ṣẹ, bi o tilẹ jẹ pe ẹni naa jẹ ọlọrọ, eniyan pataki, tabi ọmọwe. Ifẹ Jesu ati inurere Rè̩ pọ si eniyan gbogbo to bẹẹ ti Oun ki i fi ṣe ojusaju fun ẹnikẹni. Ẹkọ Rè̩ wa fun gbogbo eniyan. Jesu jẹ olootọ lati tọka si è̩ṣẹ ti o wa ninu igbesi-ayé oniruuru awọn eniyan, ati lati mu è̩ṣẹ naa kuro ninu igbesi-ayé awọn ti o ronupiwada.
Awọn eniyan wọnyi ti wọn tọ Jesu lọ fara han bi ẹni pe wọn wá lati beere nipa ọna otitọ, ṣugbọn ni tootọ wọn ko fẹ lati mọ ohun ti Jesu n sọ. Wọn n fẹ lati dẹkùn mu Un ni, ki wọn ba le lọ ọrọ Rè̩ ki wọn si túmọ rè̩ si ọna miiran.
Sisan Owode
Ibeere ti awọn eniyan wọnyi beere jẹ iru eyi ti a le fi dẹkùn mu eniyan kan lasan. Wọn beere lọwọ Jesu bi o ba “tọ lati mā san owode fun Kesari, tabi ko tọ”? Wọn ni ireti pe, idahun Jesu yoo mu ki O bọ sinu wahala. Bi Jesu ba sọ pe ki wọn san owode, awọn ọmọ-ẹyin awọn Farisi yoo rú ọkàn awọn eniyan soke lodi si Jesu. Ni ọna keji, bi Jesu ba wi fun wọn pe wọn ko gbọdọ san owode, awọn ti Hẹrọdu yoo lọ sọ fun Hẹrọdu. Wọn rò pe wọn ti dẹkùn mu Jesu. Wọn rò pe ohunkohun ti o wù ki O fi dahun yoo sọ Ọ di eniyan buburu si ijọba tabi si awọn eniyan. Wọn beere pe, “Ki awa ki o fifun u, tabi ki a má fifun u?” (Marku 12:15).
Ọgbọn Kristi
Jesu mọ ero buburu ati agabagebe wọn (Marku 12:15), ati arekereke wọn (Luku 20:23). Jesu mọ pe ipinnu wọn ki i ṣe fun rere Oun tabi fun awọn tikara wọn. Wọn kò ṣe afẹri otitọ. Wọn ti fi ọgbọn è̩wé̩ gbe ipinnu buburu wọn kalè̩, wọn si mu ki o fara hàn bi ipinnu rere, ṣugbọn o di asan nitori pe Ọmọ Ọlọrun ni awọn eniyan wọnyi n ṣe e si, Ẹni ti ọgbọn Rè̩ tayọ ti ẹnikẹni. Awọn eniyan wọnyi ati awọn ẹlomiran ti kọ ẹkọ pe eniyan ko le tan Oluwa Ọlọrun jẹ tabi ki o fi ohun ti o wà ninu ọkàn rè̩ pamọ fun Un. “OLUWA a ma wò ọkàn” (I Samuẹli 16:7). “Iwọ, Oluwa, olumọ ọkàn gbogbo enia” (Iṣe Awọn Apọsteli 1:24). “Nitori ọrọ Ọlọrun yè, o si li agbara, . . . . on si ni olumọ ero inu ati ète ọkàn” (Heberu 4:12). “Bayi li OLUWA wi,. . . . mo mọ olukuluku ohun ti o wá si inu nyin” (Esekiẹli 11:5).
Owo Idẹ Kan
Dajudaju, idahun Jesu jẹ iyalẹnu fun awọn ọmọ-lé̩yìn Hẹrọdu ati awọn ọmọ-è̩yìn awọn Farisi. O beerè fun owo idẹ kan. Boya Jesu ko ni. O di talaka nitori ti wa, ki awa ki o ba le ni ọrọ tootọ ti i ṣe ti Ọrun (II Kọrinti 8:9). Ohun ti ẹmi ni Jesu n fiyesi jù ohun ti igba diẹ tabi ti ara lọ.
A mu owo idẹ kan ti i ṣe owode kan wa fun Jesu. O beerè nipa akọle ati aworan ti o wa lara owo naa. Ofin kan wa laarin awọn Ju pe, ẹni ti a ba n lo owo rè̩, oun ni alaṣẹ ni orilẹ-ède naa; gẹgẹ bi o ti jẹ pe awọn ti o ba ti gba Jesu ni Ọba aye wọn a maa ni aworan Kristi ninu ọkàn wọn. A ti kọ ẹkọ pe Kristi ni Ọba awọn, ọba ati pe ni ọjọ kan yoo si jọba lori gbogbo eniyan. Nisisiyi Kristi n ṣakoso, O si n jọba ninu ọkàn awọn eniyan Rè̩, awọn ti wọn ni ootè̩ aworan Kristi ninu ọkàn ati ayé wọn.
Ko si Ohun Idigbolù
Lara owode naa ni aworan ati akọle Kesari wà. Jesu sọ pe, “Ẹ fi ohun ti iṣe ti Kesari fun Kesari, ati ohun ti iṣe ti Ọlọrun fun Ọlọrun.” Ohun ti Jesu sọ ni yii. Kò sọrọ lodi si ijọba tabi awọn eniyan. Idahun Jesu yé ni yekeyeke, o si jẹ otitọ. A kò le ṣi itumọ rè̩. Dipo ti wọn i ba fi dẹkùn mu Jesu, ibawi ni wọn gbà; nitori gbogbo wọn ni o jẹbi kikuna lati fi ohun ti i ṣe ti Ọlọrun fun Un.
Ninu ọrọ diẹ ti Jesu sọ, O fi hàn wa pe ọmọ-ibilẹ rere ni awọn Onigbagbọ jẹ. Wọn a maa ṣe ojuṣe wọn si orilẹ-ède wọn. Dajudaju, wọn a maa ṣe ojuṣe wọn si Ọlorun pẹlu, nitori “Awa kò gbọdọ má gbọ ti Ọlọrun jù ti enia lọ” (Iṣe Awọn Apọsteli 5:29). Ọpọlọpọ eniyan ni o maa n boju to awọn nnkan ti igba diẹ ni ayé isisiyi, ṣugbọn wọn a gboju fo awọn ohun ti ẹmi. Ẹ má ṣe jẹ ki a kuna lati gbọran si apa ikẹyin ọrọ Jesu, ti o wi pe ki a fi “ohun ti iṣe ti Ọlọrun fun Ọlọrun.” Ọkàn ati ayé wa jẹ ti Ọlọrun. Njẹ a n fi wọn fun Un? Itumọ ọrọ ti a pe ni “fi fun” ni da pada fun tabi mu pada fun. A ha n san ifẹ ti Ọlọrun fi hàn fun wa pada fun Un? Jesu ti fi ọpọlọpọ fun wa. Ki ni ohun ti a fi fun Un?
Awọn ọmọ-è̩yìn Hẹrọdu ati awọn ọmọ-è̩yìn awọn Farisi ko ri èrè kan gbà nipa titako Kristi. Idahun Rè̩ ya wọn lẹnu. Wọn dakẹ jẹẹ, wọn si fi I silẹ, O ti ṣẹgun wọn, ṣugbọn wọn kọ lati gba ọrọ iyè Rè̩. Sibẹ, wọn ko fi ọlá ti o tọ fun Ọlọrun fun Un.
Paulu sọ ninu iwe ti o kọ si awọn ara Romu pe: “Nitorina ẹ san ohun ti o tọ fun ẹni gbogbo: owo-ode fun ẹniti owo-ode iṣe tirè̩: owo-bode fun ẹniti owo-bode iṣe tirè̩: è̩ru fun ẹniti è̩ru iṣe tirè̩; ọlá fun ẹniti ọlá iṣe tirè̩” (Romu 13:7).
Ibeere Miiran
Ni ọjọ kan naa, awọn ẹgbẹ miiran tun wa lati beere ibeerè lọwọ Jesu. Ni akoko yii, awọn Sadusi ni, awọn ti wọn sọ wi pe ajinde kò si. Wọn pe Jesu ni “Olukọni,” gẹgẹ bi awọn ti iṣaaju ti ṣe. Wọn sọ Ofin Mose (Deuteronomi 25:5). Wọn si fi apẹẹrẹ fun Jesu lati fi idi ọrọ wọn nipa ajinde mulè̩. Wọn rò pe Jesu kò ni le da wọn lohun, nipa bẹẹ wọn o fi hàn pe ohun ti o tọ ni awọn n ṣe nipa sisẹ ajinde. Apẹẹrẹ ti wọn mu wa jẹ eyi ti kò wọpọ: Awọn arakunrin meje wà, gbogbo wọn si kú; awọn mẹfa si ti gbọran si Ofin Mose nipa fifẹ opo arakunrin wọn. Awọn Sadusi yii n fẹ lati mọ iyawo ẹni ti obinrin yii yoo jẹ ni ajinde, nitori pe o ti jẹ iyawo awọn arakunrin meje wọnyi ni ayé.
Òpè nipa Iwe Mimọ
Jesu dahun ibeere alailọgbọn wọn nipa sisọ fun wọn pe wọn ṣe aṣiṣe yii nitori pe wọn jẹ òpè nipa ohun ti Iwe Mimọ sọ nipa wiwà lẹyin ikú, bẹẹ ni wọn kò si mọ agbara Ọlọrun. Jesu wi fun wọn pe, ni ajinde kò si igbeyawo.
Jesu pa awọn Sadusi lẹnu mọ ni ọna ti o jẹ wi pe wọn ko tun jẹ beere ibeere kan lọwọ Rè̩ mọ. Lati inu Iwe Mose ti awọn tikara wọn ti kọkọ tọka si ni O ti fun wọn ni idahun wọn, O si fi han fun wọn pe ajinde wà, nitori O wi pe, “Ọlọrun ki iṣe Ọlọrun awọn okú, bikoṣe ti awọn alāye.”
Ajinde
Awọn Sadusi ṣe aṣiṣe wọn nitori pe wọn ko gba gbogbo ọrọ Iwe Mimọ gbọ. Majẹmu Laelae kọ ni nipa ajinde gẹgẹ bi Majẹmu Titun ti kọ ni. Jobu sọ nipa igbagbọ rè̩ ninu ajinde (Jobu 19:25-27). Dafidi Onipsalmu sọrọ nipa ajinde (Orin Dafidi 71:20). Daniẹli sọ asọtẹlẹ nipa ajinde (Daniẹli 12:2). (Ka ẹkọ ọgọfa (120) ti o n sọ fun wa ni kikun ju bayi lọ nipa ajinde.
Gbogbo Bibeli
Loni, awọn eniyan a maa lọ sinu iṣinà nitori pe wọn ko gba gbogbo ọrọ Iwe Mimọ gbọ, ki wọn si fi maa kọ ni. A ni lati gba gbogbo Bibeli gbọ, lati ẹsẹ kin-in-ni Gẹnẹsisi ti i ṣe Iwe Kin-in-ni, titi de ẹsẹ ti o kẹyin ninu Ifihan, Iwe ti o kẹyin – bi a ba fẹ lọ si Ọrun.
Jesu fi Ọrọ Ọlọrun da awọn agabagebe ti o fẹ dẹkùn mu Un lohun. Kò ta awọṅ ti o wa beere lọwọ Rè̩ nu. Loni, a ri i pe Bibeli ni idahun si gbogbo ibeere tootọ nipa ohun ti ẹmi ti yoo ran eniyan lọwọ lati mura silẹ ki o si wà ni ipo imurasilẹ bẹẹ fun bibọ Oluwa.
Ibeere Kan lati ọdọ Jesu
Jesu beere ibeere kan lọwọ awọn Farisi ti o pejọ sibẹ, ki i ṣe lati dẹkùn mu wọn, ṣugbọn lati kọ wọn l’ẹkọ. Ibeere Rè̩ ni yii, “Ẹnyin ti rò ti Kristi si? ọmọ ta ni iṣe?” Idahun wọn ni “Ọmọ Dafidi.” Itumọ eyi ni pe, wọn rò pe eniyan ni Kristi i ṣe. O yẹ ki Kristi jù bẹẹ lọ loju wọn. Fun awọn Onigbagbọ, Kristi jẹ Ọmọ Ọlọrun, Olugbala ati Olurapada wọn. Jesu beere ibeere kan lọwọ wọn, eyi ti olukuluku wa ni lati dahun. Iwọ ti ro ti Kristi si? Olugbala ati Olurapada rẹ ni bi?
Nigba ti awọn Farisi dahun pe awọn rò pe Ọmọ Dafidi ni Kristi i ṣe, Jesu wa beere lọwọ wọn pe bawo ni Dafidi ti ṣe le pe E ni “Oluwa” bi o ba jẹ ọmọ Dafidi. Eyi yii kò ye wọn, o si dabi ẹni pe o ṣoro fun wọn lati ṣe alaye rè̩. Otitọ nikan ni o le jẹ idahun si ibeere yii. Lotitọ ni Jesu jẹ eniyan; gẹgẹ bi ọmọ eniyan, O jẹ ọmọ Dafidi. Bakan naa ni Jesu tun jẹ Ọlọrun, Ọmọ Ọlọrun, ẹni ti Dafidi pè ni “Oluwa mi” (Orin Dafidi 110:1). (Ẹkọ aadọfa-le-mẹta (113) ati aadoje (130) kọ wa jù bẹẹ lọ nipa Jesu Ọmọ Ọlọrun.
Awọn Farisi kò tun ni ohunkohun kan ti wọn le sọ fun Jesu mọ. Ẹnikẹni ko tun beere ibeere lọwọ Rè̩ mọ. Ko si ẹni ti o bori ninu awọn ti wọn wa lati gbá ọrọ mọ Kristi lẹnu. Ọpọlọpọ ni ọgbọn Jesu ya lẹnu, sibẹsibẹ wọn lọ si ile wọn lai gbagbọ. Ẹ jẹ ki a jẹ “oluṣe ọrọ na, ki o má si ṣe olugbọ nikan” (Jakọbu 1:22).
Questions
AWỌN IBEERE- Ki ni ṣe ti awọn eniyan naa n fẹ lati dẹkùn mu Jesu nipa ọrọ Rè̩?
- Ki ni ọrọ miiran fun owode?
- Ta ni Kesari i ṣe?
- Ki ni ohun ti a ni lati fi fun Ọlọrun?
- Ki ni igbagbọ eke awọn Sadusi?
- Bawo ni Jesu ṣe da awọn Sadusi lohùn?
- Ki ni awọn Farisi rò nipa Kristi?
- Ki ni ṣe ti idahùn wọn tọnà ni apakan nikan ṣoṣo?
- Ki ni ṣe ti a ni lati gba gbogbo Bibeli gbọ?
- Ki ni ṣe ti o jẹ ọranyan lati gbọ ati lati pa gbogbo Ofin Ọlọrun mọ?