Johannu 12:20-36

Lesson 220 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI:“Ọlọrun kò rán Ọmọ rè̩ si aiye lati da araiye lẹjọ; ṣugbọn ki a le ti ipasẹ rè̩ gbà araiye là”(Johannu 3:17).
Notes

Isopọ Laarin Ọrun ati Aye

Lẹyin ti Ọlọrun ti da eniyan sinu Ọgba Edẹni, Ọlọrun sọkalẹ, O n ba a rin, O si n ba a sọrọ. Irẹpọ timọtimọ wà laarin Ọrun ati ayé, iṣọkan laarin Ọlọrun ati eniyan. S̩ugbọn nigba ti è̩ṣẹ wọ inu Ọgba, irẹpọ naa bajẹ, a si yi ẹda eniyan pada. Adamu fi ara rè̩ pamọ fun Ọlọrun. Ọlọrun dá a lẹbi pe ki o fi ẹwà ati alaafia Edẹni silẹ, ki o si maa ṣiṣẹ fun atijẹ ati atimu rè̩, ki o maa ro ilẹ lati ri ounjẹ jẹ. Iṣọkan rè̩ pẹlu Ọrun ti bajẹ, O ni lati maa ṣaniyan awọn ohun ti aye.

Lati ọdun-mọdun ti eniyan ti ṣubu, awọn eniyan ti wá ọna pupọ lati gbiyanju lati pada bọ sinu ẹwà pipé ti wọn ti gbadun ninu Ọgba nì lai beere ọna lọwọ Ọlọrun tikara Rè̩. Awọn kan tilè̩ gbiyanju lati kọ ile-iṣọ Babeli ki wọn ba le de Ọrun, ki wọn ba le gba ọna miiran wọle yatọ si ọna ti Ọlọrun ti là silẹ. S̩ugbọn inu wọn ki ba ti dun bi o ba tilẹ ṣe e ṣe fun wọn lati goke wọle. Wọn jẹ ẹlẹṣè̩, ara kò si le rọ wọn ni Ọrun.

Erupẹ fun Erupẹ

Nigba ti a ṣẹṣẹ da ayé, ipinnu Ọlọrun ni pe ki eniyan maa wà titi, ṣugbọn è̩ṣẹ mu ikú ati aisan wá. Lati igbà naa ni awọn ẹlẹkọ ijinlè̩ ti gbiyanju lati mu ki awọn ọmọ eniyan ni alaafia si i, ti wọn si n gbiyanju lati mu ki wọn ni ẹmi gigun si i pẹlu. S̩ugbọn sibẹ, eniyan yoo sa kú, ara rè̩ yoo si pada si erupè̩. Ọlọrun sọ fun awọn ẹlẹṣè̩ akọkọ pe: “Li õgun oju rẹ ni iwọ o ma jẹun, titi iwọ o fi pada si ilẹ; nitori inu rè̩ li a ti mu ọ wá, erupẹ sa ni iwọ, iwọ o si pada di erupẹ” (Gẹnẹsisi 3:19).

Awọn ohun ti a n jẹ ti a si n mu, lati inu ilẹ ni wọn ti wá. Aṣọ ti a n wọ, ohun ti yoo dibajẹ ni a fi ṣe wọn. Owo wa paapaa, bi a ba ni rara, kò ni wa laelae. Apọsteli ni sọtẹlẹ pe, wura ati fadaka naa yoo dipaarà (Jakọbu 5:3). Ko si nkankan ninu ayé yii ti yoo duro titi -- ayé paapaa ko ni wà titi.

Ibi Giga

Bi a tilè̩ jẹ “ẹni ti aye,” sibẹ, nigba gbogbo ni oungbẹ ti wà ninu ọkàn awọn eniyan fun igbesi-ayé ti o dara jù eyi lọ. Awọn ọjọgbọn pupọ ti gbiyanju lati wa igbesi-ayé ti o ga jù bẹẹ ri. Awọn mi ran kọ awọn ọmọ-ẹyin wọn lati fi igbadun aye du ara wọn, ki ounjẹ wọn jẹ iwọntunwọnsi, boya pẹlu, ki wọn má ṣe aṣehàn ninu aṣọ wiwọ, lati fi hàn pe awọn kò lepa nnkan ti ayé. S̩ugbọn sibẹ wọn kú, wọn si pada si erupẹ lai ri ipa-ọna iye-ainipẹkun nipa ṣiṣe bẹẹ.

Ọna si iye-ainipẹkun kò nira lati ri. Bi eniyan ba fi tinutinu wa Ọlọrun, oun yoo rii pe iye-ainipẹkun yoo bè̩rẹ ninu ọkàn rè̩ nigba ti oun tilẹ wà ninu ayé yii sibẹ. Nigba ti Onigbagbọ kan ba ri igbala, ohun kan maa n bè̩rẹ ninu ọkàn rè̩, eyi ti kò ni dopin laelae bi oun kò ba pada lẹyin Jesu. Ninu Bibeli, ọna yii fara han kedere to bẹẹ ti awọn ọmọde paapaa le fi mọ bi wọn ti ṣe le ri igbala. Idi rè̩ ti awọn ọlọgbọn kò fi ri i ni pe wọn ti gbiyanju lati ba “ọna miiran” wọle yatọ si eyi ti Jesu ti là silè̩.

Ọlọrun mọ pe eniyan ko dara tó ti yoo fi le pada bọ si iwa pipé ti awọn obi wa akọkọ ti gbadun ninu Ọgba Edẹni, bẹẹ ni kò ṣe e ṣe fun eniyan lati goke lọ si Ọrun lati kọ bi wọn ti ṣe n huwà; nitori bẹẹ Baba rán Jesu wa sinu ayé lati maa ba eniyan gbe, ki O ba le fi han wọn bi wọn ti ṣe le wà ni irẹpọ pẹlu Ọrun.

Ibè̩wo awọn Hellene

Ni ọjọ kan, awọn Hellene kan wa ri Jesu. Awọn Hellene jẹ ọmọwé eniyan, awọn ọjọgbọn, wọn si pẹlu awọn wọnni ti wọn ti gbiyanju lati kọ ni ni igbesi-aye rere; ṣugbọn awọn wọnyi fẹ lati ri Jesu nitori pe wọn gbagbọ pe Oun ni O ni kọkọrọ si iye-ainipẹkun lọwọ ni tootọ.

Jesu mọ ẹkọ ti awọn alejo Rè̩ fẹ lati kọ, O si da wọn lohùn pe: “Bikoṣepe wóro alikama ba bọ si ilẹ, ti o ba si kú, o wà on nikan: ṣugbọn bi o ba kú, a si so ọpọlọpọ eso. Ẹniti o ba fẹ ẹmi rè̩ yio sọ ọ nu; ẹniti o ba si korira ẹmi rè̩ li aiye yi ni yio si pa a mọ titi di iye ainipẹkun.”

È̩kọ ijinlẹ pupọ wà ninu ọrọ wọnni. Ẹ jẹ ki a kọkọ ṣakiyesi wóro alikama. Eniyan le pa alikama naa mọ fun ọdun pupọ, ki o maa dan ni ibi gbigbẹ kan; o si le fi han awọn ọrẹ rè̩ ki o si sọ wi pe gẹgẹ bi oun ti fi i silẹ gan an ni ijọsi, bẹẹ ni o wà sibẹ. S̩ugbọn iba woro kan naa ni oun yoo sa maa ni, kò ni jù bẹẹ lọ. S̩ugbọn bi a ba fi woro kan naa si ilẹ tutu nibi ti yoo ti rà, ti yoo si dabi ẹni pe a ba woro lile korokoro naa jẹ, lai pẹ irugbin titun yoo yọ jade lati inu eehù ti o wa ninu woro ti o dibajẹ naa. Nigba ti akoko ẹẹrùn yoo ba fi de, igi kan ni a o ri pẹlu ṣiiri alikama pupọ, awọn woro rè̩ yoo si gbẹ, yoo si le korokoro gẹgẹ bi woro ẹyọ kan ṣoṣo ti a ti gbin sinu ilẹ. Ẹni ti o ni in yoo ni pupọpupọ jù eyi ti i ba ni bi o ba ṣe pe o fi irugbin rè̩ pamọ sinu apoti ti a fi n polowo ọja.

Ohun ti o n ṣẹlẹ nigba gbogbo ni yii si irugbin-kirugbin nibikibi ti wọn ti n gbin nnkan. Eyii ki i ṣe ohun ajeji fun ẹnikẹni. Kàkà bẹẹ, ti ninu irugbin wọn ko ba hù, ijatilẹ ni o maa n jẹ fun wọn. Lati inu ikú woro naa ni iye titun ti sú jade lọpọlọpọ.

Iyè ni Ẹkunré̩ré̩

Lati inu ọrọ wọnyii, Jesu kọ ni ni ohun ti eniyan ni lati ṣe ki o to le gbadun iyè ni ẹkunrẹrẹ. Bi eniyan kan ba n té̩ ifẹ ara rè̩ lọrùn, ti o n fi gbogbo akoko rè̩ lepa dukia ayé yii -- ounjẹ ti yoo jẹ, aṣọ ti yoo di gbigbó, mọto ti yoo darugbo ti yoo si wo palẹ -- ko le ni ilọsiwaju rara. Bẹẹ ni oun yoo si kú ni ọjọ kan lai ni ireti ibi ti o n lọ. Eyi ki i ṣe igbesi ayé ti o wú ni lori.

Iye ni ẹkunré̩ré̩, eyi ti Jesu n ṣe apejuwe rè̩ maa n wá nipa kikú si ohun ti ara, fifi ayé ẹni rubọ fun Oluwa. Nigbà ti eniyan ba fi ọkàn rè̩ fun Jesu, ti o ba si kọ è̩ṣẹ rè̩ silẹ, nigba naa iyè ainipẹkun yoo bẹrẹ ninu rè̩. Oun a bẹrẹ si i gbadun awọn nnkan ti è̩mi, nnkan ti Ọrun. Isopọ pẹlu Ọrun ti eniyan ti sọnu nipa iṣubu yoo tun fidi mulẹ lẹẹkan si i. Oun yoo mọ wi pe Jesu wà ni tosi lati tù oun ninu ati lati mu oun lọkan le, lati wò oun san nigba ti oun ba ṣaisan. Oun mọ pe Jesu n gbọ adura rè̩, idahun si n wá. Bi o ti n fi ara rè̩ rubọ fun Oluwa to, ti o si n pa awọn nnkan wọnni run ti ki i ṣe è̩ṣẹ ṣugbọn ti o n gba pupọ ninu akoko rè̩ kuro ninu ijọsin fun Ọlọrun, bẹẹ ni yoo maa gbadun iyè yii ni ẹkunré̩ré̩ si i. O si mọ wi pe nigba ti oun ba kú ẹmi oun yoo lọ si Ọrun: ati ni Ajinde Kin-in-ni a o ji ara oun paapaa dide ki o le maa wà laayè titi lae.

Nigba ti Ipè Ọlọrun ba dun, “awọn okú ninu Kristi ni yio si kọ jinde: nigbana li a o si gba awa ti o wà lāye ti o si kù lẹhin soke pẹlu wọn sinu awọsanma, lati pade Oluwa li oju ọrun: bẹli awa ó si ma wà titi lai lọdọ Oluwa” (I Tẹssalonika 4:16, 17). Jesu wi pe: “Eyi si ni ifẹ ẹniti o rán mi, pe ẹnikẹni ti o ba wò Ọmọ, ti o ba si gbà a gbọ, ki o le ni iye ainipẹkun: Emi ó si ji i dide nikẹhin ọjọ” (Johannu 6:40). Aṣiiri iyè-ainipẹkun ni gbigba Jesu ni Ọmọ Ọlọrun, ati gbigba A gbọ fun igbala ọkàn wa.

Akọbi ninu Awọn Ti O Sùn

Bawo ni a ti ṣe mọ daju pe a o wà laayè titi lae? Njẹ ara ti a ti gbe sin ti o si ti di erupè̩, tabi eyi ti a ti sun ti o si ti di eerú le pada tun di ara eniyan bi? Njẹ alikama ti a sọ nipa rè̩ n kọ, eyi ti o n jẹrà ki ọjẹlẹ titun to hù ti o si n mu alikama pupọ jade? A gbin alikama, o si jẹrà, o hù, o si tun dagba soke; awọn wóro titun si tun so, eyi ti a le tun gbin. Ki i si i yipada. Bẹẹ gẹgẹ ni ara ti o ti di erupè̩ yoo tun jade ni iru kan naa bi o ti wà ri.

Ọlọrun ti fun wa ni ẹri ti o daju fun ọrọ Rè̩ pe awọn oku yoo tun wà laayè. Jesu kú, O si tun ji dide. Jesu ti sọ tẹlẹ fun awọn ọmọ-è̩yìn Rè̩ pe Oun yoo ku – pe nitori eyi ni O ṣe wa si ayé yii -- ṣugbọn pe, ni ọjọ kẹta Oun yoo tun ji dide. O tun sọ pẹlu pe ara ti Oun yoo gbe wọ yoo jẹ eyi ti wọn yoo mọ -- wọn si mọ Ọn. Awọn eniyan ri I -- wọn pọ to ẹẹdẹgbẹta (500) ni akoko kan. Wọn mọ Ọn; wọn ba A rin wọn si ba A sọrọ. Jesu tilẹ ba wọn jẹun, nitori naa ki i ṣe iwin.

Iba ṣe pe iku Jesu ni o pari iṣẹ Rè̩ ni ayé, ki ba ti si ireti iyè-ainipẹkun fun wa. Paulu Apọsteli kọwe bayii: “Bi a kò bá si ji Kristi dide, asan ni igbagbọ nyin; ẹnyin wà ninu è̩ṣẹ nyin sibẹ. . . . Njẹ nisisiyi Kristi ti jinde kuro ninu okú, o si di akọbi ninu awọn ti o sùn” (I Kọrinti 15:17, 20). Didi akọbi n sọ pe Oun ni yoo kọ ji dide, lẹyin naa ni awọn miiran yoo tè̩le E ni ọna kan naa. O tun fi awọn ọrọ ti o kun fun ireti wọnyi kun un: “Nitoriti emi wà lāye, ẹnyin ó wà lāye pẹlu” (Johannu 14:19).

Ara Ologo

Bi o tilẹ jẹ pe Jesu ni ẹran-ara nigba ti O ji dide, ara Rè̩ ni awọn agbara kan ti o logo pupọ tayọ ara ti wa ti o kun fun iyọnu yii. Bi a ba jù ohunkohun soke, o ni lati pada ja bọ si ilẹ: ṣugbọn ilẹ tabi idiwọkidiwọ kankan kò lagbara lori ara Jesu. O le ba ẹnu ọna ti a tì wọle. Bi O ba fẹ lọ si ibi kan, Oun yoo de ibẹ lẹsẹ kan naa lai ṣẹṣẹ wa ọkọ oju-irin tabi mọto, bi awa ti n ṣe loni. Iru ara ologo bayii ni olukuluku Onigbagbọ yoo gbadun nigba ti Jesu ba de, yala oluwarè̩ wa laayè titi ọjọ naa tabi o ku ki a si ji i dide. Ara ologo naa yoo wà lai kú titi lae.

Iyà Jijẹ

Nigba ti Jesu wà ninu ayé, O jẹ eniyan bi o ti jẹ Ọlọrun pẹlu. Erò nipa iyà ti O mọ wi pe o wà niwaju Rè̩ nipa iku Rè̩ lori agbelebu ko ni ṣai yọ Ọ lẹnu. O mọ wi pe irora Rè̩ yoo pọ jù eyi ti eniyan ẹlẹran-ara le fara dà, nitori pe è̩ṣẹ gbogbo araye ni Oun yoo rù. Bi o ba ṣe pe ọna miiran wà ni nipa eyi ti O le ṣiṣẹ irapada eniyan, boya Oun i ba yan iru ọna bẹẹ. S̩ugbọn ọna miiran kò si, nitori bẹẹ O gbà lati jiya.

Ni akoko idanwo yii, O gbadura si Baba pe: “S̩e orukọ rẹ logo.” Ọlọrun dahun pe: “Emi ti ṣe e logo na, ẹmi o si tun ṣe e logo.” Ni gbogbo akoko iṣẹ-iranṣẹ Kristi, O ti ṣe ọpọlọpọ iṣẹ iyanu nipa agbara Ọlọrun. O wi pe Oun kò dá ohunkohun ṣe. Baba ni O ti ṣiṣẹ nipasẹ Rè̩. Ni ọna bayii Ọlọrun ti ṣe E logo pe O jẹ ọkan naa pẹlu Oun. Jesu ti wi pe, “Ọkan li emi ati Baba mi jasi” (Johannu 10:30). Siwaju si i Ọlọrun ti sọrọ lati Ọrun wa nigba ti a ṣe iribọmi fun Jesu, awọn eniyan si ti gbọ ohùn Ọlọrun: “Eyi ni ayanfẹ Ọmọ mi, ẹniti inu mi dùn si gidigidi” (Matteu 3:17). Lẹẹkan si i, ni akoko ipalarada, Ọlọrun tun sọ ọrọ kan naa.

Jesu wi pe, Ohùn ti o ti Ọrun wa naa wá lati ọdọ Baba lati ran awọn eniyan lọwọ ki wọn ba le gbagbọ pe Ọmọ Ọlọrun ni Jesu I ṣe. Akoko ti a o kan An mọ agbelebu ti sun mọle, nigba ti a o “gbe E soke” lori agbelebu; ṣugbọn nigba ti O ba ti la iku ati ajinde Rè̩ kọja, Oun yoo pe gbogbo ọkunrin ati obinrin sọdọ ara Rè̩ lati fi iyè ainipẹkun fun gbogbo awọn ti o ba fẹ ẹ.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Apẹẹrẹ wo ni Jesu lo lati fi ṣe àlàyé ajinde?
  2. Njẹ ẹmi wa nikan ni a o ji dide? Tabi ara pẹlu?
  3. Ninu iru ara wo ni Jesu jinde kuro ninu oku?
  4. Fun saa wo ni Onigbagbọ yoo wa laayè lẹyin ajinde lati maa gbadun awọn ibukun Ọlọrun?
  5. Ki ni a ni lati ṣe ki iyè ainipẹkun ba le bẹrẹ ninu wa?
  6. Bawo ni a ti ṣe le gbadun iyè ni è̩kúnré̩ré̩ ninu aye yii?
  7. Nigba wo ni a o ji ara dide?
  8. Bawo ni Ọlọrun ti ṣe ṣe Ọmọ logo?
  9. Ki ni itumọ ọrọ ti Jesu sọ wi pe Oun ni akọbi ninu awọn ti o sun?
  10. Lori otitọ pataki wo ni igbagbọ wa duro le?