Matteu 27:57-66;28:1-20

Lesson 221 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI:“Emi mọ pe Oludande mi mbẹ li āyè” (Jobu 19:25).
Notes

Kikan Kristi Mọ Agbelebu

O fẹrẹ to ọsẹ kan ṣaaju kikan Jesu mọ agbelebu, awọn eniyan ti bu ọlá fun Un nigba ti O n wọ Jerusalẹmu ninu ọlanla Rè̩. Awọn eniyan naa ti ké, “Hosanna; Olubukun li ẹniti mbọwá li orukọ Oluwa” (Marku 11:9). Laarin ọjọ diẹ, iyin wọn ti yipada di igbe ikà pe, “Kàn a mọ agbelebu, kàn a mọ agbelebu” (Luku 23:21). Lẹyin ti Pilatu ti sọ ni ẹrinkẹta pe oun kò ri è̩ṣẹ kan lọwọ Kristi, awọn eniyan naa bori, a si mu Kristi lọ lati kàn An mọ agbelebu.

Idariji

Lori Oke Kalfari, lẹyin ti a ti kàn An mọ agbelebu, Jesu wi pe “Baba, dariji wọn; nitoriti nwọn kò mọ ohun ti nwọn nṣe” (Luku 23:34). Ifẹ Rè̩ fun awọn ẹlẹṣè̩ pọ to bẹẹ ti o fi tọkàntọkàn dariji awọn ti wọn pa A, lẹyin fifi ayé Rè̩ lelẹ ki awọn ti o gba A gbọ le ni iyè ainipẹkun. Nigba ti ifẹ Jesu ba gba ọkàn wa kan, a ki i ni ikannu si ẹnikeni – i baa tilẹ jẹ ẹni ti o ti huwa ti ko dara si wa. Awa paapaa yoo ni ifẹ ti o n dariji ni tọkantọkan.

Jesu, Ọmọ Ọlọrun kú lori agbelebu, laarin awọn ole meji. Bayi ni a mu Iwe Mimọ ṣẹ (Isaiah 53:12). “Ọkan ninu awọn ọmọ-ogun na fi ọkọ gún u li ẹgbẹ, lojukanna è̩jẹ ati omi si tú jade” (Johannu 19:34). Kristi fi ẹmi Rè̩ lelẹ, O si ta È̩jẹ Rè̩ silẹ ki a ba le wẹ è̩ṣẹ wa nu, ki a si le gbe igbesi ayé mimọ ati aileeri nihin ni ayé yi, ki a si mura silẹ fun Ọrun.

Awọn Ọmọ-Ẹyin Rè̩

Ni akoko ti a kàn Jesu mọ agbelebu ati ni akoko ikú Rè̩, awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ ti fọnká. Peteru sẹ Jesu pe oun kò mọ Ọn (Matteu 26:70-72). Awọn iyoku duro ni okeere, wọn n wo ohun ti o n ṣẹlẹ. Awọn miiran kun fun è̩rù pe awọn eniyan le mọ pe ọmọ-ẹyin Jesu ni wọn. Boya wọn bè̩rù pe irú ikú kan naa ni o n duro de awọn bi wọn ba jẹwọ pe ọmọ-ẹyin Jesu ni awọn. Niwọn bi o ti jẹ ọjọ ipalẹmọ Ajọ Irekọja, ti ko si gbọdọ si ẹni kan lori agbelebu ni Ọjọ Isimi (Johannu 19:31), ki ni yoo ṣẹlẹ si okú Kristi?

Ijolootọ

Nigba iṣoro ati wahala, a maa n ri awọn eniyan olootọ ti yoo ṣiṣẹ fun Oluwa. Ni akoko yii ti awọn kan fà sẹyin, ti ibanujẹ tẹri ọkàn awọn miiran ba, ọkunrin ọlọrọ ara Arimatea kan mu anfaani ti o ṣí silẹ fun un lo lati ṣe ohun ti o wà ni ipa rè̩ lati ṣe. Ọkunrin yii, Josẹfu jẹ eniyan rere ati olootọ, ẹni ti o ni igbagbọ ti “on pẹlu nreti ijọba Ọlọrun” (Luku 23:50, 51). Josẹfu jẹ “ọmọ-ẹhin Jesu, ṣugbọn ni ikọkọ nitori ibẹru awọn Ju” (Johannu 19:38). Awọn Ju ti fi ohùn ṣọkan pe ẹnikẹni ti o ba jẹwọ Kristi, a o le e kuro ninu sinagọgu (Johannu 9:22). Ni igba iṣoro yii, Josẹfu fi ara rè̩ hàn pe ọkan ninu awọn ọmọ-ẹyin Kristi ni oun.

Ki o to to akoko yii, ki Jesu to kú, è̩rù ba Josẹfu tẹlẹtẹlẹ -- ni ikọkọ ni oun n tẹle Jesu. Nisisiyi, ni akoko iku Jesu, o ni igboya. Bi ẹni pe ko tilẹ rò nipa ipo rè̩ gẹgẹ bi ọkan ninu awọn igbimọ, tabi lai ro ohun ti abayọrisi ohun ti o fẹ ṣe yoo jẹ fun un, Josẹfu tọ Pilatu lọ pẹlu igboya (Marku 16:43) o si gba aṣẹ lati tọju oku Jesu. Josẹfu tọ ẹni ti o ni aṣẹ lati fi okú Jesu le e lọwọ lọ. Josẹfu ko gbiyanju lati ṣe e ni ikọkọ ki ẹnikẹni ma ba ri i, ṣugbọn o gba aṣẹ lọnà ti o tọ ti o si yẹ. Pilatu fi oku Jesu fun Josẹfu, nipa bayii o gba A kuro lọwọ awọn ọta, o si fi I le ọwọ awọn ọré̩.

Imurasilẹ

Nigbà ti a fi okú Jesu fun Josẹfu, o fi aṣọ ọgbọ ti o mọ we E. Omiran ninu awọn ọmọ-ẹyin Jesu – Nikodemu, ẹni ti o tọ Jesu lọ ni oru – ran Josẹfu lọwọ. Nikodemu mu adapọ ikunra wá lati fi kun ara Rè̩, gẹgẹ bi iṣe awọn Ju nigba isinku wọn (Johannu 19:39). Wọn ṣe eto ara Jesu fun sisin pẹlu ifẹ, itọju, ati ọkàn ti o ronu jinlẹ, gẹgẹ bi àye ti wà fun wọn to laarin akoko kukuru ti wọn ni. Josẹfu ni iboji titun kan, ti a gbẹ ninu okuta, eyi ti a ti pese silẹ fun Josẹfu tikara rè̩. A sọ fun wa pe awọn ọlọrọ nikan ni o le ni irú iboji bẹẹ -- ti a gbẹ ninu apata ti ẹnikẹni kò lo ri. Eyi pẹlu mu asọtẹlẹ nipa iku ati isinku Kristi ṣẹ: “O si ṣe iboji rè̩ pẹlu awọn enia buburu, ati pẹlu ọlọrọ ni ikú rè̩” (Isaiah 53:9).

Nikodemu mu ikunra olowo iyebiye wa, Josẹfu si yọọda iboji rè̩ fun Jesu. Eyi ko ha jẹ apẹẹrẹ rere fun wa – lati fi ohun kan fun Jesu? Boya a ti ṣe eto lati lo ayé wa fun ara wa ati fun èrè wa. S̩ugbọn aye wa jẹ eyi ti Jesu le lò. Boya a ti pinnu lati lo talenti wa fun igbadun ara wa. Jesu le lo wọn pẹlu. Bi a ti n kà nipa awọn ti o fi nnkan kan fun Jesu, ohun kan ko ha si ninu ọkàn wa ti o n fẹ lati fi ohun kan fun Jesu bẹẹ? Awa ha ṣetan bi ti Josẹfu lati fi ohun kan lelẹ fun Oluwa, eyi ti Jesu le lo ti O si n fẹ?

Isinku

A tẹ Jesu sinu iboji Josẹfu titun, a si yi okuta nla kan di ẹnu ọna rè̩. Awọn diẹ ninu awọn ọmọ-ẹyin Jesu wà ni tosi -- awọn obirin lati Galili (Luku 23:55) -- awọn ti o ri ibi ti a tẹ Jesu si. Bayii ni a sinku Jesu bi ẹni pe awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ rò pe ninu iboji naa ni yoo wà titi. Ara awọn ti o ti kú a maa gbe inu iboji ni tootọ; ṣugbọn Ọmọ Ọlọrun ni Jesu I ṣe, Oun si ni agbara ajinde. Jesu ti sọ tẹlẹ pe Oun yoo ji dide ni ọjọ kẹta (Matteu 16:21). Jesu ni agbara lori iku ati iboji.

O dabi ẹni pe awọn ọmọ-ẹyin Jesu gbagbe ẹkọ Rè̩. Awọn miiran ranti pe O ti wi pe Oun yoo ji dide lati inu iboji. Awọn olori alufa ati awọn Farisi tọ Pilatu lọ lati beere pe ki o ṣe iboji naa dajudaju ki awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ ma ba wa ji okú Rè̩ gbe, ki wọn si wi pe O jinde (Matteu 27:63). Pilatu fun wọn ni aṣẹ lati ṣe iboji Jesu daju ni gbogbo ọna ti wọn ba fẹ.

Awọn olori alufa ati awọn Farisi fi edidi di okuta ti o wà ni ẹnu iboji naa. A fi awọn ọmọ-ogun sibẹ lati maa ṣọ ọ. Wọn ṣe gbogbo eyi ti o wà ni ipa wọn lati mu ki Jesu wà ninu iboji naa sibẹ, ṣugbọn wọn kunà. “Kò si ọgbọn, kò si imoye, tabi igbimọ si OLUWA” (Owe 21:30).

Ni Ọjọ Kẹta

Ni kutukutu owurọ ọjọ kẹta ti a sin Jesu, awọn obirin ti i ṣe ọmọ-ẹyin Jesu mu ọna pọn ni afẹmọjumọ lọ si ọgba naa, nibi ti a gbe sin Jesu si (Johannu 19:41, 42). Bi wọn ti n lọ, wọn bẹrẹ si rò bi wọn yoo ti ṣe le yi okuta ti o wà ni ẹnu iboji naa kuro (Marku 16:3). Nigbà ti wọn de iboji naa bi ilẹ ti n mọ bọ, wọn ri i pe a ti yi okuta naa kuro. O yà wọn lẹnu, wọn si ti daamu lai nidi. Wo o, ni igba pupọ bi a ti maa n banujẹ lori ohun ti ko tilẹ ṣẹlẹ rara? A ba jẹ le kọgbọn lati fi ayé wa le Ọlọrun lọwọ, ki a si gbẹkẹle E dipo ki a maa banujẹ ki a si maa daamu nipa ọjọ ọla!

Angẹli Kan

Ta ni ẹni ti o yi okuta kuro ni ẹnu iboji naa? Isẹlẹ kan sè̩, angẹli kan lati Ọrun si yi okuta nla naa kuro. Ifarahan angẹli naa mu ki è̩rù ba awọn ọmọ-ogun. Aṣọ angẹli naa n dan, o si funfun bi sno. Oju angẹli naa n dan bi manamana. Awọn ọmọ-ogun ti wọn n ṣọ iṣọ naa wariri, wọn si dabi okú.

Angẹli naa sọrọ imulọkanle fun awọn obirin naa, o si wi fun wọn pe, ki wọn ma ṣe bẹrù. O pe awọn obirin naa lati wa wo inu iboji naa nibi ti a ti tẹ Jesu si. Wọn ko ri okú Jesu ninu aṣọ ọgbọ ti a fi di I gẹgẹ bi wọn ti n reti. Jesu ko si nibè̩; O ti jinde, gẹgẹ bi angẹli nì ti wi, aṣọ isinku si wa ninu iboji (Johannu 20:5).

È̩rù ati Ayọ

Bi awọn obirin wọnyi ti n lọ lati sọ fun awọn ọmọ-ẹyin iyoku, è̩rù ati ayọ ni o dapọ ninu ọkan wọn. Wọn ni è̩rù nitori pe agbara Jesu ya wọn lẹnu rekọja, nitori pe o tobi rekọja oye wọn. Wọn ni ayọ nitori pe wọn o ri Jesu, kò tun jẹ okú mọ. Bi awọn obirin wọnyi ti n sure lọ mu iroyin ayọ yii lọ fun awọn ọmọ-ẹyin iyoku, Jesu tikara Rè̩ pade wọn. O wi pe “Alafia.” Awọn obirin naa wolẹ lẹsẹ Rè̩, wọn si tẹriba fun Un. Jesu sọ pe ki wọn lọ sọ fun awọn iyoku pe Oun yoo pade wọn ni Galili.

Abẹtẹlẹ ati Eke

Ninu awọn ọmọ-ogun ti a yàn lati ṣọ iboji Jesu lọ royin ohun ti o ṣẹlẹ fun awọn alaṣẹ. Awọn olori alufa ṣe ipade kan pẹlu awọn agbagbà. Wọn pinnu lati fi otitọ naa pamọ fun awọn eniyan. Wọn ki yoo jẹwọ pe Jesu jinde kuro ninu oku. Wọn fun awọn ọmọ-ogun ni owo pupọ lati purọ. Awọn ọmọ-ogun wọnyii fi ẹmi wọn wewu iku ti i ṣe ijiya fun sisun lẹnu iṣẹ. Wọn gba owo yii, wọn si wi pe nigba ti awọn sùn ni awọn ọmọ¬-ẹyin Jesu wa ji oku Rè̩ gbe lọ. Itan ti wọn sọ yii mu eniyan lọkan to bẹẹ ti o fi tàn kalẹ laarin awọn Ju.

Itumọ Ajinde Jesu

Ajinde Jesu lati isa-oku jẹ ohun pataki fun gbogbo Onigbagbọ. Eyi yi fi hàn pe Olugbala ti o wà laayè ni a n sin, Ẹni ti a ti fi gbogbo agbara fun – gbogbo agbara ni Ọrun ati gbogbo agbara ni ayé. O ṣe pataki fun Jesu lati fi ẹmi Rè̩ lelẹ fun è̩ṣẹ wa. Bẹẹ gẹgẹ ni o si ṣe pataki fun Jesu lati jinde kuro ninu okú ki a ba le da wa lare (Romu 4:25). Ajinde Jesu si tun jẹ è̩jé̩ ati apẹẹrẹ (ileri ati apẹẹrẹ) ti ajinde awọn oku ninu Kristi nigba ti ipè Ọlọrun ba dun. Awọn ti o wà laayè ti wọn si ti mura silẹ lati pade Jesu “li a ó si gbà. . . soke pẹlu wọn sinu awọsanma, lati pade Oluwa li oju ọrun: bḝli awa ó si ma wà titi lai lọdọ Oluwa” (I Tessalonika 4:17)

Pipade Jesu

Bi o tilẹ jẹ pe awọn miiran kò fara mọ, tabi gbagbọ pe Jesu jinde kuro ninu oku, ọgọọrọ awọn ẹlẹri ni o fi oju wọn ri I. Awọn ọmọ-ẹyin mọkanla lọ si Galili, Jesu si pade wọn gẹgẹ bi O ti wi. Jesu ba awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ sọrọ, wọn si wolẹ sin Jesu Olugbala wọn ti o jinde.

Jesu rin lọ ni ọna Emmausi pẹlu meji ninu awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ (Luku 24:13-15). Ni akọkọ, wọn ko mọ pe Jesu ni, ṣugbọn ifarahàn Rè̩ mu ki ọkàn wọn gbina ninu wọn bi O ti n fi oye Iwe Mimọ ye wọn; nigba ti wọn si mọ pe Oun ni, O nù mọ wọn loju (Luku 24:31, 32). Jesu fara hàn fun awọn miiran pẹlu. Bi ẹẹdẹgbẹta (500) ọmọ-ẹyin ni o ri Jesu ni igba kan (I Kọrinti 15:6).

Awọn Oniyemeji

Awọn miiran ninu awọn ọmọ-ẹyin Jesu kò gbagbọ pe ni tootọ ni O ti jinde kuro ninu oku, ati pe O wa laayè. Wọn gbọ gbogbo iroyin awọn iyokù, sibẹ wọn n fẹ ri I tikara wọn. Tọmasi ko si nibẹ ni igbà kin-in-ni ti Jesu fara han fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩. Bẹẹ gẹgẹ ni o maa n ri nigba ti eniyan ba fà sẹyin kuro ninu ipade Ihinrere kan, nigba ti ayè wa fun un lati lọ, ẹni naa yoo padanu ohun pataki kan. Tomasi padanu riri Jesu. Tọmasi wi pe: “Bikoṣepe mo ba ri àpá iṣó li ọwọ rè̩, ki emi ki o si fi ika mi si àpá iṣó na, ki emi ki o si fi ọwọ mi si iha rè̩, emi ki yio gbagbọ” (Johannu 20:25).

Nigba ti Jesu tun wá, Tọmasi wà nibẹ. Jesu naa wà nibẹ. Nigba ti Tọmasi ri Jesu, ko tun ṣẹṣẹ to pe ki o fi ọwọ rè̩ si àpa iṣo naa. Nigba ti Tomasi ri Kristi, o gbagbọ. Jesu wipe, “Tọmasi, nitoriti iwọ ri mi ni iwọ ṣe gbagbọ: alabukun-fun li awọn ti kò ri, ti wọn si gbagbọ.”

Imọ nipa Iriri

Ọpọlọpọ ni awọn Onigbagbọ ti wọn ko ri Kristi, sibẹ ti wọn mọ pe O wa laayè. Jobu paapaa sọ pẹlu idaniloju, nigba ti o wi pe: “Emi mọ pe oludande mi mbẹ li āye.”

Awọn ọmọ-ẹyin Jesu loni ko i ti ri Jesu, ṣugbọn ninu ọkàn wọn, wọn mọ pe O wa laayè. Irin-ajo Onigbagbọ jẹ nipa igbagbọ, ki i ṣe nipa riri (II Kọrinti 5:7). Bawo ni a ti ṣe mọ nigba naa pe, Jesu wa laayè? O jù igbagbọ lọ. O jù ireti lọ. Iriri igbala ti eniyan ni ninu ọkàn rè̩ ni o n fun ni ni idaniloju ti Olugbala ti o wà laayè.

“O mbẹ, O mbẹ lati fi igbala fun ni!

O mbere bi mo ṣe mọ pe O mbẹ?

O NGBE NINU ọKA

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni ṣe ti a kàn Kristi mọ agbelebu?
  2. Ki ni ṣe ti Jesu lọ si Jerusalẹmu nigba ti O mọ pe awọn eniyan naa ti pinnu lati pa Oun?
  3. Ta ni sinku Jesu?
  4. Nibo ni a sin Jesu si?
  5. Bawo ni a ti ṣe mọ pe Jesu kú ni tootọ?
  6. Ọjọ melo ni Jesu lo ninu iboji?
  7. Ki ni ohun ti o ṣẹlẹ si okuta ti o wà ni ẹnu ọna iboji?
  8. Ki ni ṣe ti Jesu jinde kuro ninu oku?
  9. Ki ni ṣe ti o jẹ ohun pataki fun wa lati gba ajinde Jesu gbọ?
  10. Bawo ni a ti ṣe mọ pe Jesu jinde kuro ninu oku?