Matteu 23:1-39

Lesson 222 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Ẹnikan ni Olukọ nyin, ani Kristi; ará si ni gbogbo nyin” (Matteu 23:8).
Cross References

I Isin awọn Farisi

1 Awọn Farisi a maa kede ofin Mose, ṣugbọn wọn ki i ṣe ohun ti wọn n waasu rè̩, Matteu 23:1-4; 21:28, 30; Luku 6:46; Titu 1:16

2 Awọn Farisi n ṣe iṣẹ wọn ki awọn eniyan le ri wọn, Matteu 23:5-7; 6:2, 5, 16; Johannu 5:44

II Oluwa Kan S̩oṣo

1 Kristi nikan ṣoṣo ni Oluwa ni Ijọba Ọrun, Matteu 23:8, 10.

2 Ko si ẹni kan ti a gbọdọ kà si baba ijọ, nitori Ọlọrun ni Baba wa ti n bẹ ni Ọrun, Matteu 23:9; 1 Kọrinti 8:6; Efesu 4:6; Heberu 12:9

3 Ẹni ti o ba fẹ tobi ni Ijọba Ọrun ni lati jé̩ iranṣẹ gbogbo eniyan, Matteu 23:11, 12; 5:19; Luku 1:52

III Idalẹbi awọn Agabagebe

1 Iwa arekereke yoo mú ijiya nla bá awọn ti wọn n ṣe bé̩ è̩, Matteu 23:13-15; Marku 12:38-40; Iṣe Awọn Apọsteli 8:18-23

2 Jesu Oluwa bá ẹkọ èké wí, Matteu 23:16-22; 15:9;

1 Timoteu 6:3-5; Titu 1:10, 11; 2 Peteru 2:1

3 Idajọ, aanu ati igbagbọ jẹ ohun pataki niwaju Ọlọrun ti o ni lati fi idi mulẹ ninu Ijọ Rè̩, Matteu 23:23; Deuteronomi 10:12; Hosea 6:6; Mika 6:8; Marku 12:33

4 Isin otitọ ni lati duro lori ẹkọ Ọrọ Ọlọrun, Matteu 23:24-28; Romu 2:1; Jakọbu 3:10; 1 Johannu 2:4

5 Ododo-ara-ẹni jé̩ ami idibajẹ ọkàn eyi ti a o mú wá si imọlẹ nigba ti akoko bá tó, Matteu 23:29-36; Luku 11:39; 2 Kọrinti 10:12; Owe 30:12

IV Ipè Ikẹyin

1 Jesu fi ifẹ ati aniyan Rẹ hàn fun awọn eniyan ọlọkan lile ti n gbé ni Jerusalẹmu, Matteu 23:37

2 Jesu kuro lọdọ awọn eniyan buburu, ṣugbọn O ṣeleri lati pada bọ fun awọn eniyan ti yoo fi tayọtayọ gba A ni Oluwa wọn, Matteu 23:38, 39; Luku 12:40; 21:27; Johannu 14:3; Iṣe Awọn Apọsteli 1:11.

Notes
ALAYE

Iṣẹ-iranṣẹ Jesu ni aye yii ni lati ṣi ilẹkun Ijọba Ọrun silẹ. Iwaasu Rè̩ lati ibẹrẹ iṣẹ-iranṣẹ Rẹ titi de opin igbesi-ayé Rẹ ni lati fi ẹbun ọfẹ ti Ọlọrun fi fun araye hàn ati gbese ti O ni lati san ni Kalfari fun è̩ṣẹ. “O tọ awọn tirè̩ wá, awọn ará tirè̩ kò si gbà a. S̩ugbọn iye awọn ti o gbà a, awọn li o fi agbara fun lati di ọmọ Ọlọrun, ani awọn na ti o gbà orukọ rè̩ gbọ” (Johannu 1:11, 12). Awọn akọwe ati awọn Farisi wà lara awọn wọnni ti o kọ Ọmọ Ọlọrun.

Afaraṣe Kò Tó

Igba pupọ ni Jesu kilọ fun awọn ẹlẹsin wọnyii pé eto ofin atọwọdọwọ ati àṣà wọn kò le gbé wọn de Ọrun. Awọn akọwe ati Farisi ni agbara laaarin awọn eniyan, wọn si n bu ọlá fun wọn. Pẹlu ọwọ lile ni wọn fi n ṣakoso è̩sin ni Jerusalẹmu. Jesu mọ pe lati ri ojurere Ọlọrun tayọ iyin eniyan ati afarawe iwa-mimọ. O dabi ẹni pe awọn aṣiwaju ninu è̩sin wọnyii rò pé wọn le tan Ọlọrun ayeraye, Ẹni ti o mọ ọkàn ọmọ-eniyan jẹ, gẹgẹ bi wọn ti n tan eniyan jẹ. S̩ugbọn Ọrọ Ọlọrun wi pe, “Ki a máṣe tàn nyin jẹ; a kò le gàn Ọlọrun: nitori ohunkohun ti enia ba funrugbin, on ni yio si ká” (Galatia 6:7). Jesu fé̩ ọkàn awọn eniyan wọnyii sibẹ, idi rè̩ ti O fi n sọ ọrọ lile ti O si n tọka si iwa è̩ṣẹ wọn nigba gbogbo ni pe ki wọn le ri aṣiṣe wọn ki wọn si le wá si imọ otitọ.

Idi miiran ti Jesu ṣe fi gbogbo ọkàn bá awọn akọwe ati Farisi wi ni pe ki awọn ẹlomiran le ri ikuna wọn ki wọn ma ba ṣe aṣiṣe kan naa. Jesu wi fun awọn eniyan pe, “Nitori mo wi fun nyin, bikoṣepe ododo nyin ba kọja ododo awọn akọwe ati ti awọn Farisi, ẹnyin kì yio le de ilẹ-ọba ọrun bi o ti wù ki o ri” (Matteu 5:20). Jesu mọ agbara ati aṣẹ ti awọn akọwe ati Farisi ni lori awọn eniyan, nitori naa O fi abuku ti o wà ninu ẹkọ wọn hàn kedere pe, ọna wọn ki i ṣe ọna tootọ si Ijọba Ọrun. Ọmọ Ọlọrun mọ pe awọn Ju ni yoo pa Oun, ṣugbọn kò bẹru lati sọ otitọ, ohunkohun ti o wu ki o dé. Ihinrere Kristi i ba fẹsẹ mulẹ ju bi o ti ri lonii yií lọ bi awọn ọmọlẹyin Kristi ba ni igboya bi ti Oluwa wọn. Paulu sọ fun wa pe, “Ẹ ni ero yi ninu nyin, eyi ti o ti wà pẹlu ninu Kristi Jesu: ẹniti ..... o rè̩ ara rè̩ silẹ, o si tẹriba titi di oju ikú” (Filippi 2:5-8).

Kò Si Igbagbọ

Ki i ṣe pe awọn eniyan wọnyii kò mọ ọna otitọ, nitori Jesu sọ fun ọpọ eniyan ati awọn ọmọ-ẹyin Rẹ pe awọn akọwe ati Farisi jokoo ni ipo Mose. Itumọ eyi ni pe awọn ni ẹni ti o kẹkọọ nipa Ofin Mose ti wọn si n kede rè̩ laaarin agbo awọn ẹlẹsin. Bawo ni i ba ti dùn to bi awọn eniyan wọnyii ba gbagbọ ki wọn si maa ṣe ohun ti wọn fi n kọ awọn eniyan. “Nitoripe ẹnyin iba gbà Mose gbọ, ẹnyin iba gbà mi gbọ: nitori o kọ iwe nipa ti emi. S̩ugbọn bi ẹnyin kò ba gbà iwe rè̩ gbọ, ẹnyin o ti ṣe gbà ọrọ mi gbọ?” (Johannu 5:46, 47). Koko ohun ti o n dà wọn laamu ni pe wọn kò gba gbogbo Ọrọ Ọlọrun gbọ pẹlu gbogbo ọkàn wọn, bẹẹ ni wọn kò fi ẹkọ ti wọn n fẹnu jé̩wọ ṣe iwa hù. Wọn n fẹ ki awọn ẹlomiran pa gbogbo Ofin mọ kinnikinni, nigba ti wọn fi aṣa ati ofin atọwọdọwọ dipo rè̩, nipa bayii wọn lero lati yẹ eyi ti o tobi ju ninu ofin silẹ. Jesu wi pe “Wọnyi li o tọ ti ẹnyin iba ṣe, ẹnyin kì ba si fi wọnni silẹ laiṣe.”

Ẹni ti o ṣe alairiwi ju lọ niwaju Ọlọrun ni ẹni naa ti o n tọka si è̩ṣẹ ti o wà ni igbesi-aye awọn ẹlomiran ṣugbọn ti oun paapaa kò bọ lọwọ è̩ṣẹ ti ó wà ni igbesi-ayé ti rè̩. “Ati iwọ ọkọnrin na ti nṣe idajọ awọn ti nṣe irú ohun bawọnni, ti iwọ si nṣe bḝ na, iwọ ro eyi pe iwọ ó yọ ninu idajọ Ọlọrun?” (Romu 2:3). Ohun kin-in-ni ti Jesu sọ fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ nipasẹ eyi ti awọn akọwe ati Farisi jẹ ẹlẹbi ni pe wọn n sọ ohun ti o yẹ ki awọn eniyan ṣe fun wọn, ṣugbọn awọn tikara wọn kò ṣe e. Iru è̩sin awọn Farisi wọpọ ninu aye ode-oni sibẹ.

Imọ Tootọ

Aṣiṣe keji ti Jesu fi hàn ni pe awọn Farisi ati akọwe n ṣe iṣẹ wọn ki awọn eniyan ba le ri wọn. Imọ tootọ nipa Ihinrere kọ wa lati ṣe ohun gbogbo bi ẹni pe fun Ọlọrun. “Ohunkohun ti ẹnyin ba nṣe, ẹ mā fi tọkàntọkàn ṣe e, gẹgẹ bi fun Oluwa, ki si iṣe fun enia; ki ẹ mọ pe lọwọ Oluwa li ẹnyin ó gbà ère ogun: nitori ẹnyin nsìn Oluwa Kristi” (Kolosse 3:23, 24). Awọn akọwe ati Farisi fẹran iyin eniyan wọn ko si bikita to bẹẹ fun iyin Ọlọrun. Opin ti wọn n lepa lodi si eyi ti o yẹ ki wọn lepa. Bi o ba ṣe pe wọn ti naani iyin Ọlọrun ni, wọn kò ni naani iyin eniyan. Igba ayé kuru lọpọlọpọ. Ọna ti o tọ lati lo igbesi-aye wa ni lati gbe ogo Ọlọrun ga ati lati kede ifẹ Rè̩ fun awọn ọmọ-eniyan, nipa bẹẹ ki a le jere ọpọ ọkàn fun Ijọba Ọrun.

Ẹṣẹ Igberaga

Olori ẹṣẹ ti o wà ni igbesi-aye awọn akọwe ati Farisi ni igberaga. Wọn fẹ ipo ọla ni ibi ase ati ipo giga ninu sinagọgu; wọn fẹ ikini ni ọja ati ọla ti awọn eniyan n bù fun wọn. Ki i ṣe ẹṣẹ lati wà ni ipo giga tabi ki a dá ni lọla, ṣugbọn ohun ti o jẹ ẹṣẹ gan an ni lati ni ifẹ fun iru nnkan bawọnni, fifi iwọra wá a, ati gbigberaga nigba ti ọwọ ba ti tè̩ wọn tan. Si ibanujẹ wọn, awọn akọwe ati Farisi ri i gbangba pe otitọ ni Ọrọ Ọlọrun. “Nitori ọjọ OLUWA awọn ọmọ-ogun yio wà lori olukuluku ẹniti o rera, ti o si gberaga, ati lori olukuluku ẹniti a gbe soke, on li a o si rè̩ silẹ” (Isaiah 2:12). Igberaga, ti o ti kó awọn eniyan wọnyii ti o kà ara wọn si olododo lẹru, ni o tì wọn si iparun ati iyapa kuro lọdọ Ọlọrun titi laelae. Bi igberaga ti n ṣeku pani ni ọjọ oni, bakan naa ni o ri nigba ti Jesu wa ni ayé. A le ri i ni igbesi-aye awọn eniyan kaakiri, a si le ri i ni ile Ọlọrun nigba miiran pẹlu. Nigba ti eniyan ba lọ si ile Ọlọrun lati fi ara rè̩, ẹri rè̩, tabi ipo rè̩ han, o daju pe ibinu Ọlọrun yoo wá sori iru ẹni bẹẹ.

Awọn miiran wà gẹgẹ bi awọn Farisi, ti o fẹ orukọ giga; ṣugbọn Jesu fi aṣilo awọn ipo ọla bawọnni hàn. Ọlọrun ni Baba wa, Kristi si ni Oluwa wa. Jesu kò wi pe ki a má fi ọlá, ìfé̩ ati ọwọ fun awọn wọnni ti o n ṣe olori wa ninu Ihinrere ṣugbọn O n fẹ ki awọn eniyan ranti pe Ọlọrun ni Olupilẹṣẹ ati Alaṣepe igbala wa. Ipa kan ṣoṣo ti eniyan ni lati sà nipa igbala ni lati gbagbọ, lati ní in ati lati kede anfaani ayeraye ti o wà ninu rè̩ fun awọn ẹlomiran. Awọn ọmọ-ẹyin Jesu jẹ iranṣẹ, ẹnikẹni ti o ba si fẹ ṣe olori ninu wọn ni lati jẹ olori ninu awọn ti o n ṣe iranṣẹ. Awọn ojiṣẹ Ọlọrun pataki ninu Ihinrere lọjọ oni ni awọn wọnni ti wọn ṣe ìránṣé̩ jù lọ. Ẹnikẹni ti o ba n ṣe iranṣẹ lati inu ọkàn rè̩ wa ti fọ itẹgun igberaga.

Titako Agabagebe

Igba mẹjọ ni Jesu fi awọn akọwe ati Farisi ré ninu ori iwe ti a yàn fun ẹkọ wa yii, nitori wọn ko fẹ rin ninu imọlẹ ti Jesu mu wa si aye ati pe wọn jẹ agabagebe. Eyi ki i ṣe igba kin-in-ni ti Jesu tako ẹṣẹ yii ṣugbọn nihin yii O n tẹnu mọ ọn gidigidi nitori awọn eniyan wọnyii ko naani ikilọ Rẹ iṣaaju. Ọlọrun Baba tabi Ọlọrun Ọmọ ki i fi ibawi ṣiwaju ọrọ ti O n ba awọn eniyan sọ nigba ti O ba kọ n ba wọn sọrọ. Wọn a maa sọrọ pẹlu ifẹ ati aanu – “Wá nisisiyi, ki ẹ si jẹ ki a sọ asọyé pọ.”

Jesu ti ba awọn eniyan wọnyii sọ asọye nigba pupọ, ṣugbọn nisisiyii, O n dagbere fun wọn, O si n fẹ ki wọn mọ iduro wọn niwaju Ọlọrun. Otitọ yoo sọ gbogbo eniyan di ominira, bí wọn ba gbọ ti Rẹ. Nigba ti a ba waasu Otitọ ni kikun lọna to yé ni, awọn eniyan ni lati jihin fun Ọlọrun, iru iha ti wọn kọ si Otitọ naa. A le wi, lẹẹkan sii pe, Jesu di idà Otitọ mu ni ireti ati tú aṣiiri è̩ṣẹ ni igbesi-aye awọn alafẹnujẹ ẹlẹsin wọnyii, lati mu iyipada wọ inu igbesi-aye wọn. Iru iwuwo kan naa ni o n wa lọkan awọn ojiṣẹ Ọlọrun nipa awọn ti o wa labẹ iṣẹ iranṣẹ wọn, wọn a si maa ké mọ è̩ṣẹ pẹlu gbogbo ipá wọn. Awọn miiran ko fẹ iru awọn ojiṣẹ Ọlọrun bayii, ṣugbọn a ni lati kede Otitọ bi a ba fẹ ki awọn eniyan bọ kuro lọwọ è̩ṣẹ.

Ibukun Ti O Di Ègún

Jesu wa si ayé lati jẹ ibukun fun ọkàn ọmọ-eniyan; ṣugbọn bi O ba ni lati fi ọkàn kan ré, ẹjọ Rẹ jare. Bi Alagbawi Nla ba doju kọ ọkàn kan, ta ni oluwarẹ ti o le bẹbẹ fun iru ọkàn bẹ ẹ? Jesu sọ fun awọn eniyan wọnyii pe nipa agabagebe ati ṣiṣe aṣiwaju ni ọna eke, wọn n ti ilẹkun Ijọba Ọrun mọ awọn eniyan -- è̩sùn yii wuwo pupọ. Wọn jé̩ ọta abinuku Ihinrere Jesu Kristi, ti i ṣe ọna kan ṣoṣo si Ijọba Ọrun.

Ki i ṣe atako awọn eniyan nikan ni o n fa awọn ẹlomiran kuro ni Ijọba Ọrun. Agabagebe jẹ ohun ikọsẹ nlá nlà. Awọn eniyan n ṣọ awọn ti o n jẹwọ pe Onigbagbọ ni wọn i ṣe, bi wọn ba ri agabagebe kan, ọpọlọpọ a sọ igbagbọ nù. Gbogbo awọn ẹlẹsin ni wọn kà si ọkan naa, wọn si gbagbọ pe niwọn igba ti awọn kan ti kuna lati gbé igbesi-aye ti o bá Ọrọ Ọlọrun mu, ko ṣe e ṣe fun ẹnikẹni lati le ṣe e. Nipa bayii ni agabagebe n ti ilẹkun Ijọba Ọrun mọ awọn ti n ṣọ igbesi-aye rè̩.

Lọna miiran ẹwẹ, a n ri imọlẹ Ihinrere ti n tàn lati ọdọ ẹni ti n gbe igbesi-aye ti o wà fun Ọlọrun patapata. Ayọ ati inu-didun ti o n tàn jade lati ọdọ Onigbagbọ tootọ jé̩ ẹri ti o to lati fi han pe ọna si Ijọba Ọrun ṣi silẹ fun “ẹnikẹni ti o ba fẹ.”

Idagbere Oluwa

Jesu mọ pe eti didi ni awọn akọwe ati Farisi kọ si ọrọ Rè̩. Lai pẹ, wọn yoo kan Ọmọ Ọlọrun mọ igi, ṣugbọn O fẹ ki gbogbo awọn ara Jerusalẹmu mọ pe titi de opin ni Oun n wá alaafia wọn. Oun i bá kó awọn Ju ọlọkan lile wọnyii mọra, ani titi de wakati ikẹyin yii, ṣugbọn wọn ko fẹ feti si ipe ikẹyin Rẹ. Ọlọrun kun fun ipamọra lọpọlọpọ ṣugbọn bi a ba n gan aanu Rẹ leralera, Oun yoo fa ọwọ aanu naa sẹyin nikẹyin. Jesu sọ fun awọn eniyan wọnyii pe wọn ko mọ akoko ibẹwo wọn; nitori naa a fi ile wọn silẹ fun wọn ni ahoro. A kọ Tẹmpili wọn nibi ti wọn gbe n ṣe fọri-fọri ati aṣa atọwọdọwọ silẹ; Tẹmpili ti wọn ti sọ di ile ọja tita ati iho ole.

Nigba ti Ọmọ Ọlọrun fi Tẹmpili ati ilu Jerusalẹmu silẹ, ogo Ọlọrun jade pẹlu Rẹ. Niwọn ọdun diẹ si i, iparun yoo dé ba ilu ati Tẹmpili naa. Awọn eniyan wọnyii ni wọn fa ibanujẹ yii wá sori ara wọn nitori wọn kọ Jesu, Olugbala. Kikọ Ọmọ Ọlọrun lonii yoo fa idajọ wá sori ọkàn olukuluku eniyan. Sibẹ, ireti imọlẹ didan kan tàn lati inu okunkun biribiri jade wá. Jesu ṣeleri lati pada wa mú awọn wọnni ti n wọna fun bibọ Rè̩ ati lati pade Rè̩. Awọn eniyan diẹ, paapaa ni Jerusalẹmu, ti gba Jesu Oluwa. Oluwa ki yoo fi wọn silẹ lai ni itunu – Oun yoo pada wa mu wọn. Ireti aaye ti Ijọ tootọ ni eyii, o si ti jẹ ireti awọn Onigbagbọ lati ayebaye. Jesu n pada bọ! Bawo ni ireti iyanu yii ti dara to!

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Sọ ọkan ninu ohun pataki ti Jesu ri wi si ẹsin awọn akọwe ati Farisi.
  2. Erè wo ni awọn akọwe ati Farisi ni lọkan nigba ti wọn ba n ṣiṣẹ isin wọn?
  3. Iru ipo wo ni ọkàn wa ni lati wà ki a to le ṣiṣẹ ti o jẹ itẹwọgba lọdọ Ọlọrun?
  4. Bawo ni eniyan ṣe le di nla ni Ijọba Ọrun gẹgẹ bi itọni Jesu?
  5. Sọ ohun kin-in-ni ti agabagebe awọn akọwe ati Farisi yọri si.
  6. Igba meloo ni Jesu kígbe mọ ìwà agabagebe ninu ori iwe yii?
  7. Oju wo ni Ọlọrun fi n wo ìwà agabagebe lọjọ oni?
  8. Kí ni ere ti lile aya awọn Ju mú bá orilẹ-ede wọn?
  9. Ireti nla wo ni Jesu fi silẹ fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩?
  10. Njẹ ireti yii jamọ nnkankan fun ayé lode oni?