Johannu 12:37-50

Lesson 223 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Iye ainipẹkun na si li eyi, ki nwọn ki o le mọ ọ, iwọ nikan Ọlọrun otitọ, ati Jesu Kristi, ẹniti iwọ rán” (Johannu 17:3).
Cross References

I Aigbagbọ Israẹli

1 Kikọ Jesu Kristi lati ọdọ awọn Ju, gẹgẹ bi Ọmọ Ọlọrun ati Arole Rè̩ jé̩ imuṣẹ asọtẹlẹ atayebaye, Johannu 12:37-41; Isaiah 6:9, 10; 53:1; Jeremiah 5:2-22; Esekiẹli 12:2; Matteu 13:10-17; Luku 8:10; Iṣe Awọn Apọsteli 28:24-27

2 Ibẹru eniyan ati ibẹru ijiya kò jẹ ki ọpọlọpọ jẹwọ igbagbọ wọn ninu Kristi, Johannu 12:42; 7:13; 9:22

3 Ogunlọgọ kò fẹ kọ iyin eniyan silẹ lati gba iyin ti Ọlọrun, Johannu 12:43; 5:44; 1 Samuẹli 2:30; Marku 8:38; Luku 12:8, 9

II Iranṣẹ Ọlọrun

1 Jesu wi pe, “Ẹniti o ba gbà mi gbọ, emi kọ li o gbàgbọ, ṣugbọn ẹniti o rán mi,” Johannu 12:44; Marku 9:37; 1 Peteru 1:21

2 Jesu tun sọ pe, “Ẹniti o ba si ri mi, o ri ẹniti o rán mi,” Johannu 12:45; 14:9; Kolosse 1:15; Heberu 1:3

3 Jesu wá lati jé̩ imọlẹ fun ayé, Johannu 12:46, 35, 36; 9:5, 39; Efesu 5:14; Isaiah 9:2

III Idajọ nipa Ọrọ Ọlọrun

1 Iṣẹ-iranṣẹ ti Jesu Kristi wá ṣe ni lati gba araye là, ki i ṣe lati dá wọn lẹjọ, Johannu 12:47; 3:17; 5:45; 8:15, 16; 10:10; 18:37

2 A o dá awọn eniyan lẹjọ nipa Ọrọ Ọlọrun gẹgẹ bi igbọran wọn si awọn ẹkọ rè̩, Johannu 12:48; Deuteronomi 18:18, 19; Marku 16:16; Luku 10:16; 1 Tẹssalonika 2:8

3 Jesu kò sọrọ nipa ti ara Rè̩ bi kò ṣe ohun ti Baba ti palaṣẹ fun Un, Johannu 12:48-50; 8:38-59; 14:10; 17:8, 14, 22-26

4 Ofin Ọlọrun nipasẹ Jesu Kristi jẹ iye ainipẹkun, Johannu 12:50; 17:2

Notes
ALAYE

Aigbagbọ Israẹli

Bibeli sọ nipa ohun ijinlẹ è̩ṣẹ (2 Tẹssalonika 2:7) – ohun ijinlẹ si ni ní tootọ. O si jẹ ohun ti o ya ni lẹnu lati ri i kà bi Israẹli ti kọ Jesu Kristi ti wọn si pe E ni ẹlè̩tàn ati eleke.

O ya ni lẹnu pe Israẹli le kọ Kristi ki wọn si tun takú sinu aigbàgbọ pẹlu, paapaa ju lọ nigba ti a ba wo gbogbo awọn àmi ti Jesu fi hàn, pe Oun ni Ẹni náà ti a rán lati ọdọ Ọlọrun wá. O n sọrọ taṣẹtaṣẹ nipa awọn ohun ti ọrun; ọgbọn ti Kristi fi ko awọn ọta Rè̩ loju daamu wọn titi wọn kò fi le beere ohunkohun mọ lọwọ Rè̩. (Wo Matteu 13:54; 22:46; Marku 1:22, 27; Heberu 1:2; 11:3). Jesu sọrọ pẹlu agbara to bẹẹ ti awọn olufisun ti o wá lati mu Un ati lati kan An mọ agbelebu ṣubu lulẹ nigba ti O sọrọ kan pere (Johannu 18:6).

Awọn nnkan wọnyii nikan tó lati mu ki Israẹli jẹ alairiwi niwaju Ọlọrun, ṣugbọn Jesu tun ṣiṣé̩ iyanu ti ẹni kan kò le ṣe afi Ọlọrun. Eyi mu ki Israẹli di ajigbese fun awọn nnkan wọnni ti wọn n ri ti wọn si n gbọ. Ẹwẹ, pẹlu gbogbo iṣẹ iyanu nla wọnyii, wọn tun gboju-gboya lati pe Jesu ni ẹlẹmi eṣu ti o ni idapọ pẹlu Eṣu (Matteu 12:22-30; Johannu 8:48-59).

Títú Aṣiiri È̩ṣẹ

Atako nla ti wọn gbé dide si Jesu ati ẹkọ Rè̩ fi hàn pe eṣu n jọba ninu ọkàn awọn eniyan náà. Igba aimọ awọn orilẹ-ede Keferi ni Ọlọrun ti gboju fò da, ṣugbọn nisisiyii akoko dé ti Ọlọrun yoo tú aṣiiri è̩ṣẹ, Israẹli ni a si kọ pè lati ṣe iṣiro iṣẹ wọn (Wo Iṣe Awọn Apọsteli 17:30). Eyi tọ bé̩è̩, nitori Israẹli ni a fi Ọrọ iye, ogo, majẹmu, fifun ni ní ofin, iṣẹ-isin Ọlọrun, ati irubọ lé lọwọ (Romu 9:4, 5; Iṣe Awọn Apọsteli 17:29-31).

Isaiah sọ asọtẹlẹ pe imọ Kristi n bọ wa: “Awọn enia ti nrin li okùnkun ri imọlẹ nla: awọn ti ngbe ilẹ ojiji ikú, lara wọn ni imọlẹ mọ si” (Isaiah 9:2). Itanṣan imọlẹ náà bẹrẹ si tàn diẹdiẹ ni iran Israẹli lati igba Abrahamu olóòótọ; imọlẹ náà si n tàn siwaju ati siwaju gẹgẹ bi ọdun ti n yi lu ọdun. Lati ọdọ awọn alufaa, awọn wolii, awọn onidajọ, awọn ọba, ati awọn ẹni iwa-bi-Ọlọrun lọkunrin ati lobinrin ni a ti kede ihin irapada ati ìwáyé Ọba ti o n bọ wa, fun awọn Heberu ọlọrùn lile ati alagidi. Nisisiyii O wà laaarin wọn. Ẹni ti a kede Rè̩ gẹgẹ bi “Ọba awọn Ju” wá sọdọ awọn ti Rè̩, awọn ti Rè̩ ko si gba A.

Jesu sọ nipa awọn eniyan wọnyii “Ibaṣepe emi kò ti wá ki ng si ti ba wọn sọrọ, nwọn kì ba ti li è̩ṣẹ: ṣugbọn nisisiyi nwọn di alairiwi fun è̩ṣẹ wọn. Ẹniti o ba korira mi, o korira Baba mi pẹlu. Ibaṣepe emi kò ti ṣe iṣẹ wọnni larin wọn, ti ẹlomiran kò ṣe ri, nwọn kì ba ti li è̩ṣẹ: ṣugbọn nisisiyi nwọn ti ri, nwọn si korira ati emi ati Baba mi” (Johannu 15:22-24). Jesu tun sọ bayii pe, “Eyi ni idajọ na pe, imọlẹ wá si aiye, awọn enia si fẹ òkunkun jù imọlẹ lọ, nitoriti iṣẹ wọn buru” (Johannu 3:19).

Ibawi nipa Asọtẹlẹ

Nipa imisi Ọlọrun, oju Isaiah riran tayọ ọdun wọnni ti o wà laaarin akoko rẹ de igba ti Messiah yoo wa si aye (Isaiah 6:9, 10). Johannu Apọsteli ṣe atunwi ọrọ Isaiah pe “O ti fọ wọn loju, o si ti se àiya wọn le; ki nwọn má ba fi oju wọn ri, ki nwọn má ba fi ọkàn wọn mọ, ki nwọn má ba yipada, ki emi má ba mu wọn larada” (Johannu 12:40).

Ki i ṣe ifẹ Ọlọrun lati mu ki òye Israẹli ki o ṣokunkun ki wọn má ba le gba otitọ irapada gbọ. Iṣọtẹ wọn si ofin Ọlọrun fun ọpọlọpọ ọdun fọ wọn loju si ohun ti i ṣe ti ẹmi to bẹẹ ti òye imọlẹ otitọ Ọlọrun ti o fara han nipasẹ Jesu Kristi kò fi ye wọn; wọn si yan eke Satani eyi ti o fara han nipasẹ ẹkọ awọn Farisi ati awọn eke wolii. Fun ọdun pupọ ni Israẹli ti feti si ẹkọ awọn wolii eke ti o n sọrọ “didundidun” fun wọn; nisisiyii wọn n sé̩ Oluwa ati Olugbala wọn. (Wo Isaiah 30:8-14). Gẹgẹ bi Esau, wọn gbé ogun ibi wọn tà nitori ipẹtẹ; gẹgẹ bi Judasi, wọn ta Olugbala wọn fun ere ayé yii.

Ikede Ọlọrun

Jesu sọ ni gbangba pe Oun ni Ọmọ Ọlọrun, eyii si pa awọn Ju lẹnu mọ lati maa pe E ni ọmọ gbẹnagbẹna. “Ẹniti o ba gbà mi gbọ, emi kọ li o gbàgbọ, ṣugbọn ẹniti o rán mi.” Lati gba Kristi gbọ ni lati gba otitọ ti Ọlọrun Baba rán Jesu lati wá kede rè̩ gbọ. Ẹni ti o ba sé̩ Jesu, o sé̩ Ọlọrun Baba. Awọn Ju gbagbọ tọkantọkan pe Ọlọrun ni Baba wọn, ṣugbọn wọn kò gbagbọ lọna kan náà pe Ọmọ Ọlọrun ni Jesu i ṣe. Sibẹ, Jesu sọ fun wọn pe Oun ti ọdọ Ọlọrun wá, iṣẹ ti Oun jẹ fun wọn ti ọdọ Baba wá pẹlu. Awọn ẹsẹ Iwe Mimọ tun jẹri si i pe “Ẹniti o ba ti ri mi, o ti ri Baba” (Johannu 14:9). (Ka Heberu 1:3; ati Kolosse 1:15).

Ọrọ Ikilọ

Bi Jesu ti mọ pe awọn Ju yoo kọ Oun, O ṣe ìkìlọ fun wọn nipa iṣẹ ti Ọlọrun rán An si wọn. Ni ireti lati là wọn loju ati lati mú è̩tanú ọkàn wọn kuro, O lakaka lati jé̩ ki o di mímọ fun wọn pe ewu wà ninu kíkọ Ọrọ Rè̩, nitori Ọlọrun ni o ranṣẹ si ọmọ eniyan nipasẹ Rè̩: “Ẹniti o ba kọ mi, ti kò si gbà ọrọ mi, o ni ẹnikan ti nṣe idajọ rè̩: ọrọ ti mo ti sọ, on na ni yio ṣe idajọ rè̩ ni igbẹhin ọjọ.”

Ẹyin ọmọ-eniyan, ẹ ki yoo ha gba Kristi? Bi ẹ ba kọ Ọ, ẹ ki yoo ni ipin lọdọ Ọlọrun tabi igbala Ọlọrun; nitori Jesu wi pe “Kò si ẹnikẹni ti o le wá sọdọ Baba, bikoṣe nipasẹ mi” (Johannu 14:6). Bi iwọ ba kọ ọrọ Kristi, iwọ ti kẹyin si ohun kan ṣoṣo ti i ṣe ireti igbala rẹ ni ọjọ idajọ. Jesu wi pe, Oun kò wa lati dá araye lẹjọ bi ko ṣe lati gba araye là. Wiwa si aye Rè̩ mú ki awọn eniyan mọ ipò è̩ṣẹ wọn, wọn si di ẹlẹbi niwaju Ọlọrun, sibẹ didun inu Jesu ni lati sọ fun wọn pe nipasẹ Oun ni wọn ti le ri idariji è̩ṣẹ gbà. Kò si orukọ miiran ti a fi fun ni, tabi ti a o fi fun ni, nipa eyi ti a fi le gba eniyan là (Iṣe Awọn Apọsteli 4:11, 12).

Jẹ ki gbogbo eniyan nibi gbogbo bu ọlá fun Ọrọ Ọlọrun; nitori Bibeli, ti ọpọlọpọ n kẹgan ti wọn kò si kà si, ni a o fi ṣe idajọ wọn ni ọjọ ikẹyin, boya wọn o jogun iye ainipẹkun, tabi bẹẹ kọ. Fun awọn ti o n pa ilana rè̩ mọ, yoo jé̩ iye ainipẹkun. S̩ugbọn fun awọn ti o tako otitọ rè̩, yoo rán wọn lọ sinu òkunkun biribiri titi ayeraye.

È̩ṣẹ Aigbagbọ

Kikọ ti Israẹli kọ Kristi patapata yoo rán wọn, bi ẹni kọọkan, sinu adagun iná ayeraye. Iwe itan jẹri si ijiya ti o bá awọn Ju fun ipinnu ti wọn ṣe gẹgẹ bi orilẹ-ede nigba ti wọn kọ Kristi ti wọn si kigbe pe, “Ki ẹjẹ rè̩ wà li ori wa, ati li ori awọn ọmọ wa” (Matteu 27:25). Itan wọn kún fun itajẹsilẹ ati ibanujẹ kikoro, ọpọlọpọ inunibini ni wọn si ti fara gbá titi di ọjọ oni.

Onigbagbọ Abẹru

Awọn miiran wà ti wọn gba ihin igbala gbọ ṣugbọn ti wọn n bẹru èrò awọn eniyan, eyi kò si jẹ ki wọn le jẹwọ igbagbọ wọn ninu Kristi ni gbangba. Wọn fẹran iyin eniyan ju iyin Ọlọrun lọ. Sibẹ Ọrọ Ọlọrun ko ṣe alaileso nitori a kà nipa awọn ti o jade gbangba lati jẹwọ igbagbọ wọn ninu Kristi (Iṣe Awọn Apọsteli 6:7; Johannu 19:38, 39).

Yatọ si awọn abẹru wọnyii, awọn miiran wà ti o ṣe pe lati igba ti wọn ti gbọ ihin Kristi ni wọn kò ti tiju lati jẹwọ pe otitọ ni ohun ti Jesu sọ nipa ara Rè̩. Diẹ ninu awọn wọnyii ni awọn Apọsteli mejila, Maria iya Jesu, Maria Magdalene, Maria ati Marta arabinrin rè̩, Lasaru, ati awọn pupọ miiran. A mọ pé ọgọfa eniyan ni o pejọ pọ si iyara oke ni ọjọ Pẹntikọsti, awọn ti o wà ni inu kan ati ọkàn kan. Fun awọn eniyan bayii ni Oluwa wi pe, “Bi ẹnikẹni ba nsìn mi, on ni Baba yio bù ọlá fun” (Johannu 12:26) ati pẹlu “Nitorina ẹnikẹni ti o ba jẹwọ mi niwaju enia, on li emi o jẹwọ niwaju Baba mi ti mbẹ li ọrun. S̩ugbọn bi ẹnikan ba si sẹ mi niwaju enia, on na li emi o sẹ pẹlu niwaju Baba mi ti mbẹ li ọrun” (Matteu 10:32, 33).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Imọ wo ni awọn Ju ti ni tẹlẹ nipa Ọba ti o n bọ wá?
  2. Ta ni sọ asọtẹlẹ nipa aigbagbọ awọn Ju?
  3. Bawo ni awọn Wolii ṣe mọ pe awọn Ju yoo kọ Jesu nigba ti O ba wá si ayé?
  4. Njẹ Ọlọrun ni o fọ awọn eniyan wọnyii loju ki wọn ki o má ba mọ otitọ?
  5. Ki ni a o fi ṣe idajọ eniyan ni ọjọ idajọ?
  6. Njẹ Jesu dá ayé lẹjọ nipa wiwa Rè̩ si ayé? Fi Bibeli gbe idahun rẹ lẹsẹ.