Matteu 25:1-13 Orin Dafidi 45:1-17

Lesson 224 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Ẹniti o ba foritì i titi de opin, on na li a o gbalà” (Matteu 24:13).
Cross References

I Kristi fi Owe S̩e Apejuwe Ijọ Ọlọrun ni Ayé

1 Awọn eniyan naa ṣọna de aye kan fun bibọ Oluwa, Matteu 25:1; 2 Kọrinti 11:2

2 Imurasilẹ wọn fi irú iha ti wọn kọ si i hàn, Matteu 25:2-4; Orin Dafidi 119:105

II Ikede Bibọ Ọkọ Iyawo

1 Awọn ti o mura silẹ ati awọn ti kò mura silẹ jumọ n ṣọna, Matteu 25:5; 13:30; Orin Sọlomọni 5:2; Luku 19:13

2 Ohun ẹda ọrun kan ke pe, “Wo o, ọkọ, iyawo mbọ,” Matteu 25:6, 7; 1 Tẹssalonika 4:16

3 Ipò ibẹru ti awọn alaimura silẹ wà, ati idaniloju ti o wà lọkan awọn ti o mura silẹ fara han ninu ibeere ati idahun olukuluku wọn, Matteu 25:8, 9; Johannu 11:10

4 Kò ni le ṣe e ṣe lati gbadura agbayọri ni akoko ikẹyin lati ní awọn iriri ti o yẹ ki eniyan ní, Matteu 25:9, 10; 24:27

III Wiwọle awọn Wundia Marun Ọlọgbọn si Ibi Igbeyawo

1 “Awọn ti o si mura tan bá a wọle lọ. . . . a si ti ilẹkun,” Matteu 25:10; 24:44; Ifihan 19:7-9; Heberu 2:1-3; Orin Dafidi 45:1-17

2 A kọ fun awọn alaimura silẹ wundia alailọgbọn lati wọle, Matteu 25:11, 12; Luku 13:23-30

3 Ikilọ ikẹyin fi itumọ owe naa hàn, Matteu 25:13; Marku 13:32-37; Luku 12:35-40; Ifihan 3:11

Notes
ALAYE

Owe

Ẹni kan sọ pe owe jé̩ “itan nipa ohun ayé lati fi ṣe apejuwe ohun ti ọrun.” Nigba gbogbo ti a ba pa owe, otitọ Ọrọ Ọlọrun pataki kan ni a fẹ fi kọ ni, o si ṣe danindanin fun wa lati pin Ọrọ Ọlọrun bi o ti yẹ, ki oye iṣẹ ti Ọlọrun ran si wa le ye wa ki a si gba a tọkantọkan (2 Timoteu 2:15).

A le ri i, nigba naa pe ki i ṣe gbogbo apejuwe ti o wa ninu owe ni o kuku ba ohun ti a n fi we mu rẹgi ni gbogbo ọna, ṣugbọn awọn apẹẹrẹ ati ojiji inu Bibeli a maa fi otitọ ati itumọ ohun ti Ẹmi hàn ni kikun. Iwe Mimọ si ni lati fi idi itumọ ati otitọ wọnyii mulẹ nitori “Kò si ọkan ninu asọtẹlẹ inu iwe-mimọ ti o ni itumọ ikọkọ” (2 Peteru 1:20). S̩ugbọn gẹgẹ bi a ti sọ tẹlẹ, a kò gbọdọ ni ero lati kọ ẹkọ ti o tayọ otitọ nla kan ṣoṣo ninu ẹyọ owe kan. Nigba miiran ẹwẹ, a le ri ẹkọ pupọ kọ. Ohun kan ti a gbọdọ fi sọkan nigba gbogbo ibá a ṣe pe a n tumọ awọn ọrọ ti o dikoko tabi ẹsẹ Iwe Mimọ, owe tabi apẹẹrẹ, ni pe, itumọ ti o wù ki a fi fun ọrọ naa ti a n ṣe ayẹwo rè̩ ni lati duro lori gbogbo Ọrọ Ọlọrun ki o si ṣe deedee pẹlu ẹkọ Bibeli. Ni ọna bayii ni a le ni idaniloju pe a kò ṣi Ọrọ Ọlọrun tumọ.

Ijafara

Owe yii fi otitọ kan hàn ti a kò gbọdọ fi ọwọ yẹpẹrẹ mú: eyi ni ewu nla ati jamba ti o wà ninu ijafara lati ni igbala kikún. Ohun pupọ miiran ni a le fi kọ ni ninu owe yii. Otitọ pupọ ni a si le fi hàn ninu rè̩. S̩ugbọn ohun kan ti a gbọdọ fi sọkan nigba gbogbo ni ikilọ nla nipa ewu ti ó wà ninu è̩ṣẹ ijafara.

Awọn è̩ṣẹ miiran wà ti o fara sin nipa ẹda ṣugbọn ti igbẹyin wọn kún fun iparun gẹgẹ bi è̩ṣẹ ti a tilẹ mọọmọ dá. Ẹṣẹ ijafara jé̩ ọkan ninu wọn. A le ri i ninu owe yii pe igbẹyin iru ẹṣẹ bayii buru ju ohun ti a le fẹnu sọ lọ. Bakan naa ni a kò ni ké ijiya ninu ọrun apaadi kuru nitori è̩ṣẹ naa jẹ eyi ti o fara sin. Oró ati abamọ ti o wà ninu ipinya ayeraye kuro lọdọ Ọlọrun, Ẹni ti wọn ti fé̩ nigba kan, ti wọn ti gbega, ti wọn si sìn tọkantọkan, ki yoo dinkù nitori ki i ṣe pe wọn mọọmọ ṣọtẹ tabi ṣaigbọran si ofin Ọlọrun.

Ọna pupọ ni a le fi jẹ alafara. A le jẹ alafara niwọn igba ti a ko ba wá awọn nnkan wọnni ti Ọlọrun fẹ fun wa. A si le gba awọn ibukún ati iriri ti Ọlọrun ṣeleri fun wa, ṣugbọn ki a sọ wọn nù nipa ijafara. Lọna mejeeji yii ni a le gba jé̩ ẹlẹbi niwaju Ọlọrun. Lọna mejeeji wọnyii ni awọn wundia alaigbọn wọnyii gbé jẹbi è̩ṣẹ ijafara. Wọn kunà lati lọ si pipe ibukún ti Ọlọrun ti pese silẹ fun wọn, wọn si tun fi ọwọ yẹpẹrẹ di eyi ti wọn ti ni mú; ati, nikẹyin, wọn sọ gbogbo eyi ti Ọlọrun ti fi fun wọn nù. Idajọ ti a ṣe ti o da wọn lẹbi tọ, kò si le yipada. Wọn sọ ohun gbogbo nù nitori wọn kuna lati rìn ninu gbogbo imọlẹ Ihinrere ti ó tan si ipa ọna wọn.

Oye awọn Wundia Ọlọgbọn

A kà pe awọn wundia ọlọgbọn wọnyii fi ororo sinu fitila wọn ati sinu kolobo ororo wọn. Nipa bayii a ri i pe wọn lo gbogbo oye, iriri ati anfaani ti o ṣi silẹ fun wọn. Wọn tọju eyi ti wọn ti ri gbà, wọn kò si jẹ ki o bọ kuro lọwọ wọn.

Awọn wundia ọlọgbọn wọnyii dabi awọn wọnni ti kò kuna lati gba gbogbo iriri ti Ọlọrun fẹ fun wọn, nigba ti wọn si ti gba ẹkunrẹrẹ ibukun naa wọn tun tè̩ siwaju lati gba agbara Ọlọrun ati lati fi ọwọ danindanin pa agbara naa mọ ti Ọrọ Ọlọrun ṣeleri lati fi fun wọn “nigbati Ẹmi Mimọ ba bà le nyin” (Iṣe Awọn Apọsteli 1:8). Awọn eniyan Ọlọrun mọ pe a le ri igbala, ki a sọ wa di mimọ patapata, ki a si fi agbara Ẹmi Mimọ wọ wa, ki a má si jẹ aṣẹgun ni kikun bi ko ṣe pe a ba pa awọn iriri wọnyii mọ nipa pipa igbagbọ mọ -- ki a si maa rin ninu imọlẹ ti o tan si ipa ọna wa. Bi o tilẹ jẹ pe eniyan ti ri awọn iriri iyanu mẹtẹẹta wọnyii gbà, o tun le di ẹni itanu nipa fifi igbala rè̩ ni kikún jafara. È̩ṣẹ ijafara le gba iyè ati ogo ainipẹkun lọwọ ẹni.

Niwọn bi owe yii ti n sọ nipa awọn ti n ṣọna fun bibọ Oluwa, a le wi pe awọn wundia ọlọgbọn wọnyii duro fun awọn ọmọ Ijọ Kristi tootọ. Wọn ki i ṣe àdàlù eniyan bi ti akoko awọn Ọmọ Israẹli, wọn si yatọ si awọn wọnni ti o kunà lati wọ Ilẹ Ileri. Wọn n lo gbogbo anfaani ti wọn ni ninu Kristi, wọn si n ṣe afẹri ojurere Ọlọrun ni igbesi-aye wọn nigba gbogbo. Wọn kò fi igbala wọn ati anfaani ti wọn ni lati ni iranwọ kikun tafala. Wọn n rìn ninu gbogbo imọlẹ Ihinrere ti o tàn si ọna wọn.

Bi a ti n kẹkọọ nipa Ijọ Ologo yii, eyi ti a pè ni Iyawo Kristi nibomiran ninu Iwe Mimọ, a ri i pe wọn jẹ aṣẹgun ni kikun nitori wọn wà ni imurasilẹ (Ifihan 12:11; 19:7). Onisaamu ṣe apejuwe ogo Ọkọ iyawo, ati anfaani ayeraye ti i ṣe ti Iyawo Ọdọ Agutan nigba ti o wi bayii pe “Ọlọrun, lai ati lailai ni ité̩ rẹ: ọpá-alade ijọba rẹ ọpá-alade otitọ ni. Iwọ fẹ ododo, iwọ korira iwa buburu: nitori na li Ọlọrun, Ọlọrun rẹ, ṣe fi àmi ororo ayọ yà ọ ṣolori awọn ọgba rẹ. . . . li ọwọ ọtún rẹ li ayaba na gbe duro ninu wura Ofiri.” Siwaju si i o tun kilọ fun gbogbo eniyan lati ya ara wọn kuro ninu gbogbo ohun idiwọ ati eeri, nigba ti o wi bayii pe, “Dẹti silẹ, ọmọbirin, si ronu, si dẹ eti rẹ silẹ! gbagbe awọn enia rẹ, ati ile baba rẹ! Bḝli Ọba yio fẹ ẹwà rẹ gidigidi: nitori on li Oluwa rẹ; ki iwọ ki o si ma sìn i” (Orin Dafidi 45:6, 7, 9-11).

Aimoye awọn Wundia Alailọgbọn

Niwọn bi ẹkọ pataki ti a ri kọ ninu owe yii ti dá lori ewu fifi igbala wa jafara -- è̩ṣẹ ti awọn wundia alaigbọn jẹbi rè̩ -- apa ibi yii ni a ni lati fi ọkàn si ju lọ ninu ẹkọ wa yii.

A le ri awọn eniyan ti o ni anfaani kan naa gẹgẹ bi awọn wundia ọlọgbọn. Awọn paapaa ti gba iwọn ibukun ti Ọlọrun pese silẹ fun wọn. Wọn si ti gbà ninu iriri iyebiye ti o daju ti ilana igbala ti pese silẹ. S̩ugbọn Ọlọrun jẹri si wọn pe Oun kò mọ wọn ri! Wọn ki i ṣe ti Rè̩ mọ! Orukọ wọn kò si ninu Iwe Iye ti Ọdọ-Agutan!

Nitori wọn tilẹ jẹ wundia fi hàn pe wọn ti jẹ alabapin ninu igbala Ọlọrun. Ni ti pe wọn ni iwọn ororo lati fun wọn ni imọlẹ fun igba diẹ, fi hàn pe Ẹmi Ọlọrun ti n ba wọn gbe niwọn iba. S̩ugbọn wọn kunà lati lọ si pipe, ati lati ri gbogbo iriri wọnni ti o wà fun wọn, wọn kò si rin ninu gbogbo imọlẹ ti o tàn si ọna wọn. Wọn ro pe wọn ti gba Ẹmi Mimọ ati pe O tilẹ ti fi edidi di wọn nitori wọn ti ni ibalo Ẹmi iyebiye ni niwọn iba diẹ. S̩ugbọn eyi ti o buru ju ni pe, nipa ijafara, wọn ti sọ iba ibalo Ẹmi Ọlọrun ti wọn ni nigba kan rí nù.

A mọ pe ororo ti a n sọrọ nipa rè̩ nihin jẹ apẹẹrẹ Ẹmi Ọlọrun. Ororo yii ni o n fun wa ni imọlẹ ẹmi. Jesu wi pe awọn akọwe ati Farisi n rìn ninu okunkun nitori wọn kò ni imọlẹ, nitori naa ni wọn ṣe n kọsẹ ti wọn si n ṣubu. Ọrọ Ọlọrun ni fitila fun ẹsẹ wa ati imọlẹ si ipa ọna wa (Orin Dafidi 119:105); ṣugbọn lati ni imọlẹ ti Ẹmi gbà ju pe ki a kan maa ka Bibeli. Ẹmi Ọlọrun ni lati fi oye yé wa ati lati tọ wa si Otitọ gbogbo; nitori naa Ẹmi ati Ọrọ ni o n lọ pọ, wọn si jẹ ọkan naa (Johannu 16:13; 1 Johannu 5:7).

Ẹmi Mimọ bẹrẹ iṣẹ Rè̩ ninu wa nigba ti O ba pe wa si ironupiwada, ti O si fi oye è̩ṣẹ yé wa (Johannu 6:44; 16:7-11). Oun yoo tọ wá wá, yoo si wà pẹlu wa nigba ti a ba dá ọkàn wa lare; yoo si ṣe ohun kan naa ati ju bẹẹ lọ nigba ti a ba sọ ọkàn wa di mimọ. S̩ugbọn yoo wọ inu wa ni ẹkunrẹrẹ nigba ti a ba fi Ẹmi Mimọ wọ wá (Johannu 14:17, 18). Ẹni ti o ri isọdimimọ gbà a maa ni imọlẹ ju ẹni ti o ni igbala; ẹni ti a si ti fi Ẹmi Mimọ wọ a maa ni ẹkunrẹrẹ ibukun ju ẹni ti o ni isọdimimọ lọ.

A kò gbọdọ ni ero pe Ẹmi Mimọ ni ipele. Ẹmi Mimọ tikara Rè̩ kò ni ipele ṣugbọn oṣuwọn wà nipa bi eniyan ti ṣe n gbà Á ati bi O ti n kún inu eniyan to. Ẹni ti o ri idalare gbà ní Ẹmi Ọlọrun ni iwọn iba, ṣugbọn eyi kò to ti ẹni ti o ri anfaani Ọlọrun gbà ni kikun nipa isọdimimọ ati fifi Ẹmi Mimọ wọ ni.

Awọn wundia alaigbọn ti gba Ẹmi Mimọ niwọn iba diẹ, ṣugbọn wọn jé̩ ki o jò danu nipa ainaani. Atupa wọn ti kú tabi o n kú lọ, eyi si fi hàn pe wọn ni iba ororo diẹ tẹlẹ ri. A kilọ fun wa lati “mā fi iyè gidigidi si ohun wọnni ti awa ti gbọ, ki a má bā gbá wa lọ kuro ninu wọn nigbakan” (Heberu 2:1). Awọn ti o ni imọ nipa ede ti a fi kọ Bibeli ki a to tumọ rè̩ si oriṣiriṣi ede sọ fun ni pe koko ẹsẹ yii ni pe a ni lati “fi iye gidigidi si ohun wọnni ti awa ti gbọ ki a má bā jẹki nwọn jo danu gẹgẹ bi ohun ti a fi sinu ikoko fifọ.” Paulu Apọsteli sọ nibomiran pe, “Bi ẹnikẹni kò ba ni Ẹmí Kristi, on kò si ninu ẹni tirè̩” (Romu 8:9). Nipa ainaani, awọn wundia alaigbọn ti jẹ ki eyi ti wọn gbà jò danu, wọn si ti sọ ibarẹ pẹlu Oluwa wọn nù. Wọn ki i ṣe ti Rè̩ mọ nitori Ẹmi Rè̩ ti fi wọn silẹ. Lai si aniani ohun ti o mu ki wọn wà ni ipo ijafara yii sibẹ ni pe wọn ṣe alainaani lati wá ororo ati lati fi i sinu kolobo ati fitila wọn. Wọn kunà lati rìn ninu imọlẹ ti o tàn si ipa ọna wọn; wọn si tun kunà lati pa imọlẹ ti wọn ti ri gbà mọ. Kò si ohun kan fun wọn mọ bi ko ṣe òkunkun.

Igbe Laaarin Ọganjọ

A sọ fun awọn alaigbọn wọnyii lati lọ ra ororo. Eyi fi han pe a ni ohun kan lati ṣe ki a to le gba awọn ohun wọnni ti Ọlọrun n fun wa lọfẹẹ. A kò le ra ojurere Ọlọrun tabi ki a gba ibukun Rè̩ nipa iṣẹ ọwọ wa. Sibẹ a ni ohun kan lati ṣe, eyii ni jijọwọ ifẹ wa, ara wa ati ilana wa fun Ọlọrun – fifi ara wa rubọ patapata fun Ọlọrun – bi a ba fẹ rin ninu gbogbo imọlẹ Ihinrere ti o tàn si ipa ọna wa.

Awọn wundia mẹwẹẹwa sùn, ṣugbọn oorun yii ki i ṣe ti ẹmi. Iṣẹ oojọ ni o gba wọn ni akoko. Marun un ninu wọn ti lọ si pipe ifẹ Ọlọrun ṣugbọn awọn marun un iyoku ti kuna lati ṣe aṣeyọri. A ri apẹẹrẹ pe gbogbo wọn ni o n reti ti wọn si n ṣọna fun bibọ Oluwa wọn. S̩ugbọn o daju pe awọn alaigbọn kò fi tinutinu ṣọna fun ọjọ nla yii. O ṣe e ṣe ki wọn ti sọrọ pupọ nipa bibọ Oluwa wọn, ki wọn si ti maa fara han bi ẹni ti o mura silẹ de bibọ Rè̩ nitori imọlẹ wà ninu atupa wọn ni ibẹrẹ. S̩ugbọn wọn fi igbala wọn jafara nitori wọn kunà lati gba gbogbo oore-ọfẹ ti Ọlọrun fẹ fun wọn, wọn si padanu ti kò lopin.

S̩iṣọna fun bibọ Oluwa wa a maa fi ibẹru si wa lọkan nigba miiran. Ki i ṣe pe a n bẹru pe O n bọ, ṣugbọn a n bẹru ki a má kuna lati ni awọn amuyẹ tabi wa ni ipò ti o le ṣe wa yẹ fun bibọ Rè̩. A o bẹru lati fi igbala wa jafara ki a si di ẹni egbe laelae nitori è̩tan è̩ṣẹ ti o fara sin. Dajudaju, a o ni ifẹ si ifarahan Rè̩, a o si maa sa gbogbo ipá wa lati mura silẹ.

Ẹmi Ọlọrun ni n kede nigba gbogbo nipa bibọ Kristi. Ẹmi Ọlọrun ni o pe awọn wundia mẹwaa ni akọkọ lati mura silẹ, Oun naa ni o si pè wọn nikẹyin lati dide ati lati pade Oluwa wọn. Jesu yoo fara hàn gẹgẹ bi manamana ti n kọ, ariwo ati iró ipè Ọlọrun yoo dún ni akoko naa: ṣugbọn eyi yoo ṣẹlẹ lẹsẹkẹsẹ ti O ba fara han, a kò si le pe e ni ikilọ Ẹmi gẹgẹ bi eyi ti a fun awọn wundia wọnni ti o n sùn.

Lai pẹ a o gbọ ariwo olori angẹli ati iro ipe Ọlọrun. A o si ri Olugbala gẹgẹ bi O ti n bọ lati mú Iyawo Rè̩ ti o n ṣọna fun bibọ Rè̩ lọ -- eyi ni Ijọ Kristi. Akoko imurasilẹ Rè̩ ni eyi a si ti gbọ ohùn ikilọ Ẹmi Ọlọrun. Ẹmi Mimọ olóòótọ nì si n ṣiṣẹ Rè̩ ni ayé lati pese Ijọ Kristi fun akoko ologo nì. Ẹ jẹ ki a maa “ṣọna ki a si mā wà li airekọja. . . . ki a mā gbé igbaiya igbagbọ ati ifẹ wọ; ati ireti igbala fun aṣibori” (1 Tẹssalonika 5:6, 8). Ẹ jẹ ki a ni idaniloju yii pe ororo wà ninu fitila wa ati ninu kolobo ororo fitila wa, ki a má si fi ayè silẹ fun ororo naa lati jò danu nipa ijafara, ki a má ba ṣegbe titi lae.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni owe?
  2. Bawo ni a ṣe ni lati tumọ Ọrọ Ọlọrun?
  3. Ta ni gbọdọ jẹ olutọ wa si Otitọ gbogbo?
  4. Ki ni ohun iwuri ti o wà ninu iṣesi ati iwa awọn wundia ọlọgbọn ati awọn alaigbọn?
  5. Ọna wo ni awọn wundia alaigbọn fi kuna?
  6. Apẹẹrẹ wo ni a fun wa nipa iwa ati iṣesi awọn wundia ọlọgbọn?
  7. Sọ oriṣiriṣi iṣẹ ti Ẹmi Mimọ n ṣe lonii.
  8. Sọ itumọ “ohun ti Ihinrere yoo gbà lọwọ wa” niwọn igba ti a mọ pe a kò le ra igbala tabi ojurere Ọlọrun?
  9. Bawo ni a ṣe mọ pe awọn wundia alaigbọn kò ri ororo ti wọn wá lọ rà?
  10. Ka ẹsẹ ti o kẹyin ninu ẹkọ wa yii lati ori wá.