Lesson 225 - Senior
Memory Verse
AKỌSORI: “Ẹnikẹni ti o ba ni, li a o fifun, yio si ni lọpọlọpọ: ṣugbọn li ọwọ ẹniti kò ni li a o tilẹ gbà eyi ti o ni” (Matteu 25:29).Cross References
I Talẹnti ati Awọn ti o Gbà Wọn
1 A fi talẹnti fun awọn ọmọ-ọdọ ti a ti yiiri wò, gẹgẹ bi iwọn agbara wọn, Matteu 25:14, 15; Luku 19:12, 13; Romu 12:6-8; 1 Kọrinti 12:1-31; Efesu 4:11, 12
2 Awọn olóòótọ ọmọ-ọdọ fi talẹnti wọn ṣiṣẹ, wọn si sọ ọ di ilọpo meji, Matteu 25:16, 17; Luku 19:16, 18; 1 Kọrinti 12:31; 14:1; 15:10; 2 Timoteu 2:15
3 Nipa aiṣe ohunkohun, alaiṣootọ ọmọ-ọdọ naa fi ara rè̩ hàn bi alaimoore ati alaiṣee-fọkantan, Matteu 25:18; Luku 12:47; 19:20, 21; Jakọbu 2:14; 4:17
II Èrè ati Idajọ nigba Bibọ Oluwa
1 Ipadabọ Oluwa ni yoo bẹrẹ akoko idajọ ati gbigba iyin, Matteu 25:19, 31-46; Luku 12:37; 19:15; Ifihan 3:11; 16:15
2 Awọn ti o ṣe olóòótọ yoo gba èrè anikun iṣé̩ ati ipò, Matteu 25:20-23; Luku 19:16-19; 22:28-30; Ifihan 5:10; 19:11-16; 20:1-6; 1 Kọrinti 6:2; Juda 14, 15
3 Awọn alaiṣootọ yoo padanu gbogbo ibukun ati ayọ iṣẹ-isin, a o si ta wọn nù titi ayeraye, Matteu 25:24-30; Luku 19:20-24; Romu 11:29; 2 Tẹssalonika 1:6-10
Notes
ALAYEItọni Atọkanwa
Jesu pa owe pupọ nipa Ijọba Ọrun. Ninu eyi ti a n ṣe aṣaro le lori yii, Jesu fi ara Rè̩ wé ọkunrin kan ti o n re ajo ti o pè awọn iranṣẹ rè̩ jọ ti o si fi ohun ini rè̩ le wọn lọwọ, ki wọn ki o le maa bojuto o titi yoo fi de. A le ri i pe ọkunrin naa bá awọn iranṣẹ rè̩ sọ asọye o si fi iṣẹ ti wọn ni lati ṣe nigba ti oun ba lọ le wọn lọwọ. Iranṣẹ rè̩ ni wọn i ṣe tẹlẹtẹlẹ. Wọn mọ ọn, wọn mọ ohun ti o fẹ ati bi o ti le ba ni wi. O mọ bi ipá wọn ti to ati bi wọn ti jẹ olóòótọ si. Kò beere ohun ti kò ṣe e ṣe lọwọ wọn, ohun kan ti o n beere lọwọ wọn ni lati boju to awọn ohun ini rè̩.
Gẹgẹ bi aye wa bi oṣiṣẹ ninu ọgbà ajara Ijọba Ọlọrun, a mọ pe a ni lati waasu Ọrọ naa pẹlu agbara, a ni lati gbadura fun awọn alaisan ki wọn le ri imularada, a si ni lati mu awọn aṣako pada bọ wa sinu agbo. Awọn eniyan mimọ ni lati pejọ pọ ki a si rú ọkàn wọn soke nipa riran wọn leti awọn aṣẹ ati ileri Ọlọrun. Awọn ti o ni ẹbun orin ni lati kọ bi a ti n lo ohun-elo orin daradara; bakan naa ni o ṣe danindanin lati ni awọn akọrin lọkunrin ati lobinrin lati maa kọrin ninu ile Ọlọrun. Awọn eniyan si ni lati wa ti yoo jẹ aladura agbayọri lati maa gbadura fun aye ẹṣẹ ati egbe yii; bakan naa ni awọn kan ni lati wà ti yoo maa jade lọ si opopo ati si abuja ọna lati rọ ẹlẹṣẹ lati wá, wọn kò si gbọdọ gbagbe Ọrọ Oluwa wa ti o wi pe, “Ẹ lọ si gbogbo aiye, ki ẹ si ma wasu ihinrere fun gbogbo ẹda” (Marku 16:15).
Iṣẹ pupọ wà fun wa lati ṣe, ṣugbọn Ọlọrun ti fun wa ni ileri iyebiye fun itọni ati imulọkanle. O ni Oun ki yoo fi wa silẹ lai ni Olutunu; Oun yoo fun wa ni agbara lati ṣe aṣeyọri ninu ọgbà ajara Rè̩; Oun yoo si pese fun gbogbo aini wa gẹgẹ bi ọrọ Rè̩ ninu ogo; O si tun ṣeleri pe awa yoo jẹ ajumọjogun pẹlu Rè̩ ati pe awa yoo ba A jọba ni Ijọba Rè̩.
Lai si aniani, lẹyin ọrọ asọye yii laaarin oluwa ati awọn iranṣẹ rè̩, ọkàn ọpọlọpọ ninu awọn iranṣẹ naa gbọgbẹ, wọn si jẹjẹ ninu ara wọn lati lo gbogbo talẹnti ti a fi fun wọn, bi ipá wọn ba ti to. A ri i pe awọn diẹ ninu wọn ṣe bẹẹ, ṣugbọn awọn miiran ṣeleri lati ṣe bẹẹ nigba ti wọn n wa ojurere oluwa wọn; ṣugbọn wọn jokoo wọn si kuna lati mu ileri wọn ṣẹ. Awọn miiran jé̩ ọlẹ to bẹẹ ti wọn kò le ṣaapọn rara.
Pipin Talẹnti
Oluwa wa n fun ni ni talẹnti, tabi ojuṣe, gẹgẹ bi agbara olukuluku ti to. Oun mọ ẹbun ti a ni fun iṣẹ kọọkan. Bi o tilẹ jẹ pe ẹbun ti a fun olukuluku yatọ si ara wọn, ṣugbọn ọkàn otitọ kan naa ni a n beere lọwọ olukuluku, eyi ni a o si fi fun ni ni ere. Talẹnti marun un yoo pọ ju fun ẹlomiran, bẹẹ ni ọkan ṣoṣo yoo kere ju fun awọn miiran. Ẹni ti o ni kekere ko gbọdọ ṣe ilara ẹni ti o ni pupọ, nitori Ọlọrun ni o pín awọn talẹnti naa ninu ọgbọn awamaridi Rè̩. Oun ki i beere ohun ti kò ṣe e ṣe lọwọ wa. Oun mọ wá, O si mọ bi agbara wa ti to. Ibeere ti o yẹ ki o maa lu agogo lọkan wa ni pe ṣe a n lo talẹnti ti O fi fun wa tabi a dì wọn pamọ ni.
Lẹyin igba ti o ṣe eto tan ti o si ti pin talẹnti, oluwa wọn naa mu ọna ajo rè̩ pọn o lọ si ilu okeere, a si fi awọn iranṣẹ naa silẹ lati ṣe ojuṣe wọn. O wà ni ipá wọn lati lo talẹnti ti a fi fun wọn tabi ki wọn jokoo ki wọn si kawọ gbenú. Erè tabi idalẹbi wọn duro lori bi wọn ba ti lo talẹnti ti a fi fun wọn si. Ere tabi idalẹbi ti yoo jẹ ti wa ni ayeraye dá lori bi a ba ṣe lo talẹnti wa si.
Fifi Talẹnti S̩owo
Ninu owe yii Jesu wi pe ẹni ti o gba talẹnti marun un ati ẹni ti o gba meji lọ lẹsẹkẹsẹ lati fi ṣowo. Iṣẹ oluwa wọn gbà wọn lọkàn. Wọn sa ipá wọn lati ri i pe talẹnti wọn lé si i. Wọn ni ifarada ninu iṣẹ wọn. Wọn ko si ṣe ilọra bi o tilẹ jẹ pe oluwa wọn fa bibọ rè̩ sé̩yìn. Nitori eyi wọn ṣe aṣeyọri. Wọn si jere talẹnti pupọ si i. Awọn miiran kawọ gbenú titi oluwa wọn fi de.
Ninu igbesi-aye Onigbagbọ ati ogun igbagbọ, awọn miiran wà ti o bẹrẹ daradara ti wọn si ṣe deedee bi oloootọ iranṣẹ fun iwọn igba diẹ, ṣugbọn ti wọn kuna lati foriti i titi de opin. Paulu Apọsteli kọ iwe si awọn eniyan bawọnyi pe, “Ẹnyin ti nsáre daradara; tani ha di nyin lọwọ ki ẹnyin ki o máṣe gba otitọ?” (Galatia 5:7).
Onilọra Ọmọ-ọdọ
Ọmọ-ọdọ ti o gba talẹnti kan lọ wa ilẹ o si ri owo oluwa rè̩ mọlẹ dipo ki o fi ṣowo fun oluwa rè̩. Awọn ẹlomiran sọ pe ọlẹ ni. S̩ugbọn kò ha gba agbara lati wa ilẹ ati lati ri owo naa mọlẹ? Bi o ba sa ipá ti o to bayii lati fi talẹnti ṣowo, kò ha ni jere diẹ fun oluwa rè̩? Jesu wi fun wa pe, “Gbogbo ẹká. . . . ti kò ba so eso, on a mu u kuro” (Johannu 15:2).
Ipadabọ Oluwa
Jesu wi pe oluwa awọn ọmọ-ọdọ wọnni pada dé o si pe wọn jọ lati gba iṣiro lọwọ wọn. Awọn ti o ṣe oloootọ fi ayọ pade oluwa wọn. Ki i ṣe ohun ti o ṣoro lati mọ iru idalẹbi ti yoo wa ni ọkàn alaiṣootọ iranṣẹ yii.
Ijolootọ ati ifi-ara-ji fun Kristi a maa fun ni ni igboya. Awọn ti o ni oore-ọfẹ yii ko ni ohunkohun lati bẹru nigba ti a ba pe wọn lati pade Oluwa wọn. Bawo ni ayọ naa yoo ti pọ to nigba ti a ba fara han pẹlu talẹnti wa ti a si wi pe, “Oluwa, talẹnti ti O fun mi ni eyi; eyi ti mo si jere nipa oore-ọfẹ Rẹ ni yii.” Fi oju ẹmi wo awọn ẹni irapada bi wọn ti n duro pẹlu ọwọ nina ti wọn si n dá talẹnti wọn pada fun Oluwa ati Olugbala wọn. Wo bi Oluwa ti rẹrin musẹ bi O ti yin wọn wi pe, “O ṣeun, iwọ ọmọ-ọdọ rere ati olõtọ.” Eyi kò ha tó ẹsan fun gbogbo iṣẹ, ijakadi, idanwo ati iṣoro ti a ti fara dà?
Diẹ ni awọn ti o mọ pe iṣẹ ẹmi jé̩ ohun ribiribi ti a kò gbọdọ fi ọwọ yẹpẹrẹ mú. S̩e ayẹwo ẹsẹ Iwe Mimọ ti o wi pe, “Ẹnikẹni ti o ba fi kìki ago omi tutù fun ọkan ninu awọn onirẹlẹ wọnyi mu nitori orukọ ọmọ-ẹhin, lõtọ ni mo wi fun nyin, ki o padanù ère rè̩;” ati pẹlu, “Ẹniti o ba ṣe olõtọ li ohun kikini, o ṣe olõtọ ni pipọ pẹlu.” Bawo ni yoo ti dùn to nigba ti Oluwa ba fi olubori iyin yii kun un fun ni pe, “Iwọ bọ sinu ayọ Oluwa rẹ.” Ikore ti kọja! Iṣẹ ti pari! Ayọ ailopin! Erè nlá nlà!
Talẹnti Kan
Ọmọ-ọdọ ti o gba talẹnti kan kò ṣe bi awọn ọmọ-ọdọ ẹlẹgbẹ rè̩ yoku. O pinnu pe oun ki yoo fi talẹnti ti a fi fun un ṣe ohunkohun. Kò tilẹ gbiyanju. O mọ oluwa rè̩. O si ti gba eyi ti o tọ si i. Oluwa rè̩ gbẹkẹle e. S̩ugbọn kò gbiyanju rara lati jere talẹnti miiran pẹlu, ki o le ri ohun ti yoo dá pada ni ilọpo fun oluwa rè̩. Nigba ti akoko iṣiro de, kò si ri ohun kan lati fi fun oluwa rè̩. Lati bo aṣiiri ọlẹ ati ọtè̩ ti o wà lọkàn rè̩, o bẹrẹ si fi oluwa rè̩ sùn bi onroro eniyan. Alagidi ati alaigbọran ọmọ-ọdọ sọ otitọ nigba ti o wi pe, “Emi si bè̩ru.”
Nigba ti è̩ṣẹ ba wọ inu ọkàn ibẹru yoo wà nibẹ pẹlu; ko ni si igbẹkẹle ninu Ọlọrun. Lẹyin ti Adamu ti dẹṣẹ, ẹru ba a nigba ti Ọlọrun pe e. Ẹgbaa-mọkanla (22,000) ni o fi ẹgbẹ-ogun Gideoni silẹ nitori ibẹru. Ẹṣẹ ni o n mu ki eniyan bẹru.
Awọn abẹru ati alaigbagbọ yoo ni ipa ti wọn ninu adagun ti n fi ina ati sulfuru jó nitori ẹṣẹ ati aigbagbọ wọn ti o mu ibẹru ba wọn. Eredi rè̩ ti ọkàn ọpọlọpọ eniyan kò fi balẹ lọjọ oni nigba ti wọn ba n wo ohun wọnni ti n bọ lori aye? Ẹru ni; è̩ṣẹ ti o wà ninu wọn ni o si mu ibẹru wa.
Èrè awọn Eniyan Buburu
Ohun idalẹbi ti o fọ si ẹni ti o fi talẹnti rè̩ pamọ ni eyi pe, “Iwọ ọmọ-ọdọ buburu ati onilọra,” “Nitorina ẹ gbà talẹnti na li ọwọ rè̩, ẹ si fifun ẹniti o ni talẹnti mẹwa. Nitori ẹnikẹni ti o ba ni, li a o fifun, yio si ni lọpọlọpọ: ṣugbọn li ọwọ ẹniti kò ni li a o tilẹ gbà eyi ti o ni.” Onilọra ọmọ-ọdọ yii dabi awọn ti o fé̩ ayé isisiyii ju iye ainipẹkun lọ. Nigba ti awọn wọnni ti o ti fi anfaani ti a fi fun wọn nisisiyii jafara ba duro niwaju Oluwa wọn, gbogbo anfaani lati ṣiṣẹ fun Un titi ayeraye ni a o fi dù wọn, wọn yoo si duro nibẹ pẹlu itiju.
S̩ugbọn eyi nikan kọ ni idalẹbi ti onilọra ọmọ-ọdọ yii gbà. Ohùn yii tun fọ si i pe, “Ẹ si gbé alailere ọmọ-ọdọ na sọ sinu òkunkun lode: nibẹ li ẹkún on ipahinkeke yio gbé wà.” Atubọtan buburu ni o wà fun onilọra, abẹru ati eniyan buburu! Titi ayeraye ni yoo maa ronu lori “ohun ti oun i ba ti ṣe.” Gẹrẹ ti eniyan ba ti de ipò awọn ti o ti ṣegbe, kò si etutu fun è̩ṣẹ mọ. Nigba ti ọjọ aanu ba ti kọja, kò tun si atunṣe mọ.
Omije ironupiwada lati wá Ọlọrun tọkantọkan fun idariji è̩ṣẹ nisisiyii yoo ṣi ilẹkun ibukun Ọrun silẹ yoo si yọ ọkàn naa kuro ninu ẹkún ati ipayinkeke ailopin. Ẹ jẹ ki a bi ara wa leere “Njẹ gbogbo talẹnti wa ni a n lò fun iṣẹ-isin Oluwa?”
Questions
AWỌN IBEERE- Iru ipò wo ni awọn ti o gba talẹnti ati ẹni ti o fun wọn ni talẹnti wà si ara wọn, ṣaaju pipin awọn talẹnti naa?
- Apẹẹrẹ ki ni talẹnti wọnyii jé̩ ninu iriri Onigbagbọ?
- Ki ni ṣe ti a fun awọn kan ni talẹnti ju awọn miiran lọ?
- Ki ni a n wò lati pín talẹnti fun olukuluku wa?
- Ki ni èrè awọn olóòótọ?
- Sọ awọn ọrọ iyin ti a sọ si awọn ti o fi talẹnti wọn ṣowo?
- Sọ awọn ọrọ idalẹbi ti a sọ si ẹni ti o ri talẹnti ti rè̩ mọlẹ.
- Ki ni ṣẹlẹ si alailere ọmọ-ọdọ naa?
- Sọ awọn otitọ Ọrọ Ọlọrun pataki ati awọn ẹkọ ti a kọ ninu owe daradara yii.