Orin Dafidi 34:1-22

Lesson 226 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “OLUWA mbẹ leti ọdọ awọn ti iṣe onirobinujẹ ọkàn; o si gbà iru awọn ti iṣe onirora ọkàn là” (Orin Dafidi 34:18).
Cross References

I Orin Iyin

1 Ohun ti o mu ki Dafidi kọ orin yii ṣẹlẹ laaarin oun ati Abimeleki, ọba Gati, 1 Samuẹli 21:10-15; Owe 29:25; Oniwasu 7:7

2 Dafidi bẹrẹ orin rè̩ pẹlu iyin atọkanwa si Ọlọrun, Orin Dafidi 34:1, 2; 71:8, 15; 145:2

3 Dafidi fẹ ki gbogbo eniyan gbe Oluwa ga pẹlu oun, Orin Dafidi 34:3; 35:26-28; Luku 1:46

II Orin Idande

1 Dafidi wi pe oun gbadura si Ọlọrun, Ọlọrun si gbohun oun, Orin Dafidi 34:4-6; 18:6; 22:24; 10:17

2 Aabo ati idande jé̩ ogún ti awọn ọmọ Ọlọrun, Orin Dafidi 34:7; 91:9-12; Matteu 18:10; Heberu 1:14

3 A kọ ọ pe, aabo Ọlọrun wà fun kiki awọn ti i ṣe ọmọ Ọlọrun, Orin Dafidi 34:8-10; 23:5; Isaiah 25:4; Gẹnẹsisi 28:15; Orin Dafidi 37:28; 2 Timoteu 4:18

III Ìpè lati Sin Ọlọrun

1 Dafidi fẹ ki awọn eniyan rè̩ kọ ibẹru Oluwa nipasẹ rè̩, Orin Dafidi 34:11; Owe 1:8; 4:1; Oniwasu 12:1

2 Dafidi fi yé awọn ti o fẹ ri rere ati ọjọ gigun lati kọ ẹkọ lara rè̩, Orin Dafidi 34:11-14; 1 Peteru 3:10, 11; Jobu 28:28

3 Ọlọrun n gba awọn eniyan Rè̩ là kuro ninu gbogbo ipọnju ati wahala wọn, ṣugbọn awọn eniyan buburu ni a o parun, Orin Dafidi 34:15-22; 2 Kronika 16:9; Orin Dafidi 11:4-7

4 Dafidi sọ asọtẹlẹ ti ikú Kristi, Orin Dafidi 34:20; Johannu 19:36; Ẹksodu 12:46; Numeri 9:12

Notes
ALAYE

Idanwo Dafidi

Dafidi ni o kọ Saamu Kẹrinlelọgbọn yii ni iranti igbà ti Ọlọrun yọ ọ kuro ninu iṣoro nlá nlà. Dafidi ti sá kuro ni ilu rè̩ lọ si ilẹ awọn Filistini nitori owú ati ikorira Saulu. Aarẹ ti bẹrẹ si mu Dafidi, ọkàn rè̩ si fẹrẹ rẹwẹsi ninu rè̩ nitori inunibini igbakuugba lati ọdọ Saulu; nigba ti o sún kan ogiri, o salọ si ọdọ Abimeleki (Akiṣi) ọba Gati fun aabo. Awọn Filistini jé̩ ọta Israẹli, nitori Ọlọrun ti pa a laṣẹ fun awọn Ọmọ Israẹli lati gbogun ti awọn Filistini titi wọn o fi run wọn. Dafidi, iranṣẹ Ọlọrun, ti sún kan ogiri ki o to lọ wá iranlọwọ sọdọ awọn Filistini. Ohun ti o ṣe yii fi iru ipò idaamu ti Dafidi wa hàn – nitori o gbagbọ pe aanu wà lọdọ awọn ọta Israẹli ju ọdọ Saulu Ọba lọ.

A dán igbagbọ Dafidi ninu Ọlọrun wò gidigidi ni ọjọ wọnni, idanwo naa si tun pọ ju bẹẹ lọ nigba ti o yan ọna ti kò ni laari yii lati bọ kuro ninu iyọnu rè̩ nipa wiwa aanu lọ sọdọ awọn eniyan buburu. Ọrọ Ọlọrun wi pe “iyọnu awọn enia buburu, ika ni” (Owe 12:10).

Nitori Dafidi wá aabo sọdọ Ọba Gati, o gbọ bi awọn ọmọ-ogun ti n sọrọ nipa rè̩, eyi si mu ki ẹru ba a gidigidi. Awọn ọmọ-ogun wọnyii mọ Dafidi gẹgẹ bi ọkan ninu awọn ọta wọn ti wọn korira ju lọ. Okiki Dafidi ti kàn gidigidi nipa pipa ti o pa Goliati ati awọn miiran ninu awọn Filistini; nitori naa nigba ti awọn iranṣẹ Abimeleki mọ ọn, oun ko ni ireti mọ lati ri aanu gbà lọdọ wọn. Ipo ti Dafidi wà léwu to bẹẹ ti o fi dibọn pe oun n ṣiwere. Ọba si paṣẹ fun awọn iranṣẹ rè̩ lati le e sọnu, nipa bayii, Dafidi sá asala.

Dafidi kọ ẹkọ nla ni akoko yii; ati ni ọdun diẹ lẹyin eyi, bi Dafidi ti n ṣe aṣaro lori agbara igbala Ọlọrun ni gbogbo akoko idaamu, a mí si i lati sọ nipa rè̩.

Ni akoko wahala nla, idaamu ti ẹmi ati ewu, o gbà ki a jẹ alagbara ninu ẹmi Ọlọrun, ki a si ni igbẹkẹle ninu Ọlọrun ki a to le duro jẹẹ de Ọlọrun lati yọ wa kuro ninu wahala wa. Akopọ ọrọ Dafidi ninu Saamu Kẹrinlelọgbọn yii fi hàn pe igbagbọ rè̩ ninu Ọlọrun tun jinlẹ ju bi o ti ri lọ.

O ranti Igbala Ọlọrun

Dafidi boju wo è̩yìn lati wo akoko iṣoro rè̩ lọdọ ọba Gati, o si ronu ohun ti iṣoro rè̩ sun un ṣe. Ọkàn rè̩ kò ni ṣalai jẹ ẹ lẹri pe oun i ba ti ṣegbe i ba ma ṣe pe Ọlọrun ti dide fun iranlọwọ oun. Koko Saamu Kẹrinlelọgbọn yii n sọ nipa oore nla Ọlọrun, titobi Rè̩, ati aabo ifẹ Rè̩ lori awọn eniyan Rè̩, ati iparun ti a ṣeleri fun awọn eniyan buburu.

Ọnakọna ti o wu ki Dafidi gbà – yala o fa ọgbọn yọ tabi bẹẹ kọ, nigba ti o sún kan ogiri ni tabi bẹẹ kọ, eyikeyi ti o wu ki o jé̩, Dafidi ni idaniloju yii pe asán ni gbogbo rè̩ i ba jẹ, i ba ma ṣe pe Oluwa dide fun iranlọwọ oun.

Dafidi kò ṣe alaye bi o ti ṣe mọ pe nipa iranlọwọ Ọlọrun ni oun fi bọ lọwọ awọn Filistini; sibẹ, o ni idaniloju pe Ọlọrun ni o yọ oun kuro ninu ewu. Iru igbagbọ bayii ninu igbala Ọlọrun, bi o tilẹ jẹ pe kò si alaye ti o hàn kedere fun iru ero bayii, ni igbagbọ tootọ.

Oju igbagbọ tootọ a maa ri ọwọ Ọlọrun ninu ohun gbogbo, eyi ti ọkàn ati oju eniyan nipa ti ara kò le ri. A mọ pe otitọ ni eyi, ki i ṣe nitori a ni iriri iṣẹ ti Ọlọrun ṣe ni igbesi-aye awọn eniyan Rè̩ nikan, ṣugbọn Ọrọ Ọlọrun fi idi rè̩ mulẹ: “Igbagbọ ni idaniloju ohun ti a nreti, ijẹri ohun ti a kò ri” (Heberu 11:1).

Aabo Ọlọrun

Dafidi sọ fun wa pe, “Angẹli OLUWA yi awọn ti o bè̩ru rè̩ ká, o si gbà wọn.” Ki i ṣe pe o wà ni tosi wa nikan, ṣugbọn o yi wa ka pẹlu aabo rè̩.

Ohun kan naa ni Jesu n sọ nipa rè̩ nigba ti O n sọ nipa aabo Ọlọrun lori Jerusalẹmu, ifẹ ati aabo ti wọn kọ. “Jerusalẹmu, Jerusalẹmu, iwọ ti o pa awọn wolĩ, ti o si sọ okuta lù awọn ti a rán si ọ pa, igba melo li emi nfẹ radọ bò awọn ọmọ rẹ, bi agbebọ ti iradọ bò awọn ọmọ rè̩ labẹ apá rè̩, ṣugbọn ẹnyin kò fẹ!” (Matteu 23:37). Iru apejuwe kan naa ni Mose lò nipa aabo Ọlọrun lori awọn eniyan Rè̩ nigba ti o kọ Orin Mose fun Israẹli: “Bi idì ti irú ité̩ rè̩, ti iràbaba sori ọmọ rè̩, ti inà iyé̩-apa rè̩, ti igbé wọn, ti ima gbé wọn lọ lori iyé̩-apa rè̩: bḝni OLUWA nikan ṣamọna rè̩” (Deuteronomi 32:11, 12).

Dafidi tun ṣe alaye ẹri rè̩ nipa aabo Ọlọrun ati ipese Rè̩ bayii pe “Kò si aini fun awọn ti o bè̩ru rè̩”, o si tun fi ẹsẹ yii gbè é lẹsẹ, “Awọn ọmọ kiniun a ma ṣe alaini, ebi a si ma pa wọn: ṣugbọn awọn ti nwá OLUWA, ki yio ṣe alaini ohun ti o dara.” Ọmọ kiniun jé̩ ọba ẹranko. Kiniun jẹ ọkan ninu awọn ẹranko ti o lagbara ninu awọn ti n pa ẹranko miiran jẹ. Wọn lọgbọn ẹwẹ, wọn si yara, nigba pupọ ni wọn n fi ikuuku kan ṣoṣo pa ohun ọdẹ wọn. Nitori awọn ẹranko naa gbọn wọn si ṣoro lati pa, gbogbo ẹni ti o wà ni tosi ibi ti wọn ba wa ni o maa n wariri nitori wọn. Bi o tilẹ jé̩ pe wọn lagbara ti wọn si koro ni wiwá ohun ọdẹ wọn, igba pupọ ni wọn n rù nitori ebi n pa wọn, nigba yii wọn a maa gboke-gbodo lati ri iwọn iba diẹ jẹ ki ebi ma ba pa wọn kú.

Lai si aniani Dafidi n ronu nipa awọn eniyan ti iwa aye wọn jọ ti kiniun lọna pupọ. Wọn níkà, wọn ṣe féfé, wọn si ṣe alailaanu ni ọna ti wọn gbà n wá ipò ati awọn ohun ayé yii. Otitọ ni Dafidi sọ nigba ti o wi pe bi wọn ti jẹ alailaanu to ninu ilepa wọn, sibẹ wọn a maa ṣe alaini. Ipin awọn ọta Ọlọrun ni pe nigba gbogbo ni wọn wà ninu iwaya ija pẹlu awọn oluṣe buburu bi ti wọn. Kò si alaafia fun eniyan buburu, wọn dabi okun riru, nigba ti kò le simi, eyi ti omi rè̩ n sọ ẹrè̩ ati eri soke. (Wo Isaiah 57:20). Eyi ko ri bẹẹ pẹlu awọn ọmọ Ọlọrun, nitori “awọn ti nwá OLUWA, ki yio ṣe alaini ohun ti o dara.” Awọn ọmọ Ọlọrun wà labẹ itọju ati ipamọ Ọlọrun, a si fi ifẹ Rè̩ ṣe agbàrà yi wọn ká, eyi ti o le awọn ọta jinna rere, ki awọn ọmọ Ọlọrun ba le maa jẹ ni alaafia ati ọpọ.

Ibẹru Oluwa

Dafidi mọ pe oun n kọ ibẹru Oluwa ati pe Ọlọrun n ṣe itọju awọn ti Rè̩. Otitọ ati oore-ọfẹ Ọlọrun dabi iṣan omi ti o mọ gaara ni ọkàn ati igbesi-aye Dafidi, eyi ni o si fun un ni anfaani lati jé̩ ẹni diduro ṣinṣin. Nitori naa, gẹgẹ bi o ti jé̩ aṣaaju ati ẹni ami-ororo Oluwa ti yoo jẹ ọba Israẹli, o mọ pe iṣẹ oun ni lati sọ fun awọn ẹlomiran nipa igbala nla ti Ọlọrun.

O ṣe e ṣe ki Dafidi ti maa kọ awọn ọmọ kekeke ni tootọ gẹgẹ bi o ti fi ye ni ninu Saamu yii, o tun le jẹ pe o kó awọn eniyan rè̩ jọ lati sọ fun wọn pẹlu ọrọ ti o rọrun lati ye wọn lọna kan naa ti Jesu gbà lati fi ba awọn ọmọ-è̩yìn Rè̩ sọrọ nipa ohun ijinlẹ ti Ijọba Ọlọrun, pe, “Bikoṣepe ẹnyin ba pada, ki ẹ si dabi awọn ọmọ kekere, ẹnyin kì yio le wọle ijọba ọrun” (Matteu 18:3).

Ileri Igbala

Dafidi sọ nipa iṣẹlẹ ti yoo jẹ imuṣẹ, lapa kan, àkókò ti Ọlọrun tikara Rè̩ yoo pese ẹbọ fun è̩ṣẹ awọn ẹda. Ọrọ ti Dafidi sọ bayii pe, “O pa gbogbo egungun rè̩ mọ; kò si ọkan ti o ṣé̩ ninu wọn,” n tọka si Ọdọ-Agutan tootọ ni. Ọkan ninu awọn ohun afiyesi nigba ipalẹmọ ati jijẹ ọdọ-agutan ti a pa fun ase Irekọja ni pe a kò gbọdọ fọ ọkan ninu egungun rè̩. Ilana yii ni wọn mu ṣẹ kinnikinni nigba ti wọn kan Kristi mọ agbelebu ati nigba ikú Rè̩. O jé̩ aṣa awọn ara Romu lati ṣé̩ egungun itan awọn ti wọn ba kàn mọ igi ki o le mu ikú wọn yá kankan. Bayii ni wọn ṣe si awọn ole meji wọnni ti wọn kàn mọ agbelebu pẹlu Jesu; ṣugbọn nigba ti awọn ọmọ-ogun Romu ri i pe Jesu ti kú ná, wọn kò ṣé̩ eyikeyi ninu egungun itan Rè̩.

Ọlọrun mí si Dafidi lati kọ akọsilẹ nipa Ajọ Irekọja gẹgẹ bi asọtẹlẹ ati ileri nipa Jesu Kristi Ẹni ti yoo fi ara gba oniruuru ẹgan ati iya, nikẹyin ti a o si ti ọwọ awọn ọta Rè̩ pa A. S̩ugbọn Ọlọrun yoo jí I dide kuro ninu oku yoo si gbe E ga pẹlu ogo nlá nlà. Bi Dafidi ti boju wo è̩yìn wo awọn iṣoro Rè̩, o ri i pe oun ti jiya ni igba kan ṣugbọn Ọlọrun ti mu un bori lai lewu ati lai ni ipalara. Bi o tilẹ jẹ pe Dafidi kò fi ijiya rè̩ wé eyi ti Oluwa rè̩ yoo fara dà, sibẹ o ni ọkàn imoore lọpọlọpọ, fun igbala nla Ọlọrun. Dafidi, pẹlu ọkàn ti o kún fun iyin si Ọlọrun, pari Saamu yii pẹlu awọn ọrọ daradara wọnyii pe, “OLUWA rà ọkàn awọn iranṣẹ rè̩; ọkan ninu awọn ti o gbẹkẹle e ki yio jẹbi.”

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni mu ki Dafidi kọ Saamu yii?
  2. Ki ni ṣe ti Dafidi fi bẹru awọn Filistini?
  3. Bawo ni Ọlọrun ṣe yọ Dafidi kuro lọwọ awọn Filistini?
  4. Awọn ọmọ wo ni Dafidi n kọ?
  5. Ọna wo ni a gba tọka si Kristi ninu Saamu yii?
  6. Ọna wo ni Dafidi fi fara mọ ijiya Jesu Kristi?