Orin Dafidi 103:1-22

Lesson 227 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Bi baba ti iṣe iyọnu si awọn ọmọ, bḝli OLUWA nṣe iyọnu si awọn ti o bè̩ru rè̩” (Orin Dafidi 103:13).
Cross References

I A Pa a laṣẹ lati fi Ibukun fun Oluwa

1 Onisaamu sọ nipa iṣẹ-isin wa eyi ti i ṣe fifi ogo fun Oluwa, Orin Dafidi 103:1, 2; Deuteronomi 8:10, 18; Luku 19:40

2 A sọ idi rẹ ti Ọlọrun fi yẹ fun iyin awọn eniyan, Orin Dafidi 103:3-6; 130:4; Matteu 1:21; Luku 9:56; 1 Peteru 2:9

II Ojurere Ọlọrun ti Eniyan Kò Yẹ Fún

1 Ọlọrun fi ara Rè̩ han fun Mose lori Oke Sinai, ati si gbogbo awọn Ọmọ Israè̩li nipasẹ Ofin, Orin Dafidi 103:7; Deuteronomi 4:8-14; Daniẹli 2:22; Johannu 1:17; Heberu 1:1-3

2 Aanu jé̩ ẹwà iwa mimọ Ọlọrun ti o tayọ, gẹgẹ bi gbogbo awọn ti o tọ Ọ wá pẹlu irobinujẹ ọkàn ti mọ, Orin Dafidi 103:8-12; 108:4; Ẹkun Jeremiah 3:22, 23; Joẹli 2:12-14; Titu 3:5

3 Ọjọ aye eniyan kúrú pupọ, ṣugbọn Ọlọrun mọ ẹda wa, Orin Dafidi 103:13-16; 89:48; Isaiah 40:6, 7; Heberu 9:27; Jakọbu 4:14

4 Aṣiiri iye ti ko nipẹkun wà ninu pipa Ọrọ Ọlọrun mọ, Orin Dafidi 103:17, 18; Isaiah 1:19; Johannu 8:31, 32; 14:23

III Ọba Gbogbo Ayé

1 Dafidi tilẹ pe awọn angẹli lati jumọ yin Ọlọrun, Ẹni ti ijọba Rè̩ bori ohun gbogbo, Orin Dafidi 103:19, 20; 1 Kronika 29:11; Isaiah 6:2, 3

2 Onisaamu pe awọn ogun ọrun; nikẹyin o si tun pe ọkàn rè̩ pẹlu lati yin Oluwa, Orin Dafidi 103:21, 22

Notes
ALAYE

Igba miiran wà ninu igbesi-aye olukuluku ẹni ti n sin Ọlọrun otitọ ati alaaye nigba ti titobi, ọlanla ati ẹwa iyanu Ọlọrun yoo ṣadede fi ara hàn lọtun ninu ọkàn rè̩ pẹlu ẹkún iyanu. Iru ipò bayii ni Onisaamu wà nigba ti o n kọ Saamu ikẹtalelọgọrun yii. Koko ọrọ rè̩ ni pe titobi ati ayeraye ni Oluwa Ọlọrun, ṣugbọn bi o ṣe ti eniyan ni, ẹni ilẹ ti ọjọ rè̩ si n kọja lọ ni; sibẹ Ọlọrun n boju wo eniyan ati ọna ti o n tọ lati Ọrun wá. Ero yii ni o mu ki Dafidi pe gbogbo ohun ti o wà ninu rè̩, ati awọn angẹli ati awọn ẹgbẹ-ogun Ọrun lati fi iyin ati ibukun fun Ọlọrun, nitori eyi ni o yẹ fun Ẹni ti i ṣe Ẹlẹda ati Ọba.

Iyin ti o S̩e Itẹwọgba

Eniyan buburu kò le fi iyin ti o tọ si Ọlọrun fun Un lati inu ọkàn buburu rè̩ wá, nitori “lati ọpọlọpọ ohun ọkàn li ẹnu rè̩ isọ” (Luku 6:45); ṣugbọn oore-ọfẹ Ọlọrun le yí ọkàn buburu pada. Nigba kan ni Onisaamu ni ọkàn buburu, ṣugbọn o gbadura titi o fi ni iriri idariji è̩ṣẹ rè̩ (Orin Dafidi 32:5); nitori eyi, oun le fi iyin ti o ṣe itẹwọgba fun Oluwa lati inu ọpọlọpọ ohun ti o wà ninu ọkàn rè̩ ti o ti di titun. Igba pupọ ni alagbara ọba Israẹli yii n ṣiwọ kuro lẹnu iṣẹ rè̩ lati fi iyin fun Ọlọrun rè̩! Iyin eniyan si Ẹlẹda rè̩ a maa mu ki o wà ni irẹpọ pẹlu Ọlọrun a si maa fi ẹsẹ eniyan mulẹ gidigidi ninu Ọlọrun. Lonii, aṣiiri Onigbagbọ wà ni fifi ọpẹ ati ibukun atọkanwa fun Ọlọrun alaaye nitori aanu ati iṣeun ifẹ Rè̩ si awọn ọmọ-eniyan. Bi eniyan kò ba fi iyin Ọlọrun ṣe ọran danindanin, wọn kò ni pẹ gbagbe gbogbo oore Rè̩. Orin daradara naa gba awọn Onigbagbọ ni imọran lati “ka ibukun rẹ, ati lati kà wọn lọkọọkan.”

Idariji Ẹṣẹ

Onisaamu ka eredi rè̩, lọkọọkan, ti eniyan fi ni lati maa yin Ọlọrun logo ki o si maa sin In. A darukọ idariji è̩ṣẹ ṣaaju nitori è̩ṣẹ ni o n ti ilẹkun ibukun Ọlọrun mọ eniyan. Ẹṣẹ n fa ijiya ikú wa sori ẹlẹṣẹ, ṣugbọn Ọlọrun a maa dari gbogbo irekọja awọn ti o ba wá sọdọ Rè̩ jì.

Iwosan nipa Agbara Ọlọrun

Idi keji ti a fi ni lati maa yin Ọlọrun ni pe O n wo oniruuru arun sàn. Bi oniṣegun kan ninu aye ba ni iru agbara yii, okiki rè̩ ki yoo ha kàn kaakiri? Njẹ gbogbo awọn ti o ba ṣe e ṣe fun ki yoo ha fẹ ki oniṣegun naa lo agbara rè̩ fun wọn? Ọlọrun kò yipada, agbara iwosan lọna iyanu wà lọwọ Rè̩ sibẹ lati wo oniruuru arun sàn. Ọmọ Ọlọrun wo gbogbo awọn ti o wá sọdọ Rè̩ sàn, a si kà pe, “Jesu Kristi ọkanna ni li aná, ati li oni, ati titi lai” (Heberu 13:8). Ki ni ṣe ti gbogbo awọn alaisan kò ṣe tọ Ọ wa? È̩ṣẹ wọn ni o yà wọn kuro lọdọ Ọlọrun. Nigba pupọ, bi awọn eniyan ba ti pinnu lati ronupiwada è̩ṣẹ wọn, wọn a maa ri ọwọ Ọlọrun lara wọn fun iwosan. Ileri Ọlọrun fun awọn Ọmọ Israẹli ni pe, “Bi iwọ o ba tẹtisilẹ gidigidi si ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ, ti o ba si ṣe eyiti o tọ li oju rè̩, ti iwọ o ba si fetisi ofin rè̩, ti iwọ o ba si pa gbogbo aṣẹ rè̩ mọ, emi ki yio si fi ọkan ninu àrun wọnni ti mo múwa sara awọn ara Egipti si ọ lara: nitori emi li OLUWA ti o mu ọ lara dá” (Ẹksodu 15:26).

Awọn miiran le wi pe Saamu ikẹtalelọgọrun n tọka si iwosan ti ẹmi, ṣugbọn nibi ti a gbe sọ nipa Messia ninu Iwe Isaiah, a tun ri i kà pe: “S̩ugbọn a ṣá a li ọgbẹ nitori irekọja wa, a pa a li ara nitori aiṣedede wa; ìna alafia wa wà lara rè̩, ati nipa ina rè̩ li a fi mu wa lara da” (Isaiah 53:5). Ninu Ihinrere ti Matteu, Ẹmi Ọlọrun sọ pe Jesu wo gbogbo awọn olokunrun nipa ti ara sàn ni imuṣẹ awọn asọtẹlẹ náà (Matteu 8:16, 17). Nihin yii a ri i daju pe Jesu ṣe etutu fun è̩ṣẹ ati fun iwosan ara pẹlu.

È̩ṣẹ ni o fa aisan, È̩jè̩ kan naa ti a ta silẹ fun imukuro è̩ṣẹ ní agbara lati mú aisan kuro. Ki ni ṣe ti awọn eniyan ki yoo fi gbẹkẹ le Ọlọrun fun iwosan ara wọn, ki wọn si fi iyin fun Un nigba ti O ba si ṣe iṣẹ naa?

“Ohun Didara”

“Ẹniti o fi ohun didara té̩ ọ lọrun.” Ọrọ yii tayọ ounjẹ oojọ ti awọn ọmọ-eniyan n jẹ lati fun ara lokun. Jobu sọrọ ti o fi ẹsẹ ọrọ wọnyii mulẹ nigba ti o sọ bayii pe, “Emi si pa ọrọ ẹnu rè̩ mọ jù ofin inu mi lọ” (Jobu 23:12). Ohun pataki ni ounjẹ oojọ, Ọlọrun si ti ṣeleri pe awọn ọmọ Rè̩ ki yoo ṣe alaini ohun ti o dara. “On na yio gbe ibi giga: ile apáta yio jẹ ibi ābo rè̩: a o fi onjẹ fun u; omi rè̩ yio si daju” (Isaiah 33:16). S̩ugbọn Ounjẹ Ọrun kan wà ti o ṣe pataki ju lọ fun ọkàn. Ni tootọ ounjẹ a maa mu eniyan wà laaye, ṣugbọn ọkàn ni lati gba ounjẹ ti rè̩ lati ọdọ Ọlọrun wá. Iṣẹ ti Ọrọ Ọlọrun n ṣe ni eyi: oun ni ounjẹ ẹmi. Gbogbo ẹni ti o jokoo ti tabili Jesu ni yoo jẹ ajẹyo ati ajẹṣẹku: “Emi li onjẹ iye: ẹnikẹni ti o ba tọ mi wá, ebi kì yio pa a; ẹniti o ba si gbà mi gbọ, ọrùngbẹ kì yio gbẹ ẹ mọ lai” (Johannu 6:35).

Onisaamu wi pe jijẹ ohun didara ti Ọlọrun a maa sọ igba ewe di ọtun. O fi idì ṣe akawe, boya nitori ẹmi rè̩ gùn pupọ. A sọ fun ni pe idì a maa lò tó ọgọrun ọdun; bi ọjọ ori rè̩ ti pọ to yii, a sọ fun ni pe, iyẹ ti o ti di ogbó lara idì a maa gbọn danu patapata, awọn miiran a si hù lọtun dipo gbogbo rè̩, eyi a si mu ki o dabi èwe. Ọkàn ẹni ti o ba gbẹkẹ le Ọlọrun ki i di arugbo. Agọ ara yii le wó, ki o si kọja lọ, ṣugbọn ẹmi yoo pada tọ Ọlọrun ti o fi i fun ni lọ. Ni owurọ ọjọ ajinde ara ati ọkàn yoo pade pẹlu ara ologo ti o ti jinde, yoo si wà titi lae lọdọ Oluwa. (1 Tẹssalonika 4:16, 17). Ireti Onigbagbọ ki i yè̩ lae.

Iṣe Aanu

Lẹyin ti Dafidi ti ka diẹ ninu awọn ibukun ti o ti ri gbà lọwọ Ọlọrun, kò gbagbe awọn ibukun ti awọn ẹlomiran ri gbà. O dùn mọ ọn pe Ọlọrun n ṣe ododo ati idajọ fun awọn ẹni ti a ni lára. Eyi yatọ si iṣe awọn ọmọ-eniyan, nitori awọn alagbara a maa ṣogo ninu pipọn awọn ti kò lagbara loju. Bayii ni o ri ni igba ayé Dafidi, nigba pupọ ni o n dide lati gbẹsan awọn talaka lara awọn aninilara. O dun mọ Dafidi lati mọ pe Ọlọrun wà pẹlu awọn ẹni ti a n ni lara. Gbogbo Onigbagbọ lati ayebaye ni o n yin Ọlọrun nitori idi eyi. “Ọlọrun si ti yàn awọn ohun ailera aiye lati fi dāmu awọn ohun ti o li agbara” (1 Kọrinti 1:27). Igberaga kò jẹ ki awọn alagbara ayé yii le feti si ipè Ihinrere, wọn si rò ninu ara wọn pe awọn kò ni iranlọwọ Ọlọrun fi ṣe. S̩ugbọn awọn ti a n jẹ niya n fẹ olugbeja, wọn si ri i pe Ọlọrun Ọrun ni olugbeja wọn. Eyi kò ha tó lati rọ ọkàn ọmọ-eniyan lati maa sin Ọlọrun ati lati maa yin In?

Ifẹ Ọlọrun

Onisaamu tun ṣe alaye pe ododo Ọlọrun, idajọ Rè̩, ati iṣipaya Rè̩ jade lati inu awọn àmúyẹ mẹrin wọnyii wá: “OLUWA li alānu ati olõre, o lọra ati binu, o si pọ li ānu.” Nigba pupọ ni o n ṣoro fun eniyan lati loye nipa awọn è̩wà iwà Ọlọrun wọnyii. Awọn miiran tilẹ n wi pe, “Bi Oluwa ba n ṣe Ọba gbogbo agbaye ti O si ni agbara to bi a ti n royin Rè̩, ki ni ṣe ti è̩ṣẹ ati iwà buburu fi wà ni aye?” Ọlọrun kò ṣai ṣe ọna ti è̩ṣẹ ki yoo fi si mọ, bẹẹ ni kò si dakẹ. Ọlọrun n fara da è̩ṣẹ ninu aye nitori ki ẹlẹṣẹ le ni aafo lati ronupiwada. Ta ni i ba là bi o ba jẹ pe Ọlọrun mu idajọ ṣẹ kankan lori olukuluku è̩ṣẹ ati aigbọran? Ninu è̩ṣẹ ni a bí gbogbo eniyan, wọn si ni lati ni iyipada ọkàn lati gbé igbesi-aye ailẹṣẹ. Oore-ọfẹ Ọlọrun, ipamọra ati aanu Rè̩ ni o n fara da a lati igba ti eniyan ti ni imọ è̩ṣẹ ati titi di akoko ti o ronupiwada.

Pẹlu ifẹ ailẹgbẹ ni Ọlọrun fi n boju wo ọkàn ọmọ-eniyan lati Ọrun wá. Apejuwe ti o le yé wa ni ti iru ifẹ ti baba ni si awọn ọmọ rè̩. Gẹgẹ bi baba ti n kọ ọmọ rè̩ lọgbọn, ti o si n fara da fun ọmọ rè̩ ti o rú ofin rè̩ ti o si n dariji i tọkantọkan nigba ti ọmọ naa ba ronupiwada, gẹgẹ bi baba ti n ṣe itọju ọmọ rè̩ nigba aisan, bẹẹ ni Baba wa Ọrun n ṣe itọju awọn ti o bẹru Rè̩. Ọlọrun mọ ẹda eniyan O si ranti pe erupẹ ni wọn i ṣe. O ranti pe igbesi-aye ọmọ eniyan kò duro pẹ titi. Onisaamu fi igbesi-aye wa niwaju Ọlọrun wé koriko igbẹ. Lonii, ododo rè̩ yọ itanna, ṣugbọn lọla o le ti rọ a si le ṣe alai ri i mọ; bẹẹ ni igbesi-aye ọmọ eniyan rí niwaju Ọlọrun, ṣugbọn ọkàn yoo wà laaye titi ayeraye.

Ki ni i ba jẹ ireti ọmọ eniyan bi ko ba ṣe ti ifẹ Ọlọrun Ẹni ti aanu Rè̩ wà lati irandiran fun gbogbo awọn ti o bẹru Rè̩? Ọmọ-eniyan kò ni ẹtọ si ifẹ Ọlọrun lọnakọna; sibẹ Ọlọrun ki i ṣe si awọn ti o ba yipada si I gẹgẹ bi aiṣedeedee wọn. Aanu n ṣogo lori idajọ gẹgẹ bi ọrun ti ga si ilẹ. Nigba ti Ọlọrun ba nu irekọja eniyan nù kuro, a o ko wọn lọ jinna rere – “bi ila-õrun ti jina si ìwọ-õrun.” Aanu Ọlọrun san ju igbesi-aye yii; nitori aye n kọja lọ, ṣugbọn aanu Ọlọrun wà titi lae. Pẹlu gbogbo ero iyebiye wọnyii ni ookan-aya Dafidi, eredi rè̩ ha kọ ni eyi ti Dafidi fi ké si gbogbo ẹda lati sin Ọlọrun? Gbogbo agbaye ni yoo jumọ kọrin iyin ati ọpẹ si Ọlọrun bi wọn ba le jẹ ki awọn ọrọ wọnyii wọ inu ọkàn wọn.

Isin Ifẹ

Boya ayọ ti o wa lọkan Dafidi kò mọ niwọn bi o ti n rọ gbogbo awọn iranṣẹ Ọlọrun lati fi iyin fun Ọlọrun; ki i ṣe nitori wọn n fẹ iwuri kan fun isin ifẹ wọn, ṣugbọn ki wọn le fi hàn fun gbogbo agbaye pe Ọlọrun ni iyin yẹ fun. Gbogbo iyin agbaye ati ti awọn angẹli Ọrun kò di Dafidi lọwọ lati fi iyin fun Ọlọrun. O pari Saamu yii gẹgẹ bi o ti bẹrẹ rẹ, “Fi ibukún fun OLUWA, iwọ ọkàn mi;” iro iyin rè̩ si Ọlọrun si lù bi agogo titi de opin igbesi-aye rè̩. O jẹ ohun iyebiye lati ni ọkàn ti o le fi iyin ti o ṣe itẹwọgba fun Ọlọrun; kò si ohun ti o le mu ibukún yii wá kankan si igbesi-aye eniyan bi iyin atọkanwa ati ọpẹ si Ọlọrun fun iṣeun ati aanu Rè̩ ailopin.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni idi pataki ti o mu ki Onisaamu fi ibukun fun Oluwa?
  2. Ki ni itumọ gbolohun yii, “Ẹniti o fi ohun didara té̩ ọ lọrun.”
  3. Anfaani wo ni o wa ninu jíjẹ “ohun didara” ti Ọlọrun?
  4. Bawo ni Ọlọrun ṣe n san ẹsan fun awọn ti a n ni lara bi wọn ba gbẹkẹ wọn le E?
  5. Ọna wo ni Oluwa gba fi ara Rè̩ hàn fun Mose ati awọn Ọmọ Israẹli?
  6. S̩e apejuwe ọkan ninu awọn ọna ti Ọlọrun gba n fi aanu hàn si awọn ọmọ eniyan.
  7. Ki ni n ṣẹlẹ si è̩ṣẹ eniyan nigba ti o ba ti ronupiwada?
  8. Bawo ni Onisaamu ṣe ṣapejuwe ọjọ aye kukuru ọmọ eniyan ni aye yii?
  9. Awọn ta ni n ri aanu Ọlọrun gbà?