Owe 31:10-31

Lesson 228 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Oju daradara li è̩tan, ẹwà si jasi asan: ṣugbọn obirin ti o bè̩ru OLUWA, on ni ki a fi iyin fun” (Owe 31:30).
Cross References

I Awọn Iwa ati Ọṣọ Iyawo Kristi

1 O jẹ ohun iyebiye ti o ṣọwọn, Owe 31:10; Isaiah 62:3; Deuteronomi 32:10; Luku 12:32; 18:8

2 O jẹ ẹni ti o ṣe é gbẹkẹle, Owe 31:11; 2 Awọn Ọba 12:15; 2 Kronika 34:11, 12; Nehemiah 7:2; Daniẹli 6:4; 1 Kọrinti 4:2; Ifihan 17:14

3 Olóòótọ ninu ohun ti i ṣe rere, Owe 31:12; Luku 19:17; Heberu 3:5; Ifihan 2:10

4 Oṣiṣẹ ti o n fi tinutinu ati tọkantọkan ṣiṣẹ, Owe 31:13, 24; Romu 12:11; 1 Kọrinti 4:10-12

5 O n gba agbara lati ọdọ Ọlọrun, Owe 31:14; Ẹksodu 15:2; Orin Dafidi 46:1; 73:26; 84:5; 89:21

6 O jẹ akikanju ninu iṣẹ rè̩ si Ọlọrun ati si eniyan, Owe 31:15; 22:29; Romu 12:6-8; Heberu 6:10-12

7 O n ṣe akiyesi ohun ti o lè ṣẹlẹ ni ọjọ iwaju, Owe 31:16; Heberu 11:8-16

8 O gbe ihamọra ti ẹmi wọ, Owe 31:17; 2 Kọrinti 6:7; 10:4; Ifihan 19:7; Efesu 6:13-17; 1 Tẹssalonika 5:8

9 O ni oye rere nipa Ọrọ Ọlọrun, Owe 31:18; 1 Kọrinti 2:9-16; Jakọbu 1:22-25

10 O wà ni ojúfò, o si n ṣọna fun bibọ Oluwa rè̩, Owe 31:18; 1 Tẹssalonika 5:8; Matteu 25:1, 4-7, 9, 10

11 O kún fun ifẹ ati ero rere fun awọn ẹlomiran, Owe 31:19, 20; 1 Johannu 3:16, 17; 2 Peteru 1:7; Jakọbu 1:27; Isaiah 58:6, 7; Iṣe Awọn Apọsteli 20:35; Romu 15:1; Galatia 6:2; 1 Peteru 3:8

12 O ni igbẹkẹle ninu Ọlọrun, Owe 31:21; Orin Dafidi 3:6; 20:7; 23:4

13 O wọ aṣọ ododo, Owe 31:22; Jobu 29:14; Ifihan 3:5; 7:14; 19:8; 21:2; Luku 15:22; Isaiah 61:10; Sẹkariah 3:4

14 O wà laaye fun Ọkọ rè̩; ifẹ rè̩ si wà ninu Rè̩, Owe 31:23; Romu 7:4; 2 Kọrinti 11:2; Ifihan 19:7; Luku 14:33

15 Gbogbo iwa Ọlọrun jé̩ ti rè̩, Owe 31:25; Efesu 5:23-27

16 O ni ireti ainipẹkun, Owe 31:25; 1 Kọrinti 15:19, 49-54; 1 Tẹssalonika 4:13-18

17 O pọ ni eso ti Ẹmi, Owe 31:26; 2 Peteru 1:5-8; Galatia 5:22, 23

18 O jẹ ajihin-rere fun awọn ti o wà lẹyin agbo, sibẹ o si tun n ṣe iranlọwọ fun awọn ti o wà ninu agbo, Owe 31:27; Ifihan 22:17; 2 Timoteu 4:1-5; 1 Peteru 5:2-4

19 O ri ojurere lọdọ Ọlọrun ati eniyan, Owe 31:28; Romu 8:16; Galatia 4:6, 7; Isaiah 62:5

20 O n gbe igbesi-aye ti kò ni ariwisi, Owe 31:29; 2 Peteru 3:14; 2 Kọrinti 6:3; 1 Timoteu 4:12; Titu 2:7-8

21 Kò gbẹkẹle iṣẹ ọwọ ara rè̩ fun igbala ọkàn rè̩, Owe 31:30; Romu 3:20; 11:6; Galatia 2:16; Efesu 2:8, 9; Titu 3:4, 5

22 O ni gbogbo ẹri Onigbagbọ, Owe 31:31; Johannu 15:1-16; Kolosse 1:10; Filippi 1:11.

Notes
ALAYE

A yan apa kan Iwe Owe ori ikọkanlelọgbọn fun ẹkọ Ọjọ awọn Iya fun ọdun yii. A fi ibeere yii siwaju wa, “Tani yio ri obinrin oni iwa- rere?” Gbogbo amuyẹ ti obinrin oni iwa-rere ní ni a darukọ ninu awọn ẹsẹ ọrọ wọnyii. Wọn n sọ nipa iwa ti ojulowo obinrin ni lati ni. Aye yii i ba ti dara to bi olukuluku obinrin ba le fi awọn ọrọ ti o wà ninu ẹsẹ Ọrọ Ọlọrun yii diwọn igbesi-aye rẹ!

Ọjọgbọn kan nigba ni sọ fun ni pe iwa iya John ati Charles Wesley bá Ọrọ Ọlọrun mu. O ṣe akiyesi igbesi-aye obinrin naa lati igba ibi rè̩ titi de igba iku rè̩, o si ta gbogbo obinrin yọ.

Ninu iran ti wa yii a ti ri obinrin kan ti igbesi-aye rè̩ ta gbogbo ti awọn iya miiran yọ. Obinrin naa ni a n pè ni Florence L. Crawford, ẹni ti o dá Ijọ Apostolic Faith silẹ. Igbesi-aye rè̩ gẹgẹ bi iya ati alakoso fi apẹẹrẹ giga silẹ fun awọn iya ti ode-oni. Owe ori kọkanlelọgbọn yii jẹ ibi kan ninu Ọrọ Ọlọrun ti o ni ifẹ si lọpọlọpọ. O si n lo o nigba pupọ lati kọ ni lé̩kọọ ati lati waasu lori Iyawo Kristi.

Lootọ, apejuwe ti o wà ninu ori iwe yii n tọka si obinrin; ṣugbọn a gbagbọ pe itumọ rè̩ nipa ti ẹmi n tọka si Iyawo Kristi, eyi ti o kó ọkunrin ati obinrin pọ.

Ibi titun

Iṣisẹ kin-in-ni ti a ni lati gbe ki a to di obinrin oni iwa-rere ati Iyawo Kristi ni lati ni ibi titun, nipa eyi ti Ẹjẹ Jesu n wẹ ọkàn mọ kuro ninu è̩ṣẹ. Ẹmi Ọlọrun n ra ọkàn pada o si n sọ ọ di aaye. Eyi tayọ pe ki a ni ipinnu lati sin Kristi. O tayọ pe ki a “yí iwa pada.” Iriri iṣẹ ti Ẹjẹ Jesu ṣe ninu ọkàn ni. Ẹṣẹ a kuro, igbesi-aye titun a si bẹrẹ. Lai si iriri ibi titun yii, è̩ṣẹ yoo jọba ninu ọkàn ko si ni ṣe e ṣe lati gbe igbesi-aye iwa-bi-Ọlọrun ti awọn ẹsẹ Ọrọ Ọlọrun yii là silẹ. Nigba ti a ba ti pa è̩ṣẹ run ti ọkàn si di mimọ, ọkan naa yoo bẹrẹ ire-ije rè̩ si ipè giga ti Ọlọrun pè é si ninu Kristi Jesu.

Iwa Rere ti Ẹmi

Peteru kọ wa lé̩kọọ nipa bi a ṣe le ni awọn iwa rere wọnyii. “Bi agbara rè̩ bi Ọlọrun ti fun wa li ohun gbogbo ti iṣe ti iye ati iwa-bi-Ọlọrun, nipa imọ ẹniti o pè wa nipa ogo ati ọlanla rè̩: nipa eyiti o ti fi awọn ileri rè̩ ti o tobi pupọ ti o si ṣe iyebiye fun wa: pe nipa iwọnyi ni ki ẹnyin ki o le di alabapin ninu iwa Ọlọrun, nigbati ẹnyin ba ti yọ kuro ninu ibajẹ ti mbẹ ninu aye nipa ifẹkufẹ. Ati nitori eyi nā pāpā, ẹ mā ṣe aisimi gbogbo, ẹ fi iwarere kún igbagbọ, ati imọ kún iwarere; ati airekọja kún imọ; ati sru kún airekọja; ati iwa-bi-Ọlọrun kún sru; ati ifẹ ọmọnikeji kún iwa-bi-Ọlọrun; ati ifẹni kún ifẹ ọmọnikeji” (2 Peteru 1:3-7).

Igbẹkẹle

“Aiya ọkọ rè̩ gbẹkẹle e laibè̩ru.” Eniyan ṣoro gbẹkẹle lode oni. Ogunlọgọ ọkunrin ni o lọ si ogun lati jà fún ilu wọn, ni akoko ogun ti o kọja yii, ṣugbọn wọn pada de lati ri i pe ifẹ awọn iyawo wọn ti fà si awọn ọkunrin miiran. Iyawo Kristi ṣe e gbẹkẹle. Bi Jesu tilẹ fa bibọ Rè̩ sẹyin, Iyawo Kristi yoo jé̩ olóòótọ. Oun ko ni fi awọn ti o ti ba ara wọn jẹ ṣe.

Isin Atọkanwa

“Obinrin na yio ma ṣafẹri kubusu ati ọgbọ, o si fi ọwọ rè̩ ṣiṣẹ tinutinu.” Iyawo Kristi jẹ alaapọn. Paulu n pa agọ ninu eyi ti o fi n bọ ara rè̩ ati awọn alabaṣiṣẹpọ pẹlu rè̩. Bi o ti n ṣiṣẹ ni o n waasu Kristi fun awọn abọriṣa igba nì.

Pupọ ninu awọn ọmọ Ọlọrun laaarin wa ni o n fi gbogbo ọsán ṣiṣẹ, wọn a si sare wá si ipade aṣaalẹ ki wọn ba le ni anfaani lati jade lọ si opopo ati abuja ọna, lati sọ itan Jesu fun awọn eniyan ti n lọ ti n bọ. Bakan naa ni o ri ni gbogbo iṣẹ ti a n ṣe. Gbogbo ọsan ni awọn olorin wa fi n ṣiṣẹ oojọ wọn ati ni irọlẹ wọn a maa lo talẹnti wọn lati tan Ihinrere kalẹ ninu orin kikọ ati lilo awọn ohun-elo orin, eyi ti i ṣe ọrẹ atinuwa si Ọlọrun. Nigba ti ọkọ oju omi wa ti a fi n ṣe iṣẹ itankalẹ Ihinrere ba kó awọn ajihinrere lọ si idalẹ, gbogbo awọn oṣiṣẹ inu ọkọ naa ni o n fi taratara ṣiṣẹ. Ko si “alairiṣe” kan ninu ọkọ. Aafo iṣẹ pupọ ni awọn iranṣẹ Kristi ti wọn fi tinutinu yọọda ara wọn dí. A n bẹ awọn alaisan wò a si n sọ ọrọ itunu fun wọn, a n tẹ iwe kéékèèké ti o n sọ nipa ifẹ Ọlọrun a si n pin in fun awọn eniyan tabi ki a fi ranṣẹ si wọn, a n tun ile Ọlọrun ṣe ki o le mọ, ki o si le fani mọra. Diẹ ninu awọn nnkan ti a n ṣe ni wọnyii.

“O dabi ọkọ oniṣowo: o si mu onjẹ rè̩ lati ọna jijin rére wá.” Manna Ọrun ni ounjẹ rè̩. Jesu wi fun awọn ọmọ-è̩yìn nigba kan pe Oun ní ounjẹ kan ti wọn kò mọ. Nigba ti awọn ọmọ-è̩yìn Rè̩ fi I silẹ lati lọ ra ounjẹ, O jokoo lẹba kanga Jakọbu O si bẹrẹ si ba ọkàn kan ti oungbẹ n gbẹ sọrọ nipa Omi Iye.

Ẹni ti o ba n gba ounjẹ ẹmi lati Ọrun wá a maa wà ni imurasilẹ lọsan tabi loru lati dide lati bẹ awọn alaisan tabi awọn alaini wò tabi lati ṣe oniruuru iṣẹ ti o ba kàn lati ṣe. “Nigbati a ri ọrọ rẹ, emi si jẹ wọn” (Jeremiah 15:16).

Oko Eleso

Iyawo Kristi a maa foju silẹ nigba gbogbo lati wá ilẹ eleso fun Ihinrere. Nigba ti o ba ri ilẹ ọlọra, a yẹ ẹ wo, a si rà á. O dá aṣọ ọgbọ daradara, o si tà á ki o ba le ri owó lati ra ilẹ eleso naa. Lẹyin eyi; a jade lọ lati gbin ọgba ajara. Yoo si fi tọkantọkan ṣiṣẹ lati kọ ile Ọlọrun ki o ba le fi idi Ihinrere mulẹ ni ilẹ eleso naa. O fi agbara di ara rè̩ ni amurè; bi ọta tilẹ dide bi iṣan omi, o lagbara lati kọjuja si ogun ọrun apaadi.

Iji Ipọnju

“On kò si bè̩ru òjo-didi fun awọn ara ile rè̩; nitoripe gbogbo awọn ara ile rè̩ li a wọ li aṣọ iṣẹpo meji.” Afẹfẹ le ṣọwọ odi, ipọnju le de; ṣugbọn o ti wà ni imurasilẹ fun wọn. O n kọ ile igbagbọ rè̩ lọna ti o le fi dojukọ awọn iṣoro aye. Ibẹru kò sí ninu ọkàn rè̩. O le kọrin nigba iṣoro; nitori o mọ pe ohun gbogbo ni o n ṣiṣẹ pọ si rere fun awọn ti o fé̩ Oluwa.

Ọgbọn ati Iṣeun

“O fi ọgbọn yà ẹnu rè̩; ati li ahọn rè̩ li ofin iṣeun.” Boya eyi ni ẹbun ti o ta gbogbo awọn iyoku yọ. Iba eniyan diẹ ni o ni ẹbun yii. Alabukun-fun ni ọkunrin tabi obinrin ti a ba le sọ eyi nipa ti rè̩. Eyi le jẹ ipin rẹ nipa oore-ọfẹ Ọlọrun.

“Oluranlọwọ”

“A mọ ọkọ rè̩ li ẹnu-bode, nigbati o ba joko pẹlu awọn àgba ilẹ na.” O fi ọlá ati iyi fun ọkọ rè̩ o si ti ṣe rere fun un ki i si ṣe buburu ni ọjọ aye rè̩ gbogbo. O ti ṣe ojuṣe ti Ọlọrun dá a fun lati ṣe -- oluranlọwọ fun ọkunrin. “Obinrin oniwa-rere li ade ọkọ rè̩” (Owe 12:4).

Ni ọna kan naa ni gbogbo ifẹ Iyawo Kristi wà ninu Kristi. Iwa mimọ Ọlọrun ti o fara hàn ni igbesi-aye rè̩ a maa mu ki awọn eniyan fi ọlá ati iyin fun Kristi.

Imoore

“Awọn ọmọ rè̩ dide, nwọn si pè e li alabukúnfun.” Kaakiri gbogbo orilẹ-ede wa ni ọjọ oni ni gbogbo awọn ọdọmọde n fi imoore wọn hàn si iya wọn. Bi wọn ba ni iya ẹni iwa-bi-Ọlọrun, wọn ni ogún rere ti o niyelori ju fadaka tabi wura, ile tabi ilẹ lọ; ko si si ohun ti o pọ ju fun wọn lati fi ta iya wọn lọrẹ. S̩ugbọn o ṣe ni laanu pe ọpọlọpọ ọdọmọde ni kò ni anfaani yii. Lati nnkan bi aadọta ọdun sẹyin ni ọpọlọpọ awọn iya ti n yipada kuro ninu ọna iwa mimọ ati igbesi-aye ailẹgan, ti wọn si ti di ọmuti, amutaba, ti wọn si n jẹ aye ijẹkujẹ. Ibi ti igbesi-aye bẹẹ n mu wá hàn gbangba ninu awọn ọmọ wọn ati ogunlọgọ ọdọmọkunrin ati ọdọmọbinrin ode-oni. Owe laelae ni ti o wi pe, “Ọwọ abiyamọ ti n gbé ọmọ jó ni o n ṣakoso ayé” fi agbara ti wọn ni hàn nigba ti è̩ṣẹ gbilẹ tabi nigba ti otitọ ba leke.

Ẹwà Asan

“Oju daradara li è̩tan, ẹwà si jasi asan.” Ọpọlọpọ obinrin ni o n fi ohun aye yii ṣe ara wọn lọṣọ, lati fi hàn fun awọn eniyan pe wọn lẹwà; ṣugbọn ninu lọhun, ọkàn wọn kún fun è̩tan ju ohun gbogbo lọ o si buru jai. Eniyan n wo oju ṣugbọn Ọlọrun n wo ọkàn. Obinrin ti i ṣe Onigbagbọ tootọ kún fun oore-ọfẹ ti o n fun ọkàn ni itura, ti o n mu ọkàn mọ, ti o si n ṣe akoso iwà ati iṣe, ani oore-ọfẹ ti o n fun ọkàn ni ọṣọ ti inu ti i ṣe iwà tutu ati suuru, eyi ti i ṣe iyebiye niwaju Ọlọrun.

Iyin

Iyawo Kristi n foju sọna pẹlu ayọ o si n fi irẹlẹ dupẹ fun ere ti yoo gbà nigba ti o ba pade Oluwa rè̩ ni awọsanma. Èso ọwọ rè̩, talẹnti ti o ti jere ati igbesi-aye ti o ti gbé yoo “yìn i li ẹnu-bode.”

“Tani yio ri obinrin oni iwa-rere? nitoriti iye rè̩ kọja iyùn.”

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ta ni obinrin oni iwa-rere yii duro fún?
  2. Ki ni iye rè̩?
  3. Nibo ni o gbé n ri ounjẹ rè̩?
  4. Bawo ni o ṣe n gbin ọgbà ajara?
  5. Ki ni ṣe ti ko bẹru ojo dídì?
  6. Ki ni o fi ṣe ara rè̩ ni ọṣọ?
  7. Ki ni a sọ ninu ẹkọ wa nipa ẹwà?
  8. Ta ni fi iyin fun obinrin oni iwa-rere yii?