2 Samuẹli 2:1-7, 11; 5:1-5; 6:1-15, 17

Lesson 229 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “OLUWA ti yàn Sioni; o ti fẹ ẹ fun ibujoko rè̩” (Orin Dafidi 132:13).
Cross References

I Dafidi Kọja lọ si Hebroni

1 Lẹyin iku Saulu, Dafidi beere lọwọ Oluwa bi oun le pada si ilẹ Israẹli, 2 Samuẹli 2:1-3; 1 Samuẹli 30:8; 1 Kronika 14:10, 14-16

2 A fi ororo yan Dafidi lọba lori Juda ni Hebroni, nibi ti o gbe jọba ọdun meje aabọ, 2 Samuẹli 2:4, 11

3 A rán iṣẹ iwuri si awọn ọkunrin Jabeṣi-gileadi fun aanu ti wọn fi hàn fun Saulu, 2 Samuẹli 2:5; 1 Samuẹli 31:11-13

II Ọba lori Gbogbo Israẹli

1 Awọn ẹya Israẹli rán awọn aṣoju lati fi imọ ṣọkan pẹlu Dafidi ati lati yàn án lọba lori gbogbo eniyan, 2 Samuẹli 5:1-3; 1 Samuẹli 16:1, 12, 13; 1 Kronika 12:23-40; Iṣe Awọn Apọsteli 13:22

2 Gbogbo ọjọ ti Dafidi fi jọba jé̩ ogoji ọdun, 2 Samuẹli 5:4, 5

3 Jerusalẹmu di olu-ilu Israẹli, 2 Samuẹli 5:5-9

III Ero nipa Apoti-ẹri Ọlọrun

1 Ẹgbaa-mẹẹdogun ọkunrin bá Dafidi lọ lati gbé Apoti-ẹri pada kuro ni ile Abinadabu, 2 Samuẹli 6:1-4; 1 Samuẹli 7:1; 1 Kronika 13:1-8

2 A ké ọkunrin kan lulẹ nitori o gbá Apoti-ẹri naa mú, 2 Samuẹli 6:5-8; Numeri 4:15; 1 Kronika 13:9, 10

3 Dafidi bẹru lati gbé Apoti-ẹri naa wá si ilu rè̩, 2 Samuẹli 6:9-11; 1 Kronika 13:12; Orin Dafidi 119:120

4 Apoti-ẹri fa ọpọ ibukun wá fun wọn, nitori eyi, Dafidi mu aya le lati gbé e pada wá si Ilu Dafidi, 2 Samuẹli 6:12-15

5 A gbé Apoti-ẹri sinu agọ kan ti Dafidi ti pese silẹ fun un, 2 Samuẹli 6:17; 1 Kronika 15:1; 16:1

Notes
ALAYE

Mímọ Ifẹ Ọlọrun

Nigba ti Dafidi gbọ pe Saulu ti kú nigba ti o ba awọn Filistini jà, kò si ayọ ninu ọkàn Dafidi bi kò ṣe ibinujẹ kikoro. “Máṣe yọ nigbati ọta rẹ ba ṣubu, má si ṣe jẹki inu rẹ ki o dùn nigbati o ba kọsè̩” (Owe 24:17). Ko si è̩tan ninu ibanujẹ ti Dafidi ni fun Saulu; ọkàn kan ti tun lọ si ọrun egbe. Olóòótọ Onigbagbọ kò le fẹ ki eyi jẹ ipin ọta rè̩ ti o buru ju lọ.

Nipa igbagbọ Dafidi mọ daju pe ni ọjọ kan, lọna kan, Oluwa yoo mú Saulu kuro lori oyè; ṣugbọn nigba ti igbagbọ naa di riri, Dafidi duro pẹlu ibẹru nitori idajọ Ọlọrun. Oun kò fi ikanju bé̩ siwaju lati fi agbara rè̩ hàn, lati gba ijọba Israẹli bi o tilẹ jẹ pe Samuẹli, nipa itọni Ọlọrun, ti fi ororo yàn án fun ipò yii ni ọpọlọpọ ọdun sẹyìn. Igbagbọ kan naa ti o ti Dafidi lẹyin ni gbogbo ọdun ti o fi duro jẹẹ ni o tun fi si i lọkan nisisiyii pe Oluwa ti o ti bẹrẹ iṣẹ Rè̩ yoo ṣe e de opin. Sibẹ Dafidi beere lọwọ Oluwa ohun ti o yẹ ki oun ki o ṣe. Oun ko tè̩ si ọtun tabi si osi titi o fi mọ inu Ọlọrun rè̩. Igbagbọ tootọ kò fi hàn pe Onigbagbọ kò jafafa nigba ti o ba lọra lati ṣe ohunkohun; ṣugbọn igbagbọ tootọ a maa mú suuru de Oluwa, a si maa tè̩ siwaju nigba ti o ba ti mọ inu Oluwa.

Awọn ohun miiran hàn gbangba ninu eto Ọlọrun fun awọn ọmọ Rè̩, bí i idalare, isọdimimọ, ifiwọni Ẹmi Mimọ, ati agbara Ọlọrun lati wo olokunrun sàn nipa igbagbọ. Oore-ọfẹ ati ẹbun wọnyii wà fun gbogbo awọn ti a ba pe wá sinu Ihinrere a si ni lati fi tinutinu wá wọn titi a o fi ri wọn gbà; sibẹ awọn ipò ati ipè miiran wà fun awọn ti o ba duro de Oluwa ninu adura gbigba ati ifi-ara-rubọ. Ibi ti o dara ju lọ laye yii fun ọkàn kọọkan ni lati wà ninu ifẹ Ọlọrun. Ọpọlọpọ ni o fẹ lati mọ ifẹ Rè̩, ṣugbọn wọn kò sunmọ Ọn ninu adura pẹlu ifi-ara-rubọ ati ọkàn ti o ṣipaya si Ọlọrun to bẹẹ ti Oun yoo fi le maa fi ifẹ Rè̩ hàn fun wọn nigbakuugba. Ayọ Ọrun ninu aye ni lati mọ ifẹ Ọlọrun ati lati ṣe e. Dafidi mọ pe ipe oun sori oyè ki i ṣe ipe kan lasan, o si mọ pe o tọ ki ifẹ Ọlọrun fara han gbangba ki oun to le tè̩ siwaju.

Ririn ninu Imọlẹ

Dafidi ati ẹgbẹta ọmọ-ogun wà ni ilẹ awọn Filistini nigba ti wọn gbọ ikú Saulu. Ọlọrun jẹ olóòótọ si ibeere Dafidi O si paṣẹ fun un lati pada si ilẹ Israẹli, si ilu Hebroni. Ninu ilu atijọ yii, nibi ti Abrahamu ti gbe ri, nibi ti a gbe sin aya rè̩ Sara si, nibẹ ni awọn ọkunrin ẹya Juda pejọ pọ si ti wọn si fi ororo yan Dafidi lọba lori ile Juda. Lotitọ ohun ti ẹya Juda ṣe yii jẹ ifẹsẹmulẹ ifororoyan ti Dafidi ti ri gbà lọwọ Ọlọrun nipasẹ Samuẹli. Ẹnikẹni ti o ba n rin ninu imọlẹ Ọrọ Mimọ Ọlọrun yoo maa ri imuṣẹ ileri Ọlọrun lati igba de igba.

A le wi pe ijọba Juda jẹ apa kan ileri ti Ọlọrun ṣe fun Dafidi. Otitọ ni eyi, ṣugbọn ki i ṣe dandan ki gbogbo ileri Ọlọrun ṣẹ ni akọbẹrẹ igbesi-aye wa tabi ni ibẹrẹ ajo wa bi Onigbagbọ. Oluwa ninu ọgbọn Rè̩ le dá imuṣẹ apa kan ileri tabi ibukun kan duro ki Oun ba le kọ wa ni ẹkọ iyebiye, ki O si ṣe wa ni “ohun èlo. . . . . ti o si yẹ fun ìlo bāle.” Ọpọlọpọ ẹkọ ni o kù fun Dafidi lati kọ ki Ọlọrun to yọọda fun un lati jọba lori Israẹli. O ti kọ nipa ogun jija ati bi a ti n ṣe ọgagun nigba ti Saulu n lepa rè̩; nisisiyii, nipa ijọba kekere yii, Ọlọrun n kọ Dafidi bi a ti n lo agbara ati aṣẹ. Olukuluku ọmọ Ọlọrun ni a pe lati kẹkọọ - lati la idanwo ati iyiiriwo kọja – eyi ti yoo ṣe wọn yẹ fun ilana Oluwa.

Awọn Akọni Ọmọ-ogun Ọlọrun

A pe Dafidi lati ibi ti o ti n ṣọ agbo-agutan baba rè̩ lati jẹ oluṣọ-agutan Israẹli; pupọ ninu awọn Apọsteli ni a pè lati ibi iṣẹ apẹja lati di apẹja eniyan; ati pẹlu ni akoko yii, Ọlọrun n pe oniruuru eniyan lati jẹ “ọba ati alufa fun Ọlọrun.” Ọna si isin Ọlọrun ati Ijọba ki i yipada -- ọna tooro ati hiha. Bi Dafidi ba kọ igbọran nipa fifi ara da iṣoro; bi awọn Apọsteli ati awọn akọni ninu igbagbọ ba di alagbara ninu ailera, idojukọ ati inunibini (Heberu 11:34); Onigbagbọ ha ṣe le ni ireti lati wọ ẹnu ibode pearli Ọlọrun lai tọ apa kan ninu awọn nnkan wọnyii wò? Ọlọrun n lo ọna kan naa lonii lati sọ awọn ọmọ-ogun Rè̩ di akọni ninu ija igbagbọ.

“Bi awa ba farada, awa ó si ba a jọba” (2 Timoteu 2:12). S̩ugbọn iriri Onigbagbọ ki i ṣe kiki ipọnju. Ere ijolootọ wà niwaju fun awọn ọmọ-ogun Ọlọrun. Awọn aṣẹgun yoo wà laaye, wọn yoo si jọba pẹlu Kristi ni ẹgbẹrun ọdun ninu ayé yii (Wo Ifihan 20:4). O le gba pe ki a mu suuru ki a to le ri imuṣẹ gbogbo ileri Ọlọrun ni igbesi-aye olukuluku, ṣugbọn ọkàn ti o ba ni igbagbọ ati igbẹkẹle ninu Ọlọrun ti ri koko ileri ogun ti rẹ gbà ná. “OLUWA yio fun ni li ore-ọfẹ ati ogo: kò si ohun rere ti yio fà sẹhin lọwọ awọn ti nrìn dede” (Orin Dafidi 84:11).

Dafidi gẹgẹ bi Ọba

Nigba ti a ba yan ẹni kan ni ọba dipo ẹni ti o ti n jọba tẹlẹ ri, ni ọpọlọpọ igba, ohun ti yoo kọ ṣe ni lati lé awọn ti o ba ni ẹtọ si oyè naa jade kuro ni ilu. Ni aye igba nì ki i ṣe pe a ka eyi si ohun ti o tọ ti o si yẹ nikan ṣugbọn a ka a si pe o ṣe dandan lati pa gbogbo awọn ti wọn le fé̩ du oyè ọba tabi ti wọn le jé̩ elewu fun ọba ti o jẹ. S̩ugbọn Dafidi ki i ṣe iru eniyan bayii nitori ko gbe ọwọ rè̩ soke si idile Saulu. Abneri, olori-ogun Saulu fi ororo yan ọkan ninu awọn ọmọ Saulu ni ọba dipo baba rè̩; ṣugbọn “agbara Dafidi si npọ si i, ṣugbọn idile Saulu nrè̩hin si” (2 Samuẹli 3:1). Dafidi jọba fun ọdun meje ati oṣu mẹfa ni Hebroni ṣugbọn lopin akoko yii, Oluwa ti pa gbogbo ẹya Israẹli pọ ṣọkan labẹ akoso Dafidi; lọna bayii ni Ọlọrun mu ileri Rè̩ ti o ṣe fun Dafidi ṣẹ.

Ki o ba le ṣe e ṣe fun ijọba Israẹli lati papọ ṣọkan, Oluwa fi aye silẹ fun ikú Abneri, ati ti Iṣboṣeti ọmọ Saulu ẹni ti Abneri fi jọba lori Israẹli. Nigba ti awọn Ọmọ Israẹli ri i pe kò si atilẹyin mọ fun ile Saulu, wọn tọ Dafidi wa si Hebroni lati fi jọba. Wọn ranti pe Dafidi ni olori-ogun wọn ni ọdun diẹ sẹyin ati pe Ọlọrun ti ṣeleri fun Dafidi pe, “Iwọ o bọ Israẹli awọn enia mi, iwọ o si jẹ olori fun Israẹli.” Gbogbo awọn agba si ṣe adehun pẹlu Dafidi ni Hebroni niwaju Oluwa, wọn si fi ororo yan Dafidi ni ọba Israẹli. Inu gbogbo eniyan si dùn.

Ijọba Ọrun, ti i ṣe ijọba Ọmọ Dafidi gẹgẹ bi iran Rè̩ nipa ti ara, fara jọ ijọba Dafidi lọna pupọ. A fi ororo yan Dafidi ni ọba ni ọdun pupọ sẹyin ki o to di pe a mu ileri naa ṣẹ. Lọna kan, a le wi pe, gbogbo awọn eniyan Israẹli fi ohun kan wi pe, “Awa kò fẹ ki ọkunrin yi jọba lori wa,” o si ri i pe yoo ṣe anfaani lati sá kuro ni ilẹ Israẹli lati sá asala fun ẹmi rè̩. Igbagbọ Dafidi ninu Ọlọrun kò yẹ, akoko naa si dé ti Oluwa bukun fun un siwaju ati siwaju to bẹẹ ti gbogbo Israẹli fi di ijọba rè̩. Ọnakọna ni Eṣu ati awọn alaṣẹ ibi okunkun ti gbà lati dojukọ ijọba Jesu. Gbogbo awọn olugbe aye yii ti ṣọtẹ si Ọmọ Ọlọrun, wọn kò fẹ juba Rè̩; sibẹ, Ijọba Rè̩ n lọ lati ipá de ipá. Lonii, o le dabi ẹni pe agbara Eṣu n gbilẹ, ṣugbọn wakati naa n bọ lai pẹ jọjọ, nigba ti idà lati ẹnu Kristi yoo fọ itẹgun eṣu. A o si mọ Jesu ni ọjọ naa gẹgẹ bi i “ỌBA AWỌN ỌBA ati OLUWA AWỌN OLUWA” (Ifihan 19:16). Gbogbo ẹda ni aye yoo yọ lati sin In ati lati juba Rè̩. Bi awọn eniyan Israẹli ba yọ nitori ọba aye, ayọ awọn eniyan mimọ Ọlọrun yoo ti pọ tó ninu Ọba wọn Ọrun.

Apoti Majẹmu

Bi a ti n kẹkọọ nipa igbesi-aye Dafidi ọba, a o ri i pe ohun rere ti o tayọ ju lọ ninu igbesi-aye rè̩ ni ọkàn ailẹtan ti o fun un ni anfaani lati mọ Ọlọrun gẹgẹ bi Ọba ti O ga ju lọ ati oun paapaa gẹgẹ bi iriju Ijọba ninu aye. Dafidi rii pe olu-ilu orilẹ-ède ni lati jé̩ ilu Ọlọrun ati olu ibujoko fun isin ti i ṣe anfaani ti awọn Ọmọ Israẹli ní. Agọ ti o wà ni S̩ilo ti di ikọsilẹ fun ọpọ ọdun; bẹẹ si ni Apoti Majẹmu, lẹyin idapadabọ rè̩ lati ilẹ awọn Filistini, ti fẹrẹ di ohun igbagbe si ile Abinadabu nibi ti wọn gbe e si. Nigba ti Dafidi jẹ ọba lori gbogbo ẹya Israẹli, ọkàn rè̩ bẹrẹ si fà lati gbé Apoti-ẹri Ọlọrun wá si ilu Jerusalẹmu. O kó ẹgbaamẹẹdogun aṣayan ọkunrin jọ pẹlu rè̩ lati gbe Apoti-ẹri naa wá si Jerusalẹmu ti awọn ti orin ayọ.

Ohun danindanin ni lati ṣe ohun gbogbo gẹgẹ bi itọni Ọlọrun bi awọn eniyan ba fẹ ri ojurere Ọlọrun ni igbesi-aye wọn. Bi o ba ṣe pe awọn Ọmọ Israẹli ti fara balẹ lati ka Ọrọ Ọlọrun ni akoko yii, wọn i ba ti mọ pe ohun ti o yẹ ni lati fi nnkan bo Apoti-ẹri ki awọn eniyan má ba bojuwo o, ati pe awọn ọmọ Lefi ni lati fi ọpa gbe e lejika wọn. Ẹnikẹni kò gbọdọ fi ọwọ kan Apoti-ẹri tabi ohun mimọ afi awọn alufaa ti n jọsin ninu agọ, ẹni ti o ba fọwọkan an, yoo kú.

Awọn Filistini dá Apoti-ẹri naa pada fun awọn Ọmọ Israẹli lori kẹkẹ titun. Dafidi ati awọn eniyan rè̩ ko naani ofin Ọlọrun, wọn si gbiyanju lati gbe Apoti-ẹri ni ọna kan naa lati ile Abinadabu lọ si ilu Jerusalẹmu. Bi awọn eniyan naa ti n lọ lọna, awọn maluu ti n wọ kẹkẹ kọsẹ, Apoti-ẹri naa si sún siwaju. Loju kan naa, Ussa ti n ṣe itọju Apoti-ẹri na ọwọ rè̩ lati tun un ṣe, ṣugbọn eyi bi Ọlọrun ninu nitori ohun ti o ṣe yii lodi si aṣẹ Ọlọrun. Ọlọrun lu u pa nibẹ nitori aṣiṣe rè̩. Inu Dafidi bajẹ nitori ikú Ussa, o si bè̩ru lati gbé Apoti-ẹri naa wá si Jerusalẹmu. Awọn eniyan naa si yà si ile Obedi-Edomu, wọn si gbé Apoti-ẹri naa sibẹ.

Gbigba Ibukun

Ọlọrun bukun ile Obedi-Edomu lakoko ti Apoti-ẹri fi wà nibẹ. Bi a ba lo nnkan Ọlọrun lọna ẹtọ ti a si bu ọla fun un, ibukun Oluwa a maa tẹle e. Ifẹ Dafidi ni ki Apoti-ẹri naa ki o le wà pẹlu rè̩ ni Jerusalẹmu; bi o si ti ri i pe a bukun Obedi-Edomu nitori Apoti naa, o pinnu lati gbe Apoti-ẹri naa lati ile Obedi-Edomu wá si Jerusalẹmu. Awọn ọmọ Lefi si ru Apoti-ẹri naa lejika wọn, ni igba keji yii, ibukun Ọlọrun si wá sori gbogbo awọn eniyan naa. Wọn gbe Apoti-ẹri naa wa si Jerusalẹmu pẹlu ihó ayọ ati pẹlu iró ipè, wọn si gbe e kalẹ ni àyè rè̩ ninu agọ ti Dafidi pa fun un.

Ohun ti o ṣẹlẹ yii ni lati jé̩ ikilọ ọtun fun gbogbo eniyan pe Ọlọrun Ọrun n ṣe akiyesi ohun gbogbo kinnikinni. O fi han bi o ti ṣe rọrun to lati ṣi ẹsè̩ gbé - lati yà kuro ninu aṣẹ Oluwa ati ijiya nla ti o n tẹle iru iwà bẹẹ. Bi Oluwa ba n ṣe ọfintoto nipa isin Dafidi, njẹ Oluwa kò ha n ṣe akiyesi irin Onigbagbọ lonii? O fi han bi o ti jẹ ohun danindanin to lati ni Oluwa ni ọdọ wa lati maa tọ iṣisẹ wa ni gbogbo akoko. Bi awọn eniyan ba tọ ipasẹ Kristi ti wọn si n tẹle gbogbo itọni Rè̩, wọn yoo ni idaniloju aṣeyọri ni ọna iwà mimọ, ilẹkun yoo si ṣí silẹ fun wọn nigba ti wọn ba de Ọrun.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Nibo ni Dafidi wà nigba ti o gbọ nipa ikú Saulu?
  2. Ki ni Dafidi ṣe ki o to lọ? ilu wo ni o si lọ?
  3. Ta ni wá si ilu naa? Ki ni ohun ti wọn ṣe?
  4. O to ọdun meloo ki gbogbo Ọmọ Israẹli to fi ororo yan Dafidi ni ọba?
  5. Ilu wo ni Dafidi yàn lati fi ṣe olu-ilu rè̩?
  6. Ki ni ṣe ti Dafidi ṣe fẹ ki Apoti Majẹmu wà ni ilu ti oun wà?
  7. Ki ni ṣe ti Oluwa fi lu Ussa ti o si kú?
  8. Bawo ni a ṣe gbe Apoti Majẹmu wá si Jerusalẹmu nikẹyin?
  9. Ẹkọ wo ni a ri kọ ninu apẹẹrẹ yii?