2 Samuẹli 7:1-29; Orin Dafidi 30:1; Isaiah 66:1, 2

Lesson 230 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Bayi ni OLUWA wi, pe, Ọrun ni ité̩ mi, aiye si ni apoti itisè̩ mi: nibo ni ile ti ẹ kọ fun mi gbe wà? ati nibo ni isimi mi gbe wà?” (Isaiah 66:1).
Cross References

I Ibeere Dafidi ati Idahun Rè̩

1 Ọkan Dafidi kò balẹ lakoko irọra rè̩ nitori ibugbe ti rè̩ dara ju ti Apoti-ẹri lọ, 2 Samuẹli 7:1, 2; 5:11; 6:17; 1 Kronika 17:1; Orin Dafidi 30:1

2 Natani, gẹgẹ bi eniyan Ọlọrun, gba Dafidi niyanju lati kọ Tẹmpili kan fun ijọsin, 2 Samuẹli 7:3; 1 Kronika 17:2

3 Natani, gẹgẹ bi Wolii Ọlọrun, gba aṣẹ Ọlọrun nipa Tẹmpili naa, 2 Samuẹli 7:4; 1 Kronika 17:3

II Iṣẹ ti Ọlọrun Rán si Dafidi

1 Ọlọrun kò paṣẹ pe ki o kọ Tẹmpili, 2 Samuẹli 7:5-7; Isaiah 66:1, 2; Johannu 4:20-24; 1 Kronika 17:4-6; Iṣe Awọn Apọsteli 7:48-50

2 Ọlọrun yin Dafidi fun ifẹ ọkàn rè̩ lati kọ Tẹmpili naa, 1 Awọn Ọba 8:18; 2 Kronika 6:7, 8

3 Ọlọrun pe Dafidi lati jé̩ ologun, ki i ṣe lati kọ Ile Alaafia, 2 Samuẹli 7:8, 9; 1 Kronika 17:7, 8; 22:7-10; Romu 11:29; 1 Kọrinti 7:20; 12:28; Efesu 4:11

4 A kò gba Dafidi laye lati kọ Tẹmpili nitori Ọlọrun ni eto giga miiran fun un ati fun gbogbo Israẹli, nipasẹ rè̩, 2 Samuẹli 7:10; 1 Awọn Ọba 8:16-20; 1 Kronika 17:9, 10; Jeremiah 32:37-42; Isaiah 55:8, 9; 1 Kọrinti 3:16, 17; 6:19

5 Solomọni ni a fi fun lati kọ Tẹmpili naa, 2 Samuẹli 7:12, 13; 1 Awọn Ọba 8:19; 1 Kronika 17:11-14; 22:9, 10; 2 Kronika 6:9, 10

6 Awọn ileri Ọlọrun nipa Sọlomọni duro lori igbọran pípé rè̩, 2 Samuẹli 7:14, 15; 1 Kronika 22:12, 13; Orin Dafidi 89:30-32

7 A fi idi majẹmu Ọlọrun pẹlu Dafidi mulẹ nipa ibura, a o si mu un ṣẹ nipa bibọ Messia, 2 Samuẹli 7:16, 17; 1 Kronika 17:14, 15; Orin Dafidi 89:1-4, 20-37; Numeri 24:17-19; Isaiah 9:7; Sekariah 14:9, 16, 17; Matteu 21:5-9; 27:37; Luku 1:32, 33; Ifihan 19:11-16

III Esi Dafidi fun Ọlọrun

1 Ori ọkàn Dafidi tẹba nitori awọn anfaani nlá nlà ti o wà ninu majẹmu ti Ọlọrun bá a dá, 2 Samuẹli 7:18; 1 Kronika 17:16; Isaiah 51:1

2 Esi Dafidi fi hàn pe o mọ rírì gigun ati gbigbooro majẹmu ti Ọlọrun ba a dá, 2 Samuẹli 7:19; 1 Kronika 17:17; Matteu 13:17; Heberu 11:32-35; 1 Peteru 1:10-12

3 Dafidi yin Ọlọrun pe o wu Ọlọrun lati bojuwo oun ati Israẹli pẹlu lati oke wa, 2 Samuẹli 7:20-29; 1 Kronika 17:18-27; Deuteronomi 4:7, 8; 33:29; Numeri 23:8-10.

Notes
ALAYÉ

Bi a ti n ba ẹkọ wa iyebiye yii lọ a o lọ yẹ ẹsẹ Ọrọ Ọlọrun kan ti kò si ninu ẹkọ wa yii wo. Bi a ba fara balẹ kà ẹsẹ wọnyii a o ri i pe wọn tọka si ohun ti o ṣẹlẹ ni igbesi-aye ọba Israẹli keji.

Ọpọ eniyan ti ka ẹsẹ ọrọ wọnyii lai fi ara balẹ ṣe akiyesi itumọ ayeraye ati jijin ipese nla ti o wà ninu rè̩. Ohun ti o ṣẹlẹ yii kò ṣẹlẹ bẹẹ lasan. A o mọ abayọrisi rè̩ ni ayeraye nitori o ṣe pataki ju lọ ni igbesi-aye ọba iṣaaju nipa ohun ti i ṣe ti Ijọba ayeraye. Dafidi jẹ “akọbi Ọlọrun, Ẹni-giga jù awọn ọba aiye lọ,” ọba ti Ọlọrun tikara Rè̩ fi ororo mimọ yàn, ati ẹni ti iru-ọmọ rè̩ yoo “pẹ titi, ati ité̩ rè̩ bi ọjọ ọrun” (Orin Dafidi 89:20, 27, 29).

Ọna Ọlọrun

“Nitori èro mi ki iṣe èro nyin, bḝni ọna nyin ki iṣe ọna mi, li OLUWA wi.

“Nitori bi ọrun ti ga ju aiye lọ, bḝni ọna mi ga ju ọna nyin lọ, ati èro mi jù èro nyin lọ” (Isaiah 55:8, 9).

Eyi jé̩ ọna kan nibi ti o ti hàn gbangba pe ọna Ọlọrun tayọ ọna ti wa ati pe èro Rè̩ ki i ṣe èro wa. Ninu ohun ti o ṣẹlẹ yii, Wolii Dafidi ati Wolii Natani ri giga ogo Ọlọrun ati ẹkún ilana Rè̩ ati bi ero ti wọn ti jé̩ kukuru to. Kò si ohun ti o buru ninu ohun ti Dafidi pinnu lati ṣe. S̩ugbọn gẹgẹ bi ẹda, ero rè̩ kuru ati pe kò si ẹni kan ti o le ni ireti ayeraye ti o tayọ gẹgẹ bi Ọlọrun ti ni in fun ẹni naa ti ọkàn rè̩ ṣe deede pẹlu Rè̩.

Olufọkansin kan sọ bayii pe, “Ọlọrun ni olupilẹṣẹ gbogbo ero mimọ ati gbogbo iṣẹ rere wa; Oun ni o n rú wọn soke; bi a ba si jẹ alabaṣiṣẹpọ pẹlu Rè̩, Oun yoo mu wọn yọri, yoo si san èrè wọn fun wa bi ẹni pe ti wa ni awọn ero ati iṣẹ rere naa, bi o tilẹ jẹ pe Oun nikan ni olupilẹṣẹ wọn.” Ohun ti ọkunrin yii n sọ ni pe “Gbogbo è̩bun rere ati gbogbo è̩bun pipé lati oke li o ti wá, o si nsọkalẹ lati ọdọ Baba imọlẹ wá, lọdọ Ẹniti kò le si iyipada tabi ojiji àyida” (Jakọbu 1:17).

Awọn miiran lero pe Oluwa bá Dafidi wí nigba ti a kọ fun un lati kọ ile fun Oluwa. S̩ugbọn Ọrọ Ọlọrun sọ fun wa pe ipinnu rè̩ dara o si gba iyin lọdọ Ọlọrun. Kikọ ti a kọ fun un fi hàn pe ọnà Ọlọrun ki i ṣe ọna wa, ati pe ero Rè̩ ga ju èrò wa lọ.

Fifi Ẹbọ dá Majẹmu

Ohun ti o dara pupọ ni lati fẹ Ọlọrun ati ohun ti i ṣe ti Rẹ ju ti wa lọ. Ko si aṣiṣe lati tete wá “Ijọba Ọlọrun” ati lati wá itẹsiwaju rè̩ bi o tilẹ gba pe ki a ṣe alainaani itura ati igbadun ara wa ki a si fi ọwọ yẹpẹrẹ mu awọn nnkan wọnni ti a ro pe o ṣe danindanin fun wa. O jẹ didun inu Ọlọrun nigba ti a ba gbe E ga ju ara wa lọ, awọn ọrẹ wa, iṣẹ wa ati nnkan wọnni ti a ni ifẹ si ni aye yii. Ihinrere ti Ijọba Ọrun jẹ isin ti o ni irubọ ninu. Kò si ọna ọlá si Ọrun. Ọna agbelebu ni o lọ sile ogo taara. Awọn eniyan mimọ ti yoo wà pẹlu Kristi yoo jẹ awọn ti o ti fi ẹbọ ba A dá majẹmu (Orin Dafidi 50:1-6).

Ọlọrun ni Olupilẹṣẹ ero ọkàn awọn ero ti n lọ si Ọrun, awọn ti yoo fi ohun gbogbo lelẹ si apa kan – i baa ṣe ẹmi paapaa – fun itẹsiwaju Ijọba Ọlọrun ati igbeleke orukọ Ọlọrun. Iru ifẹ ati ipinnu bẹẹ ki i ṣe ti aye; eyi jẹ ọkan ninu ohun daradara ti o niyelori ti o n ti Ọrun wá. Kò ti i si isẹra-ẹni ti olóòótọ Kristiani kan ṣe -- bẹrẹ lati ọdọ Dafidi ọlọrọ ọba titi de obinrin opo nì ti o fi irẹlẹ fi gbogbo ohun ti o ni sinu apoti-iṣura Ọlọrun, -- ti Ọlọrun kò ri, Oun a si san ẹsan ti o tọ. Awọn ti kò i ti fi “ẹbọ ba Ọlọrun da majẹmu” kò mọ iru ayọ ti fifi ẹbọ bá Ọlọrun dá majẹmu n fun ni. Kika ohun gbogbo sofo nitori Ijọba Kristi n fi ẹni ti a jẹ olóòótọ sí hàn, ani ẹni ti Ọba wa i ṣe ati ẹni ti a fi ifẹ wa fun.

Kò si isẹra-ẹni kan ti o ga jù lati ṣe fun Ọlọrun nitori Oun yoo san an pada fun wa ni ilọpo ọgọrọọrun. Kò si ohunkohun ti a ni ni aye yii, ti a fi silẹ nitori Rè̩, ti o pọ ju. Aye yii n kọja lọ; bi a tilẹ kú ṣaaju ọjọ nla Oluwa, nigba ti ohun gbogbo yoo yọ ninu ooru nla, bi a fẹ bi a kọ, a o fi gbogbo ohun-ini wa laye yii silẹ a o si kọja lọ si ayeraye lai mu ohunkohun lọwọ ninu ohun-ini wa. Ere ayeraye ni yoo jẹ ti wa fun ohunkohun ti a ba ṣe fun Ọlọrun. A le ṣe alaini wura ati fadaka aye yii, ṣugbọn, a le ni ile ti o kún fun iṣura ni ayeraye dipo eyi.

Kristi fi Ara Rubọ fun Wa

Irubọ ṣe ohun danindanin fun Jesu ti o tilẹ jé̩ Ọmọ Ọlọrun paapaa. Ọlọrun gbe E ga lọpọlọpọ a si fun Un ni Orukọ ti o ga ju ti ẹnikẹni lọ nitori O fi tifẹtifẹ ṣe irubọ naa. O fi ara Rè̩ rubọ. O yọọda gbogbo rè̩. Oun kò ka ikú è̩sín lori igi agbelebu sí ohun ti o pọ ju lati ṣe. Gbogbo ifẹ Kristi ni pe ki orukọ Ọlọrun le di ayin-logo ati pe ki Oun le ra gbogbo araye ti o ti nù pada.

A fi gbogbo ijọba aye lọ Jesu boya Oun yoo sé̩ Ọlọrun ki O si yan ayé yii dipo. Ẹgbẹẹgbẹrun n ṣe ohun kan naa lonii: wọn n wolẹ buruburu, wọn si n yọọda ohun-ini wọn ati agbara wọn fun ẹni ti kò le fun wọn ni ere kankan rara. Ogunlọgọ awọn ti o n ṣe eleyi n pe orukọ mimọ nì ni ete lasan ninu isin eke ti wọn n ṣe. Wọn n wi pe, “Oluwa, Oluwa” nigba ti ọkàn wọn jinna si Ọlọrun. S̩ugbọn, Jesu kò gbọ ti Satani; lọna bayii, Jesu jé̩ apẹerẹ fun gbogbo awa ti n tọ ipasẹ Rè̩.

Dafidi Yọọda Ifẹ-Ọkàn ati Ipinnu Rè̩

Igi kedari ni a fi kọ ile Dafidi, ṣugbọn Apoti-ẹri wà labẹ àgọ. Dafidi beere ohun ti ẹnikẹni ti i ṣe ti Ọlọrun ni è̩tọ lati beere: ki Ọlọrun le gba eyi ti o dara jù. Natani, eniyan Ọlọrun, gbọ ohun ti Dafidi gbero lati ṣe, pẹlu ero pe lati ọdọ Ọlọrun wá ni, o fi ọwọ si i. Boya ni gbogbo oru, Wolii naa fẹrẹ má fi oju ba oorun. Natani ati Dafidi n fé̩ itẹsiwaju ohun ti i ṣe ti Ọlọrun ṣugbọn wọn kò fé̩ ki ifẹ ti ara wọn leke. Dajudaju, Natani gbadura pe ki Ọlọrun mú ohunkohun ti ki i ṣe ifẹ ti Rè̩ kuro ki o si jẹ ki ifẹ Ọlọrun leke. Ẹni ti o ba ni eti lati gbọ ni Ọlọrun n bá sọrọ. O bá Natani sọrọ. A le ri i pe ọkàn Dafidi pẹlu ṣipaya si ifẹ pipe Ọlọrun, nitori nigba ti o n gbadura ifi-ara-rubọ rè̩ ati imuṣẹ ifẹ Ọlọrun, o sọ bayii pe eredi rẹ niyii ti oun “ṣe ni i li ọkàn rè̩ lati gbadura yi” si Ọlọrun. Ẹni ti o ba n wa iṣura ti ẹmi nikan ni o n ri i. Nitori naa a mọ pe Dafidi pẹlu fé̩ mọ ifẹ Ọlọrun bi o tilẹ jẹ pe eniyan Ọlọrun ti lóhùn ninu ohun ti o fẹ ṣe.

Eto Ọlọrun fun Dafidi

Ọlọrun kò beere pe ki a kọ ile fun Oun. Kò si ile ti o le gba Ẹni ti O tobi ju gbogbo ayé lọ. Oun kò yan ibi kan sọtọ nibi ti yoo maa gbé. O yan ọkunrin kan dipo eyi, ẹni naa ni Dafidi. Ifẹ Dafidi lati kọ ile fun Ọlọrun dùn mọ Ọlọrun ninu; O si fi àyè silẹ fun wọn nigbooṣe lati ṣe bẹẹ lọna kan. S̩ugbọn a kò kọ ọ gẹgẹ bi ibugbe Ọlọrun. S̩ugbọn a kọ ọ fun ọlá orukọ Ọlọrun.

Kò si ile kan ti ẹda le kọ ti o le gba Ọlọrun. O sọ bayii pe, “S̩ugbọn eleyi li emi o wò, ani òtoṣi ati oniròbinujẹ ọkàn, ti o si nwariri si ọrọ mi” (Isaiah 66:1, 2). Ọlọrun ri Dafidi bi ẹni kan ninu ẹni ti Oun le mu ileri majẹmu Rè̩ fun aye è̩ṣẹ yii ṣẹ. Dafidi ri i pe ero Ọlọrun tayọ ifẹ ti oun ni lati kọ ile fun Ọlọrun. Ọlọrun fẹ kọ ile fun Dafidi, ki i ṣe lati fi ọlá fun un, bi kò ṣe pe lati mú ileri majẹmu ti o bá Abrahamu dá ṣẹ.

Tẹmpili Ọlọrun Tootọ

Ara wa ni Tẹmpili Ẹmi Mimọ (1 Kọrinti 3:16, 17; 6:19, 20). A ti rà wá ni iye kan. A ki i ṣe ti ara wa mọ. Ọlọrun ti yan Dafidi lati mu ilana ati ipinnu Rè̩ ayeraye ṣẹ; Ọlọrun, ni ọna ti o tobi ju eyi nì lọ, n pe awọn wọnni ti yoo fi “ẹbọ” bá A dá majẹmu, ti wọn yoo si yọọda ara wọn patapata fun Ẹni ti n ṣe ododo ati otitọ.

Ọlọrun n wá awọn wọnni ti Oun yoo gbe iṣẹ majẹmu ti Ijọba Ọrun lé lọwọ, ki Ihinrere le tàn ká gbogbo ayé, si ogunlọgọ awọn eniyan ti o wà lẹyin agbo, ti wọn kò si mọ ọna lati wọle. Iṣẹ Ẹmi Mimọ ati Iyawo Kristi ni lati tan Ihinrere kalẹ lonii. Kristi wà ni ọwọ ọtun Ọlọrun Baba, O n bẹbẹ fun araye, O si ti fi iṣẹ ilaja lé wa lọwọ. Nitori iṣẹ yii ni Ẹmi Mimọ ṣe n kún wa – awa Tẹmipili Rè̩ -- ti O n fi agbara ati okun fun wa ti O si n tọ wa. Iwuwo yii wà lọkàn awọn wọnni ti wọn sun mọ Ọlọrun ti wọn si n wa ogo Ọlọrun nikan, ti wọn si fẹ ọna Rè̩ ju ọna ti wọn lọ. Nipa wọn, Ọlọrun le mu ileri Rè̩ ti O ṣe fun awọn patriarki igba nì ṣẹ.

Awọn Majẹmu

A tun ri iṣipaya ilana majẹmu nla Ọlọrun nihin. Ọlọrun ba Abrahamu dá majẹmu ayeraye ti a o mu ṣẹ nipasẹ ati ninu orilẹ-ede Israẹli. O bá Israẹli dá majẹmu kan pato lori eyi. Majẹmu ti Ọlọrun bá Abrahamu da ni a fi idi rè̩ mulẹ nipa ibura, ati nitori Ọlọrun kò ri ẹni ti o pọ ju Oun lati fi bura, O fi ara Rè̩ búra (Heberu 6:13).

Orilẹ-ede Israẹli kuna lati pa majẹmu ti Ọlọrun bá wọn dá ni oke Horebu mọ, wọn kò si ṣe ohun ti o wà ninu gbogbo majẹmu ti Ọlọrun ba Abrahamu dá. S̩ugbọn olukuluku ẹni ti o yan ọna ifararubọ pa majẹmu wọnyii mọ dipo ati jẹ “fāji è̩ṣẹ fun igba diẹ” (Heberu 11:25). Ọpẹ ni fun Ọlọrun pe awọn olóòótọ kọọkan bi Mose, Joṣua, Deborah, Baraki, Samuẹli, Dafidi, Elijah, Eliṣa ati Johannu Baptisti wà lati mu ilana Ọlọrun ṣẹ nipa igbala gbogbo ayé.

Majẹmu ti Ọlọrun ba Abrahamu dá yoo wà titi a si fi idi rè̩ mulẹ nipa ibura. Majẹmu ti a ba awọn Ọmọ Israẹli dá jé̩ ti wọn nikan, a o mu un ṣẹ nipa Ẹni ti o wá lati mu gbogbo ododo ṣẹ. Majẹmu yii ti a bá awọn Ọmọ Israẹli dá ki i ṣe majẹmu ayeraye, nitori idi eyi, a kò fi idi rè̩ mulẹ nipa ibura.

Boya awọn miiran le jiyàn ọrọ yii, ki wọn si wi pe kò si iyatọ, niwọn-igba ti Ọrọ Ọlọrun wà titi lae ati pe ohun gbogbo ti O sọ kò le ṣe alai ṣẹ. Otitọ ni eyi. Fifi idi ekinni mulẹ pẹlu ibura fi hàn pe yoo wà titi lae ati pe o lagbara ju eyi nì ti a kò fi idi rè̩ mulẹ pẹlu ibura. Awọn ọrọ ti Ọlọrun sọ lori Oke Sinai nipa Israẹli wà fun orilẹ-ede wọn nikan. Nigba ti a si ti mu awọn ohun ti o wà ninu Ofin ṣẹ, Ofin naa ati majẹmu ti a ṣe pẹlu Israẹli ti rekọja.

A de ibi kan pataki ninu idagbasoke eto Ọlọrun fun igbala eniyan nigba ti Dafidi beere pe ki a fun oun laaye lati kọ ile fun Ọlọrun. Ọlọrun tun sọ apa kan ninu majẹmu ti O bá Abrahamu dá di ọtun, paapa ju lọ, awọn wọnni ti o kan Dafidi ati ayè ti yoo dì mú ninu Ilana Ọlọrun.

Ọlọrun wi pe, “Emi kò yàn ilu kan. . . . lati kọ ile kan . . . ṣugbọn emi yàn Dafidi” (1 Awọn Ọba 8:16). “emi ti mu iwọ (Dafidi) kuro lati inu agbo agutan, . . . . emi si ti sọ orukọ rẹ di nla” (2 Samuẹli 7:8, 9). Ọlọrun si fi han Wolii Dafidi lati ọwọ Natani Wolii, pe Oun yoo gbé ijọba kan dide ti ki yoo nipẹkun, Oun o si yan ibi kan fun awọn iyoku Israẹli, awọn ti yoo si mọ Ọn ni Ọba wọn. Ọlọrun wi pe Oun yoo kọ ile kan fun Dafidi, aanu Oun ki yoo si yipada kuro ninu ile naa gẹgẹ bi Oun ti yi i pada kuro lọdọ Saulu.

Dafidi mọ riri ileri nla ati majẹmu yii, nitori Ọlọrun tun fi idi rè̩ mulẹ pẹlu ibura. Dafidi si gbadura bayii pe, “Iwọ si sọ ti idile iranṣẹ rẹ pẹlu ni ti akoko ti o jina.” Ninu ọrọ yii, o jẹ ki o di mimọ fun wa pe oun ri imuṣẹ eto Ọlọrun ti ayeraye ni okeere. Dafidi le ri i pe idile oun yoo wà titi lae nitori Ẹni kan wà ti yoo wà laaye titi lae. A mọ pe Jesu Kristi ni Ẹni naa. Dafidi ni ọba keji Israẹli, ṣugbọn oun ni ọba ayé yii kin-in-ni ninu Ijọba ti ki yoo nipẹkun.

Dafidi tun sọ bayii pe, “Eyi ha ṣe ìwa eniyan bi, Oluwa ỌLỌRUN?” A sọ fun ni pe ọrọ yii kò lọ lọna ibeere ninu ede Heberu. Bi ọrọ naa ti lọ gan an ni eyi: “Ati eyi, Oluwa ỌLỌRUN, ni ofin Adamu.” (Adamu ati eniyan jé̩ ohun kan naa ni ede Heberu). Lai si aniani Dafidi n tọka nihin si ileri kin-in-ni ti Ọlọrun ṣe nipa Olugbala, pe iru-ọmọ obinrin naa yoo fọ ejo naa lori. Itumọ eyi ni pe, “Eyi yoo jẹ imuṣẹ ileri nla ati ireti Olugbala.” Pẹlu inu-didun ati ọkàn ti o kún fun ọpẹ, Dafidi duro niwaju Oluwa lati tú ọkàn rè̩ silẹ ninu adura ifararubọ ati iyin ti o pari ẹsẹ ẹkọ wa yii.

Majẹmu pẹlu Gbogbo Agbaye

Ọọdunrun ọdun lẹyin eyi, Oluwa na ọwọ ipè Rè̩ si gbogbo agbaye lati wá “sibi omi, ati ẹniti kò li owo; ẹ wá, ẹ rà, ki ẹ si jẹ; lõtọ, ẹ wá, ẹ rà ọti-waini ati wàra, laini owo ati laidiyele.” Ọlọrun ṣe ileri pe Oun yoo dá majẹmu ainipẹkun pẹlu gbogbo awọn ti o ba jé̩ ipe naa. Ati pe ki o má ba si tabitabi nipa ohun ti o mu ki majẹmu naa wà, O fikun un pe, “nu Dafidi ti o daju.” (Isaiah 55:1-3).

Ọlọrun gba aanu Rè̩ kuro lọwọ Saulu, ṣugbọn O fi i fun Dafidi ati iru-ọmọ rè̩ laelae nitori majẹmu ti Dafidi, “nipa ẹbọ.” Ọlọrun ti fi Ọrọ Rè̩ ti kò le yipada fun wa pé gbogbo ibukun ayeraye ti a ṣeleri fun Dafidi ni yoo jé̩ ti wa pẹlu, bi a ba jé̩ ipè Rè̩ ti a si dá majẹmu kan naa “nipa ẹbọ” gẹgẹ bi Dafidi ti ṣe.

A ti ri i bi Dafidi ti di ọba aye yii kin-in-ni ni Ijọba ayeraye, awa paapaa tun le ri i pẹlu pe awa naa le di ajumọjogun ijọba pẹlu Ọba ayeraye nì ní Ijọba ti ki yoo nipẹkun. Ọlọrun bá Dafidi dá majẹmu O si fi idi rè̩ mulẹ pẹlu ibura, awa si le mọ bi majẹmu yii ti daju to ati bi o ti jẹ ti ayeraye to. Ki i ṣe majẹmu ti a lè mú kuro nigba ti a ba mu ipinnu kan ṣẹ gẹgẹ bi majẹmu ti Ọlọrun dá pẹlu awọn Ọmọ Israẹli ni Horebu. Oluwa fẹ ba wa dá irú majẹmu ti O bá Dafidi dá. A le ri majẹmu yii gbà nipa “ānu Dafidi ti o daju.” Majẹmu yii ni Ọlọrun fi ibura si nipa ẹwà iwà mimọ Rè̩ -- eyi yii ni ẹwà ti o tobi ju lọ ninu Ọlọrun, ti o fi Ara Rè̩ bura nitori kò si ẹni ti o pọ ju U lọ lati fi bura (Heberu 6:13; Orin Dafidi 89:3, 35). Nitori naa kò si ifoya fun wa lọjọ iwaju bi a kò ba fasẹyin ninu è̩jé̩ wa ti a ba Ọlọrun jé̩ -- bi a ba le dá majẹmu naa “pẹlu ẹbọ” ki a si pa á mọ.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ipò wo ni Israẹli wà gẹgẹ bi orilẹ-ede ni akoko ẹkọ wa yii?
  2. Ipa meji wo ni Natani kó ninu ẹkọ wa yii?
  3. Njẹ a bá Dafidi wí nitori a kò mu ibeere rè̩ ṣẹ?
  4. Ki ni wà ninu Dafidi ti o mu ki o beere ibeere yii?
  5. Ki ni Ọlọrun sọ nipa ibeere Dafidi?
  6. Eto wo ni Ọlọrun ni fun Dafidi ati fun Israẹli nipasẹ Dafidi?
  7. Ta ni ẹni ti yoo ṣe ohun ti Dafidi ni ifẹ lati ṣe nigbooṣe?
  8. Ọna wo ni majẹmu ti Ọlọrun bá Abrahamu dá ati eyi ti O ba Dafidi dá fi jọ ara wọn?
  9. Bawo ni a ṣe le mu ileri nla ti a ṣe fun Dafidi ṣẹ?
  10. S̩e apejuwe iwa Dafidi ati esi rè̩ si Ọlọrun lẹyin ti Ọlọrun ti sọ gbogbo ifẹ Rè̩ fun Dafidi ati fun Israẹli di mimọ.