2 Samuẹli 9:1-13

Lesson 231 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Jade lọ si igboro, ati si abuja ọna, ki o si mu awọn talakà, ati awọn alabùkù arùn, ati awọn amọkun, ati awọn afọju wá si ihinyi” (Luku 14:21).
Cross References

I Mefiboṣeti -- Apẹẹrẹ Ẹda ti ó S̩ubu

1 Mefiboṣeti, gẹgẹ bi ọkan ninu idile Saulu, ni Ọlọrun kọ lati jé̩ ọba, 2 Samuẹli 9:1, 2; 1 Samuẹli 15:28; 13:13, 14; 2:30

2 Mefiboṣeti di ẹni ti a tanù kuro nidii ohun-ini rè̩, 2 Samuẹli 9:7; Gẹnẹsisi 3:22-24

3 Gẹgẹ bi arole ọba ti a ti kọ, Mefiboṣeti yẹ si ikú, 2 Samuẹli 3:1; Isaiah 43:27; Romu 5:12; 1 Kọrinti 15:21

4 Mefiboṣeti ya arọ patapata nipa iṣubu rè̩, 2 Samuẹli 9:3; 4:4; Romu 5:6

II Majẹmu Dafidi

1 Mefiboṣeti jẹ anfaani májè̩mú ti Dafidi bá Jonatani dá nigba aye rè̩, 2 Samuẹli 9:1; 1 Samuẹli 20:15, 16; Ẹksodu 2:24; Gẹnẹsisi 26:3

2 Dafidi wá arole Saulu ti o kù lé̩yìn ki o le ṣe e loore, 2 Samuẹli 9:2-5; Luku 19:10; Johannu 10:10; Galatia 4:4, 5

III A Dá Ohun-Ini Pada fun Ẹni Ti O Ni In

1 Mefiboṣeti fi irẹlẹ tootọ hàn niwaju Dafidi, gẹgẹ bi ẹlẹṣẹ ti ni lati ṣe niwaju Ọlọrun, 2 Samuẹli 9:6, Luku 18:13; Jakọbu 4:8-10; 1 Peteru 5:5

2 A dá ohun-ini Mefiboṣeti ti o ti sọnu pada fun un, 2 Samuẹli 9:7-9; 1 Peteru 1:3, 4; Efesu 1:5-7

3 Mefiboṣeti jokoo ni tabili ọba eyi ti i ṣe apẹẹrẹ ẹlẹṣẹ ti a ti rà pada, 2 Samuẹli 9:10; Luku 22:29, 30; Ifihan 19:9

4 Dafidi yan awọn iranṣẹ lati maa ṣe iranṣẹ fun Mefiboṣeti, 2 Samuẹli 9:9-13

Notes
ALAYÉ

Aanu Ọlọrun

Akọsilẹ ojurere ati aanu ti Dafidi ṣe fun Mefiboṣeti, ti idile Saulu, (bi o tilẹ jẹ pe Saulu jé̩ ọta Dafidi ti o buru ju lọ) fi han fun ni ohun ti oore-ọfẹ Ọlọrun le ṣe ninu ọkàn ọmọ eniyan.

Dafidi jiya pupọ nitori Saulu Ọba; ṣugbọn nisisiyii Saulu ti kú, iwọnba eniyan ni o si kù ti o le tako Dafidi lori oye. Lé̩yìn ikú Saulu awọn eniyan diẹ kan ti o lero lati ṣe Dafidi loore pa diẹ ninu idile Saulu. Nitori eyi Mefiboṣeti bẹrẹ si bẹru boya a o pa oun naa. Mefiboṣeti ṣe oriire pupọ nitori Dafidi jẹ iranṣẹ Ọlọrun, Ẹmi Ọlọrun alaaye si n ṣe akoso igbesi-aye rè̩. Nitori Dafidi n fẹ lati bu ọlá fun Ọlọrun ninu igbesi-aye rè̩, Ọlọrun fi í jẹ ọba, ki a ba le ṣakoso Israẹli lọna ti o tọ (Wo Orin Dafidi 78:70-72).

Ọlọrun sọ bayii nipa ara Rè̩, “Kò dá ibinu rè̩ duro titi lai, nitori on ni inudidun si ānu” (Mika 7:18). Ọlọrun jẹri si eyi ninu Dafidi, nitori imisi Ọlọrun ninu ayé Dafidi ni o mu ki o fi aanu hàn fun Mefiboṣeti. Nipa fifi aanu han, ati ṣiṣe iranlọwọ fun Mefiboṣeti, Dafidi bu ọla fun Ọlọrun lọpọlọpọ o si fi hàn bi iwa rere oun paapaa ti pọ tó. (Wo 2 Samuẹli 4:10-12).

Ogún ti o Sọnù

Mefiboṣeti arọ jé̩ apẹẹrẹ eniyan ti o ti ṣubu kuro ninu oore-ọfẹ ati apẹẹrẹ ẹni ti a dá ogun-ibi rè̩ ti o ti sọnu pada fun nipasẹ aanu ati inurere ẹlomiran. Jonatani (ti i ṣe baba Mefiboṣeti) ti bá Dafidi dá majẹmu pé bi Dafidi ba di ọba ki o má ṣe gbagbe lati ṣe ojurere si ile Saulu. Dafidi ṣeleri lati ṣe bẹẹ, o si mú ileri rè̩ ṣẹ (Wo 1 Samuẹli 20:15-17).

Mefiboṣeti kò lọwọ ninu è̩ṣẹ Saulu, sibẹ o jiya nitori rè̩. Bakan naa ni gbogbo ẹda alaaye n jiya nitori è̩ṣẹ Adamu baba wọn, bi o tilẹ jẹ pe wọn kò lọwọ ninu è̩ṣẹ naa. A gba ogun-ibi Mefiboṣeti kuro lọwọ rè̩, o di ẹni itanù, o si wà ninu ibẹru nigba gbogbo nitori igbẹsan lati ọdọ awọn ọta Saulu. Gbogbo eyi de bá a nitori Saulu dé̩ṣè̩ si Ọlọrun.

Itumọ Mefiboṣeti ni “itiju” a si tun n pe e ni orukọ miiran, Merib-baali ti itumọ rẹ i ṣe “iṣọtẹ” (1 Kronika 8:34). O dabi ẹni pe Mefiboṣeti jẹ ọmọ-ègun torukọ-torukọ. Oun kò yatọ si Adamu, ọkunrin iṣaaju!

Adamu dẹṣẹ o si sọ ogun-ibi rè̩ nù, oun ati awọn ara ile rè̩ sọ ogún wọn nù, è̩ṣẹ wọ inu ọkàn ọmọ eniyan, ọkàn rè̩ si dibajẹ o si n rùn nitori è̩ṣẹ naa. Gbogbo eniyan ni o wà ni abẹ idajọ ikú nitori irekọja iṣaaju nì, bi o tilẹ jẹ pé wọn kò lọwọ ninu rè̩ (Ka 1 Kọrinti 15:21, 22).

Ilaja

A mọ pe aṣẹ ati ifẹ Ọlọrun ni pe ki awọn ẹlẹṣẹ ba A laja. (Wo 2 Kọrinti 5:20). Ko ha ṣe e ṣe ko jẹ pe irú ero bayii ni o wà lọkàn Dafidi ati pe ó ranti ileri ti ó ṣe fun Jonatani, nigba ti ó fi aanu ipò ọba ti ó wà hàn fun Mefiboṣeti? Lati ọdọ ta ni iru imisi fun iṣẹ rere ati iwà pipe bayii ti wá bi kò ṣe lati ọdọ Ẹni ti o n fun ni ni gbogbo ẹbun rere ati gbogbo ẹbun pipe? Òwú òdòdó ati eto igbala nla Ọlọrun gba ọdọ Jonatani kọja ó sì mi sí Dafidi ti i ṣe ọrẹ rè̩. Òwú ododo yii kan naa gba ọdọ Dafidi kọja ni gbogbo ọjọ ayé rè̩, a si ri bi Dafidi ti n fi okun ifẹ naa fa ẹni kan mọra.

Ọba n wá Mefiboṣeti ti wọn ti dá lẹbi ti wọn si ti lé kuro ni ilu, lati ba a laja. Eyi fara jọ iriri ẹlẹṣẹ bi awọn iranṣẹ Ọba ti n wá a kiri lati fun un ni ihin ayọ ti ìlàjà. Bibeli sọ nipa ihin naa lọna bayii pe: “Ọlọrun wà nínu Kristi, o mba araiye làja sọdọ ara rè̩, kò si kà irekọja wọn si wọn lọrùn; o si ti fi ọrọ ìlaja le wa lọwọ” (2 Kọrinti 5:19). A fi ifẹ iyanu ti Ọlọrun ni si eniyan hàn nihin, ani bi wọn tilẹ jẹ ọlọtè̩, ẹni itanù ati ẹni ti a le jade kuro ni ilu, nipa oore-ọfẹ nla Ọlọrun, wọn tun le bá Oluwa ati Ọba wọn laja.

Tabili Ọba

Dafidi paṣẹ pe ki a mu Mefiboṣeti jokoo nibi tabili ọba ki o si maa jẹ ninu ounjẹ ọba. Eyi ni ọlá ti o ga jù ti Dafidi le fun un, eyi si jé̩ ikede fun gbogbo eniyan pe Mefiboṣeti wà labẹ aabo ọba, ẹnikẹni ti o ba si huwa iwọsi si Mefibosẹti tabuku si ọla nla ọba paapaa.

Ohun kan naa yii ni o n ṣẹlẹ ninu igbesi-aye awọn ẹni ti o ba gba ọrọ ilaja lati ẹnu awọn iranṣẹ Ọlọrun gbọ, ti a si gbà wọn si Ijọba Ọlọrun. Ọlọrun ti ṣe ikede fun gbogbo eniyan pe a o ba A jokoo nibi tabili Rè̩ lati jè̩ ninu ounjẹ Ọba. Otitọ yii hàn gbangba ninu owe Ase-Alẹ ti Jesu pa, ati ninu awọn ẹsẹ Ọrọ Ọlọrun miiran gbogbo. Jesu wi pe awọn talaka, alabuku arun ati awọn amukun ati awọn afọju ni a pè sibi ase nla ti Ọlọrun. Oniruuru eniyan wọnyii jé̩ apẹẹrẹ awọn ẹlẹṣẹ ti yoo jé̩ ipe Ihinrere. (Wo Luku 14:16-24). Bakan naa ni Jesu wi pe akoko kan n bọ wa ti Oluwa yoo ṣe iranṣẹ fún awọn ọmọ-ọdọ Rẹ: “Ibukun ni fun awọn ọmọ-ọdọ wọnni nigbati oluwa na ba de ti yio ba ki nwọn ki o ma ṣọna: lõtọ ni mo wi fun nyin, yio di ara rè̩ li amure, yio si mu nwọn joko lati jẹun, yio si jade wá lati ṣe iranṣẹ fun wọn” (Luku 12:37).

Gẹgẹ bi a ti pe Mefiboṣeti lati jokoo sibi tabili ọba, ti ki i ṣe pe iṣẹ rere ti o ṣe ni o fun un ni è̩tọ si oore-ọfẹ yii, ṣugbọn nipa aanu ati ododo ẹlomiran, bakan naa ni o rí fun ẹlẹṣẹ. Kò si ohunkohun ninu ẹlẹṣẹ ti o le fun un ni ẹtọ si anfaani inu-rere Ọlọrun. S̩ugbọn nipasẹ ododo ẹlomiran ni Ọlọrun fi wá ẹlẹṣẹ rí, ẹni naa ni Jesu Kristi, Ọmọ bibi kan ṣoṣo ti Ọlọrun. Nitori itoye Rè̩, Ọlọrun ti na ọwọ igbala nla Rè̩ si awọn talaka, alabuku arun, awọn amukun ati awọn afọju lati wá jẹ ninu ase nla Rè̩.

A Dá Ogún-Ibi Pada

Dafidi dá ohun gbogbo ti i ṣe ti Saulu ati ile rè̩ pada fún Mefiboṣeti. O ri ogun-ibi rè̩ gbà pada; o ri oju-rere ọba, o si wá dabi ọkan ninu awọn ọmọ ọba. Bakan naa ni o ri pẹlu awọn ti o ri oore-ọfẹ Ọlọrun gbà. Ohun gbogbo ti a gbà lọwọ wọn ni a dá pada nipa aṣẹ Ọba. A si fun wọn ni oore-ọfẹ ati aanu lati tán gbogbo aini wọn, wọn si wà gẹgẹ bi ọmọ Ọba.

Iwe Mimọ fi idi otitọ yii mulẹ bayii pe, “S̩ugbọn iye awọn ti o gbà a, awọn li o fi agbara fun lati di ọmọ Ọlọrun, ani awọn na ti o gbà orukọ rè̩ gbọ” (Johannu 1:12). A tun ri i kà pẹlu pe, “Ẹnyin ti gbà ẹmi isọdọmọ, nipa eyi ti awa fi nke pè, Abba, Baba. Ẹmi tikararè̩ li o mba ẹmí wa jẹrí pe, ọmọ Ọlọrun li awa iṣe: Bi awa ba si jẹ ọmọ, njẹ ajogun li awa, ajogun Ọlọrun, ati ajumọ-jogun pẹlu Kristi” (Romu 8:14-17).

Lati inu awọn ẹsẹ Ọrọ Ọlọrun yii, a le ri i bi ifẹ iyanu Ọlọrun si ọmọ-eniyan ti pọ to; eyi si le mu ki o yé wa si i eredi rè̩ ti Dafidi fi fi oju-rere rè̩ gẹgẹ bi ọba wo ọgbẹni arọ ati alailagbara yii.

Apẹẹrẹ Iwa-Bi-Ọlọrun

Jesu sọ nipa awọn ti wọn bọ awọn ẹni ti ebi n pa, ti wọn daṣọ bo ẹni ti o wà ni ihoho, ti wọn ṣe iranlọwọ fun awọn ti o wà ninu tubu; O si yìn wọn nitori wọn ṣaanu fun Oun. Nigba ti wọn si beere lọwọ Rè̩, igba ti wọn ṣe gbogbo nnkan wọnyii fun Un, Jesu dahun pe, “Niwọn bi ẹnyin ti ṣe e fun ọkan ninu awọn arakọnrin mi wọnyi ti o kere julọ ẹnyin ti ṣe e fun mi’ (Matteu 25:40). Idahun yii jé̩ akotan iṣẹ ati anfaani ti olukuluku ọmọ Ọlọrun ni lati ṣoore fun arakunrin ati aladugbo rè̩ ti oun sàn ju lọ.

Dafidi fi hàn pe ọmọ Ọlọrun ni oun i ṣe nitori o bọ ẹni ti ebi n pa, o ranti ileri rè̩, o si mu un ṣẹ; o dá ògò ti o nù pada o si ṣe iranlọwọ fun apa ti o rọ ati eekun ti kò lagbara. Bakan naa ni o ri pẹlu Ọlọrun: O n pese ounjẹ ti o tó fun wa, O n fi itura fun ọkàn wa, O si n fun wa ni iye ainipẹkun.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni ṣe ti Mefiboṣeti fi n bẹru igbẹsan lati ọdọ awọn ọta baba rè̩ wá?
  2. Ki ni mu ki Mefiboṣeti sọ ogun ibi rè̩ nù?
  3. Ọna wo ni Mefiboṣeti fi jé̩ apẹẹrẹ ẹni ti o ṣubu?
  4. Ki ni ṣe ti Dafidi ni ifẹ si Mefiboṣeti?
  5. Ki ni ṣe ti Ọlọrun fi ni ifẹ si ẹlẹṣẹ?
  6. Ta ni a pè si ibi tabili Ọba?
  7. Njẹ a yẹ fun ipe lati jẹun lori tabili Ọba?