Orin Dafidi 51:1-19

Lesson 232 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Bi awa ba nrìn ninu imọlẹ, bi on ti mbẹ ninu imọlẹ, awa ni idapọ pẹlu ara wa, è̩jẹ Jesu Kristi Ọmọ rè̩ ni nwè̩ wa nù kuro ninu ẹṣẹ gbogbo” (1 Johannu 1:7).
Cross References

I Adura Dafidi fun Idalare

1 O bẹbẹ fun aanu Ọlọrun gẹgẹ bi ẹlẹṣẹ ti o jé̩ onirobinujẹ ọkàn, Orin Dafidi 51:1; Luku 15:11-24; 23:42; Mika 7:18, 19; Isaiah 43:25; 44:22

2 Ijẹwọ è̩ṣẹ rè̩ ati ẹbẹ lati mu wọn kuro jẹ eyi ti o ti ọkàn otitọ wá, Orin Dafidi 51:2, 3; 32:5; 1 Johannu 1:9

3 O jẹwọ ẹṣẹ nla rè̩, Orin Dafidi 51:3, 4; Esra 9:5, 6; Romu 7:12, 13; 2 Samuẹli 12:13

II Adura Dafidi fun Isọdimimọ

1 O mọ ipò ti ọkàn rè̩ wa dajudaju, Orin Dafidi 51:5; Gẹnẹsisi 5:3; 6:5; Matteu 15:19; Marku 7:21; Jeremiah 17:9, 10

2 O mọ daju pe Ọlọrun fẹ ki awọn eniyan Rè̩ jẹ mimọ, Orin Dafidi 51:6; 24:3, 4; Matteu 5:8, 48; 1 Tẹssalonika 4:3; Heberu 12:14; 2 Kọrinti 13:11; Jakọbu 1:4; Galatia 6:15

3 O gbadura fun imukuro è̩ṣẹ abinibi ati pe ki a dá ọkàn titun sinu oun, Orin Dafidi 51:7-10; Efesu 4:17-24; 5:25-27; Kolosse 3:10

III Ireti Dafidi lati fi Ayọ S̩iṣẹ Isin

1 Oun kò fẹ di ẹni itanu, gẹgẹ bi Saulu, Orin Dafidi 51:11; 2 Samuẹli 8:15; Johannu 15:6; 1 Kọrinti 9:26, 27; Matteu 8:12; 25:30

2 O fẹ sin Ọlọrun o si n fẹ jere ọkàn, Orin Dafidi 51:12, 13; Daniẹli 12:3

3 O ṣeleri pe oun yoo fi iyin fun Ọlọrun nigba ti a ba gba oun lọwọ aiṣododo gbogbo, Orin Dafidi 51:14, 15; 2 Kronika 5:11-14

4 O sọ nipa ami irobinujẹ tootọ, Ofin Dafidi 51:16, 17; Isaiah 1:2-20; Luku 18:9-14

5 Ki i ṣe fun ara rè̩ nikan ni o n rò ṣugbọn fun awọn ti o wà labẹ rè̩, ti wọn le pin ninu iyà è̩ṣè̩ rè̩, Orin Dafidi 51:18, 19; Galatia 5:9.

Notes
ALAYÉ

Bi a ti n kẹkọọ nipa igbesi-aye Dafidi a ri ọpọlọpọ ẹkọ iyebiye kọ. Ọkan ninu wọn ni a o ri bi a ti n kẹkọọ ninu Saamu ti a n kà yii, ati ohun ti o mu ki a kọ ọ.

Dafidi ti mọ ojúrere Ọlọrun, o si ti jẹ olóòótọ iranṣẹ Ọlọrun fun ọpọlọpọ ọdun, ṣugbọn o kuna, o si ṣubu sinu è̩ṣẹ ti o buru jai. Bi oun ki ba i ṣe iru eniyan ti o jẹ, jijoko ni i ba jokoo sinu ipo iṣubu rè̩ lai wá ọna ati bọ kuro ninu rè̩. A dupẹ lọwọ Ọlọrun ti O fun wa ni akọsilẹ nipa è̩ṣè̩ Dafidi ati ironupiwada rè̩ ati pe a dari è̩ṣè̩ Dafidi jì í!

Nigba ti ẹni kan ba ṣe aigbọran si ofin Ọlọrun bi o ba si ṣubu kuro ninu ojúrere Rè̩, ipo ibajẹ rè̩ yoo buru ju igba ti a bi i lọ, nitori nigba ti ẹmi aimọ ba pada lọ si ile ti a gbá ti a si ti ṣe lọṣọ, oun a “mu ẹmi meje miran pẹlu ara rè̩, ti o buru jù on tikararè̩ lọ;. . . . . igbẹhin ọkọnrin na si buru jù iṣaju rè̩ lọ” (Matteu 12:45). Dafidi ti gbadun ojurere Ọlọrun tẹlẹ ri. O ti ni ibarẹ ati ibalo pẹlu Ọlọrun, ti a ba si foju inu wo o, ibarẹ ati ibalo yii lọla, o si kún gidi ju eyikeyi ti ẹnikẹni ninu awọn eniyan Ọlọrun ti Igba Majẹmu Laelae ti ni. Nitori naa adura rè̩ fun ìmúpadà yoo jẹ lati dé ipò ododo ati iwà mimọ ti oun ti wà ṣaaju. Nitori o ṣe eyi kò fi han pe awọn iriri Onigbagbọ ti idalare ati isọdimimọ patapata jé̩ iriri oore-ọfẹ kan naa. Ninu Saamu yii a ri iru ipo ti a gbọdọ fi ara ati ọkàn wa sí ki a tó le jé̩ alabapin awọn iriri meji wọnyii, ati iru eso ti a o so bi a ba ti ri wọn gbà.

Idalare nipa Igbagbọ

A mọ pe Dafidi ti ni iriri idalare nigba kan ri, nitori o n beere pe ki a dá a pada fun oun. A si mọ pe o ri oore-ọfẹ yii gba pada, nitori Natani sọ bayii pe, “OLUWA pẹlu si ti mu è̩ṣẹ rẹ kuro” (2 Samuẹli 12:13). Dafidi wá siwaju Ọlọrun pẹlu ironupiwada tootọ lai ṣe ohunkohun lati mu ki iwuwo è̩ṣè̩ rè̩ ki o dinku niwaju Ọlọrun ati eniyan. Oun kò tọka si ohun rere kan ninu ara rè̩, ṣugbọn o n bẹbẹ fun aanu Ọlọrun nikan pẹlu ọkàn pe oun ni olori ẹlé̩ṣè̩.

Dafidi jẹbi è̩ṣẹ meji ti o buru jù lọ; ṣugbọn awọn è̩ṣẹ ti o tilẹ kere loju ẹda jé̩ ohun ti o buru jai niwaju Ọlọrun, yoo ya eniyan ya Ọlọrun, oluwarẹ yoo si di ẹni itanu patapata. Dafidi huwà aitọ lọpọlọpọ si aladugbo rè̩; ṣugbọn ofin Ọlọrun ni o ṣè̩ sí, Ọlọrun ni yoo si jihin fún. Ẹṣẹ ti o wuwo ti o si buru jai ti Dafidi ṣẹ si ofin Ọlọrun olóòótọ, alaaanu, ati onifẹ dabi oke nla niwaju rè̩, ṣugbọn eyi ko mu iwa buburu ti o ṣe si aladugbo rè̩ kuro. O ni lati ṣe atunṣe ni gbogbo ọna, nibi ti eyi ba le ṣe e ṣe, bi on ba fẹ wà ninu ojúrere Ọlọrun. S̩ugbọn ki ni Dafidi le ṣe, nitori kò le ji ọkọ obinrin ti o pa dide kuro ninu okú ki o si mu ile wọn ti o ti bajẹ tooro.

Bi ẹnikẹni ba ja ẹni keji rè̩ ni olè, o huwa aitọ si ẹni naa. S̩ugbọn o ti rú ofin ilu a o si jẹ ẹ niya nitori ofin ti o rú. Bi ẹni ti a jà lole ba fẹ gba ohun-ini rè̩ pada o ni lati lọ si ile-ẹjọ. Ni iwọnba, eyi fi gbese ojuṣe ti a jẹ ara wa hàn ati gbese ojuṣe ti o ga ju wọnyii, ti a jẹ Ọlọrun Ọrun.

A n ri iriri idalare tabi idariji è̩ṣè̩ gba bi a ba ronupiwada tọkantọkan gẹgẹ bi Dafidi ti ṣe nihin. A n pe iriri yii ni orukọ pupọ, orukọ kọọkan si n ṣe apejuwe iṣẹ ti o ṣe ninu ẹlẹṣẹ ati ohun ti ẹni ti o ronupiwada naa ri gbà.

Iriri nla ti ilaja yii ni a saba maa n pe ni idariji (Isaiah 55:7). Ọba nikan ni o ni agbara lati dariji, ṣugbọn nihin yii, Ọlọrun tikara Rè̩ ni o n fi è̩ṣẹ ji ẹlẹṣẹ ti o ba ronupiwada. A ki yoo da ẹlẹṣẹ ti a ba ti dariji lẹjọ mọ fun awọn è̩ṣẹ rè̩ ti o ti kọja. Kristi ti gba iya wọn jẹ.

Idalare ni orukọ miiran ti a tun fi n pe iriri ologo yii (Romu 5:1). Onidajọ ni o n dá ni lare. Idalare ni pe ki a ka eniyan si olododo, ki a ka a si bi ẹni pe kò tilẹ ti i dẹṣẹ ri. A le dariji eniyan ṣugbọn ki a má fọkan tan oluwarẹ mọ. S̩ugbọn bi a ba da ni lare, è̩ṣè̩ ti o ti ṣẹ ki yoo tabuku fun un rara ni ọjọ iwaju. Ohun kan naa ni idariji ati idalare, a n fi i fun ẹlẹṣẹ lọfẹẹ ni.

Igba pupọ ni a n pe iriri yii ni iyipada tabi atunbi (Iṣe Awọn Apọsteli 3:19). Lati ni iyipada ni pe ki a sọ wa di ọmọ Ọlọrun. Itumọ eyi ni pe ẹni ti o ronupiwada yii ti di alabapin iwa Ọlọrun, o bọ si igbesi-aye titun, o si di ẹda titun. Iṣẹ yii, gẹgẹ bi idariji, ni a ṣe ninu ẹlẹṣẹ ti o ronupiwada.

Iṣisẹ miiran nipa aye titun yii tun farahàn ninu ede yii -- isọdọmọ (Galatia 4:4, 5). Nipa atunbi a sọ ẹlẹṣẹ naa di ẹbi Ọlọrun. Tẹlẹ ri, ọmọ ọrun apaadi ni oun i ṣe -- ọmọ Satani -- ṣugbọn nisisiyii o ti ni Baba titun – ani Ọlọrun – o si di ajogun Ijọba Ọrun ati ogún awọn eniyan mimọ.

Ipa Meji ti Ẹṣẹ Pin sí, ati Etutu Rẹ

S̩ugbọn adura Dafidi si Ọlọrun fi hàn pe Dafidi mọ pe iṣẹ oore-ọfẹ ti o jinlẹ ju idariji è̩ṣẹ wà, o si ṣe danindanin. O tun ri ọkàn ara rè̩ lẹẹkan si i ni ipò ibajẹ, ti o jọ ti ẹni ti a ko ti i fi Ẹjẹ isọdimimọ nì wè̩. Gbogbo eniyan, afi Kristi, ni a bí pẹlu ọkàn ti o tè̩ si ibi; nitori gbogbo eniyan, afi Kristi, ni i ṣe iru ọmọ baba wọn, Adamu. Kristi ni ẹda mimọ nitori Ọmọ Ọlọrun ni Oun i ṣe. A bi Kristi lati inu Maria gẹgẹ bi “ohun mimọ,” a si tun sọ pe Oun ni “Jesu Ọmọ mimọ”, “Ẹni Mimọ Ọlọrun” ati “lai si è̩ṣẹ.” A si tun kọ ọ pe Oun “kò mọ è̩ṣẹkẹṣẹ” ati pe Oun “kò dẹṣè̩.” Ni ọna bayii, O yatọ si awọn iyoku eniyan ti a bí ninu aye yii. Gbogbo eniyan iyoku ni a bi ninu è̩ṣẹ ati pẹlu ẹṣẹ ninu ẹda wọn: a si ni lati fi Ẹjẹ iwẹnu ni wè̩ wọn.

Ninu ede Heberu ọrọ meji wà ti a fi n ṣe apejuwe oriṣiriṣi iwẹnu, a si n lo awọn ọrọ wọnyii pẹlu ikiyesara gidigidi. Ekinni duro fun iru iwẹnu eyi ti o n fọ ohun naa ti a n wè̩ ni afọdenu, a si wè̩ é̩ mọ laulau. Ekeji si n sọ ti iwẹnu ti kò de inu, ti o jẹ ti ode ara nikan ṣoṣo. Dafidi n tọka ninu Saamu yii si iwẹnu ti iṣaaju, pe iwẹnumọ patapata wà -- ti ode ati ti inu – nipa Ẹjẹ etutu. Ọrọ kan naa ni Jeremiah lò nigba ti o wi pe, “wẹ ọkàn rẹ kuro ninu buburu, ki a ba le gba ọ la” (Jeremiah 4:14).

Ohun gbogbo ti o wà ninu Agọ, ati gbogbo ijọ Israẹli ni a wè̩ mọ nigba ti alufaa ba fi hissopu wọn ẹjẹ irubọ. Igbe atọkanwa Dafidi pe, “Fi ewe-hissopu fọ mi” n tọka si iwẹnumọ nipa Ẹjẹ Etutu. O fẹ iṣẹ aṣepe, o si fé̩ lati ṣe ohun gbogbo ti o yẹ lati ṣe ki iṣẹ iwẹnumọ nì le ṣe ni igbesi-aye rè̩.

Gẹgẹ bi ẹri pe Dafidi n walè̩ jin nipa eto igbala tayọ idariji è̩ṣẹ ti o ti da, o kigbe bayi pe, “Da aiya titun sinu mi.” Iru ọrọ kan naa ti a lo nigba dida aye ni Dafidi lo nihin yii, itumọ eyi ti i ṣe lati mu riri jade lati inu airi. Dafidi kò beere agbara kún agbara, tabi iranlọwọ fun ailera rè̩, tabi lati huwa ọmọluwabi, nipa ipá ati agbara Ọlọrun. Ohun ti o n beere fun ni ẹda titun.

Nipa ẹda, gbogbo wa ni o buru ti a si bajẹ, nitori a ti kú ninu aiṣedeedee ati è̩ṣẹ. Ohun ti o ti kú ki i tun wà ni aaye mọ afi bi a ba fi agbara ẹmi iye ti kò si ninu rè̩ mọ fun un. Eyi ti o si ti dibajẹ ki i tun di ọtun afi bi a ba fi ohun titun miiran rọpo rè̩. Ogbologbo ọkunrin ni kò le yipada lati di ọkunrin titun. A ni lati bọ ogbologbo ọkunrin nì “sọnù.” Ogbologbo ọkunrin nì kò le jẹ ipilẹṣẹ fun igbesi-aye titun. Idiwọ ni o tilẹ jẹ fun igbesi-aye titun. Ọkunrin titun, eyi ti a “dá ninu Kristi Jesu,” ni a ni lati gbé wọ dipo, bi a ba fẹ dabi Jesu.

A fi ọna meji ti è̩ṣè̩ pin si ati iwẹnu ilọpo meji ti a ti pese silẹ hàn fun ni ni ibi pupọ ninu Bibeli. A n ri idariji gbà fun gbogbo iwa buburu ati aiṣedeedee wa, ṣugbọn orisun aiṣododo -- iṣẹ ara, ati è̩ṣẹ abinibi – ni a n wè̩ mọ. Nigba pupọ, iwa buburu – tabi irekọja – ni a saba maa n tọka si bi ohun ti o ju ẹyọ kan lọ, ṣugbọn orisun aiṣododo, -- iṣe-ara, è̩ṣẹ abinibi – ni a saba maa n tọka si bi ohun ti kò ju ẹyọ kan lọ. “Bi awa ba jẹwọ è̩ṣẹ wa, olõtọ ati olododo li on lati dari ẹṣẹ wa jì wa (iwẹnu kin-in-ni) ati lati wè̩ wa nù kuro ninu aiṣododo gbogbo (iwẹnu keji)” (1 Johannu 1:9). “Bi awa ba wipe awa kò dẹṣè̩” – eyi yìí ni pe awa kò fẹ iwẹnu ikinni, -- ki i ṣe pe a mu Ọlọrun leke nikan ṣugbọn awa tikara wa di ẹlẹri eke, nitori è̩ṣẹ abinibi kò fara sin. (1 Johannu 1:10; Galatia 3:22).

A tun le ka imukuro ilọpo meji è̩ṣè̩ ninu awọn ẹsẹ miiran ninu Bibeli. Gbogbo è̩ṣẹ ode-ara ni a o fi ji (Isaiah 55:7), ti a o dariji (Marku 11:25; Efesu 4:32), ti a o mú kuro (Orin Dafidi 103:12), ti a o parẹ (Isaiah 44:22), ti a o gbe sọ sẹyin Ọlọrun (Isaiah 38:17), a ki yoo ranti wọn mọ (Heberu 8:12). S̩ugbọn ti iṣé̩ oore-ọfẹ keji yatọ patapata si eyi, nitori nipa rè̩ ni a n pa è̩ṣè̩ run ninu ọkàn (Romu 6:6), ti a n di okú si è̩ṣẹ (Romu 6:11), ti a n wè̩ wa mọ (Esekiẹli 37:23; Efesu 5:26, 27), ti a n wẹ wa ni ọkàn mọ (Iṣe Awọn Apọsteli 15:9); awọn ti o si ri oore-ọfẹ yii gbà a maa wà ni inu kan (Johannu 17:17, 21, 23; Heberu 2:11; Iṣe Awọn Apọsteli 2:1), wọn si jẹ aláyà funfun (Orin Dafidi 24:4; Matteu 5:8).

Pípé ati Itẹsiwaju ninu Iwa-bi-Ọlọrun

Ododo ni jijẹ ọkan pẹlu Kristi -- jijọ Kristi. Nigba ti a ba n dagba ninu oore-ọfẹ ati imọ Oluwa wa Jesu Kristi, nipa ririn ninu gbogbo imọlẹ ti o tàn si ipa ọna wa a n dagba ninu ododo. Idagbasoke yii bẹrẹ pẹlu isọdọmọ ninu ẹbi Ọlọrun, ṣugbọn kò pari si iriri isọdimimọ, nitori pe ati igba de igba ni a n ri imọlẹ si i, nipa iriri Onigbagbọ. S̩ugbọn idagbasoke yii ki i ṣe isọdimimọ nitori iriri ologo yii jẹ ohun ti a n ri gbà lẹsẹkẹsẹ. Iwẹnumọ n sọ nipa iṣẹ ti a ti ṣe pari, nitori nigba ti a ba ti wẹ ohunkohun mọ, nnkan naa di mimọ. Ẹwẹ, a n kà wa si ẹni pipe bi a ba mu gbogbo ohun wọnni ṣẹ ti a n beere lọwọ wa. A n ka ọmọ ti o n ka iwe kin-in-ni si ẹni pipe, bi o ba ṣe gbogbo ohun ti a n beere lọwọ oniwe kin-in-ni, bi o tilẹ jẹ pe oun kò di pipe bi ẹni ti o wa ni iwe kẹjọ ti jẹ. Iriri isọdimimọ patapata, eyi ti i ṣe iwẹnumọ kuro ninu è̩ṣẹ abinibi, jẹ iṣẹ oore-ọfẹ ti o yanju ti o si n ṣe lẹsẹkẹsẹ. S̩ugbọn iṣẹ aṣepe yii ki i ṣe ohun ti o pari lẹẹkan ṣoṣo, iṣẹ ti o n tẹ siwaju ni.

Èdè ti a n lò ninu Bibeli lati fi ṣe apejuwe isọdimimọ fi hàn pe iṣẹ yii a maa ṣe lẹsẹkẹsẹ. A n pè é ni ikọla àya (Deuteronomi 30:6; Kolosse 2:11). Iṣẹ iwẹnu ni, ti a ṣe ilana rè̩ lati mu iṣẹ ti ara kuro ninu ẹda eniyan (Orin Dafidi 51:7; Johannu 15:2). Iṣẹ fífọmọ ni, eyi ti i ṣe gbigbá ohun eeri kuro ninu igbesi-aye eniyan (Orin Dafidi 51:7; Esekiẹli 36:26; 1 Johannu 1:9). A n tọka si i bi iṣẹ atunda, eyi ti i ṣe mimu ohun titun wá si aye (Orin Dafidi 51:10; Efesu 4:24; Orin Dafidi 33:9). A si n pe e ni iparun (Romu 6:6).

A tun ri idaniloju rè̩ lati inu awọn ede ti a ti kọ Bibeli jade. Ogbogi kan ninu ede Griki ti a fi kọ Majemu Titun sọ bayii pe: “Nigba ti a ba n ṣe ayẹwo iṣẹ iwẹnumọ ninu ọkàn Onigbagbọ. . . .i baa ṣe ti ibi titun tabi isọdimimọ patapata, a o ri i pe ede ti a lo fun isọdimimọ kò fi hàn pe ohun ti o n ṣe diẹdiẹ tabi ohun ti o n di ara fun ni nigbooṣe, tabi ti a n ri gba diẹdiẹ titi a o fi ri i gba ni kikun ni, ṣugbọn o n sọ nipa rè̩ bi ohun ti o n ṣẹlẹ lẹsẹkẹsẹ lẹẹkan ṣoṣo gbọn ọn.” Gbogbo iwe atumọ ede ti o ni laari yoo fi hàn pe ede Griki ti o sọ nipa isọdimimọ ṣe apejuwe rè̩ bi ohun ti a ti ṣe, kò si lo èdè yii lọna ti o fi hàn fun ni pe ohun ti a n ṣe diẹdiẹ tabi leralera ni. Ninu ibi mejidinlaadọrun (88) ninu Majẹmu Titun ti a ti tọka si iṣẹ isọdimimọ, nibi ti a ti lò awọn ọrọ wọnyii: “Wẹmọ,” “sọdimimọ,” “wẹnu,” ibi mẹrinlelogoji (44) ni a gbe lo èdè ti o fi han ni pe ohun ti o ti ṣe kọja ti o si ṣẹlẹ lẹsẹkẹsẹ ni. Awọn ọrọ miiran ni a lò ni ọna ti o fi hàn bi ẹni pe ohun ti o ṣẹlẹ naa ṣe lẹsẹkẹsẹ tabi kò si ti pari, ṣugbọn kò si ibi kan ti a gbe sọrọ lọna ti o fi hàn pe iṣẹ ti a ṣe naa jẹ iṣẹ ti o n ṣe diẹdiẹ nikan.

A kò sọ fun ni ninu Iwe Mimọ bi a o ti duro pẹ to ki a to gba isọdimimọ lẹyin ti a ti ni igbala. Ohun ti o ṣe pataki ti a gbọdọ ni ki a to beere fun isọdimimọ ni idalare ati wiwa ni ipo atunbi. A rọ awọn “ọmọ-ọwọ ninu Kristi” lati “lọ si pipé”; aṣẹ yii si wa fun gbogbo awọn Onigbagbọ, “Ẹ jẹ mimọ; nitoriti emi jẹ mimọ.” Ọrọ Ọlọrun ti o wi pe, “nitori eyi ni ifẹ Ọlọrun, ani wiwà ni mimọ nyin,” wà fun gbogbo awọn Onigbagbọ niwọn bi o ti jẹ pe awọn ti o ṣẹṣẹ di Onigbagbọ ti wọn si jẹ ọmọ-ọwọ ninu Kristi ni a kọ sọ ọrọ wọnyii fun. O jé̩ iṣẹ aigbọdọ má ṣe ati anfaani fun gbogbo awọn Onigbagbọ lati ni ọkàn ti a wè̩ mọ kuro ninu è̩ṣẹ abinibi, ki a si fi ifẹ kún ọkàn wọn lẹsẹkẹsẹ lẹyin ti wọn ti ri idalare gbà.

Eso Ododo

Atunbi jé̩ iriri Onigbagbọ ti o pé nitori a ti fi gbogbo è̩ṣẹ ji ẹni ti o ronupiwada o si ni alaafia pẹlu Ọlọrun. Gbogbo awọn ẹni irapada ni a fi agbara fún lati gbé igbesi-aye ailẹṣẹ, lati rin ninu imọlẹ Ọlọrun, lati bori gbogbo idanwo aye yii, ti ara ati ti eṣu, ati lati gbe igbesi-aye iwa-mimọ ati lati wà ni irẹlẹ.

Isọdimimọ patapata jẹ ifẹ pipe eyi ti Ọlọrun n fi sinu ọkàn. On ni o n wẹ ọkàn ati ara mọ kuro ninu è̩ṣẹ abinibi o si n fi agbara iwa mimọ Ọlọrun kún ọkàn. O n mu aworan Ọlọrun pada bọ sinu ọkàn. Iriri ologo yii ni a n ri gbà lẹsẹkẹsẹ nipa igbagbọ, lẹyin ti a ba ti fi ara wa rubọ ni pipe -- ọmọ Ọlọrun nikan ni o si le ṣe e. Isọdimimọ a maa mu ki eniyan wa ni ipo ifọkansin pipe si Ọlọrun a si maa mu iṣelodi si Ẹmi Ọlọrun ti o wà ninu ara kuro nitori isọdimimọ a maa mu ero ti ara ti i ṣe “ọtá si Ọlọrun” kuro. Ero ti ara “ki itẹriba fun ofin Ọlọrun, on kò tilẹ le ṣe e.” Isọdimimọ patapata a maa mu ki gbogbo ọkàn wà ni irẹpọ pẹlu Ọlọrun ati ifẹ Rè̩.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni mú ki Dafidi ro pe Ọlọrun nikan ni on ṣè̩ si?
  2. Iru ọkàn wo ni Dafidi fi gba a nigba ti a fi è̩ṣẹ rè̩ hàn án?
  3. Njẹ Dafidi ri idariji ati iyọnu Ọlọrun gbà?
  4. Sọ oriṣiriṣi orukọ ti a fun ipilẹṣẹ iriri oore-ọfẹ ninu Bibeli.
  5. Iṣẹ wo ni a ṣe ninu ọkàn ẹni ti a sọ di mimọ?
  6. Sọ oriṣiriṣi ọna ti Ọlọrun n gbà fi ba wa lò lati ṣe wa pé ati lati mú wa yẹ lati pade Rè̩?
  7. Ki ni a n pe ni pipe Onigbagbọ?
  8. Ki ni awọn ẹri ti a ni lati fi hàn pe isọdimimọ jé̩ iriri ti o n ṣẹlẹ lé̩è̩kan gbọn ọn?
  9. Kọ awọn ẹsẹ ti o ṣe pataki ninu Saamu yii ki o si kà wọn.
  10. Irú ipò wo ni Dafidi wà ni ikẹyin, gẹgẹ bi ipari ẹsẹ Saamu yii ti fi hàn?