Lesson 233 - Senior
Memory Verse
AKỌSORI: “Alabukún-fun li awọn oninu-funfun: nitori nwọn ó ri Ọlọrun” (Matteu 5:8).Cross References
I Apẹẹrẹ Oriṣi Ẹlẹṣẹ Mẹta ninu Ayé
1 Awọn eniyan buburu ti o pa ti Ọlọrun tì ninu aye wọn ati ero wọn, Orin Dafidi 1:1; Efesu 2:12
2 Awọn ẹlẹṣẹ ti o mọọmọ rú ofin Ọlọrun ni ọgbagadè, Orin Dafidi 1:1; Gẹnẹsisi 13:13
3 Awọn ẹlẹgan ti o n kẹgan iwa-bi-Ọlọrun, Orin Dafidi 1:1; Owe 22:10
II Ẹni ti o Ni Ayọ
1 O kọ ọna awọn ẹlẹṣẹ silẹ, Orin Dafidi 1:1
2 Ofin Oluwa ni didun inu rè̩, Orin Dafidi 1:2; Filippi 4:8
3 Oun a maa ṣe aṣeyọri, ṣugbọn ẹlẹṣẹ a maa bọ sinu iparun, Orin Dafidi 1:3-6; Jakọbu 1:25; Matteu 3:12
III Ọkunrin naa ti o fi Ọrun S̩e Ile Rè̩
1 O n rìn ninu ofin Oluwa, Orin Dafidi 15:1, 2; 1 Johannu 5:3
2 O fé̩ aladugbo rè̩ o si bu ọlá fun olododo, Orin Dafidi 15:3, 4; 1 Peteru 4:8
3 O wẹ ọkàn rè̩ mọ kuro ninu ojukokoro gbogbo, Orin Dafidi 15:5; Luku 12:15
4 Ọwọ rè̩ mọ, àyà rè̩ si funfun, Orin Dafidi 24:1-10
Notes
ÀLÀYÉIlepa Ibukun
Itumọ “ibukun” ninu Saamu yii ni “ayọ.” Nitori naa a le ri ọna si ayọ tootọ ninu awọn ẹsẹ ọrọ wọnyii. Ilepa ayọ ti mu ki awọn eniyan la aṣalẹ gbigbona Sahara ati awọn oke Alaska oniyinyin kọja. Awọn eniyan si ti dara pọ mọ awọn ẹgbẹ ajiṣefinni lati lepa ayọ, awọn miiran ninu ile-iwe adado ti wọn n kọ nipa è̩sin. Ohun kan naa ni ọkàn amoye ati ope n ṣe afẹri – eyi yii ni ilepa ayọ. S̩ugbọn ayọ tayọ ọrọ tabi aini, o yatọ si pe ki a jẹ ọlọgbọn tabi ope. Iṣisẹ kin-in-ni ti a ni lati gbe ki a ba le ni ayọ ni pe ki a kọ imọran awọn eniyan buburu, ki a si yà kuro lọna awọn ẹlẹṣẹ, ki a si maa wá Oluwa.Iṣubu sinu È̩ṣẹ
Iru eniyan mẹta ni a darukọ ninu ẹsẹ kin-in-ni Saamu yii -- awọn eniyan buburu, awọn ẹlẹṣẹ ati awọn ẹlẹgan. Ohun mẹta ni awọn ẹgbẹ mẹtẹẹta yii si n ṣe – irin, iduro ati ijokoo. Ninu apejuwe yii ni a ri apẹẹrẹ eniyan ti o n tọ ipa ọna iṣubu sinu è̩ṣẹ. Lọna kin-in-ni o n ba awọn eniyan buburu rìn -- awọn eniyan ti kò ti i rin jinna ninu è̩ṣẹ dida, ṣugbọn wọn kò ni Ọlọrun. O le jẹ pe awọn eniyan ti o n ba pade ni ibi iṣẹ ti wọn n pe e lati lọ pẹja ni ọjọ Oluwa nigba ti o yẹ ki o wà ninu ile Ọlọrun. Ẹwẹ a tun ri i ti o duro ni ọna awọn ẹlẹṣẹ. Nihin a ri i bi o ti duro ti o n fi ẹsẹ palẹ kiri pẹlu awọn ti n da è̩ṣẹ ni gbangba. Ọkàn rè̩ balẹ, laipẹ oun naa bẹrẹ si rin lọna ti wọn n rin, nikẹyin o jokoo ni ibujokoo awọn ẹlẹgan, o si bẹrẹ si pẹgan ohun gbogbo ti o jé̩ ododo ati mimọ ni ọgbagade, ọkàn rè̩ si korira gbogbo ẹkọ ti o wà ninu Bibeli. “Ẹgbé̩ buburu bà iwa rere jẹ” (1 Kọrinti 15:33).
Ọna si Inudidun
Ẹni ti o ni ayọ ni ẹni naa ti o takete si ohun ti i ṣe ibi ti o si pa ara rè̩ mọ kuro ninu imọràn awọn eniyan buburu. “Máṣe bọ si ipa-ọna enia buburu, má si ṣe rìn li ọna awọn enia ibi. Yè̩ ẹ silẹ, máṣe kọja ninu rè̩, yè̩ kuro nibẹ, si ma ba tirẹ lọ” (Owe 4:14, 15). S̩ugbọn ayọ tayọ pe ki a yẹra kuro ni ọna awọn ẹlẹṣẹ nikan. Ohun kan wà ti a ni lati ṣe. “Didùn-inu rè̩ wà li ofin OLUWA; ati ninu ofin rè̩ li o n ṣe aṣaro li ọsan ati li oru.” Bi ẹni kan ba ni inudidun si Ofin Oluwa, eyi nì ni pe yoo jẹ oloootọ si Ofin naa. Bi o ba n ṣe aṣaro ninu rè̩ ni ọsan ati ni oru, Ofin naa yoo si di ara fun un. S̩iṣe aṣaro ninu Ofin Oluwa ki i ṣe igbala; ṣugbọn kikọ ẹkọ nipa ofin naa a maa fi Kristi ati ohun ti o yẹ ki a ṣe hàn fun ni, a si maa fi ibukun ti o wà ninu eto nla ti igbala hàn ni. Bi a ba mọ ara wa ni ẹlẹbi ti a si ronupiwada tọkantọkan a o gba ọkàn wa la, èyí yii ni ọna si igbesi-aye ayọ.
Wo bi iyatọ naa ti pọ to laaarin awọn ti o ti bá Ọlọrun laja ati awọn alaiwa-bi-Ọlọrun ti o n tọ ọna ti ara wọn lati wá ayọ ti aye yii. Awọn olododo dabi “igi ti a gbìn si eti ipa odò, ti nso eso rè̩ jade li akokò rè̩,” ṣugbọn awọn eniyan buburu “dabi iyangbo ti afẹfẹ nfẹ lọ.” Awọn eniyan buburu le fẹ fidimulẹ ṣinṣin ni aye yii; wọn le fi ara wọn si abẹ aabo kuro lọwọ gbogbo iyọnu aye yii; wọn si le fi ara wọn si abẹ aabo awọn ẹgbẹ oniṣowo nla; ṣugbọn nigba ti afẹfẹ ba fẹ, wọn yoo dabi iyangbo ti afẹfẹ n fẹ lọ. Awọn olododo le ṣe alai ni ohun pupọ ni aye yii, ṣugbọn gbongbo wọn fi idi mulẹ ni ayeraye. A o pa wọn lara dà ni iṣẹju aaya, ṣugbọn wọn yoo maa tàn bi irawọ lae ati laelae.
“Ọna kan wà ti o dabi ẹnipe o dara li oju enia, ṣugbọn opin rè̩ li ọna ikú” (Owe 14:12). Ọpọ eniyan ni o ti ṣe eto igbesi-aye wọn – ti wọn ti ṣe ilana ipa ọna wọn ni aye – lai si itọni Ọlọrun; ṣugbọn ayeraye ni yoo fi hàn bi aṣiṣe wọn ti pọ to. “OLUWA mọ ọna awọn olododo; ṣugbọn ọna awọn enia buburu ni yio ṣegbe.”
Ọwọ Mimọ ati Aya Funfun
“Tani yio gùn ori oke OLUWA lọ? tabi tani yio duro ni ibi-mimọ rè̩?” (Orin Dafidi 24:3). Itumọ ibeere yii ni pe, “Ta ni yio fi Ọrun ṣe ibugbe rè̩?” A si dahun bayii pe, “Ẹniti o li ọwọ mimọ, ati aiya funfun.” Nigba ti a ba tun eniyan bí, Ẹmi Ọlọrun a jẹri pe o ti di ọmọ Ọlọrun; kò tun si tabitabi nipa eyi. Iwà oluwarẹ ni gbangba kò ni abuku – ó ni ọwọ mimọ. A dari è̩ṣẹ rè̩ ji i, o si wa ni ominira, ṣugbọn ninu ọkan rè̩ ni aworan ẹṣẹ eyi ti a bi ni bi wà. Aworan ẹṣẹ yii ni gbogbo eniyan jogun nipa iṣubu Adamu, a si saba maa n pe e ni aworan Adamu. Nigba ti a ba tun eniyan bi a o tẹri ẹda Adamu ba, a o si mu un wa sabẹ akoso agbara irapada ti o ti wọ ọkàn naa; ṣugbọn ogbologbo ẹda Adamu nì wà nibẹ sibẹ, yoo si fẹ lati maa gbe ori soke ti kò ba ṣe pe ibi titun nì tẹri rè̩ ba. Nigba isọdimimọ, È̩jẹ Jesu Kristi a maa mu aworan è̩ṣẹ kuro, a si pa a run. Pipa è̩ṣẹ run patapata kuro ninu ọkàn ni o n mu ki eniyan wà ni pipe ati mimọ. Nigba naa ni isinmi nì yoo wọ inu ọkàn, ani eyi ti kò ṣe ajeji si olukuluku ẹni ti o ti tọ anfaani yii wò.
Sisẹ Ara Ẹni
Sibẹ, lẹyin ti a ti sọ wa di mimọ ti a si ti bọ lọwọ è̩ṣẹ dida, ifẹ-inu-ẹni wà sibẹ ti a ni lati ba jagun. Paulu Apọsteli wi pe, “Emi nkú lojojumọ.” Ifẹ-inu-ẹni ti o wà ninu rè̩ ni oun n pa kú. Nigba miiran, dipo kikú lojoojumọ si ohun ti i ṣe ti ara ati ohun gbogbo ti o lodi si ifẹ Ọlọrun, yala o tobi tabi o kere, awọn eniyan a maa jẹ ki Ọrọ Ọlọrun bọ sọnu kuro lọwọ wọn nitori iṣoro diẹ. Ninu ipo ìfàsé̩yìn yii, ogbologbo ọkunrin nì yoo tun sọji. A sọ fun wa pe ki a maa yẹ ara wa wo lati mọ bi a ba wa ninu igbagbọ. Saamu ikẹẹdogun dara lọpọlọpọ bi awojiji lati yẹ ara ẹni wò.
Yiyẹ Ara Ẹni Wò
“Ẹniti . . . nsọ otitọ inu rè̩.” Awọn eniyan wà ti irisi oju wọn n tako wọn ti o si n fi hàn pe otitọ kò si ninu wọn. Ohun kan ni lati sọ otitọ inu ẹni – lai si lilọ tabi ayidayida tabi ki a fẹ lati fi otitọ pamọ, ṣugbọn lati fi ọkàn otitọ gba ohun gbogbo. Ẹni ti o n sọ otitọ inu rè̩ jẹ ẹni ti ọkàn rè̩ gbooro ti o si ṣipaya; kò si ohunkohun ti o fẹ fi pamọ.
“Ẹniti kò fi ahọn rè̩ sọrọ ẹni lẹhin, . .” Ẹni ti o fẹ gbe inu ile Oluwa tabi Oke Mimọ Rẹ ko ni sọrọ ẹni lẹyin; tabi ki o sọrọ ibi; kò ni pẹgan tabi ki o kùn, tabi ki o maa wá aleebu ẹlomiran. O yẹ ki a fara mọ otitọ yii lonii ki a má ba padanu Ipalarada Ijọ Ọlọrun. Awọn ẹlomiran a maa rẹ ọmọnikeji wọn silẹ niwaju eniyan. A kò gbọdọ ri iru iwà bẹẹ ninu ọmọ Ọlọrun tootọ. Ohun kan wà ninu rè̩ ti kò ni jẹ ki o ṣe bẹẹ. Nitootọ o le ri i, o si le mọ pe ẹni kan ti ṣe aṣiṣe kan ṣugbọn oun kò jé̩ maa sọ ọ kaakiri. Bi kò le pari ọrọ kan ti o wa laaarin oun ati arakunrin, yoo fi ọrọ naa lọ awọn aṣaaju nipa ti Ọlọrun, awọn ti o ni ẹtọ lati yẹ ọrọ naa wò. Ki i ṣe pe Onigbagbọ kò ni jẹ sọrọ ọmọnikeji rè̩ lẹyin nikan, ṣugbọn oun yoo tun maa kiyesara pe oun kò feti si awọn ti o n ṣe bẹẹ. Oun ki i kẹgan ẹni keji rè̩ bẹẹ ni ki i gba ọrọ è̩gan si ẹnikeji rè̩. Ọpọ ọmọ Ọlọrun ni o ti sọ otitọ nù nipa fi fi eti si awọn asọrọ-kẹlẹ.
“Ẹniti o bura si ibi ara rè̩, ti kò si yipada.” Akoko wà ni igbesi-aye Onigbagbọ nigba ti o ni anfaani lati bura si ibi ara rè̩, ti kò si yipada. Eyi ni pe oun kò jẹ rẹ asia otitọ silẹ niwaju Oluwa lati le bọ kuro ninu iṣoro tabi ijiya ti o wù ki o wà lọna rè̩. Fun apẹẹrẹ, oluwarẹ ti le sa gbogbo ipá rè̩, o le ti rin deede ki o si ṣe eyi ti o tọ; sibẹ ki a ṣe inunibini si i. Boya o le maa ro pe; “Tabi mo ti ṣe aṣeju” nipa bayii ki o si bẹrẹ si fawọ sẹyin diẹdiẹ. Nihin yii gan an ni o ti n “yipada.” Ẹni ti o “bura si ibi ara rè̩” ki i wá lati gbe ẹbi ru ẹni keji rẹ tabi ki o kó ọmọnikeji rè̩ sinu wahala. Bi o tilẹ jẹ pe kò ye e, oun yoo yàn lati jiya ju ati mu ki ẹni keji rè̩ ki o jiya lọ.
“Ẹniti kò fi owo rè̩ gbà èle, ti kò si gbà owo è̩bẹ si alaiṣẹ.” Kò si ohun ti o n fun ni ni ifọkanbalẹ bi ọkàn ti o mọ. Ẹni ti o n ṣiṣẹ ododo ki i ṣe ibi. Eti Oluwa si ṣi si igbe awọn ti a n nilara, O si n rán idajọ si awọn ti o n jẹ talaka niya. “Ọna awọn eniyan buburu ni yio ṣegbe.” Gbogbo owo abẹtẹlẹ ati owo ele ti eniyan buburu gbà ni yoo fi silẹ lọ, oun paapaa yoo si ṣegbe titi lae.
Ipin olododo yatọ si eyi! “Ẹniti o ba ṣe nkan wọnyi ki yio yẹsẹ lailai.” O fidii mulẹ ni aye yii, o bura si ibi ara rè̩ kò si yipada, yoo si maa gbe ni Oke Mimọ titi laelae, -- ani nibi ti Ọlọrun n pese silẹ fun gbogbo “awọn ti o fẹ ẹ.”
Questions
AWỌN IBEERE- Ki ni itumọ ọwọ mimọ?
- Ki ni a n pè ni aya funfun? Iriri wo ni o n fun ni ni aya funfun?
- Ki ni a fi awọn eniyan buburu wé? Ki ni a si fi awọn ẹni iwa-bi-Ọlọrun wé?
- Fun ni ni apẹẹrẹ bibura si ibi ara ẹni.
- Ki ni itumọ sisọ otitọ inu ẹni?
- Sọ ọna meji si ayọ.
- Ki ni Ofin Oluwa?
- Ki ni èdè ti o le lo dipo “isọrọ ẹni lẹyin” ati “ipẹgan”?