Orin Dafidi 8:1-9; 19:1-14; 119:1-24

Lesson 234 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “OLUWA, Oluwa wa, orukọ rẹ ti ni iyin to ni gbogbo aiye!” (Orin Dafidi 8:9).
Cross References

I Iyin si Ẹlẹda lati Ọwọ Ẹda Gbogbo

1 Dafidi kokiki ọlanla Ọlọrun, Orin Dafidi 8:1, 2; Matteu 21:10, 11, 15, 16

2 O ronu nipa ètò awọn iṣẹ Ọlọrun loju ọrun, Orin Dafidi 8:3; Isaiah 40:26; Romu 1:20

3 O tun ṣe aṣaro lori ẹda eniyan ti kò jamọ nnkan, Orin Dafidi 8:4; Romu 1:25

4 O ro ti Kristi ati ti ẹda titun, Orin Dafidi 8:5-9; Heberu 2:6-9

II Gbigbe Ọlọrun Ga Nipasẹ Iyanu Iṣẹ Ọwọ Rè̩

1 Ẹda ọwọ Rè̩ n fi ogo ati imọ Rè̩ hàn, Orin Dafidi 19:1, 2; 98:7, 8; Isaiah 55:12

2 Awọn iṣẹ Rè̩ yin In titi de opin aye, Orin Dafidi 19:3-6; Isaiah 55:11

III Gbigbe Ọlọrun Ga Nipa Ọrọ Iyanu Rè̩

1 Ofin OLUWA pé, Orin Dafidi 19:7-10

2 Ni pipamọ rè̩, ere nla n bẹ, Orin Dafidi 19:11-14; Luku 10:25-28

3 Ọrọ naa ninu ọkàn n gba ni lọwọ è̩ṣẹ, Orin Dafidi 119:1-24

Notes
ÀLÀYÉ

Ìfihàn

Ni ọganjọ oru nigba ti oju ọrun mọlẹ kedere ti irawọ si gba oju ọrun kan, bi Dafidi ti jokoo lẹba oke ti o n ṣọ awọn agutan rè̩, o bẹrẹ si ṣe aṣaro lori ẹwà awọn ogun ọrun, o si n ronu nipa Ẹlẹda ti o dá gbogbo agbaye ti o tobi bẹẹ. O wi pe, “Awọn ọrun nsọrọ ogo Ọlọrun; ati ofurufu nfi iṣẹ ọwọ rè̩ han” (Orin Dafidi 19:1). Ọpọlọpọ awọn ọjọgbọn lọjọ oni ti o ni imọ nipa awọn awari nlanlà kuna lati fi awọn awojiji ati ẹrọ ti a fi n wo awọn ohun ti o wà lokeere réré riran to bi Dafidi ti riran nigba ti oju igbagbọ rè̩ mu un riran kọja awọn ohun ti a dá lọ si ọdọ Ẹlẹda, Alagbara ju lọ. Nigba pupọ ni awọn ti o n ṣe iwe fun awọn akẹkọọ n fi iṣẹ iyanu Ọlọrun pe ohun ti o ṣẹlẹ lasan, nipa imọ ijinlẹ ti o n kọ ni pé n ṣe ni eniyan dagba lati inu degbenseri ki o to wa di eniyan.

Ọrọ Ọlọrun sọ fun wa pe: “Nitori ohun rè̩ ti o farasin lati igba dida aiye a ri wọn gbangba, a nfi oyé ohun ti a da mọ ọ, ani agbara ati iwa-Ọlọrun rè̩ aiyeraiye, ki nwọn ki o le wà li airiwi: Nitori igbati nwọn mọ Ọlọrun, nwọn kò yin i logo bi Ọlọrun, bḝni nwọn kò si dupẹ; ṣugbọn nwọn wa idasan ni ironu wọn, a si mu ọkàn òmúgọ wọn ṣòkunkun. Nwọn npè ara wọn li ọlọgbọn, nwọn di aṣiwere” (Romu 1:20-22). Ọpọlọpọ aṣiwere ni o n sọ ninu ọkàn wọn sibẹ pe Ọlọrun kò si. Sibẹ Ẹni ayeraye ni Ọlọrun, awọn ọrun n sọrọ ogo Rè̩ sibẹ.

Ailopin

“Sa wò ori awọn irawọ bi nwọn ti ga tó!” (Jobu 22:12). Awọn eniyan kò dẹkun lati maa ṣe iwadi ọrun bi o ti tobi tó ti wọn si n fi digi ifi wo ohun ọnà jínjìn wo awọn irawọ ti o gbilẹ de ọna jijin réré ti o tayọ oye eniyan. A sọ fun ni pe ọkan ninu awọn irawọ ti a ṣè̩ṣè̩ ṣe awari rè̩ jinna to bẹẹ ti yoo gba eniyan ni ẹgbaafa le ẹẹdẹgbẹta ọkẹ ọdun (ọdun 250,000,000) lati de ibi ti o wà bi oluwarẹ tilẹ le sare bi manamana. Eyi yii ni o ya Dafidi lẹnu ti o fi sọ bayii pé, “Nigbati mo rò ọrun rẹ, iṣẹ ika rẹ, oṣupa ati irawọ, ti iwọ ti ṣe ilana silẹ; Kili enia, ti iwọ fi nṣe iranti rè̩?” (Orin Dafidi 8:3, 4). Sibẹ, Ọlọrun ninu aanu Rè̩ sọ fun wa pé Oun yoo bá onirobinujẹ aya ati onirẹlẹ ọkàn gbé. Ẹlẹda ọrun on aye a maa ṣe awari ero ati ete ọkàn eniyan, ki Oun ki O le fi ara Rè̩ hàn bi alagbara fun awọn ọkàn wọnni ti o pé sọdọ Rè̩.

“Gẹgẹ bi a kò ti le ka iye ogun-ọrun, tabi ki a le wọn iyanrin eti okun” (Jeremiah 33:22). Nigba pupọ ni aye igba nì, eniyan a maa ka iye awọn irawọ wọn a si maa fi orukọ fun wọn, ṣugbọn pẹlu awojiji yii, eniyan le ni anfaani lati ri ẹgbaa ọkẹ (40,000,000) irawọ dipo ẹyọ kan ti oun le fi oju lasan ri lọ. Bi awojiji yii ti a n lo ba ti lagbara tó bẹẹ ni akojọ awọn irawọ titun n fi ara hàn to. Ailonka ni awọn irawọ ti a ti ṣe awari rè̩ lode oni. S̩ugbọn ta ni le mọ bi iye awọn irawọ ti o fara pamọ ti a kò i ṣe awari wọn ti pọ tó? “Njẹ tani ẹnyin o ha fi mi we, tabi tali emi o ba dọgba? ni Ẹni-Mimọ wi. Gbe oju nyin soke sibi giga, ki ẹ si wò, tali o dá nkan wọnyi, ti nmu ogun wọn jade wá ni iye: o npè gbogbo wọn li orukọ nipa titobi ipá rè̩, nitoripe on le ni ipá; kò si ọkan ti o kù” (Isaiah 40:25, 26). Pẹlupẹlu gẹgẹ bi irawọ ti pọ to ni oriṣiriṣi nì, sibẹ olukuluku wọn ni o yatọ si ara wọn. Olukuluku wọn ni Ọlọrun si fun ni orukọ! “Ọtọ li ogo ti õrùn, ọtọ li ogo ti oṣupa, ọtọ si li ogo ti irawọ; irawọ sá yàtọ si irawọ li ogo” (1 Kọrinti 15:41). S̩ugbọn gbogbo wọn ni o n fi ogo Ọlọrun wa hàn.

Yíyípo

Aye n yipo lẹẹkan ni wakati mẹrinlelogun. Eyi ni pé bi ẹni kan ba wa ni agbedemeji aye, ẹni naa yoo rin to ọkẹ kan le ẹgbẹẹdọgbọn ibusọ (25,000) ni wakati mẹrinlelogun nipa ayika aye yii. Ki i ṣe pe aye n yipo lojoojumọ nikan ṣugbọn ni ọdọọdun ni o n yi oorun ká lẹẹkan, nipa bayii o n rin tó ẹgbaa mẹẹdogun ọkẹ ibusọ (600,000,000). Ki i ṣe eyi nikan, gbogbo awọn aye ti o dabi ti wa yi n yi ara wọn po, wọn si n rin to ẹgbaawa ọkẹ ibusọ (400,000,000) ni ọdun kan. Ronu le iṣipopada yii – gbogbo ẹda alaaye kọọkan ti o wà lori ilẹ aye ni o n rin ẹgbaa ibusọ (2,000) ni iṣẹju kan, sibẹ a kò mọ ohunkohun, a kò si mọ ọn lara rara. Ọkọ oju-omi n kọlu ara wọn lori agbami okun, ọkọ ofuurufu n sọlu ara wọn, ọkọ ilẹ n dà wó, bẹẹ ni ayọkẹlẹ n ṣe jamba; ṣugbọn aimoye ẹda ọrun (ayé, awọn irawọ ati bẹẹ bẹẹ lọ) n sare jú bi a ti le rò lọ, sibẹ “kò si ọkan ti o kù.” Wo bi aye yii ti Ọlọrun ti sọ lọjọ si ofuurufu yii ti wuwo tó, si wo bi agbara nì ti le pọ tó, ti yoo maa mun un sáré ni ipa rè̩ -- “O…si fi aiye rọ li oju ofo” (Jobu 26:7).

Dafidi sọ nipa ijade oorun pe “o dabi ọkọ iyawo ti njade ti iyẹwu rè̩ wá, ti o si yọ bi ọkọnrin alagbara lati sure ije. Ijadelọ rè̩ ni lati opin ọrun wá, ati ayika rè̩ si de ipinlẹ rè̩: kò si si ohun ti o fi ara pamọ kuro ninu õru rè̩” (Orin Dafidi 19:5, 6). Oluwa ba Jobu sọrọ nipa bi awọn ẹda ọrun wọnyii ti n yi bayii pe: “Iwọ le ifi ọja de awọn irawọ meje (Pleyade) tabi iwọ le itudi irawọ Orionu? Iwọ le imu awọn ami mejejila irawọ (Massaroti) jade wá ni igba akoko wọn? tabi iwọ le ṣe amọna Arketuru pẹlu awọn ọmọ rè̩? Iwọ mọ ilana-ilana ọrun?” (Jobu 38:31-33). Nigba ti a wo bi awọn ẹda ọrun wọnyii ti n yipo leto leto lọna ti ki i tase – ani irawọ ni awọn alagogo ti o n ṣe agogo ti o n ṣiṣẹ deede n wò lati ṣeto iṣiṣẹ agogo wọn – a kò le ṣe alai gbe ohun wa soke wi pé, “Titobi li OLUWA, o si ni iyìn pupọpupọ; awamaridi si ni titobi rè̩” (Orin Dafidi 145:3).

Ọrọ Ọlọrun

Bi o tilẹ jẹ pé awọn ohun ti Ọlọrun dá n fi titobi Ẹlẹda hàn, Ọlọrun paapaa ti fi ara Rè̩ hàn ni oriṣiriṣi ọna lai si tabitabi, lati ipilẹṣẹ aye titi di akoko yii. S̩aaju ki Adamu to dé̩ṣè̩, Ọlọrun a maa ba a rìn ninu Ọgbà. Lẹyin iṣubu rè̩ nipa eyi ti è̩ṣẹ wọ inu gbogbo ẹda alaaye, Ọlọrun kò dẹkun lati maa fi ara Rè̩ ati ifẹ Rè̩ hàn fun eniyan. Ọlọrun bá awọn wolii sọrọ O si fi ara Rè̩ hàn fun wọn ninu iran ati àlá. A sọ fun wa pe “asọtẹlẹ kan kò ti ipa ifẹ enia wá ri; ṣugbọn awọn enia mimọ Ọlọrun nsọrọ lati ọdọ Ọlọrun bi a ti ndari wọn lati ọwọ Ẹmí Mimọ wá” (2 Peteru 1:21). “Ọlọrun, ẹni, ni igba pupọ ati li onirru ọna, ti o ti ipa awọn woli ba awọn baba sọrọ nigbāni. Ni ikẹhin ọjọ wọnyi o ti ipasẹ Ọmọ rè̩ ba wa sọrọ, ẹniti o fi ṣe ajogun ohun gbogbo, nipasẹ ẹniti o dá awọn aiye pẹlu” (Heberu 1:1, 2). Ọlọrun fi ara Rè̩ hàn gbangba nigba ti Jesu, Ọmọ Ọlọrun wá si aye yii lati maa ba eniyan gbe, lati kọ wọn ati lati jẹ apẹẹrẹ fun wọn bi a ṣe le rìn ninu gbogbo ofin Ọlọrun. Ki i ṣe kiki pe O jẹ apẹẹrẹ iru igbesi-aye ti a ni lati gbe nikan, ṣugbọn nipa ikú Rè̩, O fi ara Rè̩ ṣe etutu fun è̩ṣẹ; ki awa, nipa Ẹjẹ Rè̩ le ri irapada gbà kuro ninu è̩ṣẹ wa, ati nipa agbara Rè̩ ki a le pa ifẹ tabi ofin Rè̩ mọ.

Ofin Pipe

Ninu Orin Dafidi ikọkandinlogun a ṣe apejuwe ofin Oluwa ni oriṣiriṣi ọna. A pe e ni ofin pipe, ofin ti o daju, ti o tọ, ti o si funfun, ofin ti o mọ ti o si jẹ otitọ ati ododo. Iṣẹ ti Ọrọ yii n ṣe pọ pupọ: o n yi ọkàn pada, o n sọ ope di ọlọgbọn, o n mu ọkàn yọ, o n ṣe imọlẹ oju, pipẹ ni titi lae. Iye rè̩ ju “wura daradara pupọ” wọn si “dùn jù oyin lọ, ati riro afara oyin.” Ọlọrun wa ti o n ṣe ilana gbogbo agbaye, bi o ti tó ni, ti fun wa ni ilana pipe nipa eyi ti a le ṣe akoso igbesi-aye wa ki a si maa ba A gbe titi ayeraye.

Ninu ẹsẹ mẹrindin-ni-ọgọsan ti o wà ninu Orin Dafidi ikọkandinlọgọfa, ẹsẹ meji pere ni a kò ti ṣe apejuwe ofin Ọlọrun, lọna kan tabi lọna miiran. A pin Saamu naa si ọna mejilelogun a si fi ọrọ ti o bẹrẹ pẹlu ede Heberu si ori ipin kọọkan. Saamu yii n kọ wa ni iru iha pataki ti a gbọdọ kọ si Ọrọ Ọlọrun; gẹgẹ bi Onisaamu ti wi pe, “Ọrọ rẹ ni mo pamọ li aiya mi, ki emi ki o má ba ṣè̩ si ọ” (Orin Dafidi 119:11). Ọlọrun n fẹ ki a pa Ọrọ Rè̩ mọ ki a si maa gbe e ga, nitori a sọ fun wa pe, “Iwọ gbé ọrọ rẹ ga jù gbogbo orukọ rẹ lọ” (Orin Dafidi 138:2). Johannu pe Kristi ni Ọrọ naa: “Li àtetekọṣe li Ọrọ wà, Ọrọ si wà pẹlu Ọlọrun, Ọlọrun si li Ọrọ na” (Johannu 1:1). “Ọlọrun wà nínu Kristi, o mba araiye làja sọdọ ara rè̩” (2 Kọrinti 5:19). Eto irapada Ọlọrun bá eto dida aye mu. “Laiṣiyemeji, titobi ni ohun ijinlẹ iwa-bi-Ọlọrun” (1 Timoteu 3:16).

Iyin si Ọlọrun

Jesu n tọka si ẹsẹ keji Orin Dafidi kẹjọ nigba ti O wi pe, “Ẹnyin kò ti kà a, . . . Lati ẹnu awọn ọmọ-àgbo ati awọn ọmọ-ọmu ni iwọ ti mu iyìn pé?” (Matteu 21:16). Awọn ọta Kristi, ti wọn lero pe wọn n sin Ọlọrun kuna lati fi iyin fun Un, ṣugbọn awọn “ọmọ-ọwọ ati ọmọ-ọmu” – ti wọn jẹ olóòótọ ti wọn kò si ni ododo ara wọn –ni o n kọrin iyin si Ọmọ Ọlọrun. Bi awọn wọnyii ba tilẹ pa ẹnu wọn mọ awọn okuta yoo kigbe soke. Gbogbo ẹda ni o n fi ogo fun Ẹlẹda afi erupẹ ilẹ lasan ti o n fẹ gbe ara wọn ga jù Ẹlẹda lọ. Bi iṣẹ Ọlọrun ti jẹ iyanu to ni, “Ẹniti o kọ ile ti li ọla jù ile lọ” (Heberu 3:3). Oun “ga ju gbogbo ijọba ati ọla, ati agbara, ati oyè, ati gbogbo orukọ ti a ndá, ki iṣe li aiye yi nikan, ṣugbọn li eyiti mbọ pẹlu” (Efesu 1:21).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Akoko wo ni Jesu ka Orin Dafidi ikẹjọ ẹsẹ keji?
  2. Nibo ni a ti le ri i ninu Bibeli ti a gbe tun ṣe atunwi Orin Dafidi Kẹjọ ẹsẹ kẹrin de ẹkẹfa?
  3. Ọna wo ni awọn ẹsẹ wọnyii gba tọka si Kristi?
  4. Ki ni ṣe ti a fi ri ogo Ọlọrun ninu awọn ọrun ju bi Dafidi ti le ri wọn ni igba ti rè̩?
  5. Ọna wo ni Orin Dafidi ikọkandinlogun ẹsẹ keji si ẹkẹrin fi jọ Romu ori kin-in-ni ẹsẹ ogun?
  6. Ọna wo ni iwọ le fi iṣẹ Ọlọrun ati ofin Rè̩ wé ara wọn?
  7. Awọn ọrọ wo ni a lò lati ṣe apejuwe ofin Ọlọrun ninu Orin Dafidi ikọkandinlogun?
  8. Ki ni è̩ṣẹ ìkùgbù?
  9. Ki ni kókó Orin Dafidi ikọkandinlọgọfa?
  10. Bawo ni a ṣe sọ nipa ohun ti i ṣe kókó pataki ninu Orin Dafidi yii ti o fi fẹrẹ jẹ pe ẹsẹ kọọkan ni o sọ nipa rè̩?