Matteu 23:1-39

Lesson 222 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Ki gbogbo nyin ṣe oninu kan, ẹ mā ba ará nyin kẹdun, ẹ ni ifẹ ará, ẹ mā ṣe ìyọnú, ẹ ni ẹmi irẹlẹ” (1 Peteru 3:8).
Notes

Fifẹran Ẹni Keji

Awọn ẹni rere wà ninu aye ti wọn jẹ oninuure ti wọn maa n ro ti ẹni keji wọn, ti wọn si fẹran ẹni keji wọn bi ara wọn. Wọn n gbiyanju lati pa aṣẹ Kristi mọ ti o wi pe: “Gbogbo ohunkohun ti ẹnyin ba nfẹ ki enia ki o ṣe si nyin, bḝni ki ẹnyin ki o si ṣe si wọn gẹgẹ” (Matteu 7:12). Jesu si fi kun un bayii pe, “Nitori eyi li ofin ati awọn woli.”

S̩ugbọn bakan naa ni awọn eniyan mìíràn wà ti wọn kò fẹran ẹnikẹni bi kò ṣe awọn tikara wọn. Bi wọn ba ṣe iṣẹ oore, fun anfaani ara wọn ni, tabi fun awọn ará ile wọn tabi fun ọrẹ wọn timọtimọ. Wọn le ṣe itọrẹ-aanu owó, ṣugbọn wọn n ṣe e lati gba iyin awọn eniyan pe wọn jẹ ẹni ti o lawọ. Bi o tilẹ jẹ pe wọn jẹ anikanjọpọn wọn n fẹ fi ara hàn gẹgẹ bi ẹni rere niwaju awọn ẹlomiran.

Awọn akọwe ati awọn Farisi, nipa awọn ti a n kẹkọọ bayii, jé̩ irú eniyan bẹẹ. Nigba pupọ ni wọn maa n lọ si ile-isin, ṣugbọn wọn a maa lakàkà ni gbogbo ọna pe ki ibujoko ti o dara ju lọ le jẹ ti wọn. Wọn a maa duro ni ikorita opopo ọnà lati gba adura gigun ki awọn eniyan ba le ri wọn. Wọn a maa fá irun wọn nigba ti wọn ba n gbaawẹ, ki gbogbo eniyan ba le ri bi wọn ti jẹ olufọkansin to. Sibẹ ifẹ awọn eniyan wọnyii si ẹni keji wọn kò to nnkan.

Olufunni ni Ofin

Nipasẹ Mose ni Ọlọrun ti fi Ofin fun awọn Ọmọ Israẹli, a si maa n pe Mose ni olufunni ni ofin nigba miiran. Pẹlupẹlu o ti ṣe alaye fun awọn Ọmọ Israẹli ki ni itumọ awọn ọrọ Ofin naa jé̩, ki wọn ba le mọ ohun ti wọn yoo ṣe lati té̩ Ọlọrun lọrun.

Nisisiyii Jesu wa n sọ fun awọn akọwe ati Farisi pe wọn jokoo ni ipò Mose, a si n reti pe ki wọn ṣe ohun ti Mose ti ṣe rí. O jẹ ojuṣe wọn lati kọ awọn ọkunrin ati obinrin ni ohun ti o yẹ ki wọn ṣe ki wọn ba le wà ni ipò ati bá Ọlọrun pade. S̩ugbọn awọn akọwe ati Farisi kò ni iyọnú ti Mose ti ni. N ṣe ni wọn n duro ninu sinagọgu ti wọn si n fi ikanra paṣẹ bayii pe, “Iwọ kò gbọdọ ṣe eyi, . . Iwọ kò gbọdọ ṣe tọhun,” ṣugbọn wọn kò fẹran awọn alaini. Ifẹ Ọlọrun ni o yẹ ki o jẹ ohun ti o ṣe pataki jù lọ ninu igbesi-ayé wọn. Paulu Apọsteli kọwe pe, “Ifẹ li akója ofin” (Romu 13:10).

Nigba ti Jesu wi pe ki a ṣe si awọn ẹlomiran gẹgẹ bi a ti fẹ ki wọn ṣe si wa, O ṣe alaye pe, “Eyi li ofin ati awọn woli,” ki si i ṣe ẹkọ titun. Eyii ni Ofin ti Ọlọrun ti fi fun Mose ti awọn akọwe ati awọn Farisi si ti n kà ti o si yẹ ki wọn ti mọ.

Ofin ninu Ọkàn

Ọlọrun ti paṣẹ fun awọn Ọmọ Israẹli lati maa so Ofin Rè̩ mọ ọwọ wọn ki wọn si fi i ṣe ọja-igbaju niwaju wọn. Eyi ni awọn Farisi ṣe. Wọn wọ filakteri, ti i ṣe ewe iwe gbọọrọ mẹrin, lara ọkọọkan eyi ti a kọ ẹsẹ kan tabi meji Ofin si, ti a si lè̩ mọ apo awọ tabi apamọ kan. Eyii ni wọn so mọ ọrùn ọwọ òsi ati si iwaju ori, wọn si maa n wọ wọn paapaa ni akoko adura. Awọn Farisi pa ofin naa mọ gẹgẹ bi àṣà, ṣugbọn wọn ṣe aifiyesi apa kan ninu eyi ti Ọlọrun ti sọ pẹlu pe: “Ki iwọ ki o si fi gbogbo àiya rẹ, ati gbogbo ọkàn rè̩, ati gbogbo agbara rẹ fé̩ OLUWA Ọlọrun rẹ. Ati ọrọ wọnyi, ti mo palaṣẹ fun ọ li oni, ki o ma wà li àiya rẹ” (Deuteronomi 6:5, 6). Ohun ti o ṣe pataki jù ni lati ni ifẹ Ọlọrun ninu ọkàn wọn dipo ki a kọ ọ sinu iwe pẹlẹbẹ pẹlẹbẹ ki a si so ó mọ ọrùn ọwọ.

Kò si Aanu

Nitori awọn Farisi so Ọrọ Ọlọrun mọ iwaju ori wọn ati ọrùn ọwọ wọn nikan, ti wọn kò si fi si ọkàn wọn, wọn jé̩ alai ni ifẹ, wọn le di ẹrù wuwo ru awọn ẹlomiran, nigba ti awọn funra wọn kò jẹ fi ika wọn kan an lati ṣe iranwọ. Wọn le “jẹ ile awọn opó run,” itumọ eyi ti i ṣe pe wọn le fi orukọ ẹsin wọn gba owo pupọ lọwọ awọn opó to bẹẹ ti wọn o fi gba iba ohun diẹ ti wọn ni.

Ni aipẹ pupọ yii, iru eniyan bẹẹ kan lọ si ile obinrin kan ti ọkọ rè̩ ṣè̩ṣẹ kú. Obinrin naa rò pe o wá lati tu oun ninu ni ati lati ba oun tọju awọn ọmọ rẹ kekeke ti wọn di alai ni baba; ṣugbọn nnkan ti o n wá kò ju lati beere owo fun ṣọọṣi. Obinrin naa ko ni ohun miiran lati fi silẹ bi kò ṣe maluu kan ṣoṣo ti o tipasẹ rè̩ n jẹun. Nigba ti o wa lẹẹkeji ti o si takú lati gba owo dandan, obinrin naa sọ pe o le maa mu maluu naa lọ -- oun kò rò pe ọkàn ọkunrin naa lè le to bẹẹ ti yoo fi gba ohun kan ṣoṣo ti oun ni. O mu maluu naa lọ, ẹbi naa si ni lati pinya, a si mu awọn ọmọde naa lọ si ile ọtọọtọ fun abojuto.

Bayii ni awọn Farisi ti jé̩ ọlọkan lile to – wọn kò ni aanu. Jesu wi pe lootọ ni wọn n san idamẹwa gẹgẹ bi Ofin, ṣugbọn wọn ti fi ọran ti o “tobiju ninu ofin silẹ laiṣe, idajọ, ānu ati igbagbọ.”

Ifẹ Ọlọrun si Ẹlẹṣẹ ti o n Fẹ Otitọ

Jesu pe awọn akọwe ati Farisi ni agabagebe, afọju ti n ṣe amọna afọju, iran paramọlẹ ati ejo. Oun kò jẹ sọrọ si awọn ẹlẹṣẹ ti n wá otitọ bayii. O maa n pe wọn: “Ẹ wá sọdọ mi gbogbo ẹnyin ti nṣíṣẹ, ti a si di ẹrù wuwo le lori, emi o si fi isimi fun nyin” (Matteu 11:28). “Ẹniti ongbẹ ngbẹ ki o wá. Ẹnikẹni ti o ba si fẹ, ki o gbà omi ìye na lọfẹ” (Ifihan 22:17). O na apá Rè̩ jade, O si gbá olukuluku ẹni ti n fẹ ri igbala mọra.

S̩ugbọn fun awọn agabagebe eniyan ti wọn n duro ni ikorita òpópó ọna ti wọn si n gba adura gigun, O wi pe: “Egbé ni fun nyin, ẹnyin akọwe ati Farisi, agabagebe;... nitorina li ẹnyin o ṣe jẹbi pọju.” O pè wọn ni “ibojì funfun, ti o dara li ode, ṣugbọn ninu wọn kún fun egungun okú, ati fun ẹgbin gbogbo.” Ronu bi Jesu ti n wo inu ọkàn wọn ¬¬rekọja aṣọ gigun ti wọn fi n jọsin, filakteri wọn, ifarahan wọn bi olufọkansin, oju wọn ti o dabi ti ẹlẹsin – ti O si ri awọn è̩ṣẹ ti o buru jai eyi ti o rán Jesu leti “egungun okú ati ẹgbin gbogbo.”

Jesu tun wi pe wọn dabi awo ti a fọ mọ ni ode, ṣugbọn ti inu rè̩ dọti. O ṣe pataki ju, pe ki a fọ awo mọ ninu nibi ti a o fi ounjẹ si, ki o má ba si ẹni ti yoo di alaisan nipa jijẹ kokoro idọti mọ ounjẹ naa. Eniyan le wọṣọ ti o bo itiju, ki o dabi Onigbagbọ, ki o si maa ṣiṣẹ isin tọkantọkan ninu ile-isin; ṣugbọn bi o ba n sọ ọrọ è̩gàn nipa ẹni keji rè̩, ti o si n gbiro buburu nipa ọrẹ rè̩, ọkàn rè̩ ko mọ. “Nitoripe bi o ti nṣiro li ọkàn rè̩, bḝ li o ri” (Owe 23:7). Awọn oninu mimọ ati alayà funfun ni yoo ri Ọlọrun.

Baba Wa ni Ọrun

Awọn Farisi jẹ awọn eniyan ti wọn maa n lọ si ile ẹsin deede ti wọn si n ka Bibeli, ti wọn si n fi ara hàn gẹgẹ bi eniyan mimọ to bẹẹ ti awọn eniyan fi n pè wọn ni Rabbi, Olukọni, tabi Baba. Wọn gbe ara wọn ga wọn si n huwa bi ẹni pe wọn sàn ju gbogbo ẹlomiran lọ. S̩ugbọn Jesu wi pe: “Ará si ni gbogbo nyin. Ẹ má si ṣe pè ẹnikan ni baba nyin li aiye: nitori ẹnikan ni Baba nyin, ẹniti mbẹ li ọrun.” Eyi kò wi pe awọn ọmọ kò le pe ẹni ti o bí wọn ni baba, ṣugbọn pe wọn kò gbọdọ bu ọla fun alufaa gẹgẹ bi Ọlọrun, ki wọn si pè é ni baba. Kò si alufaa ti o le duro laaarin awa ati Ọlọrun, lati bẹbẹ fun wa tabi lati dari è̩ṣẹ wa ji wa. Jesu ni Olori Alufaa wa, O si kọ awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ lati gbadura si Ọlọrun Baba ati lati beere pe ki O fun wọn ni ibeere ọkàn wọn, ni orukọ Rè̩. O ṣeleri pe bi wọn ba gbadura bẹẹ, wọn o ri ohun ti wọn beere gbà.

Irẹlẹ

Jesu kò gbe ara Rè̩ ga ri. O wi pe Oun wá si aarin wọn gẹgẹ bi iranṣẹ, lati ṣe wọn loore. O sọ fun wọn pe bi wọn ba n fẹ gba èrè ni Ọrun wọn ni lati ṣe gẹgẹ bi Oun ti ṣe. Bi wọn ba rẹ ara wọn silẹ, Oun yoo gbé wọn ga Oun yoo si yé̩ wọn sí niwaju Baba Rè̩ ni Ọrun. S̩ugbọn awọn ti wọn gbe ara wọn ga, ti wọn n gbiyanju lati mu ki awọn ẹlomiran rò pe awọn jẹ eniyan pataki ati eniyan mimọ, Jesu yoo dá wọn lẹbi; oju yoo si tì wọn gidigidi nigba ti wọn ba duro niwaju Ọlọrun ninu idajọ.

Ofin Atọwọdọwọ Asán

Pupọ ninu ofin atọwọdọwọ awọn Farisi kò mu ọgbọn dani. Wọn sọ pe kò ṣe nnkan kan bi eniyan ba fi Tẹmpili bura, ṣugbọn o jẹ ohun ti kò dara lati fi wura ti o wà ninu Tẹmpili bura. Jesu beere lọwọ wọn èredi rè̩ ti wọn fi ṣe iyatọ yii. Tẹmpili kò ha ṣe pataki ju ohunkohun ti o wà ninu rè̩? Ile Ọlọrun kọ ha ni, tabi kò ha yẹ ki a fi ọlá ti o tọ si i fun un? Bi wọn ba si fi Tẹmpili, Ile Ọlọrun bura, ki ha i ṣe nipa Ọlọrun tikara Rẹ ni wọn fi bura, ti wọn si tipa bẹẹ ṣai bu ọlá fun Un? Jesu wi pe wọn ko gbọdọ fi ohunkohun bura. Bi o ba jẹ otitọ ni wọn sọ, kò ṣanfaani pe ki wọn tun sọ ohun kan ju bẹẹ ni tabi bẹẹ kọ. Bi wọn ba sọrọ ju bẹẹ lọ yoo dabi ẹni pe ohun ti wọn sọ kò fi bẹẹ daju. Ijọba wa ti fi anfaani silẹ pe kò ṣe dandan fun Onigbagbọ lati maa “bura” ni ile-ẹjọ, ṣugbọn o le “fi idi ọrọ rè̩ mulẹ” pe otitọ ni oun sọ.

Jesu wi pe n ṣe ni awọn Farisi tilẹ ti ilẹkun Ọrun ki awọn ẹlomiran má ba le ri igbala. Bawo ni wọn ṣe le ṣe bẹẹ? Ni ọna kin-in-ni, wọn kò gbagbọ pe ẹnikẹni ni o le ri igbala, eyi si ni wọn n waasu. Lai ṣe aniani eyi yii yoo mu irẹwẹsi bá ọpọlọpọ ti wọn kò fi ni tilẹ gbiyanju lati wá igbala. Irẹwẹsi si le ba awọn ẹlomiran nipa wiwo awọn agabagebe naa, ki wọn si wi pe bi awọn ti n tẹle Ọlọrun ba jẹ ikà ati alailaanu bayii, kò ṣe anfaani fun awọn lati jé̩ eniyan Ọlọrun. Nitori bẹẹ nipa è̩ṣẹ wọn, awọn Farisi ti ilẹkun Ọrun mọ ara wọn, wọn si n dena awọn ẹlomiran lati ri igbala.

A Kọ Jesu

Awọn Farisi wi pe i ba ṣe pe awọn wa ni ọjọ awọn wolii awọn kì bá ti pín ninu ẹbi awọn baba wọn ti wọn pa awọn Wolii bi Isaiah, Jeremiah, Sekariah ati Hosea. S̩ugbọn Jesu ti O ju awọn wolii lọ wà laaarin wọn nigba yii, wọn si n gbimọ ati pa A. Awọn olusin wọnyii, ti wọn pe ara wọn ni ọmọ Abrahamu, ti a si ti fun ni Ofin Ọlọrun, korira Jesu pẹlu ikorira buburu to bẹẹ ti wọn fi n mura ati kàn An mọ agbelebu. Nipa ṣiṣe eyi wọn yoo mu ki ago iwa buburu wọn kún, idajọ yoo si tẹle e lai pẹ.

O dun Jesu pe awọn eniyan naa kò jẹ ronupiwada. Oun kò fẹ ki iya jẹ wọn, bi o tilẹ jẹ pe wọn ti huwa iwọsi si I. Nigba ti o kù diẹ ki wọn da A lẹbi ikú, O sọkun lori Jerusalẹmu: “Jerusalẹmu, Jerusalẹmu, iwọ ti o pa awọn wolĩ, ti o si sọ okuta lù awọn ti a rán si ọ pa, igba melo li emi nfẹ radọ bò awọn ọmọ rẹ, bi agbebọ ti iradọ bò awọn ọmọ rè̩ labẹ apá rè̩, ṣugbọn ẹnyin kò fẹ! Sawò o, a fi ile nyin silẹ fun nyin li ahoro.”

Anfaani wọn ikẹyin lati gba A ni yii. Wọn kò tun ni ri I mọ titi akoko naa ti wọn o fi wi pe, “Olubukún li ẹniti o mbọ wá li orukọ Oluwa.” A o ri ninu awọn Ju ti o jẹ irandiran ọmọ awọn akọwe ati Farisi buburu wọnyii ti yoo yi pada sọdọ Jesu sibẹ ti wọn o si kigbe pe E, ani Messiah wọn, fun aanu. Wọn o jẹwọ è̩ṣẹ wọn, wọn o si bẹbẹ fun idariji. Nigba naa wọn o wa jẹ igbadun ibukun Ọlọrun gẹgẹ bi awọn ọmọ tootọ ti o ni ifẹ si gbogbo eniyan.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Kọ Ofin Wura (Matteu 7:12)
  2. Ta ni a pè ni olufunni ni ofin? awọn wo ni o si wà ni ipò yii ninu ẹkọ yii?
  3. Nibo ni Ọlọrun wi pe ki awọn Ọmọ Israẹli fi Ofin Rè̩ si?
  4. Nibo ni awọn akọwe ati awọn Farisi fi Ofin naa si?
  5. Awọn Farisi n san idamẹwa, ṣugbọn ki ni wọn gbagbe lati ṣe?
  6. Ki ni Jesu pe awọn akọwe ati awọn Farisi?
  7. Ki ni Jesu n sọ fun awọn è̩lẹṣẹ ti wọn n wá otitọ?
  8. Ọna wo ni awọn Farisi fi “sé ijọba ọrun” mọ awọn ẹlomiran?