Johannu 12:37-50

Lesson 223 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Tali o gbà iwasu wa gbọ? ati tali a si fi apá Oluwa hàn fun?” (Johannu 12:38).
Notes

Iran Isaiah

Wolii Isaiah, ẹni ti o ti wà ni aye fun nnkan bi ẹẹdẹgbẹrin (700) ọdun ṣiwaju ibi Jesu fẹran Ọlọrun o si fi ọkàn otitọ sin In. Ni ọjọ kan bi o ti n jọsin ninu Tẹmpili, ohun kan ṣẹlẹ si i ti o jẹ iyanu fun un ju ohunkohun ti o ti mọ lọ. O ri iran Oluwa ti o jokoo lori itẹ Rẹ! O si tun ri awọn angẹli ti o duro ni oke itẹ naa ti wọn n kọrin pe, “Mimọ, mimọ, mimọ, li OLUWA awọn ọmọ-ogun, gbogbo aiye kún fun ogo rè̩” (Isaiah 6:3). (Eleyi n sọ fun wa ni ti iyin si Ọlọrun Baba, Ọlọrun Ọmọ, Ọlọrun Ẹmi Mimọ). Awọn òpo ile mi titi nipa iró awọn akọrin ti Ọrun yii, eefin si kún Tẹmpili Oluwa.

Wo o bi ọkàn Isaiah ti gbina to ninu rè̩ lati sọ ohun ti o ri fun ẹlomiran! O woye pe oun ko yẹ lati duro niwaju Ọlọrun mimọ yii, ṣugbọn ọkàn rè̩ n fẹ gidigidi lati mu awọn Ọmọ Israẹli lọkàn le lati sin Ọlọrun otitọ kan ṣoṣo naa ti o wà ki wọn si gbadun idapọ pẹlu Rẹ. Ni ọjọ naa o ri i pe ohun kan kù sibẹ ti oun ni lati ṣe.

Isọdimimọ Isaiah

Laaarin ogo naa, ti o tàn jade lati ori itẹ Ọlọrun, a sọ Isaiah di mimọ; a si ran an lati lọ waasu fun awọn Ọmọ Israẹli. Ọlọrun kilọ fun un tẹlẹ pe iṣẹ naa yoo ṣoro, nitori awọn eniyan naa ki yoo fé̩ lati fi eti si ọrọ rè̩; wọn ki yoo gba ohun ti o sọ fun wọn nipa iwa mimọ Ọlọrun gbọ ati èrè ti o wà fun awọn oloootọ. Iru awọn eniyan wọnyii jé̩ aditi ati afọju nipa ti ẹmi.

Kò Si Iriran tabi Eti-Igbọ

Nigba ti Jesu wà ni aye, ti O n ṣe iṣẹ-iyanu ti iwosan, jiji okú dide, fifi alaafia fun awọn ọkàn ti o daamu, O ri iru awọn eniyan ti Isaiah waasu fun yii. Wọn ni oju lati rí ṣugbọn wọn kò fẹ lati ri ohun ti o yẹ lati ri; wọn ni eti lati fi gbọ, ṣugbọn wọn kò fẹ lati moye ohun ti o ṣe pataki ju lọ ni aye.

Ni akoko iṣẹ-iranṣẹ Isaiah o ti kigbe bayii, pe, “Tali o ti gbà ihìn wa gbọ? tali a si ti fi apá OLUWA hàn fun?” (Isaiah 53:1). O tè̩ siwaju lati ṣe apejuwe Jesu ati awọn iya ti yoo jẹ lati ra araye pada. Ọlọrun fi ohun ti yoo ṣẹlẹ gan an si Jesu ni ẹẹdẹgbẹrin (700) ọdun si akoko naa hàn fun Isaiah.

Awọn asọtẹlẹ wọnyii ni a n múṣẹ ninu akọsilẹ ẹkọ wa ti ọjọ oni. Jesu ti fi inurere hàn fun awọn eniyan: O ti ṣe awotan awọn onirobinujẹ ọkàn, O ti wo awọn alaisan sàn. O ti ṣe awọn ohun wọnni laaarin wọn ti ẹni kan kò i ti ṣe ri. Pẹlu gbogbo iṣẹ-iyanu Rè̩, sibẹ Jesu jẹ Ẹni ti “a kẹgàn rè̩ a si kọ ọ lọdọ awọn enia, ẹni-ikānu, ti o si mọ ibanujẹ” (Isaiah 53:3), gẹgẹ bi Isaiah ti wi pe yoo ri. Ọpọlọpọ awọn eniyan ti kò i ti gba ọrọ Jesu gbọ jẹ afọju ati aditi nipa ti ẹmi.

Apá Ọlọrun

Ta ni a ti fi apá Ọlọrun hàn fún? Ta ni o ti ri agbára Jesu, ti o si ti gbadun ibukun Rè̩? Awọn ti wọn gba ihin naa gbọ, gba ohun ti Jesu waasu gbọ.

O ranti itan obinrin ti o ṣaisan fun ọdun mejila ti o si ti ná gbogbo owó rè̩ fun awọn oniṣegun, sibẹ ti kò si sàn. O gbagbọ pe Jesu yoo wo oun sàn bi oun ba sa le fi ọwọ kan iṣẹti aṣọ Rè̩. Nitori o gbagbọ, o ri iwosan. Apá Oluwa ni eyi nì ti a fi hàn fun un.

A kà nipa balogun ọrún ẹni ti ọmọ rè̩ de oju ikú tán. O gbagbọ pe bi Jesu ba sa le sọ ọrọ jade, ọmọ oun yoo ri imularada. Igbagbọ yii ninu ọrọ Jesu ni o mú imularada yii wá, balogun ọrun yii si ri ifarahàn apá Oluwa.

Ọpọlọpọ iṣẹ iyanu bayii ni o wà, eyi ti Johannu kọ silẹ ninu Ihinrere rè̩ pe, “Bi a ba kọwe wọn li ọkkan, mo rò pe aiye pāpā kò le gba iwe na ti a ba kọ” (Johannu 21:25). Ọpọlọpọ nnkan wọnyii ti Jesu ṣe ti to lati mu ki gbogbo eniyan jẹ onigbagbọ. S̩ugbọn Johannu kọ akọsilẹ pe, “Nwọn kò gbà a gbọ.”

Nigba ti awọn eniyan kò ba gbagbọ, Jesu ki yoo ṣiṣẹ. Ni ilu ti Rè̩ ti i ṣe Nasarẹti awọn eniyan kò gbagbọ. “Oun kò si ṣe ọpọ iṣẹ agbara nibè̩, nitori aigbagbọ wọn” (Matteu 13:58).

Ta ni a fi apá Oluwa hàn fún lonii? Ki ha ṣe awọn ti o gba ọrọ ti Jesu sọ gbọ? Jesu wi pe, “Ẹ wá sọdọ mi gbogbo ẹnyin ti nṣíṣẹ, ti a si di ẹrù wuwo le lori, emi o si fi isimi fun nyin” (Matteu 11:28). Ẹnikẹni ti o ba fi ọkàn rè̩ gbagbọ ti o si ronupiwada è̩ṣẹ rè̩, ni o n ri isinmi yii. Eyi daju gbangba ni aye isisiyii gẹgẹ bi igba ti Jesu n rin lori ilẹ aye yii. Oun a maa fi ara Rè̩ han fun awọn ti o ba gbagbọ.

A Wo Alaisan Sàn

Jesu wo awọn alaisan sàn; a si ka ninu Iwe Jakọbu pe: “Inu ẹnikẹni ha bajẹ ninu nyin bi? jẹ ki o gbadura. . . . . Ẹnikẹni ṣe aisan ninu nyin bi? ki o pè awọn àgba ijọ, ki nwọn si gbadura sori rè̩, ki nwọn fi oróro kùn u li orukọ Oluwa: Adura igbagbọ yio si gbà alaisan na là, Oluwa yio si gbé e dide” (Jakọbu 5:13-15). Awọn ti o gbagbọ ni a n mú lara dá ni idahun si adura. Wọn ti gba ihin naa gbọ a si n fi apá Oluwa hàn fun wọn.

Nigba ti o kù diẹ ki Jesu fi aye yii silẹ, O rán awọn ọmọ-ẹyin Rẹ lati lọ waasu ni gbogbo aye, O si wi pe, “Àmi wọnyi ni yio si ma ba awọn ti o gbagbọ lọ; Li orukọ mi ni nwọn o ma lé awọn ẹmi èṣu jade; nwọn o si ma fi ède titun sọrọ;... nwọn o gbé ọwọ le awọn olokunrun, ara wọn ó da” (Marku 16:17, 18). Ami wọnyii yoo maa ba awọn ti o ba gbagbọ lọ.

Igbagbọ

Lai si igbagbọ kò ṣe e ṣe lati wu Ọlọrun (Heberu 11:6). Bawo ni Jesu ṣe le ṣiṣẹ iyanu fun wa bi a kò ba gbagbọ pe yoo ṣe e? S̩ugbọn bi a ba wu Oluwa nipa gbigba ohun ti O wi gbọ, Oun yoo ṣe awọn ohun iyanu fun wa. Bawo ni o ṣe le ni ireti pe Ọlọrun yoo fun ọ ni ohun ti o beere, bi o ba jẹ igbà ti o ba ṣe alai ni nikan ni o n ronu nipa Rè̩ ti o si n gbadura si I, ti o si gbagbe Rè̩ ni gbogbo igbà ti o kù? Inu Oluwa a maa dùn si adura ọpẹ ati ti ifẹ ti a ba gbà si I. O n fẹ ki a sọ fun Oun pe a fẹran Oun, ki a si gbe igbesi-aye wa lati fi hàn pe a fẹran Rè̩ ni tootọ. A ni lati ṣe isin Rè̩ ni ohun pataki ju lọ ninu aye wa.

A ni lati lo akoko wa ninu aye lati mura silẹ fun Ọrun ati lati ran awọn ẹlomiran lọwọ lati mura silẹ lati pade Jesu. Igbesi-aye wa ti i ṣe ọdun diẹ nihin yii kò ṣe i fi we ayeraye. A ti sọ pe: “Akoko wa nihin nikan ni anfaani ti a ni lati fi ri i pé Ọrun daju fun wa. O jẹ ohun ti o ṣe pataki ju lọ ti a ni ni aye yii. Njẹ bi eniyan ba si ni anfaani iyebiye yii, ti kò wà pẹ titi, yoo ha lọ lò o fun ohun ti kò ni laari bi?”

Bi a ba gba ohun ti Jesu sọ fun wa nipa Ọrun gbọ nitootọ, ati ogo ti a o gbadun nibẹ pẹlu Rè̩, awọn nnkan aye yii ki yoo jẹ ohun pataki ni oju wa rara. A o jẹ ọmọ-ibilẹ rere, a o si ṣe otitọ pẹlu inu rere si awọn ẹlomiran, ṣugbọn iwuwo ọkàn wa yoo jẹ lati jere ọkàn fun Jesu. A n ṣafẹri pe ki Jesu wa sọ aye yii di ibi mimọ lati gbé.

Iyin Awọn Eniyan

Diẹ ninu awọn olori sinagọgu gba Jesu gbọ, ṣugbọn wọn n bẹru lati jẹwọ bẹẹ. A n bu ọlá fun wọn nitori ipo giga wọn ninu ile-isin, wọn si fẹ iyin awọn eniyan. Wọn rò pe bi wọn ba tẹle Jesu a o korira wọn bi a ti korira Rè̩. A le ri i pe wọn kò rò nipa bi o ti ṣe pataki to lati mura silẹ lati lọ si Ọrun. Ohun ti awọn ọrẹ wọn n rò nipa wọn ṣe pataki fun wọn ju ohun ti Ọlọrun rò nipa wọn lọ. Dipo ti wọn i ba fi jiya inunibini diẹ nihin fun ọjọ diẹ, ki wọn si jẹ igbadun ogo Ọlọrun titi ayeraye, wọn n fẹ lati fi ẹmi wọn wewu nitori ọlá igbà diẹ ni aye isisiyii.

Awọn miiran tun wà ti wọn gba Ọlọrun gbọ, ṣugbọn ti wọn kò gbà pe Ọmọ Rè̩ ni Jesu i ṣe. Jesu gbiyanju lati fi hàn fun wọn pe gbogbo ọrọ ti Oun n sọ wá lati ọdọ Baba. Kò gbe ẹkọ kan ti i ṣe ti ara Rè̩ kalẹ. O n fẹ ki wọn mọ pe bi wọn ba gba ẹkọ Oun gbọ, Ofin Ọlọrun ni wọn gbagbọ -- ¬¬ọkan naa ni wọn, wọn o si duro laelae. Ọrọ ti Jesu sọ -- ọrọ Ọlọrun – yoo ṣe idajọ olukuluku eniyan ni ọjọ ikẹyin.

Fun awọn ti o gbagbọ, ọrọ Jesu di iyè ainipẹkun. A le gbẹkẹle Ọlọrun fun imuṣẹ awọn ileri Rè̩ ni igbesi-aye wa bi a ba ṣe ipa ti wa. Oun yoo ṣe itọju awọn ọmọ Rè̩, yoo si mu wọn de Ile-Ogo ni alaafia bi wọn ba gbọran si awọn ẹkọ Rè̩.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni Isaiah rí ninu Tẹmpili?
  2. Ki ni eyi mu ki ó fẹ lati ṣe?
  3. Bawo ni Ọlọrun ṣe pese Isaiah silẹ fun iṣé̩?
  4. Iru awọn eniyan wo ni Isaiah ati Jesu waasu fun?
  5. Awọn wo ni wọn n jẹ igbadun ibukun iṣẹ-iyanu Kristi?
  6. Ki ni ohun ti a o ri gbà bi a ba gbọran si ọrọ Jesu?
  7. Ki ni iyatọ ti o wà ninu gigun igbesi-aye wa nihin ati ayeraye?
  8. Bawo ni a ṣe le ni idaniloju wiwà ni imura-silẹ lati pade Jesu?