Lesson 224 - Junior
Memory Verse
AKỌSORI: “ Nitorina, ẹ ma ṣọna, bi ẹnyin ko ti mọ ọjọ, tabi wakati ti Ọmọ-enia yio de” (Matteu 25:13).Notes
Ipadabọ Jesu
Jesu sọ nipa akoko ti Oun yoo tun pada bọ sinu aye. O ṣeleri wi pe, “Bi mo ba si lọ ipèse àye silẹ fun nyin, emi o tún pada wá” (Johannu 14:3). O n sọ nipa ohun ti yoo maa ṣẹlẹ ninu ayé nigba ti O ba pada. Jesu wi pe yoo dabi ọjọ Noa, nigba ti ikun omi de. Bi o tilẹ jẹ pe a ti kilọ fun awọn eniyan, wọn kò mura silẹ. Jesu kilọ fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ lati maa ṣọra ati lati maa gbadura ki wọn ba le wà ni imurasilẹ de bibọ Rè̩. Jesu yoo tun pada wa.
Ẹkọ wa bẹrẹ pẹlu ọrọ yii, “Nigbana”, eyi ti o n sọ nipa akoko ti O ti n sọ nipa rè̩ -- pipada bọ Rè̩ wa si aye yii. Nigba ti O ba pada wa, yoo ri gẹgẹ bi o ti ri ninu owe ti a o kọ nipa rè̩ yii: awọn kan yoo wà ni imurasilẹ awọn miiran kò si ni wà ni imurasilẹ.
Akoko ti A Kò Mọ Daju
Ninu owe naa, ẹni ti ọkọ iyawo duro fun ni Jesu. Awọn eniyan n wọna fun ifarahan Rè̩, ṣugbọn akoko naa gan an ni wọn kò mọ. “Ẹnyin kò mọ wakati ti Oluwa nyin yio de” (Matteu 24:42). Kò si ẹni ti o mọ ọjọ naa, ki a má ṣẹṣẹ sọ ti wakati naa. Jesu wi pe “S̩ugbọn niti ọjọ ati wakati na, kò si ẹnikan ti o mọ ọ, awọn angẹli ọrun kò tilẹ mọ ọ, bikoṣe Baba mi nikanṣoṣo” (Matteu 24:36). Aidaniloju akoko ti Jesu yoo fi de yẹ ki o mu ki a maa ṣọna si i ki a ba le wà ni imurasilẹ ni gbogbo igbà.
A pin awọn ti wọn n reti ọkọ iyawo si ẹgbẹ meji, awọn ọlọgbọn ti wọn mura silẹ ati awọn alaigbọn ti wọn kò mura silẹ. Awọn ẹgbẹ mejeeji ni wọn n reti ọkọ iyawo. Awọn ẹgbẹ mejeeji ni wọn ni fitila, awọn mejeeji ni wọn si sùn ki ọkọ iyawo to de.
Imọlẹ
A le fi awọn eniyan wọnyii wé gbogbo awọn ti n tẹle Kristi. Jesu wi pe, “Emi ni imọlẹ aiye; ẹniti o ba tọ mi lẹhin kì yio rìn ninu òkunkun, ṣugbọn yio ni imọlẹ ìye” (Johannu 8:12). Ihinrere Jesu maa n fun ni ni imọlẹ. A ni lati gbọran ki a si tẹle E lati ni iriri igbala. “Bi awa ba nrìn ninu imọlẹ, bi on ti mbẹ ninu imọlẹ, awa ni idapọ pẹlu ara wa, è̩jẹ Jesu Kristi Ọmọ rè̩ ni nwè̩ wa nù kuro ninu ẹṣẹ gbogbo” (1 Johannu 1:7).
Nipa Bibeli ni Onisaamu n sọ nigba ti o wi pe, “Ọrọ rẹ ni fitila fun ẹsẹ mi, ati imọlẹ si ipa ọna mi” (Orin Dafidi 119:105). Iṣẹ fitila ni lati fun ni ni imọlẹ. Nigba ti a ba ni Jesu ninu igbesi-aye wa, a maa n ni ohun ti n fun wa ni imọlẹ nipa ti ẹmi.
Oorun
Gbogbo awọn eniyan wọnyii ni wọn sùn nigbà ti wọn n reti. Ni oru ni ọkọ iyawo de, ni akoko ti o yẹ ki eniyan maa sùn. Eyi kò sọ nipa oorun ikú, tabi oorun nipa ti ẹmi tabi irẹwẹsi. Oorun ti ara ni. Bi Jesu ba pẹ ti O ba si fa bibọ Rè̩ sẹyin, awọn eniyan Rẹ gbọdọ maa huwa deede nigba gbogbo. Wọn ní ile wọn ati iṣẹ wọn; ṣugbọn ero ti o gbọdọ maa leke ninu ọkàn wọn ni lati maa wà ni imurasilẹ fun bibọ Jesu.
S̩iṣowo
Ninu owe miiran, eyi ti o sọ nipa mina, a fi yé ni pe Oluwa ti fun olukuluku ni iṣẹ ti rè̩ (Marku 13:34), O si n reti pe ki a “mā ṣowo” titi Oun o fi de (Luku 19:13). Lati ṣowo ni lati ṣiṣẹ, lati mura, lati ṣọna, ati lati tẹti silẹ fun bibọ Rè̩. A n gbe igbesi-aye wa lojoojumọ bi ẹni pe ọjọ kọọkan jẹ ọjọ dide Rè̩. A ki i gbero fun ọjọ ti o jinna pupọ siwaju. Nigba ti a ba n sọ nipa ọjọ iwaju a maa n wi pe, “Bi Jesu ba fa bibọ Rè̩ sẹyin.” Sọlomọni wi pe “Emi sùn, ṣugbọn ọkàn mi ji” (Orin Sọlomọni 5:2). Bẹẹ gẹgẹ ni Onigbagbọ maa n sun oorun ti ara ṣugbọn ọkàn rè̩ ṣí silẹ nigba gbogbo fun bibọ Jesu.
Alaigbọn ati Ọlọgbọn
Lara awọn eniyan ti wọn n reti ọkọ iyawo jé̩ ọlọgbọn, ninu wọn si jé̩ alaigbọn. Ki ni iyatọ ti o wà laaarin wọn? Gbogbo wọn ni o ní fitila; ṣugbọn jijẹ ọlọgbọn tabi alaigbọn wọn wà lori bi ororo ti wọn ní ti pọ to. Awọn ọlọgbọn mú ororo lọwọ pẹlu fitila wọn ṣugbọn awọn alaigbọn mu fitila pẹlu ororo diẹ lọwọ tabi boya wọn kò tilẹ mú ororo lọwọ rara.
Fitila
O le ti ri fitila ti wọn ti n lo ki a to ni ina mànamána. Ni isalẹ fitila naa ni aye wà fun ororo. Ni oke ni igo wà, pẹlu òwu ti a rẹ sinu oróro; nigba ti a ba si tan iná sí i, a maa jó pẹlu imọlẹ nla ti a ba ti fi gbogbo nnkan si eto. Lojoojumọ ni wọn n fọ igo yii, bi kò ba ṣe bẹẹ kò ni pé̩ dudu ki o si kún fún eefin, eyi ti yoo dí imọlẹ naa lọwọ. Lati igba de igba ni wọn maa n rọ ororo kún fitila naa ki o má ba jẹ pe akoko ti wọn ba n lo o lọwọ ni ororo yoo tán. Lati igba de igba ni wọn si maa n ré̩ oju owu naa bi wọn ti n lo o, ki ajokù rẹ má ba mu ki ina rè̩ pọn si apa kan ti yoo fi mu ki igo naa di dudu. Fitila n fẹ abojuto lojoojumọ.
Titanmọlẹ fun Jesu
Jesu sọ fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ pe awọn ni imọlẹ aye (Matteu 5:14) gẹgẹ bi Oun ti jẹ Imọlẹ. Gẹgẹ bi ọmọ-ẹyin Jesu lonii, a ti fi wa wé imọlẹ. A ni lati fi awọn ohun ti ẹmi si eto, gẹgẹ bi o ti yẹ ki a boju to awọn ohun ti yoo mu ki fitila ti ara jó geere.
Igbesi-aye wa gbọdọ jẹ mimọ lojoojumọ, ni wakati kọọkan, ti imọlẹ wa yoo ba jẹ eyi ti o mọ gaara ti yoo si duro pẹ. A ni lati ge gbogbo idiwọ tabi idena kuro ti ina wa yoo ba maa jó geere dipo ki o pọn si apa kan ki o si maa rú èéfín.
Ororo
Gbogbo nnkan wọnyii le wa letò, ṣugbọn lai si ororo imọlẹ ko le si. Bi o ti ri ni yii fun wa nipa ti ẹmi: a gbọdọ ni Ororo ti i ṣe Ẹmi Ọlọrun. Nigbà ti eniyan ba ri igbala oun a ni Ẹmi Ọlọrun de àye kan. Bi o ti n gbadura sii ti o si n ya aye rè̩ sọtọ, ti o si ri iriri isọdimimọ gbà, oluwarè̩ yoo kún fun Ẹmi Ọlọrun si i.
Sibẹ iriri ti ẹmi kan wà ti o jinlẹ ju eyi lọ lati ní, eyi ti o n mu ki a tubọ kún fun Ẹmi Ọlọrun siwaju sii – lati kún fun Ẹmi, lati fi Ẹmi Mimọ wọ ni. Lẹyin ti Jesu goke re Ọrun, a fi Ẹmi Mimọ wọ awọn ọmọ-ẹyin ni ibi ti wọn ti n gbadura (Iṣe Awọn Apọsteli 1:5). Wọn kún fun Ẹmi Mimọ (Iṣe Awọn Apọsteli 2:4). Iriri yii wà fun awa naa lonii. “Nitori fun nyin ni ileri na, ati fun awọn ọmọ nyin, ati fun gbogbo awọn ti o jìna rére, ani gbogbo awọn ti Oluwa Ọlọrun wa ó pè” (Iṣe Awọn Apọsteli 2:39). O maa n fun wa ni Ẹmi Ọlọrun sii, ati Ororo sii nipa eyi ti imọlẹ wa yoo maa tàn.
Igbe
Laaarin ọganjọ oru, a gbọ igbe kan: “Wo o, ọkọ iyawo mbọ; ẹ jade lọ ipade rè̩.” Awọn ọlọgbọn ni ororo ti o ṣé̩kù, fitila wọn si n jó. Awọn alaigbọn ti ṣe ainaani. Ororo wọn kò to, fitila wọn si ti kù.
Awọn alaigbọn mọ ohun ti o yẹ ki wọn ni. Wọn mọ ohun ti wọn ṣe alai ni, wọn si mọ ibi ti o yẹ ki wọn lọ ati ọna ti wọn ni lati gbà ki wọn ba le ni in. Iṣẹ ẹni kọọkan ni; ojuṣe ẹni kọọkan ni lati pese ara rè̩ silẹ. Ki eniyan to le ni Ẹmi Ọlọrun ni iwọn ti o tọ ati awọn ẹbun ti ẹmi miiran gbogbo ti a kò le ṣe alai ni, oluwarè̩ ni lati gbadura, ki o fi ayé rè̩ rubọ, ki o si gba Ọlọrun gbọ. Bi Jesu ba de ni ọgànjọ oru lonii, o ha ti ṣe tan?
Akoko ti Kọja
Nigbà ti awọn alaigbọn lọ ra ororo, ọkọ iyawo de. Kò si àye mọ lati tun ṣe imurasilẹ kankan. Awọn ti wọn ti ṣe tan wọle sibi igbeyawo, a si ti ilẹkun. Awọn ọlọgbọn wà ninu ile ninu alaafia, a si sé awọn alaigbọn mọ ode.
Bi Kristi ba sé ilẹkun kò si ẹni ti o le ṣí i (Ifihan 3:7). Lai pẹ awọn alaigbọn gbiyanju lati wọle. Wọn kankun wọn si pè -- ṣugbọn wọn ti pé̩ jù. Bawo ni ijatilẹ wọn ti pọ to! Boya wọn gbadura wọn si sọkun, ṣugbọn kò ṣe wọn ni anfaani. Wọn ti duro pẹ jù. “Ẹ wá OLUWA nigbati ẹ le ri i, ẹ pè e, nigbati o wà nitosi” (Isaiah 55:6).
S̩iṣọra
A gbà wá ni imọran lati maa ṣọna ati lati maa mura silẹ. Ki Ọlọrun jẹ ki owe yii ji wa giri lati yẹ ọkàn wa wò boya a ti ṣe tan, ti Ororo ba wa ninu kolobo fitila wa. Rii daju pe Ororo wà nibẹ, má si ṣe jẹ ki o yọ jò danu. “Nitorina o yẹ ti awa iba mā fi iyè gidigidi si ohun wọnni ti awa ti gbọ, ki a má bā gbá wa lọ kuro ninu wọn nigbakan” (Heberu 2:1).
Aṣọ
Lẹyin ti eniyan ba ti ri gbogbo iriri ti o jinlẹ wọnyii, o ni lati maa ṣiṣẹ ki o si maa gbadura. Bi a ba n ṣọna ti a ba si n ṣe gbogbo nnkan ti o yẹ, a kò ni bẹru bibọ Jesu, ṣugbọn a o fẹran ifarahan Rè̩. A ni lati maa dagba ki a si maa jọ Kristi sii, ki ẹwa ti ẹmi ati iwa rere tubọ pọ sii ninu aye wa. Nnkan wọnyii ni a n pè ni oore-ọfẹ Onigbagbọ. Episteli keji ti Peteru 1:5-7 sọ fun wa pe awọn nnkan wọnyii ni lati dagba sii ki wọn si pọ sii ninu igbesi-aye wa.
Nigba pupọ ni a maa n fi awọn oore-ọfẹ ti ẹmi wọnyii wé aṣọ ti eniyan n wọ. Fun apẹẹrẹ, a kà pé “aṣọ ọgbọ wíwẹ nì ni iṣe ododo awọn enia mimọ” (Ifihan 19:8) ati pe “agbara ati iyìn li aṣọ rè̩” (Owe 31:25).
Ninu Orin Dafidi 45:13, 14 a ka nipa ọmọbinrin ọba ti a wọ ni aṣọ ogo ati “aṣọ iṣẹ ọnà abẹrẹ.” Olukuluku Onigbagbọ jẹ ọmọ Ọba awọn ọba, aṣọ ọgbọ wiwẹ ni a si fi wọ ọ nipa ti ẹmi. Bi olukuluku ti n pọ sii ninu igbagbọ, suuru, iṣoore, ifẹ, bẹẹ ni iṣẹ ọnà n pọ sii lara aṣọ ẹmi rè̩. Bi o ti n jọ Kristi sii bẹẹ ni yoo ni aṣọ ẹmi ti o funfun sii ti o si logo sii.
Nigba ti Jesu ba de, aṣọ Rè̩ yoo maa run “turari, ati aloe, ati kassia, lati inu āfin ehin-erin jade” (Orin Dafidi 45:8). Awọn wọnyii jé̩ apẹẹrẹ ẹbun oore-ọfẹ ti ẹmi ti awa naa gbọdọ ni, ki a ba le dabi Kristi. Jesu yoo wá ninu ogo ati ọlánla “nitori otitọ ati iwa-tutu ati ododo” ti Oun fé̩ (Orin Dafidi 45:4, 7).
A ni lati ni Ororo ninu kolobo pẹlu fitila wa bi a ba n reti ati bá Jesu wọle lọ fun Ase-Alẹ Igbeyawo. Ẹmi Ọlọrun ni lati pọ ninu aye wa ki a si fi awọn aṣọ oore-ọfe ti ẹmi wọ wá. “Ibukún ni fun ẹniti nṣọna, ti o si npa aṣọ rè̩ mọ” (Ifihan 16:15).
Nipa gbigbadura ati gbigbọran, ẹ jẹ ki a mura silẹ de ipadabọ Jesu lai pẹ. Nipa ṣiṣe iṣẹ ati ṣiṣọna, ẹ jẹ ki a bá wa ni imurasilẹ lati pade Jesu nigbà ti O ba de.
Questions
AWỌN IBEERE- Bawo ni a ṣe mọ pe Jesu yoo tun pada wa?
- Nigba wo ni Jesu yoo tun pada wa?
- Ki ni eniyan ni lati ṣe ki o ba le mura silẹ fun bibọ Jesu?
- Ki ni ṣe ti ninu awọn wundia naa fi jé̩ alaigbọn?
- Ki ni mu ki awọn iyoku jé̩ ọlọgbọn?
- Ki ni ṣẹlẹ nigba ti ọkọ iyawo de?
- Ki ni ṣe ti awọn alaigbọn fi lọ rà?
- Bi a kò ba wà ni imurasilẹ, ki ni yoo ṣẹlẹ nigbà ti Jesu ba de?