Lesson 225 - Junior
Memory Verse
AKỌSORI: “O ṣeun, iwọ ọmọ-ọdọ rere ati olõtọ: iwọ ṣe olõtọ, ninu ohun diẹ, emi o mu ọ ṣe olori ohun pipọ” (Matteu 25:21).Notes
A Pin Talẹnti
Ọkan ninu awọn owe ti Jesu pa fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ n sọ nipa ọkunrin ọlọrọ kan ti o mura lati lọ si irin-ajo si ilu miiran, ti o si fi ile ati iṣẹ rè̩ le awọn iranṣẹ rè̩ lọwọ. O rò pe awọn ti oun le gbẹkẹle ni oun pè lati jẹ alagbaṣe, nitori naa o pè wọn jọ nigba ti akoko lilọ rè̩ fẹrẹ to, o fun olukuluku wọn ni owo ti o pọ ti wọn o fi maa ṣowo nigba ti o ba lọ.
O fun ọmọ-ọdọ kin-in-ni ni talẹnti marun un, o si ni ki o lo owo naa lọna ti yoo fi jere. Ẹyọ talẹnti meji ni o fun ọmọ-ọdọ keji. Ọmọ-ọdọ yii ko ni agbara ti o pọ to ti akọkọ, kò si ni agbara to lati lo talẹnti ti o ju meji lọ bi o ti yẹ. Ẹni kẹta ni o fun ni talẹnti kan gẹgẹ bi agbara rè̩ ti tó.
Iṣiro
Lẹyin ọjọ pipẹ (o ni lati jẹ ọpọ ọdun), oluwa awọn ọmọ-ọdọ wọnni dé. O pe awọn ọmọ-ọdọ rè̩ lati wá fi ohun ti wọn jere lori iṣẹ ti wọn ṣe nigba ti o re ajo hàn fun un.
Ọmọ-ọdọ kin-in-ni mu talẹnti mẹwaa wá -- ilọpo iye ti a fun un. Inu oluwa rè̩ dùn pupọ. Iru ọmọ-ọdọ ti ọkàn rè̩ n fẹ ni yii. Bayii ni o wi fun oloootọ naa: “Iwọ ṣe olõtọ, ninu ohun diẹ, emi o mu ọ ṣe olori ohun pipọ: iwọ bọ sinu ayọ oluwa rẹ.” O tilẹ fi fun ọmọ-ọdọ yii ju iye ti o mu wá lọ.
Wo o bi ayọ ọmọ-ọdọ yii yoo ti pọ to! O ni itẹlọrun nipa mimọ pe oun ti ṣe iṣẹ oun daradara -- yatọ si eyi, tun wo ere nla ti o ri gbà! O ti fi ara rè̩ hàn gẹgẹ bi oṣiṣẹ rere, nisisiyii a si fun un ni anfaani lati maa ṣakoso pẹlu oluwa rè̩.
Nigba ti awọn ọmọ-ọdọ iyoku ri ere yii boya o wù wọn pe awọn i ba ti ni talẹnti marun un lati fi ṣiṣẹ bẹẹ gẹgẹ; ṣugbọn ẹ jẹ ki a wo ohun ti oluwa wọn sọ fun ọmọ-ọdọ ti a fun ni talẹnti meji pere. Labẹ abojuto rere ọmọ-ọdọ keji yii, talẹnti meji nì ti jere talẹnti meji miiran. Ohun kan naa ti oluwa wọn sọ fun ọmọ-ọdọ akọkọ ni o sọ fun oun naa: “Iwọ ṣe olõtọ, ninu ohun diẹ, emi o mu ọ ṣe olori ohun pipọ: iwọ bọ sinu ayọ oluwa rẹ.” O mọ pe ọmọ-ọdọ yii kò ni ẹbùn nipa ti ara to ti akọkọ, ṣugbọn a san ere ijolootọ rè̩ fun un. Ọmọ-ọdọ keji yii naa yoo jé̩ alakoso bakan naa. O le jẹ pe yoo ṣe alakoso lori ilu marun un nigba ti ọmọ-ọdọ kin-in-ni yoo ṣe alakoso lori ilu mẹwaa (Luku 19:17-19), ṣugbọn iwọn ti o le ṣakoso ni eyi, inu rè̩ si dun si ere ti a fun un.
A Da a Lẹbi
Ẹni ti o gba talẹnti ẹyọ kan n kọ? Oluwa rè̩ kò reti pe yoo jere talẹnti mẹwaa, ṣugbọn o nireti ilọpo meji ohun ti o fi fun un. S̩ugbọn ọmọ-ọdọ yii jé̩ onilọra kò si ṣiṣẹ fun ọga rè̩. Inu ilè̩ ni o ri talẹnti naa mọ, nibi ti ẹnikẹni kò ni le ri i ni gbogbo ọdun ti i ba fi wulo.
A kò le nireti pe inu oluwa ọmọ-ọdọ naa yoo dùn si i. Ọmọ-ọdọ naa mọ pe oun ti ṣe ohun ti kò dara; ṣugbọn ẹsẹkẹsẹ ni o bẹrẹ si i ba oluwa rè̩ wijọ bi ẹni pe ẹbi rè̩ ni ti o fi lọ ri talẹnti naa mọlẹ. Wò o bi awọn eniyan ti maa n di ẹrù ẹbi wọn le ori ẹlomiran! Bi oluwa ọmọ-ọdọ naa ba tilẹ jẹ “onroro enia”, bi ọmọ ọdọ na ti wi, eyi kò gbọdọ mu ọmọ-ọdọ yii kuna lati jé̩ oloootọ ninu iṣẹ rè̩.
Gbọ ohun ti oluwa ọmọ-ọdọ naa wi fun un: “Iwọ ọmọ-ọdọ buburu ati onilọra.” È̩ṣẹ ti o ṣè̩ ni è̩ṣẹ ainaani. Ki i ṣe iwa ibi ni o mu idalẹbi yii wá, ṣugbọn ainaani iṣẹ rere ti o yẹ ki o ṣe. Bẹẹ ni a gbe ọmọ-ọdọ naa sọ sinu okunkun lode, nibi ti “ẹkún on ipahinkeke yio gbé wà.”
Jesu tun sọ nigba kan pe awọn eniyan yoo tọ Oun wá lọjọ idajọ, wọn yoo si maa ké pe, “Oluwa, Oluwa, awa kò ha sọtẹlẹ li orukọ rẹ? ati orukọ rẹ ki a fi lé awọn ẹmi èṣu jade? ati li orukọ rẹ ki a fi ṣe ọpọ iṣẹ iyanu nla?” Oun o si dá wọn lohùn pe, “Emi kò mọ nyin ri, ẹ kuro lọdọ mi, ẹnyin oniṣẹ è̩ṣẹ” (Matteu 7:22, 23). Iru awọn eniyan bẹẹ yoo rò pe a o gbà wọn si Ọrun nitori wọn ti ṣe iṣẹ rere; ṣugbọn Jesu ni a gbọdọ kọkọ gba ọkàn wọn là ki iṣẹ wọn ba le yẹ fun ere ni Ọrun.
Bi awọn ti wọn ṣiṣẹ rere ni orukọ Jesu ba gba idalẹbi nitori wọn kò ni igbala, irú ipò wo ni eniyan bi ọmọ-ọdọ ti o gba talẹnti kan yoo wà ni ọjọ idajọ? Kò tilẹ ni iṣẹ ti o le sọ pe oun ṣe fun oluwa rè̩.
Fifi fun Jesu
A n sọ pe o ṣe e ṣe ki a fi nnkan fun ni lai ni ifẹ si ni, ṣugbọn kò ṣe e ṣe ki a ni ifẹ ki a má le fi fun ni. Itumọ eyi ni pe o le fi ẹbùn fun eniyan ti o kò bikita lọ titi nipa rè̩ nitori o woye pe o jé̩ ẹtọ rẹ lati ṣe bẹẹ. S̩ugbọn bi o ba fẹran ẹni kan ni tootọ, yoo wù ọ lati ọkàn wa lati fun un ni gbogbo eyi ti o wà ni ipá rẹ lati fun un. Bi a ba fẹran Jesu nitootọ pẹlu gbogbo ọkàn wa, eyi ti o dara ju lọ ninu ohun ti a ni ni a o fi fun Un.
Ki ni a le fun Jesu? Ekinni a gbọdọ fi ifẹ wa fun Un. Lẹyin naa a o maa sin In. Ọkan ninu iṣẹ isin naa ni adura. A gbọdọ kiyesara lati bẹrẹ ọjọ kọọkan pẹlu adura. A o gbadura fun igbala awọn ti o n ṣegbe ati iwosan awọn ti ara wọn ṣe alaida. A o gbadura fun ibukun sori awọn ipade wa. Ni opin ọjọ kọọkan a o gbadura ọpẹ si Ọlọrun fun ṣiṣe amọna wa ati fun aabo ni gbogbo ọjọ naa.
Iṣẹ-isin miiran ni ẹri. Oju kò ni ti wa lati jẹ ki awọn eniyan mọ pe Onigbagbọ ni wá. A n fẹ ki wọn mọ nipa ifẹ Jesu si wa, ati bi a ti layọ to lati jẹ ọmọ Rè̩. Boya awọn ọmọde ti o n ba ṣire le ṣe alai gbọ nipa Jesu ri. Iṣẹ-isin rẹ ni lati pe wọn wa si Ile-ẹkọ Ọjọ Isinmi, ki o si sọ fun wọn pe Jesu fẹran wọn O si n fẹ sọ wọn di ọmọ rere, ki wọn ba le ba A gbe ni Ọrun titi lae.
Iṣẹ ti Inu
Gbogbo awọn iṣẹ wọnyii jẹ ti ode-ara. A ni iṣẹ ti ọkàn bakan naa lati ṣe. Bi a ba n fẹ ki iṣẹ wa ti ode-ara ki o jẹ itẹwọgba fun Ọlọrun a ni lati fi kun awọn oore-ọfẹ ti a ni gẹgẹ bi Onigbagbọ: “Ẹ fi iwarere kún igbagbọ, ati imọ kún iwarere; ati airekọja kún imọ; ati sru kún airekọja; ati iwa-bi-Ọlọrun kún sru; ati ifẹ ọmọnikeji kún iwa-bi-Ọlọrun; ati ifẹni kun ifẹ ọmọnikeji. Nitori bi ẹnyin bá ni nkan wọnyi, ti nwọn bá si pọ, nwọn ki yio jẹ ki ẹ ṣe ọlẹ tabi alaileso ninu imọ Oluwa wa Jesu Kristi. Nitori ẹniti o ba ṣe alaini nkan wọnyi, o fọju, kò le riran li òkere, o si ti gbagbé pe a ti wè̩ on nù kuro ninu è̩ṣẹ rè̩ atijọ” (2 Peteru 1:5-9).
Talẹnti Wa
Talẹnti marun un ni a fun ọmọ-ọdọ kin-in-ni. Ẹ jẹ ki a fi eyi ni we igbesi-aye Onigbagbọ. A le fun ẹni kan ni talẹnti marun un ti o le fi sin Oluwa. Ẹni naa le jẹ alufaa ti o le waasu daradara. Talẹnti kan ni eyii. O le kọrin; ifarahan rè̩ wu ni o si mu inu ọpọ eniyan dùn: ẹni ti o mọ iṣẹ òwo ṣiṣe daradara ni; o si jẹ alagbara ọkunrin ti o le ran awọn eniyan lọwọ. Bi o ba lo awọn talẹnti wọnyii pẹlu ijolootọ fun Jesu, wọn o maa dagbà soke si i. S̩ugbọn o ni lati lo gbogbo wọn ni ọna ti yoo fi gbọ ohùn Oluwa pe, “O ṣeun, iwọ ọmọ-ọdọ rere ati olõtọ; iwọ ṣe olõtọ, ninu ohun diẹ, emi o mu ọ ṣe olori ohun pipọ.” O ni lati ṣiṣẹ kara fun ere rè̩.
Ẹlomiran le ni talẹnti meji. O le jẹ pe ẹni naa fẹran lati maa bẹ awọn ti n ṣaisan ati awọn ti o n fẹ iranlọwọ wò, ọrọ iṣiri rè̩ a si maa fun wọn layọ. O le kọrin daradara, o si n lo talẹnti rè̩ mejeeji papọ. Ọpọlọpọ awọn alaini ati awọn ti o wà ninu inira ni o wà, nitori naa iṣẹ pọ fun un lati ṣe; ṣugbọn o ni lati jẹ oloootọ ninu ohun ti o n ṣe bi o ba n fẹ lati gbọ:”O ṣeun, iwọ ọmọ-ọdọ rere ati olõtọ. . . . .emi o mu ọ ṣe olori ohun pipọ.”
A le rò pe ọwọ wa kún fun iṣẹ pupọ nihin fun Oluwa, ati pe nigba ti O ba de a o ṣiwọ iṣẹ ṣiṣe. S̩ugbọn ninu owe yii o dabi ẹni pe iṣẹ wa nihin n pese wa silẹ fun nnkan ti o tobi ju eyi lọ lọhun. Ẹ jẹ ki a ṣiṣẹ ni oju mejeeji ki Oluwa ba le lo wa ni ayeraye ni ilẹ ti O ti pese silẹ fun awọn ti o fẹ Ẹ!
Ojuṣe Wa
Ọlọrun ti fun gbogbo wa ni talẹnti ti O n fẹ ki a lò. A o si ṣe iṣiro ki i ṣe fun ohun ti a ni nikan ṣugbọn fun ohun ti o yẹ ki a ni. Bi a ba lo ohun ti Ọlọrun fi fun wa a o tun ri gbà si i, Ọlọrun yoo si beere iṣẹ ti o tobi ju eyi ni lọwọ wa. A kò le kawọ gbenu ki a si wi pe a ni itẹlọrun pẹlu ohun ti a ni, pe a kò bikita fun ere nla; a ko si le fi ọrọ gbe ara pe a kò yẹ lati ṣe ohun nla fun Oluwa. Bi Oun ba ti fun wa ni talẹnti ti a ko lo fun Oluwa, a o ba ara wa ni ipo ọmọ-ọdọ onilọra nigba ti O ba pè wa lati ṣe iṣiro.
Gbogbo awọn ọmọ-ọdọ wọnyii ni o n reti pe oluwa wọn yoo de. Wọn mọ pe yoo beere nipa talẹnti ti wọn gbà lọwọ rè̩. Sibẹ ọmọ-ọdọ onilọra naa dán an wò lati lọ ri talẹnti rè̩ mọlẹ, kò si lò ó.
Ọpọlọpọ eniyan ni o n wọna fun pipada bọ Oluwa, wọn si ro pe wọn ti mura silẹ. Wọn le ti ri igbala, ṣugbọn wọn kò fi iwa rere kún igbagbọ wọn, ati imọ kún iwa-rere ati awọn oore-ọfẹ Onigbagbọ iyoku, nitori naa imọlẹ ti wọn ni ti di okùnkùn. Apọsteli ni kọ akọsilẹ pe, “Bi awa ba nrìn ninu imọlẹ, bi on ti mbẹ ninu imọlẹ, awa ni idapọ pẹlu ara wa, è̩jẹ Jesu Kristi Ọmọ rè̩ ni nwè̩ wa nù kuro ninu è̩ṣẹ gbogbo” (1 Johannu 1:7). S̩ugbọn a ni lati rìn ninu imọlẹ; bi kò ba ri bẹẹ yoo di okunkun, a o si tun ri pe a ti pada sinu è̩ṣẹ.
Nitori naa a kọ ẹkọ pe ki a ba le gbọ ohùn ni pe, “O ṣeun, iwọ ọmọ-ọdọ rere ati olõtọ”, a ni lati jé̩ oloootọ ninu gbogbo nnkan ti Oluwa ba fi hàn wa lati ṣe; ki a si fi inu didun ṣe eyi ti a fifun wa lati ṣe.
Questions
AWỌN IBEERE- Talẹnti meloo ni a fun awọn ọmọ-ọdọ wọnni?
- Ki ni wọn ni lati fi talẹnti naa ṣe?
- Ki ni ere ọmọ-ọdọ kin-in-ni? ki ni ere ekeji?
- Ki ni ọmọ-ọdọ kẹta ṣe pẹlu talẹnti rè̩?
- Ki ni ere rè̩?
- Ki ni a le pe ni talẹnti ni igbesi-aye wa?
- Nibo ni a ti n rí talẹnti wa gbà?
- Bawo ni a ṣe le jere talẹnti si i?
- Ki ni iṣẹ wa nihin n pese wa silẹ fun?
- Bawo ni a o ti ṣe idajọ iṣẹ wa?