Lesson 226 - Junior
Memory Verse
AKỌSORI: “Angẹli OLUWA yi awọn ti o bè̩ru rè̩ ká, o si gbà wọn” (Orin Dafidi 34:7).Notes
È̩ri Kan
Nigba gbogbo ni Dafidi maa n ranti iriri ti o ti ni nigbà ti o jẹ atipo, ti o sá niwaju awọn ọta rè̩. Ni igba pupọ ati ni ọna pupọ ni Ọlọrun ti ran Dafidi lọwọ ti O si ti pa a mọ. Nipa awọn iriri wọnyii, igbagbọ ati ireti Dafidi ninu Ọlọrun ti jinlẹ de ibi ti igboya ati igbẹkẹle rè̩ ninu Ọlọrun ti fi idaniloju ati ifọkanbalẹ sinu ọkàn rè̩. Nigba ti Dafidi gbẹkẹ le Ọlọrun, o mọ pe oun wà lai lewu.
Nigba ti Ọlọrun ran Dafidi lọwọ ninu ewu nla kan ni o ni imisi lati kọ Orin yii. Nihin yii Abimeleki jẹ orukọ oye gẹgẹ bi Farao, ọba tabi aarẹ. Dajudaju ẹni ti Dafidi n sọ nipa rè̩ ni Akiṣi, ọba Gati, ẹni ti oun bẹru gidigidi (1 Samuẹli 21:12). Dafidi mọ pe Ọlọrun ni O ti ran oun lọwọ lati le sá là. Bi Dafidi ti n ro nnkan wọnyii, o ri pe oun jẹ Ọlọrun ni igbese ọpẹ pupọ. Orin yii ni è̩ri Dafidi.
Iyin Nigbà Gbogbo
Dafidi wi pe, “Emi o ma fi ibukún fun OLUWA nigbagbogbo.” Nihin yii o sọ ipinnu rè̩ di mimọ lati maa yin Ọlọrun logo ni ipokipo ti o wù ki oun wà. Awọn miiran le yin Ọlọrun logo nigbà ti gbogbo nnkan ba dabi ẹni pe o n lọ deede fun wọn. Awọn ẹlomiran ẹwẹ, a maa yin Ọlọrun lẹẹkọọkan. Dafidi mọ pe nigba gbogbo ni idi kan ni lati wà ti a fi ni lati yìn, ati lati dupẹ lọwọ Ọlọrun. Nigbà ti Dafidi ba tilẹ wà ninu è̩ru ati ewu, ọkàn rè̩ maa n gbẹkẹle Ọlọrun ṣa ni. Nigbà ti ibanujẹ, ati ipọnju de bá Dafidi, sibẹ o ni eredi lati gbẹkẹle ati lati yin Ọlọrun. Dafidi wi pe iyin Ọlọrun yoo maa wà ni ẹnu oun titi lae, nigba gbogbo ati ni àyè gbogbo. Ẹni ti o kọ Episteli si awọn ara Efesu paṣẹ fun awa naa lati “mā dupẹ nigbagbogbo fun ohun gbogbo lọwọ Ọlọrun” (Efesu 5:20).
Fifi Ogo fun Ọlọrun
Ọpọlọpọ iṣẹ akinkanju ni Dafidi ti ṣe ni igbesi-aye rè̩ -- gẹgẹ bi i fifi kànnàkànnà ati okuta pa Goliati, omiran, ẹni ti o jé̩ ọta awọn eniyan Ọlọrun, tabi gbigba kiniun mú ni irungbọn lati pa á nigbà ti o gbiyanju lati jí ọdọ-agutan Dafidi kan gbé lọ, tabi pipa amọtẹkun nì ti o gbé ọdọ-agutan kan lati inu agbo-ẹran Dafidi. Dafidi kò sọrọ ifọnnu nipa igboya rè̩ tabi nipa ohunkohun ti o ti ṣe. Dafidi fi ogo naa fun Ọlọrun nitori o mọ pe lai si iranwọ Ọlọrun oun ki ba ti le ṣe eyikeyi ninu awọn nnkan wọnyii. Paulu Apọsteli sọ ọrọ kan ti o jọ ti Dafidi pupọ. Paulu wi pe, “Ki a máṣe ri pe emi nṣogo, bikoṣe ninu agbelebu Jesu Kristi Oluwa wa” (Galatia 6:14). Njẹ a ti fọnnu ri? O ha jẹ nipa ara wa ni, tabi nipa ohun ti Ọlọrun ti ṣe?
Dafidi fẹ ki awọn ẹlomiran mọ ohun ti Ọlọrun ti ṣe fun oun. Dafidi ro pe gbigbọ iru nnkan bẹẹ, yoo mu ayọ kún ọkàn awọn eniyan. Fifi ogo fun Ọlọrun mu inu Dafidi dùn, bẹẹ naa ni awọn ẹlomiran pẹlu. Lẹyin ti Dafidi ti sọ ẹri rè̩ fun awọn ẹlomiran, o wa pe wọn lati bá oun yin Ọlọrun logo. Wọn ti gbọ nipa idasilẹ rè̩, o si rò pe o yẹ ki wọn ba oun ni ẹmi ọpẹ.
Adura ti a Dahun
Dafidi sọ eredi rè̩ ti oun fi n yin Ọlọrun – Oluwa ti gbọ adura Dafidi nigba ti o gbadura. Ki i ṣe pe Oluwa gbọ adura Dafidi nikan, ṣugbọn O dahun rè̩ pẹlu. Dafidi yin Oluwa nitori Ọlọrun tun mu ibẹru kuro ninu ọkàn Dafidi. Nigbà ti ifẹ Ọlọrun ba wọ inu ọkàn, ibẹru ti o maa n jẹ ni niya a fo lọ; alaafia ati ifọkanbalẹ a si dipo rè̩. Nigbà ti Johannu n kọ nipa ifẹ pipe Ọlọrun, o sọ nipa ọrọ yii kan naa: “Ibẹru kò si ninu ifẹ; ṣugbọn ifẹ ti o pé nlé ibẹru jade: nitoriti ibẹru ni iyà ninu” (1 Johannu 4:18).
Dajudaju gbogbo wa ni Ọlọrun ti dahun adura rè̩. Kò ha yẹ ki a yin Ọlọrun fun eyi? Fun adura ti O ti dahun a jẹ Ẹ ni igbese iyin ati ọpẹ wa. Lai ṣe aniani, a ti ri awọn ibukun miiran gbà pẹlu; ṣugbọn ki a tilẹ wi pe Ọlọrun kò ṣe ohun miiran fun wa, o yẹ ki a yin In logo fun adura ti O ti dahun.
Angẹli Oluṣọ
Eyi nikan kọ ni Ọlọrun ṣe fun Dafidi. Oluwa ti rán angẹli kan lati daabo bo Dafidi. Angẹli oluṣọ ni awọn ẹlomiran n pe angẹli yii, ti n daabo bo wọn kuro ninu jamba ti o si n yọ wọn kuro ninu ewu. Ọmọde pupọ ni wọn fẹran aworan kan ti a yà nipa awọn ọmọde meji ti n dá afara tooro kan kọja eyi ti o wà loke omi ti o n ru. Ni ẹgbẹ awọn ọmọde naa ni angẹli Oluwa kan wà lati mu wọn la afara naa kọja lai foya. Aworan yii n rán wa leti pe Ọlọrun maa n rán awọn angẹli Rè̩ lati wà nitosi awọn ti o bẹru Rè̩.
Ibẹru yii yatọ si eyi ti o ni iyà ninu, eyi ti Ọlọrun gbà kuro ninu ọkàn Dafidi. Ibẹru eyi ki i fi ipaya ati ibẹrubojo sinu ọkàn eniyan. O jẹ fifi ọwọ fun Ọlọrun eyi ti yoo mu ki a maa sin In ki a si maa ṣọra lati má ṣe ohunkohun ti kò ni té̩ Oluwa lọrun. Ibẹru ti o ti ọdọ Ọlọrun wá a maa mu ki a sin Oluwa. Bibeli sọ pe “Ibè̩ru OLUWA ni ipilẹṣẹ ìmọ” ati “ipilẹṣẹ ọgbọn” (Owe 1:7; Owe 9:10).
Ibẹru Oluwa
A ṣe ileri awọn ibukun miiran fun awọn ti o ni ibẹru Oluwa. Dafidi ni iwuwo ọkàn nipa awọn ẹlomiran. O fẹ ki gbogbo eniyan ṣe alabapin ibukún ti oun ni. Dafidi wi pe oun o kọ wa ni è̩rù Oluwa bi awa o ba tẹti si ọrọ rè̩. Boya Dafidi i ba kọ awọn ẹlomiran lati maa lu duru, nitori olorin ni oun jé̩. O si ṣe e ṣe ki o kọ ni bi a ti n lo idà nitori akinkanju ologun ni oun i ṣe. Dafidi kò sọ nipa iwọnyi, nitori o mọ pe ibẹru Oluwa ni o ṣe pataki ju lọ.
Dafidi wi pe, “Tọ ọ wò, ki o si ri pe, rere ni OLUWA.” O rọ wa pe ki a tọ Oluwa wò funra wa. A le ni awọn iriri kan naa gẹgẹ bi Dafidi ti ni, nitori Ọlọrun yoo ràn wá lọwọ gẹgẹ bi O ti ran Dafidi lọwọ.
Ko Si Aini Ohun ti o Dara
A rọ wa lati gbẹkẹle Ọlọrun ati lati wá oju Rè̩. Nigba naa a o ni ibukun Ọlọrun, a ko si ni ṣe alai ni ohun ti o dara. Dafidi kò sọ pe a o ni gbogbo nnkan ti a n fé̩. Ohun ti o sọ ni pe Ọlọrun yoo fun wa ni awọn nnkan ti o dara fun wa. A ko ni ṣe alai ni ohun ti o dara, ibukun ti ẹmi, nitori Ọlọrun ni in lai loṣuwọn. Kò yẹ ki a ṣe alai ni ohun ti o dara, nitori ileri Ọlọrun ni lati fi fun awọn ti n ṣafẹri Rè̩ ti wọn si n gbẹkẹle E. A le gbe igbesi-aye igbagbọ ki a má si ṣe alai ni nnkan kan.
Igbesi-ayé Rere ti o si Ni Ayọ
Njẹ ẹnikẹni ha wà ti kò ni fẹ igbesi-ayé rere, ẹmi gigun ti o kún fun ayọ? Gbogbo eniyan ni o n fẹ lati ni igbesi-aye ti o kun fun ayọ. Dafidi sọ fun wa bi oun ti ṣe ni in ati bi awa naa ti ṣe le ni igbesi-aye rere ni aye yii ati ni aye ti n bọ.
Itọni Dafidi ni pe ki a yẹra fun iwa buburu, yala ninu ọrọ tabi ninu iṣe wa. Ọlọrun ko fẹ iwa buburu. O korira rè̩. Oju Ọlọrun kan si awọn ti n ṣe buburu. “Ibi ni yio pa enia buburu.” È̩ṣẹ a maa mu iparun wa. Fun awọn ti n ṣe ibi, è̩ṣẹ yoo pa wọn run, yoo si mu ikú ayeraye wa sori wọn. Dafidi kò le sọ ohun rere kan nipa è̩ṣẹ ati iwa buburu. S̩ugbọn o kọ ẹsẹ orin pupọ nipa awọn ibukún ti n wá sori awọn olododo ati awọn ti n ṣe rere.
Rironupiwada
Awọn kan le wà ti o jẹ pe wọn n fẹ lati maa ṣe rere ṣugbọn o dabi ẹni pe ibi ni wọn sa maa n ṣe nigba gbogbo. Wọn a maa binu, wọn a si maa sọrọ ibajẹ, nigba naa ọkàn wọn a bajẹ pe inu bi wọn. Wọn a maa purọ, wọn a si maa bẹru pe aṣiiri wọn yoo tú. Wọn maa n bọ sinu wahala; wọn si ni lati jiya è̩ṣẹ wọn. Dafidi mọ pe Ọlọrun le ran irú ẹni ti o fẹ ṣe rere bẹẹ lọwọ. Kò si ẹni ti o le gbé igbesi-aye rere lai ni Ọlọrun.
Nigba ti eniyan ba ké pe Ọlọrun fun iranwọ, ti o ronupiwada ti o si banujẹ fun iwa buburu rè̩, Ọlọrun yoo gbọ yoo si dahun adura naa. Ọlọrun n bẹ leti ọdọ awọn ti i ṣe onirobinujẹ ọkàn, Oluwa yoo si gba awọn ti n kaanu fun è̩ṣẹ wọn là. Ọlọrun yoo ran ọkàn ti o ronupiwada lọwọ yoo si fun un ni agbara lati gbe igbesi-aye ododo. Nigbà gbogbo ni oju Ọlọrun maa n wà lara olododo lati ri aini wọn. Nigba gbogbo ni eti Ọlọrun maa n ṣí si igbe awọn eniyan Rè̩. “Kiyesi i, ọwọ OLUWA kò kuru lati gbàni, bḝni eti rè̩ kò wuwo ti ki yio fi gbọ” (Isaiah 59:1).
S̩iṣe Rere
Dafidi wi pe, “Lọ kuro ninu ibi, ki o si ma ṣe rere; ma wá alafia, ki o si lepa rè̩.” Pe ki eniyan má pa ẹlomiran lara ko to. A ni lati “ma ṣe rere” – a gbọdọ wulo ki a si ṣe iranwọ. Nigbà ti a kẹkọọ nipa Debora ati Baraki (Ẹkọ 191) a gbọ pe a fi ilu Merosi bú lati ọdọ Oluwa nitori kò ṣe nnkan kan. Awọn ara ibẹ kò di awọn eniyan Ọlọrun lọwọ ṣugbọn bakan naa ni wọn kò ṣe iranwọ nigba ti o wà ni ipá wọn lati ṣe bẹẹ. “Nwọn kò wá si iranlọwọ OLUWA, si iranlọwọ OLUWA si awọn alagbara” (Awọn Onidajọ 5:23).
S̩iṣe rere nikan kọ ni Ọlọrun n fẹ lati ọdọ eniyan. A ni lati lọ kuro ninu ibi. Awọn kan wa ti n ṣiṣẹ oore ṣugbọn wọn kò le ni ayọ tootọ titi wọn o fi lọ kuro ninu ibi. “Òpopo-ọna awọn aduro-ṣinṣin ni ati kuro ninu ibi” (Owe 16:17). “Ki olukuluku ẹniti npè orukọ Oluwa ki o kuro ninu aiṣododo” (2 Timoteu 2:19). Ọna ti o ba lodi si ọna Ọlọrun, ọna buburu ni. Ibi wà ninu ṣiṣe aigbọran si Ọrọ Ọlọrun. Ọpọ eniyan ni kò fẹ lati gbà pe ọna wọn jé̩ buburu, ṣugbọn ẹnikẹni ti kò ba ri igbala, o kuna lati pa aṣẹ Ọlọrun mọ. Aigbọran si Ọlọrun ati aigbagbọ ninu Rè̩ a maa sọ igbesi-aye wa nihin di alailayọ ati ni ayeraye, idajọ.
Ipọnju
“Bakanna li ohun gbogbo ri fun gbogbo wọn; ohun kanna li o nṣe si olododo, ati si ẹni buburu; si enia rere, ati si mimọ ati si alaimọ; si ẹniti nrubọ, ati si ẹniti kò rubọ” (Oniwasu 9:2). S̩ugbọn iyatọ nlá nlà ni o wà laaarin awọn eniyan buburu ati eniyan rere. Nigbà ti wahala ati àjalu ba de ba eniyan buburu, kò si ẹni ti yoo ràn wọn lọwọ. Awọn ti n ṣe ibi kò le ṣai jiya, ṣugbọn Ọlọrun a maa gba olododo. Oluwa a maa rán iranwọ si awọn ti o gbẹkẹle E. Dafidi wi pe ọpọlọpọ ni ipọnju olododo ṣugbọn Ọlọrun gbà á ninu wọn gbogbo. Kò ha ṣaṅfaani lati ni oludasilẹ kuro ninu ọpọlọpọ ipọnju ju ati ni ipọnju ẹyọ kan ṣoṣo lai si ẹni ti yoo gba ni?
Isọdahoro
Dafidi fi iyatọ hàn laaarin alaiwa-bi-Ọlọrun ati ẹni iwa-bi-Ọlọrun. Ninu ibanujẹ ati labẹ ibinu Ọlọrun ni awọn ti kò wá Ọlọrun ti wọn ko si gbẹkẹ le E maa n wà, wọn o si duro niwaju Rè̩ ni idajọ. Wọn jẹbi -- ẹni ti a kọ silẹ, ti kò ni abanikẹdun, ti o si sọnu, boya ti a si n pọn loju. Ko ni si ẹni ti yoo rà wọn pada, nitori wọn ti kuna lati ke pe Oluwa ki o to pẹ ju. Iparun ati idalẹbi ni yoo jé̩ ipin wọn laelae. S̩ugbọn Oluwa n ra awọn ti wọn n ṣafẹri Rè̩ pada. Ẹnikẹni ti o ba gbẹkẹ le Oluwa ki yoo jẹbi, ki yoo wà lai ni ọrẹ tabi oluranlọwọ.
Igboya
Bi a ti n kà nipa iriri Dafidi, njẹ kò ha rú ifẹ wa soke lati gbẹkẹle Ọlọrun sii? O ṣe e ṣe fun wa lati ni igboya kan naa ninu Ọlọrun eyi ti Dafidi ti ni. Bawo ni Dafidi ṣe ni iru igboya bayii? Dafidi jé̩ onirẹlẹ, o si n gbadura. Dafidi gbẹkẹ le Ọlọrun, ki i ṣe ninu agbara tabi ọgbọn ti rè̩. Dafidi dán Ọlọrun wò o si gbọran si aṣẹ Rè̩. Nitori Dafidi daṣa lati gbẹkẹ le Ọlọrun, o ni idaniloju pe iranwọ ati aabo Ọlọrun wà fun oun. O mọ pe Ọlọrun yoo gba oun. Awa naa pẹlu le ni irú igboya kan naa ninu Oluwa, nitori ileri Rè̩ kò le yè̩.
Questions
AWỌN IBEERE- Nigba wo ni Dafidi yin Oluwa?
- Ninu ta ni Dafidi n ṣogo?
- Bawo ni Dafidi ṣe mọ pe Oluwa gbọ nigba ti o gbadura?
- Ki ni Ọlọrun maa n ṣe fun olododo?
- Ki ni Oluwa yoo ṣe fun awọn ti i ṣe onirobinujẹ ọkàn ati awọn ti i ṣe onirora aya?
- Ta ni n yọ olododo kuro ninu ipọnju rè̩?
- Ninu meloo ninu ipọnju olododo ni a o yọ ọ kuro?
- Ta ni angẹli Oluwa maa n yí ká? Lati ṣe ki ni?
- Ki ni igboya?
- Bawo ni Dafidi ṣe ni igboya ninu Ọlọrun?