Orin Dafidi 103:1-22

Lesson 227 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Fi ibukún fun OLUWA, iwọ ọkàn mi, ati gbogbo ohun ti o wà ninu mi, fi ibukún fun orukọ rè̩ mimọ” (Orin Dafidi 103:1).
Notes

Pẹlu Gbogbo Ipá Rè̩

Bi Dafidi ti n rò nipa ọpọlọpọ ibukún rè̩, ọkàn rè̩ kún fun iyin si Ọlọrun. Dafidi kò le fi ibukún fun Ọlọrun to bi Ọlọrun ti bukún fun un, ṣugbọn Dafidi le fi ogo fun Ọlọrun nipa yiyin In. Dafidi mọ-lara pe oun jẹ Ọlọrun ni igbese lati maa yin In. Ẹmi imoore ati idupẹ rú ọkàn Dafidi soke lati yin Ọlọrun lati odò ọkàn rè̩ wá, pẹlu gbogbo ohun ti o wà ninu rè̩: pẹlu gbogbo ayà, pẹlu gbogbo ọkàn, pẹlu gbogbo inu, pẹlu gbogbo agbara rè̩, ati pẹlu gbogbo ipá rè̩.

Anfaani lati ọdọ Oluwa ni awọn ibukún ati awọn ohun rere ti O fi fun wa. A kò gbọdọ gbagbe ọkan ninu wọn. Awọn ẹlomiran a maa yin ara wọn fun ire ti o wà ninu ayé wọn; wọn rò pe awọn ni o ṣiṣẹ fun awọn ohun rere wọnni ninu ayé wọn, ẹtọ wọn si ni. S̩ugbọn Ọlọrun ni olupilẹṣẹ ati orisun ohun rere gbogbo. “Gbogbo è̩bun rere ati gbogbo è̩bun pipé lati oke li o ti wá, o si nsọkalẹ lati ọdọ Baba imọlẹ wá” (Jakọbu 1:17). Iyin wa kò to nnkan lati fi san aanu Ọlọrun pada.

Idariji

Bi Dafidi ti n rò nipa aanu Ọlọrun, o bẹrẹ si ṣiro awọn ibukún wọnni ti o mu ki o maa yin Ọlọrun. Dafidi ti ri idariji gbà fun gbogbo è̩ṣẹ rè̩, ki i ṣe fun awọn è̩ṣẹ kékèké lasan tabi awọn ti o buru ju lọ nikan. Dafidi yin Ọlọrun Ẹni ti o ti dari gbogbo è̩ṣẹ rè̩ jì í. Bawo ni Dafidi ṣe mọ pe Ọlọrun ti dari gbogbo è̩ṣẹ rè̩ jì í? Dafidi ti gbà pe è̩lẹṣẹ ni oun i ṣe; o ti jẹwọ gbogbo è̩ṣẹ rè̩ fun Ọlọrun; o ti ronupiwada gbogbo è̩ṣẹ naa; o ti beere pe ki Ọlọrun dariji oun; nigbà ti o si gba gbogbo ileri Ọlọrun gbọ, alaafia ati idaniloju pe a ti dari awọn è̩ṣẹ rè̩ jì í ati pe wọn si ti rekọja wọ inu ọkàn Dafidi. Ki i ṣe Dafidi nikan ni idariji è̩ṣẹ yii wa fun; ẹnikẹni ni o le rí i gbà lọdọ Ọlọrun. “Bi awa ba jẹwọ è̩ṣẹ wa, olõtọ ati olododo li on lati dari ẹṣẹ wa jì wa, ati lati wè̩ wa nù kuro ninu aiṣododo gbogbo” (1 Johannu 1:9).

Iwosan

Ibukún miiran ti Dafidi ri gbà lọdọ Ọlọrun ni iwosan fun ara rè̩ -- iwosan fun gbogbo arun. Ki i ṣe awọn arùn diẹ tabi awọn ti kò nira pupọ nikan ni agbara Ọlọrun le bojuto. Gbogbo aisan ati gbogbo arun ni Ọlọrun n wosan. Anfaani yii ki i si ṣe ti awọn ti o wà ni ayé ni akoko ti Bibeli nikan. Awa ti akoko yii le ri imularada gbà fun ara wa nipasẹ È̩jè̩ Jesu.

Itọni wà ninu Bibeli fun awọn ti n ṣaisan. “Inu ẹnikẹni ha bajẹ ninu nyin bi? jẹ ki o gbadura. . . . adura igbagbọ yio si gbà alaisan na là, Oluwa yio si gbé e dide” (Jakọbu 5:13-15). Apẹẹrẹ pupọ ni o si wà ninu Bibeli nipa bi a ti wo awọn alaisan sàn: ti ẹtẹ (Matteu 8:3), ti arun-ẹgbà (Matteu 8:6, 13), ti ibà (Matteu 8:14, 15), ti oju fifọ (Matteu 9:28-30), ti ọwọ ti o rọ (Matteu 12:13), ti ẹni ti o yadi (Matteu 12:22), ati awọn ọpọlọpọ arun miiran. “Jesu si rìn si gbogbo ilu-nla ati iletò, o nkọni ninu sinagogu wọn, o si nwāsu ihinrere ijọba, o si nṣe iwòsan arun ati gbogbo àisan li ara awọn enia” (Matteu 9:35). Ni ile iṣẹ ti Ijọ Igbagbọ Aposteli (Apostolic Faith) ni Portland, Oregon, awọn akọsilẹ ati ẹri wà nipa awọn ti o ti ri imularada gbà ninu oriṣiriṣi arùn ati aisàn nigbà ti a gbadura fun wọn ti wọn si ni igbagbọ ninu Ọlọrun. Bi o ba n ṣaisan tabi ti o ba mọ ẹni kan ti o n ṣaisan, awọn ọrọ Dafidi wọnyii kò ha ki ọ laya lati yin Ọlọrun Ẹni ti O le wo “gbogbo àrun rẹ”? Dajudaju Ọlọrun ti mu ọ lara dá tẹlẹ ri. Njẹ o ranti lati dupẹ ki o si yin In?

Awọn Ibukún Miiran

Dafidi mọ pe ẹni ti o ba lo igbesi-aye rè̩ ninu è̩ṣẹ doju kọ iparun ati ikú ẹmi. Dafidi mọ pẹlu pe Ọlọrun le ra ọkàn oun pada lọwọ apanirun, ti i ṣe Satani. Lati rà pada ni lati ri nnkan ti o ti sọnu ati lati rà á pada. Ọmọ Ọlọrun, Jesu Kristi, fi ẹmi Rè̩ lelẹ lati ra ẹmi wa pada. O san owo irapada ẹmi wa. Dafidi mọ pe Ọlọrun lagbara lati ra ni pada, ṣugbọn o tilẹ mọ ju bẹẹ lọ -- pe Ọlọrun ti ra ọkàn oun pada. Ọpọlọpọ eniyan ni o mọ pe a le gbà ọkàn wọn là. S̩ugbọn ohun miiran patapata ni pe ki eniyan mọ pe oun ti ri igbala, ki o si ni idaniloju pe a ti ra oun pada. Lati ni imọ pe a le ri igbala kò to. A gbọdọ le sọ pẹlu idaniloju – ki a mọ pe Ọlọrun ti gbà wá là. Iwọ ha ni ẹri yii ninu ọkàn rẹ ati ninu aye rẹ pe a ti gbà ọ là?

Ki i ṣe lọwọ ikú ati ninu iparun nikan ni Ọlọrun ti gbà Dafidi là ṣugbọn O ti mú ki o ni ẹkunrẹrẹ ayọ tootọ. Ọlọrun ti fi ọlá, inudidun ati ẹmi gigùn dé Dafidi ni ade. Igbadùn ti o ga ju lọ laye ni nini ojurere, aabo, ati idariji lati ọdọ Ọlọrun. Dafidi maa n ronu nipa ifẹ, inurere, ati aanu ti Ọlọrun ti fi hàn fun un, ti o si ti fi fun un. Nigbà ti eniyan ba ri igbala, Ọlọrun a fi ẹmi kan sinu ọkàn rè̩ ti yoo mu ki o maa fi “iṣeun-ifẹ ati iyọnu” hàn fun awọn ẹlomiran. Onigbagbọ a maa so eso Ẹmi (Galatia 5:22, 23). Onigbagbọ a maa gbà ibukún lati ọdọ Oluwa ki o ba le dàbi Kristi. Itumọ Onigbagbọ ni dida-bi-Kristi.

Bibeli

Dafidi fi mimọ riri ati ọpẹ hàn fun Ọrọ Ọlọrun. Ọrọ Ọlọrun ni ounjẹ fun ọkàn wa. Lai si Ọrọ naa ebi yoo pa wá nipa ti ẹmi. Jobu pọn Ọrọ Ọlọrun le ju ounjẹ rè̩ nipa ti ara lọ. O ni, “Emi si pa ọrọ ẹnu rè̩ mọ jù ofin inu mi lọ” (Jobu 23:12). Wolii Isaiah ké si gbogbo eniyan lati wá jẹ ninu ounjẹ ẹmi, ki wọn ba le ni itẹlọrun. “Nitori kini ẹ ṣe nná owo fun eyiti ki iṣe onjẹ? ati lāla nyin fun eyi ti kì itẹnilọrun? ni gbigbọ, ẹ gbọ t’emi, ki ẹ si jẹ eyi ti o dara, si jẹ ki inu nyin dùn ninu ọra” (Isaiah 55:2).

A kò i ti ri iwe miiran ti a kọ ti o le gbé eniyan ró nipa ti ẹmi bi Bibeli. Ọrọ Ọlọrun jẹ kò ṣe-e-mani, nitori Oun ni o n fun wa ni imulọkanle nipa igbagbọ, ireti, ati ifẹ wa ninu Ọlọrun. Lati atetekọṣe, ni Ọlọrun ti bá eniyan sọrọ ti O si fun un ni Ọrọ Rè̩. Mose ati Ofin kọ awọn Ọmọ Israẹli ni ifẹ Ọlọrun ati ọna Rè̩. Awa ni Bibeli a si tun ni anfaani lati bá Ọlọrun sọrọ nipa adura.

Gẹgẹ bi Idì

Dafidi fi Onigbagbọ wé idì, ẹyẹ kan ti o ni ẹmi gigùn -- awọn miiran a maa lò tó ọgọrun ọdún. A le rò pe nigba ti idì ba to iye ọdun yii ara rè̩ yoo ti gbó bi àkisá, ti ninu awọn iyẹ rè̩ yoo ti di ogbologbo ki o si yọ sọnu. Ìyé̩ ṣe pataki fun ẹyẹ. On ni o n fun un ni aabo lọwọ ooru ati iji. Ìyé̩ ṣe pataki fun ẹyẹ lati fò. Bi iyẹ ti o pọ ju ba yọ kuro ni apa ẹyẹ kan, ẹyẹ naa kò ni le fo taara lọ si ọna ti o n fẹ. A sọ fun ni pe idì a maa lo iyẹ rè̩ bi ohun-ija – lati fi lù ati lati fi gún ọta rè̩ ati ẹran ọdẹ rè̩ si wẹwẹ. Ẹmi idì kò ni gùn bi o ba sọ iyẹ rè̩ nù tabi bi wọn ba ge ti wọn si di gbigbo. Ọlọrun ti pese fun idì: lati igba de igba ni ipaarọ maa n ṣẹlẹ -- nigba ti awọn iyẹ atijọ yoo bọ, ni ọkọọkan, ti awọn iyẹ titun yoo dipo wọn. Lọna bayii aabo, ohun-ija, ati iranlọwọ fun fifo idì a di ọtun.

Isọdọtun wà fun Onigbagbọ nipa Ọrọ Ọlọrun – ki i ṣe ni ifarahan nikan ṣugbọn isọdọtun ti ẹmi. Ọlọrun ti ṣe ipese silẹ fun Onigbagbọ, “gẹgẹ bi ọrọ ogo rè̩, ki a le fi agbara rè̩ mú nyin li okun nipa Ẹmi rè̩ niti ẹni inu” (Efesu 3:16). Adura ati ifararubọ jẹ aigbọdọ ma ṣe pẹlu lati mu ki ẹmi eniyan maa wà ni ọtun nigba gbogbo.

Dafidi sọ pe “igba ewe rẹ” si di ọtun bi ti idì. Ni titọkasi igbà ewe, eyi n sọ ti igba agbara, igba aapọn, itara ṣaṣa ninu ṣiṣe nnkan, ati igba didagbasoke. Gbigbe igbesi-aye wa nipasẹ Ọrọ Ọlọrun -- gbigbọran si i ati kikọ ẹkọ ninu rè̩ -- a maa sọ ẹmi Onigbagbọ di ọtun a si maa sọ ọ jí. Ki i ṣe ti rè̩ lati de aye kan ti ẹmi rè̩ yoo fi di alailera ki ẹmi rè̩ si tẹba fun ogbó. Ilera eniyan nipa ti ara le dinku – ki o má si le ṣaapọn mọ ṣugbọn ẹni ti inu rè̩ a jé̩ alagbara, a si wà ni iduro ṣinṣin sibẹ. Wolii Isaiah paapaa lo idì lati fi ṣe apejuwe ohun ti Ọlọrun yoo ṣe fun awọn ti o gbẹkẹ wọn le E. Isaiah wi pe “Awọn ti o ba duro de OLUWA yio tun agbara wọn ṣe; nwọn o fi iyé̩ gùn oke bi idì; nwọn o sare, ki yio si rè̩ wọn; nwọn o rìn, ārè̩ ki yio si mu wọn” (Isaiah 40:31).

Tì Rẹ

Awọn ibukún wọnyii ti Dafidi mẹnu ba ki i ṣe ti rè̩ nikan ṣugbọn fun olukuluku ẹni ti o bá gbagbọ. Ninu awọn ẹsẹ wọnyii Dafidi kò wi pe temi; o ni ibukún rẹ. Ni afikun awọn nnkan rere ti Dafidi sọ wọnyii a le tun sọ nipa awọn miiran, bi irẹpọ pẹlu awọn eniyan Ọlọrun, ati anfaani wiwá si ile-isin. Njẹ o le fi awọn ohun rere ti Ọlọrun ti pese fun ọ kún awọn akọsilẹ wọnyii?

Aanu Ọlọrun

Ọlọrun kò fi iyà jẹ wa gẹgẹ bi o ti tọ si wa fun awọn è̩ṣẹ ti a ti ṣè̩. Ọlọrun jé̩ alaaanu o si ni ipamọra pupọ; Oun kò i ti huwa lile kan ti o nira si ni lai nidii ri (Romu 11:22). Ọlọrun jé̩ Olododo, A si maa ṣe ohun ti o tọ. Nipasẹ Ọrọ Rè̩ O jẹ ki a mọ ohun ti Oun n fẹ lọwọ wa, ati pe a le gbẹkẹ wa le E. Bi eniyan ba ronupiwada ti o si gbadura fun idariji, ibinu Ọlọrun kò ni si lori rè̩ mọ. A mu è̩ṣẹ rè̩ jinna rere kuro to bẹẹ ti a kò le mọ jijin -- “bi ila-õrun ti jina si iwọ-õrun.” Oun o rí aanu, ibakẹdun, ati idariji kikún dipo èrè è̩ṣẹ rè̩.

Dafidi fi bi aanu Ọlọrun ti wà pẹ to wé ọjọ aye eniyan. Ni afiwe aanu Ọlọrun, igba aye eniyan dabi “ikku. . . . ti o hàn nigba diẹ, lẹhinna a si túka lọ” (Jakọbu 4:14). Dafidi tun fi igba igbesi-aye eniyan we itanna eweko igbẹ -- ki i tilẹ i ṣe itanna inu ọgba. Kò si itọju fun itanna igbẹ bẹẹ ni a ki i bomi rin ín, a ki i si fọn oogun si i lara nitori kokoro ati arun. Itanna igbẹ kò ni aabo lọwọ otutu nla, ooru, ati iji. Itanna kan naa ṣá ni bi awọn itanna iyoku. O ṣe e ṣe ki a tẹ ẹ mọlẹ ki a si pa a, tabi ki ẹranko jẹ ẹ ki o si pa a run. Awọn itanna eweko igbẹ ki i wa pẹ lọ titi. Lai pẹ wọn a rekọja à á si gbagbe wọn. Bakan naa ni, ohun ti o maa n ṣẹlẹ ni ki eniyan wà fun igba kukuru, ki o si kú. S̩ugbọn aanu Ọlọrun kò ri bẹẹ. O wà titi lae fun awọn ti o bẹru Ọlọrun ti wọn si sin In, fun awọn ti o pa ofin Rè̩ mọ, ti wọn si gbe igbesi-aye igbagbọ ati igbọran. “Dajudaju koriko ni enia. Koriko nrọ, itana nrè̩: ṣugbọn ọrọ Ọlọrun wa yio duro lailai” (Isaiah 40:7, 8). “nu OLUWA lati aiyeraiye ni lara awọn ti o bè̩ru rè̩” (Orin Dafidi 103:17, 18).

Gbogbo Eniyan ni Ibi Gbogbo

Dafidi ni ẹmi imoore eyi ti o n fi iyin fun Ọlọrun. Dafidi kò ni itẹlọrun titi o fi mu awọn ẹlomiran lọkan le ti o si rú ọkàn wọn soke lati yin Oluwa pẹlu. Ọlọrun, Ẹni ti o dá ohun gbogbo, ti O si n ṣakoso ohun gbogbo, ni ẹtọ si ifẹ wa ati iyin wa. Gbogbo iṣẹ ọwọ Ọlọrun -- awọn angẹli ti ogun ọrun, awọn Onigbagbọ ati olukuluku eniyan – ni lati yin In. Dafidi mọ pe gbogbo iṣẹ Ọlọrun, awọn eniyan, ati ohun gbogbo, ni ibi gbogbo ni o jẹ Ọlọrun ni igbese iyin. Ọpọlọpọ nnkan ti a dá ni kò le wi iyin jade, ṣugbọn wọn n fi iyin fun Ọlọrun nipa ẹwa ati awọ wọn.

Dafidi pari Saamu yii gẹgẹ bi o ti bẹrẹ rè̩. “Fi ibukún fun OLUWA, iwọ ọkàn mi.” O dara lati rán awọn ẹlomiran leti lati yin Ọlọrun; ṣugbọn ẹ jé̩ ki olukuluku wa jé̩ olóòótọ. Ẹ jẹ ki a yin Ọlọrun, ojurere Rè̩ yoo si wà lori ayé wa.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ta ni Dafidi yin pẹlu ohun gbogbo ti o wà ninu rè̩?
  2. Darukọ diẹ ninu awọn anfaani ti Dafidi mẹnu ba?
  3. Ki ni ṣe ti a fẹran Bibeli?
  4. Ire wo ni a n ri gbà lati inu Ọrọ Ọlọrun?
  5. Ẹyẹ wo ni Dafidi fi Onigbagbọ wé?
  6. Lọna wo ni igbesi-aye eniyan fi dabi ikuuku?
  7. Bawo ni Ọlọrun ti maa n mu è̩ṣẹ eniyan jinna kuro tó?
  8. Bawo ni aanu Ọlọrun ti wà pé̩ tó?
  9. Ta ni Dafidi n rọ lati yin Ọlọrun?
  10. Ọrọ wo ni Dafidi fi pari Saamu yii?