Owe 31:10-31

Lesson 228 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “O fi ọgbọn yà ẹnu rè̩; ati li ahọn rè̩ li ofin iṣeun” (Owe 31:26).
Notes

Ọkunrin Ọlọgbọn

Nigbà ti Sọlomọni di ọba lori Israẹli, o rí ara rè̩ ni alainilaari niwaju Ọlọrun, o si gbadura bayii: “Ọmọ kekere ni mi, emi kò si mọ jijade ati wiwọle” (1 Awọn Ọba 3:7). Ninu adura naa o beere fun ọgbọn dipo ọrọ ati ọlá fun ara rè̩. Ọlọrun dahun pe, “Emi fun ọ ni ọkàn ọgbọn ati imoye; tobḝ ti kò ti isi ẹnikan ti o dabi rẹ ṣāju rẹ, bḝni lẹhin rẹ ẹnikan kì yio dide ti yio dabi rẹ” (1 Awọn Ọba 3:12). Ọkunrin ọlọgbọn yii ni o kọ eyi ti o pọ ju ninu Iwe Owe.

È̩kọ fun awọn Ọdọ

Pẹlu ọgbọn ti Ọlọrun fi fun Sọlomọni yii, o le kọ awọn ọdọ bi wọn ti ṣe le gbe igbesi-aye ti o kún fun ayọ ati aṣeyọri. O gbagbọ pe bi a ba tọ awọn ọmọde ati awọn ọdọ si ọna rere, ti wọn ba si bẹrẹ igbesi-aye wọn nipa gbigbọran si aṣẹ Ọlọrun, wọn o dagba lati jé̩ ọkunrin rere ati obinrin rere. Ki a tilẹ wi pe awọn ọdọ wa oni kò ni ẹkọ miiran nipa iwa rere ju ohun ti wọn ba pade ninu Iwe Owe, wọn o ri ẹkọ kọ nibẹ tó lati mu wọn ṣe aṣeyọri ninu igbesi-aye wọn. Ọba Sọlomọni sọ ninu ọkan ninu awọn owe rè̩ pé: “Ọmọ mi, máṣe gbagbe ofin mi; si jẹ ki aiya rẹ ki o pa ofin mi mọ. Nitori ọjọ gigùn, ati ẹmi gigùn, ati alafia ni nwọn o fi kún u fun ọ. Máṣe jẹ ki ānu ati otitọ ki o fi ọ silẹ: . . . bḝni iwọ o ri ojurere, ati ọna rere loju Ọlọrun ati enia” (Owe 3:1-4).

Iya Rere

Lẹyin ti Sọlomọni ti kọ ẹgbẹẹgbẹrun owe, ki o to pari iwe rè̩ o kọ ohun miiran ti o yatọ. O fi hàn pe oun mọ iyi iya rere. Oun kò ka ara rè̩ si ẹni ti o ti ni ọgbọn kọja ti iya rè̩, bi o tilẹ jẹ pe Ọlọrun funra Rè̩ ni O kọ ọ. Ninu ọgbọn rè̩ o mọ pe, fun olukuluku ọmọde, ogún ti a ko le fi owo rà ni iya rere jé̩.

Iye owo obinrin rere kọja ti iyùn. Itumọ èyi ni pe anfaani rè̩ ju ohun ti owo le rà lọ. Ewo ni iwọ i ba yàn, iya rere ti o jé̩ talaka, tabi iya ti o ni ọrọ ṣugbọn ti kò ni kọ ọ nipa Jesu? Eyi ti o buru pupọ tilẹ ni pe ki i ṣe obi pupọ ni n kọ awọn ọmọ wọn ni ofin Ọlọrun yala wọn jé̩ talaka ni tabi wọn jé̩ ọlọrọ.

Mímọ Rírì Iya Onigbagbọ

Nigba pupọ ni awọn ọmọde ki i mọ riri iya Onigbagbọ. Oju tilẹ lè maa tì wọn fun un ki wọn to dagba. Aṣẹ Ọlọrun ni lati bu ọlá fun awọn obi wa; nigba ti a ba dagba diẹ sii a maa n ri irú wahala ti wọn ti gbà wa ninu rè̩ ati anfaani pupọ ti adura wọn ti ṣe fun wa; bi ifẹ Ọlọrun ba si wà lọkàn wa, a o bu ọlá fun wọn bi o tilẹ jẹ pe wọn le ṣe alaini ati alaijafafa ninu ẹkọ aye. Nigba ti a ba mọ pe fun anfaani wa ni wọn ṣe kọ wa pe a ni lati ṣiṣẹ, ki a si tẹriba fun aṣẹ awọn ti o ju wa, a o wa rii pe iye wọn “kọja iyùn.” A le wa mọ ohun ti kò dara ninu igbadun aye ti iya wa kò jẹ ki a lọ sinu rè̩. Awọn ọmọ ti wọn mọ rírì iya wọn ti o jé̩ Onigbagbọ yoo dide, wọn o “si pè e li alabukúnfun.”

Sọlomọni, ọlọgbọn nì¸ wi pe, “Ọlọgbọn ọmọ ṣe ayọ baba; ṣugbọn aṣiwère enia gàn iya rè̩” (Owe 15:20); ati pe, “Fetisi ti baba rẹ ti o bi ọ, má si ṣe gàn iya rẹ, nigbati o ba gbó” (Owe 23:22).

Apẹẹrẹ Kristi

Jesu fun wa ni apẹẹrẹ rere fun gbogbo ọmọde lati tè̩le. Lati ipilẹṣẹ ni Oun ti jé̩ Ọmọ Ọlọrun, O si ni ọgbọn ti Ọrun. O bá Ọlọrun dọgba O si ti wà pẹlu Baba Rè̩ lati ayeraye. Sibẹ nigbà ti O n dagba, O gbọ ti iya Rè̩. Lẹyin ti o tilẹ ti fi òye Rè̩ nipa Iwe Mimọ ya awọn rabbi amoye lẹnu ninu Tẹmpili nigba ti o jé̩ ọmọ ọdun mejila, O bá baba ati iya Rè̩ sọkalẹ lọ si ile, O si “fi ara balẹ fun wọn” (Luku 2:51). Oun, gẹgẹ bi Ọmọ Ọlọrun, tẹriba fun awọn obi Rè̩ nipa ti ara, O si fun wa ni apẹẹrẹ bi o ti yẹ ki gbogbo ọmọde maa ṣe.

Ọlọrun ti paṣẹ pe ki awọn ọmọ maa gbọ ti awọn obi wọn “ninu Oluwa” (Efesu 6:1). Ki i ṣe ifẹ Jesu pe ki awọn obi alaiwa-bi-Ọlọrun kọ ọmọ wọn lati jale ati lati purọ; a kò si gbọdọ tẹle iru aṣẹ bẹẹ. A gbọdọ gbọ ti Ọlọrun ṣiwaju ohun gbogbo.

Awọn Iwa Iya Rere

Ninu owe yii a sọ iwa obinrin rere fun wa. Anfaani ọkọ rè̩ ni yoo maa wá nigba gbogbo, oun kò si ni jé̩ ṣe ohunkohun ti o le mu ki itiju bá ọkọ rè̩. Oun ki i ṣe ọlẹ, ṣugbọn o n ṣiṣe tinutinu, o si ni inu didun si ohun ti o le ṣe fun awọn ẹlomiran. O ṣe rere fun awọn ọmọ rè̩, o fẹran wọn, o si n da aṣọ daradara fun wọn, o n fun wọn ni ounjẹ ti o tọ lati mu wọn wà ni ilera. O mọ ile rè̩ bojuto lọna ti awọn alaini fi n ri diẹ nibẹ. Oun kò bẹru igbà otutu ti n bọ, nitori o ti pese aṣọ ti o mooru silẹ fun awọn ara ile rè̩, ki iyà má ba jẹ wọn. Oun kò pa iṣẹ Oluwa tì ki o ba le to ọrọ jọ nitori “ọjọ ọla”, ṣugbọn o jẹ ẹni ti n tẹpá mọṣẹ ti o fi n ronu nipa aini rè̩ ki ọkàn rè̩ ba le sinmi ki o si le ni itẹlọrun nigbà ti o ba ni ajalù.

Sísùn Nigba ti Ìji ba n Jà

A sọ itan kan fun ni nipa agbè̩ kan ti o n wá alagbaṣe fun oko rè̩. Ẹni kan ninu awọn ti o n fẹ ṣe iṣẹ alagbaṣe yii jẹri ara rè̩ pe “Mo le sùn nigbati iji ba n jà.” Idahun yii mú agbè̩ naa lọkàn, o si gba ọgbẹni naa si iṣẹ lati mọ ki ni itumọ ọrọ yii. Lati ọjọ de ọjọ alagbaṣe yii ṣiṣẹ tọkantọkan o si ṣe e daradara pẹlu; a kò ri ohun kan ti o yatọ ninu iwa rè̩. S̩ugbọn ni oru ọjọ kan iji nla jà, ariwo ilẹkun ti n pade, ati ti awọn maluu ati adiẹ ti n sá kiri si ji agbè̩ naa. Akeku koriko ti a fi silẹ ni ita si n fò kiri ninu atẹgun. S̩ugbọn ọgbẹni alagbaṣe yii sun fọnfọn. Nigba ti agbè̩ naa lọ jí i, ohun ti o sọ kò ju pe, “Mo le sùn nigbati iji ba n jà.” Nigba naa ni agbè̩ naa rii pe ohun-ọsin aladugbo oun ni o ti n sá kiri. A ti ti ilẹkun ọgbà rè̩ gbọningbọnin, awọn maluu si wà lai lewu ninu ọgbà. Gbogbo adiẹ rè̩ wà ninu ago ti wọn. A ti de apoti koriko rè̩ mọlẹ. Ọgbẹni alagbaṣe rè̩ ti mura silẹ de iji naa, kò si si eredi fun un lati ṣe iyọnu nigba ti iji naa dé.

Bẹẹ ni o ri fun iya ti n fi oju silẹ wo iwa awọn ara ile rè̩. O yẹ ki o mura silẹ, ki i ṣe fun abojuto ohun ti ara nikan, ṣugbọn o ni lati kiyesi iwa awọn ọmọ rè̩ nigba ti wọn ṣi kere, ki wọn ba le mọ bi a ti i gbọran ti a si i ṣe rere nigba ti wọn ba dagba. O ni lati pese wọn silẹ de ewu ati idanwo ti kò le ṣai doju kọ wọn, ki òye è̩ṣè̩ ba le yé wọn, ki wọn ki o si le mọ bi a ti i doju kọ wọn.

Obinrin oni iwa-rere yii fi ara balẹ wá oko ti o le rà. O gbin ọkà rere sinu rè̩ fun ounjẹ ni akoko otutu, ati fun ere ni ọjà. Pẹlu gbogbo iṣẹ yii oun kò kanra mọ ni nigba ti o ba rè̩ é̩. “O fi ọgbọn yà ẹnu rè̩; ati li ahọn rè̩ li ofin iṣeun.” Ki i ṣe pe o n fi iwa pẹlẹ sọrọ fun awọn ọmọ rè̩ nikan, o pa a laṣẹ fun wọn lati maa ran ara wọn lọwọ pẹlu.

Iyawo Kristi

A le fi obinrin oni iwa-rere yii wé Iyawo Kristi, ti i ṣe ọmọ ni tootọ fun Ọlọrun. Jesu ni Ọkọ-iyawo, O si le fi ọkàn tán Iyawo Rè̩, Ijọ tootọ, lati má mu ẹgan bá orukọ Rè̩ nihin ninu aye. Igbesi-aye Onigbagbọ wà lori ipinnu pe ki Jesu má ṣe tiju oun.

Tinutinu ni Iyawo Kristi n ṣiṣẹ lati tan ihin igbala kalẹ. Ni ọna kin-in-ni, o kọ awọn ọmọ rè̩ lati maa ṣe ifẹ Jesu, o si n gbe igbesi-aye Onigbagbọ niwaju wọn. O si n sọ fun awọn aladugbo rè̩ ati awọn eniyan miiran ti o n ba pade nipa ifẹ Jesu fun wọn ati ifẹ Rè̩ lati gbà wọn kuro ninu è̩ṣẹ wọn.

Awọn nnkan ti aye yii kò té̩ Iyawo Kristi lọrun, ṣugbọn o n mu ounjẹ rè̩ “lati ọna jijin rére wá.” Itumọ eyi ni pe ohun ti o ṣe pataki ninu igbesi-aye rè̩ ni awọn nnkan ti Ọrun, ati pe “ayọ OLUWA” ni agbara rè̩. O n gbadura si Ọlọrun fun ọgbọn, o si n ka Bibeli rè̩ ki o ba le mọ ifẹ Ọlọrun. Jobu wi pe “Emi si pa ọrọ ẹnu rè̩ mọ jù ofin inu mi lọ” (Jobu 23:12). O ni lati yé wa pe Bibeli ni Amọna wa si Ọrun o si gbọdọ jẹ ohun ti o niye lori jù lọ ninu igbesi-ayé wa.

Oluwa ni inu-didun pupọ lori Ijọ Rè̩, ani Iyawo Rè̩. O yẹ ki gbogbo wa sa gbogbo ipá wa bi ẹni kọọkan lati rii pe lae, ireti Oluwa wa kò ni já si asán. Nipa iwa wa, a fẹ ki aye mọ pe ti Jesu ni a jé̩.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ta ni kọ Iwe Owe?
  2. Bawo ni o ti ṣe di ọlọgbọn?
  3. Ta ni o kọ eyi ti o pọ ju ninu awọn ẹkọ rè̩ fun?
  4. Ki ni ofin Ọlọrun fun awọn ọmọ?
  5. Darukọ diẹ ninu iwa iya rere?
  6. Ta ni Iyawo Kristi?
  7. Ifẹ ta ni o n fẹ lati ṣe?