2 Samuẹli 2:1-7, 11; 5:1-5; 6:1-15, 17

Lesson 229 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Iwọ o bọ Israẹli awọn enia mi, iwọ o si jẹ olori fun Israẹli” (2 Samuẹli 5:2).
Notes

S̩iṣọfọ fun Saulu ati Jonatani

Dafidi ṣọfọ fun ikú Saulu ati Jonatani. O fi ibọwọ ti o tọ hàn fun ọba rè̩ atijọ ti i ṣe ọta rè̩ pẹlu, inu rè̩ si bajẹ gidigidi fun ikú Jonatani, ọmọ Saulu. Dafidi pohun-rere ẹkun nipa kikọ orin kan silẹ eyi ti o sọ kiki iṣẹ rere ati ohun nla ti wọn ṣe. O sọ nipa Jonatani pe “Jonatani, arakọnrin mi” o si ranti ifẹ Jonatani ati inurere rè̩ si i.

Niwọn igba ti Saulu ti kú Dafidi ni a o fi jọba, nitori Oluwa ti fi ami-ororo yàn án tẹlẹ. Bi o tilẹ jẹ pe ikú Saulu jé̩ igbega fun Dafidi, kò yọ tabi ki o wi pe oun bọ nitori ọta oun kú. Dafidi kò yọ nigba ti ọta rè̩ ṣubu (Owe 24:17).

Adura

Dafidi i ba rán awọn onṣẹ jakejado gbogbo Israẹli ki o si paṣẹ fun gbogbo wọn pe ki wọn maa tẹriba fun oun gẹgẹ bi ọba. Dafidi kò ṣe irú nnkan bẹẹ rara. O duro de imuṣẹ ileri Ọlọrun. Dafidi a maa gbadura a si maa beere lọdọ Ọlọrun ni igbà oju rere ati ni igbà wahala. Dafidi kò jokoo fẹyin ti lai ṣe nnkan kan nigba ti o n duro de Oluwa, ṣugbọn o ṣe gbogbo eyi ti a tọ ọ sọna lati ṣe. Dafidi beere lọwọ Ọlọrun bi oun ba le lọ si ọkan ninu awọn ilu Juda. Ọlọrun si sọ pe ki Dafidi lọ. Dafidi kò lọ si Bẹtlẹhẹmu, ilu ti rè̩ tabi ibomiran ti oun i ba fẹ. Ọlọrun dari Dafidi si Hebroni, ilu awọn alufaa ti i ṣe ilu aabo pẹlu.

Ni Igbà Alaafia ati ni Igbà Ogun

Dafidi mu awọn ọkunrin wọnni pẹlu rè̩ ti wọn ti darapọ mọ ọn ni gbogbo igbà ti o n sá kiri. Awọn ti o wà ninu ipọnju, ati awọn ti o jẹ gbese, ati awọn ti o wà ninu ibanujẹ ti fi Dafidi jẹ olori wọn (1 Samuẹli 22:2). Awọn eniyan wọnyii ti wà pẹlu Dafidi ni igbà aini ati isapamọ. Nigba ti Dafidi de ipo ọba, kò gbagbe awọn ọrẹ rè̩. Wọn ti ba Dafidi jiyà, wọn ti wà ninu ebi pẹlu rè̩, wọn si ti wà ninu ibanujẹ pẹlu rè̩. Nisisiyii, awọn ẹgbẹ olóòótọ wọnyii yoo ṣe akoso pẹlu rè̩. Bibeli kọ wa pé awọn ti wọn ṣe olóòótọ, ti wọn si gbọran, ti wọn si bá Kristi jiya yoo jọba pẹlu Rè̩, nigbà ti Oun yoo sé̩ awọn ti wọn ba sé̩ Ẹ (2 Timoteu 2:12).

Ọba Juda

Lẹyin ti oun ati awọn eniyan rè̩ ati awọn ẹbi wọn ti lọ si Hebroni, ile Juda ti i ṣe awọn eniyan Dafidi fi ororo yan Dafidi lọba. Eyi ni igbà keji ti a fi ororo yan Dafidi lọba. Niwọn ọdun mẹwaa sẹyin, Samuẹli ti fi ororo yàn án lọba nipa aṣẹ Oluwa. Nisisiyii ifororoyan yii jé̩ lati ọwọ awọn eniyan Juda, apakan ninu awọn Ọmọ Israẹli.

Fun ọdun meje aabọ ni Dafidi fi jọba ni ile Juda ni Hebroni. Ni akoko yii Dafidi ba awọn eniyan Jabeṣi-gileadi ṣọrẹ, o si yin wọn fun inu-rere wọn si Saulu, ọba wọn atijọ, ẹni ti wọn sinku rè̩. Dafidi sọrọ ibukún Oluwa lori wọn ati ti inu-rere rè̩ si wọn. O fi iwa pẹlẹ sọ fun wọn pe a ti yan oun lọba ni ipò Saulu.

Awọn Ọmọ Saulu

Dafidi kò pa gbogbo eniyan Saulu run, gẹgẹ bi o ti jẹ aṣa lati ṣe. Ni ọjọ wọnni wọn ka a si ọranyan, fun fifi idi ijọba wọn mulẹ, pe ki wọn pa iran ọba ti o wà ṣiwaju wọn run. Dafidi kò gbe ọwọ rè̩ soke si ẹnikẹni ninu awọn ẹbi Saulu. Kò si ọba bi Dafidi ni ọna bayii. Awọn miiran ninu awọn ọmọ Saulu kú loju ogun a si pa awọn miiran lẹyin eyii, ṣugbọn ki i ṣe lati ọwọ Dafidi tabi nipasẹ iditẹ lati ọwọ rè̩.

Israẹli

Awọn aṣoju awọn ẹya Israẹli pejọ pọ si Hebroni. Wọn fi “ọkàn pipe wá. . . . . . lati fi Dafidi jọba” (1 Kronika 12:38). Dafidi ni Ọlọrun yàn, oun si ni awọn eniyan naa yàn pẹlu. Fun ọjọ mẹta ni wọn wà ni Hebroni lati bá Dafidi dá majẹmu, wọn n rọ ọ lati jé̩ alakoso wọn. Wọn sọ idi mẹta ti wọn fi fẹ ki o jẹ ọba wọn ati ọba Juda pẹlu. Gẹgẹ bi Ọmọ Israẹli, wọn jé̩ ará kan naa. Ofin Ọlọrun ni pe ọba wọn ni lati jẹ ọkan ninu awọn eniyan wọn, ki i ṣe alejo (Deuteronomi 17:15). Wọn rán Dafidi leti pe, “Wõ, egungun rẹ ati ẹran ara rẹ li awa iṣe”; eyi ti o fun un ni ẹtọ lati jé̩ ọba wọn.

Idi miiran ni pe wọn ranti iṣẹ rere ti Dafidi ti ṣe sẹyin fun awọn Ọmọ Israẹli. O ti jẹ olóòótọ lati ṣe ohun gbogbo ti o wa ni ipa rẹ lati ṣe fun ire awọn Ọmọ Israẹli. Boya wọn tọka si igba ti Dafidi pa Goliati nigbà ti awọn ọmọ-ogun, ani ọba paapaa, n bẹru niwaju omiran ọta wọn yii.

Idi kẹta ti awọn ọkunrin Israẹli sọ ni o ṣe pataki ju lọ. Ọlọrun ni o yàn Dafidi ti O si fi ami ororo yàn an. Oun ni yoo jẹ ọba ni igbà alaafia ati ni igbà ogun. Oluwa sọ fun Dafidi, “Iwọ o bọ Israẹli awọn enia mi, iwọ o si jẹ olori fun Israẹli.”

Ọba Ayé Wa

O wà ni ọkàn gbogbo Israẹli lati fi Dafidi jọba lori wọn. Kò si ẹni kan ti o sọ idi kan ti Dafidi kò fi ni lati jọba. Ẹni kan wà ti o tọ fun lati jẹ ọba ninu aye gbogbo eniyan lode oni. Kò si idi kan ti a le sọ fun kikọ lati fi Jesu ṣe Ọba ninu igbesi-aye wa. Awọn ẹlomiran a maa ṣe awawi ṣugbọn kò si idi kan ti o jẹ itẹwọgba. Ọpọlọpọ idi ni o wà ti Jesu fi ni lati jọba ninu ọkàn wa ati ninu aye wa, awọn ịdi ti o fara jọ eyi ti awọn ti o fi Dafidi jọba mu jade. Awọn ti o gbà Jesu ni Ọba ni a n pe ni arakunrin. Jesu wi pe, “Nitori ẹnikẹni ti o ba ṣe ifẹ Ọlọrun, on na li arakunrin mi” (Marku 3:35). Jesu nikan ṣoṣo ni o le fun ni ni idasilẹ kuro lọwọ ọta nì ti O si le mu è̩ṣẹ kuro ninu igbesi-aye wa. Bi Johannu Baptisti ti n wo Jesu, o wi pe, “Wò o, Ọdọ-agutan Ọlọrun, ẹniti o kó è̩ṣẹ aiye lọ” (Johannu 1:29).

Gẹgẹ bi oluṣọ-agutan ti n ṣe itọju agbo-ẹran rè̩, bẹẹ ni Jesu n tọ awọn eniyan Rè̩ ti O si n fi ounjẹ iye bọ wọn. Wọnyii ni ọrọ Jesu, “Ẹniti o ba tọ mi lẹhin ki yio rìn ninu òkunkun, ṣugbọn yio ni imọlẹ iye” (Johannu 8:12); ati, “Emi li onjẹ iye: ẹnikẹni ti o ba tọ mi wá, ebi ki yio pa a; ẹniti o ba si gbà mi gbọ, orùngbẹ ki yio gbẹ ẹ mọ lai.” (Johannu 6:35).

Jesu ni eto Ọlọrun fun igbala wa. Ọlọrun ni O fi I fun ni (Johannu 3:16), Ọlọrun fi ami-ororo yàn An (Iṣe Awọn Apọsteli 10:38), Ọlọrun si jẹwọ Rè̩ (Matteu 17:5). Jesu yoo gba ipò Rè̩ gẹgẹ bi Ọba awọn ọba ati Oluwa awọn oluwa (1 Timoteu 6:15). Ki ni ṣe ti iwọ ki yoo jẹ ki Jesu jé̩ Ọba ati Alakoso ninu ọkàn ati ayé rẹ nisisiyii?

Ijọba Dafidi

Ọlọrun jẹ ẹlẹri majẹmu ti Dafidi ati gbogbo àgba Israẹli ṣe. Ni ẹẹkẹta, a fi ororo yàn Dafidi lọba. Ọmọ ọgbọn ọdun ni Dafidi nigbà ti o bẹrẹ si i jọba. Bakan naa ni ọjọ ori awọn ọmọ Lefi nigba ti a ba pe wọn lati ṣe iṣẹ-isin fun Oluwa ninu Agọ (Numeri 4:47). Ọjọ ori Dafidi jẹ bakan naa bi ti Jesu nigba ti Jesu bẹrẹ iṣẹ-iranṣẹ Rè̩ laaarin awọn eniyan (Luku 3:23).

Dafidi jọba fun ogoji ọdun. Apa kan ijọba yii jé̩ ni Hebroni ilu kan ti o lokiki jalẹ itan awọn Ọmọ Israẹli. O jẹ ibi ti awọn iṣẹlẹ ti o yẹ fun iranti ti ṣẹlẹ. Ni Hebroni, Abrahamu mọ pẹpẹ kan fun Oluwa. Nibẹ ni Sara iyawo rè̩ gbe kú, a si sin in sinu iho kan nitosi ni Makpela, ni ilẹ isinku ẹbi wọn (Gẹnẹsisi 12:8; 23:2, 19, 20). Hebroni ni ilẹ-ini Kalẹbu nitori o tẹle Oluwa lẹyin patapata (Joṣua 14:14). Lẹyin eyi ni a fi Hebroni fun awọn Ọmọ Lefi (Joṣua 21:11-13) o si di ilu aabo (Wo Ẹkọ 139).

Dafidi jọba fun ọjọ pipẹ ju eyi lọ ni Jerusalẹmu. O di olori-ilu a si mọ ọn kaakiri ju Hebroni paapaa lọ, nitori a darukọ rè̩ titi de opin Bibeli. O fẹrẹ jẹ pe aarinmeji Ilẹ Mimọ ni o wà. “Bayi li Oluwa ỌLỌRUN wi; Eyi ni Jerusalẹmu: Emi ti gbe e kalẹ li ārin awọn orilẹ-ède, ati awọn ilẹ ti o wà yi i ka kiri” (Esekiẹli 5:5). Onisaamu kọrin nipa Jerusalẹmu pe, “Didara ni ipò itẹdo, ayọ gbogbo aiye li òke Sioni” (Orin Dafidi 48:2). Jerusalẹmu to iwọn ogun mile ti awọn ara Romu si ihà ariwa Hebroni, o si wà lori oke ti o tẹju pẹrẹsẹ -- ilu ori oke ti awọn arinrin-ajo maa n là kọja bi wọn ti n rin irin-ajo wọn lọ si ariwa ati guusu Palẹstini. A kà Jerusalẹmu si ibi ijọsin ti o lọwọ nitori nibẹ ni a kọ Tẹmpili Oluwa si. Ọlọrun a maa gbọ a si maa dahun adura ti a gbà ni ibi yii ati si ihà ilu naa (2 Kronika 7:12-15). O jé̩ apẹẹrẹ Jerusalẹmu titun (Ifihan 21:2), Ilu Mimọ ti Ọlọrun alaaye (Heberu 12:22), Ilu ti Ọrun eyi ti Ọlọrun tè̩do ti O si kọ (Heberu 11:10) ti a si pese silẹ fun awọn eniyan Rè̩. (Ẹkọ 169).

Apoti Oluwa

Lẹẹkan sii awọn aṣayan ọkunrin Israẹli pejọ pọ pẹlu Dafidi ọba wọn. Gbogbo wọn fi ohùn ṣọkan pe ohun ti o tọ ti o si dara ni lati mú Apoti Oluwa wá (1 Kronika 13:3, 4). Fun ọpọlọpọ ọdun ni Apoti naa ti wà ni ile Abinadabu, awọn Ọmọ Israẹli kò bikita nipa rè̩. Apoti naa jé̩ ami ifarahan Ọlọrun; nigba ti o si wà laaarin wọn, o jé̩ ibukun fun wọn. Nigbà ti awọn Filistini gba Apoti naa, wahala pupọ ni o de bá wọn. Ohun ti o jé̩ ibukun fun awọn eniyan Ọlọrun le jé̩ ègun fun aye. Ọrọ Ọlọrun jé̩ iye fun wa, o si jé̩ ikú fun awọn ti kò gba a layè lati ṣakoso aye wọn.

Ero rere ni o wà lọkàn Dafidi ni mimu ti o mu Apoti naa wá si Jerusalẹmu, ṣugbọn a kò sọ fun wa pe o gbadura lati beere fun itọsọna Ọlọrun nipa iṣipopada ohun ami mimọ ti ifarahan Oluwa yii. Ohun ti o lọlá ni fun awọn Ọmọ Israẹli lati ṣafẹri ifarahan Oluwa laaarin wọn. Ifarahan Oluwa a maa mu idalẹbi è̩ṣẹ wọ inu ọkàn, eyi ti i maa yọri si igbala. Ifarahan Oluwa a maa mu alaafia, igbẹkẹle, aabo, ati ireti wa. Lai si Oluwa kòrofo lasan ni eniyan jé̩.

Ọna ti Kò Tọ

Dafidi ati awọn Ọmọ Israẹli kò ṣe aṣiṣe lati fẹ ki Apoti Oluwa wà pẹlu wọn. S̩ugbọn ẹkọ ti wọn ni lati kọ ni pe a gbọdọ ṣe iṣẹ Ọlọrun ni ọna ti Ọlọrun. Wọn gbé Apoti Oluwa sori kè̩kẹ titun kan ti Ussa ati Ahio awọn ọmọ Abinadabu n dari rè̩. Gẹgẹ bi Ofin awọn ọmọ Lefi ni o gbọdọ ru u lori ejika wọn. Ọna kan naa ti awọn Filistini gbà fi gbe Apoti naa ni awọn Ọmọ Israẹli gbà (1 Samuẹli 6:7, 8). Wò iye eniyan ti wọn ti jiya nitori wọn fi awọn eniyan ti o yí wọn ká ṣe awoṣe wọn, dipo ti wọn i ba fi gbọran si aṣẹ Oluwa!

Ọlọrun Pa a

Bi awọn Ọmọ Israẹli ti n gbé Apoti naa bọ wá si Jerusalẹmu, ayọ wọn pọ pupọ. Wọn kọrin si Oluwa, awọn alo-ohun-elo orin si fi gbogbo ọkàn wọn ṣe e. Lojiji ni wọn kun fun è̩rù ati ibanujẹ. Awọn maluu kọsè̩ Apoti ti o wà lori kẹkẹ si mì. Ussa na ọwọ rè̩ lati di Apoti naa mu – o si ṣubu lulẹ, o si kú. Ọlọrun ti paṣẹ pe awọn ti n rù Apoti naa kò “gbọdọ fọwọkàn ohun mimọ kan, ki nwọn ki o má ba kú” (Numeri 4:15). Ussa fi ọwọ kan Apoti naa; nitori eyi Ọlọrun lù ú o si kú lẹba Apoti naa. Ussa le ni ero rere lọkàn lati mu Apoti naa duro, ṣugbọn o ṣe alafara pẹlu anfaani ti o ni lati tọju Apoti naa. Bi wọn ba ti gbe e gẹgẹ bi aṣẹ Ọlọrun, kò ni si aye fun Ussa lati fọwọ kan an. Aṣiṣe Ussa jé̩ apẹẹrẹ otitọ naa pe nitori a ni ero rere lọkàn kò dá eniyan lare lati huwà buburu. A ba jẹ le kẹkọọ lati maa sọrọ ati lati maa huwa si ohun mimọ Ọlọrun pẹlu ibẹru ati ọwọ.

Ọna Ọlọrun

Inu Dafidi bajẹ è̩rù si ba a. Ki Ọlọrun má ba pa gbogbo wọn, wọn gbe Apoti naa si ile Obedi-edomu, ara Gati. Ibukun Oluwa wà pẹlu Apoti naa. Obedi-edomu ati ile rè̩ rii pe o lere lati sin Oluwa, nitori Oluwa bukun fun wọn nigbà ti Apoti naa wà pẹlu wọn.

Dafidi gbadura o si beere bi wọn o ṣe gbe Apoti naa wá. Bi o ba ti gbadura lakọkọ ni, Ussa ki ba ti kú ni akoko yii, wọn i ba si ti ni ibukun Oluwa nigba naa. Dafidi pese ibi kan silẹ fun Apoti naa o si pa agọ kan fun un. Lẹyin oṣu mẹta awọn Ọmọ Israẹli gbé Apoti naa wá si Jerusalẹmu. Ni akoko yii wọn gbe e gẹgẹ bi ọna Ọlọrun – lori ejika awọn ọmọ Lefi (Numeri 7:9; 1 Kronika 15:2, 12-15), wọn fi aṣọ seali bò o (Numeri 4:6), wọn fi ọpa rù u (Ẹksodu 25:14). A gbe Apoti naa sinu agọ ti a ti pese silẹ fun un, wọn si rú ẹbọ si Ọlọrun ni iyin ati idupẹ. Nigba ti wọn gbé Apoti naa lọna ti o wu Ọlọrun, awọn Ọmọ Israẹli ṣe aṣeyọri. Ayọ nla ni o wà nitori wọn gbọran.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Darukọ awọn igbà ti a fi ami-ororo yan Dafidi ni ọba.
  2. Ninu ilu meji wo ni Dafidi gbé jọba?
  3. Ki ni ṣe ti a fi Dafidi jọba lori gbogbo Israẹli?
  4. Apẹẹrẹ wo ni Apoti Oluwa duro fun?
  5. Ki ni ṣẹlẹ si Ussa? Ki ni ṣe?
  6. Aṣiṣe wo ni awọn Ọmọ Israẹli ṣe ni gbigbe Apoti naa ni akọkọ?
  7. Ki ni ṣe ti Oluwa fi bukun Obedi-edomu ati ile rè̩?
  8. Nibo ni a gbé Apoti Oluwa sí nikẹyin?