Lesson 230 - Junior
Memory Verse
AKỌSORI: “Tani to lati kọ ile fun u, nitori ọrun ati ọrun awọn ọrun kò le gbà a? tali emi ti emi iba kọle fun u, bikòṣe kiki ati sun ẹbọ niwaju rè̩?” (2 Kronika 2:6).Notes
Alaafia ati Isimi
Ọlọrun ti fun Dafidi ni alaafia ati isimi kuro lọwọ gbogbo awọn ọta rè̩. Dafidi ti ja ogun pupọ ṣugbọn Ọlọrun wà pẹlu rè̩ lati gba a. Akoko de ti alaafia yí i kaakiri. Dafidi jokoo ninu idẹra ati irọrun ninu ile ti a fi igi kedari kọ. Lai ṣe aniani ohun ti o n rò ni iṣeun-ifẹ Oluwa lori rè̩. Dafidi jé̩ ọba, ilẹ rè̩ si wà ni alaafia. Bi o ba jẹ pe o fẹ bẹẹ o ni anfaani ati gbe igbesi-aye idẹra ati gbè̩fé̩.
Igbesi-aye Dafidi kò ti fi igbà gbogbo ri bẹẹ. Ni igbà ọdọ rè̩, gẹgẹ bi oluṣọ-agutan, o ti bá awọn ẹranko buburu jà lati daabo bo agbo ẹran rè̩. Nigba ti o dagba diẹ sii, Saulu ti gbiyanju lati gba ẹmi Dafidi. O di ọranyan fun Dafidi lati maa wà ni iṣọra nigba gbogbo. Nigba miiran a fi ara pamọ laaarin apata ati ihò, kuro lọdọ awọn eniyan rè̩, á si bá ọpọlọpọ ogun pade. Oluwa pa Dafidi mọ, O gbe e ga lati di ọba, O si fun un ni alaafia ati isimi. Dafidi ki ba ti le di ọba bi kò ṣe pe Oluwa ti ran an lọwọ. Dafidi fi ogo fun Ọlọrun fun aṣeyọri ti o ni ati ipò ọlá ti o wà. Dafidi wi pe, “Iwọ li o gbé mi leke, ti iwọ kò si jẹ ki awọn ọta mi ki o yọ mi.”
Ohun Kan fun Oluwa
Ẹmi ọpẹ si Ọlọrun wà ninu ọkàn Dafidi. Lati fi imoore rè̩ hàn, Dafidi fẹ ṣe ohun kan fun Ọlọrun. Dafidi rò nipa ile ti o kún fun irọra ati igbadùn ninu eyi ti oun n gbé. Gẹgẹ bi ero rè̩, ile ti rè̩ tilẹ lẹwa o si tu ni lara ju ile ijọsin Ọlọrun lọ -- agọ kan ti a gbe Apoti Ẹri Majẹmu sinu rè̩. Bi o ti wà ninu ọkàn Dafidi gidigidi lati ri ohun kan ṣe fun Oluwa, o pinnu lati kọ ile kan fun ogo orukọ Oluwa.
Bi a ti n ṣiro ohun ti Ọlọrun ti ṣe fun wa, ọkàn wa kò ha fẹ bi ti Dafidi lati wá ohun kan ṣe fun Oluwa? A ha n da ọrọ Onisaamu rò pe: “Kili emi o san fun OLUWA nitori gbogbo ore rè̩ si mi? Emi o mu ago igbala, . . . . emi o san ileri ifẹ mi fun OLUWA. . . . emi o ru ẹbọ ọpẹ si ọ, emi o ma ke pè orukọ OLUWA” (Orin Dafidi 116:12-18). Ki ni ọmọde le ṣe fun Oluwa? Ọmọde le ri igbala, ki o si wà fun Ọlọrun. Nipa fifi aye rè̩ rubọ, ọmọde le fi ogo fun Ọlọrun. Ọmọde le yin Ọlọrun logo ki o si dupẹ. Ọmọde le gbadura. Ẹ jẹ ki a fi ifẹ ọkàn wa siwaju Ọlọrun pẹlu adura. Oun yoo fi ohun ti a le ṣe fun Un siwaju sii hàn wa. Oun le fun wa ju ohun ti a tilẹ beere tabi ti a nireti, gẹgẹ bi O ti ṣe fun Dafidi.
Natani, Wolii
Dafidi sọ fun Natani, ẹni ti o jé̩ Wolii ni akoko naa. Dafidi rò pe ile oun ti a fi igi kọ dara ju agọ nì ninu eyi ti Apoti-ẹri Ọlọrun gbe wà ti a si fi aṣọ yi ká. A fi ye ni pe ile Dafidi jẹ eyi ti o dara pupọ fun aye igba naa, nitori kiki igi ti o dabi ẹni pe o ṣọwọn ti o si niyelori ni wọn fi kọ ọ. S̩ugbọn agọ ti o yi Apoti-ẹri Oluwa naa ká jé̩ ibi ipamọ fun igba diẹ.
Natani woye pe ifẹ Dafidi lati ṣe ohun kan fun Oluwa jẹ ero mimọ ti o si logo. Ni gbogbo ọna, kò si ohun ti o dabi ẹni pe o buru ninu rè̩. Ninu itara ati igbona ọkàn wọn, wọn kuna lati beere ifẹ Ọlọrun nipa ọran ti o ṣe pataki to bayii. Kiakia ni Natani fi inu didun rè̩ ati atilẹyin rè̩ hàn. O ni ki Dafidi ṣe ohunkohun ti o wà ni ọkàn rè̩.
Eto Ọlọrun
Ọlọrun mọ ọkàn Dafidi pe fun ogo Oluwa ati lati inu ọkàn gbigbooro ni o ti ni ipinnu yii. Ọlọrun kò binu bẹẹ ni Oun kò si bá Dafidi wi bi o tilẹ jẹ pe ki i ṣe ifẹ Ọlọrun pe ki a kọ ile fun Ọlọrun ni akoko yii. Ọlọrun kò jẹ ki Dafidi pé̩ ninu aṣiṣe. Nipasẹ Natani kan naa ti o ti ki i laya ni Ọlọrun ranṣẹ si Dafidi.
Ọlọrun kò rán ẹlomiran, bẹẹ ni Oun kò si sọ fun Dafidi, ki ede-aiyede má ba si. Letoleto ni iṣẹ Ọlọrun. Ọlọrun ki i sọ ohun kan fun ẹni kan ki O si sọ ohun ti o yatọ fun ẹlomiran nipa ifẹ Rè̩.
Iṣẹ ti Ọlọrun rán si Dafidi rán an leti pe Ọlọrun “ko iti gbe inu ile kan” ṣugbọn O “nrin ninu agọ, ati ninu agberin.” Ọlọrun kò beere ile kankan lọwọ awọn Ọmọ Israẹli; Oun kò ni i fi ṣe. Ohun ti Ọlọrun maa n wò ni eniyan onirẹlẹ ti o ni è̩rù Ọlọrun ninu ọkàn rè̩ (Isaiah 66:2).
Ẹmi Ijọsin Tootọ
Ọlọrun tobi pupọ to bẹẹ ti kò fi le si ile kankan ti o le tobi tó lati gbà gbogbo Ẹmi Rè̩. Aye ni apoti itisè̩ Ọlọrun, Ọrun si ni itẹ Rè̩ (Isaiah 66:1). Gbogbo awọn ọrun kò tilẹ le gba Ọga-ogo Ọlọrun Israẹli (2 Kronika 2:6). “Emi kò ha kún ọrun on aiye, li OLUWA wì?” (Jeremiah 23:24). Ohun ti o wà lọkàn Dafidi ni lati kọ ibi kan ti o dara ju bẹẹ lọ ninu eyi ti awọn eniyan Ọlọrun le maa jọsin. Dafidi kò reti pe a le fi ogiri yí Ọlọrun ka ki a si se E mọ ni ọna ti eniyan fi n gbe inu ile. Dafidi mọ pe kò si ile naa, bi o ti wù ki a ṣe ọnà si i to tabi ki o ná ni lowo to, ti o le lẹwa pupọ jù fun ọlánlá Ọlọrun.
Lode oni, inu Onigbagbọ maa n dùn lati ri ile Ọlọrun ni ipo ọwọ, pẹlu gbogbo nnkan ni eto ati ni mimọ tonitoni. Onigbagbọ ki i ro pe ohun-elo ti o dara ju tilẹ dara to fun iṣẹ Ọlọrun. Awọn nnkan wọnyii maa n wulo sii ninu iṣẹ itankalẹ Ihinrere, wọn si maa n fi han awọn ẹlomiran iru ifẹ ati ọwọ ti awọn eniyan Ọlọrun ní ninu ọkàn wọn.
Ki i ṣe Dafidi ni o paṣẹ fun awọn Ọmọ Israẹli lati maa rubọ ni ibi kan ti a yàn. Ọlọrun ni o pa aṣẹ bẹẹ. Agọ ti Ọlọrun sọ pe ki awọn Ọmọ Israẹli kọ jẹ eyi ti wọn lè gbé rìn. Wọn gbe e bi wọn ti n rin kiri ninu aginju. Ọlọrun ti fun wọn ni ilẹ Kenaani, nibi ti wọn le maa gbe titi. Gẹgẹ bi wọn si ti kọ ile ti a kò le ṣi kiri bẹẹ ni Dafidi si n fẹ pe ki ṣọọṣi kan ti a kò ni maa gbe kiri wà nibi ti wọn le maa ṣe irubọ ki wọn si maa sun ọrẹ-ẹbọ si Ọlọrun, ibi ti wọn le maa pejọ pọ lati sin Oluwa.
O jé̩ didun inu Ọlọrun pe ki awa ti ode-oni maa jọsin ni ipejọpọ. A rán wa leti pe ki a má ṣe kọ “ipejọpọ ara wa silẹ” (Heberu 10:25) S̩ugbọn lilọ si ile-isin jé̩ apa kan ninu iṣẹ-isin wa si Ọlọrun. Ọna ti a fi n jọsin tun ṣe pataki pẹlu. Jesu sọ fun obinrin ara Samaria pe awọn ọmọ-ẹyin Oluwa tootọ a maa sin In ni ẹmi ati ni otitọ “Ẹmí li Ọlọrun: awọn ẹniti nsìn i ko le ṣe alaisìn i li ẹmi ati li otitọ” (Johannu 4:24). Gẹgẹ bi Dafidi ti fẹ kọ ile fun Ọlọrun fun idi kan ṣoṣo, nitori “kiki ati sun ẹbọ niwaju rè̩” (2 Kronika 2:6), bẹẹ gan an ni awa naa gbọdọ sin Ọlọrun lati inu ọkàn wá, pẹlu otitọ inu ati adura – ki i ṣe pe ki a sin In nipa ile ti a ṣe lọṣọ tabi nipa iṣẹ ode ara.
Iṣẹ Dafidi
Ọlọrun ti gbé Dafidi ga lati ṣe akoso lori awọn eniyan Rè̩. Iṣẹ miiran wà fun Dafidi lati ṣe dipo kikọ ile fun orukọ Oluwa. Gẹgẹ bi Onisaamu, Dafidi kọ ọpọlọpọ Ọrọ Ọlọrun ati orin fun imulọkanle awọn Ọmọ Israẹli ati awọn eniyan Ọlọrun lati ọdun wọnyii wá, ati fun anfaani wa. Dafidi jé̩ ologun. O ni ọpọlọpọ ogun ti o ṣé̩ lati fẹ aala ilẹ wọn. Ninu ogun wọnyii, Dafidi ti mu ki a ta ẹjẹ silẹ lọpọlọpọ. Nitori Dafidi ti ta ẹjẹ pupọ silẹ niwaju Ọlọrun a kọ fun un lati kọ ile naa gẹgẹ bi o ti n fẹ (1 Kronika 22:8). S̩ugbọn Ọlọrun sọ fun Dafidi pe, “Bi o tijẹpe o wà li ọkàn rẹ lati kọ ile kan fun orukọ mi, iwọ ṣe rere ti o fi wà li ọkàn rẹ” (1 Awọn Ọba 8:18).
A fun Dafidi ni anfaani lati ya aworan ile Ọlọrun. Dafidi fi i fun Sọlomọni ọmọ rè̩ gẹgẹ bi apẹẹrẹ ti Ẹmi Ọlọrun ti mí si Dafidi lati yà (1 Kronika 28:11, 12). Dafidi tun kó ọpọlọpọ ohun-elo jọ, o si fi silẹ ninu ohun-ini oun tikara rè̩, fun lilo lati kọ ile Ọlọrun. Pẹlu awọn aworan ile ati ohun-elo kikọ ile naa, Dafidi gba Sọlomọni ni imọran yii “Ati iwọ, Sọlomọni ọmọ mi, mọ Ọlọrun baba rẹ, ki o si fi aiya pipé ati fifẹ ọkàn sìn i” (1 Kronika 28:9).
Ileri Ọlọrun
Ọlọrun ṣe ileri pe ọmọ Dafidi ni yoo kọ ile ti Dafidi ti fẹ kọ. Ọlọrun yoo san è̩san rere fun ipinnu ti o ti wà lọkàn Dafidi. Gẹgẹ bi baba, Ọlọrun yoo bá ọmọ Dafidi wí Oun yoo si tọ ọ sọna bi o ba dẹṣẹ, ṣugbọn Ọlọrun kò ni kọ ọ lọmọ. Niwọn igbà ti ọmọ Dafidi ba n gbọ ti Ọlọrun, aanu Ọlọrun kò ni fi i silẹ.
Siwaju sii, Oluwa yoo kọ ile kan fun Dafidi, yoo si fi idi ijọba Dafidi mulẹ titi lae. Ninu idile Dafidi a kò ni fẹ ẹni kan kù lori ité̩ awọn eniyan Ọlọrun. Oju rere yii pọ ju eyi ti a fi hàn fun ẹnikẹni ninu awọn ti o ti ṣe alakoso awọn Ọmọ Israẹli ri, o tilẹ ju eyi ti Mose, Joṣua tabi eyikeyi ninu awọn onidajọ ri gbà lọ.
Saulu ni ọba kin-in-ni fun awọn Ọmọ Israẹli. Saulu ti yipada kuro lẹyin Ọlọrun. O ti ṣaigbọran, a si gbà ijọba kuro lọwọ rè̩ ati kuro lọwọ awọn ọmọ rè̩. Lẹyin ikú Saulu, Dafidi jọba dipo ọkan ninu awọn ọmọ Saulu. Ọlọrun ni o ti pinnu rè̩ bẹẹ; a si fun Dafidi ni ileri pe idile rè̩ yoo ni ẹtọ ti o daju si ité̩ naa.
Ijọba Ainipẹkun
Ninu iṣẹ ti Ọlọrun rán si Dafidi ni ileri ijọba ainipẹkun kan wà -- eyi ti yoo wà laelae. Diẹ ninu ileri yii sọ nipa Sọlomọni ti yoo jọba ni akoko rè̩ lẹyin Dafidi baba rè̩. S̩ugbọn ni ọna ti o ju bẹẹ lọ, ileri yii sọ nipa Messia ti O n bọ wa, Jesu Kristi, lati idile Dafidi, Ẹni ti “yio gbà awọn enia rè̩ là kuro ninu è̩ṣẹ wọn” (Matteu 1:21), ijọba Ẹni ti ki yoo nipẹkun, (Isaiah 9:7), Ijọba ẹni ti a ki yoo si le parun (Daniẹli 7:14). S̩iwaju ibi Jesu, angẹli nì sọ fun iya Rè̩ pe Oluwa Ọlọrun yoo fun ọmọ rè̩ ni “ité̩ Dafidi baba rè̩.” “Yio si jọba ni ile Jakọbu titi aiye; ijọba rè̩ ki yio si ni ipẹkun” (Luku 1:32, 33). Johannu Apọsteli ni a fun ni iran nipa igbà ti n bọ ni erekuṣu Patmo. O ri angẹli kan, o si gbọ ikede bayii pe: “Ijọba aiye di ti Oluwa wa, ati ti Kristi rè̩; on o si jọba lai ati lailai” (Ifihan 11:15)
Adura Dafidi
Natani, Wolii jiṣẹ ti Oluwa rán si Dafidi pe Ọlọrun kò fun un ni anfaani ati kọ ile kan fun orukọ Oluwa. Dafidi tẹriba fun Ọrọ Ọlọrun lai jiyan. Dafidi kò gbó Natani lẹnu bẹẹ ni kò si ba Ọlọrun wijọ. Kò banujẹ pe a kò gba oun laaye. Kò tẹsiwaju lati mu ipinnu rè̩ ṣẹ. Dafidi gbọran si Ọlọrun. Tirẹlẹ-tirẹlẹ ati tọwọtọwọ ni Dafidi tọ Oluwa lọ ninu adura.
Adura ọpẹ ni Dafidi fi fesi si Ọrọ Ọlọrun. Dafidi fi ogo fun Ọlọrun, o si sọrọ irẹlẹ nipa ara rè̩ ati ipo rè̩. Dafidi wi pe, “Tali emi. . . ti iwọ fi mu mi di isisiyi?” Dafidi jé̩ eniyan ọlọlá; o ṣe aṣeyọri, o si wulo fun Ọlọrun. S̩ugbọn o rè̩ ara rè̩ silẹ fun Oluwa, nitori Dafidi mọ pe kò le ṣe e ṣe fun oun lati ṣe aṣeyọri to bẹẹ lai si Ọlọrun. Dafidi wi pe, “Ki si ni idile mi?” “Iwọ si sọ ti idile iranṣẹ rẹ pẹlu ni ti akoko ti o jina” Ki ni ile Dafidi? Idile ọba ti Ọlọrun yàn. Dafidi woye pe Ọlọrun ti yé̩ oun sí nipa ibukun atẹyinwa ati pẹlu ninu ohun ti Ọlọrun ti ṣeleri lati ṣe ni ọjọ iwaju. Ọlọrun tilẹ fun Dafidi ju ohun ti o n beere ati ohun ti o n reti.
Dafidi gbà lati jẹ ki Ọlọrun fi idi ile oun mulẹ titi lae. Awọn miiran wà ti wọn kò fẹ jẹ ohun ti Ọlọrun fẹ ki wọn jẹ. Awọn miiran wa ti wọn fẹ ṣe bi wọn ti fẹ, yala Ọlọrun fé̩ bẹẹ tabi kò fẹ. S̩ugbọn ohun ti o leke lọkàn Dafidi ni fun ogo Ọlọrun ati ki orukọ Ọlọrun le di ayinlogo.
Dafidi gba Ọlọrun gbọ. Kò si igbà kan ti Dafidi ṣiyemeji ileri yii. Igbagbọ ati ireti rè̩ duro lori ileri Ọlọrun. Awọn ileri Oluwa fun Dafidi kò yè̩. Kò si ọkan ninu ileri Ọlọrun ti o kuna ri.
Questions
AWỌN IBEERE- S̩e apejuwe ile Dafidi.
- Ki ni ṣe ti Dafidi fẹ kọ ile kan fun Oluwa?
- Iṣẹ wo ni Ọlọrun rán si Dafidi?
- Ta ni jiṣẹ Ọlọrun fun Dafidi?
- Ki ni ṣe ti a du Dafidi ni anfaani ati kọ ile fun Oluwa?
- Ta ni wá kọ ile naa fun Oluwa?
- Bawo ni Dafidi ṣe ni ipin ninu ipese silẹ fun ile naa?
- Ileri wo ni Ọlọrun ṣe fun Dafidi?
- Ijọba ti ta ni a sọ asọtẹlẹ rè̩ ni akoko yii?
- Ki ni idahun Dafidi si iṣẹ ti Ọlọrun rán?