Lesson 231 - Junior
Memory Verse
AKỌSORI: “Bi iṣẹ ẹnikẹni ti o ti ṣe lori rè̩ ba duro, on ó gbà ère” (1 Kọrinti 3:14).Notes
Ọmọ-Ọba Kekere Arọ
Ninu ẹkọ wa oni a o kọ nipa ọmọ-ọba kekere kan ti o jé̩ arọ, ti a bí ninu aafin ni ilẹ Israẹli ni ọpọlọpọ ọdun sẹyin. Mefiboṣeti ni orukọ rè̩.
Nigba ti Mefiboṣeti jé̩ ọmọ ọdun marun un, ogun wà ni Israẹli, ninu ọkan ninu awọn ogun ti o gbona gidigidi naa ni a pa baba rè̩ ati baba rè̩ agba. Ẹru ba olutọju Mefiboṣeti nigba ti o rii ti awọn ọmọ-ogun Israẹli sá niwaju awọn Filistini, o ro o pe awọn ọta wọnyii le wá kó aafin ki wọn si mu ọmọ-ọba kekere yii lẹru. O fẹran ọmọdekunrin yii, nitori naa o gbe e o si bẹrẹ si sá lọ lati fara pamọ; ṣugbọn ninu ibẹru ati iyara rè̩, o jabọ lọwọ rè̩. S̩iṣubu ti Mefiboṣeti ṣubu yii pa a lara to bẹẹ ti o fi yarọ ni gbogbo ọjọ aye rè̩.
Ni gbogbo akoko ti Mefiboṣeti fi n dagba, kò gbe aafin, wọn kò si mu un lẹru. A ti pa awọn arakunrin baba rè̩ loju ogun, nitori naa oun nikan ni o n dá gbé lọna jijin si ile.
Iran Saulu
Baba ọmọ-ọba arọ yii ni Jonatani, baba rè̩ agba si ni Saulu Ọba, ọba Israẹli kin-in-ni. Nigba ti Jonatani ṣi wà ni ọmọde, baba rè̩ ti pe Dafidi wá lati maa fi harpu kọrin ni aafin, fun ọdun ti o niye ni Dafidi fi gbe ni aafin ọba. Jonatani ati Dafidi a maa ṣire pọ wọn si di ọrẹ timọtimọ. Jonatani tilẹ fẹran Dafidi to bẹẹ ti o fi fẹ lati fi ipò ọba silẹ fun ọrẹ rè̩. Nigba ti Saulu ọba gbọ eyi inu bi i gidigidi o si n fẹ pa Dafidi. Jonatani gbọ nipa ete buburu ti baba rè̩ ni, o si kilọ fun Dafidi pe ki o sá kuro ni aafin ọba.
Ọlọrun ti wi pe Dafidi ni yoo jọba lẹyin Saulu nitori Saulu kò jé̩ olóòótọ si Ọlọrun kò si gbọran si aṣẹ Rè̩ ninu ohun gbogbo. S̩ugbọn Dafidi mọ pe akoko Ọlọrun kò i ti to fun oun lati jọba, nitori naa kò dojuja kọ Saulu, ṣugbọn o sá kuro niwaju ọba ti o kún fun ibinu yii.
Majẹmu Dafidi ati Jonatani
Lọjọ naa ti Dafidi ati Jonatani ki ara wọn pe o digbooṣe wọn ro pe wọn kò tun ni ri ara wọn mọ. Wọn dá majẹmu niwaju Ọlọrun pe ẹni kin-in-ni yoo maa fẹran ẹnikeji titi ati pe olukuluku wọn yoo maa ṣe rere si ẹbi ekeji rè̩ ni igbà ti n bọ.
Ọpọlọpọ ọdun lẹyin eyi ni Dafidi fi n sá kiri fun awọn ọmọ-ogun Saulu ninu aginju. Dafidi naa kó awọn ọmọ-ogun rè̩ jọ, lati igbà de igba ni awọn ọmọ-ogun wọn si n kọlura, ṣugbọn inurere ṣá ni Dafidi maa fi n hàn fun Saulu.
Ifẹ si awọn Ọta
Jesu kọ ni pe: “Ẹ fẹ awọn ọtá nyin, ẹ sure fun awọn ẹniti o n fi nyin ré, ẹ ṣõre fun awọn ti o korira nyin, ki ẹ si gbadura fun awọn ti nfi arankàn ba nyin lò, ti nwọn nṣe inunibini si nyin” (Matteu 5:44). Dafidi ni ifẹ Ọlọrun ninu ọkàn rè̩, ni akoko ti rè̩ o si ṣe ohun naa gan an ti Jesu wi lẹyin naa pe Onigbagbọ ni lati ṣe. Saulu ti gbiyanju lati pa a, ibinu rè̩ si ru soke gidigidi nigba ti Ọlọrun sọ pe Dafidi yoo jọba. Sibẹ, Dafidi kò korira Saulu, o si ṣọra ki o ma ba pa a lara ni akoko ija naa.
Bi owú ba wà ninu ọkàn Jonatani, ọta ni oun naa i ba ka Dafidi sí, nitori a yàn án lati jọba Israẹli ni ipò Jonatani. S̩ugbọn o ni ifẹ Ọlọrun ninu ọkàn rè̩, o si fẹran Dafidi dipo ti i ba fi gba a ni ọta.
Majẹmu ti A Ranti
Lẹyin ikú Saulu, ati Jonatani ati awọn arakunrin rè̩, a kò tún gburo ohunkohun mọ nipa idile ọba yii. S̩ugbọn nigba ti Israẹli simi ti wọn si n gbe ni alaafia, Dafidi ranti majẹmu rè̩ pẹlu Jonatani, o si bẹrẹ si i rò o bi ẹnikẹni ba kù silẹ ninu awọn ẹbi rè̩. Alagbà kan wà ti o n gbe ni aafin, ẹni ti o ti n ṣe iranṣẹ fun Saulu ri, o si mọ ibi ti Mefiboṣeti wà ni ifarapamọ fun ọpọlọpọ ọdun. Dafidi sọ pe ki a mu ọmọ-ọba arọ yii tọ oun wá.
Mefiboṣeti de pẹlu ibẹru, o si ba búrúbúrú niwaju ọba. Kò mọ bi a o tẹwọgba oun gẹgẹ bi ọrẹ tabi gẹgẹ bi ẹrú. Dafidi wi pe: “Máṣe bè̩ru: nitoripe nitotọ emi o ṣe ore fun ọ nitori Jonatani baba rẹ, emi o si tun fi gbogbo ilẹ Saulu baba rẹ fun ọ: iwọ o si ma ba mi jẹun nigbagbogbo ni ibi onjẹ mi” (2 Samuẹli 9:7). Bawo ni yoo ti jé̩ iyalẹnu fun Mefiboṣeti to! O wá ninu è̩rù, ṣugbọn nisisiyii a tẹwọgba a gẹgẹ bi ọmọ. Ki i ṣe kiki pe yoo maa gbe ninu aafin ọba ki o si maa jẹun lori tabili ọba nikan, ṣugbọn gbogbo ilẹ ti o ti jé̩ ti baba rè̩ ati ti baba rè̩ agba yoo jé̩ ti rè̩.
Mefiboṣeti jé̩ arọ kò si le tọju ilẹ rè̩ tikara rè̩; ṣugbọn iranṣẹ wọn atijọ Siba, ni ọpọlọpọ ọmọkunrin ati iranṣẹ awọn ti yoo fi tifẹtifẹ ṣe iṣẹ fun ọmọ-ọmọ ọga wọn atijọ, wọn si n ṣe abojuto gbogbo oko Mefiboṣeti.
A San Ẹsan fun Inurere
Bayi ni a san ẹsan inurere ti Jonatani fi hàn fun Dafidi pada. Dafidi kò ka Mefiboṣeti si ẹrú, tabi ki o gba ilẹ naa ti o ti ni nipa iṣẹgun fun ara rè̩ ni ẹtọ gẹgẹ bi ikogun. O huwa si Mefiboṣeti gẹgẹ bi o ti fẹ ki a ṣe si ọmọ oun tikara rè̩.
Inurere Dafidi si Mefiboṣeti ni lati mu ki gbogbo ibẹru ati ikorira ti Mefiboṣeti le ni si ọba ti o gba ijọba lọwọ ẹbi rè̩ kuro ninu ọkàn rè̩. O wà ninu aafin ọba, o si n gbadun alaafia ati ọrọ.
Igbà kan de ti Siba iranṣẹ agba nì ditẹ lati gba ini Mefiboṣeti. Dafidi ti lọ si ogun, nigba ti o si de ti o gbọ pe a ti fi ẹtàn mu ki oun fi ogun Mefiboṣeti fun iranṣẹ rè̩, o ni wọn ni lati pin in si meji laaarin ara wọn. S̩ugbọn ọkàn Mefiboṣeti kún fun imoore si Dafidi fun dida ti o dá ẹmi rè̩ si ti o si tun fun un ni ile (“Nitoripe gbogbo ile baba mi bi okú enia ni nwọn sa ri niwaju oluwa mi ọba: iwọ si fi ipò fun iranṣẹ rẹ larin awọn ti o njẹun ni ibi onjẹ rẹ”) to bẹẹ ti kò fi bikita lati ni ipinlẹ oko nla (2 Samuẹli 19:28). Pe Dafidi pada ni alaafia lati oju ogun tó lati mu ki ọgbẹni arọ yii kún fun ayọ. O tẹ ẹ lọrun lati lo iyoku ọjọ aye rè̩ niwaju Dafidi, eniyan Ọlọrun, lai beere ọlá kan fun ara rè̩.
Questions
AWỌN IBEERE- Ki ni orukọ ọmọ-ọba kekere arọ naa?
- Ta ni baba rè̩?
- Nigba wo ni a kọ è̩kọ nipa baba rè̩?
- Ki ni majẹmu ti Dafidi ati Jonatani dá?
- Ki ni ṣe ti Dafidi kò duro ni aafin Saulu ọba?
- Ki ni ṣẹlẹ si Saulu ati Jonatani?
- Ki ni ṣe ti Dafidi fi ronu nipa ẹbi Saulu?
- Ta ni ẹni kan ṣoṣo ninu awọn ọmọkunrin Saulu ti o kù?
- Ki ni opin itan naa?