Orin Dafidi 51:1-19

Lesson 232 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Da aiya titun sinu mi, Ọlọrun; ki o si tún ọkàn diduro-ṣinṣin ṣe sinu mi” (Orin Dafidi 51:10).
Notes

Ijọba Rere Dafidi

Nigba ti a fi ororo yan alakoso Israẹli ti o ga ju lọ, ti i ṣe Dafidi ni ọba awọn ẹni ayanfẹ Ọlọrun, Wolii Samuẹli sọ nipa rè̩ pe o jẹ ẹni bi ti inu Ọlọrun. Lati igba ọmọde ni Dafidi ti fi ayé rè̩ fun Ọlọrun, o si ti fi otitọ ọkàn sin Ọlọrun lati igba naa wá.

Nipa kika ọpọlọpọ Orin ti Dafidi kọ, a rii pe o jẹ ẹni ti n gbadura. Nigbakuugba ti o ba bọ sinu wahala o maa n ke pe Ọlọrun fun iranwọ. Nigba ti o ba kó awọn ọmọ-ogun Israẹli lọ si oju ija, o maa n beere itọni Ọlọrun. Orin Dafidi ẹkẹtalelogun jẹ eyi ti o kọ lati dupẹ lọwọ Ọlọrun fun oore ati aanu Rè̩ ti o ti n tọ ọ lẹyin ni ọjọ aye rè̩ gbogbo.

Dafidi kọ Ofin Ọlọrun o si fi i ṣe odiwọn igbesi-aye rè̩ pẹlu. O fẹ lati mọ ifẹ Ọlọrun ati lati ṣe e. O wi pe, “Inu mi dùn lati ṣe ifẹ rẹ, Ọlọrun mi, nitõtọ, ofin rẹ mbẹ li aiya mi” (Orin Dafidi 40:8).

Ifasẹyin Dafidi

Akoko kan de ni akoko ijọba Dafidi nigba ti o jẹ pe, dajudaju, jija ogun ati nini iṣẹgun gbà a lọkàn to bẹẹ ti kò fi naani ijọsin rè̩ fun Ọlọrun. Kò kà Ofin Ọlọrun ki o si gbadura to bi o ti yẹ; abayọrisi rè̩ ni pe o fà sẹyin o si dá è̩ṣẹ ti o buru jai.

Ọlọrun jé̩ olóòótọ si Dafidi gẹgẹ bi Oun i ti maa jé̩ olóòótọ si olukuluku afasẹyin. Ọlọrun rán Wolii kan lati sọ fun Dafidi pe o ti dẹṣẹ o si ti sọ ibarẹ Ọlọrun nù. Ọlọrun kò wo ijolootọ Dafidi atẹyinwá ki O si gboju fo è̩ṣẹ Dafidi. Ninu ipò è̩ṣẹ bayii Ọlọrun kò ni mu Dafidi lọ si Ọrun. Kò si bi eniyan ti ṣe le jẹ Onigbagbọ tó, bi o ba dẹṣẹ o di afasẹyin, o si ti kú kuro ninu ẹbi Ọlọrun. Bi o ba fẹ pada sọdọ Ọlọrun o ni lati kọkọ gbà pe oun jẹ ẹlẹṣẹ, ki o si kaanu fun iwà ti o ti hù.

Nigba ti Wolii Natani fi òye è̩ṣẹ Dafidi ye e, ti o si wi pe “Iwọ li ọkọnrin na” (2 Samuẹli 12:7), ọkàn Dafidi bajẹ gidigidi o si gbadura si Ọlọrun fun idariji. Ọba Israẹli rẹ ara rè̩ silẹ o si jẹwọ pe oun ti dẹṣẹ. O sọkun kikoro si Ọlọrun pe, “Iwọ, iwọ nikanṣoṣo ni mo ṣè̩ si, ti mo ṣe buburu yi niwaju rẹ.” O fẹ ki a dariji oun ki oun ba le gbadun irẹpọ pẹlu Ọlọrun ti oun ti ni rí. È̩ṣẹ ti yà a nipa kuro lọdọ Ọlọrun, oun kò si tun jẹ ọmọ Baba Ọrun mọ nisisiyii.

Irora Aya

Dafidi mọ pe “OLUWA mbẹ leti ọdọ awọn ti iṣe onirobinujẹ ọkàn; o si gbà iru awọn ti iṣe onirora ọkàn là.” O wa gbadura bayii, “Irobinujẹ ati irora aiya, Ọlọrun, on ni iwọ ki yio gàn.” Ọlọrun gbọ ẹbẹ ironupiwada rè̩, O si dariji í patapata.

Ronu ohun ti i ba ṣẹlẹ si Dafidi otoṣi ni ẹmi bi o ba ṣe pe o gbiyanju lati ṣe awawi fun è̩ṣẹ rè̩, ti o si ba Wolii naa jiyàn pe ohun ti oun ṣe kò buru to bẹẹ. Ki ni opin rè̩ i ba ti ri bi o ba jẹ pe oun, bi agberaga ọba, ba ti kọ lati gbọ ọrọ Ọlọrun lati ẹnu Natani? Ọlọrun i ba da a lẹbi sinu iya ainipẹkun. S̩ugbọn adura ironupiwada Dafidi ati irobinujẹ fun è̩ṣẹ rè̩ de eti Ọlọrun o si mú idariji wá.

Gbongbo È̩ṣẹ

Inu Dafidi dùn pe Ọlọrun ti dari irekọja rè̩ jì, iwa-buburu ti o ti hù, ṣugbọn o woye pe oun n fẹ ni ifẹ Ọlọrun sii ninu ọkàn oun. Gbongbo è̩ṣẹ, iwa abinibi, ṣi wà ninu ọkàn rè̩ sibẹ.

Nigba ti Adamu ṣè̩ ninu Ọgbà Edẹni, o mu idalẹbi lati ọdọ Ọlọrun wá sori gbogbo eniyan. Ẹda ẹṣẹ ti Adamu gbe wọ nigba ti o ṣaigbọran si Ọlọrun bọ sori awọn ọmọ rè̩ pẹlu, ati ọmọ-ọmọ titi fi di iran isisiyii. Iwa ọmọde ni lati maa ṣe ibi bẹrẹ lati igba ti a ti bi i. Ọlọrun ki i ka è̩ṣẹ si i lọrun niwọn igbà ti oun kò mọ ju bẹẹ lọ; bi ọmọde ba si kú ki o to mọ iyatọ laaarin rere ati buburu, Jesu yoo mu un lọ si Ọrun bi o tilẹ jẹ pe kò i ti gbadura fun idariji. S̩ugbọn nigba ti eniyan ba dagba sii bi o ba si ni òye pe oun maa n ṣe ohun ti kò yẹ ki oun ṣe, o ni lati gbadura pe ki Jesu dariji oun bi o ba fẹ lọ si Ọrun. Nigba ti a ba bẹ Jesu lati dari è̩ṣẹ wa ji wa, O maa n gbà wa là a si maa n di atunbi. A maa n wẹ è̩ṣẹ wa nu. Ọlọrun maa n dariji wa O si maa n gbagbe è̩ṣẹ wa. S̩ugbọn kiki awọn nnkan ti o lodi ti a si ti ṣe ni o maa n di igbagbe ti a si maa n dari rè̩ ji ni.

Iwa abinibi eyi ti o mu ki eniyan dẹṣẹ wa nibẹ sibẹ. Niwọn igba ti o ba n gbadura ti o si n bẹ Ọlọrun pe ki O pa oun mọ kuro ninu è̩ṣẹ, iwa abinibi naa kò le mu ki oluwarè̩ tun ṣè̩. S̩ugbọn o wà nibẹ o si n wa ọna ati mu un dẹṣẹ.

Aya Titun

Dafidi mọ pe lẹyin ti a ti dari è̩ṣẹ oun jì iwa abinibi wà ninu ọkàn oun sibẹ, o si fẹ ki Ọlọrun mu eyi naa kuro. O tun gbadura, o si beere lọwọ Ọlọrun pe, “Da aiya titun sinu mi.” O mọ pe bi o ti wù ki oun ṣe rere to ni ode ara, Ọlọrun le ri ododo ọkàn oun ki o si ri pe kò mọ tán patapata. Awọn ẹran ti a pa rubọ, ati awọn eto ijọsin, kò to lati sọ ọkàn rè̩ di funfun. S̩ugbọn Dafidi fẹ ki Ọlọrun wẹ ọkàn oun ni àwè̩mọ ki o ba le maa wu oun nigba gbogbo lati ṣe ohun gbogbo ti Ọlọrun n fẹ ki oun ṣe. Dafidi fẹ ki iwa oun jẹ eyi ti yoo maa ṣe deede pẹlu ohun gbogbo ti Ọlọrun ba wi. Iwẹnumọ ọkàn yii ni a n pe ni isọdimimọ patapata, tabi iwa-mimọ; nipa Ẹjẹ Jesu ni a si maa n ri i gba. “Nitorina Jesu pẹlu, ki o le fi è̩jẹ ara rè̩ sọ awọn enia di mimọ, o jiya lẹhin bode” (Heberu 13:12).

Dafidi nikan kọ ni o n fẹ ọkàn funfun. Anfaani yii wà fun olukuluku Onigbagbọ lonii, ọranyan si ni, nitori Bibeli sọ fun ni pe, “Ẹ mā lepa alafia pẹlu enia gbogbo, ati ìwa mimọ, li aisi eyini kò si ẹniti yio ri Oluwa” (Heberu 12:14).

Ọkan pẹlu Ọlọrun

Jesu gbadura bayii fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩: “Sọ wọn di mimọ ninu otitọ: otitọ li ọrọ rẹ. . . . . ki gbogbo nwọn ki o le jẹ ọkan; gẹgẹ bi iwọ, Baba, ti jẹ ninu mi, ati emi ninu rẹ, ki awọn pẹlu ki o le jẹ ọkan ninu wa. . . . ki a le ṣe wọn pé li ọkan” (Johannu 17:17-23).

A ti pe iriri isọdimimọ ni Pipé Onigbagbọ pẹlu. Laaarin ọdun 1700 ati ọdun 1800 lẹyin ti a bi Jesu, Ọlọrun gbe Oniwaasu nla kan dide lati kede otitọ nla nlà yii. Orukọ rẹ ni John Wesley. Eniyan pupọ ni o ti lodi si i, ti wọn si wi pe kò ṣe e ṣe fun eniyan lati gbe igbesi-aye ti John Wesley waasu, bi o tilẹ jẹ pe taara lati inu Ọrọ Ọlọrun ni o ti mu un jade. Jesu wi pe “Nitorina ki ẹnyin ki o pé, bi Baba nyin ti mbẹ li ọrun ti pe” (Matteu 5:48). Ẹni ti o kọ iwe si awọn Heberu gbadura pe ki a le mu wọn “pé ninu iṣẹ rere gbogbo lati ṣe ifẹ rè̩” (Heberu 13:21). Ọlọrun kò ni beere pe ki a ṣe ohun ti a kò le ṣe.

P

ipe Onigbagbọ

Ki ni a n pe ni “Pipé Onigbagbọ?” John Wesley gbiyanju lati ṣe alaye pe ohun ti o n jé̩ bẹẹ ni “igbala kuro ninu è̩ṣẹ gbogbo, ati fifi gbogbo ọkàn fẹran Ọlọrun lati le maa yọ titi lae, lati maa gbadura laisimi ati ninu ohun gbogbo lati maa dupẹ.” Ọlọrun ti fun wa ni odiwọn yii ninu 1 Tẹssalonika 5:16-18. Itumọ rè̩ ni pe nigba gbogbo ni a o maa ni adura ninu ọkàn wa, a o si le maa yọ bi o tilẹ jẹ pe a wà ninu iṣoro. Ifẹ ti o maa n kún ọkàn wa a maa kọrin iyin si Oluwa bi o tilẹ jẹ pe awọn ohun ti o yi wa ka n fẹ bà wá ni ọkàn jé̩. “Ifẹ pipe nikan, ti o n jọba ninu ọkàn ati igbesi-aye eniyan, eyi ni gbogbo pipé Onigbagbọ.”

Jesu wi pe ifẹ ni akoja Ofin. Ofin kin-in-ni bi O ti fi i fun ni ni pe “Ki iwọ ki o si fi gbogbo àiya rẹ, ati gbogbo ọkàn rẹ, ati gbogbo iye rẹ, ati gbogbo agbara rẹ, fẹ Oluwa Ọlọrun rẹ.” O si fi kun un pe, “Ekeji si dabi rè̩, Fẹ ọmọnikeji rẹ bi ara rẹ” (Marku 12:30, 31). Nigba ti a ba ti sọ ọkàn wa di funfun, ifẹ ni yoo maa dari ohun gbogbo ti a ba n ṣe.

Diduro ninu Ifẹ

A wi pe a ti sọ wa di mimọ. A mọ pe a gbadura fun isọdimimọ a si ri i gbà lẹyin ti a ti dari è̩ṣẹ wa ji wa. A le ranti ifẹ ti o kún inu ọkàn wa nigba naa. A kò jẹ gbero ibi si ẹnikẹni; a kò jẹ sọrọ eniyan lẹyin ti o le pa a lara; a maa n huwa otitọ, a kò si jẹ fi ọwọ bo ohunkohun ti a ba ṣe. S̩ugbọn ifẹ naa ha wà nibẹ sibẹ? O ha fẹran ọmọnikeji rẹ sibẹ gẹgẹ bi ara rẹ, tabi o maa n ṣe ohunkohun lati ta á yọ? O ha n fi ifẹ Ọlọrun ṣe akọkọ ninu ohun gbogbo ti o n ṣe?

Kò si ẹni ti o le wo ọkàn rẹ lati ri boya o fẹran Ọlọrun pẹlu gbogbo àya, ọkàn, iye ati agbara rẹ; ṣugbọn bi o ba ṣe bẹẹ o n gbọran si aṣẹ Rè̩. Igbọran ni odiwọn ifẹ. Ninu 1 Johannu 2:5 a kà pe, “Ẹnikẹni ti o ba npa ofin rè̩ mọ, lara rè̩ li a gbé mu ifẹ Ọlọrun pé nitõtọ.”

Awọn Aṣẹ Ọlọrun

Ki ni awọn aṣẹ ti Ọlọrun n beere pe ki ẹni ti a ti sọ di mimọ pamọ? A ri diẹ ninu wọn ni 1 Kọrinti 13: “Ifẹ a mā mu suru, a si mā ṣeun; ifẹ ki ṣe ilara; ifẹ ki isọrọ igberaga, ki ifè̩; ki ihuwa aitọ, ki iwá ohun ti ara rè̩, a ki imu u binu, bḝni ki igbiro ohun buburu; ki iyọ si aiṣododo, ṣugbọn a mā yọ ninu otitọ; a mā farada ohun gbogbo, a mā gbà ohun gbogbo gbọ, a mā reti ohun gbogbo, a mā fàiyarán ohun gbogbo.”

A le ri i kà sii jakejado awọn iwe Paulu, Johannu ati Peteru; Jakọbu si wi pe, “Isin mimọ ati ailẽri niwaju Ọlọrun ati Baba li eyi, Lati mā bojutó awọn alainibaba ati awọn opó ninu ipọnju wọn, ati lati pa ara rè̩ mọ lailabawọn kuro li aiyé” (Jakọbu 1:27). Ko si ọkan ninu awọn aṣẹ Ọlọrun ti o ṣe yẹpẹrẹ. A le pa ara wa mọ kuro ninu faaji ati àṣà aye, ṣugbọn a tun paṣẹ fun wa lati ran awọn alaini lọwọ, ati lati bẹ awọn alaisan wò -- ki i ṣe lati toju bọ ile, ṣugbọn lati dara yá wọn ati lati ba wọn sọrọ nipa ohun ti ọrun. Jesu wi pe, “Niwọn bi ẹnyin ti ṣe e fun ọkan ninu awọn arakọnrin mi wọnyi ti o kere julọ, ẹnyin ti ṣe e fun mi” (Matteu 25:40).

Didagba ninu Oore-Ọfẹ

Ki i ṣe ẹsẹkẹsẹ ti a ba sọ wa di mimọ ni a maa n de oju ọwé̩n, tabi oju ami gbogbo Ọrọ Ọlọrun, ṣugbọn pẹlu iriri yii ninu ọkàn wa, a maa n wè̩ wa mọ ki a ba le ni agbara lati de oju ọwẹn Ọrọ Rè̩ bi a ba ti n ṣi wọn paya fun wa. Paulu Apọsteli sọ fun Timoteu pe, “S̩āpọn lati fi ara rẹ hàn niwaju Ọlọrun li ẹniti o yéjé” (2 Timoteu 2:15). Nitori naa Ọlọrun n fẹ ki awọn ọmọ Rè̩ kọ ohun ti ifẹ Rẹ jé̩ ki wọn si ṣe e.

Ipinnu Ọlọrun ni sisọ awọn eniyan Rè̩ di mimọ ni pe ki Oun ki o le mu wọn wá si ọdọ ara Rè̩ bi “ìjọ ti o li ogo li aini abawọn, tabi alẽbu kan, tabi irú nkan bawọnni; ṣugbọn ki o le jẹ mimọ ati alaini àbuku” (Efesu 5:26, 27).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Nigba wo ni Dafidi fi ọkàn rè̩ fun Ọlọrun?
  2. Ki ni Ọlọrun rò nipa rè̩ nigba ti o di ọba?
  3. Ki ni Dafidi ṣe nigba ti o dẹṣẹ ti o si bí Ọlọrun ninu?
  4. Dafidi gbadura fun ohun meji, ki ni awọn nnkan naa?
  5. Ki ni Ọlọrun maa n ṣe fun ni nigba ti a ba ri igbala?
  6. Ki ni isọdimimọ maa n ṣe fun ọkàn?
  7. Darukọ ninu awọn nnkan ti Ọlọrun n beere ninu ọkàn ẹni ti a ti sọ di mimọ?
  8. Ki ni ṣe ti Ọlọrun fi n sọ awọn eniyan Rè̩ di mimọ?