Orin Dafidi 1:1-6; 15:1-5; 24:1-10

Lesson 233 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Tani yio gùn ori oke OLUWA lọ? tabi tani yio duro ni ibi-mimọ rè̩? Ẹniti o li ọwọ mimọ, ati aiya funfun” (Orin Dafidi 24:3, 4).
Notes

Alabukún-fun

Onisaamu sọ fun wa nipa oriṣi eniyan meji – olododo ati alaiṣododo. Awọn eniyan ti n gbe igbesi-aye iwa-bi-Ọlọrun nikan ni awọn eniyan ti o ni ayọ tootọ. Nini ojurere Ọlọrun ati ibukun Rè̩ ní igbesi-aye ẹni a maa mu inu eniyan dùn. Lai si Ọlọrun eniyan kò le ni ayọ ti yoo wa titi. È̩ṣẹ a maa mu ibanujẹ wa, ṣugbọn iwa-bi-Ọlọrun ni orisun ayọ. Iwa rere ati iwa mimọ ki i ṣe ọna si ayọ nikan bi kò ṣe ayọ gan an funra rè̩.

Orin Dafidi kin-in-ni fi hàn wa pe oriṣiriṣi awọn eniyan alaiwa-bi-Ọlọrun ni o wà. Eniyan alaiwa-bi-Ọlọrun le ṣe alai ti i jinlẹ ninu è̩ṣẹ -- o sa kan wà lai ni Ọlọrun ni. Awọn miiran si wa ti wọn maa n lọ jinna ju bẹẹ lọ wọn a maa dá ẹṣẹ gan an. Bẹẹ ni awọn miiran si tun wà, awọn ẹlẹgàn, awọn ti o korira Ọlọrun ati gbogbo iwa-bi-Ọlọrun. Wọn sé̩ Bibeli wọn a si maa kẹgàn awọn Onigbagbọ. Awọn ẹgbẹ mẹtẹẹta yii jẹ ẹlẹṣẹ, nitori wọn kò mọ Ọlọrun.

Igbesi-aye Olododo

A sọ fun wa nipa bi ẹni ti o ni ayọ ṣe n gbe igbesi-aye rè̩. Eniyan ti o ba ni Ọlọrun ninu aye rè̩ yoo maa gbe gẹgẹ bi ohun ti Onisaamu ti sọ fun wa. Kò ṣe e ṣe fun eniyan lati gbe igbesi-aye ododo ati ayọ afi bi Ọlọrun ba wà ninu ọkàn rè̩. Onisaamu kọkọ sọ awọn ohun ti alabukun-fun ki i ṣe. Ki i rin ni imọ awọn eniyan buburu. Oun ki i fi ifẹ ati ilepa awọn eniyan aye ṣe odiwọn igbesi-aye rè̩. Oun a maa yẹra kuro ni ọna awọn alaiwa-bi-Ọlọrun nitori wọn ki i ni igbẹkẹle ninu Ọlọrun. Oun ki i ba awọn ti o ṣe alaibikita ninu iṣẹ wọn si Ọlọrun kẹgbẹ pọ. Oun ki i yàn ọrẹ rè̩ laaarin awọn oluṣe buburu, nitori wọn kò bè̩ru Ọlọrun. Onigbagbọ ki i bọ si ọna awọn ẹlẹṣẹ, ki a ma ṣẹṣẹ sọ pe ki o duro nibẹ. Oun ki i dẹsẹ duro ni ọna awọn ẹlẹṣẹ, ki wọn ba le wa pe e nibẹ. Oun ki i duro nibẹ lati wo è̩ṣẹ ti wọn n lepa ti wọn si n dá. Onigbagbọ ki i ba awọn ẹlẹgàn jokoo lati kẹgbẹ pọ, awọn ti wọn n gan Ọlọrun. Oun ki i ni isimi tabi ifayabalẹ laaarin awọn eniyan buburu.

Ọna Iparun

Njẹ iwọ ri i pe ni ṣisẹ-n-tẹle, Satani le mu eniyan lọ diẹdiẹ sinu iparun? Bi o ba le yi eniyan lọkàn pada lati ṣe bi awọn ẹlẹṣẹ ati lati gbe igbesi-aye rè̩ bi ti wọn, yoo mu ẹni naa jinna si Ọlọrun ju bẹẹ lọ. Lẹyin eyi, yoo ni ikuna lati ṣe ohunkohun ti o tọ, yoo fi awọn ohun ti o tọ lati ṣe silẹ lai ṣe, yoo si maa ṣe awọn ohun wọnni ti kò gbọdọ ṣe. Diẹdiẹ ni Satani yoo maa mu un lọ titi yoo fi ṣọtẹ si Ọlọrun ati ohun gbogbo ti i ṣe ododo.

Ifẹ fun Bibeli

Onisaamu sọ iṣe Onigbagbọ fun ni. Dipo ti i ba maa wo aye fun iranlọwọ, Onigbagbọ a maa gbẹkẹle Ọlọrun fun itọsọna. A maa sin Ọlọrun gẹgẹ bi ọna ti Ọlọrun, ki i ṣe ni ọna ti rè̩ ti ko de ibì kan. O fẹran Bibeli, Ọrọ ati Ofin Ọlọrun. A maa gbadun Bibeli to bẹẹ ti o fi maa n ronu nipa rè̩ ni igbà ọsan ati loru. Oun a maa ṣe ju pe ki a ka Bibeli ni aarọ -- ni ibẹrẹ ọjọ -- ki o si kà a ni aṣaalẹ -- ni ibẹrẹ oru. Ni ọsan ati ni oru, Onigbagbọ a maa rò nipa Ọlọrun ati Ọrọ Rè̩. Iyin ati aṣaro ṣiṣe yoo dapọ mọ iṣẹ oojọ ati isinmi oru. “Ohunkohun ti iṣe õtọ, ohunkohun ti iṣe ọwọ, ohunkohun ti iṣe titọ, ohunkohun ti iṣe mimọ, ohunkohun ti iṣe fifẹ, ohunkohun ti o ni irohin rere, bi ìwa-titọ kan ba wà, bi iyìn kan ba si wà, ẹ mā gbà nkan wọnyi rò” (Filippi 4:8).

A gba Joṣua niyanju lati pọn Ofin lé ki o ba le ṣe aṣeyọri ki o si ṣe rere. “Iwe ofin yi kò gbọdọ kuro li ẹnu rẹ, ṣugbọn iwọ o ma ṣe àṣaro ninu rè̩ li ọsán ati li oru, ki iwọ ki o le kiyesi ati ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti a kọ sinu rè̩: nitori nigbana ni iwọ o ṣe ọna rẹ ni rere, nigbana ni yio si dara fun ọ” (Joṣua 1:8).

Bi Igi

A le fi igi ṣe apejuwe igbesi-aye Onigbagbọ. A ti pe awọn Onigbagbọ ni “igi ododo, ọgbìn OLUWA”, ki a le yin in logo (Isaiah 61:3). Idagbasoke a maa hàn ninu igbesi-aye Onigbagbọ. Gẹgẹ bi igi ti i maa mu ewe tutu yọyọ ati eso jade, bẹẹ gẹgẹ ni Onigbagbọ maa n gberu nipa ti ẹmi, ti o n fi hàn pe iye wa ni inu ọkàn rè̩. Ẹni ti o ba ni ireti rè̩ ti o si ni igbẹkẹle rè̩ ninu Ọlọrun “yio si dabi igi ti a gbìn lẹba omi, ti o nà gbòngbo rè̩ lẹba odò, ti ki yio bè̩ru bi õru ba de, ṣugbọn ewe rè̩ yio tutu, ki yio si ni ijaya li ọdun ọdá, bḝni ki yio dẹkun lati ma so eso” (Jeremiah 17:7, 8). Eyi yii ni ileri pe ẹni ti ireti ati igbẹkẹle rè̩ ba wà ninu Ọlọrun yoo dabi igi. Ki i ṣe pe o lè tabi o ṣe e ṣe ki o ri bẹẹ, ṣugbọn yoo dabi igi, gbongbo rè̩ yoo maa gbilẹ si i ki o ba le ni ipilẹ ti o sàn ju bẹẹ lọ! Yoo sa maa fi ipò ilera nipa ti ẹmi hàn! A ki i ṣi i nipo pada tabi ki o rọ! Kò ni ṣe alai ni eso ti Ẹmi!

Onigbagbọ le reti igba iṣoro “bi õru ba de.” Ninu gbogbo idanwo, eso rè̩ ki yoo dẹkun bẹẹ ni igbesi-aye rè̩ nipa ti ẹmi ki yoo di gbigbẹ. Awọn kokoro wà, ati irẹdanu, ati arùn ti o le mu ki igi wọwé. Kò si ọta ti o le mu igbesi-aye ti ẹmi, ati ẹwa kuro ninu ẹni ti o gbẹkẹle Ọlọrun nigba gbogbo. A o pa a mọ kuro ninu abuku ati idibajẹ. “Ohunkohun ti o ṣe ni yio ma ṣe dede.” Eyi ni ẹni ti o ni ayọ tootọ.

Ẹ jẹ ki a ranti pe awọn ileri wọnyii ati ipò rere wọnyii wà fun gbogbo Onigbagbọ. Kò ṣe nnkan kan bi o tilẹ jẹ pe ẹni naa ṣẹṣẹ ri igbala ní. Kò ṣe nnkan kan bi ẹni naa jé̩ ọmọde. Ẹnikẹni – i baa jé̩ agba tabi ọmọde- -- ti o gbé ẹkẹ rè̩ le Ọlọrun ti o si n gbọran si ifẹ Ọlọrun, yoo wà laaye yoo si maa ṣe rere nipa ti ẹmi gẹgẹ bi Onisaamu ti wí.

Awọn Eniyan Buburu Kò Ri Bẹẹ

Kò si ọkan ninu gbogbo nnkan wọnyii ti a le sọ nipa ẹlẹṣè̩. “Awọn enia buburu kò ri bḝ.” Igbesi-aye wọn jé̩ odikeji ti olododo ninu iwa ati ipo wọn. Awọn alaiwa-bi-Ọlọrun dabi iyangbò ti afẹfẹ n fẹ lọ ti o si parun. Ninu Matteu 3:12 a kà pe akoko n bọ ti a o ko awọn alikama jọ sinu abà, ṣugbọn iyangbo ni yoo fi “iná ajõku sun.” Iyangbo kò wulo. Kò ni eso! Kò ni gbongbo! Kò ni iye! Kò ni ireti! Bi ẹlẹṣẹ ti ri ni eyi.

Ọna igbesi-aye mejeeji ni a ṣe apejuwe nihin yii. Ọna awọn wọnni ti wọn gbẹkẹle Ọlọrun a maa layọ. Hihá ni ẹnu ọna naa “ti o lọ si ibi ìye, diẹ li awọn ẹniti o nrin i” (Matteu 7:14). Ibanujẹ ni ọna awọn ti kò ni Ọlọrun. Gbooro ni ẹnu-ọna naa “ti o lọ si ibi iparun; ọpọlọpọ li awọn ẹniti mba ibè̩ wọle” (Matteu 7:13). Ewo ni iwọ n rin ninu ọna mejeeji yii?

Lati Wọ Ọrun

Lai si aniani olukuluku eniyan ni o n fẹ wọ Ọrun. S̩ugbọn ki i ṣe olukuluku eniyan ni yoo de Ọrun afi bi o ba mura silẹ. Eyi ni o jẹ ẹdùn ọkàn Onisaamu. Nigba ti o n beere pe ta ni yoo maa gbe inu agọ Ọlọrun tabi ta ni yoo gùn ori oke mimọ Rè̩, ohun ti Onisaamu n sọ ni yii, “Ta ni yoo lọ si Ọrun?” N ṣe ni o n beere nipa irú eniyan naa, ki i ṣe orukọ wọn ni o n beere. A beere ibeere yii lati wadii lẹnu Oluwa nipa ọna si Ọrun.

Idahun naa wà ninu Ọrọ Ọlọrun; Oluwa si kọ awọn ohun ti a gbọdọ ṣe, ati awọn ohun ti a kò gbọdọ ṣe. Lilọ si Ọrun jẹ ọlá ati anfaani ti i ṣe ti awọn ti o fi Ọrọ Ọlọrun ṣakoso igbesi-aye wọn. Eniyan ki yoo lọ si Ọrun nitori ẹbi rè̩ tabi nitori ohun ti o jogun rè̩. O ni lati ni iriri pẹlu Ọlọrun eyi ti o wẹ ọkàn rè̩ mọ ti o si mu iyipada wá sinu iwa ati iṣe rè̩.

Idahun naa ni yii: “Ẹniti o nrìn dede, ti nṣiṣẹ ododo, ti o si nsọ otitọ inu rè̩.” Lati rìn deede ki i ṣe pe ki a gbori gún ténté nigba ti a ba n rìn. Lati rin deede niwaju Ọlọrun ni pe ki iwa wa ki o jẹ iwa otitọ ati ododo, ijolootọ ati aiṣègbè. O ṣe ọranyan lati jé̩ olotitọ -- ninu ohun ti a n gbà ladura, ninu ohun ti a ṣeleri, ninu ohun ti a jẹwọ rè̩ ati ninu ohun ti a n ṣe.

Agbara Ọlọrun

Kò ṣe e ṣe fun eniyan lati gbe igbesi-aye rè̩ lati ba gbogbo ohun ti a beere yii mu afi bi o ba ni ifẹ Ọlọrun ninu ọkàn rè̩. Ọlọrun a maa fun eniyan lagbara lati gbe igbesi-aye rè̩ gẹgẹ bi Ọlọrun ti n fẹ ki o gbe e. Awọn miiran a maa gbiyanju ninu agbara wọn lati gbe igbesi-aye wọn gẹgẹ bi Ọrọ Iwe Mimọ ti i ṣe ipilẹ Ofin Wura: “Nitorina gbogbo ohunkohun ti ẹnyin ba nfẹ ki enia ki o ṣe si nyin, bḝni ki ẹnyin ki o si ṣe si wọn gẹgẹ; nitori eyi li ofin ati awọn woli” (Matteu 7:12). Nigba ti wọn ba kuna wọn a maa fi awawi gbe ara wọn lẹsẹ.

Jesu wi pe: “Ki iwọ ki o fi gbogbo àiya rẹ, ati gbogbo ọkàn rẹ, ati gbogbo iyè rẹ, ati gbogbo agbara rẹ, fẹ Oluwa Ọlọrun rẹ” ati pẹlu, “Fẹ ọmọnikeji rẹ bi ara rẹ” (Marku 12:30, 31). Ifẹ Ọlọrun ninu ọkàn eniyan nikan ṣoṣo ni o le mu ki eniyan ni iru ifẹ bẹẹ fun awọn ẹlomiran.

Ọmọnikeji Rè̩ gẹgẹ bi Ara Rẹ

Ohun miiran ti o jẹ pataki ni iwa wa si awọn eniyan -- awọn aladugbo wa. A kò gbọdọ pa wọn lara lọnakọna. A kò gbọdọ mu awọn ẹlomiran binu, a kò si gbọdọ mu wọn bi wa ninu. Bi eniyan ba fẹran aladugbo rè̩ gẹgẹ bi ara rè̩ nitootọ, yoo ṣe ohun gbogbo gẹgẹ bi ifẹ Ọlọrun.

Ahọn

Ẹni ti o n ṣiṣẹ ododo kò ni sọrọ ẹlomiran lẹyin ki o si maa sọrọ lodi si ẹlomiran nigba ti ẹni naa kò si nibẹ. Awọn ẹlomiran a maa dá ara wọn lare nipa sisọ pe otitọ ni awọn n sọ. Bi eniyan kò ba le sọ ọrọ rere nipa ẹlomiran, o sàn ki o má sọ ohunkohun rara. Melomeloo ni igba ti ahọn ti mu ki eniyan bọ sinu wahala! Nigba miiran o ti sọrọ ti o pa ẹlomiran lara, tabi ohun ti ki i ṣe otitọ. “Ahọn jẹ ẹya kekere, . . . . ohun buburu alaigbọran ni” ti o n ba gbogbo è̩yà ara jẹ (Jakọbu 3:5-8).

Iru ọrọ ti eniyan n sọ ni o n fi ohun ti o wa ninu ọkàn rè̩ hàn. “Bi ẹnikẹni ba ro pe on nsin Ọlọrun nigbati kò kó ahọn rè̩ ni ijanu, ṣugbọn ti o ntàn ọkàn ara rè̩ jẹ, isin oluwarè̩ asan ni” (Jakọbu 1:26). “Ẹnikẹni ti o ba pa ẹnu ati ahọn rè̩ mọ, o pa ọkàn rè̩ mọ kuro ninu iyọnu” (Owe 21:23). Onisaamu ni, “Emi o ma kiyesi ọna mi, ki emi ki o má fi ahọn mi ṣè̩” (Orin Dafidi 39:1).

Ti Kò Yẹsẹ

Onigbagbọ ki i kín eniyan buburu lẹyin, ohunkohun ti o wu ki ipò ẹni naa jẹ ni aye. Oun a maa bu ọlá fun awọn ti o ni ibẹru Ọlọrun ninu ọkàn wọn. Oun ki i gbà abẹtẹlẹ. O fẹ lati ni ẹri-ọkàn ti o mọ gaara ju pe ki o dù lati jere fun anfaani ara rè̩. Oun yoo sọ otitọ bi o tilẹ jẹ si ipalara fun un, ki yoo si yipada.

Ẹni ti o n fi Ọrọ Ọlọrun ṣe akoso igbesi-aye rè̩ ki yoo yẹsẹ lae -- ẹkọkẹkọ ki yoo le gbá a kuro (Efesu 4:14) tabi igbi wahala. A fi we ọkunrin ọlọgbọn kan ti o kọ ile rè̩ sori apata to bẹẹ ti o fi duro ṣinṣin nigba ti ikun omi ati igbi de (Matteu 7:24-27). Kò si ohun kan tabi ẹni kan ti o le yà wá kuro ninu ifẹ Ọlọrun a fi awa tikara wa (Romu 8:35-39).

A ti sọ pe Orin Dafidi ikẹẹdogun jẹ Saamu iwadii iduro idalare wa. Nigba ti eniyan ba ri igbala, a maa gbe igbesi-aye ti o yẹ ọmọ-ibilẹ Sioni, oke mimọ Ọlọrun. A fi we oke nì ti a kò le ṣi nidii.

Ọwọ Mimọ ati Aya Funfun

Iru awọn eniyan ti yoo lọ si Ọrun ni a sọ fun wa ni kukuru ninu Orin Dafidi ikẹrinlelogun nipa ọrọ wọnyii: “Ẹniti o li ọwọ mimọ, ati aiya funfun.” Eyi fi hàn fun wa bi o ti jẹ ohun pataki fun wa lati pa ara wa mọ kuro ninu iwa è̩ṣẹ, lai ni abawọn kuro ninu aye, ki ọrọ wa si jẹ alaileeri. Iriri kan wa nipa eyi ti a fi n wẹ ọkàn mọ kuro ninu gbogbo eeri ikọkọ niwaju Ọlọrun, ti o si n mu ki ọwọ wa wà ni mimọ niwaju awọn eniyan. Eniyan ni lati jé̩ olóòótọ niwaju Ọlọrun ati eniyan, ninu majẹmu rè̩ pẹlu Ọlọrun ati adehùn rè̩ pẹlu awọn eniyan – lai si yiyẹ ileri tabi ibura èké.

Ọlọrun ni o ga ju lọ lori gbogbo aye, lori ohun gbogbo ati ẹni kọọkan. O n beere igbesi-aye mimọ ati ọkàn mimọ lọwọ awọn ti o n sin In. O n beere gbogbo ifẹran wa pẹlu. Ọwọ ni a fi n ṣiṣẹ, ahọn ni a fi n sọrọ, ọkàn ni a si fi n fẹran. Gbogbo nnkan wọnyii ni a gbọdọ lò fun ogo Ọlọrun. Nigba ti eniyan ba fẹran Oluwa, ti o n ṣe aṣaro ninu Ọrọ Rẹ, ti o n lo ahọn rè̩ lati yin Ọlọrun, ti o n ṣiṣẹ fun Un, kò si akoko tabi àye fun è̩ṣẹ. Ẹni ti o ba rẹ ara rè̩ silẹ lati wá Ọlọrun yoo gba ibukun Oluwa. Oun ni alabukún-fun, oun ni ilẹkun Ọrun yoo si ṣi silẹ fun. O ni ayọ nihin ati igbadun ayeraye lẹyin ayé yii.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ki ni itumọ “alabukún-fun?
  2. Bawo ni Satani ti ṣe n mu eniyan lọ diẹ diẹ sinu ọna iparun?
  3. Ki ni didùn inu Onigbagbọ?
  4. Ki ni awọn ohun aṣaro Onigbagbọ?
  5. Bawo ni awọn alaiwa-bi-Ọlọrun ṣe dabi iyangbo?
  6. Bawo ni awọn ẹni iwa-bi-Ọlọrun ṣe dabi igi?
  7. Bawo ni ahọn ti ṣe n fa wahala wá?
  8. Ki ni itumọ pe eniyan ki yoo yẹsẹ lae?
  9. Ki ni ohun ti o ni lati jé̩ mimọ ati alaileeri niwaju Ọlọrun?
  10. Bawo ni eniyan ti le ṣe gbogbo nnkan wọnyii ki o si gbe igbesi-aye ti o tọ ki o si lọ si Ọrun?