Orin Dafidi 8:1-9; 19:1-14; 119:1-24

Lesson 234 - Junior

Memory Verse
AKỌSORI: “Awọn ọrun nsọrọ ogo Ọlọrun; ati ofurufu nfi iṣẹ ọwọ rè̩ han” (Orin Dafidi 19:1).
Notes

Iyin fun Ọlọrun

Nihin yii Dafidi n fi iyin fun Ọlọrun Ẹni ti ifarahan ọlanla ati titobi Rè̩ yẹ lati gba iyin ati ọlá. Orukọ Oluwa jẹ ọwọn o si niyelori nitori o tayọ gbogbo ohun iyokù ni gbogbo aye. O dara ju ohunkohun ni ọrun tabi ni sánmà.

Oluwa ni Ẹlẹda ohun gbogbo. Ọpọlọpọ igbà ni O maa n ba eniyan sọrọ nipa iṣẹ ọwọ Rè̩. Oun a maa fi ara Rè̩ hàn fun awọn eniyan nipa awọn nnkan ti O dá. Ko si ninu ede tabi ohùn kan ti ki i gbọ ohùn Ọlọrun, nigba ti wọn ba n wo awọn ohun ti a dá (Orin Dafidi 19:3). “Jẹ ki odò ki o ma ṣapẹ, ki awọn òke ki o ma ṣe ajọyọ niwaju OLUWA” (Orin Dafidi 98:8, 9). “Awọn oke-nla ati awọn oke kékèké yio bú si orin niwaju nyin, gbogbo igi igbẹ yio si ṣapé̩” (Isaiah 55:12).

Ogo Ọlọrun ninu awọn Ọrun

Awọn ohun ti a n ri lojoojumọ n sọ ti ogo Ọlọrun. Ronu nipa awọn ọrun! Wọn “nsọrọ ogo Ọlọrun” (Orin Dafidi 19:1). Iṣẹ ọwọ Ọlọrun ni wọn, orukọ Rè̩ si ga rekọja wọn ni ọlanla. Ẹwa awọsanma maa n fun awọn eniyan ni igbadun pupọ. Awọ ofefe ti o ri mulọmulọ nì jẹ ipilẹ fun oriṣiriṣi awọ ti o wà ninu oṣumare, ileri Ọlọrun pe Oun ki yoo tun fi ikun-omi pa aye ré̩ mọ (Gẹnẹsisi 9:11).

Njé̩ o ti i kiyesi ikuuku ti o dàbi iṣu è̩gbọn owu funfun bi ojo didi ti n rekọja lati apa kan ofuurufu si apakeji titi o fi parẹ ti a kò fi rii mọ? Njé̩ iwọ ki i gbadun ati maa wo awọn oriṣiriṣi awọ ti o n wà loju ọrun nigba ti oorun ba fẹ wọ, ati bi àwọ ti o tàn yan an ti maa n yipada di awọ ti o dara loju ti o si fani mọra? Ọlọrun ni o dá wọn. Wọn n sọrọ ogo Rè̩ bi o tilẹ jẹ pe a kò gbọ iró kan lati inu wọn.

Oju ọrun wulo o si lẹwa pẹlu. Oorun n yi lọ nipa ọna ti rẹ ti a n pe ni ayika rè̩, ni ojoojumọ, ni ipa ọna kan naa, o si wa bẹẹ lai yipada to bẹẹ ti o fi jẹ pe fun ọpọlọpọ ọdun kò si ọna miiran ti a gba fi n mọ akoko ju ohun elo kan ti a fi n mọ wakati nipa hihàn ojiji oorun lara rè̩. Oorun ni o n ṣe akoso gigùn ọsan ati oru ni gbogbo aye. Oorun a maa fun ni ni ooru ati imọlẹ, “kò si si ohun ti o fi ara pamọ kuro ninu õru rè̩” (Orin Dafidi 19:6). Oorun, pẹlu awọn oluranlọwọ rè̩ ni alẹ --oṣupa ati awọn irawọ -- ni o n ṣe akoso igbà ojo, igba ẹẹrun, igba oworẹ ati igba otutu. Ọlọrun ni O ṣeto nnkan wọnyii ti O si n ṣe akoso wọn. Awọn eniyan miiran a maa sin wọn a si maa fi ogo fun awọn imọlẹ oju ọrun; ṣugbọn ẹ jẹ ki a fi ogo ati iyin fun Ọlọrun Ẹni ti i ṣe Ẹlẹda ati Alakoso, Baba imọlẹ (Jakọbu 1:17).

Ogo Ọlọrun ni Ayé

Awọn ohun ti o wà ni aye n fi iṣẹ ọwọ Ọlọrun hàn pẹlu. Njé̩ o ti ri iji lile ri, eyi ti o n bi awọn igi nla nla sihin sọhun tabi ti o tilẹ n fà wọn tu? Tabi o ti kiyesi igbi omi okun ti afẹfẹ ru soke? Ọlọrun “paṣẹ, o si mu ìji fẹ, ti o gbé riru rè̩ soke” to bẹẹ ti “nwọn gòke lọ si ọrun, nwọn si tún sọkalẹ lọ si ibú.” Ọlọrun “sọ ìji di idakẹ-rọrọ, bḝni riru omi rè̩ duro jẹ” (Orin Dafidi 107:25-29).

Ogo Ọlọrun ninu Awọn Ohun Kéékèèké

Awọn ohun kéékèèké paapaa ti wọn jẹ alailera ti wọn si wọpọ n sọrọ ogo Ọlọrun. O maa n yà wa lẹnu nigba ti a ba n rò nipa awọn kokoro ati awọn ẹda kéékèèké ti n gbe ori ilẹ. Awọn eera miiran wà ti wọn kere pupọ, sibẹ wọn n fi ogo Ọlọrun hàn ni ọna ti wọn gba n gbe igbesi-aye wọn. Ta ni n kọ eera lati mọ ọna pada si ile lẹyin ti o ba ti lọ kaakiri láàárín awọn eweko giga? Ta ni n ran awọn kokoro wọnni lọwọ lati gbe ohun ti o tobi ti o si wuwo jù wọn lọ lọpọlọpọ? Ta ni n kọ wọn lati wá ounjẹ wọn silẹ de igbà otutu? Kò si ẹlomiran bi kò ṣe Ọlọrun tikara Rẹ. A ti tọka si awọn ẹda kinnkinni wọnyii gẹgẹ bi apẹẹrẹ. Sọlomọni wi pe: “Tọ ẽrùn lọ, iwọ ọlẹ: kiyesi iṣe rè̩, ki iwọ ki o si gbọn: ti kò ni onidajọ, alabojuto, tabi alakoso, ti npese onjẹ rè̩ ni igba-è̩run, ti o si nkó onjẹ rè̩ jọ ni igba ikore” (Owe 6:6-8).

Boya o ti gbọ tabi o tilẹ ti ri kokoro kekere kan ti o n yipada di labalaba ti o dara ti o si lẹwa. Bi o ti rọra n rako lọ, a fẹrẹ ma le ri i nitori awọ rè̩ bá awọn ewe tabi igi ti o wà ni agbegbe rè̩ mu. Ki i ṣe kokoro yii ni o yan iru awọ bẹẹ tabi iri bẹẹ funra rè̩. Ọlọrun ni o fi wọn fun kokoro kekere yii gẹgẹ bi aabo. Láàárín akoko kan kokoro yii yoo hun ile kan fun ara rè̩ ti a n pe ni ekùkù. Kokoro yii kò lọ si ile-ẹkọ lati kọ nipa bawo tabi ni akoko wo ni o yẹ fun un lati ṣe eyi. Okun yii wà lara rè̩, Ọlọrun a si fi hàn fun kokoro yii nipa imọ inu pe ki o mura silẹ. Lẹyin ti o ba ti sùn fun igba diẹ ninu ekuku yii, ekuku naa a si faya, arẹwa labalaba kan a si fo jade. Kò si ẹni ti o wá lati ji i ninu oorun rè̩ tabi ti o ran an lọwọ lati wọṣọ. Oun a jade a si na iyẹ rè̩ alaràbara, a si gbọn ara nù, a si fo lọ. Ni akọkọ ẹyin, lẹyin eyi kokoro, lẹyin eyi ekuku, kokoro kan ti n sùn ninu ekuku naa, ati lẹyin eyi labalaba ti ara rè̩ rọ ti o si le tete faya, sibẹ ti o lagbara lati fi ogo Ọlọrun hàn.

Awọn ẹda wọnyii jẹ iṣẹ ọwọ Ọlọrun. O n lò wọn lati fi gba ọlá ati ogo fun ara Rè̩. Wọn n fi titobi ati agbara Rè̩ hàn fun dida wọn ati ṣiṣe akoso wọn.

Eniyan

“Kili enia, ti iwọ fi nṣe iranti rè̩?” Bi a ti n ro ti ọlanla Ọlọrun, o maa n jẹ iyalẹnu fun awa paapaa pe O n ranti awọn ọkunrin ati obinrin ti o wà ni aye. Sibẹ Ọlọrun si ti fun wa ni ọpọlọpọ ibukun. O ti ṣe awọn ohun nlá pupọ fun wa. Ọlọrun ti fun eniyan ni agbara ati talẹnti lati ronu ati lati kẹkọọ, lati gbe nnkan ró ati lati ṣe nnkan. O ti fi eniyan si ipò kan ti o ga ju awọn ẹranko ati awọn iṣẹ ọwọ Ọlọrun iyokù lọ. Eniyan ni olori ẹda Ọlọrun. Ọlọrun fun eniyan lagbara lati lo awọn ohun ti a da – eedu ati awọn iṣura ti o wà ninu ilẹ, igi ati awọn ẹranko ti o wà lori ilẹ aye, awọn ẹyẹ oju ọrun, ati ẹja inu okun.

Awọn ẹranko, awọn ẹyẹ, ẹja ati awọn kokoro, gbogbo wọn ni wọn n tẹle eto ti Ọlọrun ti ṣe silẹ fun wọn. Ọlọrun fi eniyan ṣe olori gbogbo wọn. Ọlọrun ṣe gbogbo nnkan wọnyii fun wa nitori O fẹran wa; nisisiyii paapaa O n woye ki O ba le ran eniyan lọwọ. “Kiye si i oju OLUWA mbẹ lara awọn ti o bè̩ru rè̩, lara awọn ti nreti ninu ānu rè̩; lati gba ọkàn wọn la lọwọ ikú, ati lati pa wọn mọ lāye ni igba ìyan” (Orin Dafidi 33:18, 19).

Eto Ọlọrun fun Wa

Ọlọrun ni eto kan fun wa lati tẹle, bakan naa. Ifẹ kan wà ninu ọkàn eniyan lati wá ayọ. Ọlọrun ti la ọna kan silẹ fun eniyan lati ni ayọ. O sọ ẹni ti o ni ayọ fun wa ati bi olukuluku eniyan ṣe le ni ayọ ki o si jẹ alabukún-fun – nipa ririn “ninu ofin OLUWA” (Orin Dafidi 119:1). Ofin Ọlọrun jẹ ohun ti a gbọdọ fẹran ju wura daradara pupọ nitori “ni pipamọ wọn ere pipọ mbẹ” (Orin Dafidi 19:10, 11).

Ofin Ọlọrun ni Bibeli. Ọlọrun a maa ba awọn eniyan sọrọ nipasẹ Ọrọ Rẹ gẹgẹ bi O ti n ba wọn sọrọ nipa awọn ohun ti O dá. A paṣẹ fun wa lati pa Ofin Ọlọrun ati Ọrọ Rè̩ mọ (Orin Dafidi 119:4), ọna ti a si le gba lati ni ayọ tootọ ni eyi ni. “Kili ... ọmọ enia, ti iwọ fi mbè̩ ẹ wò?” Eniyan jé̩ apa kan ninu awọn ohun ti Ọlọrun dá. Ọlọrun n fẹ lati gba ogo lọwọ wa. Nitori Ọlọrun fẹran wa O si n fẹ ki a gbe igbesi-aye wa fun Oun ki a si ni ayọ, O ti fi Bibeli Ọrọ Rè̩ fun wa.

Niniyelori Bibeli

Dafidi gẹgẹ bi ẹni ti o kọ ọpọlọpọ ninu awọn Orin Dafidi, n sọ fun wa pe oun ri iṣura nla ninu Ọrọ Ọlọrun. Dafidi bu ọlá fun Ọrọ Ọlọrun o si fẹran rè̩. O mu Ọrọ Ọlọrun lò nipa gbigba ikilọ lati inu rè̩. A ṣi i leti nipa iṣe rè̩ si Ọlọrun ati eniyan. A ki i nilọ nipa ewu ti o n bọ. Ọrọ Ọlọrun kilọ fun Dafidi lati mura silẹ lati duro niwaju Ọlọrun.

Adura ti Dafidi n gba jé̩ adura ikorira fun è̩ṣẹ. O gbadura fun aanu. O gbadura fun oore-ọfẹ ni igbà iṣoro lati le bori è̩ṣẹ. O gbadura ki agbara Ọlọrun pa oun mọ. Onisaamu gbadura o si tun ṣaapọn. O fi gbogbo ọkàn rè̩ wá Ọlọrun (Orin Dafidi 119:10). O pa Ọrọ naa mọ sinu ọkàn rè̩ ki o má ba dẹṣẹ si Ọlọrun (Orin Dafidi 119:11). O ṣe aṣaro ninu gbogbo Ọrọ Ọlọrun – ki i ṣe ninu awọn ere ati ibukun nikan. Ofin Ọlọrun, aṣẹ Ọlọrun, ẹkọ ati ilana Ọlọrun jẹ ohun ti o leke ninu ọkàn rè̩. Awọn ni o n ṣe inudidun rè̩ ki o ba le gbe igbesi-aye rè̩ lọna ti yoo fi pa Ọrọ Ọlọrun mọ (Orin Dafidi 119:16, 17).

Ilepa Dafidi ni lati gbe igbesi-aye iwa-titọ. O n fẹ ki ero rè̩ ati ọrọ rè̩ jẹ iru eyi ti yoo jé̩ itẹwọgba fun Ọlọrun. O fẹ ki wọn jé̩ iyin ati adura si Ọlọrun Ẹni ti Dafidi pe ni “agbara mi, ati oludande mi.”

Iyin lati ọdọ Eniyan

Ninu ẹkọ yii a ti kọ pe awọn ẹda Ọlọrun ati Ọrọ Ọlọrun a maa fi ogo ati agbara Rè̩ hàn. Wọn n fi ogo ati ọla fun Ọlọrun. Ọlọrun a si tun maa gba iyin lati ẹnu awọn ọmọde pẹlu. Wọn si jẹ ewe, boya wọn kò lagbara pupọ, awọn miiran kò tilẹ ti i bẹrẹ si i lọ si ile-iwe, ṣugbọn wọn le yin Ọlọrun. Gẹgẹ bi awọn ọmọde ti ṣe nigba ti Jesu wọ Jerusalẹmu bi Ọba! Awọn ọmọde naa yin Jesu ninu Tẹmpili, “wipe, Hosanna fun Ọmọ Dafidi” (Matteu 21:15).

A n fi ogo fun Ọlọrun nipa ọrọ ti a n sọ ti a fi n fi iyin fun Un. Iwa wa -- awọn ohun ti a n ṣe – le fi ogo fun Ọlọrun bakan naa. Onisaamu wi pe: “Emi o maa fi aiya diduro-ṣinṣin yìn ọ, nigbati emi ba ti kọ idajọ ododo rẹ” (Orin Dafidi 119:7). Nigba ti a ba gbọran si Bibeli, a o maa yin Ọlọrun logo nipa igbesi-aye wa. Nigba ti a ba ri igbala, a o maa gbé igbesi-aye iwa mimọ fun Oluwa. Igbesi-aye iwa mimọ a maa fi ogo fun Ọlọrun a si maa fi agbara Rè̩ hàn. Ki awọn Orin Dafidi ti a ti kọ yii má ṣai ràn wá lọwọ lati ka Ọrọ Ọlọrun si iyebiye ki wọn si mu ki a gbe igbesi-aye wa, nipa oore-ọfẹ Rè̩, ni ọna ti Ọlọrun yoo fi gba ọlá ati ogo nipa igbesi-aye wa.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. Ta ni dá Ọrun on aye?
  2. Bawo ni wọn ti ṣe n fi ogo Ọlọrun hàn?
  3. Ọna meji wo ni Ọlọrun n gbà bá awọn eniyan sọrọ?
  4. Ki ni ṣe ti Ọlọrun fi n ranti eniyan?
  5. Ta ni Ọlọrun fi ṣe olori awọn ẹda Rè̩?
  6. Bawo ni Bibeli ti niye lori to?
  7. Ki ni ṣe ti Onisaamu fi Ọrọ Ọlọrun pamọ si aya rè̩? (Orin Dafidi 119:11).
  8. Ki ni adura Dafidi? (Orin Dafidi 19:14).