Johannu 14:1-31

Lesson 235 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Ẹ máṣe jẹ ki ọkàn nyin daru, ẹ má si jẹ ki o warìri” (Johannu 14:27)
Cross References

I Ọrọ Itunu Jesu si awọn Ọmọ-Ẹyin ti Ọkàn Wọn Dàru

1 Jesu ṣeleri lati pese àye kan silẹ fun wọn, Johannu 14:1-3

2 A ṣe alaye Ọna, Otitọ ati Iye fun Tomasi oniyemeji, Johannu14:4-7

3 A ṣe alaye nipa ijinlẹ Ọlọrun “Baba” ati “Ọmọ” fun Filippi ti ọkan rẹ dàrú, Johannu 14:8-11

4 Jesu ṣeleri pe iṣẹ ti o tobi ju wọnyii lọ ni awọn ti o gbagbọ yoo ṣe, Johannu 14:12-14

II Ileri Olutunu

1 “Olutunu miran” yoo wá lati ba ni gbe titi lae, Johannu 14:15-17

2 Jesu yoo fara hàn fun awọn ọmọ-ẹyin Rẹ, ṣugbọn ki i ṣe fun araye, Johannu 14:18-24; Matteu 18:20

3 “Olutunu na, ti i ṣe Ẹmi Mimọ,” yoo jẹ Olukọ wọn, Johannu 14:25, 26;16:12-14

4 Jesu tun sọ ọrọ itunu ni ipari gbogbo rè̩, Johannu 14:27-31

Notes

Ọkàn ti o Dàrú

Ọkan awọn ọmọ-ẹyin dàrú bi wọn ti n ronu pe Jesu yoo fi wọn silẹ, nitori pe Jesu sọ bayii pe, “Nigba diẹ si i li emi wà pẹlu nyin”, ati “Nibiti emi gbé nlọ, ẹnyin ki o le wá” (Johannu 13:33). S̩ugbọn Kristi, ninu aanu ati ifẹ Rè̩ lati tu ọkàn awọn ti n tọ Ọ lẹyin ninu, sọ awọn ọrọ iyebiye wọnyii: “Ẹ maṣe jẹ ki ọkàn nyin dàru: ẹ gbà Ọlọrun gbọ, ẹ gbà mi gbọ pẹlu. Ninu ile Baba mi ọpọlọpọ ibugbe li o wà; ibamáṣe bḝ, emi iba ti sọ fun nyin. Nitori emi nlọ ipèse àye silẹ fun nyin. Bi mo ba si lọ ipèse àye silẹ fun nyin, emi o tún pada wá, emi o si mu nyin lọ sọdọ emi tikarami; pe nibiti emi gbé wà, ki ẹnyin le wà nibẹ pẹlu” (Johannu 14:1-3).

Akoko kan wa “nigbati awọn irawọ owurọ jumọ kọrin pọ, ti gbogbo awọn ọmọ Ọlọrun nhó iho ayọ” (Jobu 38:7); ṣugbọn ni ọjọ kan è̩ṣẹ wọ inu aye o si ba irẹpọ ti o wà laaarin Ọlọrun ati eniyan jé̩, o si mu ègun wọ inu aye. Ẹṣẹ ba irẹpọ ti o wa laaarin Ọlọrun ati eniyan jé̩ o si mu ibajẹ wọ inu aye; ṣugbọn ọkàn Ọlọrun n fa si awọn ẹda Rè̩, ati ninu awamaridi ọgbọn Rè̩ O la ọna kan silẹ nipa eyi ti ẹlẹṣẹ le di ẹni irapada. “Ninu ile Baba mi ọpọlọpọ ibugbe li o wà.” Ọlọrun Baba rán Kristi sinu aye lati ba araye laja sọdọ ara Rè̩ ki awọn eniyan ti a rapada nipa Ẹjẹ Jesu le maa ba A gbe titi lae. Ro bi yoo ti larinrin tó nigba ti ọrọ ohun nla nì ti Johannu gbọ lati Ọrun wa ba ṣẹ: “Kiyesi i, agọ Ọlọrun wà pẹlu awọn enia, on ó si mā ba wọn gbé, nwọn o si mā jẹ enia rè̩, ati Ọlọrun tikararè̩ yio wà pẹlu wọn, yio si mā jẹ Ọlọrun wọn” (Ifihan 21:3).

Ile Baba

Ilu Mimọ nì, Jerusalẹmu Titun ti Johannu ri ti o n sọkalẹ, ni ile Baba. Ọpọlọpọ ibugbe ni o wà nibẹ, ẹwa rè̩ kò ṣee royin; Jesu ti lọ pese wọn silẹ – lati pese wọn silẹ fun awọn ti o fẹ Ẹ. Fi oju ẹmi wo awọn ita wura didan, awọn ogiri jasperi, omi iye nì, ati awọn igi ti n so eso ni oṣooṣu, ewe eyi ti n mu awọn orilẹ-ède larada – eyi ni Ile Baba wa. Ọlọrun si n pe wa si Ile lati maa ba A gbe titi lae. Ikini oun ase nla wà nibẹ fun awa ọmọ oninakuna ti a dari ẹṣẹ ji, ti a si san gbese wa nipasẹ itoye Ọmọ Rè̩ ọwọn. Ẹni Mimọ ati Alailabawọn fi ara Rè̩ rubọ ki awọn ẹlẹgbin ati eleeri le ri irapada gbà. Ta ni jẹ huwa wèrè to bẹẹ ti yoo kọ eto nla ti Ọlọrun? Ta ni o si ṣe ọlọgbọn to bẹẹ lati ri ibi ti o dara ti o si kún fun alaafia ju eyi ti O ti pese silẹ fun wa?

“Ẹnyin si mọ ibi ti emi gbé nlọ, ẹ si mọ ọna na” (Johannu 14:4). Jesu sọ ọ ni ọna ti o le ye gbogbo eniyan pe ọdọ Ọlọrun ni Oun ti wa Oun si n pada lọ sọdọ Ọlọrun. Fun ọdún mẹta ti Jesu lo fun iṣẹ-ìranṣẹ, O n tọka awọn eniyan si ọna iye ainipẹkun. O n kọ awọn eniyan ni ironupiwada ati ibi titun. O sọ fun wọn nipa igbesi-aye ailẹṣẹ ati ọna ti wọn fi le di mimọ ati pipé. O paṣẹ fun wọn lati duro ni Jerusalẹmu titi a o fi fi agbara wọ wọn lati Oke wa. O si sọ fun wọn nipa Olutunu ti yoo maa ba wọn gbé titi lae. Jesu dá Ounjẹ-alẹ Oluwa ati Iwẹsẹ awọn ọmọ-ẹyin silẹ. O si pa a laṣẹ fun wọn lati maa ṣe iribọmi – lati maa baptisi “li orukọ Baba, ati ni ti Ọmọ, ati ni ti Ẹmi Mimọ.” S̩ugbọn ju gbogbo rè̩ lọ, Oun ni Ọna. Nipasẹ irubọ ati itajẹ-silẹ Rẹ nikan ni awọn eniyan n ri idariji gbà fun è̩ṣẹ wọn.

Mẹtalọkan

“Ẹ gbà mi gbọ pe, emi wà ninu Baba, Baba si wà ninu mi: bikoṣe bḝ, ẹ gbà mi gbọ nitori awọn iṣẹ na pāpā.” Jesu fẹ ki awọn ọmọ-ẹyin mọ pe Ọlọrun ni Oun. Nigba ti Peteru, nipa itọni Ẹmi mọ ẹni ti Jesu i ṣe, o wi bayii pe, “Kristi, Ọmọ Ọlọrun alāye ni iwọ iṣe.” Jesu si dahun pe iṣipaya yii kò ti ibomiran wa bi kò ṣe lati Ọrun ati pe “Ori apata yi li emi ó si kọ ijọ mi le” (Matteu 16:16-18). Ijọ Kristi ni lati mọ pé Kristi ki i ṣe kiki Olukọni lati ọdọ Ọlọrun wa nikan, ṣugbọn pe Ọlọrun ni Oun ati Ọdọ-agutan Ọlọrun ẹni ti a fi ṣẹbọ fun è̩ṣẹ gbogbo agbaye. “Ẹ gbà Ọlọrun gbọ, ẹ gba mi gbọ pẹlu.” Lọna miiran O wi pe, “Ẹ gbagbọ pe Ọlọrun ni emi.” “Ẹniti o ba ti ri mi, o ti ri Baba.” Kristi ni aworan pipe ti Baba. Gẹgẹ bi Ọmọ bibi kan ṣoṣo, Jesu Kristi ni “aworan on tikararẹ” (Heberu 1:3). Eyi ki i ṣe pe Oun jẹ Ẹni kan naa, bi kò ṣe aworan pipe Ọlọrun. Kò si ede aiyede tabi atakò ninu eto ati ilana Wọn. Ẹni kin-in-ni ninu wọn n fi ifẹ pipe ti ẹni keji hàn.

Ninu ori iwe yii ni a n fi bi ẹni kọọkan ninu Mẹtalọkan ti jẹ hàn ni. Jesu wi pe, “Emi nlọ sọdọ Baba.” Eyi n kọ ni pe Baba ti o wà ni Ọrun ati Jesu ti o wà ni aye jẹ ẹni ọtọọtọ. Jesu tun wi pe, “Olutunu na, Ẹmi Mimọ, ẹniti Baba yio rán li orukọ mi, on ni yio kọ nyin li ohun gbogbo, yio si ran nyin leti ohun gbogbo ti mo ti sọ fun nyin” (Johannu 14:26). Ninu ẹsẹ kan ṣoṣo yii a n fi Mẹtalọkan hàn nipa bi Baba yoo ṣe rán Ẹmi Mimọ lati ran ni leti ohun gbogbo ti Jesu, Ọmọ Rè̩ ti sọ. Nihin a n sọrọ nipa Ẹmi Mimọ gẹgẹ bi ẹni kẹta, a pe E ni Oun, Ẹni kan. Idapọ kan wà ninu Ọlọrun Mẹtalọkan ti kò le yé ni patapata, ṣugbọn a mọ pe Mẹtalọkan Olubukun wà: Baba, Ọmọ ati Ẹmi Mimọ. A tun ri i bi Mẹtalọkan ti fara hàn nigba iribọmi Kristi, nigba ti Ẹmi Mimọ sọkalẹ ni aworan adaba ti o si bà le Ọmọ, ti Baba si sọrọ lati Ọrun wa.

Nigba ti Jesu wi fun Filippi pe, “Ẹniti o ba ti ri mi, O ti ri Baba,” ohun ti Jesu n sọ ga ju ohun ti Filippi le fi oju ara ri lọ. Ki i ṣe ara-iyara ti a gbe wọ yii ni i ṣe eniyan gan an. A le mọ olukuluku eniyan nipa irisi oju rè̩, ṣugbọn nigba ti a ba bá ara wa lò de ayè kan ti a si mọ wọn daju, iwa wọn ati ọkunrin ti inu nì ni o n sọ wọn di ẹni ọwọn fun wa. Bakan naa ni o ri pẹlu Kristi -- kì i ṣe ara Rè̩ tabi awọ irun Rè̩ ni o fi Baba hàn bi kò ṣe ọkàn iyọnu ati ifẹ nla ti O ni, igbesi-aye ti O gbe ati iṣẹ ti O ṣe ni o fi Baba hàn awọn ọmọ-ẹyin.

Ifi Ẹmi Mimọ Wọ Ni

“Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹniti o ba gbà mi gbọ, iṣẹ ti emi nṣe li on na yio ṣe pẹlu; iṣẹ ti o tobi jù wọnyi lọ ni yio si ṣe; nitoriti emi nlọ sọdọ Baba” (Johannu 14:12). Ileri yii n sọ fun wa eredi rè̩ ti a fi n fi Ẹmi Mimọ wọ ni. Ẹbun agbara ni lati ṣiṣẹ fun Ọlọrun. “Ẹnyin ó gbà agbara, nigbati Ẹmi Mimọ ba bà le nyin: ẹ o si ma ṣe ẹlẹri mi ni Jerusalẹmu, ati ni gbogbo Judea, ati ni Samaria, ati titi de opin ilẹ aiye” (Iṣe Awọn Apọsteli 1:8). A kò gbọdọ fi ẹbun agbara yii, ani ifi Ẹmi Mimọ wọ ni, pe isọdimimọ, eyi ti i ṣe iwẹnumọ ọkàn.

Isọdimimọ ni iwa mimọ, Ẹmi Mimọ ni fifi agbara wọ ni. Dafidi ri isọdimimọ gbà nigba ti o gbadura pe, “Dá aiya titun sinu mi, Ọlọrun” (Orin Dafidi 51:10). A sọ Isaiah di mimọ nigba ti ẹṣẹ-iná lati ori pẹpẹ nì kan ètè rè̩. S̩ugbọn a kò tú Ẹmi Mimọ jade ṣaaju ọjọ Pẹntikọsti nigba ti a fi Ẹmi Mimọ ati iná baptisi awọn eniyan. Awọn eniyan mimọ igbà nì a maa sọrọ bi Ẹmi Mimọ ti n dari wọn; Johannu kún fun Ẹmi Mimọ lati inu iya rẹ wa; ṣugbọn ni ọjọ Pẹntikọsti a fi Ẹmi Mimọ wọ awọn ọgọfa eniyan – a fi Ẹmi Mimọ kun wọn. Ki i ṣe awọn nikan ni Ẹmi Mimọ yii kún, ṣugbọn O kún gbogbo ile nibi ti wọn gbe wà, Orisun Omi Iyè sí n ṣan lati inu ọkàn wọn jade.

Ifi Ẹmi Mimọ wọ ni kò pin si ọjọ Pẹntikọsti nikan, nitori ni ọdun kẹjọ lẹyin eyi a tun ri itujade Ẹmi Mimọ ni ile Korneliu (Iṣe Awọn Apọsteli 10:44-46), ati ni ọdun kẹtalelogun lẹyin igba naa ni Efesu (Iṣe Awọn Apọsteli 19:6). Ni gbogbo akoko yii wọn fi ede titun sọrọ, eyi ti i ṣe ẹri fifi Ẹmi Mimọ wọ ni. Iriri ti o ya ni lẹnu yii ko mọ si igba aye awọn Apọsteli; ṣugbọn gẹgẹ bi Iwe Mimọ ti wi, “Fun nyin ni ileri na, ati fun awọn ọmọ nyin, ati fun gbogbo awọn ti o jina rére, ani gbogbo awọn ti Oluwa Ọlọrun wa ó pè” (Iṣe Awọn Apọsteli 2:39). Ọlọrun n pe awọn eniyan sibẹ O si n tú Ẹmi Rè̩ jade sori awọn ti a ti sọ di mimọ patapata. “Ẹnyin ha gbà Ẹmi Mimọ na nigbati ẹnyin gbagbọ?” (Iṣe Awọn Apọsteli 19:2).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 S̩e alaye nipa ipadabọ Kristi ni ẹẹkeji?

  2. 2 Nibo ni a ti le ri apejuwe Ọrun ni kikún?

  3. 3 Ki ni iyatọ ti o wà ninu ifarahan Ẹmi Mimọ ni igbà Majẹmu Laelae ati ni akoko yii?

  4. 4 Eeṣe ti ọkàn awọn ọmọ-ẹyin fi dàrú ni akoko yii?

  5. 5 Ileri wo ni o fi itunu fun ọkàn wọn?

  6. 6 Ileri melo ni o le ri ninu ori iwe yii?

  7. 7 Njẹ ileri wọnyi wà fun wa lọjọ oni?

  8. 8 Sọ diẹ ninu iṣẹ Ẹmi Mimọ ninu aye ni ọjọ oni?

  9. 9 Sọ awọn ẹsẹ Iwe Mimọ ti o jẹri si Mẹtalọkan?

  10. 10 Nigba wo ni a mu ileri rirán Olutunu ṣẹ?