Johannu 15:1-27

Lesson 236 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Ẹ máṣe jẹ ki ọkàn nyin daru, ẹ má si jẹ ki o warìri” (Johannu 14:27)
Cross References

I Ajara ati awọn Ẹka Rè̩ -- Kristi ati awọn Ọmọ-ẹyin Rè̩

1 Kristi ni Ajara Tootọ; Ọlọrun Baba si ni Oluṣọgba, tabi Olutọju, Johannu 15:1; Efesu 4:21

2 A wẹ awọn ẹka mọ ki wọn ki o le so eso pupọ, Johannu 15:2; Galatia 5:22, 23

3 A sọ awọn ọmọ-ẹyin di mimọ nipa Ọrọ ti Jesu ti sọ, Johannu 15:3; 1 Peteru 1:22

II Awọn Ẹka ni lati maa Gbé inu Ajara

1 Bi ẹká ba n gbé inu ajara nikan ṣoṣo ni eso le wà, Johannu 15:4, 5

2 A fi ipo ati igbẹyin ẹká ti kò ba n gbe inu ajara hàn, Johannu 15:6; I Johannu 2:6; II Peteru 2:20

3 Adura n gbà, a si n yin Baba logo nipa gbigbe ti a n gbé inu Ajara, Johannu 15:7, 8; Orin Dafidi 91:1, 15; I Johannu 3:22

III Okun Ifẹ ti o wà Laaarin Kristi ati awọn Ọmọ-ẹyin Rè̩

1 Pipa Ofin Ọlọrun mọ ni yoo jẹ ki a le pa ifẹ Rè̩ mọ ninu ọkàn wa, Johannu 15:9, 10; I Johannu 3:24

2 Olori ofin Kristi ni pe ki a fẹran Rè̩, ki a si fẹran ara wa, Johannu 15:11-14

3 Kristi ni o yàn awọn ọmọ-ẹyin, ki i ṣe awọn ọmọ-ẹyin ni o yàn Kristi, Johannu 15:15-17; 8:31

IV Awọn Ọmọ-ẹyin ati Ikorira ti Araye ni si Wọn

1 Aye korira Jesu ki o to korira awọn omọ-ẹyin Rè̩, Johannu 15:18, 19; I Johannu 3:1

2 Jesu rán wa leti pe, “ọmọ-ọdọ kò tobi ju oluwa rè̩ lọ”, Johannu 15:20, 21; 13:16

3 Gbogbo awọn oninunibini Jesu ni o jẹbi, wọn kò si le ṣe awawi, Johannu 15:22-27; Owe 29:1

Notes

Apejuwe daradara ti Jesu ṣe nipa ajara ati ẹká n fi iṣọkan ti Ẹmi ti Kristi ni pẹlu awọn eniyan Rè̩ hàn. O n sọ gẹgẹ bi Oun ti jẹ si wọn bi orisun iyè ati agbara.

Ajara Tootọ ati Adamọ-di Ajara

Nigba ti Jesu wi pe, “Emi ni ajara totọ”, O n fi hàn pato pe awọn ajara miiran wà ti ki i ṣe ajara tootọ. Awọn ajara ti ki i ṣe ajara tootọ le ni ewe pupọ, ewe wọn si le dabi ẹni pe o lẹwa pupọ ni oju eniyan. S̩ugbọn eso iwa mimọ ati ododo kò si lori wọn. Ninu Ajara Tootọ nikan ni a ti le ri iwa-mimọ ati ododo, awọn ohun ti o jé̩ kò-ṣee-mani fun wiwà laaye nipa ti ẹmi, ti o si le jẹ ki awọn ẹká so eso ti Ẹmi ti i ṣe ifẹ, ayọ, alaafia, ipamọra, iwa pẹlẹ, iṣoore, igbagbọ, iwa tutu ati ikora-ẹni-nijanu.

Ọpọlọpọ ẹsìn ti o wà lode oni ni o kún fun aṣehàn ati eto isìn, ṣugbọn wọn kò ni Ajara Tootọ nì ti i ba fun wọn ni Ẹmi iyè. “Igi-àjara wọn, ti igi àjara Sodomu ni, ati ti igbé̩ Gomorra: eso-àjara wọn li eso àjara orõro, idi wọn korò: ọti-waini wọn, iwọ ti dragoni ni, ati oró mimu ti pamọlẹ” (Deuteronomi 32:32, 33). Wo iyatọ ti o wà ninu awọn eso mejeeji! Njẹ eniyan a maa ká eso-àjara lori è̩gun ọgàn, tabi eso ọpọtọ lara ẹwọn? Bẹẹ kọ. Ajarà kan ṣoṣo ni o wà ti o le so eso tootọ, a kò si le ṣe ayederu ẹká tabi eso Àjara yii.

Ipo awọn Ẹká

Awọn ẹka kan le jẹ eleso ki awọn miiran si jẹ alaileso. Eyi wà lori bi ẹka kọọkan ti faramọ àjara to. Nigba ti a ba lọ awọn ẹká miiran sinu àjara, wọn a fi apẹẹrẹ yiyè hàn ṣugbọn lai pẹ wọn a rọ, wọn a si kú lai so eso rara. Awọn ọmọ-ẹyin Kristi bẹẹ gẹgẹ yoo le so eso ẹmi nitori pe wọn fara mọ Ajara timọtimọ wọn si n gba agbara lọdọ Ọlọrun wọn. Bi wọn kò ba fara mọ Ajara timọtimọ, wọn ki yoo le so eso fun Ọlọrun, bi o ti wu ki ifarahàn wọn lode ti dara to. Idapọ ode-ara lasan ni eyii. Wọn kò gba iyè tabi agbara lati ọdọ Ọlọrun.

Ẹká ti yoo maa so eso yoo wà lara ajara yoo si fara mọ ọn timọtimọ. Iyè ti o ni ni eyi ti n ti inu ajara jade lọ sinu ẹya ẹka gbogbo. Olukuluku ewé ati ẹká ni o n gba oje, lọna bayii wọn kún fun iyè. Awamaridi ohun ijinlẹ nì ti a n pe ni iyè wà ninu ajara, awa tikara wa si ti mọ a si ti ri i pe bi ẹká kò ba fara mọ ọn timọtimọ, ki yoo si eso. Ìbi titun ti Jesu ṣe alaye rè̩ fun Nikodemu n so wa pọ pẹlu Ọlọrun -- ẹká pẹlu Ajara – nipa eyi ti awa n ri iyè gbà. Gbogbo wa ni a ti kú sinu aiṣedeedee ati è̩ṣẹ ṣugbọn a sọ wa di aaye nipa lilọ wa sinu Ajara Tootọ, a si sọ wa di alabapin Ẹda Ọlọrun. Awa wa laaye nitori ti a ti so wa pọ pẹlu Orisun Iyè a si n gbà ounjẹ ati agbara wa lati inu orisun nì ti ki i gbẹ.

Irẹpọ kan wà laaarin àjara ati ẹká iru eyi ti ọgbọn ati oye ẹda kò le mu wa. Ninu ẹgbẹ awọn ẹlẹsìn, awọn eniyan le gbé eto kalẹ ki wọn si yan awọn àgbààgbà, awọn diakoni, ati awọn igbimọ oriṣiriṣi ki wọn si ṣe ilana awọn ofin lati ṣe akoso gbogbo ijọ; ṣugbọn kò si ọkan ninu awọn eto wọnyii ti o le so ni pọ mọ Ajara. Ẹ wo bi Eto Ọlọrun ti jẹ iyanu to, nitori pe ironupiwada bi ọmọ kekere, ibinujẹ ẹni iwa-bi-Ọlọrun fun è̩ṣè̩, ati igbagbọ ninu Ẹjẹ Jesu Kristi yoo so ọkàn kọọkan mọ Ajara Tootọ nì.

Wiwẹ Ẹká Mọ

Jesu ni Ajara Tootọ, Ọlọrun Baba si ni Oluṣọgba tabi Olutọju. “Gbogbo ẹká ninu mi ti kò ba so eso, on a mu u kuro: gbogbo ẹká ti o ba si so eso, on a wẹ ẹ mọ, ki o le so eso si i.” Gbogbo oluṣọgba rere ni ọgba ajara rè̩ kún loju. O n fẹ ki o so eso ti o dara ju lọ. O n fẹ ki o lẹwa ki o lagbara ki o si so eso ọpọlọpọ. Bakan naa ni Oluwa ṣe ni ifẹ si awọn eniyan Rè̩ -- Ọgba Ajara Rè̩. Kì i ṣe kiki ki o so eso nikan, ṣugbọn ki o so eso lọpọlọpọ, eso ti o dara ju lọ. O n fẹ ki o jẹ aṣoju Oun, ki o si maa mu iyìn ati ọlá wa fun Un.

Iṣẹ oluṣọgba ni lati wẹ ọgba ajara mọ. Ni ṣiṣe bayii oun a gé ohunkohun sọnu ti yoo di ẹká kọọkan lọwọ lati so eso ti o dara ju lọ. Bi a ba wo olutọju ajara bi o ti n ge ẹká ajara kuro, o dabi ẹni pe kò ni aanu, ṣugbọn oun mọ ohun ti oun yoo gé ati ibi ti oun yoo ti ge e lati mu ajara naa so eso si i. Oluwa n wo ọkàn wa, O si mọ ọna ati akoko ti o tọ lati fi àyè silẹ fun iyiiriwo, idanwo ati inunibini ti yoo mu gbogbo aṣeju tabi ohun gbogbo ti yoo di wa lọwọ kuro, ki Oun ki O le sọ wa di ẹka eleso.

Jesu wi pe, “Ni yiyara nyin kuro lọdọ mi, ẹ ko le ṣe ohun kan.” Eyi fi hàn gbangba pe bi ẹni kan kò ba n gbe inu Kristi, gbogbo iṣẹ rere rè̩, gbogbo itọrẹ-aanu ati gbogbo isin rè̩, yoo jasi asan. Gbogbo awọn wọnyi dabi afomọ ti o n gba agbara lọwọ igi, ti ki i si jẹ ki ẹka so eso. A kò si gbọdọ gbagbe pe ọkàn ni Oluwa n wo, ki i si ṣe ode-ara. Oun mọ aini wa; bi a ba si gbà lati duro labẹ itọju ati itọni Rè̩, Oun yoo ṣe wa pé gẹgẹ bi ọgbọn awamaridi Rè̩ ba ti ri i pe o dara ju lọ fun wa ati fun ijafafa wa ninu isin Rè̩. A ni lati gbe ara wa le E lojoojumọ. A kò lagbara kan ninu ara wa. Ninu Rè̩, ani ninu Rè̩ nikan ni a gbé le so eso. Ti awa ba duro ninu ifẹ Rè̩ ti a si n pa ofin Rè̩ mọ, a o maa so eso. Bi a ba si ti so eso pọ tó, bẹẹ ni ayọ wa yoo ti kún to ni ọjọ nì nigba ti Oun yoo pada wa lati gba awọn ti Rè̩.

Ẹka ti a Gbé Sọnu

A ka a pe: “Bi ẹnikan kò ba gbé inu mi, a gbe e sọnu gẹgẹ bi ẹka, a si gbẹ.” Oluwa n kọ wa nihin ni ọna ti o le ye ni dajudaju pe o ṣe e ṣe fun eniyan lati fara mọ Oun timọtimọ gẹgẹ bi ẹká ti ri lara igi, sibẹ nigbooṣe ki a ge e sọnu ki a si wọ ọ sinu ina. A n kọ ni nihin pe kikuro ninu Rè̩ tabi ṣiṣe aini ibarẹ timọtimọ ni o mu eleyi wa; abayọri si rè̩ ni pe ẹni naa kò ni le so eso fun ogo Ọlọrun.

Kò si ẹni ti o le ge ẹká kuro lara igi, bi ẹka naa kò ba ti wá lara igi tẹlẹ ri. S̩ugbọn a ri i nihin pe o ṣe e ṣe ki a ti wà lara Ajara nigba kan ri, ṣugbọn lẹyin naa ki a tun ge ẹni naa kuro ki a si wọ ọ ju sinu ina ki o si jona – iyapa kuro lọdọ awọn eniyan Ọlọrun, kuro lọdọ Ọlọrun tikara Rè̩ ati kuro ninu gbogbo ogo Ọrun.

O ṣe e ṣe ki a jẹ Onigbagbọ, ki a si ti gbe igbesi-aye ẹni-iwabi-Ọlọrun, ki a si jẹ ajogun iyè ainipẹkun ti a n fi fun gbogbo awọn ti o ti ni igbala tootọ, ki a si sọ igbala naa nu. A le wà lai sọ ọ nu. Kò ṣe anfaani lati duro ninu ipo ainireti ti oluwarẹ ba ti sọ ọ nu. Ọrọ Mimọ Ọlọrun kún fun apẹẹrẹ awọn ti o ti ni igbala Ọlọrun tẹlẹ ri ti wọn si ti sọ ọ nu, ṣugbọn ti a tun mu pada bọ sipo nipa gbigbadura ironupiwada bi wọn ti ṣe nigba ti wọn kọ ri i gbà niṣaaju.

Otitọ ni pe ọmọ Ọlọrun ki i dẹṣẹ. Otitọ Ọrọ Ọlọrun si ni pe bi o ba dẹsẹ oun ki i ṣe ọmọ Ọlọrun mọ bi kò ṣe ọmọ eṣu. Ẹni ti o ba n pe ara rè̩ ni Onigbagbọ ti o ba n dẹṣẹ ki i ṣe Onigbagbọ rara nitori aworan Satani wà ninu rè̩ dipo ki o wà ninu ẹbi Ọlọrun.

Ọlọrun yoo pa wa mọ bi a ba sun mọ Ọn. Oun ki yoo jẹ ki ohunkohun ki o yà wa kuro ninu ifẹ Rè̩, itọju Rè̩, ireti iyè ainipẹkun Rè̩ ati ọrọ ikiya Rè̩ ojoojumọ, bi awa ba “ngbe inu ajara.” S̩ugbọn ti a ba mọọmọ dẹṣẹ lẹyin ti a ti gbà imọ Otitọ nì, bi oore-ọfẹ Ọlọrun ti o n mu igbala wa si ti ṣiṣẹ ninu ọkàn wa, ẹbọ nì ti o ti wà ninu ọkàn wa lẹẹkan ri ki yoo duro ninu ọkàn wa mọ, a ki i si ṣe ẹbi Ọlọrun mọ.

Irẹpọ ati Iṣọkan ninu Ajara

Jesu pe awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ ni ọrẹ Rè̩. Wọn ki i ṣe ọmọ-ọdọ Rè̩ mọ. Jesu wi pe ọmọ-ọdọ kò le mọ eto tabi ohun ti oluwa rè̩ fẹ. Aṣẹ ti a ba pa fun un nikan ni o n mu ṣẹ. Eyi yatọ nipa ọrẹ, nitori oun jẹ korikosun fún ni, o si jẹ ẹni ti a le fi aṣiiri wa pamọ si lọwọ.

Itan ifẹ ti o wà laaarin Dafidi ati Jonatani jẹ iyanu fun ni. Ifẹ ti Jonatani ni si Dafidi mu ki o bọ ẹwu oye rè̩ kuro ki o si fi wọ Dafidi, nigba ti o yẹ ki Jonatani le ronu pe oun ni ẹwu oye naa tọ si bi ofin. Ifẹ kan tun wà laaarin awọn ọmọ Ọlọrun tootọ ti o so wọn pọ bi ẹni kan ninu Kristi. Ifẹ yii kọja ohun ti a le ṣe apejuwe. S̩ugbọn Jesu ni ifẹ ti o pọ ju eleyi nitori O fi ẹmi Rè̩ lelẹ fun awọn ọta Rè̩.

Awọn Ẹni ti a Yàn

O jẹ aṣa laaarin awọn Ju fun eniyan lati yàn olukọ ti o ba fẹ bẹrẹ iṣẹ igbesi-aye rè̩. Bakan naa ni o ri laaarin awa naa pẹlu. S̩ugbọn Jesu wi fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ pe awọn kọ ni o yàn Oun nigba ti wọn jẹ ipe Rè̩ ti wọn si n tẹle E. O ni Oun ni o yan wọn ti Oun si fi wọn sipo, lati lọ ati lati so eso. A pe wọn lati jẹ ẹlẹri fun Un. Bakan naa ni o ri fun awa naa pẹlu.

Jesu fi eyi kún un pe bi ayé ba korira wọn, wọn kò gbọdọ jẹ ki ọkàn wọn ki o dàru, nitori o ti korira Oun ṣaaju. O wi pe bi aye ba ṣe inunibini si wọn ki wọn ranti pe a ti ṣe inunibini bẹẹ si Oun ṣaaju. O mọ pe yoo jẹ itunu fun wọn lati mọ pe nigbà ti inunibini ba dide si wọn, pe wọn wà ni ipa ọna tootọ nitori pe wọn n tọ ipa ọna ti Jesu rin. Nipa awọn inunibini bẹẹ wọn le mọ pe wọn wà ninu Ajara Tootọ sibẹ.

Ẹ Fẹran Ara Yin

“Eyi li ofin mi, pe ki ẹnyin ki o fẹran ara nyin, gẹgẹ bi mo ti fẹràn nyin.” Gẹgẹ bi a ti mọ, eyi ni ofin ikẹyin ti Jesu fi fun awọn ọmọ-ẹhin Rè̩ ki a to kan An mọ agbelebu. O fun wọn ni ofin yii gẹrẹ ki O to lọ si Ọgba Getsemane lọ gbadura. Lati inu Ọgba nì ni O ti lọ si gbọngan idajọ.

O daju pe akoko ìkẹyìn yii ati ọrọ aikú ti Jesu sọ fidi-mulẹ ṣinṣin ninu ọkàn Johannu Ayanfẹ. Ọrọ ifẹ si ẹni keji jé̩ koko pataki ninu awọn Episteli ti o kọ. Lemọlemọ ni o n wi pe ki wọn ki o fẹran ara wọn. Ọkan ninu awọn eniyan mimọ igba nì sọ bayii pe: “Ofin yii jinlẹ ni ookan-àya onihinrere yii (Johannu Ayanfẹ) to bẹẹ nigba ogbo rè̩, nigba ti awọn eniyan mimọ n gbé e lọ si ipejọpọ awọn onigbagbọ, ohun ti o n tẹnu mọ nigba gbogbo ni pe, ‘Ẹnyin ọmọde, ẹ fẹran ara nyin.’ Nigba ti gbigbọ ọrọ yii nigbakuugba sú awọn ọmọ-ẹyin rè̩, wọn beere idi rè̩ ti o fi n tẹnu mọ ohun kan naa gbọnmọgbọnmọ to bẹẹ, o si dahun pe, ‘Nitori pe, ofin Oluwa ni, pipamọ rè̩ nikan si tó.’”

Orisun ifẹ naa kò si ninu ẹká bi kò ṣe ninu Ajara. Ẹká ni lati so pọ timọtimọ mọ Ajara ki oje ifẹ ti Ọlọrun ki o le ṣàn ninu rè̩ ni kikún, “Nipa eyi ni gbogbo enia yio fi mọ pe, ọmọ-ẹhin mi li ẹnyin iṣe, nigbati ẹnyin ba ni ifẹ si ọmọnikeji nyin” (Johannu 13:35).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Ta ni a fi pe Ajara, awọn ẹká ati Oluṣọgba?

  2. 2 Ọna wo ni a le gbà so eso?

  3. 3 Ọna wo ni a n gba wè̩ wa mọ lati so eso si i?

  4. 4 Ki ni yoo ṣẹlẹ bi ẹká kan kò ba so eso?

  5. 5 Njè̩ o ṣe e ṣe ki eniyan ni igbala lẹẹkan ki o tun ṣegbe lẹyin naa?

  6. 6 Sọ ohun meji ti Jesu pe awọn ọmọ-ẹyin Rè̩?

  7. 7 Ki ni ofin Kristi ti o tobi ju?