Johannu 16:1-33

Lesson 237 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹniti o ba gbà mi gbọ, iṣẹ ti emi nṣe li on na yio ṣe pẹlu; iṣẹ ti o tobi jù wọnyi lọ ni yio si ṣe; nitoriti emi nlọ sọdọ Baba” (Johannu14:12).
Cross References

I Ọrọ Ikilọ

1 Jesu kilọ fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ ki wọn má ba kọsẹ lara Rè̩ nitori gbogbo awọn iṣoro ti yoo dé, Johannu 16:1; 15:11; Matteu 11:6; 26:31; Marku 14:27; Sẹkariah 13:7

2 Jesu sọ asọtẹlẹ pe a o ṣe inunibini si wọn titi de oju ikú, Johannu 16:2; Matteu 10:17, 18; 24:9, 10; I Kọrinti 4:11-13; Ifihan 2:10

3 Jesu sọ fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ pe a o ṣe inunibini si wọn nitori awọn eniyan buburu ti kò mọ Ọlọrun, Johannu 16:3; 15:21; II Timoteu 4:14, 15

II Ileri Olutunu

1 Jesu ṣe ileri pe Oun yoo ran Olutunu lati ọdọ Baba, dipo ara Rè̩, lẹyin ti Oun ba ti lọ, Johannu 16:7; 14:16, 17, 26; 15:26; Luku 24:49

2 Olutunu naa yoo si maa tọ Ijọ Ọlọrun, yoo maa tu U ninu, yoo maa kọ Ọ, yoo si maa ba iṣẹ Ọlọrun lọ fun igbala ọkàn ninu aye, Johannu 16:8-15

3 Olutunu naa yoo gbà ninu ohun ti Ọlọrun, yoo si fi han awọn onigbagbọ, Johannu 16:12-15; Efesu 1:13, 14, 17, 18; Nehemiah 9:20; I Kọrinti 2:13; I Johannu 2:27; Ifihan 1:10; Luku 12:12

III Lilọ Jesu Mu Ibanujẹ Wa

1. Ọrọ ti Jesu sọ nipa lilọ Rè̩ daamu awọn ọmọ-ẹyin, Johannu 16:4-6, 16-19; 3:8; Oniwasu 11:5

2 Jesu ṣe ileri fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ pe a o sọ ibanujẹ wọn di ayọ, Johannu 16:20-23; Luku 24:17-35; Orin Dafidi 45:14, 15; Isaiah 61:3

3 A ṣeleri itunu Ọlọrun fun ọjọ ibi ti o n bẹ niwaju, Johannu 16:24-33; II Kọrinti 1:3-6

Notes

Ọrọ Idagbere

Bi kókó idi ti Jesu fi wa si aye ti n sunmọ tosi, eyi ti i ṣe ikú ati ajinde Rè̩, o di ọranyan fun Un lati fi òye ye awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ si i nipa iṣẹlẹ nla yii. O ti sọ fun wọn ṣaaju pe Oun yoo kú ṣugbọn òye ohun ti O wi kò ye wọn. Ọrọ ti Jesu n sọ nigbakuugba nipa ikú Rè̩ bẹrẹ si i ba awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ ninu jẹ, nitori naa Jesu bẹrẹ si i gbà wọn niyanju lati le mu aṣiro ati ibinujẹ wọn fuyẹ. Oun ni Ẹni ti o ti n fi òye ye wọn nipa Ijọba Ọrun. Oun ni Oluwa ati Ọba wọn; ati lai si Rè̩, gbogbo ireti ati imisi kò si mọ fun wọn. Jesu mọ ọna ti o dara ju lọ lati ran wọn lọwọ, nitori naa ni O ṣe ba wọn sọrọ nipa ohun ti o n bọ wa ṣẹlẹ lai pẹ.

O sọ otitọ fun wọn nipa ohun ti o n bọ wa ṣẹ ati ohun ti wọn yoo fara da ni ọjọ iwaju. “Ogun agbọtẹlẹ ki i pa arọ,” Jesu fẹ ki awọn ọmọ-ẹyin Rẹ wa ni imurasilẹ. Jesu sọrọ pupọ lati fi ohun ti o n bẹ niwaju wọn ye wọn. O si wi pe, “Nkan wọnyi ni mo ti sọ fun nyin, pe nigbati wakati wọn ba de, ki ẹ le ranti wọn pe, mo ti wi fun nyin.” (Ka Johannu 16:4; 15:18-27).

Bi ẹrọ ti o n wọn afẹfẹ (baromẹta) ba fi han atukọ oju-omi pe igbi yoo ja, atukọ naa yoo mura silẹ de igbi naa. Ikilọ ti a ti ṣe fun un pe igbi yoo ja yoo jẹ ki o wà ni imurasilẹ, bẹẹ ni lai si agbọtẹlẹ yii, aimurasilẹ rè̩ le mu ki ọkọ rè̩ ati ẹmi oun paapaa ṣegbe. Bakan naa ni o ri fun ọmọ Ọlọrun. Bi o ba ti gbọ ikilọ lati inu Ọrọ Ọlọrun nipa ibinu Ọlọrun ti o rọ dẹdẹ sori aye, yoo bẹrẹsi mura silẹ fun ohun ti o n bọ wa ṣẹlẹ.

Imọtẹlẹ ati otitọ nipa ohun ti yoo ṣẹlẹ ninu aye, gẹgẹ bi Ọrọ Ọlọrun ti fi hàn, kò dẹruba Onigbagbọ. Yatọ si eyi, igbagbọ rè̩ ninu Ọlọrun yoo pọ si i nitori pe Ọlọrun ti fi otitọ hàn an, eyi si fun un ni ikiya ati agbara. Igbesi-aye le kún fun iṣoro pupọ, fun Onigbagbọ pẹlu; sibẹ o mọ pe otitọ ni Ọrọ Ọlọrun, ati pe ti oun ba jẹ olootọ, Ọlọrun yoo mu oun gunlẹ lai lewu. (Ka Orin Dafidi 107:23-30).

Ileri Baba

Jesu mọ pe ọrọ iyanju nikan kò to lati ki awọn eniyan Rè̩ laya nipa idanwo ti o wà niwaju wọn; nitori naa O sọ fun wọn nipa “Olutunu” ti o n bọ wa tu awọn eniyan Ọlọrun ninu. (Ka Johannu 16:7; II Kọrinti 3:6). Olutunu yii ni Ẹni Kẹta ninu Mẹtalọkan -- Ẹmi Mimọ. Oun ni yoo jẹ orisun imisi ati itunu fun wọn nigba ti Jesu ba lọ. Jesu sọ fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ pe yoo jẹ anfaani fun wọn ti Oun ba lọ, nitori bi Oun kò ba lọ, Olutunu naa ki yoo tọ wọn wa. Nitori naa bi awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ ti n banujẹ nitori pe Jesu kò nì wà lọdọ wọn mọ ninu ara, a tù wọn ninu nipa ileri yii pe a ki yoo fi awọn nikan silẹ. Ileri Olutunu ati imọtẹlẹ ohun ti yoo ṣẹlẹ ni igbesi-aye wọn, di orisun agbara ati imisi fun wọn ti o ran wọn lọwọ lati fara da gbogbo inunibini ati lati jere iye ainipẹkun nikẹyin. Imọ ohun ti Jesu ti sọ fun wọn nipa nnkan wọnyi jẹ apata ti ohunkohun kò le wo lulẹ.

Olukọ lati Ọrun

Ọrọ Ọlọrun sọ fun wa pe iṣẹ Ẹmi Mimọ ni lati maa ṣamọna, lati tọ ni ati lati maa kọ Ijọ Kristi nipasẹ awọn alakoso ti Ọlọrun yàn. Kò ti i si ijọ aye, ẹgbẹ tabi akojọ eniyan tabi ẹni kan ti o ti da iru ẹkọ Ọrọ Ọlọrun bẹẹ silẹ – tabi ti o le ṣe e laelae. Iṣẹ pataki ti Ẹmi Ọlọrun nikan ṣoṣo n ṣe ni eyi, ki i si i ṣe ti ẹlomiran. Ẹmi Mimọ ni Olukọni ti ki i ṣina, Oun si ni Olufihan eto igbala nla Ọlọrun fun awọn alufa Ijọ Rè̩ ati fun awọn eniyan mimọ.

Johannu Ayanfẹ sọ nipa Ẹmi Mimọ yii ti yoo jẹ olukọ awọn eniyan Ọlọrun: “S̩ugbọn ifororó-yàn ti ẹnyin ti gbà lọwọ rè̩, o ngbe inu nyin, ẹnyin kò si ni pe ẹnikan nkọ nyin: ṣugbọn ifororó-yàn na nkọ nyin li ohun gbogbo ti o jẹ otitọ, ti kì si iṣe èké, ani gẹgẹ bi o si ti kọ nyin, ẹ mā gbe inu rè̩”. (Ka I Johannu 2:27; Isaiah 8:20; Nehemiah 9:20; I Kọrinti 2:13).

A kò gbọdọ gbagbe pe ọna ti o ṣe pataki ju ti Ẹmi Mimọ n gbà lati kọ awọn eniyan Ọlọrun ni nipasẹ Bibeli. Ọlọrun gbé Ọrọ Rè̩ ga ju orukọ Rè̩, a si kà nipa eyi pe, “Nitori iwọ gbé ọrọ rẹ ga jù gbogbo orukọ rẹ lọ” (Orin Dafidi 138:2). Ẹmi Ọlọrun ki i ṣe lodi si Ọrọ Ọlọrun, Iwe Mimọ si jẹri si eyi. “Si ofin ati si ẹri: bi nwọn kò ba sọ gẹgẹ bi ọrọ yi, nitoriti kò si imọlẹ ninu wọn ni” (Isaiah 8:20). Siwaju si i Ẹmi ati Ọrọ kò le ṣe lodi si ara wọn: “Nitoripe ẹni mẹta li o njẹri li ọrun, Baba, Ọrọ ati Ẹmi Mimọ: awọn mẹtẹta yi si jasi ọkan” (I Johannu 5:7).

Olutunu ni Ẹni ti o n fi Ọrọ Ọlọrun ye ẹnikẹni ti o ba fetisilẹ, yoo si sọ igbagbọ rè̩ ninu Ọlọrun di lile, ki o le gbagbọ si igbala. Jesu wà lọdọ awọn ọmọ-ẹyin lati sọ igbagbọ wọn di lile nipa imọran Rè̩, ọrọ iṣiri Rè̩ ati awọn iṣẹ iyanu nlá nlà; Ẹmi Mimọ n bẹ lọjọ oni lati ṣe ohun kan naa fun awọn onigbagbọ.

Lai si aniani, ọpọ awọn Onigbagbọ ni yoo ti ro ninu ọkàn wọn nigba kan tabi nigba miiran pe i ba dùn mọ wọn lọpọlọpọ bi wọn ba wa laye ni akoko ti Jesu Kristi, ki wọn si fi oju wọn ri awọn ohun nla ti O ṣe. Wọn n wò iru imisi nla ti wọn i ba ni nipa riri Jesu lojukoju. Nitori pe ki iru imisi yii ba le wa lẹhin igoke-re-Ọrun Kristi, Ọlọrun ran Olutunu wa lati maa ba eniyan gbe. Gẹgẹ bi Jesu ti jẹ imisi fun awọn eniyan ti n bẹ nigba aye Rè̩, bakan naa ni Ẹmi Mimọ jẹ fun awa Onigbagbọ lọjọ oni. Jesu sọ bayii nipa Olutunu, “Nitoriti yio gbà ninu ti emi, yio si ma sọ ọ fun nyin. Ohun gbogbo ti Baba ni temi ni: nitori eyi ni mo ṣe wipe, on ó gbà ninu temi, yio si sọ ọ fun nyin” (Johannu 16:14, 15).

Tomasi kò gbà ẹri awọn ọmọ-ẹyin iyoku gbọ pe Jesu jinde kuro ninu okú. Igba ti Tomasi ri Jesu lojukoju ni o to gbagbọ pe Jesu wa laaye. Jesu wi fun un pe, “Alabukun-fun li awọn ti kò ri, ti wọn si gbagbọ” (Johannu 20:29). Bi o tilẹ jẹ pe awa kò ri Jesu lojukoju, awa ti gbọ ohun Ẹmi Ọlọrun, awa si ti gbà ohun ti Ẹmi Mimọ fi hàn wa nipa Kristi gbọ.

Ẹri Ogún Wa

A ni lati mọ pe iriri idariji è̩ṣẹ -- eyi ti i ṣe ipo idalare niwaju Ọlọrun; ati ibukun isọdimimọ patapata -- iṣẹ oore-ọfẹ keji ninu ọkan Onigbagbọ, kọ ni o n mu Olutunu nì, ti Jesu ti ṣeleri wọ inu ọkàn wa. Ẹmi Ọlọrun ni o ba ẹni ti o gbagbọ jẹri pe a ti gba ọkàn rè̩ la ati pe o ti di ọkan ninu awọn ọmọ agbo-ile igbagbọ. (Ka Romu 8:14-16; II Kọrinti 1:22; I Johannu 5:6-10). Ẹmi Ọlọrun bakan naa n jẹri si isọdimimọ wa, a si n ṣe alabapin agbara Ẹmi Ọlọrun ati itanṣan Rè̩ ju ti atẹyinwa lọ. (Ka I Kọrinti 2:12, 13; II Tẹssalonika 2:13; I Peteru 1:12). S̩ugbọn ni akoko ti a ba fi Ẹmi Mimọ wọ ni gẹgẹ bi iriri ti Bibeli ni Olutunu to wá lati maa gbe tẹmpili ara ati ọkan eniyan. Aṣẹ ti Jesu pa fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ lẹhin Ajinde Rè̩ fi eyi hàn gbangba: “Si kiyesi i, Mo rán ileri Baba mi si nyin: ṣugbọn ẹ joko ni ilu Jerusalẹmu, titi a o fi fi agbara wọ nyin, lati oke ọrun wá” (Luku 24:49). Awọn ọmọ-ẹyin gbọran si aṣẹ yii; bi wọn si ti duro ninu adura ni Ọjọ Pẹntikọsti, wọn gba Olutunu nì. (Ka Iṣe Awọn Apọsteli 2:1-21).

Bi awọn ọgọfa eniyan ti o pejọ si yara oke ti ri Ẹmi Mimọ gbà ko yatọ si asọtẹlẹ Joẹli. (Ka Joẹli 2:28, 29). Jesu wi pe Ẹmi Mimọ yoo wa sọdọ gbogbo ẹni ti o ba fẹ Ẹ, Peteru si fi idi eyi mulẹ ninu iwaasu rè̩ ni Ọjọ Pẹntikọsti, ninu eyi ti a kà pe: “Ẹ ronupiwada, ki a si baptisi olukuluku nyin li orukọ Jesu Kristi fun idariji è̩ṣẹ nyin, ẹnyin o si gbà ẹbun Ẹmi Mimọ. Nitori fun nyin ni ileri na, ati fun awọn ọmọ nyin, ati fun gbogbo awọn ti o jina rére, ani gbogbo awọn ti Oluwa Ọlọrun wa ó pe” (Iṣe Awọn Apọsteli 2:38, 39).

Gbigba Ẹmi Mimọ yii ni Paulu n tọka si nigba ti o sọ pe: “Ninu ẹniti, nigbati ẹnyin ti gbagbọ pẹlu, a fi Ẹmi Mimọ ileri ni ṣe edidi nyin, eyiti iṣe ẹri ini wa, fun irapada ohun ini Ọlọrun si iyìn ogo rè̩” (Efesu 1:13, 14).

Ileri Ipadabọ

Jesu kò fi awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ silẹ lai si ireti ati ri I mọ lẹyin ikú Rè̩. O fi ọrọ yii tu wọn ninu: “Nitorina ẹnyin ni ibinujẹ nisisiyi: ṣugbọn emi o tún ri nyin, ọkàn nyin yio si yọ, kò si si ẹniti yio gbà ayọ nyin lọwọ nyin” (Johannu 16:22). A le wi pe ọrọ yii jẹ asọtẹlẹ meji tabi ileri meji. Ki i ṣe pe awọn ọmọ-ẹyin yoo tun ri Jesu lẹyin ajinde Rè̩ nikan, ṣugbọn wọn ó tun ri I gẹgẹ bi yoo ti fara han ni ọjọ nla ajinde nì pẹlu.

Lai pẹ jọjọ, wọn yoo ni ibanujẹ nitori pe Jesu yoo kú lori agbelebu. Iru ikú oro ti Jesu yoo kú yii mu ki ibinujẹ pupọ wọ inu ọkàn wọn gẹgẹ bi O ti sọ fun wọn pe yoo ri; ṣugbọn wọn ni ileri Rè̩ pe ibanujẹ wọn yoo di ayọ, ati pe a ki yoo gbà ayọ naa lọwọ wọn. A mu ileri naa ṣẹ; nitori nigba ti wọn ri i pe O jinde ni tootọ wọn kún fun ayọ pupọ nitori iṣẹgun Rè̩ lori ikú. Lati igbà naa lọ ni ayọ yii ti jẹ ireti ati agbara fun Ihinrere.

Kò si ẹni ti o le gbà ayọ naa kuro lọwọ ọmọ Ọlọrun, nitori pe o mọ pe Oluwa oun wà laaye. Yoo tun pada wa mu awọn ti Rè̩ ti o wa laaye ati awọn olododo ti o ti kú. Ninu gbogbo ẹsin ti o wà laye loni, Ihinrere Jesu Kristi nikan ni o le fọwọ sọya pẹlu idaniloju pe Olulana rè̩ ji dide kuro ninu okú. Ọrọ Ọlọrun, nipasẹ Ẹmi Mimọ, n fun ẹni ti o ba gbagbọ ni ẹri ti o daju nipa igbesi-aye ati ajinde Jesu Kristi. Eyi ni ayọ ti o wà fun gbogbo awọn ti o ba gbà Ihinrere gbọ, gẹgẹ bi o ti wà fun awọn ọmọ-ẹyin Jesu, gẹgẹ bi ileri Rè̩.

Bibeere ati Riri Gbà

Jesu wi pe, “Ohunkohun ti ẹnyin ba bère lọwọ Baba li orukọ mi, On o fifun nyin.” Awa ni anfaani ti o dara ju lọ lati lọ sọdọ Ọlọrun ninu adura, ati ni orukọ Jesu, ki a le beere, ki a si ri ẹbẹ wa gbà lati ọdọ Rè̩. Jesu pari ọrọ idagbere ti o ya ni lẹnu ti o si kún fun imisi yii pẹlu ọrọ ti o jẹ orisun ireti ati agbara nla fun awọn eniyan Ọlọrun: “Nkan wọnyi ni mo ti sọ fun nyin tẹlè̩, ki ẹnyin ki o le ni alafia ninu mi. Ninu aiye, ẹnyin o ni ipọnju; ṣugbọn ẹ tújuka; mo ti ṣẹgun aiye.”

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Ki ni ṣe ti Jesu fi kilọ fun awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ ki wọn ki o maṣe kọsẹ lara Rè̩?

  2. 2 Nibo ni Jesu wi pe inunibini yoo ti dide si wọn?

  3. 3 Ki ni ṣe ti o fi jẹ ọranyan fun Jesu lati lọ?

  4. 4 Ta ni Olutunu naa? Ki ni iṣẹ Rè̩?

  5. 5 Awọn wo ni Olutunu yoo tọ wa?

  6. 6 Ki ni ṣe ti awọn ọmọ-ẹyin fi banujẹ?

  7. 7 Nigba wo ni ibanujẹ wọn yoo di ayọ? Nitori ki ni?