Johannu 17:1-26

Lesson 238 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Ki si iṣe kiki awọn wọnyi ni mo ngbadura fun, ṣugbọn fun awọn pẹlu ti yio gbà mi gbọ nipa ọrọ wọn; ki gbogbo nwọn ki o le jẹ ọkan; gẹgẹ bi iwọ, Baba, ti jẹ ninu mi, ati emi ninu rẹ, ki awọn pẹlu ki o le jẹ ọkan ninu wa: ki aiye ki o le gbagbọ pe, iwọ li o rán mi” (Johannu 17:20, 21)
Cross References

I Jesu Ọmọ Ọlọrun

1 Wakati iṣelogo Kristi nipasẹ ati gẹgẹ bi agbara Ọlọrun Baba, sun mọ tosi, Johannu 17:1; I Peteru 1:18-21

2 Iṣelogo naa yoo yọri si iyè ti kò nipẹkun fun gbogbo awọn ti yoo gba Baba ati Ọmọ gbọ, Johannu 17:2, 3; 3:14-16

3 Jesu gbadura fun idapada ogo Rè̩ ti O ti ni té̩lè̩, Johannu 17:4, 5; Filippi 2:6-9; Heberu 1:3

4 Awọn ọmọ-ẹyin ti gba ọrọ Kristi, nipa bẹẹ a fi ipo Rè̩ gẹgẹ bi Messia hàn fun wọn, Johannu 17:6-8; Matteu 16:13-17

II Adura Jesu fun Ijọ

1 Olugbala bẹ Baba lati pa awọn ọmọ-ẹyin mọ ni iṣọkan ki a si yà wọn kuro ninu aye, Johannu 17:9-11; 10:28, 29; Filippi 4:7

2 Jesu ti pa awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ mọ ni orukọ Baba ati nipa Ọrọ Rè̩, Johannu 17:12-14

3 Awọn ọmọ-ẹyin ni iṣẹ lati ṣe; nitori naa a kò ni mu wọn kuro ninu aye lakoko yii, Johannu 17:15, 16; Filippi 1:23-25

III Isọdimimọ ati bi O ti jé̩ Ohun Pataki To

1 A o ṣiṣẹ Isọdimimọ nipasẹ otitọ Ọlọrun, Johannu 17:17; I Kọrinti 1:30; Heberu 10:10; 13:12, 13

2 Jesu yà ara Rè̩ si mimọ ki awọn ọmọ-ẹyin ba le di mimọ, ki a si wẹ wọn mọ, Johannu 17:18, 19; Efesu 5:25-27

3 Adura ẹbẹ fun isọdimimọ ati iṣọkan wà fun gbogbo ọmọ-ẹyin ti o gbà Jesu gbọ, Johannu 17:20; Iṣe Awọn Apọsteli 10:15, 34, 35; Heberu 2:9-13

4 Iṣọkan Ijọ yoo fi otitọ Kristi hàn fun aye, Johannu 17:21-23; Iṣe Awọn Apọsteli 2:1; 4:13, 14; Romu 12:5

5 Jesu gbadura pe ki Ijọ ti a ti sọ di mimọ ni tootọ le wà pẹlu Rè̩ ninu ogo nikẹyin, Johannu 17:24-26

Notes

Olori Alufa Wa

Ipo woli, alufa ati ọba ti o ti wa lọtọọtọ ni igba Ofin, ni a papọ ṣe ọkan ṣoṣo ninu Jesu Kristi. Olukuluku àyè wọnyi fi iṣẹ kọọkan ti Jesu n bọ wa mu ṣẹ ninu eto Ọlọrun hàn. Woli ni ẹni ti n sọ ọrọ Ọlọrun fun awọn eniyan – eyi ni Jesu mu ṣẹ laaarin ọdun mẹta ati aabọ ti O fi ṣe iṣẹ-iranṣẹ Rè̩ ni aye. Alufa ni ẹni ti Ọlọrun yàn lati jẹ aṣoju awọn eniyan lọdọ Ọlọrun. Ninu adura ẹbẹ iyebiye ti Apọsteli Ayanfẹ kọ silẹ fun wa yii, a fun wa ni aṣiiri ipo keji ninu iṣẹ nla pataki Jesu – eyi ti i ṣe ti Olori Alufa Ọlọrun ati Alagbawi fun ọkàn awọn eniyan. Ọrun ni O gbe n ṣe iṣẹ yii ni ọwọ ọtun Ọlọrun. “Ihaṣe Kristi Jesu ti o kú, ki a sa kuku wipe ti a ti ji dide kuro ninu okú, ẹniti o si wà li ọwọ ọtún Ọlọrun, ti o si mbè̩bẹ fun wa?” (Romu 8:34). Oun yoo bọ si ipo Rè̩ kẹta – ti Ọba – ni igbà ti akoko bibẹbẹ fun wa ba pari. Nigba naa ni a o ṣe Jesu ni Ọba awọn ọba ati Oluwa awọn oluwa, si idunnu awọn aimoye eniyan mimọ Rè̩ ati awọn ẹda Ọrun, ṣugbon si itiju ati idaamu gbogbo awọn ti o ti kọ Jesu ati ipe Ẹmi. A gbàgbọ gidigidi pe ki yoo pẹ mọ ti eyi yoo ṣẹlẹ.

Adura fun Ara Rè̩

Gẹgẹ bi awọn olori alufa ti igbà aye awọn Ọmọ Israẹli ti maa n gbadura fun ara wọn ṣaaju ati lẹyin naa fun awọn eniyan, bakan naa ni Jesu, ti i ṣe pipe imuṣẹ Ofin, bẹrẹ adura ẹbẹ Rè̩ pẹlu adura fun ara Rè̩. Jesu mọ pe wakati naa de ti Oun yoo fi ẹmi Oun iyebiye lelẹ fun è̩ṣẹ gbogbo agbaye. Jesu sọrọ bi ẹni pe wakati naa ti kọja ná; O si ni ẹtọ lati ṣe bẹẹ nitori pe ọkàn Rè̩ lọhun ti san gbese naa. Lati ipilẹṣẹ aye wa ni Ọlọrun ti mọ wakati ati akoko naa ti Jesu yoo jiya, kò si si wakati ti o ni laari bi rè̩ fun gbogbo agbaye. Ibi Jesu jẹ ohun ayọ nla fun awọn ogun ọrun ati awọn ọmọ-eniyan, ṣugbọn ikú Rè̩ fun ẹni ti o ba gbagbọ tọkàntọkàn ni idande kuro ninu è̩ṣẹ. Igba ti a rẹ Kristi silẹ gidigidi ju lọ ni akoko ti a mu ileri irapada Ọlọrun ṣẹ. (Wo Gẹnẹsisi 3:15). Agbara Èṣu di asan nipa ikú iṣẹgun Kristi lori agbelebu. Jesu kò gbadura nitori ijiya, irè̩silẹ ati ègun è̩ṣẹ ti a o gbe ru U lati mu Un san gbese irapada; ṣugbọn O gbadura pe ki a le yìn Ọlọrun Baba logo nipasẹ sisan gbese naa.

Ọna Irapada

È̩ṣẹ dá iyapa patapata silẹ laaarin Ọlọrun ati eniyan, a si ni lati wa ọna nipasẹ eyi ti eniyan yoo tun fi ri oju rere Ọlọrun ti yoo si ni irẹpọ pẹlu Rè̩. Akoko lati rú ẹbọ kan ṣoṣo naa ti o ṣe itẹwọgba fun è̩ṣẹ, eyi ti i ṣe Ẹjẹ Ọmọ Ọlọrun alailẹṣẹ, sun mọ tosi. Jesu gbadura pe ki Baba le ṣe ẹbọ ti o fi Ẹmi Rè̩ rú yii logo, ati nipa bẹẹ ki Baba le di Ẹni ayinlogo lọdọ ọpọlọpọ ọmọ-eniyan ti yoo ri idande ati ododo gbà nipasẹ ẹbọ naa. Nipa ẹbọ yii, awọn ẹni irapada ni ẹtọ lati wa niwaju Ọlọrun nitori ti a ti wẹ ọkàn wọn ninu Ẹjẹ Ọdọ-aguntan. Jesu ni aworan Ọlọrun Baba fun gbogbo agbaye, “itanṣan ogo rè̩ ati aworan on tikararẹ.” Nipa igbagbọ ninu Ọmọ Ọlọrun ati itoye Ẹjẹ Rè̩ ti O ta silẹ, eniyan tun ni anfaani lati mọ Ọlọrun ati lati di ẹbi Rè̩ pẹlu. “Bi Ẹmi ẹniti o ji Jesu dide kuro ninu okú ba ngbe inu nyin, ẹniti o ji Kristi Jesu dide kuro ninu okú yio fi Ẹmi rè̩ ti ngbe inu nyin, sọ ara kikú nyin di āye pẹlu.” “Nitori ẹnyin kò tun gbà ẹmi ẹrú lati mā bè̩ru mọ; ṣugbọn ẹnyin ti gbà ẹmi isọdọmọ, nipa eyi ti awa fi nke pè, Abba, Baba. Ẹmi tikararè̩ li o mba ẹmi wa jẹri pe, ọmọ Ọlọrun li awa iṣe” (Romu 8:11, 15, 16). Imọ Ọlọrun ti Kristi fi hàn fun ni yii, ati idapọ pẹlu Rè̩, ni o n fun gbogbo Onigbagbọ tootọ ni iye ainipẹkun.

Jesu pari adura nipa ara Rè̩ ati Baba pẹlu è̩bẹ fun iṣelogo Rè̩ bi o ti wà ni atetekọṣe. Niwọn wakati diẹ si i Jesu Olubukun yoo pari iṣẹ ti O wa ṣe ni aye. O ranti ibugbe ologo nì, aafin ti o lẹwa wọnni, ati idapọ pẹlu Baba Rè̩, ti O ti fi silẹ lọrun lati wa ṣe iṣẹ yii; ọkàn Rè̩ si n fẹ lati lọ kuro ninu aye ẹkún oun oṣi yii lati tun wà pẹlu Baba.

Adura fun awọn Apọsteli

Jesu wa lati gbà araye là kuro ninu è̩ṣẹ wọn, sibẹ awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ nikan ni O n gbadura fun lakoko yii. Iṣẹ iwaasu Ihinrere yoo di ti awọn ọmọ-ẹyin Jesu nigba ti O ba fi ayé silẹ lọ sọdọ Baba, o si ṣe dandan pe ki awọn ọmọ-ẹyin naa le ni gbogbo ihamọra fun iṣẹ ti a pe wọn si. Awọn ọmọ-ẹyin Jesu ti o wa di Apọsteli ni O n ba sọrọ yii ni pataki nitori iṣẹ wọn ni lati pa Ọrọ Ọlọrun mọ, lati kede Ọrọ naa ati lati waasu Ihinrere ti Jesu mu wa si ayé.

Jesu sọ pato pe Oun ti fi Baba hàn fun awọn eniyan ti a ti fi fun Oun lati inu ayé. Jesu ti pa awọn ọmọ-ẹyin wọnyi mọ ni orukọ Baba; ṣugbọn ni akoko ti O fẹ fi wọn silẹ yii, O n gbadura pe ki Ọlọrun ki o le fun wọn ni agbara, ki O si pa wọn mọ ninu Ihinrere, nitori Oun ki yoo wà pẹlu wọn mọ ninu ara ni ayé. Awọn ti wọn ti n kẹkọ lẹsẹ Kristi fẹrẹ di olukọ, lati maa kọ ni ni ẹkọ Kristi, Jesu si n fẹ ki Ọlọrun fun wọn ni oore-ọfẹ lati doju kọ ati lati bori gbogbo iṣoro ti i ba bi igbagbọ ti wọn ṣẹṣẹ gbà ṣubu.

Aabo awọn Ọmọ-ẹyin

Bi a ba yẹ adura yii wo kinnikinni, a o ri pe o ṣe e ṣe ki eniyan ṣegbe lẹyin ti o ti ni igbala nigba kan ri. Ta ni ha le sọ pe Judasi kò di atunbi nigba kan ri nigba ti Jesu sọ nipa awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ pe “awọn ti iwọ fifun mi, ni mo ti pamọ, ẹnikan ninu wọn kò si ṣègbe bikoṣe ọmọ egbé.” Ọkàn ti o ba fẹ wa labẹ aabo titi ayeraye ni lati ni ironupiwada kikún fun è̩ṣẹ ti o ti dá ki o si maa rin ninu ifẹ Ọlọrun. Eyi ni aṣiiri iṣẹgun awọn ọmọ-ẹyin – “nwọn si ti pa ọrọ rẹ mọ.” Jesu wi pe, “Pa wọn mọ kuro ninu ibi,” ati pe “Nwọn ki iṣe ti aiye, gẹgẹ bi emi ki ti ìṣe ti aiye;” eyi n fi hàn pe wọn n gbe lai lẹṣẹ ninu aye. Gbogbo awọn ọmọ-ẹyin ni Baba fi fun Jesu, Oun si ti pa wọn mọ. A pa awọn mọkanla mọ, nitori wọn n fẹ ki a pa wọn mọ. Judasi si ṣegbe nitori o yan ọna ti ara rè̩ ati è̩ṣẹ. Agbara ti Jesu fi n pa eniyan mọ jẹ iyanu. Ipamọ Onigbagbọ ki i ṣe lọna pe a fi ofin de e mọ Kristi, tabi ki a fi i sinu ahamọ kuro ninu ayé; ṣugbọṅ a fi okùn ifẹ de e. O ṣe e ṣe fun Onigbagbọ lati fi Kristi silẹ nigbakugba, ṣugbọn o n ba Jesu rin nitori ifẹ ti o jinlẹ gidigidi. Onigbagbọ tootọ ni iru ipinnu kan naa ti awọn ọmọ-ẹyin ni nigba ti Jesu wi pe, “Ẹnyin pẹlu nfẹ lọ bị?” (Johannu 6:67). Wọn dahun pe, “Oluwa, Ọdọ tali awa o lọ? iwọ li o ni ọrọ ìye ainipẹkun” (Johannu 6:68). Èṣu a maa rọ Onigbagbọ lati yipada kuro lẹyin Kristi lati wo awọn ohun aye yii ti kò ni laari, ṣugbọn awọn aṣẹgun a maa tẹsiwaju ninu Ihinrere lati sọ ipe ati yiyàn wọn di didaju; nitori pe wọn ri ẹwa Ihinrere ti “o ni ileri ti aiye isisiyi ati ti eyi ti mbọ” (I Timoteu 4:8).

Kò si ẹni ti o le sọ pe awọn ọmọ-ẹyin ti Jesu gbadura fun wọnyi kò ni iyipada ọkàn tootọ. Wọn ti gba Ọrọ Ọlọrun ti Jesu mú wa si aye, wọn si ti pa a mọ; wọn ti gba Jesu gbọ gẹgẹ bi Ọmọ bibi kan ṣoṣo ti Ọlọrun. Wọn kì i ṣe ti aye mọ, nitori naa ni aye ṣe korira wọn. È̩ri wo ni o tun kù lati fi hàn pe a ti ra awọn eniyan wọnyi pada kuro ninu è̩ṣẹ wọn? Idalare nikan ló lè fun eniyan ni agbara lati gbe igbesi-aye ailẹṣẹ; ṣugbọn Jesu mọ pe awọn ọmọ-ẹyin Rè̩ gbọdọ ni oore-ọfẹ si i lati le gbe igbesi-aye Onigbagbọ ni iṣọkan pẹlu ara wọn, ati lopin aye wọn, ki wọn le ṣetan lati ri Ọlọrun ni Ọrun. O gbadura pe ki a le sọ wọn di mimọ ninu otitọ Ọlọrun. Jesu, ninu àwọ ẹda, ninu igbesi-aye Rè̩, ikú Rè̩, ajinde ati iṣelogo Rè̩ jẹ ẹkún otitọ Ọlọrun.

Isọdimimọ

Isọdimimọ ni iwẹnumọ kuro ninu gbogbo è̩ṣẹ abinibi; o n tu gbongbo è̩ṣẹ, o n pa iṣẹ ara run, o si n pa aworan Adamu run patapata kuro ninu ọkàn. Jesu wi pe, “Alabukún-fun li awọn oninu-funfun: nitori nwọn o ri Ọlọrun” (Matteu 5:8). Isọdimimọ a maa fun ni ni ọkàn funfun ati àyà mimọ ti i ṣe ohun danindanin ti a ba fẹ gbe igbesi-aye iṣẹgun.

Ki ọkàn kan to tọ Ọlọrun wá, oriṣi è̩ṣẹ meji ni o wà ninu ọkàn naa -- è̩ṣẹ amọọmọ dá ati è̩ṣẹ abinibi. Iṣẹ oore-ọfẹ ti o daju n ṣe ninu ọkàn nigba ti Ọlọrun ba da ni lare, nipa eyi ti a dari gbogbo irekọja ji, a si nu un kuro, ọkàn naa a si di ẹda titun ninu Kristi Jesu. Iṣẹ oore-ọfẹ keji ti o daju a tun ṣe ninu ọkàn nigba ti a ba ri isọdimimọ gbà. Nipa eyi ni a fa è̩ṣẹ ti a jogun ba lọdọ awọn obi wa tu ti a si pa a run. Ọlọrun ni lati tún eniyan bi ki ẹni naa si bọ lọwọ ofin è̩ṣẹ ki o to ni anfaani si iṣẹ nla ti isọdimimọ, gẹgẹ bi o ti ri ni igbesi-aye awọn ọmọ-ẹyin ti Jesu gbadura fún.

Eniyan kò jẹbi è̩ṣẹ ajogunba. Kì i ṣe oun ni o dá è̩ṣẹ yii, kò si le ronupiwada pe a bi i bẹẹ. Ọna ti Ọlọrun gbà n mu un kuro ni ọna iwẹnumọ ti a n pe ni isọdimimọ, iwa-mimọ, tabi ifẹ pipé. Nigba ti ẹlẹṣẹ ba di atunbi a o ké awọn eso è̩ṣẹ kuro, eso ti Ẹmi yoo si fara hàn lẹsẹ kan naa; ṣugbọn gbongbo ogbologbo ọkunrin nì wà nibẹ, yoo si maa dá wahala silẹ. A ni lati hu u kuro ki a si pa a run patapata nipa isọdimimọ.

Lọna kan, Isọdimimọ ni iyasọtọ lọna pataki fun iṣẹ-isin; lọna keji ẹwẹ, o jẹ iwẹnumọ ati sisọ di funfun laulau. Eniyan ni ipa ti rẹ lati ṣe, gẹgẹ bi Jesu ti ṣe ya ara Rè̩ si mimọ; lọna miiran a le wi pe, Jesu sọ ifi-ara-rubọ Rè̩ di ọtun fun iṣẹ ti Ọlọrun ti lana rè̩ silẹ fun Un. Ọlọrun ni iṣẹ ti Rè̩ lati ṣe pẹlu, ani fifi Ẹjẹ Kristi wè̩ ọkàn eniyan lẹẹkeji lati pa iṣẹ ti ara run. Nigba ti ifi-ara-rubọ eniyan ba de ogogoro, ti oluwarẹ si n fẹ lati bọ ogbologbo ọkunrin ni silẹ lati ya ara rè̩ sọtọ fun Ọlọrun, ti o si fi tọkantọkan gbẹkẹle Ẹjẹ Jesu, nigba naa a o gbọ adura rè̩ lati Ọrun wa, Ọlọrun yoo si sọ ọkàn rè̩ di mimọ patapata. Ẹni naa ti a ti sọ di mimọ ti o si ya ara rè̩ sọtọ bayi, yoo ni ero bi ti Kristi Jesu ninu rè̩. Akẹkọ kan sọ bayi nipa isọdimimọ, “A le wipe eniyan di pipé ti o ba le ṣe ohun ti Ọlọrun da a fun; gẹgẹ bi Ọlọrun si ti n fẹ ki olukuluku eniyan ki o fẹran Rè̩ pẹlu gbogbo aya, ati gbogbo ọkàn, ati gbogbo inu, ati gbogbo agbara ati ọmọnikeji rè̩ gẹgẹ bi ara rè̩, ẹni pipé ni ẹni ti o ba ṣe bẹẹ -- o ti ṣe ohun ti Ọlọrun n beere lọwọ rè̩.” Nipa iriri isọdimimọ ti a fi Ẹjẹ Jesu ra nikan ni a fi le gbe igbesi-aye mimọ ti Ọlọrun n beere lọwọ wa.

Bi Isọdimimọ ti ṣe Pataki Tó

Isọdimimọ ha n ṣe ohun ti a le pati bi? A ha fi le Onigbagbọ lọwọ lati yàn lati wa isọdimimọ tabi ki o kọ lati wa a? Rara o! Ọlọrun ti pa a laṣẹ fun gbogbo eniyan ninu Ọrọ Rè̩ lati wa oore-ọfẹ iyanu yii. Ọlọrun pasẹ fun Abrahamu pe, “Ma rin niwaju mi, ki iwọ ki o si pé” (Gẹnẹsisi 17:1). O si tun paṣẹ fun awọn Ọmọ Israẹli pé, “Nitoripe Emi li Oluwa Ọlọrun nyin: nitorina ni ki ẹnyin ki o yà ara nyin simimọ, ki ẹnyin ki o si jé̩ mimọ; nitoripe mimọ li Emi” (Lefitiku 11:44). Aṣẹ ti Ọlọrun pa fun awọn ẹni irapada loni kò yatọ. “Eyi ni ifẹ Ọlọrun, ani wiwà ni mimọ nyin” (I Tẹssalonika 4:3). Bawo ni eniyan ṣe le wi pe oun fẹran Oluwa pẹlu gbogbo àyà, pẹlu gbogbo ọkàn, pẹlu gbogbo iyè ati pẹlu gbogbo agbara, ti kò si ni fé̩ lati tẹriba fun ifẹ Ọlọrun?

Ibi pupọ ninu Bibeli ni o tọka si ẹkọ Isọdimimọ ati pe Onigbagbọ ni lati jẹ mimọ. Aye ati eṣu n doju ija kọ ọ, nitori igbesi-aye iwa mimọ kò ni ariwisi tabi ẹgàn. A kò le ṣe ayederu rè̩ -- isọdimimọ ni lati jẹ ojulowo, o si ni lati ti ọdọ Oluwa wá. Iṣẹ oore-ọfẹ yii yoo ṣi ilẹkun Ọrun rere silẹ fun awọn ti o ba ni i. “Ẹ mā lepa alafia pẹlu enia gbogbo, ati iwa mimọ, li aisi eyini kò si ẹniti yio ri Oluwa” (Heberu 12:14). Isọdimimọ yoo mu ki igbesi-aye Onigbagbọ ati iṣẹ rè̩ fun Ọlọrun ni ayé ki o yọri si rere si i pupọ. O rọrun fun ẹni ti a ti sọ di mimọ lati ṣẹgun aye, oore-ọfẹ yii yoo mu ki iṣọkan wà laaarin Ijọ Ọlọrun, ti ohunkohun miiran kò le mu wa. Aye kò le gboju fo iṣọkan ti o wà laaarin Ijọ ti a ti sọ di mimọ ni tootọ dá; wọn yoo si mọ ni tootọ pe Kristi, ireti ogo, wà laaarin wọn.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Wakati wo ni o kù fẹẹfẹ fun Jesu Ọmọ Ọlọrun?

  2. 2 Ki ni ere ti o wà fun awọn ọmọ-eniyan ti o gbà Jesu Kristi gbọ?

  3. 3 Fun awọn wo ni a gba adura ẹbẹ ti o wà ninu Johannu ori kẹtadinlogun?

  4. 4 Bawo ni a ṣe pa awọn ọmọ-ẹyin mọ nigba ti Jesu wà pẹlu wọn ni aye?

  5. 5 Bawo ni a o ṣe pa wọn mọ nigba ti Jesu ba pada sọdọ Baba?

  6. 6 Ki ni idi rè̩ ti awọn ọmọ-ẹyin fi ni lati wà ni ayé bi o tilẹ jẹ pe Jesu ti lọ si Ọrun?

  7. 7 S̩e alaye ohun ti Isọdimimọ jẹ?

  8. 8 Sọ anfaani ti o wà ninu Isọdimimọ; ati idi rè̩ ti o fi ṣe pataki.

  9. 9 Nitori ki ni ayé ati èṣu fi korira isọdimimọ ti wọn si doju ija kọ ọ?