Orin Dafidi 32:1-11

Lesson 239 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Ọpọ ikānu ni yio wà fun enia buburu: ṣugbọn ẹniti o ba gbẹkẹle OLUWA, ānu ni yio yi i ka kiri” (Orin Dafidi 32:10).
Cross References

I Ipo Alaafia ti o ni Ibukun ti Olododo Wà

1 Idariji è̩ṣẹ fun irekọja n fun ni ni ayọ tootọ (Itumọ irekọja ni ṣiṣe ohun ti a ti kilọ pe a kò gbọdọ ṣe), Orin Dafidi 32:1; 1:1-6; Isaiah 43:25; 44:22; 55:1-3, 6, 7; Jeremiah 31:34; 50:20; I Johannu 1:9; Romu 8:1

2 Bibo è̩ṣẹ mọlẹ (labẹ Ẹjẹ Jesu) n fun ni ni ayọ tootọ (lati dẹṣẹ ni pe ki a tase oju àmi, tabi ki a kuna lati ṣe ohun ti a palaṣẹ), Orin Dafidi 32:1; I Johannu 1:7; 2:1, 2; 3:5, 8; Lefitiku 17:11; Heberu 8:12

3 Nigba ti a kò ba ka è̩ṣẹ (eyi ni aiṣedede, tabi yiyà kuro loju ọna ti o tọ) si eniyan lọrun yoo ni ayọ tootọ, Orin Dafidi 32:2; Mika 7:18-20; Heberu 8:12

4 Ominira kuro lọwọ è̩tan (è̩tàn tumọ si eru) n fun ni ni ayọ tootọ, Orin Dafidi 32:2; 101:7; Johannu 1:47; I Peteru 2:22; Ifihan 14:5

5 Ibanujẹ ti o tayọ omije ati arò fun è̩ṣẹ fún Dafidi ni ironupiwada ati idariji kikún, Orin Dafidi 32:3-5; 51:1-9

II Ibukun ti yoo Jẹ ti Olododo Nisisiyi ati ni Ayeraye

1 Awọn ẹni iwa-bi-Ọlọrun yoo wa ibukun Ọlọrun, ipese ati aabo Rè̩, Orin Dafidi 32:6; Habakkuku 2:4; Heberu 10:38

2 Ọlọrun yoo daabo bo awọn ti Rè̩, Orin Dafidi 32:6, 7; 91:1-16

3 A ṣe ileri itọni fun gbogbo awọn ti o tẹle Ọlọrun, Orin Dafidi 32:8; 25:9; 48:14; 73:24; Johannu 14:26; 16:13-15; Isaiah 30:21

4 Olorikunkun ati aṣe-tinu-ẹni kò ni ipin ninu ileri ti a ṣe fun awọn ẹni iwa-bi-Ọlọrun, Orin Dafidi 32:9, 10; Owe 3:32; II Peteru 2:9-17

5 Nitori naa ẹni iwa-bi-Ọlọrun yoo ni ọkàn imoore kikún fun ire gbogbo ti o n ri gbà, Orin Dafidi 32:11; 103:1-22

Notes

Ododo ti o ti Inu Igbagbọ Wa

Akọsilẹ sọ fun ni pe a fi ibeere yii siwaju Martin Luther ni ọjọ kan pe ewo ni o dara ju ninu awọn Psalmu. Idahun rè̩ ni pe “Awọn Psalmu Paulu.” O jẹ iyalẹnu fun onibeere yii pe Luther ti o jẹ ogbogi ninu imọ Ọrọ Ọlọrun ni lati wi pe Apọsteli Paulu jẹ ọkan ninu awọn ti o kọ Psalmu laelae wọnni silẹ. Nitori eyi o tun beere lọwọ Luther lati ṣe alaye itumọ idahun rè̩. Luther si dahun pe, oun pe awọn Psalmu Ironupiwada wọnyi – Psalmu 32, 51, 130, ati 143 – ni Psalmu Paulu, nitori pe wọn fara jọ akọsilẹ Apọsteli naa ti o fi otitọ nì ye ni pe nipa igbagbọ ni a n ri idariji è̩ṣẹ gbà lai si Ofin tabi iṣẹ. O tun fi eyi kún un pe, Psalmu wọnyi n kọ ni lẹkọ bi Paulu ti kọ ni ninu Majẹmu Titun pe kò si ẹni ti o le ṣogo ninu ododo ara rè̩; nitori pe nipa aanu Ọlọrun ni o ri idariji è̩ṣẹ gbà, ki i ṣe pe o ni ẹtọ si i ninu ara rè̩.

Psalmu yii bẹrẹ pẹlu alaye pe alabukun-fun tabi ẹni ti o ni ayọ tootọ ni ẹni naa ti a dari gbogbo irekọja rè̩ ji. Onipsalmu ṣe alaye kukuru lati fi hàn pe ipa mẹrin ni iwa ibi lode ati ninu pin si; awọn ni irekọja, awọn è̩ṣẹ, aiṣedede ati è̩tan. O sọ fun ni pe ẹni ti a dari irekọja rè̩ ji nipa aanu Ọlọrun ti oun kò ni ẹtọ si; ẹni ti a bò è̩ṣẹ rẹ mọlẹ sinu ọgbun okun ¬– ki i ṣe pe yoo lefo gẹgẹ bi ojuoró, ṣugbọn yoo rì sinu ọgbun nibi ti a ki yoo gbe ri i mọ; ẹni ti o ba ni iru iyipada bayi nipa agbara isọdọtun Ọlọrun to bẹẹ ti a kò ni kà aiṣedede rẹ atẹyinwa si i lọrun; ẹni naa ti a mu è̩tan ati arekereke rè̩ atẹyinwa kuro ti a si fi ododo kún ọkàn rè̩ -- Dafidi sọ fun ni pe alabukun-fun ati ẹni ti o ni alaafia ni ẹni bẹẹ i ṣe!

Awọn miiran kò tilẹ gbagbọ pe Ọlọrun le, tabi yoo ṣe iyipada ninu ẹda eniyan ki O fun un ni iriri ibi titun si ododo, eyi ti ẹnikẹni le mọ, ti o si le maa gbe ninu iriri yii. O ṣe ni laanu pe ọpọlọpọ wà ti wọn n diwọn agbara Ọlọrun ti wọn si n fẹ rè̩ ilana Rè̩ silẹ si ọna ti o rọ wọn lọrun. S̩ugbọn eto Ọlọrun kò yipada!

Igbala Ọlọrun n gba ni kuro ninu ẹbi è̩ṣẹ, kuro ninu agbara ati ijiya è̩ṣẹ. Iṣẹ oore-ọfẹ yii n fun ni ni alaafia, nitori abamọ fun è̩ṣẹ kò si mọ, a ti mu ẹbi ati “idajọ ti o ba ni lẹru ati ireti ibinu ti o muna” kuro, a si ti fi “alafia nla” rọpo fun awọn ti o fẹran ofin Ọlọrun. Aye ati ohun gbogbo ti ọwọ eniyan le tè̩ ninu rè̩ ko le ba alaafia yii dọgba, bẹẹ ni kò si le rọpo rè̩ lọnakọna.

Alaafia tootọ, Ọkan ninu awọn Ẹri Igbala

Kò si ẹni ti o le maa ṣiyemeji pe a dari è̩ṣẹ oun ji, iranti è̩ṣẹ paapaa yoo mu ki ibẹru nla ki o wọ inu ọkàn rè̩ lẹsẹkẹsẹ, afi bi a ba ti fi irin gbigbona jo ẹri ọkan rè̩. Ibẹru ikú ayeraye ati ẹru idajọ Ọlọrun yoo wa si iranti rè̩. Dajudaju iru ipo yii kò ni ayọ ninu rara.

Ayọ tootọ kò si afi eyi ti o ni igbadun ninu, a kò si le jẹ igbadun alaafia bi a kò ba mọ ọn lara. A kò si le mọ ayọ lara afi bi eniyan ba mọ pe oun ni in. Ayọ tootọ kò si ninu ọkan ti iyemeji ba gbé wa nipa ifiji è̩ṣẹ rè̩; ayọ tootọ ninu ọkàn jẹ ọkan ninu ẹri oore-ọfẹ igbala Ọlọrun ti o daniloju.

Dafidi ti dẹṣẹ. O si ni iwuwo idalẹbi è̩ṣẹ ati idajọ Ọlọrun lori rẹ, nitori naa o ronupiwada è̩ṣẹ rè̩. A ka nihin pe Ọlọrun dari è̩ṣẹ rè̩ ji i. Ninu Psalmu yii Dafidi sọ fun wa pe a dá ayọ igbala oun pada nigba ti o ri oore-ọfẹ Ọlọrun gbà pada. Dafidi ti kọkọ gbadura fun idapada ayọ naa; bi a ba fi adura fun idariji ti o wà ni Psalmu kọkanlelaadọta ati Psalmu yii we ara wọn, a o ri pe ọkan naa ni adura ti o gbà fun idapada ayọ igbala ati idapada igbala rè̩. Awọn miiran le wi pe Dafidi kò sọ igbala rè̩ nù nitori ti a du u ni ayọ rè̩ fun iwọn igba diẹ nitori iwa ailọgbọn rè̩. S̩ugbọn Psalmu yii ati adura rè̩ fun idariji fi hàn pe o gbadura bi ẹni ti kò ni idaniloju tabi ireti ninu Ọlọrun lọwọlọwọ. O ti sọnu – o ti sọnu titi ayeraye – bi kò ba ri idariji ti o n gbadura fun gbà. A si dá gbogbo anfaani isọdọmọ ati ogun awọn olóòótọ pada fun un nigba ti o ri idariji è̩ṣẹ gbà.

Ibukun Ti o n Tẹle Ironupiwada

Lẹyin ti Dafidi ti tun ri oju-rere Ọlọrun, o di alabapin ogun awọn eniyan mimọ. Nitori ti o mọ ibukun ti o wà fun “olukuluku ẹni iwa-bi-Ọlọrun” kò lọra lati gbadura pe ki Ọlọrun ki o jẹ ki oun jẹ alabapin ibukun wọnni. Inu Ọlọrun a maa dùn nigba ti a ba gbẹkẹle E. O sọ fun ni pe, “olododo yio wà nipa igbagbọ rè̩” (Habakkuku 2:4). O fẹ ki a rọ mọ Oun. O fẹ ki a fara mọ Oun. O fẹ ki a gbe gbogbo ẹkẹ wa le Oun.

Bi a ba ti mọ aini wa pọ to, ti a si mọ pe Ọlọrun ni tito wa, bẹẹ ni ibukun wa lati ọdọ Ọlọrun yoo maa pọ si i. Awọn ti n wa si ibi Itẹ Aanu nigba gbogbo ni alabukunfun ju lọ. Awon ti o fi igbẹkẹle ati ireti wọn sinu Ẹni Aikú ni o n jẹ anfaani pọ ju lati inu ọgbọn ati ipese awamaridi Ọlọrun.

Gbogbo ohun ti a ṣe alaini ni o wà ninu Àká Ọlọrun. Iwosan wà fun wa ninu Ẹjẹ nì ti a ta silẹ ati nipa ina Rè̩. Ọgbọn ati itọni wà fun gbogbo iṣoro ati idaamu aye yii ninu Olutunu mimọ nì. Ọrọ Ọlọrun yoo ṣipaya fun awọn ti o n wa itọni Ẹmi Mimọ. A maa n ni igbagbọ nigba ti a ba ni oye tootọ ninu Ọrọ Ọlọrun. Ireti ainipẹkun wà fun awọn ti n tẹle Onirẹlẹ ara Nasarẹti nì. Itura ati alaafia wà fun olukuluku ẹni ti o ba wá sọdọ Baba. Aabo ati ibi isadi wà fun gbogbo awọn ti o wa si abẹ Iyẹ Apa Rè̩ ti Oju ifẹ Rè̩ si n ṣọ. Ibukun wọnyi ati ju bẹẹ lọ ni o wà fun awọn ti igbẹkẹle wọn wà ninu Ẹni ti o wi pe Oun ki yoo fi wa silẹ bẹẹ ni Oun ki yoo kọ wa silẹ.

“Majẹmu ati Ẹjẹ Rè̩

L’emi o rọ mọ bi ‘kunmi de

Gbati kò s’atilẹyin mọ

O jẹ ireti nla fun mi.”

S̩ugbọn ikilọ kan wà ninu Psalmu yii, nitori pe Ọlọrun mọ ailagbara ẹda ati ainilaari ara erupẹ ti a gbe wọ. Ọrọ yii pe, “Ki ẹnyin ki o máṣe dabi ẹṣin tabi ibaka, ti kò ni ìyè ninu,” n sọ fun wa pe awọn miiran wà ti ki yoo gba itọni, ti ki yoo si tẹriba fun akoso ati ifẹ Ọlọrun. Ibukun diẹ, bi o ba tilẹ wà rara, ni awọn ẹni bẹẹ n ri gbà ninu ibukun nlá nlà ti awọn olododo n ri gbà. “Ọpọ ikānu ni yio wà fun enia buburu.” Eyi ni ọrọ itunu ti o dara ju lọ ti eniyan buburu le nireti lati gbọ nigbà ti wahala ati ipọnju ba de ba a. S̩ugbọn itunu kò si ninu eyi nì bi a ba ranti pe ibanujẹ yii jẹ ere ṣiṣe tinu-ẹni, orikunkun ati imọ-ti-ara-ẹni-nikan. Ni ida keji ẹwẹ, olododo ni idaniloju ti ki i yẹ ati itunu pe “ānu ni yio yi i ka kiri.”

Iyin ati Imoore

Ki ni ṣe ti olododo ki yoo fi kọrin? Ki ni ṣe ti ẹni irapada ki yoo fi yin Ọlọrun? Ki ni ṣe ti oun ki yoo fi ni inudidun? Idahun si awọn ibeere wọnyi kò fara sin, a le ri i ninu igbesi-aye awọn Onigbagbọ lati ayebaye.

Ninu isin Ọlọrun ni orin ti bẹrẹ. Orin kikọ wayé bayi a si mu un dara si i fun isin Ọlọrun. Nibi ti isọkan ba wà, ti ero ba ṣọkan ni a gbe n ri irẹpọ tootọ. Awọn ẹbi ti o layọ ju lọ ni awọn ẹbi ti o gba Alejo Oloore nì tọwọ-tẹsẹ. Awọn ẹgbẹ ti wọn jẹ olóòótọ si ara wọn julọ ni awọn ti Ọlọrun ati Ọrọ Rè̩ ti sọ di aláápọn ati ẹni rere. “Gbogbo è̩bun rere ati gbogbo è̩bun pipé lati oke li o ti wá” (Jakọbu 1:17). “Iṣan-omi nla . . . ki yio sunmọ ọdọ” ẹni ti o gbe ẹkẹ rè̩ le Ọlọrun – i baa ṣe ọkunrin tabi obinrin ti o mọ ododo ti i ṣe ti igbagbọ.

“Ki inu nyin ki o dùn niti OLUWA, ẹ si ma yọ, ẹnyin olododo; ẹ si ma kọrin fun ayọ, gbogbo ẹnyin ti aiya nyin duro ṣinṣin.”

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 S̩e alaye ipa mẹrin ti iwa ibi pin si bi a ti mẹnu kan an ninu awọn ẹsẹ ti o ṣaaju ninu ẹkọ yii.

  2. 2 Sọ ipese ti Ọlọrun ṣe lati yọ wa kuro ninu ibi kọọkan ti a darukọ ninu awọn ẹsẹ wọnyi.

  3. 3 Ọna wo ni Psalmu yii fi gbà sọ ẹkọ eke nì pe “bi eniyan ba ti ri igbala lẹẹkan, kò le sọ ọ nu mọ laelae,” di asan?

  4. 4 Ibukun wo ni a ṣeleri fun awọn ẹni-iwa-bi-Ọlọrun?

  5. 5 Ikilọ wo ni o wà ni tosi ipari Psalmu yii?

  6. 6 Ileri wo ni o wà fún eniyan buburu?

  7. 7 Fi ireti olododo ati ti eniyan buburu wé ara wọn.

  8. 8 Ki ni ipilẹ iyin si Ọlọrun?

  9. 9 Ki ni ṣe ti Luther fi pe Psalmu yii ni ọkan ninu awọn “Psalmu Paulu?”

  10. 10 Ootọ Ihinrere nla wo ni a kọ ni nihin ati ninu Psalmu kọkanlelaadọta ti o jọ awọn akọsilẹ ti Majẹmu Titun?