Orin Dafidi 10:1-18; 14:1-7; 36:1-12

Lesson 240 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “OLUWA, iwọ ti gbọ ifẹ onirẹlẹ: iwọ o mu ọkàn wọn duro, iwọ o dẹ eti rẹ si i” (Orin Dafidi 10:17).
Cross References

I Iha ti Ọlọrun kọ si Awọn Agberaga

1 Ipinnu Ọlọrun, nigba ti O ba n ba awọn eniyan Rè̩ wi, ki i tete fara hàn, Orin Dafidi 10:1; Jobu 23:10; Isaiah 48:10; II Kọrinti 12:7; I Peteru 1:6, 7; 4:12, 13

2 Igberaga ati ijọ’ra-ẹni-loju wà lọkàn awọn eniyan buburu, o si fara han lọna pupọ ti o daniloju, Orin Dafidi 10:2-6; 49:18; Owe 3:7; 13:15; 21:4; Romu 8:5-8; 12:16; I Johannu 2:16; I Kọrinti 8:2; Galatia 6:3

3 Ihuwasi eniyan buburu kò ni ododo ninu, Orin Dafidi 10:7-11; 37:1, 2, 9, 12-15, 17, 21, 32, 35, 36; Romu 1:18-32; Owe 6:12-19

4 Ihà ti Ọlọrun kọ si awọn ọlọtẹ fara hàn ninu adura Dafidi, Orin Dafidi 10:12-18; Ifihan 6:10; Jobu 10:14; Oniwasu 8:11; Jeremiah 2:22; 17:9, 10; Amosi 5:12; Romu 6:23; II Peteru 3:9

II Idibajẹ Iran Eniyan gbogbo ati Ireti-Ijọba ti Israẹli Ni

1 Ọlọrun kò ni inudidun si awọn ti kò gbà pe Ọlọrun wà ati ẹkọ wọn, Orin Dafidi 14:1; 10:4; 36;1; Jeremiah 5:12-14

2 Ọlọrun Alaanu, ti O fẹ ki gbogbo eniyan ni igbala, ri i pe wọn mọọmọ yà si ipa ọna ti kò tọ, Orin Dafidi 14:1-3; Romu 1:21-32; 3:10-12, 23; Gẹnẹsisi 6:5; 18:23-26; II Kronika 16:9; Isaiaih 1:6; 59:1-8; 64:6

3 A ba awọn kan wi, a si pe wọn ni oniṣẹ è̩ṣẹ, Orin Dafidi 14:4-6; 119:86; 143:3; Matteu 10:17; Luku 21:12-18; Johannu 16:2

4 A fi agbara ati aanu Ọlọrun ayeraye ti ki i ṣe ojusaju eniyan hàn nihin yii, Orin Dafidi 14:4-6; Iṣe Awọn Apọsteli 10:34, 35

5 A sọ ohun iyanu nipa ti ikuna majẹmu Israẹli ati ayọ ti Ijọba Ẹgbẹrun Ọdun ti o wà fun wọn, Orin Dafidi 14:7; Ẹksodu 19:5, 6; Deuteronomi 4:7-13, 23; 5:2, 3; Heberu 8:6-13; Jeremiah 31:31-34; 32:37-42; Romu 4:9-16; 11:1-15

III Ẹlẹṣẹ kò Nireti ninu Ọlọrun

1 Iwa ati iṣe awọn ẹni buburu fi hàn pe wọn kò nireti ninu Ọlọrun, Orin Dafidi 36:1-4; Owe 12:15; 20:6; 30:12; II Kọrinti 10:12

2 Awọn ti o gbẹkẹle Ọlọrun ri ire nipasẹ aanu, otitọ, ododo, idajọ ati ifẹ-inu-rere Rè̩, Orin Dafidi 36:5-9; 63:3; 103:17; 108:4; Ẹkun Jeremiah 3:22, 23; Isaiah 63:7

3 Adura olododo a maa sọ ti ifẹ Ọlọrun si awọn olododo, Orin Dafidi 36:10-12; Romu 4:21; II Peteru 1:4

Notes

Ọrọ Oluwa ati Ihà ti O kọ si Ẹṣẹ

A mọ Dafidi, Ọba Israeli ni Woli gẹgẹ bi Ọrọ Ọlọrun ti fi ye ni. Awa mọ pe otitọ ni eyi nitori awọn akọsilẹ rè̩ kún fun otitọ Ihinrere ati iṣipaya lati ọdọ Ọlọrun Ọrun nipa eto Rè̩ fun ọmọ-eniyan. Ninu awọn Psalmu mẹtẹẹta ti a gbe n kẹkọ yii, a le ri iṣẹ Ẹmi Ọlọrun dajudaju gẹgẹ bi o ti mí si eniyan Ọlọrun yii lati kọ akọsilẹ otitọ ayeraye wọnyi ti Ọlorun n fẹ ki a gbà. Ninu iṣẹ ti Ọlọrun ran si wa yii, a ri aanu, otitọ ati iṣeun ifẹ ati pẹlupẹlu ododo idajọ Ọlọrun ayeraye ti “ki yio da enia buburu silẹ” (Nahumu 1:3).

Ninu awọn Psalmu wọnyi, a ri ihà ti Ọlorun kọ si è̩ṣẹ ati ẹlẹṣẹ. A ri i pe eniyan kò le duro gedegbe lai fara mọ ododo tabi iwa buburu. A si ri i pe ọna meji ni o wà, ọna iye ati ọna ikú. Eniyan le maa fi è̩ṣẹ ṣire ni ireti lati ronupiwada lọjọ kan ṣugbọn gbogbo ọna Ọlọrun ni o dọgba. Awọn eniyan le gba è̩ṣẹ laaye ki wọn si maa ṣe awawi lati dẹṣẹ, ṣugbọn Ọlọrun a maa pe è̩ṣẹ ni orukọ ti o n jẹ gan an, yoo si jẹ ẹni ti o ba gbà a laye ninu ọkàn rè̩ niya.

Gẹgẹ bi ero eniyan, oriṣiriṣi è̩ṣẹ ni o wà. Ninu eto idajọ aye yii, ijiya ti a ṣe eto rè̩ silẹ fun è̩ṣẹ kọọkan duro le bi è̩ṣẹ tabi aiṣedeedee si ofin ba ti pọ to. S̩ugbọn lọdọ Ọlọrun, è̩ṣẹ ti o kere ju lọ a maa yà eniyan ya Ọlọrun, a si maa mu ki a sọ anfaani ti wà ninu majẹmu Rè̩ nù. Ẹni ti o ba si ti yan ọna è̩ṣẹ kò ni ohun kan lati ṣe ju pe ki o maa reti ere è̩ṣẹ, afi bi o ba le rọ lu Ẹjẹ Aanu nì, ki o si tọrọ idariji fun è̩ṣẹ rè̩. Nitori naa Ọlọrun ki i pin è̩ṣẹ gẹgẹ bi eniyan ti n ṣe, ni ero pe idajọ ayeraye wà fun awọn è̩ṣẹ nlá nla ati pe idajọ ti kò wuwo pupọ wà fun awọn è̩ṣè̩ keekeeke. Ọlọrun n wo è̩ṣẹ ninu ọkàn, O si mọ ọn ni è̩ṣẹ, yoo si ṣe idajọ ti o tọ le e lori.

È̩ṣẹ ti Eniyan Kọ Dá

A sọ fun wa pe Satani ṣubu lati Ọrun nigba ti o gbé ara rè̩ ga ti o si fẹ lati gba ipo Ọga Ogo. Satani fi igberaga dán eniyan wo, eniyan si ṣubu. Nitori naa igberaga ni o fa iṣubu ọmọ-eniyan. Oun ni ipilẹṣẹ awọn è̩ṣẹ miiran ti eniyan n dá. Kò pin sọdọ Satani nikan, nitori a o ri i pe o wà ninu gbogbo ọkàn ti kò i ti di atunbi. O jẹ è̩ṣẹ ti o n dojukọ awọn ẹni iwa-bi-Ọlọrun nigbakuugba, o si jẹ ọna idanwo ti o dabi ẹni pe o ṣoro fun ọpọlọpọ lati bori. Nitori ti i ṣe è̩ṣẹ, Ọlọrun korira rè̩! (Owe 6:16-19).

Nipa akọsilẹ Dafidi, a le ri awọn è̩ṣẹ buburu ti o le joko pẹsẹ ninu ọkàn igberaga. Agberaga a maa ṣe inunibini si talaka a si maa ṣogo ninu ifẹ ọkàn rè̩. O n sure fun oloju-kokoro, o si n wi ni ọkàn rẹ pe oun to tan, ati pe oun ti tayọ atako ẹnikẹni. Bi o ba si n ba bẹẹ lọ, yoo sé̩ Ọlọrun Ọrun ati ninu igberaga ati irera rẹ yoo wi pe a ki yoo ṣi oun –eniyan ẹlẹran ara lasan – ni ipo. Bi o ba si gba ni ikẹyin pe Ọlọrun wà, ki yoo gba pe Ọlọrun fẹran ọmọ-eniyan, pẹlupẹlu yoo si sọ pe Ọlọrun kò ni ipa lati fi ifẹ Rè̩ hàn bi O ba tilẹ fẹran eniyan rara. Iru ipo buburu yii ni igberaga ti a kò yẹ lọwọ wo n gbe eniyan de.

S̩ugbọn Woli Ọlọrun yii sọ ohun ti o jinlẹ ju eyi lọ, o fi hàn fun ni pe irugbin-è̩ṣẹ yii wà ninu gbogbo ọkàn ti kò i di atunbi nitori pe gbogbo eniyan ti kò si ninu agbo Ọlọrun ni o bajẹ patapata ti wọn si n tọ ọna iṣina ati è̩ṣẹ. O wi fun ni pe Ọlọrun alaanu boju wolẹ lati Ọrun wá, O n wo aye è̩ṣẹ yii, O si ri i pe gbogbo awọn ẹlẹṣẹ ti yà kuro ni ọna tootọ, wọn si n tọ ọna ti ọkàn wọn yàn. O sọ fun ni pe gbogbo wọn ti di eleeri patapata. O tẹnu mọ ọn pe kò si ẹni ti n ṣe rere; afi bi wọn ba ti yipada kuro ni ọna buburu wọn ki a si ti dariji wọn, ki a ti dá wọn lare, ki a ti sọ wọn di atunbi, ki a si ti gbà wọn sinu ẹbi Ọlọrun.

Awọn Psalmu wọnyi fi han wa pe ẹlẹṣẹ ti Ẹmi Mimọ Ọlọrun kò i ti fi ọwọ tọ ọkàn rè̩ lati fi han fun un pe o yẹ ki o ni Ọlọrun, kò le ni ibẹru Ọlọrun. Kaka bẹẹ, oun tikara rẹ yoo maa pọn ara rè̩ lé. Kò si ohun kan ti o dara ninu iru eniyan bẹẹ. O kún fun aiṣedeedee ati è̩tan, o si ti fi ọna rere silẹ. O wi pe, “Ọlọrun kò si.” O mọọmọ pete è̩ṣẹ, o si mu ipinnu rè̩ ṣẹ gẹgẹ bi ilana rè̩. O ni Ọlọrun ki yoo jẹ oun niya fun è̩ṣẹ ati pe Ọlọrun ti gbagbe lati bẹ oun wo; Ọlọrun ki yoo si ri bi awọn è̩ṣẹ naa ti pọ to tabi ki O jẹ oun niya nitori wọn.

Aworan ẹni ti o ṣubu ni eyi, ẹni ti è̩ṣẹ ti sọ di ibajẹ ti o si n tẹle ifẹ ati ilepa ti ara rè̩. Ọkàn rè̩ korira o si n ṣọtẹ si ohun rere ati si Ẹlẹda ohun rere gbogbo. Dajudaju kò le si iyemeji lọkàn ẹni ti o ba fẹ ṣootọ, wi pe idajọ kikún ati ododo Ọlọrun yoo wá sori gbogbo awọn ti o ṣọtẹ si I, ti wọn si n tẹle ọna ara wọn.

Ọlọrun Ọrun Alaanu

S̩ugbọn a kà pe Ọlọrun ti ri è̩ṣẹ yii. A ni itunu ninu idaniloju yii pe Ọlọrun ni iranlọwọ gbogbo awọn ti o gbẹkẹ wọn le E, ati pe ẹlẹṣẹ ki yoo lọ lai jiya ati pe ni ikẹyin Ọlọrun yoo gba gbogbo agbara ati aṣẹ nitori Oun ni wọn tọ si. Ẹmi Mimọ ti fun wa ni idaniloju ninu Psalmu mẹtẹẹta yii pe Ọlọrun ti gbọ ifẹ awọn eniyan Rè̩, Oun yoo si pese ọkàn wọn silẹ, gbogbo awọn ti a n nilara ni a o tu silẹ kuro ninu gbogbo ide ati ohun ti n doju ija kọ wọn.

A ni idaniloju fun idande kuro lọwọ ọta nipa otitọ yii pe, Oluwa ni Ọba lori ohun gbogbo, nigbooṣe Oun yoo pada wá lati gbé Ijọba Rè̩ kalẹ, Oun yoo si jọba lori gbogbo awọn alaṣẹ aye yii. A tun mu wa ri firifiri ogo Ijọba naa nibi ti ododo ati aiṣegbe yoo gbilẹ ati nibi ti awọn eniyan Ọlọrun yoo jọba pẹlu Kristi ati Oluwa wọn.

Ẹmi Mimọ fun wa ni idaniloju pe a o mu Israẹli pada bọ sipo ni akoko naa, ẹkunrẹrẹ eto majẹmu Ọlọrun yoo si wa lori ilẹ aye. Ayọ nla ati inu-didun yoo si wà lori ilẹ aye ni ọjọ wọnni nigba ti ododo ba n jọba. Ibukun Ọlọrun ni kikún yoo si fara hàn nigba naa tayọ ti akoko yii. Aṣaro Onipsalmu nipa ogo wọnyi ni o mu ki o bu si orin iyin si Ọlọrun, Ẹni ti o ni agbara ati iṣeun ti o tó lati ṣe awọn ohun ti o ya ni lẹnu to bẹẹ -- o si yẹ ki eyi mu awa naa bu si orin iyin si Ọlọrun.

Bi a ba fi ododo ati iṣeun ifẹ alailoṣuwọn ti Ọlọrun gbogbo agbaye wé ero buburu ati ete ainilaari ti awọn eniyan buburu ati ti Satani oluwa wọn, a ri iyatọ ti o hàn gedegbe! Aanu Ọlọrun kò nipẹkun! Otitọ Rè̩ de awọsanma! Ododo Ọlọrun dabi awọn oke nla! Idajọ Rè̩ dabi ibu jijin! Ẹmi Mimọ lo awọn nnkan ti o ga rekọja, ti o tobi ti o si jinlẹ ati ohun to kun fun è̩rù lọpọlọpọ lati kọ wa ni otitọ nla nipa agbara awamaridi Ọlọrun ti kò lopin. Abajọ ti o ṣe wi pe awa naa le mọ ohun Ọlọrun wọnni ti o fara sin, ani agbara ati iwa Ọlọrun Rẹ ayeraye, nipa ohun ti a n ri – ani iṣẹ ọwọ Rè̩ (Romu 1:20).

“Ẹ fi ọpẹ fun OLUWA: nitoriti o ṣeun; nitori ti ānu rè̩ duro lailai”.

“Ẹniti o ranti wa ni iwa irẹlẹ wa; nitori ti ānu rè̩ duro lailai:”

“O si dá wa ni ide lọwọ awọn ọta wa; nitori ti ānu rè̩ duro lailai.”

“Ẹ fi ọpẹ fun Ọlọrun ọrun; nitori ti ānu rè̩ duro lailai” (Orin Dafidi 136:1, 23, 24, 26).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Lẹyin igba ti o ti ka awọn ẹsẹ ti a tọka si loke ẹkọ yi nipa ibawi Ọlọrun, ki ni iwọ yoo pe ni eredi ibawi naa?

  2. 2 Njẹ a n mọ eredi rè̩ ni kikún, ti Ọlọrun fi n ba ni wi ti o si n wẹ wa mọ, ni akoko idanwo naa? Bi bẹkọ, ki ni ṣe?

  3. 3 Ki ni a le pe ni è̩ṣẹ ti eniyan kọ dá?

  4. 4 Ki ni ẹni ti o wi pe Ọlọrun kò sí ro nipa Ọlọrun wa?

  5. 5 Ki ni Ọlọrun pe awọn ti o sọ pe Ọlọrun kò si?

  6. 6 Fi apejuwe ẹni iwa-bi-Ọlọrun bi o ti wà ninu (Matteu 5:3-12) we apejuwe awọn alaiwa-bi-Ọlọrun bi o ti wà ninu ẹkọ wa yii.

  7. 7 Ọlọrun ha ti gbagbe ayé? O ha ṣe aifiyesi ẹṣẹ ọmọ-eniyan ti o ti ṣubu? Fi ẹsẹ Bibeli kan gbe idahun rẹ lẹsẹ.

  8. 8 Ki ni ireti awọn ẹni iwa-bi-Ọlọrun, bi a ti ri i kà ninu ẹkọ wa yii?

  9. 9 Ki ni ireti yii duro le lori?

  10. 10 Asọtẹlẹ nla nipa Israẹli wo ni o wa ninu ẹkọ wa yii?