II Samuẹli 15:1-17; 16:5-14; 18:1-33; 19:16-23;Orin Dafidi 3:1-8

Lesson 241 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “S̩ugbọn iwọ, OLUWA, li asà fun mi; ogo mi; ati olugbe ori mi soke” (Orin Dafidi 3:3).
Cross References

I Absalomu fi Arekereke Fa awọn Eniyan Mọra

1 O ṣe arẹwa, ọmọ ọba si ni, II Samuẹli 14:25, 26

2 Eniyan lasan ti o n lepa ipò nlá ni, II Samuẹli 15:1-4

3 Ẹlẹtan ati oniwakiwa eniyan ni, II Samuẹli 15:5, 6

II Rikiṣi Absalomu lati Gba Itẹ-Ijọba

1 O ṣe ayidayida ni irin-ajo rè̩ si Hebroni, II Samuẹli 15:7-9

2 Rikiṣi rè̩ gbilẹ jakejado Israẹli, II Samuẹli 15:10-12

III Dafidi fi Irẹsilẹ Sa Kuro ni Jerusalẹmu

1 Dafidi fi Jerusalẹmu silẹ, II Samuẹli 15:13-17

2 S̩imei yàn eebu si Dafidi lara, II Samuẹli 16:5-14

IV Iṣẹgun fun Dafidi; ati Ikú Absalomu

1 Dafidi ṣe eto ogun rè̩, o si bẹbẹ fun ẹmi Absalomu, II Samuẹli 18:1-5

2 Absalomu pade àgbako, a si ṣẹgun rè̩, II Samuẹli 18:6-18

3 Nigba ti Dafidi gbọ iroyin iṣẹgun naa, o kaanu fun Abasalomu, II Samuẹli 18:19-33

4 Dafidi fi aanu hàn fun S̩imei ni ipadabọ rè̩, II Samuẹli 19:16-23

5 Dafidi gbẹkẹle Ọlọrun, Orin Dafidi 3:1-8

Notes

Arẹwa Ọmọ-ọba

“Kò si si arẹwà kan ni gbogbo Israeli ti a ba yìn bi Absalomu: lati atẹlẹsẹ rè̩ titi de atari rè̩ kò si abùkun kan lara rè̩” (II Samuẹli 14:25). S̩ugbọn arakunrin Absalomu ti o gbọn sọ wi pe, “Ẹwà jasi asan.”

Ẹwà oju le tan eniyan jẹ gẹgẹ bi ẹwà Absalomu ti fa ọkàn Israẹli sọdọ Absalomu, ṣugbọn, “Oluwa a ma wò ọkàn” (I Samuẹli 16:7). Labẹ ọpọlọpọ ọṣọ ati afẹfẹyẹyẹ arẹwa ọmọ-ọba ti o n gun kẹkẹ ti a ṣe lọṣọ kọja laaarin igboro ti o kún fun èro, ti aadọta eniyan n sare niwaju rè̩, Ọlọrun ri ohun irira kan ti i ṣe igberaga. Ifẹnukonu Judasi ni o wà labẹ ikini ati ọyaya Absalomu. “A ba jẹ fi mi ṣe onidajọ ni ilẹ yii” ni ọrọ ti ó wà ni ẹnu ọdalẹ oṣelu yii, ti o n wa ipo ti o si n fẹ ki a dibo fun oun, o n lọ kaakiri lati gba ni lọwọ ati lati fi ẹnu ko awọn eniyan lẹnu.

Ẹtàn

Pẹlu ọkàn ẹtan, o dibọn bi ẹni pe o fẹ san ẹjẹ fun Ọlọrun, onigberaga ọmọ-ọba yii lọ si Hebroni lati já ijọba gbà kuro lọwọ Dafidi baba rè̩, ẹni ti Ọlọrun fi ami ororo yàn. Awọn eniyan Israẹli ti yara gba ẹtan to! Jesu wi fun awọn akọwe ati awọn Farisi igba aye Rẹ pe, “Ẹnyin dabi iboji funfun, ti o dara li ode, ṣugbọn ninu nwọn kún fun egungun okú, ati fun ẹgbin gbogbo.” Ipo bayii ni ọmọ yii ti o pa arakunrin rè̩ tí o si n wa ọna lati pa baba rè̩ wa. Oju didan ti jasi asan to niwaju Ọlọrun Olodumare! Awọn kan wi pe “Emi li ọrọ, emi si npọ si i li ọrọ, emi kò si ṣe alaini ohunkohun.” Ọlọrun si pe wọn ni “Òṣi, ati àre, talakà ati afọju, ati ẹni-ihoho.”

Ọpọlọpọ ẹlẹṣẹ ni o lero pe aye n dara fun wọn nitori pe wọn n wọ aṣọ olowo iyebiye, wọn si ni mọto ayọkẹlẹ ti o ṣẹṣẹ wọ’lu, ṣugbọn nigba ti o ba ti pẹ ju ni wọn yoo to mọ pe egbe ayeraye ni awọn ohun asan ti wọn n pọn lé yoo mu ba wọn. Ọkunrin nì “ti o nwọ aṣọ elesè aluko ati aṣọ àla daradara” gbe oju rè̩ soke ni ọjọ kan, o si ba ara rè̩ ninu iṣé̩ oro ninu ọwọ ina ọrun apadi. Ẹ wò ere wiwá ohun asan aye yii kiri ki a si maa fi ẹmi ẹni tàfala!

Sisa Dafidi

Pẹlu ọrọ didun ati ete ipọnni, Absalomu fa ọkàn awọn eniyan Israẹli sọdọ ara rè̩. Lai si aniani ọkàn arekereke rè̩ ti n pete fun ọpọlọpọ ọdun lati dà baba rè̩. O dabi ẹni pe Dafidi kò bikita o si kọ eti didi si iwa ọmọ rè̩ yi ti akẹju ti bajẹ. Wo iyatọ ti o wà laaarin Absalomu ati Dafidi! Laaarin iro ipe ati afẹfẹyẹyẹ, Absalomu fi ara rè̩ jọba ni Hebroni. “Dafidi si ngoke lọ ni oke Igi ororo, o si nsọkun bi on ti ngoke lọ, o si bò ori rè̩, o nlọ laini bata li ẹsẹ: gbogbo enia ti o wà lọdọ rè̩, olukuluku ọkọnrin si bò ori rè̩, nwọn si ngoke, nwọn si nsọkun bi nwọn ti ngoke lọ” (II Samuẹli 15:30).

Awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi ru Apoti-ẹri Ọlọrun, wọn si tẹle Dafidi ṣugbọn Dafidi wi pe, “Gbe apoti-ẹri Ọlọrun na pada si ilu: bi emi ba ri oju-rere gbà lọdọ OLUWA, yio si tun mu mi pada wá, yio si fi apoti-ẹri na hàn mi ati ibugbe rè̩. S̩ugbọn bi on ba si wi pe, Emi kò ni inu didùn si ọ; wõ, emi nĩ, jẹ ki on ki o ṣe si mi gẹgẹ bi o ti tọ li oju rè̩” (II Samuẹli 15:25, 26). Ninu ohun ti o ṣẹlẹ yii, Dafidi lero pe Oluwa n jẹ oun niya fun awọn è̩ṣẹ rẹ atẹyinwa. Nigba ti Natani woli jiṣẹ Oluwa fun Dafidi, ohun ti o sọ ni eyi, “Kiyesi i, emi o jẹ ki ibi ki o dide si ọ lati inu ile rẹ wá” (II Samuẹli 12:11). Pẹlu irẹlẹ ati ijọwọ ara ẹni lọwọ fun Ọlọrun, Dafidi gbà ijiya naa bi ẹni pe lati ọdọ Oluwa wá. Ẹni melo ni o dabi Dafidi – ti o le fi tọkan-tọkan gbà ibawi!

Iwa Ainitiju S̩imei

Bi ẹni pe ibinujẹ sisọ ijọba rè̩ nu ati ọtẹ ti ọmọ rè̩ ọwọn ṣe si i kò ti i to, S̩imei, ti i ṣe idile Saulu, bẹrẹsi bu Dafidi o si n sọ okuta si i ati si gbogbo awọn iranṣẹ rè̩. Awọn akọni ọmọ-ogun ti o wà lọdọ Dafidi i ba ti fi opin si gbogbo iwa buburu S̩imei yii, ṣugbọn Dafidi dá wọn lẹkun bayi wi pe, “Jẹ ki o ma bu bḝ, nitoriti OLUWA ti wi fun u pe: Bu Dafidi. Tani yio si wipe, nitori kini iwọ fi ṣe bḝ?” Dafidi si fi kún ọrọ rè̩ pe, “Wõ, ọmọ mi ti o ti inu mi wá, nwá ẹmi mi kiri: njẹ melomelo ni ara Benjamini yi yio si ṣe? jọwọ rè̩, si jẹ ki o mā yan ẽbu; nitoripe OLUWA li o sọ fun u. Bọya OLUWA yio wo ipọnju mi, OLUWA yio si fi ire san a fun mi ni ipo ẽbu rè̩ loni” (II Samuẹli 16:10-12).

Njẹ iwa irẹlẹ ti Dafidi hù yii kò le mu ọrọ Peteru jade bayii pe: “Nitoripe eyi ni itẹwọgba, bi enia ba fi ori ti ibanujẹ, ti o si njiya laitọ, nitori ọkàn rere si Ọlọrun. Nitori ogo kili o jẹ, nigbati ẹ ba ṣè̩ ti a si lù nyin, bi ẹ ba fi sụru gbà a? ṣugbọn nigbati ẹnyin ba nṣe rere, ti ẹ si njiya, bi ẹnyin ba fi sụru gbà a, eyi ni itẹwọgbà lọdọ Ọlọrun” (I Peteru 2:19, 20).

Ikú Absalomu

Lẹyin irin nnkan bi ọgọta mile (ibusọ) si Jerusalẹmu, Dafidi pin awọn ọmọ-ogun rè̩ si ẹgbẹ mẹta o si fi wọn le awọn balogun ẹgbẹẹgbẹrun lọwọ. Eyi fi hàn pe ẹgbẹ ogun nla ni o ba Dafidi jade kuro ni Jerusalẹmu. Ẹgbaawa eniyan ni o ṣubu niwaju awọn iranṣẹ Dafidi ni ọjọ naa, ṣugbọn Absalomu olori awọn ọlọtẹ kú ikú abami. “Absalomu si gun ori ibaka kan, ibaka na si gba abẹ ẹka nla igi pọnhan kan ti o tobi lọ, ori rè̩ si kọ igi pọnhan na, on si rọ soke li agbede meji ọrun on ilẹ; ibaka na ti o wà labẹ rẹ si lọ kuro.” Wọn a maa wi pe awọn ohun aye yii a maa fi ni silẹ nigba ti a fẹ lo wọn gidigidi, wọn a si salọ gẹgẹ bi ibaka Absalomu.

Ibanujẹ Dafidi

Ifẹ nlá nlà ti Dafidi ni si ọmọ rè̩ ọlọtẹ fara hàn ninu ọrọ ti o sọ nigba ti o gbọ ihin ikú Absalomu: “Ọmọ mi Absalomu, ọmọ mi, ọmọ mi Absalomu! ā! ibaṣepe emi li o kú ni ipò rẹ, Absalomu ọmọ mi, ọmọ mi!” (II Samuẹli 18:33).

S̩imei Ronupiwada

Nigba ti awọn ọmọ-ogun Dafidi n pada bọ wa si Jerusalẹmu pẹlu ayọ ịṣẹgun, ta ni kọ pade wọn bi kò ṣe S̩imei, ọkunrin ni ti o ti bu ọba kikankikan. O wolẹ buruburu niwaju Dafidi pẹlu itẹriba ati ọkàn ironupiwada. Bi o tilẹ jé̩ pe Abiṣai, ọkan ninu awọn olori ogun Dafidi n fẹ lati pa S̩imei, ọba yipada si S̩imei o si wi pe, “Iwọ ki yio kú.”

Eyi ran wa leti aanu Ọlọrun si awọn ti o ti ṣẹ si I lati igba ti a ti bi wọn titi di igba ti iṣoro tabi wahala ba mu ki wọn ke pe Ọlọrun, ti ohun yii si fọ si wọn pe, “Iwọ kì yio kú.” Wò bi ifẹ Jesu ti pọ to, Ẹni nigba ti a n kan An mọ agbelebu ti O wi pe, “Baba, dariji wọn: nitoriti nwọn kò mọ ohun ti nwọn nṣe” (Luku 23:34). Iyọnú Dafidi le pọ ni tootọ, ṣugbọn a kò le fi ṣakawe ifẹ Ọmọ Ọlọrun, Ẹni ti o kú fun awọn ọta Rè̩.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Ki ni awọn aleebu ti o wà ninu iwa Absalomu?

  2. 2 Ọna wo ni Absalomu gba lati fi iwa asan rè̩ hàn?

  3. 3 Ọna wo ni o gbà lo è̩tan?

  4. 4 Njẹ iwọ ro pe ohun ti o tọ ni fun Dafidi lati sa kuro ni Jerusalẹmu?

  5. 5 Ta ni S̩imei?

  6. 6 Njẹ S̩imei ni ẹtọ lati sọ pe ẹjẹ idile Saulu wà lori Dafidi?

  7. 7 Njẹ Abiṣai ati Dafidi ba ara wọn tan?

  8. 8 Iwọ ha le ri ọwọ Ọlọrun ni ikú Absalomu?

  9. 9 Ohun kan ha wà ti o fi hàn fun ni bi ẹgbẹ ọmọ-ogun ti o ba Dafidi jade lọ ti pọ to?

  10. 10 Ki ni awọn ohun ti o fi hàn ninu ẹkọ wa yii pe Dafidi jẹ ẹni bi ti inu Ọlọrun?