II Samueli 19:9-15

Lesson 242 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Bḝni Kristi pẹlu lẹhin ti a ti fi rubọ lḝkanṣoṣo lati ru è̩ṣẹ ọpọlọpọ, yio farahan nigbakeji laisi è̩ṣẹ fun awọn ti nwo ọna rè̩ fun igbala” (Heberu 9:28).
Cross References

I Ibeere Ọba

1 Israẹli daamu nitori ti a kò ṣeto lati mu ọba wọn pada bọ, II Samuẹli 19:9, 10; Awọn Onidajọ 18:9

2 A bi awọn àgbà Juda leere nipa iwa ainaani wọn nipa ipadabọ Dafidi, II Samuẹli 19:11; II Tẹssalonika 3:8, 9

3 Dafidi ọba rán awọn ará rẹ leti pe ẹran ara ati egungun oun ni wọn i ṣe, II Samuẹli 19:12; 5:1; Awọn Onidajọ 9:2

4 Ijọ ti o jẹwọ Kristi, Ọba wọn ti O n pada bọ wa, nipa ijẹwọ yii, gbà pe wọn ni iṣẹ ati eto kan lati ṣe fun Un, II Samuẹli 19:12; Efesu 5:30

5 Awọn Ọmọ Israẹli jẹ ará Dafidi nipa ti ara nikan, ṣugbọn Onigbagbọ jẹ ẹbi ati ajumọjogun pẹlu Ọba rè̩, II Samuẹli 19:13; Johannu 1:12; Romu 8:16, 17; Galatia 4:7; Efesu 2:19

6 Awọn agba Juda mura giri, a si mu Dafidi pada bọ si ori itẹ rè̩, II Samuẹli 19:13-15

7 Awọn Onigbagbọ ni iṣẹ kan, eyi ni lati ba è̩ṣẹ jagun ki Ọba wọn le tete pada bọ si ori itẹ Rè̩, Numeri 32:6; Awọn Onidajọ 5:23; Jeremiah 48:10

8 Awọn ibatan Kristi ni lati maa wo ọna ki wọn maa reti, ki wọn si maa ṣe afẹri ipadabọ Ọba wọn, Iṣe Awọn Apọsteli 1:11; Matteu 25:6; Luku 13:24, 25

Notes

Ibawi ni Akoko

Ori ẹkọ wa duro lori ipadabọ Dafidi si ori itẹ ti iṣọtẹ Abasalomu ti mu ki o fi silẹ. Otitọ ti bori nipa oore-ọfẹ Ọlọrun, a si ti ṣẹgun awọn ọta Dafidi; ṣugbọn awọn eniyan Dafidi kò ṣe ohunkohun lati mu ọba wọn pada bọ si ipo rè̩. Nikẹyin Dafidi ni lati beere lọwọ awọn agbagba Israẹli eredi ti wọn kò fi ṣe ohunkohun lati mu ọba pada wa sori itẹ rè̩.

Awọn agbagba ẹya Juda ni o yẹ ki o jẹ ẹni iṣaaju lati ṣeto bi Dafidi yoo ti ṣe pada si ori itẹ rè̩. Ifẹ wọn fun Dafidi bi ẹni ti i ṣe ẹya kan naa pẹlu wọn yẹ ki o rú ifẹ wọn soke lati rii pe Dafidi ni o n jọba lori gbogbo Israẹli. S̩ugbọn ohun ti o ṣẹlẹ fi han pe wọn kò ṣe ohun ti o yẹ ki wọn ṣe.

Nitori naa Dafidi fi ibeere kan siwaju wọn nipa ainaani wọn si ipo ti oun wa. Ibeere ti o kan olukuluku wọn ni. “Ẹnyin li ará mi, ẹnyin li egungun mi, ati ẹran ara mi: ẽsi ti ṣe ti ẹnyin fi kẹhìn lati mu ọba pada wá?”

Ainaani ati Ijafara

Ohun ti o mu ki ẹkọ wa yii ki o gbadun mọ awa ti ode oni ni afarawe timọtimọ ti o wà laaarin ainaani awọn arakunrin Dafidi lati mu un pada sori oye, ati iru ainaani kan naa ti o wà ninu Ijọ ti ode oni, lati pade Oluwa ati Ọba wọn, Jesu Kristi.

Awọn eniyan buburu ti wọn kò fẹ ki O jọba ni o ti n fa wiwa Ọba wa sẹyin diẹ si i, lati wa jọba lori itẹ Rè̩. Ni iwọn nnkan bi ẹgbaa ọdun ti o kọja lọ ni O ti pada lọ sọdọ Baba Rè̩ ni Ọrun, sibẹ Oun kò i ti i pada bọ. Ibeere yii ṣe deedee o si jẹ mọ awọn ti ode oni ti o n pe orukọ Kristi, “Ẽṣe ti ẹnyin fi kẹhin lati mu ọba pada wá si ile rè̩?” Awọn wọnni ti o yẹ ki o ni itara gidigidi ki wọn si maa foju sọna fun ipadabọ Ọba wọn, ni o lọra ju lọ nipa rè̩.

Ki i ṣe ohun iyanu pe awọn alaigbagbọ, awọn keferi ati awọn òpè kò ṣe ohunkohun nipa ipadabọ Oluwa lati wa jọba. S̩ugbọn ainaani awọn ti o n pe ara wọn ni ọmọ-lẹyin Ọba ni o jẹ ohun ti o ya ni lẹnu. Aibikita wọn fun igbekalẹ Ijọba Rè̩ ni aye yii ba ni lẹru lọpọlọpọ. Bibeli ṣe alaye eredi rè̩ ti wọn fi jẹ alainaani, o si sọ ohun ti yoo ṣẹlẹ si awọn ẹlẹsin bẹẹ ti kò ṣe ohunkohun lati mu Ọba pada si ori itẹ Rè̩.

Ẹsìn Asan

Ninu gbogbo awọn eniyan ti o wà laye, ọpọlọpọ lero pe awọn Ju, awọn ayanfẹ Ọlorun, ni o ni itara ati ifọkansin si Ọlọrun ju ẹnikẹni lọ ati si ipadabọ Ọba wọn. Ẹsìn ti awọn Ju ti ode oni n ṣe n mu wọn ṣe igbokegbodo asan ni ireti pe Ọba wọn fẹrẹ dé. Ilana isìn Ajọ Irekọja funra rè̩, ki a má tilẹ ṣẹṣẹ wa sọ nipa aye ijoko ti o ṣofo ninu ile olufọkansin Ju kọọkan nigba nì, ni ireti pe Ẹni naa ti wọn n reti yoo wa joko ni aye Rè̩, jẹ apa kan ilana ẹsin awọn Ju ti ode oni bakan naa. Sibẹsibẹ ẹsìn wọn jẹ ẹsìn eke ati ti ode ara ti a ba gbe e le Ọrọ Ọlọrun. Kò ni iyin rara niwaju Ọlọrun.

Kaka ki wọn gba Ọba wọn nigba ti O de, wọn ṣe inunibini kikoro si I gidigidi, wọn kan An mọ agbelebu ninu iṣọtẹ wọn, wọn si tako Ọlọrun ninu ọrọ wọn bayi pe, “Awa kò fẹ ki ọkunrin yi jọba lori wa” (Luku 19:14). Idajọ ti o ti wá sori awọn Ju lati igba naa lọ kò lẹgbé̩. Titi di oni ni awọn Ju n ṣọfọ ipọnju nla naa, wọn si n kigbe ju bẹẹ lọ si Ọlọrun ki O ran Messia wa. Pẹlu gbogbo ipọnju ti o de ba wọn yii, awọn Ju, gẹgẹ bi orilẹ-ede, taku pẹlu orikunkun sibẹ: wọn kò si gbà Kristi gẹgẹ bi Olugbala wọn ati Ọba wọn tootọ.

“Ogiri ọfọ” nibi ti awọn Ju ti n gbe Palẹstini gbe n kigbe si Ọlọrun jẹ eyi ti gbogbo eniyan pupọ mọ dunju-dunju ti wọn si ti sọrọ pupọ le lori. Ogiri yii jẹ apa kan Tẹmpili Sọlomọni ri, eyi ni o si kù fun wọn ninu gbogbo ogo wọn atẹyinwa; nibẹ ni wọn ti n sọkun ti wọn si n pohunrere ẹkún fun ipadabọ Ọba wọn ti o ti wa ti O si ti lọ. Kò ṣanfaani ki a ṣẹṣẹ maa wi pe ki yoo ṣe e ṣe fun awọn eniyan wọnyi lati mu Ọba wọn pada niwọn igba ti wọn ba taku sinu aigbagbọ ati iṣọtẹ wọn.

Fifi Akoko Dọla

Awọn eniyan miiran wà ti wọn n fi bibọ Oluwa wọn falẹ ki wọn ba le maa dẹṣẹ, kaka ki wọn ni ifẹ si ipadabọ Ọba wọn. Awọn wọnyi mọ ifẹ Ọlọrun ati ijiya ti o wà fun aigbọran, sibẹ wọn taku, wọn n dena ipadabọ Ọba wọn, wọn si n fa bibọ Rè̩ sẹyin. (Ka Romu 1:32). Nipa awọn wọnyi ni Oluwa wi pe, ”S̩ugbọn bi ọmọ-ọdọ buburu na ba wi li ọkàn rè̩ pe, Oluwa mi fà àbọ rè̩ sẹhìn; ti o si bè̩rẹ si ilù awọn ọmọ-ọdọ ẹlẹgbẹ rè̩, ati si ijẹ ati si imu pẹlu awọn ọmuti; Oluwa ọmọ-ọdọ na yio de li ọjọ ti kò reti, ati ni wakati ti kò daba. Yio si jẹ ẹ ni ìya gidigidi, yio yàn ipa rè̩ pẹlu awọn agabagebe, nibẹ li ẹkún on ipahinkeke yio gbé wà” (Matteu 24:48-51). Eyi ni ipin awọn ti o mọ rere i ṣe ti wọn kò ṣe e. O di è̩ṣẹ si wọn lọrun. Eredi ti wọn kò fi ṣe ohunkohun lati mu Ọba pada ni pe wọn kò fẹ ri i.

Iru ipo kan naa ni awọn wọnni wa ti Jesu sọ nipa wọn ninu owe Rè̩, ani awọn ti a pe si ibi ase nla ṣugbọn ni ohun kan ti gbogbo wọn bẹrẹsi ṣe awawi. Bi o tilẹ jẹ pe wọn kò sọ pato pe wọn kọ ipe Oluwa wọn, sibẹsibẹ ohun ti awawi wọn jasi ni pe wọn kọ Ọ patapata. Awọn wọnyi ṣe alaibikita fun Ijọba Oluwa. Wọn kò fẹ lati ni ipin ninu rè̩ bi o tilẹ jẹ pe a ti pe wọn. Ọba Nla naa fẹ ki gbogbo ile ki o kún, nitori naa ni O ṣe dabi ẹni pe O n fa Ase Alẹ Igbeyawo sẹyin fun ọdun pupọ titi gbogbo ile yoo fi kún fọfọ.

Ileri Bibọ Rè̩

Ẹwẹ, awọn ẹlẹgan wà ti wọn n beere pe, “Nibo ni ileri wiwa rè̩ gbé wà? lati igbati awọn baba ti sùn, ohun gbogbo nlọ bi nwọn ti wà ri lati igba ọjọ ìwa” (II Peteru 3:4). Ki iṣe pe awọn wọnyi kò ṣe ohunkohun lati mu bibọ Oluwa wọn ya kankan nikan, ṣugbọn wọn lodi si i gidigidi. Wọn tilẹ sọ pe kò si ohun ti o jọ bẹẹ, nitori naa wọn n fi awọn Onigbagbọ ti wọn n ṣe aapọn lati waasu Ihinrere kaakiri gbogbo aye ṣe ẹlẹyà.

Kò si ohun ti o le mu bibọ Jesu lẹẹkeji ya kankan bi iwaasu Ihinrere. Ọlọrun n duro titi Oun yoo fi ri i pe gbogbo ọkàn ti n fẹ ri igbala, di ẹni igbala, ati titi ẹni ti o kẹyin yoo fi wọle. Jakọbu gba awọn arakunrin rè̩ niyanju lati jẹ olóòótọ ninu ọran yii, ki wọn si maa fi suuru ṣiṣẹ Ọba wọn. “Nitorina ará, ẹ mu sụru titi di ipadawa Oluwa. Kiyesi i, àgbẹ a mā reti eso iyebiye ti ilẹ, a si mu sụru de e, titi di igbà akọrọ ati arọkuro òjo” (Jakobu 5:7).

Awọn ti a Pe ti a si Yàn

Ninu gbogbo aibikita, ojukokoro, imọ-ti-ara-ẹni-nikan ati aigbagbọ awọn ti wọn n pe ara wọn ni ọmọlẹyin Kristi, awọn kan wà ti wọn jẹ olododo ati olóòótọ si Ọba wọn; awọn wọnyi ni yoo ṣe pataki okunfa ipadabọ Ọba. Awọn ni olóòótọ ti Iwe Mimọ pe ni “Ayanfẹ” (I Peteru 1:2), “Ijọ akọbi” (Heberu 12:23), ati “awọn ọmọ Ọlọrun” (I Johannu 3:1). Awọn wọnyi ni a ti fi Ẹjẹ Jesu Kristi wẹ è̩ṣẹ wọn nu, wọn si jẹ egungun ninu egungun Rè̩ ati ẹran ara ninu ẹran ara Rè̩. (Wo Efesu 5:30). Awọn ni ẹni ti o ti ni iriri atunbi tootọ ti wọn si ti di ẹbi Ọlọrun. Wọn ti di ọmọ Ọlorun ni tootọ, Jesu kò si tiju lati pe wọn ni arakunrin. (Ka Heberu 2:11).

Apapọ awọn Onigbagbọ wọnyi ni a n pe ni Ijọ Kristi tootọ. Iwe Mimọ pe wọn ni “Ijọ”. Awọn wọnyi ni Stefanu n sọ nipa rè̩ nigba ti o ran awọn Ju leti nipa ohun ti Mose sọ nipa Kristi pe, “Eyi na li ẹniti o wà ninu ijọ ni ijù pẹlu angẹli na ti o ba a sọrọ li òke Sinai, ati pẹlu awọn baba wa: ẹniti o gbà ọrọ iyè lati fifun wa” (Iṣe Awọn Aposteli 7:38). Orukọ ti a fun Ijọ ni ede Griki ni Eklesia, eyi ti itumọ rè̩ jẹ “awọn ti a pè jade” tabi “awujọ”. Ọlọrun ni Ijọ kan laarin ijọ, awọn ti O pè jade. Laaarin awọn ijọ ẹlesìn ninu aye, awọn kan wà ti o jẹ ti Rè̩ lotitọ -- awọn ni ẹni ti yoo mu Ọba pada bọ!

Otitọ yii tun fara han ninu owe èpo ati alikama. Epo, ti i ṣe apẹẹrẹ awọn alafẹnujẹ Onigbagbọ ti wọn n ṣe afarawe iwabi-Ọlọrun, a maa dagba laaarin alikama, eyi ti i ṣe apẹẹrẹ awọn ọmọ Ọlọrun tootọ. Gbogbo wọn a maa dagba pọ, ẹni ti kò ba si ṣe akiyesi daradara kò le mọ iyatọ laaarin awọn mejeeji. S̩ugbọn owe yii kọ ni pe nigba ikore, a o ya wọn si ọtọọtọ. A o fi ina sun èpo, ṣugbọn awọn alikama ni a o ko jọ sinu abà. Eyi yii tun fi han fun ni pe awọn ayanfẹ wà, awọn ti a yàn laaarin oniruuru ati oriṣiriṣi ẹsin ode oni. (Ka Matteu 13:24-30).

Awon ẹgbẹ ayanfẹ yii ni Ijọ Kristi ti o n ṣiṣẹ t’ọsan t’oru lati tan Ihinrere kalẹ, ti wọn si n kede otitọ rè̩ yii gbogbo aye ka; wọn si n ṣiṣẹ titi di igbà aṣaalẹ lati mu ki ipadabọ Ọba wọn yá kankan. O le dabi ẹni pe ohun ti wọn n ṣe kere, o si le ṣai jọ ni loju, ṣugbọn aṣeyọri pupọ ni wọn n ṣe. Iṣẹ wọn dabi iwukara ti a fi sinu iyẹfun ninu ọpọn ipo-akara, eyi ti n ṣiṣẹ gidigidi jakejado gbogbo iyẹfun naa, titi gbogbo akara naa yoo fi di wiwú (Ka Matteu 13:33). Nigba ti agbara Ihinrere ba di mimọ yikaakiri gbogbo agbaye, nigba naa ni Ọba yoo le pada bọ. (Ka Matteu 24:14).

“Yio farahan nigbakeji laisi è̩ṣẹ fun awọn ti nwo ọna rè̩ fun igbala” (Heberu 9:28). Eyi kọ wa pe, awọn ti o ba n wo ọna fun bibọ Rè̩ nikan ni yoo ri I; lai si aniani, nitori pe wọn n ṣọna wọn si n fẹ ki O pada bọ ni Oun yoo ṣe pada wa. Jesu sọ fun awọn ọmọ-ẹhin Rè̩ pe, “Bi mo ba si lọ ipèse àye silẹ fun nyin, emi o tún pada wá, emi o mu nyin lọ sọdọ emi tikarami; pe nibiti emi gbé wà, ki ẹnyin le wà nibẹ pẹlu” (Johannu 14:3). Oun yoo tun pada wa nitori oungbẹ ọkàn awọn ti o n bẹbẹ ninu Ẹmi fun Ọkọ-iyawo ọkàn wọn. Ifẹ ati aniyan awọn Onigbagbọ fun Oluwa wọn yoo mu Ọba pada bọ.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Ki ni ti Dafidi fi beere lọwọ awọn arakunrin rè̩ idi ti wọn kò fi ṣe ohunkohun lati mu oun pada sori itẹ bi ọba wọn?

  2. 2 Ọna wo ni ohun ti o n ṣẹlẹ lode oni fi jọ ti igbà nì?

  3. 3 Awọn ta ni ninu awọn eniyan ti o yẹ ki o ṣe iranlọwọ lati mu ọba pada bọ, ṣugbọn ti wọn kò ṣe ohunkohun?

  4. 4 Awọn ta ni Ijọ tootọ?

  5. 5 Ọna wo ni awọn Onigbagbọ le gba lati ṣe iranlọwọ lati mu Ọba pada bọ?

  6. 6 Nigba wo ni Oluwa yoo pada bọ?

  7. 7 Njẹ awọn Ju fẹ ki Jesu pada wa?

  8. 8 Njẹ awọn Ju gbà Kristi ni Messia?