Lesson 243 - Senior
Memory Verse
AKỌSORI: “S̩ugbọn ānu OLUWA lati aiyeraiye ni lara awọn ti o bè̩ru rè̩, ati ododo rè̩ lati ọmọ de ọmọ” (Orin Dafidi 103:17).Cross References
I Iyàn Ọdun Mẹta ati Eredi Rè̩
1 Dafidi beere lọwọ Oluwa nipa iyàn naa, II Samuẹli 21:1; I Awọn Ọba 17:1; 18:17, 18
2 Saulu ti pa awọn ara Gibeoni lọna aitọ, II Samuẹli 21:1
3 Ọranyan ni fun Israẹli lati duro ti majẹmu ti wọn ba awọn ara Gibeoni dá, II Samuẹli 21:2; Jọṣua 9:3-27
II Ibeere awọn ara Gibeoni fun Igbẹsan Ibi ti a S̩e si Wọn
1 Dafidi jẹwọ ibi naa, II Samuẹli 21:3; Owe 14:34
2 A mu ibeere awọn ara Gibeoni ṣẹ, II Samuẹli 21:4-9
3 Rispa ṣọfọ awọn ọmọ rè̩, II Samuẹli 21:10, 11
4 Dafidi bọwọ fun ile Saulu II Samuẹli 21:12-14; 2:5, 6
III Iṣẹgun Ikẹyin lori awọn Filistini
1 Iṣbi-benobu omiran, arakunrin Goliati, gbiyanju lati pa Dafidi, II Samuẹli 21:15, 16
2 Abiṣai gba ẹmi Dafidi là, II Samuẹli 21:17; I Samuẹli 26:8; II Samuẹli 16:9; 19:21; 23:18, 19
3 Iṣẹgun ikẹyin lori awọn omiran Gati, IISamuẹli 21:18-22; I Kronika 20:4-8
Notes
Iyàn
“Iyan kan si mu li ọjọ Dafidi . . . Dafidi si bere lọdọ Oluwa” (II Samuẹli 21:1). Gẹgẹ bi akọsilẹ ninu iwe itan ti sọ fun ni, ọpọlọpọ iyàn ni o ti mú, ṣugbọn awọn eniyan bi ti Dafidi kò pọ, awọn wọnni ti yoo wadi ohun ti o fa a ati ohun ti wọn ni lati ṣe lati fi opin si ohun ti o ṣẹlẹ. Dajudaju, a ni awọn ọlọgbọn ori ti wọn ti ṣe iwadi lati mọ nipa erupẹ ilẹ, eredi irè̩dànu ohun ọgbìn ati ilẹ yiyán, ṣugbọn wọn kuna lati ri ọwọ Ọlọrun ninu àjálù wọnyi. Eliṣa sọ fun obinrin ara S̩unemu pe, “Oluwa pe iyàn” (II Awọn Ọba 8:1). Aye ode-oni n fẹ iru awọn eniyan bi Eliṣa ati Dafidi, awọn ẹni ti wọn mọ ipe Ọlọrun ninu iyàn. Onipsalmu sọ fun wa pe: “O sọ odò di aginju, ati orisun omi di ilẹ gbigbẹ; ilẹ eleso di aṣálè̩ nitori ìwa buburu awọn ti o wà ninu rè̩” (Orin Dafidi 107:33, 34).
Eredi Rè̩
Ogun, iyàn ati àjalù jẹ ohun ti o wọpọ lode oni, awọn diẹ si ti kede ki a gbadura, ṣugbọn kò si iyipada kuro ninu iwa buburu ati è̩ṣẹ ti i ṣe kókó ohun ti o mu ìyọnu naa wa. Awọn ọjọgbọn n sọ ikuna ti o wà ninu eto inawo, ibisi ati ọna ti a fi n gbìn awọn ohun ọgbìn ati awọn ohun miiran pẹlu; ṣugbọn diẹ, bi o ba tilẹ wà rara, ni o ri ọwọ Ọlọrun ninu awọn ọran adiitu wọnyi.
Aye ode-oni kò fẹ ohunkohun ti o le din ọti kù, tabi iwa buburu, tabi è̩ṣẹ. Ọlọrun sọ fun Israẹli lati ẹnu Woli Amosi pe Oun ran iyàn, ilẹ gbigbẹ, kòkòrò jewéjewé, ajakalẹ arùn, ogun ati iná saaarin wọn, “sibè̩ ẹnyin kò ti ipadà sọdọ mi” (Amosi 4:11). Ayé wa ninu ipaya lọjọ oni fun ohun ti o de ba wọn ṣugbọn oju wọn fọ si ọna ti wọn le gbà lati bọ. Aye n fẹ alaafia, ṣugbọn wọn kọ eti didi si ipe Ọmọ Alade Alaafia. Lati ayebaye ni awọn Woli ti n kede pe, “Ẹ ronupiwada! Ẹ ronupiwada!” ṣugbọn ọmọ-eniyan kò ronupiwada. “Ẹ yipada, ẹ yipada kuro ninu ọna buburu nyin; nitori kini ẹnyin o ṣe kú?” (Esekiẹli 33:11). Sibẹsibẹ aimoye ọkẹ eniyan ni o n tọ ọna è̩ṣẹ ati ikú nigba ti iparun n rọdẹdẹ ni ori orilẹ-ède wa.
Adehùn
Ohun ti Ọlọrun sọ fun Dafidi pe o fa iyàn ni pe, “Nitori ti Saulu ni, ati nitori ile rè̩ ti o kún fun è̩jẹ, nitoripe o pa awọn ara Gibeoni” (II Samuẹli 21:1). Awọn ara Gibeoni yii ni wọn tọ Jọṣua wá lẹyin iṣubu Jẹriko ti wọn fẹ ba Israẹli dá majẹmu. Wọn wá pẹlu aṣọ ti o ti gbó ati akara ti o hùkasi, wọn si fi ara hàn bi ẹni ti o ti ọna jijin wa; nipa bayi, wọn fi è̩tan mu Jọṣua lati ba wọn ṣe adehùn alaafia. Bi o tilẹ jẹ pe aṣẹ Ọlọrun kọ fun awọn Ọmọ Israẹli lati ba awọn eniyan ilẹ naa dá majẹmu, bi o si tilẹ ti jẹ pe è̩tan ni awọn ara Gibeoni lo lati mu Israẹli ba wọn dá majẹmu, sibẹ Ọlọrun fẹ ki awọn Ọmọ Israẹli duro ti ọrọ wọn. O rọrun fun awọn eniyan lode oni lati maa wá ọna lati ja àjàbọ, ati lati maa ṣe awawi fun aile mu ọrọ wọn ṣẹ; ṣugbọn olukuluku ẹni ti o ba fẹ fi Ọrun ṣe ile yoo jẹ “Ẹniti o bura si ibi ara rè̩, ti kò si yipada” (Orin Dafidi 15:4).
Irinwo ọdun ti kọja lẹyin ti Israẹli ti ba awọn ara Gibeoni da majẹmu, ṣugbọn Ọlọrun ranti rè̩ O si n beere rẹ lọwọ wọn. Adehun laaarin awọn orilẹ-ède kò jamọ nnkankan loju awọn eniyan lode oni. Asọdun ati èké ti gba ayé kan. Ọlọrun n fẹ ki awọn eniyan Rè̩ jẹ olóòótọ. “Ohun ti o ba ti ète rẹ jade, ni ki iwọ ki o pamọ, ki o si ṣe” (Deuteronomi 23:23). Paulu sọ fun wa nipa ifẹsẹmulẹ majẹmu ti Ọlọrun ba Abrahamu dá, o si wi pe Ofin Mose ti o dé ni ọgbọn-le-nirinwo ọdun lẹyin ileri naa kò le sọ ileri naa di asan, tabi alailagbara. Ọlọrun jẹ olóòótọ si Ọrọ Rè̩, O si n fẹ ki awọn eniyan Rè̩ ki o duro ti ọrọ wọn pẹlu.
Ọkàn ti o S̩è̩
Oluwa kà ẹbi iyàn yii si Saulu ati ile rè̩ lọrùn. Nigba ti awọn ara Gibeoni beere fun ọmọkunrin meje ninu awọn ọmọ Saulu lati so wọn rọ, Dafidi fi wọn le awọn ara Gibeoni lọwọ. Eyi ki i ṣe bibẹ è̩ṣẹ baba wo lara ọmọ, ṣugbọn niwọn igba ti Oluwa ti kà ẹbi yii si Saulu ati ile rè̩ lọrùn, o daju pe awọn ọdọmọkunrin wọnyi jẹbi è̩ṣẹ kan naa pẹlu baba wọn. Àṣà awọn keferi lati maa pa awọn ti a fi sọfa ni a kò gba layè ni ilẹ Israẹli. Ilana ofin ni pe, “A kò gbọdọ pa awọn baba nitori è̩ṣẹ awọn ọmọ, bḝni a kò gbọdọ pa awọn ọmọ nitori awọn baba: olukuluku enia li a o pa nitori è̩ṣẹ rè̩” (Deuteronomi 24:16). Esekiẹli sọ fun wa pẹlu pe: “Ọkàn ti o ba ṣè̩, on o kú. Ọmọ ki yio rù aiṣedẽde baba, bḝni baba ki yio rù aiṣedẽde ọmọ: ododo olododo yio wà lori rè̩, iwa buburu enia buburu yio si wà lori rè̩” (Esekiẹli 18:20).
Ọpọlọpọ eniyan ni o n kú lai jẹ pe wọn ṣè̩ si ofin ilu. Nigba miiran a n kà nipa ẹni ti a jẹ niya nitori è̩ṣẹ ẹlomiran. S̩ugbọn Oluwa kò gba pe ki ẹnikẹni jiya ikú gẹgẹ bi etutu fun è̩ṣẹ ti ẹlomiran dá. Igba kan ṣoṣo ninu Iwe Mimọ ti alaiṣẹ kú lati ṣe etutu fun ẹlẹbi ni igbà ti Jesu Kristi jiya – olododo fun alaiṣododo. Jesu, Ẹni ti kò ni è̩ṣẹ fi tifẹtifẹ yàn lati jiya lori agbelebu fun è̩ṣẹ gbogbo agbaye. “S̩ugbọn Ọlorun fi ifẹ on papa si wa hàn ni eyi pe, nigbati awa jẹ ẹlẹṣẹ, Kristi kú fun wa” (Romu 5:8).
Awọn ojiyàn le maa sọ fun ni pe ofin sọ pe a o bẹ è̩ṣẹ awọn baba wò lara ọmọ wọn, ki wọn si maa fi ẹsẹ Ọrọ Ọlọrun ti o sọ bayii gbe ara wọn lẹsẹ: “Emi li OLUWA Ọlọrun rẹ, Ọlọrun owú ni mi, ti mbè̩ è̩ṣẹ awọn baba wò lara awọn ọmọ, lati irandiran kẹta ati ẹkẹrin ninu awọn ti o korira mi” (Ẹksodu 20:5). Ọna kan ṣoṣo ti a le gbà tumọ ẹsẹ yii gẹgẹ bi igbekalẹ Iwe Mimọ ni pe nigbà ti a ba bè̩ è̩ṣẹ baba wo lara ọmọ wọn, a bẹ ẹ wò lara wọn nitori pe awọn ọmọ paapaa kò kuro ninu è̩ṣẹ kan naa ti awọn baba wọn dá.
Eyi yii ni ohun ti o ṣẹlẹ si awọn Amaleki. Idajọ ti a pinnu lori orilẹ-ede awọn Amaleki lati igbà ti wọn ti ba awọn Ọmọ Israẹli ja ni a kò mu ṣẹ titi di ẹyin irinwo ọdun, iran kẹrin tabi ju bẹẹ si ti kọja lọ nigba naa. Alaigbagbọ le beere pe, “Ki ni eyi ni i ṣe pẹlu è̩ṣẹ ti baba nla wọn ti ṣẹ ni irinwo ọdun sẹyin?” Eredi rè̩ ni pe wọn kò jawọ kuro ninu è̩ṣẹ kan naa; iwa wọn kò si yipada: ẹmi kan naa ni o n ṣe akoso ọkàn wọn ninu ibálo wọn pẹlu awọn eniyan Ọlọrun gẹgẹ bi ti awọn baba nla wọn (Ka Luku 11:48-51).
Ifẹ Iya
Rispa ti i ṣe iya awọn meji ninu awọn ọmọ Saulu ti a so rọ “mu aṣọ ọfọ kan, o si té̩ ẹ fun ara rè̩ lori àpata, ni ibẹrẹ ikore, titi omi fi dà si wọn lara lati ọrun wá, kò si jẹ ki awọn ẹiyẹ oju ọrun bà le wọn li ọsan, tabi awọn ẹranko igbẹ li oru” (II Samuẹli 21:10). Nigba ti a royin fun Dafidi, iru ifẹ ti iya naa ni si awọn ọmọ rè̩ wọnyi, o paṣẹ pe ki a sin okú wọn, ati egungun Saulu ati ti Jonatani si ilẹ kan naa ti i ṣe ti idile wọn. “Ọlọrun si gbà ẹbẹ nitori ilẹ na” (II Samuẹli 21:14). Lẹyin ti wọn ti ṣe atunṣe ti o tọ, Ọlọrun tun rọ ojo ibukun sori ilẹ Israẹli.
Awọn Òmirán
Lẹyin ọdun marundin-laadọta ti Dafidi ti pa Goliati, arakunrin rè̩ Iṣbi-benobu, ẹni ti o san idà titun, ti o si ru ọkọ nla, wa ọna lati pa Dafidi. Ogun jija fun ọpọlọpọ ọdun ti jẹ ki aarẹ mu Dafidi, ṣugbọn Abiṣai arakunrin rè̩ ti o si jẹ ọkan ninu awọn akọni ninu iranṣẹ Dafidi pa òmirán naa, o si gba ẹmi ọba rè̩ la. Awọn arakunrin Goliati mẹta miiran dide si awọn Ọmọ Israẹli, awọn akọni ni Israẹli si tun bi wọn ṣubu. Awọn Ọmọ Israẹli kò ja ija naa ninu agbara wọn nikan, nitori Ọlọrun wà pẹlu wọn. Alakoso wọn, Olorin didùn ni Israẹli jẹ ẹni bi ti inu Ọlọrun.
Questions
AWỌN IBEERE1 Ki ni ṣe ti iyàn fi mu ni ilẹ Israẹli?
2 Ta ni awọn ara Gibeoni i ṣe?
3 Ki ni ṣe ti kò fi tọna fun Saulu lati pa awọn ara Gibeoni?
4 Iru aiṣedeedee ti o jọ bẹẹ wo ni Saulu tun jẹbi rè̩?
5 Bawo ni a ṣe mọ pe ọwọ awọn ọmọ Saulu kò mọ ninu pipa awọn ara Gibeoni?
6 Sọ diẹ ninu awọn igbà miiran ti a mẹnu kan ninu Bibeli pe iyàn mu?
7 Njẹ awọn ọmọ a maa jẹbi nitori è̩ṣẹ awọn obi wọn?
8 Darukọ igbà kan ti alailẹṣẹ jiya lati ṣe etutu fun è̩ṣẹ ẹlẹbi.
9 Awọn òmirán wo ni a darukọ ninu ẹkọ yii?
10 Bawo ni Dafidi ti dagba to ni akoko yii?