II Samuẹli 22:1-51

Lesson 244 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Iwọ mu awọn enia gùn wa li ori: awa nwọ inu iná ati omi lọ, ṣugbọn iwọ mu wa jade wá si ibi irọra” (Orin Dafidi 66:12).
Cross References

I Ile-odi Agbara ni Oluwa

1 A kọ iwe yii silẹ lẹyin iṣẹgun Dafidi lori gbogbo awọn ọta rè̩, II Samuẹli 22:1

2 Oluwa ni Apáta, Odi ati Olugbala Dafidi, II Samuẹli 22:2; Orin Dafidi 18:1, 2

3 Asà ni Oluwa jẹ, Iwo igbala, Ibi-isadi giga, igbẹkẹle Dafidi, igbala, ibi-aabo ati Olugbala rè̩, II Samuẹli 22:3

II Lọwọlọwọ Iranlọwọ ni Igba Ipọnju

1 Dafidi wà ninu idaamu boya nipasẹ Saulu, II Samuẹli 22:5, 6; I Samuẹli 23:26-28; 27:1; Orin Dafidi 18:4, 5

2 Ninu idaamu rè̩, Dafidi ké pe Oluwa, II Samuẹli 22:4, 7; Luku 22:41-44; Orin Dafidi 18:3, 6

III O Lagbara lati Gbala, O si ni Ipá lati Gba Ni

1 Ọrun ati aye mì titi nigba ti Ọlọrun dide ni igbẹsan lati tú awọn ọta Rè̩ ka, II Samuẹli 22:8-16; Orin Dafidi 93:1; 18:7-15; Iṣe Awọn Apọsteli 4:23-31; 16:25, 26; Matteu 28:2-4

2 Iṣẹ igbala nla ṣe ni idahun si adura, II Samuẹli 22:17-20; Orin Dafidi 31:7, 8; 18:16-19

IV Ere Ododo

1 Dafidi ri idasilẹ nitori igbesi-aye iduroṣinṣin rè̩, II Samuẹli 22:21-25; Orin Dafidi 4:3; 18:20-24; 34:17; Heberu 1:9

2 Ọlọrun a maa nawọ aanu Rè̩ si awọn alaaanu, II Samuẹli 22:26-28; Matteu 6:12, 14; Orin Dafidi 18:25-27

V A ko le Bori Eniyan Ọlọrun

1 Ọlọrun n fun ni ni agbara fun ogun, II Samuẹli 22:29-40; Orin Dafidi 18:28-39; Filippi 4:13

2 Oun a maa tẹri awọn ọta wa ba fun wa, II Samuẹli 22:41-46; Orin Dafidi 18:40-45; Deuteronomi 11:25; Luku 10:19

3 Onipsalmu, ni ikẹyin fi ọla fun Ọlọrun ti o lagbara ni ogun, II Samuẹli 22:47-51; Orin Dafidi 18:46-50

Notes

Ọpọlọpọ eniyan ni o gbà pe Psalmu yii n sọ asọtẹle nipa Messia (tabi Kristi), iṣẹ iranṣẹ Rè̩ tabi wiwá Rè̩ si aye. Dafidi n yin Oluwa nitori ti O yọ ọ kuro ninu ipọnju rè̩, O si fun un ni iṣẹgun lori awọn ọta rè̩; bakan naa, nipa imisi Ẹmi Mimọ, o sọ asọtẹlẹ ti o larinrin pupọ fun ni nipa Messia. Ọpọlọpọ iriri Dafidi ni o dọgba pẹlu igbesi aye Kristi.

Saulu jẹ Dafidi niya o si rè̩ ẹ silẹ lọpọlọpọ. Jesu paapaa jiya iyọṣuti si ati irè̩silẹ ni aye yii. Jesu tẹ è̩yìn Rè̩ ba fun awọn aluni ati ẹrẹkẹ Rè̩ fun awọn ti o fa A ni irun tu. A mu Un lọ “bi ọdọ-agutan fun pipa,” ṣugbọn O jinde pẹlu iṣẹgun lori iku, ipo-oku ati iboji.

Dafidi kò rin deedee ni gbogbo igbesi-aye rè̩ gẹgẹ bi Jesu ti ṣe; ṣugbọn lori iwe yii, ti o dabi ẹni pe o n sọ pataki ohun ti o ṣẹlẹ laaarin Dafidi ati Saulu, a ri i pe kò si ẹbi ninu Dafidi rara, o si fi aanu hàn fun Saulu.

Apata ati Aabo

Ni ibẹrẹ orin yii, Dafidi sọ ẹri rẹ. O sọ bi Oluwa ti ṣọwọn fun un to. Ohun ti o wà lọkàn rè̩ ni eyi pe, “OLUWA li apata mi; ati odi mi.” Bi Dafidi ti n ra pálá lori pàlàpálá apata nibi ti o gbe n sa fun Saulu o ri i pe apata wọnyi jẹ odi fun oun, ni ọpọlọpọ igba. Bakan naa ni Oluwa jẹ Odi fun ọkàn rè̩. Ọpọlọpọ igba ni ọta yi i kaakiri, ti ọwọ si fẹrẹ tẹ ẹ nipa ti ẹmi, ṣugbọn nigba ti ọta ẹmi rè̩ ba gba ọna kan yọ, nipa itọni Ọlọrun, Dafidi a gbà ọna miiran jade. Nitori naa Oluwa ni aabo Dafidi ni ọjọ gbogbo.

Iwo Igbala

“On ni asa mi ati iwo igbala mi.” Iwo, ninu Ọrọ Ọlọrun duro fun agbara. Oun ni ohun ija ti Ọlọrun fi fun malu, o si jẹ aabo ati agbara rè̩. Bakan naa ni o ri fun awọn ẹranko miiran pẹlu. Nitori eyi, a maa n tọka si awọn alakoso ijọba bi iwo ninu Ọrọ Ọlọrun. Itumọ “Iwo igbala mi” ni igbala ti o ni awọn amuyẹ, ti o lagbara, ti o si muná.

Igbala nla ti Oluwa ti pese fun wa kò kú si ibikan rara. Nipa rè̩ ni a sọ wa di ominira kuro lọwọ agbara ati igbekun è̩ṣẹ. O gba pe ki a ni oludande ti o lagbara lati le dá ọkàn nide kuro lọwọ idẹkun Satani ati iwa buburu ti è̩ṣẹ ti lè̩ mọ igbesi-aye oluwarẹ. S̩ugbọn igbala ti Jesu Kristi rà fun wa tó. O si peye. Ohun gbogbo ti o yẹ fun iṣelogo wa nikẹyin ni o wa ninu rè̩.

Ibìlù Ikú

“Ibilu irora ikú yi mi kakiri.” O ṣe e ṣe ni ọpọlọpọ igba ti Dafidi fi n sa fun Saulu, ki Dafidi wà lai sùn ni ọpọlọpọ oru ni ẹba oke tabi ninu iho ilẹ tabi iho apata. Lai si aniani yoo maa ro pe boya ni ilẹ ọjọ keji tun le mọ ba oun.

Ẹni ti o kọ Episteli si awọn Heberu darukọ Dafidi pẹlu awon woli igba nì ti “nwọn rin kákiri ninu awọ agutan ati ninu awọ ewurẹ; nwọn di alaini, olupọnju, ẹniti a ndá loro; . . . ninu aṣálẹ, ati lori òke, ati ninu ihò ati ninu ihò abẹ ilẹ.”

“Iṣàn enia buburu dẹruba mi.” Awọn ọmọ-ogun Saulu ati awọn Filistini, bi riru igbi omi okun, a maa dẹruba Dafidi lẹẹkọọkan. S̩ugbọn Ọlọrun gbọ igbe rè̩, O si yọ ọ kuro ninu gbogbo ẹru rè̩ ati gbogbo ewu ti o yi i ka.

Ọrun ati Aye Mì Tìtì

Apejuwe ti Dafidi ṣe nihin yii nipa ọna ti Ọlọrun fi gbọ igbe rè̩ fun iranlọwọ jẹ afikun awọn itan ti o wà ninu akọsilẹ. S̩ugbọn awọn apejuwe yii kò fi iṣẹgun rè̩ han nikan, ṣugbọn wọn jẹ asọtẹlẹ nipa Messia pẹlu, ti o n tọka si ikú ori agbelebu ati ajinde Olugbala.

A ṣe apejuwe Oluwa nihin yii bi ologun ti O n ti Ọrun sọkalẹ wá, ti O gun kerubu lẹṣin, a si gbe E ka ori iyẹ apa afẹfẹ, ẹfufu lile si n dari Rè̩. O fi okunkun ṣe gọbi yi ara Rè̩ ka. Aara ti n san, manamana, ina ajonirun, iṣan omi ati ẹfuufu lile ni kẹkẹ ibinu Rè̩ jẹ. Ẹẹfin ti o n ti iho imu Rè̩ jade ati ina ti o n ṣẹ jade lati ẹnu Rè̩ wá jẹ apejuwe ibinu Oluwa. Ilẹ aye mì o si wariri. Isẹlẹ sẹ o si mi ipilẹ awọn oke; O fa awọn apata ya; orisun omi si tu jade. A le ri i pe nigba ti Ọlọrun ba sọrọ lọna bayii, awọn ọmọ eniyan yoo sa kuro niwaju Rè̩.

Wo bi eyi ti jọ ohun ti o ṣẹlẹ nigba ti a kan Jesu mọ agbelebu ati igba ti O jinde! Nipa iṣẹlẹ yii, ẹni ti o kọ iwe Ihinrere sọ bayi pe, “Isẹlẹ nla sẹ: nitori angẹli Oluwa ti ọrun sọkalẹ wá, o si yi okuta na kuro, o si joko le e. Oju rè̩ dabi manamana, aṣọ rè̩ si fún bi è̩gbọn owu: Nitori è̩ru rè̩ awọn oluṣọ warìrì, nwọn si dabi okú” (Matteu 28:2-4). Ati “Lati wakati kẹfa, ni òkunkun ṣú bò gbogbo ilẹ titi o fi di wakati kẹsan . . . Si wo o, aṣọ ikele tempili si ya si meji lati oke de isalẹ; ilẹ si mì titi, awọn apata si sán; awọn isà okú si ṣí silẹ; ọpọ okú awọn ẹni mimọ ti o ti sùn si jinde, nwọn ti inu isà okú nwọn jade lẹhin ajinde rè̩” (Matteu 27:45, 51-53). Wo bi ede ti a lo nihin ti jọ eyi ti a lo lati ṣe apejuwe ipadabọ Kristi ni igba ifarahan Rè̩! (Ka Ifihan 19:11-16).

A ranti pe isẹlẹ ti o sẹ laaarin ọganjọ oru ni o ṣi ilẹkun tubu silẹ fun Paulu ati Sila. Ọlọrun kan naa ti o yọ Dafidi, Paulu ati Sila ati ailonka awọn eniyan mimọ ati awọn ajagun fun Ọlọrun, yoo yọ olukuluku wa. Agbara Rè̩ wà bakan naa loni. Aanu Rè̩ kari gbogbo eniyan. S̩ugbọn a kò i ti fi kikún ogo Rè̩ hàn fun aye yii.

Ere Ododo

“Oluwa san a fun mi gẹgẹ bi ododo mi.” Dafidi fi ọkàn otitọ bá Saulu lo nigba gbogbo. Dafidi kò gbe ọwọ rè̩ soke lẹẹkan lati pa Saulu lara. Bẹẹ ni kò si gba fun awọn ọmọ-ogun rè̩ lati ṣe Saulu ni ibi. Iru ọkàn diduro-ṣinṣin bẹẹ ni o fun Dafidi ni igboya nigba ti o wà ninu ipọnju.

Nigba ti eniyan ba duro ti ẹjẹ rè̩ pẹlu Ọlọrun ti o si n rin pẹlu Ọlọrun ni ọwọ mimọ ati aya funfun, yoo si ṣe, ni akoko wahala, yoo ni anfaani lati tọ Ọlọrun wa pẹlu igboya lati rọ mọ ileri Rè̩. Kò si ohun ti yoo dena igbagbọ rè̩. Ọkàn rè̩ yoo wa ni idapọ mimọ, yoo si ṣe deedee pẹlu Ọlọrun.

A sọ fun wa pe nigba ti Isaiah jiṣẹ fun Ọba Hesekiah pe ki o pa ilẹ ile rè̩ mọ, nitori pe yoo kú, o ni anfaani lati ké pe Oluwa pẹlu igboya lati sun ọjọ aye rè̩ siwaju. Hesekiah yi oju rè̩ si ogiri, o si gbadura, o si sọ fun Oluwa pe oun ti rìn niwaju Rè̩ ni otitọ inu ati ọkàn pipe, oun si ti ṣe eyi ti o dara niwaju Rè̩. Lẹsẹkẹsẹ ni o ri idahun adura rẹ gbà lati Ọrun wá! Isaiah kò i ti kuro nibẹ nigba ti Oluwa sọ fun un lati lọ sọ fun Hesekiah pe Oun ti gbọ adura rè̩. “Olododo li OLUWA, o fẹ ododo” (Orin Dafidi 11:7).

Ẹwẹ, bi ẹni kan ba n rin ségesège ti o si kùna lati san ẹjẹ rè̩, ti kò si sọ ifararubọ rè̩ di ọtun, ti o si gba è̩ṣẹ li aya rẹ, tabi ti o ṣe ohun ibi kan, ni ọjọ idaamu rè̩, yoo gba ki o sọ ẹjẹ ati ifararubọ rẹ di ọtun, ki o si mu ohun idena ti o wà ni ọna igbagbọ rẹ kuro, ki o to le ni igbẹkẹle ninu Ọlọrun. Igbesi aye iduroṣinṣin jẹ odi nla ti ọta ẹmi kò le doju kọ. (Ka 1 Johannu 3:18-22).

Irẹlẹ ati Aanu

Dafidi sọ nihin nipa aanu ati bi o ti jẹ ọranyàn lati jẹ alaaanu. Nigba pupọ ni Dafidi fi aanu hàn fun Saulu. Ninu iwaasu Jesu lori Oke, O sọ fun ni pe, “Alabukún-fun li awọn alānu: nitori nwọn ó ri ānu gbà.” Oluwa mọ awọn wọnni ti n fi aanu ba awọn ẹlẹgbẹ wọn lo ni gbogbo iṣe wọn, O si n san an fun wọn. Oluwa n dari gbogbo è̩ṣẹ wa ji gẹgẹ bi awa ti n dariji awọn ti o ṣẹ wa.

“Irẹlẹ rẹ si ti sọ mi di nla.” Oluwa kọ Dafidi nipa ipọnju wọnni ti o de ba a lati le fara da ati lati dariji, lati jẹ alagbara nigba ipọnju ati onirẹlẹ nigba ọpọ ibukun.

Dafidi, gẹgẹ bi ẹda, ni ẹbun ifarada ati agbara. S̩ugbọn lati ọwọ Ọlọrun, Dafidi ri ibukun ti kò lẹgbẹ gbà; nigba ti o si n ba Ọlọrun rin, kò si ọta ti o ni agbara lati bori rè̩. Dafidi mọ pe Ọlọrun ni o yọ oun kuro ninu ewu ti O si jẹ ki oun ṣe aṣeyọri nipa ti ẹmi ati nipa ti ara. Kókó orin daradara yii ni fifi iyin fun Ọlọrun fun aṣeyọri ati iṣẹgun gbogbo.

“Ẹniti o fi igbala nla fun ọba rè̩; o si fi ānu hàn fun Ẹni-ororo rè̩, fun Dafidi, ati fun iru-ọmọ rè̩ lailai” (Orin Dafidi 18:50). Nihin a n sọrọ nipa Kristi, Ọba otitọ, ati Dafidi ti i ṣe ẹni ami-ororo, ati awa ti i ṣe iru-ọmọ rè̩ nipa ti ẹmi. Wo bi aanu ati ifẹ Ọlọrun ti o n gba ni ti gbooro to, bi o ti ga to ati bi o ti kari gbogbo ẹda to!

Dafidi jẹ ọba ti Ọlọrun tikara Rẹ yàn. O jẹ jagunjagun. S̩ugbọn o mọ pe ọwọ Ọlọrun ni o ran oun lọwọ lati “là ārin ogun kọja,” ti oun si fo odi kọja. Sibẹsibẹ oun mọ - bẹẹ gẹgẹ ni awa naa gbọdọ mọ pẹlu -- pe a kò le ni iṣẹgun bi a kò ba jagun; lai si agbelebu kò si ade. O “jà ija rere,” awa naa si gbọdọ ṣe bẹẹ pẹlu ti a ba fẹ jogun iye ainipẹkun.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Iru Psalmu wo ni a saba maa n pe Psalmu yii?

  2. 2 Nitori ki ni Dafidi ṣe n fi iyin fun Ọlọrun?

  3. 3 S̩e apejuwe bi Ọlọrun ti ṣe dahun igbe rè̩.

  4. 4 Njẹ igba gbogbo ni igbesi aye Dafidi fi iduroṣinṣin hàn?

  5. 5 Ki ni n fun eniyan ni igbẹkẹle ninu Ọlọrun?

  6. 6 Ihà wo ni Oluwa kọ si alaaanu?

  7. 7 Ta ni yàn Dafidi ni ọba?

  8. 8 Ta ni “iru-ọmọ” tọka si ni ẹsẹ ti o kẹyin?