Orin Dafidi 23:1-6; 27:1-14

Lesson 245 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “OLUWA li Oluṣọ-agutan mi; emi kì yio ṣe alaini. O mu mi dubulẹ ninu papa-oko tutù; o mu mi lọ si ìha omi didakẹ rọrọ. O tù ọkàn mi lara; o mu mi lọ nipa ọna ododo nitori orukọ rè̩. Nitõtọ, bi mo tilẹ nrìn larin afonifoji ojiji ikú, emi ki yio bè̩ru ibi kan; nitori ti Iwọ pẹlu mi; ọgọ rẹ ati ọpá rẹ nwọn ntù mi ninu. Iwọ té̩ tabili onjẹ silẹ niwaju mi li oju awọn ọta mi; iwọ dà ororo si mi li ori; ago mi si kún akúnwọsilẹ. Nitotọ, ire ati ānu ni yio ma tọ mi lẹhin li ọjọ aiye mi gbogbo; emi o si ma gbe inu ile OLUWA lailai” (Orin Dafidi 23:1-6).
Cross References

I Orin Oluṣọ-agutan

1 Ifẹ ti Ọlọrun fi n ṣe itọju awọn eniyan Rè̩ ni a fi wé bi oluṣọ-agutan ti i maa ṣọ awọn agutan rè̩, Orin Dafidi 23:1; Isaiah 40:11; Johannu 10:11-16; Heberu 13:20; I Peteru 2:25

2 Oluṣọ-agutan Rere a maa mu awọn agutan Rè̩ lọ si ibi ọpọ ounjẹ, ibi alaafia ati ibi itura, Orin Dafidi 23:2, 3; Isaiah 49:10; Esekiẹli 34:22-31

3 Agbara ati wiwà ni tosi oluṣọ-agutan a maa bori ipá ati ẹrù ikú ati idagiri, Orin Dafidi 23:4; 72:12-17; 91:1-14; Heberu 2:14, 15

4 Ọlọrun a maa fi ifẹ ṣe itọju awọn eniyan Rè̩ bi ọta tilẹ yi wọn ka, Orin Dafidi 23:5; 31:19-24; Jobu 36:15, 16

5 Ọlọrun a maa fi ago ibukún ni ẹkunrẹrẹ ati akúnwọsilẹ fun awọn ti O fẹ, Orin Dafidi 23:5; 45:7; 92:10; Malaki 3:10

6 Iye ainipẹkun ni ipin awọn agutan pápá Ọlọrun, Orin Dafidi 23:6; 16:11; II Kọrinti 5:1; Ifihan 21:3, 4

II Orin Dafidi Kan

1 Igbẹkẹle Dafidi ninu igbala Ọlọrun lagbara o si daju, Orin Dafidi 27:1-3; Ẹksodu 15:2; Orin Dafidi 46:2

2 Dafidi fẹ lati maa gbe inu Ile Ọlọrun titi lae nitori ninu eyi ni iyè ainipẹkun wà, Orin Dafidi 27:4-6; 31:19, 20; Johannu 14:2, 3; Heberu 12:22

3 Dafidi gbadura pe ki iranwọ Ọlọrun le wà ni igbesi aye oun titi de opin, Orin Dafidi 27:7-9, 11, 12; Deuteronomi 4:31; Orin Dafidi 50:15

4 Dafidi sọ ti aanu ati igbala Ọlọrun pẹlu idaniloju, Orin Dafidi 27:10, 13, 14; Numeri 14:8; Orin Dafidi 3:5, 6; Isaiah 12:2

Notes

Oluṣọ-agutan Rere

Psalmu kẹtalelogun jẹ ọkan ninu eyi ti ọpọlọpọ eniyan mọ dunju ti wọn si fẹran ju lọ ninu Iwe Mimọ. Ọrọ ifẹ ati ẹwa rè̩ jẹ itunu fun aimoye eniyan lati irandiran ninu gbogbo iṣoro, idanwo ati ikú paapaa. Awọn ọrọ rè̩ ti o rọrun lati yé ni ti mu ki o ṣọwọn fun ọpọlọpọ ọkàn.

“OLUWA li Olusọ-agutan mi; emi ki yio ṣe alaini,” jẹ kókó ọrọ ti o ṣe itumọ gbogbo Psalmu kẹtalelogun. Ọlọrun ni Olusọ-agutan awọn olododo, awọn eniyan Rè̩ si ni agutan Rè̩. Awọn eniyan n fi iwarapàpà ṣafẹri ọwọ kan, ti yoo maa ṣe itọni fun gbogbo akoko igbesi-ayé wọn; ṣugbọn Ọlọrun ni o n ṣe eyi, ati ju bẹẹ lọ pẹlu, fun ọkán ti o ba fẹ wá oju Rè̩ fun itọni, ifẹ ati aabo.

Ipamọ ati aabo agbo ẹran di ọwọ oluṣọ-agutan nitori agutan rè̩ kò lagbara to lati wá koriko tutu ati omi fun ara wọn bi o ti tọ ati bi o ti yẹ. Bakan naa ni wọn kò le daabo bo ara wọn lọwọ ẹranko buburu tabi ewu ti o le de ba wọn ninu iṣoro oju ọna. Iṣẹ oluṣọ-agutan ni lati tọ awọn agutan rè̩ laaarin gbogbo ewu ti o le doju kọ wọn lati ṣe jamba fun agbo agutan rè̩. Oun ni ẹni ti yoo fi ẹmi rè̩ wewu lati daabo bo agbo ẹran rè̩ ninu gbogbo ikọlu awọn ẹranko buburu, ole, igára tabi awọn apaniyan.

Jesu sọ Ọrọ iyanu fun wa ninu Majẹmu Titun nibi ti O gbe sọ fun awọn eniyan pe Oun ni Oluṣọ-agutan awọn agutan. O sọ nipa ara Rè̩ pe, “Emi ni oluṣọ-agutan rere: oluṣọ-agutan rere fi ẹmi rè̩ lelẹ nitori awọn agutan” (Johannu 10:11). Eyi yii gan an ni ohun ti Jesu ṣe fun awọn eniyan Rè̩ -- agutan pápá Rè̩. O fi ẹmi Rè̩ lelè̩ fun wọn ki wọn ki o le bọ lọwọ è̩ṣẹ ati idajọ ikẹyin – ani ikú ayeraye! È̩jẹ Jesu ti a ta silẹ lori agbelebu ni Kalfari ni etutu fun è̩ṣẹ wa, a si ti ri iyè ainipẹkun gbà nipa gbigbagbọ ninu agbara Isun iwẹnumọ naa.

Ọpọlọpọ Koriko

A kọ wa nihin pe a ki yoo ṣe alaini, bẹẹ ni ohun rere kan ki yoo fà sẹyin lọdọ wa bi a ba n wò Ọlọrun fun ipese Rè̩. Bi oluṣọ-agutan ti n dà awọn ẹran rè̩ lọ si ibi omi didakẹ rọrọ ati papa oko tutu nibi ti o ti n bọ awọn agutan ti o si n fun wọn ni omi mu lọpọlọpọ, bakan naa ni Ọlọrun n dari awọn eniyan Rè̩ si orisun ibukún ayeraye, eyi ti i ṣe Orisun Omi Iyè, ani Jesu Kristi. “Aduro-ṣinṣin yio jogun ohun rere” (Owe 28:10); ati pẹlu pe, “O ti fi ohun ti o dara kún awọn ti ebi npa” (Luku 1:53). Isaiah sọ nipa Oluṣọ-agutan Israẹli pe, “Ebi kì yio pa wọn, bḝni ongbẹ kì yio si gbẹ wọn; oru ki yio mu wọn, bḝni õrun ki yio si pa wọn: nitori ẹniti o ti ṣānu fun wọn yio tọ wọn, ani nihà isun omi ni yio dà wọn” (Isaiah 49:10). Jesu sọ fun awọn ẹni ti oungbẹ n gbẹ pé, “Bi òrungbẹ ba ngbẹ ẹnikẹni, ki o tọ mi wá, ki o si mu” (Johannu 7:37).

Ileri Ọlorun wà fun wa, ki i ṣe fun aini ti ara ati ti ọkàn fun igba isisiyi nikan ninu irin-ajo wa laye yii, ṣugbọn fun wiwa lalaafia wa, ati igbadun pẹlu Ọlọrun ni ayeraye. A fi iṣipaya Ilu Ọlọrun hàn Johannu Apọsteli ki a le mọ diẹ ninu ibukún ti yoo jẹ ti awọn eniyan mimọ Ọlọrun. O kọ akọsilẹ bayi pe: “Mo si gbọ ohùn nla kan lati ori ité̩ nì wá, nwipe, Kiyesi i, agọ Ọlọrun wà pẹlu awọn enia, on ó si mā ba wọn gbé, nwọn o si mā jẹ enia rè̩, ati Ọlọrun tikararè̩ yio wà pẹlu wọn, yio si mā jẹ Ọlọrun wọn. Ọlọrun yio si nù omije gbogbo nù kuro li oju wọn; kì yio si si ikú mọ, tabi ọfọ, tabi ẹkún, bḝni ki yio si irora mọ: nitoripe ohun atijọ ti kọja lọ” (Ifihan 21:3, 4). Nitori idi eyi kò ya ni lẹnu pe ninu Psalmu ikẹtadinlọgbọn, Onipsalmu sọ bayii pe: “Ohun kan li emi ntọrọ li ọdọ OLUWA, on na li emi o mā wakiri: ki emi ki o le ma gbe inu ile OLUWA li ọjọ aiye mi gbogbo, ki emi ki o le ma wò ẹwà OLUWA, ki emi ki o si ma fi inu-didùn wò tẹmpili rè̩” (Orin Dafidi 27:4).

Ifẹ Dafidi ni lati maa gbe inu Tẹmpili Ọlọrun -- Jerusalẹmu Titun -- pẹlu Ọlọrun titi lae. Ifẹ rè̩ ni gbogbo akoko ti o lo ni aye yii ni lati maa ṣe aṣaro lori ẹwà ati pipé Ọlọrun ninu adura ati ijọsìn. Ẹtọ ati anfaani olukuluku ọmọ Ọlọrun ni lati maa fi ibeere rè̩ siwaju Ọlọrun ninu Tẹmpili mimọ Rè̩ nipa ijọsìn ati iyìn si Ọlọrun. Ẹnikẹni ti o ba ti tọ Ọlọrun wò ti o si mọ pe rere ni Ọlọrun ki yoo ni ifẹ si ohun aye yii mọ; ohun ti yoo leke lọkàn rè̩ ni pe ki o le maa ba Ọlọrun gbe laelae. Bọya iru ero yii ni o wà lọkàn Onipsalmu nigba ti o sọ bayi pe, “Tọ ọ wò, ki o si ri pe, rere ni OLUWA: alabukún fun li ọkunrin na ti o gbẹkẹle e” (Orin Dafidi 34:8).

Itunu Oju Rè̩

A fi igbẹkẹle ti Onipsalmu ni ninu Ọlọrun hàn ninu Psalmu ikẹtalelogun ati ikẹtadinlọgbọn. Oun kò bè̩ru ibi ti o wu ki o de ba a. Giga igbẹkẹle rè̩ ninu Ọlọrun fara hàn ninu ọrọ yii pe, “Nitõtọ, bi mo tilẹ nrìn larin afonifoji ojiji ikú, emi ki yio bè̩ru ibi kan; nitori ti Iwọ pẹlu mi; ọgọ rẹ ati ọpá rẹ nwọn ntù mi ninu.”

Ikú ati oro rè̩ kò ba awọn ẹni irapada lẹrù mọ nitori pe Kristi ti ṣẹgun nipa ajinde Rè̩. Jesu ṣẹgun ikú, ipo-òkú ati iboji ninu ajinde Rè̩. Ni akoko ikú, iṣudẹdẹ le de, irora le wa fun igba diẹ, ṣugbọn ibè̩ru ati ipaya ikú kò si fun Onigbagbọ nitori pe oun n wo Oluṣọ-agutan nla nì lati ṣe amọna rè̩.

“OLUWA ni imọlẹ mi ati igbala mi; tali emi o bè̩ru? OLUWA li agbara ẹmi mi; aiya tali yio fò mi?” Kò si idahun si awọn ibeere yii, nitori ti kò si ẹni kan ti o tobi ju Ọba awọn ọba ati Oluwa awọn oluwa lọ. “Bi Ọlọrun bá wà fun wa, tani yio kọ oju ija si wa?” (Romu 8:31). Nitori “kì iṣe ikú, tabi iye, tabi awọn angẹli, tabi awọn ijoye, tabi awọn alagbara, tabi ohun igba isisiyi, tabi ohun igba ti mbọ, tabi òke, tabi ọgbun, tabi ẹda miran kan ni yio le yà wa kuro ninu ifẹ Ọlọrun, ti o wà ninu Kristi Jesu Oluwa wa” (Romu 8:38, 39).

Ago Ibukún

Dafidi ranti awọn ewu ti o ti kọja lori rè̩ ati awọn ọta pupọ ti o ti lepa lati pa a; nitori naa o yin Ọlọrun nitori igbala nla ti Ọlọrun ṣe fun un. Ọlọrun té̩ tabili ibukún ati aabo silẹ niwaju rè̩, ni oju awọn ọta rè̩. O dabi ẹni pe bi iṣoro rè̩ ti n pọ tó, bẹẹ ni oju Ọlọrun n wà lara rè̩ tó. Dafidi fi ifẹ nla Ọlọrun ati itara Rè̩ fun awọn agutan Rè̩ we ago ti o kún akúnwọsilẹ. A sọ bi ifẹ Ọlọrun ti pọ to si awọn ti Rè̩ ninu Psalmu ikẹtadinlọgbọn nibi ti Onipsalmu gbe sọ bayii pe, “Nigbati baba ati iya mi kọ mi silẹ, nigbana ni OLUWA yio tẹwọgbà mi.” Ifẹ ti awọn obi ni si ọmọ ti ọdọ Ọlọrun wá; ninu gbogbo okùn ifẹ ti o wà laaarin ẹda kò si eyi ti o ṣoro lati já bi iru okùn ifẹ ati iyọnú ti o wà laaarin awọn obi ati ọmọ wọn. S̩ugbọn Onipsalmu wi pe bi o ba tilẹ ṣe e ṣe ki èṣe yii ṣe oun – ki awọn obi kọ oun silẹ -- sibẹ Ọlọrun yoo tu oun ninu yoo si pa oun mọ.

Psalmu ikẹtadinlọgbọn yii tẹ siwaju si i lati sọ nipa aabo Ọlọrun ati pe Ọlọrun yoo pa awọn ti Rè̩ mọ ninu Agọ Rè̩ ati ni iwaju Rè̩. Awọn ẹsẹ Ọrọ Ọlọrun yii n fi idi irú ifẹ nla ti Ọlọrun ni si awọn ti Rè̩ múlẹ, o si tun rán ni leti ohun ti o ṣẹlẹ ati ẹkọ ti Jesu kọ ni nigba ti O fi aabo Ọlọrun lori awọn ti Rè̩ wé bi agbebọ adiẹ ti n radọ bò awọn ọmọ rè̩ labẹ iyẹ apa rè̩. Ni akoko naa Jesu wi pe, “Igba melo li emi nfẹ radọ bò awọn omọ rẹ, bi agbebọ ti iradọ bò awọn ọmọ rè̩ labẹ apá rè̩, ṣugbọn ẹnyin kò fẹ!” (Matteu 23:37). Ohun kan naa ni a ri ninu awọn Psalmu, nitori a kọ ọ sibẹ pe, “Yio fi iyé̩ rè̩ bò ọ, abẹ iyé̩-apa rè̩ ni iwọ o si gbẹkẹle” (Orin Dafidi 91:4).

Ire Oluwa

A mu Psalmu ikẹtalelogun ati ikẹtadinlọgbọn wa si opin pẹlu ọrọ igbẹkẹle ninu iṣeun ati aanu Ọlọrun ti i ṣe ipin awọn ọmọ Ọlọrun. Igbẹkẹle Dafidi pe ire ati aanu ni yio maa tọ oun lẹyin ni gbogbo ọjọ aye rè̩, jẹ ohun ti o tọna, nitori ẹni ti o ba n gbe igbesi-aye rè̩ fun ogo Ọlọrun ni o n ri ere gbà lọwọ Ọlọrun. Ninu awọn ere wọnyi ni ayọ, alaafia ati iyè ainipẹkun wa – gbogbo wọnyi ni a ni nipa iṣeun ati aanu Ọlọrun Olodumare. Ileri Ọlọrun ni pe, “Máṣe gbagbe ofin mi; si jẹ ki aiya rẹ ki o pa ofin mi mọ. Nitori ọjọ gigún, ati ẹmi gigún, ati alafia ni nwọn o fi kún u fun ọ” (Owe 3:1, 2).

Dafidi ni anfaani pupọ lati jẹri si agbara Ọlọrun ti o n gba ni, ati oore-ọfẹ Rè̩ ti kò loṣuwọn ninu igbesi-aye rè̩, nitori ti ọkàn ati ẹmi rè̩ wà ninu ewu ni ọpọlọpọ igba sẹyin. Eyi ni ohun ti o sọ nipa iru akoko bayii, “ṣugbọn emi ti gbagbọ lati ri ire OLUWA ni ilẹ alāye” (Orin Dafidi 27:13). Eyi jẹ idalẹbi, o si jẹri gbe gbogbo awọn onilọra ti n fa sẹyin nigbakuugba ninu iṣẹ isin wọn si Ọlọrun. Igba iṣoro n bọ, lai ni Olugbala, awọn ti kò sin Ọlọrun yoo ṣegbe gẹgẹ bi itanna ti o wà ninu igbo. S̩ugbọn eyi ki i ṣe ipin Dafidi. Igbẹkẹle rè̩ wà ninu Ọlọrun alààyè, o si gba awọn ti igbagbọ wọn kere ninu Ọlọrun niyanju lati “duro de OLUWA; ki o si tújuka, yio si mu ọ li aiya le: mo ni duro de OLUWA” (Orin Dafidi 27:14).

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Ta ni Oluṣọ awọn agutan?

  2. 2 Ki ni iṣẹ oluṣọ-agutan?

  3. 3 Ki ni ṣe ti agutan ni lati ni oluṣọ-agutan?

  4. 4 Ki ni ṣe ti Dafidi n fẹ lati maa gbe inu Ile Oluwa laelae?

  5. 5 Bawo ni Psalmu ikẹtadinlọgbọn ṣe fi ifẹ Ọlọrun si awọn eniyan Rè̩ hàn fun ni?

  6. 6 Ọna wo ni ifẹ obi si ọmọ gbà fara jọ ifẹ Ọlọrun?