Orin Dafidi 25:1-22; 94:1-23

Lesson 246 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Aṣiri OLUWA wà pẹlu awọn ti o bè̩ru rè̩, yio si fi wọn mọ majẹmu rè̩” (Orin Dafidi 25:14).
Cross References

I Igbẹkẹle ninu Adura

1 Onipsalmu gbadura, niwọn bi o ti mọ pe Ọlọrun yoo gbọ adura rè̩, Orin Dafidi 25:1-3; Matteu 7:7, 8; Heberu 11:6; I Johannu 5:14, 15

2 O gbadura tinutinu lati mọ ọna Ọlọrun ati ifẹ Rè̩, Orin Dafidi 25:4-7; Johannu 7:17

3 Mimọ iwa Ọlọrun mu igbagbọ wọ inu ọkàn eniyan Ọlọrun yii, Orin Dafidi 25:8-11; Johannu 3:16; 1 Johannu 4:10

4 A o mu awọn ti o bẹru Oluwa mọ majẹmu Rè̩, Orin Dafidi 25:12-14; Heberu 8:6; 9:14, 15

5 Iwa-titọ ati iduroṣinṣin yoo yọ ọmọ Ọlọrun kuro ninu gbogbo ipọnju rè̩, Orin Dafidi 25:15-22; Heberu 10:35, 36

II Ẹrù-jẹjẹ ni Ọlọrun si awọn Oninunibini

1 A ké si Oluwa lati kiyesi iwa buburu awọn eniyan, Orin Dafidi 94:1-4

2 O dabi ẹni pe kò si ibi kan ti o buru ju ti wọn kò le ṣe, Orin Dafidi 94:5, 6

3 Awọn ẹlẹṣẹ kuna ni riro pe Ọlorun kò ri iṣẹ wọn, Orin Dafidi 94:7; Galatia 6:7

4 Ẹlẹda ohun gbogbo n ṣakiyesi ohun gbogbo ti o n ṣẹlẹ ninu ayé, Orin Dafidi 94:8-11; Gẹnẹsisi 6:5; Romu 3:23

III Alaafia fun awọn ti a n ṣe Inunibini Sí

1 Ọlọrun ni ipinnu ninu ibawi awọn eniyan Rè̩, Orin Dafidi 94:12-14; Heberu 12:5-11

2 Ododo ni yoo bori ni ikẹyin, Orin Dafidi 94:15-18; Isaiah 33:14-17

3 Awọn ileri iyebiye ti Ọlọrun ṣe jẹ aabo ti o pé lati gba ni kuro lọwọ awọn eniyan buburu, Orin Dafidi 94:19-23; Romu 8:31, 33-39

Notes

Akọni ninu Adura

Dafidi ọba jẹ ẹni ti o n gbadura. Ni akoko ti o dabi ẹni pe ọpọlọpọ eniyan kò mọ iyi ati agbara adura, ọba Israẹli yii kò fi anfaani ilẹkun ile iṣura ifẹ Ọlọrun ti o ṣi silẹ yii jafara. Igbesi-aye adura gbigba yii ni aṣiiri igbe-aye iṣẹgun ti Dafidi gbé ati agbara ti o ni laaarin awọn eniyan. Ọlọrun Majẹmu Laelae ni Ọlọrun Majẹmu Titun, Ọlọrun kan naa ti o gbọ adura Dafidi ṣi wà ni Ọrun titi di oni oloni lati dahun ẹbẹ awọn ti o n ke pe E tọkantọkan. Ni akoko Ihinrere yii, igbà gbogbo ni a n tẹnu mọ bi adura ti ṣe pataki to, o si yẹ ki a maa ri ẹgbẹ akọni ninu adura ni gbogbo igbà ati akoko lati igba ti Kristi ti de ayé. Sibẹ o ṣe ni laaanu pe awọn eniyan kuna lati mu anfaani orisun agbara ti o tobi ju lọ laye lo – eyi yii ni lati gba iranlọwọ Ọlọrun fun ohunkohun ti o wu ki eniyan ṣe alaini. Ki ni a kò ni fẹ lati yọọda ninu ohun-ini wa lati ṣe alabapin ninu iṣẹgun ti a kọ silẹ ninu Bibeli? Iru iṣẹgun yii, lori gbogbo aini yoo jẹ ti ẹnikẹni ti o ba le gbà iru adura ti awọn akọni ninu Bibeli gbà. “Bi ẹnyin ba ngbé inu mi, ti ọrọ mi ba si ngbé inu nyin, ẹ ó bère ohunkohun ti ẹ ba fẹ, a o si ṣe e fun nyin” (Johannu 15:7). Eyi ni ipilẹ ibukun Ọlọrun fun awọn olododo.

Adura ti o wà ninu Psalmu ikarundinlọgbọn yii pin si ipa mẹrin. Dafidi gbadura lati bọ lọwọ awọn ọta rè̩, fun itọni nipa ọna iye, idariji è̩ṣẹ ti o ti da, ati iduroṣinṣin awọn eniyan mimọ. Psalmu ikẹrinlelaadọrun sọrọ lori ohun ti o fara jọ eyi, nibi ti a ti fi iparun awọn eniyan buburu nigbooṣe hàn ati iṣẹgun ayeraye fun awọn ti o gbẹkẹ wọn le Ọlọrun. Dafidi gbadura si Oluwa. Oun tikara rẹ ni o mu ẹbẹ rè̩ tọ Oluwa lọ. O mọ pe ohun ti o ṣe danindanin ni fun oun lati ni igbẹkẹle ninu Ọlọrun ju ati ni ohun igba isisiyi lọ. Awọn ọta Ọlọrun n ṣọ igbesi-aye Dafidi gẹgẹ bi awọn ọta Ihinrere ti n ṣọ igbesi-aye awọn Onigbagbọ loni. Bi igbagbọ Dafidi ati igbẹkẹle rè̩ ninu Ọlọrun kò ba mu eso jade gẹgẹ bi Ọrọ Ọlọrun ti wi, awọn ọta Dafidi yoo rẹrin rè̩, wọn yoo fi ṣe ẹlẹya, wọn yoo si tun gan Ọlọrun Ọrun pẹlu. Ohun ti o leke ọkàn Dafidi ni pe ki adura rè̩ le jé̩ itẹwọgba, nitori idahun si adura jẹ ohun ti ẹnikẹni kò le sé̩.

Ọpọlọpọ Onigbagbọ kọ ni o ha ti mu iduro wọn lori Ọrọ Ọlọrun – fun iwosan tabi igbala kuro ninu iṣoro – ti wọn si ni lati duro laaarin ẹgan ati inunibini awọn alaigbagbọ? Bi Ọlọrun kò ba dahun adura nigba naa, orukọ Rè̩ yoo di isọrọ-odi si pẹlu; ṣugbọn igbagbọ ki i kuna lati ri gbà, Ọlọrun yoo si gbe orukọ Rẹ ga nigba gbogbo. Ẹnikẹni ti o ba mu iduro rè̩ fun Ọlọrun, ti o si gbe ẹkẹ rè̩ le Ọlọrun lai yẹsẹ, yoo ri idahun si adura rè̩ gbà, orukọ Ọlọrun yoo si di ayinlogo.

Wiwa Ọna Ọlọrun

Ohun ti a ni lati wà laaaye fun ni lati mọ Ọlọrun ati lati rin ni ọna ti Oun ti la silẹ. Adura tootọ ni lati kún fun ẹbẹ lati mọ ọna ti Ọlọrun yàn, nitori eyi ni ipa ọna ti o lọ si ọrun taarata – lai si itọni, ero lọna ajo naa le tete ṣina. Ikorita pupọ ni o wà lọna wa laye yii, ṣugbọn Ọlọrun ṣetan lati tọ gbogbo awọn ti o ba fẹ gba imọran Rè̩. Dafidi ni ọkàn ti o n ṣafẹri itọni Ọlọrun igbala rè̩. Oun kò ṣalai ni ọgbọn aye yii, ṣugbọn o mọ pe gbogbo ọgbọn aye yii kò le fun ni ni oju rere Ọlọrun.

“Fi ọna rẹ hàn mi, OLUWA.” Iṣipaya Ọlọrun bẹrẹsi fara han diẹdiẹ fun ẹda lati igba ti ayé ti ṣẹ. Siwaju ati siwaju ni awọn ọmọ eniyan n kọ lati mọ ohun ti Ọlọrun fẹ lọwọ wọn. “Ọlọrun, ẹni, ni igba pupọ ati li onirụru ọna, ti o ti ipa awọn woli ba awọn baba sọrọ nigbāni, ni ikẹhin ọjọ wọnyi o ti ipasẹ Ọmọ rè̩ ba wa sọrọ, ẹniti o fi ṣe ajogun ohun gbogbo, nipasẹ ẹniti o dá awọn aiye pẹlu” (Heberu 1:1, 2). Jesu wá si ayé fun idi pataki yii, ani lati jẹ iṣipaya kedere nipa Baba fun awọn eniyan, lati kọ awọn eniyan bi a ti i gbe lọna ti Ọlọrun fẹ, ati lati fi ara Rè̩ rubọ ti kò lé̩gbé̩ fun è̩ṣẹ araye. Jesu wi pe, “Emi li ọna, ati otitọ, ati iye: kò si ẹnikẹni ti o le wá sọdọ Baba, bikoṣe nipasẹ mi” (Johannu 14:6). Bi awọn eniyan ba fi ọkàn tootọ ṣe afẹri lati mọ ifẹ ati ọna Ọlọrun lọjọ onì, wọn yoo ri Jesu. Bi wọn ba n tọ ipasẹ Rè̩ timọtimọ, wọn yoo gunlẹ si ebute ifẹ wọn. “Ọpé̩ ni fun Ọlọrun nitori alailesọ è̩bun rè̩” -- è̩bùn alailẹgbẹ fun awọn ọmọ eniyan.

Ọna iyè jẹ ọna iyanu, Onipsalmu pe e ni ọna aanu ati otitọ. Ẹri awọn Onigbagbọ ni pe o jẹ ọna alaafia, ayọ ati iṣẹgun lori è̩ṣẹ. Ọrọ iṣẹgun ti awọn Onigbagbọ ti o ti fi aye yii silẹ lati lọ gba ere wọn, yatọ si ipohunréré ẹkun awọn ẹlẹṣẹ ti n kú lọ, ni lati fi hàn lai si aniani pe ọna Ọlọrun ni ọna ti o dara ju lọ. Gbogbo awọn wọnni ti o n rin ni ọna iwa mimọ mọ ayọ ọna naa; olukuluku Onigbagbọ ni o si n rọ awọn eniyan ayé lati dán ọna yii wo ni igbesi aye wọn, ki awọn tikara wọn le fi oju wọn ri itẹlorun ti o tayọ, ti o le jẹ ti wọn.

Kikọ awọn Ẹlẹṣẹ

Ọlọrun sọ ninu Ọrọ Rè̩ pe Oun kò fi ara Oun silẹ lai si ẹlẹri ninu aye. Lọna kan tabi lọna miiran, ẹlẹṣẹ a maa ni imọ pe Ọlọrun otitọ wà; ṣugbọn bi o ba le tẹle ẹri ọkàn ti Ọlọrun fi fun gbogbo eniyan, lai pẹ ẹlẹṣẹ naa yoo ni iriri ibalo Ọlọrun. “Imọlẹ otitọ mbẹ ti ntàn mọlẹ fun olúkulùku enia ti o wá si aiye” (Johannu 1:9). Gbogbo awọn ti kò sin Ọlọrun ni o n ṣe awawi eredi rè̩ ti wọn kò fi sin In, ṣugbọn a sọ fun wa pe awawi kan ki yoo fẹsẹmulẹ niwaju Itẹ Idajọ Funfun nibi ti a o ti dá ẹlẹṣẹ lẹjọ fun è̩ṣẹ rè̩. Bibeli sọ fun wa pe gbogbo awọn ti o ba duro niwaju idajọ ni ọjọ naa kò ni le fọhun nitori pe Ọlọrun ti kọ wọn to, ani ninu ipo è̩ṣẹ ti wọn wa, ki wọn ki o má le wá si idajọ bi wọn ba jẹ gbọran.

Ọna pupọ ni Ọlọrun n gba lati kọ ẹlẹṣẹ pe Ọlọrun wà, ati pe, “On ni olusẹsan fun awọn ti o ba fi ara balẹ wá a” (Heberu 11:6). A ranti pupọ ninu awọn ẹri awọn ti wọn ro pe wọn kò mọ ohunkohun nipa Ọlọrun, sibẹ wọn ke pe E nigba ipọnju tabi idaamu, wọn si ri bi Ọlọrun ti dide fun iranlọwọ wọn ti O si gbọ adura wọn. Lootọ, wọn jẹ ẹlẹṣẹ; ṣugbọn lati wakati naa lọ, wọn mọ pe Ọlọrun wà ni Ọrun, ati pe yoo dahun adura. Akoko naa si de ti wọn gbadura si Ọlọrun fun idariji è̩ṣẹ, ti wọn si mọ Jesu ni Olugbala wọn. Awọn ẹlẹṣẹ miiran bá awọn ọmọ Ọlọrun pade; wọn ri igbesi aye onigbagbọ ti wọn n gbe lọjọọjọ, eyi si mu ki awọn tikara wọn pinnu lati wa Olugbala. Bibeli ti kò pamọ, ẹri ni opopo ati abuja ọna, iwaasu ninu ile Ọlọrun, iwe ti a tẹ jade lati inu Ọrọ Ọlọrun -- wọnyi jẹ diẹ ninu awọn ọna miiran ti Ọlọrun n lo lati tan imọlẹ si ọkàn awọn eniyan. Ohun kan ni o daju ti o si jẹ otitọ, “Rere ati diduro-ṣinṣin ni OLUWA: nitorina ni yio ṣe ma kọ ẹlẹṣẹ li ọna na.” Bi ẹnikẹni ba ni lati jihin è̩ṣẹ ti o ṣẹ ni ọjọ ti Ọlọrun yoo ṣe idajọ, eyi yoo jẹ ere kìkọ ti ẹni naa kọ lati feti si ati lati ṣe awọn ohun ti oun paapaa mọ pe oun ni lati ṣe. Bi otitọ yii ba ri bẹẹ nigba ayé Dafidi, o tun fẹsẹmulẹ ju bẹẹ lọ ni akoko ti wa yii. “Nwọn kò ha gbọ bi? Bẹni nitõtọ, ohùn wọn jade lọ si gbogbo ilẹ, ati ọrọ wọn si opin ilẹ aiye” (Romu 10:18).

Ẹsan

Bi o tilẹ jẹ pe rere ati diduro ṣinṣin ni Ọlọrun, awọn ọmọ-eniyan kò gbọdọ lero pe Oun ki yoo mu wọn wa sinu idajọ tabi pe Oun yoo fi ẹlẹṣẹ silẹ lai jiya. Ọlọrun le gba ẹlẹṣẹ laaye lati lo ọdun pupọ ninu ayé lati fun un ni àyè ironupiwada. Ọpọlọpọ igba ni o dabi ẹni pe awọn eniyan le huwa aitọ si Ọlọrun tabi awọn eniyan Rè̩ ki wọn si lọ lai jiya, ṣugbọn “Ọlọrun ẹsan” n wo gbogbo iṣẹ è̩dá, Oun yoo si san ẹsan fun eniyan buburu. “Bi ẹlẹṣẹ tilẹ ṣe ibi nigba ọgọrun, ti ọjọ rè̩ si gùn, ṣugbọn nitõtọ, emi mọ pe yio dara fun awọn ti o bè̩ru Ọlọrun, ti o bè̩ru niwaju rè̩: ṣugbọn ki yio dara fun enia buburu; bḝni kì yio fa ọjọ rè̩ gun ti o dabi ojiji, nitoriti kò bè̩ru niwaju Ọlọrun” (Oniwasu 8:12, 13).

Ero ẹtan meji ni o wà ni odo ọkàn ẹlẹṣẹ ti o taku sinu è̩ṣẹ rè̩ ti ko si fẹ ronupiwada. Ọkan ninu ero ọkàn rẹ ni pe è̩ṣẹ rè̩ ki yoo wa a ri; ṣugbọn Ọlọrun n kilọ fun gbogbo ẹlẹṣẹ pe, “Ki o si dá nyin loju pe, è̩ṣẹ nyin yio fi nyin hàn” (Numeri 32:23). Onipsalmu beere ibeere yii ti ẹni kan kò le ja niyan pe: “Ẹniti o gbin eti, o le ṣe alaigbọ bi? ẹniti o da oju, o ha le ṣe alairiran? Ẹniti nnà awọn orilẹ-ède, o ha le ṣe alaiṣe olutọ? On li ẹniti nkọ enia ni imọ, o ha le ṣe alaimọ?” Ẹlẹda, ẹni ti o fi ẹbun igbọran fun eniyan, kò ha ni ipa lati gbọran ju ẹda lọ? Ọlọrun ti n gbọ adura awọn olododo, kò ha n gbọ ọrọ ti awọn eniyan buburu n sọ? Ọlọrun ti o mọ ifẹ ọkàn ti ebi n pa lati ni ifẹ Ọlọrun si i, ki ẹni naa tilẹ to fọhun, kò ha ni le mọ ero buburu ti o wà ninu ikọkọ ọkàn? Gẹgẹ bi O ti n jẹ awọn keferi niya fun iwa buburu wọn, bẹẹ gẹgẹ ni yoo ṣe idajọ awọn ti o wá sabẹ imọlẹ Ọrọ Rè̩. Lotitọ, Oluwa mọ gbogbo ero ọkàn ọmọ eniyan, O si ri gbogbo è̩ṣẹ. Gbogbo iwa ibi ti ẹlẹṣẹ kò ronupiwada rè̩ ni a kọ sinu Iwe Ọlọrun. (Wo Ifihan 20:12).

Ero ẹtan keji ti o n wà ninu ọpọlọpọ eniyan ni pe bi ẹṣẹ ẹni naa tilẹ wa a ri, ijiya è̩ṣẹ naa ki yoo gbona tó bi Bibeli ti sọ nipa rè̩. Ayeraye kò lopin, o si buru fun ẹlẹṣẹ; nitori naa ẹnikẹni kò gbọdọ fi ẹmi ara rè̩ wewu. Ọrọ Jesu, Ọmọ Ọlọrun, nipa ibugbe ikẹyin fun awọn eniyan buburu, ni lati jẹ ikilọ fun gbogbo eniyan lati bẹru lati lọ sibẹ. Ẹri ọkunrin ọlọrọ ninu itan Lasaru tó lati fi oro ti o wà ni ọrun apaadi hàn to bẹẹ ti gbogbo eniyan yoo yà kuro ni ọna ti o lọ si iparun. Iran ti Johannu Onifihan ri nigba ti o ri awọn ohun ti o n bọ wa ṣẹ nikẹyin aye, fi ijiya kikoro ti o n bọ fun awọn ẹlẹṣẹ hàn. Ma ṣe dan Ọlọrun wò, ki o má baa ba ara rẹ ninu adagun ina, ṣugbọn sa kuro ninu ibinu ti n bọ nipa sisa wá sọdọ Ọlọrun Olododo, ti O kún fun aanu ati ifẹ.

Onipsalmu mu awọn Psalmu wọnyi wá si opin nipa sisọ fun ni nipa iṣẹgun ti o wà fun awọn ti o gbẹkẹ wọn le Ọlọrun. Awọn keferi le binu ki awọn eniyan si maa gbiro ohun asan, ṣugbọn ọna awọn olododo ni yoo bori nikẹyin. Ọlọrun kì yoo dẹkun lati maa mu ki awọn eniyan Rè̩ dabi Rè̩ -- wọn yoo maa tẹsiwaju ninu ododo ati iwa mimọ titi yoo fi mu wọn lọ si ile Ọrun. Igba pupọ ni o ṣe pe inunibini awọn ọta Ihinrere ni a fi n ṣe Iyawo Kristi ni aṣepé, ati nipa ipọnju ati ijiya ati nipa ibawi; ṣugbọn Jesu ti i ṣe Olupilẹṣẹ ati Alaṣepé igbagbọ wa ki yoo jẹ ki a dan ẹnikẹni wò ju bi o ti le gbà lọ. Ireti Onigbagbọ ki i ṣe ninu awọn ohun aye yii. Ireti rè̩ wà ninu awọn ohun ti Ọrun, ireti yii ki i si doju ti ni nitori o ju ohun ti a le fi ohunkohun ṣe akawe lọ.

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 Ki ni ṣe ti Dafidi fi tẹra mọ adura pé ki awọn ọta rè̩ ki o má ṣe bori rè̩?

  2. 2 Ki ni Onipsalmu fẹ ki Oluwa fi hàn oun?

  3. 3 Darukọ diẹ ninu awọn ẹwa iwa mimọ Ọlọrun ti adura wọnyi duro le lori.

  4. 4 Sọ diẹ ninu awọn ibukun awọn olododo.

  5. 5 Ki ni Bibeli sọ nipa ẹsan? Ti ta ni ẹsan i ṣe?

  6. 6 Bawo ni Ọlọrun ṣe n mọ nigba ti ẹni kan bá dẹṣẹ?

  7. 7 Ki ni ṣe ti awọn eniyan Ọlọrun ṣe n la ipọnju kọja lọpọlọpọ igbà, ṣugbọn ti awọn eniyan buburu si n gbèrú?

  8. 8 Sọ iyatọ ti o wà ninu ipo awọn olododo ati eniyan buburu ni ayeraye?

  9. 9 Bawo ni awọn olododo ṣe n di aṣẹgun nikẹyin? Ta ni ibi isadi wọn?