II Samuẹli 24:1-25

Lesson 247 - Senior

Memory Verse
AKỌSORI: “Kò si ọba kan ti a ti ọwọ ọpọ ogun gba silẹ: kò si alagbara kan ti a fi agbara pupọ gba silẹ” (Orin Dafidi 33:16).
Cross References

I Idi rè̩ ti Dafidi fi Kà Iye Israẹli

1 Ibinu Ọlọrun ru si Israẹli boya nitori pipada sinu ibọriṣa, II Samuẹli 24:1; Awọn Onidajọ 2:14, 20; 3:8; 10:7

2 Ọlọrun fi Dafidi ṣe ohun-elo lati jẹ Israẹli niya, Ọlọrun si tun jẹ Dafidi paapaa niya, II Samuẹli 24:1, 2; I Kronika 21:1-3; Matteu 18:7; Deuteronomi 28:50; Awọn Onidajọ 3:12; Jeremiah 5:15

3 Ọlọrun rán ikilọ si Dafidi, eyi ti kò kà si, nitori naa o wà lai ri awawi kan wi, II Samuẹli 24:3, 4; I Kronika 21:3, 4; Owe 12:15; 15:22; 29:1

4 Kika ti a kà awọn eniyan wọnyi ni lati mọ bi agbara ogun orilẹ-ede naa ti tó, o si ṣe e ṣe ki eyi jẹ idi rè̩ ti a fi ṣe ikaniyan yii ni akoko yii, II Samuẹli 24:5-9; I Kronika 21:5-7; Orin Dafidi 20:7; Matteu 7:26, 27; Orin Dafidi 33:15, 16; Hosea 1:7; Haggai 2:22

II Iyà È̩ṣẹ lati ọdọ Ọlọrun

1 Dafidi ronupiwada è̩ṣẹ rè̩, o jẹwọ rè̩ ni kikún, o si tọrọ idariji, II Samuẹli 24:10, 17; I Kronika 21:8, 16, 17; Orin Dafidi 34:18; 51:17; II Kọrinti 7:10

2 Ọlọrun fun Dafidi ni anfaani lati fi ìpìlẹ igbẹkẹle rè̩ fun igbala han, II Samuẹli 24:11-13; I Kronika 21:9-12

3 Dafidi fi hàn pe Ọlọrun ni igbẹkẹle ati aabo oun, II Samuẹli 24:14; I Kronika 21:13; Orin Dafidi 46:1; 118:8, 9; Owe 3:5; Isaiah 2:22; Habakkuku 2:4; Heberu 10:38

4 Iparun ti àrùn naa ṣe ba pipé kika eniyan jé̩ patapata, II Samuẹli 24:15; I Kronika 21:14

5 Ọlọrun dá àrùn naa duro ni Jerusalẹmu, II Samuẹli 24:16, 17; I Kronika 21:15, 20

III Irubọ ni Ibi Ipaka

1 Ọlọrun fé̩ ki Dafidi rubọ si Oun, II Samuẹli 24:18; I Kronika 21:18, 19; Romu 12:1, 2; Ẹksodu 32:29

2 Dafidi fé̩ lati sanwo fun ẹbọ ati ibi irubọ naa dandan, eyi ti o jẹ àmì ifararubọ ti o jinlẹ, II Samuẹli 24:19-25; I Kronika 21:21-27; Filippi 3:7, 8; Matteu 16:24

3 Ibi irubọ Dafidi pada di ibi ti a kọ Tẹmpili si, I Kronika 21:28-30; 22:1-5; II Kronika 3:1

Notes

Ọkunrin naa, Dafidi

Dafidi ọba ti n di arugbo. Igbesi-aye rè̩ ti kún fun ọpọlọpọ akitiyan, ọpọ igbà ati akoko rè̩ ni o si fi ṣiṣẹ ogun jija. S̩ugbọn nipa iranlọwọ Ọlọrun, o ti ṣẹgun ọpọlọpọ ilu, o si ti mu wọn wá sabẹ akoso ijọba rè̩. Labẹ ijọba rè̩ ati ti Sọlomọni, orilẹ-ede Israẹli ni ini awọn ilẹ ti Ọlọrun ṣe ileri fun wọn.

S̩aaju akoko yii, Dafidi ti dẹṣẹ. O ti ṣe awọn aṣiṣe. S̩ugbọn o ti ronupiwada ni kikun, o si ti ri idariji gbà. Ọkan ninu awọn adura rè̩ igbakuugba ni pe ki oun ki o má ṣe jẹbi è̩ṣẹ ikugbu si aanu Ọlọrun -- è̩ṣẹ yii ni o pe ni è̩ṣẹ nla. Nitori ipinnu yii ninu ọkàn rè̩, Ọlọrun lo o gidigidi ni igbesi-aye rè̩.

Nipasẹ eniyan Ọlọrun yii, a ti ri iṣipaya pupọ ninu eto Ọlọrun gbà, eyi ti o fara han ninu ọna ti Ọlọrun gbà lati ba a lo. A fi iru awọn otitọ yii kọ ni pẹlu ninu ọpọlọpọ Psalmu ti Dafidi kọ silẹ. Ni gbogbo igba ni o ti gbé ogo Ọlọrun ati ifororoyan Ọlọrun ga. O ti duro de akoko Ọlọrun ninu nnkan wọnni ti o ri i pe o jẹ ifẹ Ọlọrun fun oun. Nipa bayi o ti gba ara rè̩ kuro lọwọ ijiya ati aniyan pupọ. Olóòótọ iranṣẹ Ọlọrun ti o fara mọ Ọlọrun timọtimọ ni oun i ṣe.

A le maa ro nigba naa wi pe i ba dara lọpọlọpọ bi ohun ti o ṣẹlẹ ni akoko yii ni igbesi-ayé Dafidi kò ba ṣẹlẹ rara. O jẹ ohun ẹdùn miiran ati àbámọ. S̩ugbọn nitori ipinnu ti o wà lọkan Dafidi, gbogbo rè̩ yọri si iṣẹgun; ati nitori ọkàn ironupiwada rè̩, ki i ṣe Dafidi nikan bi kò ṣe gbogbo wa pẹlu ni a gba ibukun ti a si ri ẹkọ ti ẹmi kọ.

A kò sọ gbogbo ohun ti o ṣẹlẹ yii fun ni ni kinnikinni. A kò sọ fun ni ohun ti o sun un ṣe e, tabi gbogbo ohun ti o tẹle ṣiṣe e. S̩ugbọn a sọ ohun ti o tó fun ni lati kọ awọn ẹkọ ti ẹmi ti Ọlọrun fẹ ki a kọ. Awọn otitọ ti o fara han wọnyi ni a o yè̩ wo nigba ti a ba n kọ ẹkọ yii.

Ẹbi È̩ṣẹ

Iwe Mimọ kò sọ fun ni ni kikún pé Ọlọrun kọ ki a ka Israẹli. S̩ugbọn kò mu ọgbọn wá fun Dafidi lati ṣe e. Otitọ yii fara han dajudaju ninu awọn ọrọ pupọ ninu ẹkọ yii. Lọna kin-in-ni, aṣẹ yii kò dùn mọ Joabu, olori-ogun, ẹni ti oun paapaa kò fẹ mọ ohun ti o tọ yatọ si ohun ti kò tọ nigbakuugba ti ohun naa ba lodi si ifẹ ọkàn rè̩. Joabu sọ fun Dafidi pe ki o má ṣe bẹẹ, ohun ti o si ṣẹlẹ nikẹyin fi han kedere pe Dafidi ṣe aṣiṣe ni kikọ ti o kọ imọran olori-ogun rè̩.

Ẹri keji ti o daju ti o fi han pe Dafidi ṣe aṣiṣe ni a tun ri ninu ọrọ Ọlọrun lati ẹnu Woli Rè̩, ati ijiya ti o tẹle ohun ti Dafidi mọọmọ ṣe yii.

Ninu itan wọn gẹgẹ bi Iwe Mimọ ti fi han fun ni, igba meji pere lẹyin eyi ni a ka iye awọn ọmọ-ogun Israẹli. S̩ugbọn ni igba mejeeji yii, a ṣe e gẹgẹ bi ọrọ ati aṣẹ Ọlọrun. Eyi ti o ṣẹlẹ yii jẹ ipinnu Dafidi, ti Eṣu rú u soke lati ṣe; o si le jẹ apa kan eto ti o wà lọkàn rè̩ nipa ogun miiran ti o fẹ ja lọjọ iwaju. S̩ugbọn Ọlọrun lo ohun ti o ṣẹlẹ yii lati mu idajọ wa sori Israẹli. A ko sọ eredi idajọ yii fun wa, ṣugbọn o le jẹ pe wọn tun pada si ibọriṣa, è̩ṣẹ ti awọn Ọmọ Israẹli n ṣubu si nigbakuugba.

Idajọ Ọlọrun ẹẹkan ṣoṣo pere sọ anfaani kika awọn eniyan naa di asan, nitori ajakalẹ-arun tẹle ipa ọna awọn ti n ka eniyan, ọpọlọpọ eniyan ni o si kú. Bi o ba ṣe pe è̩ṣẹ Dafidi ni pe o fi igbẹkẹle rè̩ sinu agbara awọn eniyan rè̩ -- lori apa ẹlẹran ara -- kò si ohun iṣiro ti o le fi ṣogo fun un mọ lẹyin ti ọwọ idajọ Ọlọrun ti lu awọn eniyan naa bolẹ. Orilẹ-ede Israẹli di alailagbara patapata laaarin wakati diẹ.

Ẹwẹ, bi o ba ṣe pe è̩ṣẹ Dafidi ni mímọ ọn mọ ṣe eto ogun ti ki i ṣe gẹgẹ bi ifẹ Ọlọrun, ọwọ Ọlọrun da a duro lati ṣe ohun buburu yii. Lẹyin ajakalẹ-arun yii, Dafidi ko ni ohun kan ti a le pe ni ohun igbẹkẹle fun aabo. Aanu Ọlọrun mu ki o di ọranyàn fun un lati rọ mọ Ọlọrun Olodumare. Awọn ohun ẹrù ti o ṣẹlẹ leralera, iru eyi ti kò si ninu iwe itan ti ẹmi tabi ti ayé jẹ ki o di mimọ fun un eredi rè̩ ti o fi ṣe dandan lati maa rin nipa igbagbọ ati igbọran si ohun Ọlọrun nikan ṣoṣo.

Lakotan, bi o ba si ṣe pe igberaga ni è̩ṣẹ ti o wà ni ọkàn Dafidi, oun kò gbọdọ ṣalai dupẹ lọwọ Ọlọrun nitori ti Ọlọrun fi è̩ṣẹ buburu naa hàn ki oun ba le mu un kuro ki o to pẹ ju. Igba pupọ ni Eṣu n lo igberaga lati fi awọn eniyan sinu idẹkun. S̩ugbọn Ọlọrun korira ẹṣẹ yii Oun a si maa jẹ eniyan niya gidigidi nitori rè̩. A ni lati ṣọra ki è̩ṣẹ ti n pa ẹmi run yii ma ṣe wọ inu ọkàn ati iwa wa.

Ọna Ọlọgbọn ti Dafidi Gba Lakoko Iṣoro

A le ri i ninu akọsilẹ yii pe nipasẹ ẹri ọkàn ni Ọlọrun kọ fi ba Dafidi sọrọ. Ọlọrun mu un wa si ọkàn ati aya rẹ pé o ti dẹṣẹ, Dafidi si ke pe Ọlọrun fun ìdande: Iwe Mimọ sọ fun ni pe Ọlọrun wa Alaaanu dariji i.

S̩ugbọn Dafidi ni ohun kan lati ṣe ki idariji rè̩ ki o to tè̩ é̩ lọwọ patapata. Ohun ti awọn miiran ni lati ṣe ni atunṣe – eyi yii ni mimu ohun ti o wọ bọ si titọ ninu ohunkohun ti wọn ba ti fi ṣe ẹlomiran nibi. Ọlọrun ki i dari è̩ṣẹ ohun ti o wà ni ipa wa lati mu bọ si titọ ji wa patapata. Ofin ati Ihinrere kọ wa bi o ti ṣe ohun danindanin to lati ṣe atunṣe bi a ba fẹ ki Ọlọrun ki o dariji wa. S̩ugbọn awọn è̩ṣẹ miiran wà ti a ṣẹ ọmọnikeji wa ti a kò le ṣe atunṣe rè̩. Ẹni ti a fi ọrọ bajẹ tabi ti a ṣe ni ibi le ti kú ki ẹlẹṣẹ naa tó tọ Ọlọrun wa fun idariji. A kò le tọ wọn lọ mọ tabi beere idariji lọwọ wọn, ṣugbọn ninu eyi, Ọlọrun yoo dariji ẹlẹṣẹ naa.

Awọn ere ti o daju wà fun awọn è̩ṣẹ miiran, bi o tilẹ jẹ pe a ti mu ẹbi è̩ṣẹ wọn kuro, ti Ọlọrun si ti dariji ẹlẹṣẹ naa patapata. Nigba miiran awọn àpá èrè è̩ṣẹ naa yoo kù diẹ silẹ lati ran ẹni ti a dariji naa leti lati inu iru ọfìn ti Ọlọrun ti yọ ọ jade. Nigba miiran ere ti o n tẹle igbesi-aye è̩ṣẹ ni ailera ara tabi abuku arun ninu ara ti igbesi aye è̩ṣẹ mu wá. Nigba miiran ẹwẹ, awọn ere yii jẹ idajọ ti Ọlọrun ran tabi ti O gbà laye ni ibawi lati mú awọn idarọ tabi eeri ẹmi kuro ninu igbesi aye ẹni ti a tun bi. Dafidi ri i pe oun gbọdọ ṣe tayọ bìbeere idariji è̩ṣẹ nikan lọwọ Ọlọrun ni akoko yii. A gba a laye lati yan ọkan ninu awọn idajọ mẹta ti o n bọ lori rè̩ ati orilẹ-ède Israẹli.

Ninu ohun ti Dafidi yàn, a ri i pe o huwa ọlọgbọn, o si ṣe gẹgẹ bi eniyan ṣe ni lati ṣe. O yàn lati ṣubu si ọwọ Ọlọrun, nitori ti o wi pe, “nu rè̩ pọ.” Oun kò beere lati bọ kuro ninu ijiya ti o tọ si i. Oun kò yàn ọna ti o rọrun fun ara rè̩. Ohun ti o n fẹ ni pe ki ijiya rè̩ ki o ti ọwọ Ọlọrun wa, ki o ma ṣe lati ọdọ eniyan. Dafidi mọ bi Ọlọrun ti ni aanu ati ifẹ to, o si mọ bi eniyan ti kún fun iwa ika ati owú to. O ṣe ọlọgbọn lọpọlọpọ lati yan ibawi Oluwa.

Bi Dafidi ba ti yan ogun, oun paapaa i ba wà lai lewu niwọn-igba ti wọn ti ṣe ofin pe ki Dafidi ki o má lọ si oju ogun mọ. Bi o ba jẹ pe o yan iyàn, ki yoo ni iṣoro nitori pe pupọ ninu awọn iranṣẹ rè̩ ni i ba yàn lati fi ara wọn sinu iṣoro kaka ki ọba wọn ki o jiya. Paapaa, Dafidi jẹ ọlọrọ, bi a kò ba tilẹ fun un ni ounjẹ, o ni owo tó lati ra ounjẹ. S̩ugbọn o fi titobi ifẹ ọkan rè̩ hàn ni yiyàn lati ṣubu si ọwọ Ọlọrun ki o le ni ipin ninu ajakalẹ-arun naa.

Dafidi mọ pe Ọlọrun ki i ṣe ojusaju eniyan ninu idajọ Rè̩, yoo si jẹ ẹnikẹni ti o ba ṣẹ niya. O mọ pe kò si ọwọ eniyan tabi ogiri aafin ọba ti o le sé ọwọ ibinu Ọlọrun mọ, lati ṣiji bo oun ati ẹbi rè̩. Nitori naa nipa bi o ti ṣe yii, Dafidi fi ara rè̩ si ipo kan naa pẹlu awọn iranṣẹ rẹ ti o rẹlẹ ju lọ lati ni ipin kan naa ninu idajọ Ọlọrun. Ko si tabitabi pe Ọlọrun ri iwa irẹlẹ ọmọ-ọdọ Rè̩ ti o ronupiwada yii.

Igbẹkẹle ninu Ọlọrun tabi Eniyan

Aṣiri yiyàn ti Dafidi yàn lati ṣubu si ọwọ Ọlọrun jé̩ fifaramọ ati gbigbẹkẹle Ọlọrun Alaaye. Ọpọlọpọ eniyan ni yoo yàn lati ṣubu si ọwọ eniyan ju ati gbẹkẹle Ọlọrun nigba ti wahala ba de si igbesi aye wọn. Oju wọn a maa fọ si ọkẹ aimoye eniyan ti Ọlọrun n tu ninu, ti O n wosan, ti O n gbala, ti O si n da nide. Awọn ti kò ri ibukun wọnyi gbà nikan ni oju wọn n ri. Awọn ti o ni igbẹkẹle ninu apa ẹran ara kò ni le ri ayarọ ti n rin, ti o n fo fayọ ti o si n yin Ọlọrun logo. Posi okú nikan ni wọn n ri tabi awọn wọnni ti o n jiya ti kò i ti ri ibukun wọnni ti Ọlọrun ti pese silẹ gba. Wọn kuna lati wo odi keji ọran naa lati ri ogunlọgọ eniyan ti aye wọn ti bajẹ nitori aṣiṣe ẹlomiran, ti oju rè̩ ko riran kọja igi imu rè̩ -- awọn wọnni ti awọn ọlọgbọn ori ti fi dan awari ọgbọn wo lati ṣe iranwọ fun wọn tọkantọkan ṣugbọn ti o bu wọn lọwọ.

Kò si aanu tabi ẹdùn fun ẹlomiran ti eniyan le ni, bi ẹni naa tilẹ jẹ ẹni nla tabi ọlọla ju lọ ti a le fi we aanu ati ifẹ Ọlọrun wa ti kò lopin. Kò si ọgbẹ naa ninu aye yii ti Ọlọrun kò le wosan; ṣugbọn ọpọlọpọ ọgbẹ ati ibanujẹ wà ninu aye ti ẹnikẹni kò le wosan, kaka bẹẹ, wọn tun n fi kún un ni. Ẹ jẹ ki a ṣe bi ti Dafidi ti o yàn lati ṣubu si ọwọ Ọlọrun ju ati ṣubu si ọwọ eniyan, ati lati gbẹkẹle igbala Ọlọrun ju lati ni igbẹkẹle ninu ọgbọn ara rè̩.

Ihà ti Dafidi kọ si Eto Ọlọrun

Bi o tilẹ jẹ pe Dafidi wà ninu wahala ati imi-ẹdun, sibẹ o ṣi ọkàn rẹ paya si ọdọ Ọlọrun. Eyi ni iyatọ nla ti o wà laaarin oun ati Saulu, ọba ti o jẹ ṣaaju rè̩. Aanu Ọlọrun fi Saulu silẹ nitori ti o kọ Ọlọrun silẹ, o si yipada kuro lọdọ Rè̩ patapata. Ni akoko iṣoro, nigba ti ọjọ aye rè̩ kù fẹẹfẹ, Saulu wa Ọlọrun lọna agalamaṣa, o si kú ikú apẹyinda kuro ninu igbagbọ.

S̩ugbọn Dafidi yatọ si eyi, nitori pe nigba ti o wà ninu idaamu oun kò kọ Ọlọrun rè̩ silẹ, kaka bẹẹ o sa tọ Ọ lọ. Ọlọrun ni ibi isadi rè̩ nigba ipọnju. Ọlọrun ni ẹni ti Dafidi kọ jẹwọ è̩ṣẹ rè̩ fun, Oun ni o si kọ tọ lọ fun iranlọwọ ati idande. Dafidi fa sẹyin, ṣugbọn o ri aanu Ọlọrun gbà pada nitori ti o ronupiwada o si fi ara rè̩ le aanu Ọlọrun lọwọ. Saulu pada sẹyin kuro ninu igbagbọ o si ṣegbe ráuráu nitori pe o kọ Ọlọrun silẹ, o si kọ lati ronupiwada è̩ṣẹ ati iṣọtẹ rè̩.

S̩ugbọn Dafidi kò kọ Ọlọrun silẹ gẹgẹ bi awọn Ju ti ṣe nigba ti Kristi wà ni aye. Oun kò fẹ ṣe ohun kan lodi si ipinnu Ọlọrun. Adura rè̩ ni pe, “Ifẹ tirẹ ni ki a ṣe,” bi o tilẹ jẹ pe kò sọ wọn jade. Bakan naa ni o ṣe ni akoko yii. O mọ bi è̩ṣẹ rè̩ ti buru to, o si bẹbẹ lọdọ Ọlọrun ki o jẹ ki ọwọ idajọ Rè̩ ki o wà lara oun ati idile baba oun. Itumọ eyi ni pe ki awọn arakunrin rè̩ ati awọn arabinrin rè̩ jẹ alabapin pẹlu rè̩ ninu ijiya naa.

È̩bè̩ yii ti ṣe àjèji to! Adura awọn Ju igba aye Kristi yatọ si eyi. Wọn wi pe, “Ki ẹjẹ rè̩ wà li ori wa, ati li ori awọn ọmọ wa.” Gẹgẹ bi orilẹ-ède, wọn kò ni inu-didun si eto Ọlọrun fun wọn. Wọn kò fẹ ni ipin ninu ifẹ Ọlọrun si wọn. Wọn kò si bikita bi awọn ọmọ wọn tilẹ wa labẹ ègún to bẹẹ ti wọn kò fi ni le mú eto Ọlọrun ṣẹ. Wọn yan ẹbi è̩ṣẹ nla fun ara wọn ati fun awọn ọmọ wọn -- è̩ṣẹ ayebaye ti i ṣe kikọ ati didá Ọmọ Ọlọrun lẹbi ikú. Ègún ati ẹbi è̩ṣẹ yii ni o fa ituka ati ikolẹru awọn Ọmọ Israẹli gẹgẹ bi orilẹ-ède.

S̩ugbọn a le ri i nihin yii pe Dafidi fi ọkàn si ifẹ ati eto Ọlọrun loju mejeeji. Ọlọrun ti sọ pe lati idile Dafidi ni a o ti gbe Ijọba ainipẹkun dide. Fun Dafidi lati wi pe, “Jẹ ki ọwọ rẹ, emi bè̩ ọ, ki o wà li ara mi, ati li ara idile mi” – adura ti a le ni ero pe o yẹ ki o gba dipo eyi – yoo jasi pe Dafidi n fa sẹyin kuro ninu majẹmu ti Ọlọrun ba a da nipa idile rè̩. Eyi i bá jasi pe eto Ọlọrun yoo falẹ tabi ki o yipada si ọna miiran tabi ki o ni idena. A ri ẹri pe ohun ti Dafidi ṣe yii tọna nitori pe Ọlọrun gbọ adura rè̩ o si pa majẹmu rè̩ mọ ti o wi pe ijọba Dafidi yoo jẹ Ijọba ti kò nipẹkun.

Olufọkansin ara Jebusi ati Irubọ Dafidi si Ọlọrun

A tun le ri iwa rere ẹni kan ti ohun ti o n ṣẹlẹ yii mú lọkàn. Lai si aniani, eredi pupọ ni o wà nidi ilẹ ti Arauna yọọda fun Dafidi: o n bẹru fun Dafidi ọba; ẹdun awọn eniyan wa lọkàn rè̩; o n wa alaafia ara rè̩; oun paapaa fẹ gbe ogo Ọlọrun ga. Arauna fẹ ṣe irubọ ti o pọ ti o si niyelori. O fẹ ṣe ipa ti rẹ -- ati ju bẹẹ lọ pẹlu. O ṣetan lati fi ohun gbogbo ti o ni silẹ lati gba ẹmi rè̩ ati ti gbogbo Israẹli là.

S̩ugbọn ohun ti o ṣẹlẹ yii fi iru ọkàn ti Dafidi ni hàn. Oun kò fẹ fi ohun ti kò ná an ni owo ṣe irubọ si Ọlọrun. Bi o ba gba ọrẹ Arauna irubọ naa yoo jẹ ti Arauna, ki yoo si jẹ ti Dafidi. Ọlọrun ni o n beere irubọ naa lọwọ Dafidi, nitori naa oun kò fẹ lati tọ ọna miiran a fi ọna ti Ọlọrun nikan. O fẹ lati ná ohunkohun ti yoo gba a.

Ọna miiran i bá má ṣe itẹwọgba lọdọ Ọlọrun, Ẹniti o n fẹ igbọran kikún si gbogbo aṣẹ Rè̩. Bi o tilẹ jẹ pe Dafidi san owo ilẹ ati irubọ naa, sibẹ Arauna ṣe irubọ ti rè̩. A fi ilẹ ipaka rè̩ du u, ati awọn ẹran-ọsin rè̩ ti o ti n lo ti o si n mu owo wọle fun un. O ni lati tun bẹrẹ igbesi aye ọtun ni ilẹ miiran. Lai si aniani inu rẹ i bá dun pupọ wi pe oun ṣe irubọ naa bi o ba ṣe pe o wà laaye ni ọjọ naa ti eto Ọlọrun fun ilẹ naa fara han.

A maa n wi pe, “Ibiti a ba gbe ṣe ifararubo ti o jinlẹ yoo di Tẹmpili Ọlọrun Alaaye.” Otitọ ni eyi ni ọna ti ẹmi bi o ti jẹ otitọ pẹlu nipa ti ara ninu itan yii. Ibi ti a ti ṣe irubọ yii ni Oke Moria nibi ti Sọlomọni kọ Tẹmpili si nigbooṣe. Ibi irubọ yii si ti di ibi ti aimoye ọkẹ eniyan ti gbadura ti adura wọn si ti gbà.

S̩iro ẹgbẹẹgbẹrun ẹbọ ti a ti mu wa sibẹ ti Ọlọrun si ti tẹwọgba! S̩iro aimoye ọkẹ eniyan ti o ti ri idariji è̩ṣẹ wọn gba nibẹ! Wo ogunlọgọ ti a ti sọ di mimọ nibẹ! Wo ọpọ ọkàn ti o ti ri ibukun gba! Wo ere iyebiye ti o tẹle ẹbọ ti Arauna ati Dafidi rú ki wọn ki o le pese aye kan silẹ fun ibi isin Ọlọrun.

Ina ti Ọrun sọkalẹ sori ẹbọ ti Dafidi rú nibẹ. Ọlọrun gbà ẹbọ naa. Wọn ri idariji pipe gbà. Ajakalẹ-arun naa si duro. Alaafia ati ojurere Ọlọrun pada bọ si orilẹ-ède Israẹli ati sori Dafidi ọba wọn. Wo bi aanu ati idariji Ọlọrun wa ti jẹ iyanu to!

Questions
AWỌN IBEERE
  1. 1 È̩ṣẹ wo ni Dafidi dá ni akoko yii?

  2. 2 Ki ni ero ti o ro pe o pilẹ è̩ṣẹ yii?

  3. 3 Igba melo ni Iwe Mimọ kọ akọsilẹ pe a ka iye awọn Ọmọ Israẹli lọna bayii?

  4. 4 Bawo ni ọwọ Ọlorun ṣe sọ igbẹkẹle ti kò nilaari ti o le wa lọkàn Dafidi di asan?

  5. 5 Bawo ni Ọlọrun ṣe ran idajọ wa nitori è̩ṣẹ yii?

  6. 6 Ohun ijinlẹ wo ni o ṣẹlẹ nipa ijiya yii?

  7. 7 Iru iwa rere wo ni o fara han ninu Dafidi nipa yiyàn ọna idajọ ti o yàn?

  8. 8 Fi iwa Dafidi ati Saulu wé ara wọn nigba ti awọn mejeeji wa ninu ipọnju.

  9. 9 Iru iwa iwuri wo ni iwọ ri ninu igbesi-aye Arauna?

  10. 10 Sọ ohun meji miiran ti o ṣẹlẹ ni Oke Moria, ki o si sọ ohun ti awọn mẹtẹẹta duro fun lọna ti ẹmi.